- Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible 2017 Nahumu Ìwé Wòlíì Nahumu Nahumu Nh Ìwé Wòlíì Nahumu Ọ̀rọ̀-ìmọ̀ nípa Ninefe. Ìwé ìran Nahumu ará Elkoṣi. Ìbínú Olúwa sí Ninefe Ọlọ́run ń jẹ owú, ó sì ń gbẹ̀san, Olúwa ń gbẹ̀san, ó sì kún fún ìbínú. Olúwa ń gbẹ̀san lára àwọn ọ̀tá rẹ̀. Ìbínú rẹ̀ kò sì yí padà lórí àwọn ọ̀tá rẹ̀. Olúwa lọ́ra láti bínú, ó sì tóbi ní agbára; Olúwa kì yóò fi àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ sílẹ̀ láìjìyà. Ọ̀nà rẹ̀ wà nínú afẹ́fẹ́ àti nínú ìjì, ìkùùkuu sánmọ̀ sì ni eruku ẹsẹ̀ rẹ̀. Ó bá òkun wí, ó sì mú kí ó gbẹ; Ó sìsọ gbogbo odò di gbígbẹ. Baṣani àti Karmeli sì rọ. Ìtànná Lebanoni sì rẹ̀ sílẹ̀. Àwọn òkè ńlá wárìrì níwájú rẹ̀, àwọn òkè kéékèèké sì di yíyọ́, ilẹ̀ ayé sì jóná níwájú rẹ̀, àní ayé àti gbogbo àwọn tí ń gbé inú rẹ̀. Ta ni ó lé dúró níwájú ìbínú rẹ̀? Ta ni ó lé faradà gbígbóná ìbínú rẹ̀? Ìbínú rẹ̀ tú jáde bí iná; àwọn àpáta sì fọ́ túútúú níwájú rẹ̀. Rere ni Olúwa, òun ni ààbò ní ọjọ́ ìpọ́njú. Òun sì tọ́jú àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé e, ṣùgbọ́n pẹ̀lú ìkún omi ńlá ní òun yóò fi ṣe ìparun láti ibẹ̀ dé òpin; òkùnkùn yóò sì máa lépa àwọn ọ̀tá rẹ̀. Kí ni ẹ̀yìn ń gbìmọ̀ lòdì sí Olúwa? Òun yóò fi òpin sí i, ìpọ́njú kì yóò wáyé ní ìgbà kejì. Wọn yóò sì lọ́lù papọ̀ bí ẹ̀gún òṣùṣú wọn yóò sì mu àmupara nínú ọtí wáìnì wọn a ó sì run wọn gẹ́gẹ́ bi àgékù koríko gbígbẹ. Láti ọ̀dọ̀ rẹ, ìwọ Ninefe, ni ẹnìkan ti jáde wá tí ó ń gbèrò ibi sí Olúwa ti ó sì ń gbìmọ̀ búburú. Báyìí ni Olúwa wí: “Bí wọ́n tilẹ̀ ni ìfọwọ́sowọ́pọ̀, tí wọ́n sì pọ̀ níye, ṣùgbọ́n, báyìí ní a ó ké wọn lulẹ̀, nígbà tí òun ó bá kọjá. Bí mo tilẹ̀ ti pọ́n ọ lójú ìwọ Juda, èmi kì yóò pọ́n ọ lójúmọ́. Nísinsin yìí ni èmi yóò já àjàgà wọn kúrò ní ọrùn rẹ èmi yóò já ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ rẹ dànù.” Olúwa ti fi àṣẹ kan lélẹ̀ nítorí tìrẹ Ninefe: “Ìwọ kì yóò ni irú-ọmọ láti máa jẹ́ orúkọ rẹ mọ́, Èmi yóò pa ère fínfín àti ère dídà run tí ó wà nínú tẹmpili àwọn ọlọ́run rẹ. Èmi yóò wa ibojì rẹ, nítorí ẹ̀gbin ni ìwọ.” Wò ó, lórí àwọn òkè, àwọn ẹsẹ̀ ẹni tí ó mú ìròyìn ayọ̀ wá, ẹni tí ó ń kéde àlàáfíà. Ìwọ Juda, pa àṣẹ rẹ tí ó ní ìrònú mọ́, kí ó sì san àwọn ẹ̀jẹ́ rẹ. Àwọn ènìyàn búburú kì yóò sì gbóguntì ọ́ mọ́; wọn yóò sì parun pátápátá. Ìṣubú Ninefe Àwọn apanirun ti dìde sí ọ, ìwọ Ninefe. Pa ilé ìṣọ́ mọ́, ṣọ́ ọ̀nà náà, di àmùrè, ẹ̀gbẹ́ rẹ kí ó le múra gírí. Olúwa yóò mú ọláńlá Jakọbu padà sípò gẹ́gẹ́ bí ọláńlá Israẹli bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn apanirun ti pa ibẹ̀ run, tí wọ́n sì ba ẹ̀ka àjàrà wọn jẹ́. Asà àwọn ọmọ-ogun rẹ̀ sì di pupa; àwọn ológun wọn sì wọ aṣọ òdòdó. Idẹ tí ó wà lórí kẹ̀kẹ́ ogun ń kọ mọ̀nàmọ́ná ní ọjọ́ tí a bá pèsè wọn sílẹ̀ tán; igi firi ni a ó sì mì tìtì. Àwọn kẹ̀kẹ́ ogun yóò ya bo àwọn pópónà, wọn yóò sì máa sáré síwá àti sẹ́yìn ní àárín ìgboro. Wọn sì dàbí ètùfù iná; tí ó sì kọ bí i mọ̀nàmọ́ná. Ninefe yóò ṣe àṣàrò àwọn ọlọ́lá rẹ̀; síbẹ̀ wọ́n ń kọsẹ̀ ní ojú ọ̀nà wọn; wọn sáré lọ sí ibi odi rẹ̀, a ó sì pèsè ààbò rẹ̀. A ó ṣí ìlẹ̀kùn àwọn odò wọ̀n-ọn-nì sílẹ̀, a ó sì mú ààfin náà di wíwó palẹ̀. A pa á láṣẹ pé ìlú náà, èyí tí a ti fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ ni a ó sì kó ní ìgbèkùn lọ. A ó sì mú un gòkè wá àti àwọn ìránṣẹ́bìnrin rẹ̀ yóò kérora bí ti ẹyẹ àdàbà, wọn a sì máa lu àyà wọn. Ninefe dàbí adágún omi, tí omi rẹ̀ sì ń gbẹ́ ẹ lọ. “Dúró! Dúró!” ni wọ́n ó máa kígbe, ṣùgbọ́n ẹnìkankan kì yóò wo ẹ̀yìn. “Ẹ kó ìkógun fàdákà! Ẹ kó ìkógun wúrà! Ìṣúra wọn ti kò lópin náà, àti ọrọ̀ kúrò nínú gbogbo ohun èlò ti a fẹ́!” Òun ti ṣòfò, ó si di asán, ó sì di ahoro: ọkàn pami, eékún ń lu ara wọn, ìrora púpọ̀ sì wà nínú gbogbo ẹgbẹ́ àti ojú gbogbo wọ́n sì rẹ̀wẹ̀sì. Níbo ni ihò àwọn kìnnìún wà àti ibi ìjẹun àwọn ọmọ kìnnìún, níbi tí kìnnìún, àní abo kìnnìún tí ń rìn, àti ọmọ kìnnìún, láìsí ohun ìbẹ̀rù. Kìnnìún tipa ọ̀pọ̀lọpọ̀ fún àwọn ọmọ rẹ̀, ó sì fún un ẹran ọdẹ ní ọrùn pa fún àwọn abo kìnnìún rẹ̀, ó sì fi ohun pípa kún ibùgbé rẹ̀ àti ihò rẹ̀ fún ohun ọdẹ. “Kíyèsi i èmi dojúkọ ọ́,” ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí. “Èmi yóò sì fi kẹ̀kẹ́ rẹ̀ wọ̀n-ọn-nì jóná nínú èéfín, idà yóò sì jẹ ọmọ kìnnìún rẹ̀ wọ̀n-ọn-nì run. Èmi yóò sì ké ohun ọdẹ rẹ kúrò lórí ilẹ̀ ayé. Ohùn àwọn ìránṣẹ́ rẹ ni a kì yóò sì tún gbọ́ mọ́.” A fi Ninefe bú Ègbé ni fún ìlú ẹ̀jẹ̀ nì, gbogbo rẹ̀ kún fún èké, ó kún fún olè, ìjẹ kò kúrò! Ariwo pàṣán àti ariwo kíkùn kẹ̀kẹ́ ogun àti jíjó ẹṣin àti gbígbọn kẹ̀kẹ́ ogun jìgìjìgì! Ológun orí ẹṣin ń fi ìgbónára ju idà wọn mọ̀nàmọ́ná ọ̀kọ̀ rẹ̀ ti ń dán yanran sí òkè! Ọ̀pọ̀lọpọ̀ si ní àwọn ẹni tí a pa, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ òkú; òkú kò sì ni òpin; àwọn ènìyàn sì ń kọsẹ̀ lára àwọn òkú. Nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ panṣágà àgbèrè tí ó rójú rere gbà, ìyá àjẹ́ tí ó ṣọ́ àwọn Orílẹ̀-èdè di ẹrú nípa àgbèrè rẹ̀ àti àwọn ìdílé nípa ìṣe àjẹ́ rẹ̀. “Èmi dojúkọ ọ́,” ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí. “Èmi ó si ká aṣọ àwọ̀tẹ́lẹ̀ rẹ ní ojú rẹ. Èmi yóò sì fi ìhòhò rẹ̀ han àwọn orílẹ̀-èdè àti ìtìjú rẹ̀ han àwọn ilẹ̀ ọba. Èmi yóò da ẹ̀gbin tí ó ni ìríra sí ọ ní ara, èmi yóò sì sọ ọ́ di aláìmọ́, èmi yóò sì sọ ọ́ di ẹlẹ́yà. Gbogbo àwọn tí ó ba sì wò ọ́ yóò sì káàánú fún ọ, wọn yóò sì wí pé, ‘Ninefe ṣòfò, ta ni yóò kẹ́dùn rẹ?’ Níbo ni èmi o ti wá olùtùnú fún ọ?” Ǹjẹ́ ìwọ ha sàn ju Tebesi lọ, èyí tí ó wà ní ibi odò Naili, tí omi sì yí káàkiri? Odò náà sì jẹ́ ààbò rẹ̀, omi si jẹ́ odi rẹ̀. Etiopia àti Ejibiti ni agbára rẹ, kò sí ní òpin; Puti àti Libia ni àwọn olùgbèjà rẹ̀. Síbẹ̀síbẹ̀ a kó o ní ìgbèkùn o sì lọ sí oko ẹrú. Àwọn ọmọ wẹ́wẹ́ rẹ̀ ni a ó fọ́ mọ́lẹ̀ ní orí ìta gbogbo ìgboro. Wọ́n sì di ìbò nítorí àwọn ọlọ́lá rẹ̀ ọkùnrin, gbogbo àwọn ọlọ́lá rẹ ni a sì fi ẹ̀wọ̀n dè. Ìwọ pẹ̀lú yóò sì mu àmupara; a ó sì fi ọ́ pamọ́ ìwọ pẹ̀lú yóò máa ṣe àfẹ́rí ààbò nítorí ti ọ̀tá náà. Gbogbo ilé ìṣọ́ agbára rẹ yóò dàbí igi ọ̀pọ̀tọ́ pẹ̀lú àkọ́pọ́n èso wọn; nígbà tí wọ́n bá ń gbọ̀n wọ́n, ọ̀pọ̀tọ́ yóò sì bọ́ sí ẹnu àwọn ọ̀jẹun. Kíyèsi gbogbo àwọn jagunjagun! Obìnrin ni gbogbo wọn. Ojú ibodè rẹ ní a ó ṣí sílẹ̀ gbagada, fún àwọn ọ̀tá rẹ; iná yóò jó ọ̀pá ìdábùú ìlẹ̀kùn ibodè rẹ. Pọn omi nítorí ìhámọ́, mú ilé ìṣọ́ rẹ lágbára sí i wọ inú amọ̀ kí o sì tẹ erùpẹ̀, kí ó sì tún ibi tí a ti ń sun bíríkì-amọ̀ ṣe kí ó le. Níbẹ̀ ni iná yóò ti jó ọ́ run; idà yóò sì ké ọ kúrò, yóò sì jẹ ọ́ bí i kòkòrò, yóò sì sọ ara rẹ̀ di púpọ̀ bí i tata, àní, di púpọ̀ bí eṣú! Ìwọ ti sọ àwọn oníṣòwò rẹ di púpọ̀ títí wọn yóò fi pọ̀ ju ìràwọ̀ ojú ọ̀run lọ, ṣùgbọ́n bi eṣú ni wọn yóò sọ ilẹ̀ náà di ahoro, wọn yóò sì fò lọ. Àwọn aládé rẹ̀ dàbí eṣú, àwọn ọ̀gágun rẹ dàbí ẹlẹ́ǹgà ńlá, èyí tí ń dó sínú ọgbà ni ọjọ́ òtútù, ṣùgbọ́n nígbà tí oòrùn jáde, wọ́n sálọ, ẹnìkan kò sì mọ ibi tí wọ́n gbé wà. Ìwọ ọba Asiria, àwọn olùṣọ́-àgùntàn rẹ̀ ń tòògbé; àwọn ọlọ́lá rẹ dùbúlẹ̀ láti sinmi. Àwọn ènìyàn rẹ fọ́nká lórí àwọn òkè ńlá, tí ẹnikẹ́ni kò sì kó wọn jọ. Kò sì sí ohun tí ó lè wo ọgbẹ́ ẹ̀ rẹ sàn; ọgbẹ́ rẹ kún fún ìrora, Gbogbo ẹni tí ó bá sì gbọ́ ìròyìn rẹ yóò pàtẹ́wọ́ lé ọ lórí, nítorí ta ni kò ní pín nínú ìwà búburú rẹ ti kò ti lópin.