- Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible 2017
Jobu
Ìwé Jobu
Jobu
Jb
Ìwé Jobu
Ìbẹ̀rẹ̀ ìgbé ayé Jobu
Ọkùnrin kan wà ní ilẹ̀ Usi, orúkọ ẹni tí í jẹ́ Jobu; ọkùnrin náà sì ṣe olóòtítọ́, ó dúró ṣinṣin, ẹni tí ó bẹ̀rù Ọlọ́run, tí ó kórìíra ìwà búburú. A sì bi ọmọkùnrin méje àti ọmọbìnrin mẹ́ta fún un. Ohun ọ̀sìn rẹ̀ sì jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárin (7,000) àgùntàn, àti ẹgbẹ̀rún mẹ́ta (3,000) ìbákasẹ, àti ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (500) àjàgà ọ̀dá màlúù, àti ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (500) abo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ó sì pọ̀; bẹ́ẹ̀ ni ọkùnrin yìí sì pọ̀jù gbogbo àwọn ará ìlà-oòrùn lọ.
Àwọn ọmọ rẹ̀ a sì máa lọ í jẹun àsè nínú ilé ara wọn, olúkúlùkù ní ọjọ́ rẹ̀; wọn a sì máa ránṣẹ́ pé arábìnrin wọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta láti jẹun àti láti pẹ̀lú wọn. Ó sì ṣe, nígbà tí ọjọ́ àsè wọn pé yíká, ni Jobu ránṣẹ́ lọ í yà wọ́n sí mímọ́, ó sì dìde ní kùtùkùtù òwúrọ̀, ó sì rú ẹbọ sísun níwọ̀n iye gbogbo wọn; nítorí tí Jobu wí pé: bóyá àwọn ọmọ mi ti ṣẹ̀, wọn kò sì ṣọpẹ́ fún Ọlọ́run lọ́kàn wọn. Bẹ́ẹ̀ ní Jobu máa ń ṣe nígbà gbogbo.
Ìdánwò Jobu àkọ́kọ́
Ǹjẹ́ ó di ọjọ́ kan, nígbà tí àwọn ọmọ Ọlọ́run wá í pé níwájú Olúwa, Satani sì wá pẹ̀lú wọn. Olúwa sì bi Satani wí pé, “Níbo ni ìwọ ti wá?”
Nígbà náà ní Satani dá Olúwa lóhùn wí pé, “Ní ìlọsíwá-sẹ́yìn lórí ilẹ̀ ayé, àti ní ìrìnkèrindò nínú rẹ̀.”
Olúwa sì sọ fún Satani pé, “Ìwọ ha kíyèsi Jobu ìránṣẹ́ mi, pé kò sí ẹni tí ó dàbí rẹ̀ ní ayé, ọkùnrin tí í ṣe olóòtítọ́, tí ó sì dúró ṣinṣin, ẹni tí ó bẹ̀rù Ọlọ́run, ti ó sì kórìíra ìwà búburú.”
Nígbà náà ni Satani dá Olúwa lóhùn wí pé, “Jobu ha bẹ̀rù Ọlọ́run ní asán bí?” “Ìwọ kò ha ti ṣọgbà yìí ká, àti yí ilé rẹ̀ àti yí ohun tí ó ní ká, ní ìhà gbogbo? Ìwọ bùsi iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀, ohun ọ̀sìn rẹ̀ sì ń pọ̀ si ní ilẹ̀. Ǹjẹ́, nawọ́ rẹ nísinsin yìí, kí ó sì fi tọ́ ohun gbogbo tí ó ni; bí kì yóò sì bọ́hùn ni ojú rẹ.”
Olúwa sì dá Satani lóhùn wí pé, “Kíyèsi i, ohun gbogbo tí ó ní ń bẹ ní ìkáwọ́ rẹ, kìkì òun tìkára rẹ̀ ni ìwọ kò gbọdọ̀ fi ọwọ́ rẹ kàn.”
Bẹ́ẹ̀ ni Satani jáde lọ kúrò níwájú Olúwa.
Ó sì di ọjọ́ kan nígbà tí àwọn ọmọ rẹ̀ ọkùnrin àti obìnrin, tí wọ́n mu ọtí wáìnì nínú ilé ẹ̀gbọ́n wọn ọkùnrin, oníṣẹ́ kan sì tọ Jobu wá wí pé, “Àwọn ọ̀dá màlúù ń tulẹ̀, àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ sì ń jẹ ní ẹ̀gbẹ́ wọn, àwọn ará Sabeani sì kọlù wọ́n, wọ́n sì ń kó wọn lọ pẹ̀lú, wọ́n ti fi idà sá àwọn ìránṣẹ́ pa, èmi nìkan ṣoṣo ní ó sá àsálà láti ròyìn fún ọ.”
Bí ó ti ń sọ ní ẹnu; ẹnìkan dé pẹ̀lú tí ó sì wí pé, “Iná ńlá Ọlọ́run ti ọ̀run bọ́ sí ilẹ̀, ó sì jó àwọn àgùntàn àti àwọn ìránṣẹ́; èmi nìkan ṣoṣo ní ó sálà láti ròyìn fún ọ.”
Bí ó sì ti ń sọ ní ẹnu, ẹnìkan sì dé pẹ̀lú tí ó wí pé, “Àwọn ará Kaldea píngun sí ọ̀nà mẹ́ta, wọ́n sì kọlù àwọn ìbákasẹ, wọ́n sì kó wọn lọ, pẹ̀lúpẹ̀lú wọ́n sì fi idà sá àwọn ìránṣẹ́ pa; èmi nìkan ṣoṣo ni ó sá àsálà láti ròyìn fún ọ!”
Bí ó ti ń sọ ní ẹnu, ẹnìkan dé pẹ̀lú tí ó sì wí pé àwọn ọmọ rẹ ọkùnrin àti obìnrin ń jẹ, wọ́n ń mu ọtí wáìnì nínú ilé ẹ̀gbọ́n. Sì kíyèsi i, ẹ̀fúùfù ńlá ńlá ti ìhà ijù fẹ́ wá kọlu igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ilé, ó sì wó lu àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin náà, wọ́n sì kú, èmi nìkan ṣoṣo ni ó yọ láti ròyìn fún ọ.
Nígbà náà ni Jobu dìde, ó sì fa aṣọ ìgúnwà rẹ̀ ya, ó sì fá orí rẹ̀ ó wólẹ̀ ó sì gbàdúrà wí pé,
“Ní ìhòhò ní mo ti inú ìyá mi jáde wá,
ni ìhòhò ní èmi yóò sì tún padà lọ.
Olúwa fi fún ni, Olúwa sì gbà á lọ,
ìbùkún ni fún orúkọ Olúwa.”
Nínú gbogbo èyí Jobu kò ṣẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò sì fi òmùgọ̀ pe Ọlọ́run lẹ́jọ́.
Ìdánwò Jobu lẹ́ẹ̀kejì
Ó sì tún di ọjọ́ kan nígbà tí àwọn ọmọ Ọlọ́run wá síwájú Olúwa, Satani sì wá pẹ̀lú wọn láti pe níwájú Olúwa. Olúwa sì bi Satani pé, “Níbo ni ìwọ ti wá?”
Satani sì dá Olúwa lóhùn pé, “Láti lọ síwá sẹ́yìn lórí ilẹ̀ ayé àti ní ìrìnkèrindò nínú rẹ̀.”
Olúwa sì wí fún Satani pé, “Ìwọ ha kíyèsi Jobu ìránṣẹ́ mi, pé, kò sí ẹni tí ó dàbí rẹ̀ ní ayé, ọkùnrin tí ń ṣe olóòtítọ́ tí ó sì dúró ṣinṣin, ẹni tí ó bẹ̀rù Ọlọ́run, tí ó sì kórìíra ìwà búburú, bẹ́ẹ̀ ni ó sì di ìwà òtítọ́ rẹ̀ mu ṣinṣin, bí ìwọ tilẹ̀ ti dẹ mí sí i láti run ún láìnídìí.”
Satani sì dá Olúwa lóhùn wí pé, “Awọ fún awọ; àní ohun gbogbo tí ènìyàn ní, òun ni yóò fi ra ẹ̀mí rẹ̀. Ṣùgbọ́n nawọ́ rẹ nísinsin yìí, kí ó tọ́ egungun rẹ̀ àti ara rẹ̀, bí kì yóò sì bọ́hùn ní ojú rẹ.”
Olúwa sì wí fún Satani pé, “Wò ó, ó ń bẹ ní ìkáwọ́ rẹ, ṣùgbọ́n dá ẹ̀mí rẹ̀ sí.”
Bẹ́ẹ̀ ni Satani jáde lọ kúrò níwájú Olúwa, ó sì sọ Jobu ní oówo kíkankíkan láti àtẹ́lẹsẹ̀ títí dé àtàrí rẹ̀. Ó sì mú àpáàdì, ó fi ń họ ara rẹ̀, ó sì jókòó nínú eérú.
Nígbà náà ni aya rẹ̀ wí fún un pé, “Ìwọ di ìwà òtítọ́ mú síbẹ̀! Bú Ọlọ́run, kí ó sì kú!”
Ṣùgbọ́n ó dá a lóhùn pé, “Ìwọ sọ̀rọ̀ bí ọ̀kan lára àwọn aṣiwèrè obìnrin ti í sọ̀rọ̀; há bà! Àwa yóò ha gba ìre lọ́wọ́ Ọlọ́run, kí a má sì gba ibi?”
Nínú gbogbo èyí, Jobu kò fi ètè rẹ̀ ṣẹ̀.
Ọ̀rẹ́ Jobu mẹ́ta
Nígbà tí àwọn ọ̀rẹ́ Jobu mẹ́ta gbúròó gbogbo ibi tí ó bá a, wọ́n wá, olúkúlùkù láti ibùjókòó rẹ̀; Elifasi, ara Temani àti Bilidadi, ará Ṣuhi, àti Sofari, ará Naama: nítorí pé wọ́n ti dájọ́ ìpàdé pọ̀ láti bá a ṣọ̀fọ̀, àti láti ṣìpẹ̀ fún un. Nígbà tí wọ́n gbójú wọn wò ní òkèrè réré, tí wọ́n kò sì mọ̀ ọ́n, wọ́n gbé ohùn wọn sókè, wọ́n sọkún: olúkúlùkù sì fa aṣọ ìgúnwà rẹ̀ ya, wọ́n sì ku erùpẹ̀ sí ojú ọ̀run, wọ́n sì tẹ́ orí gbà á. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n jókòó tì í ní inú erùpẹ̀ ní ọjọ́ méje ti ọ̀sán ti òru, ẹnikẹ́ni kò sì bá a sọ ọ̀rọ̀ kan, nítorí tí wọ́n ti rí i pé ìbànújẹ́ rẹ̀ pọ̀ jọjọ.
Jobu ráhùn sí Ọlọ́run
Ẹ̀yìn èyí ní Jobu yanu, ó sì fi ọjọ́ ìbí rẹ̀ ré Jobu sọ, ó sì wí pé,
“Kí ọjọ́ tí a bí mi kí ó di ìgbàgbé,
àti òru ni, nínú èyí tí a wí pé, ‘A lóyún ọmọkùnrin kan!’
Kí ọjọ́ náà kí ó já si òkùnkùn,
kí Ọlọ́run kí ó má ṣe kà á sí láti ọ̀run wá;
bẹ́ẹ̀ ni kí ìmọ́lẹ̀ kí ó má ṣe mọ́ sí i.
Kí òkùnkùn àti òjìji ikú fi ṣe ti ara wọn;
kí àwọsánmọ̀ kí ó bà lé e;
kí ìṣúdudu ọjọ́ kí ó pa láyà.
Kí òkùnkùn kí ó ṣú bo òru náà biribiri,
kí ó má ṣe yọ pẹ̀lú ọjọ́ ọdún náà:
kí a má ṣe kà a mọ́ iye ọjọ́ oṣù.
Kí òru náà kí ó yàgàn;
kí ohun ayọ̀ kan kí ó má ṣe wọ inú rẹ̀ lọ.
Kí àwọn tí í fi ọjọ́ gégùn ún kí o fi gégùn ún,
tí wọ́n mura tán láti ru Lefitani sókè.
Kí ìràwọ̀ òwúrọ̀ ọjọ́ rẹ̀ kí ó ṣókùnkùn;
kí ó má wá ìmọ́lẹ̀, ṣùgbọ́n kí ó máa mọ́ sí i,
bẹ́ẹ̀ ni kí ó má ṣe rí àfẹ̀mọ́júmọ́
nítorí tí kò sé ìlẹ̀kùn inú ìyá mi,
láti pa ìbànújẹ́ rẹ́ ní ojú mi.
“Èéṣe tí èmi kò fi kú láti inú wá,
tàbí tí èmi kò kú ní ìgbà tí mo ti inú jáde wá?
Èéṣe tí orúnkún wá pàdé mi,
tàbí ọmú tí èmi yóò mu?
Ǹjẹ́ nísinsin yìí èmi ìbá ti dùbúlẹ̀ jẹ́ẹ́;
èmi ìbá ti sùn, èmi ìbá ti sinmi
pẹ̀lú àwọn ọba àti ìgbìmọ̀ ayé
tí wọ́n mọ ilé fún ara wọn wá dùbúlẹ̀ nínú ìsọdahoro.
Tàbí pẹ̀lú àwọn ọmọ-aládé
tí ó ní wúrà, tí wọ́n sì fi fàdákà kun ilé wọn.
Tàbí bí ọlẹ̀ tí a sin, èmi kì bá ti sí:
bí ọmọ ìṣunú tí kò rí ìmọ́lẹ̀?
Níbẹ̀ ni ẹni búburú ṣíwọ́ ìyọnilẹ́nu,
níbẹ̀ ni ẹni àárẹ̀ wà nínú ìsinmi.
Níbẹ̀ ni àwọn ìgbèkùn sinmi pọ̀,
wọn kò gbóhùn amúnisìn mọ́.
Àti èwe àti àgbà wà níbẹ̀,
ẹrú sì di òmìnira kúrò lọ́wọ́ olówó rẹ̀.
Jobu kígbe nínú ìrora rẹ̀
“Nítorí kí ni a ṣe fi ìmọ́lẹ̀ fún òtòṣì,
àti ìyè fún ọlọ́kàn kíkorò,
tí wọ́n dúró de ikú, ṣùgbọ́n òun kò wá,
tí wọ́n wá a jù ìṣúra tí a bò mọ́lẹ̀ pamọ́ lọ.
Ẹni tí ó yọ̀ gidigidi,
tí inú wọ́n sì dùn nígbà tí wọ́n wá ibojì òkú rí?
Kí ni a fi ìmọ́lẹ̀ fún ẹni
tí ọ̀nà rẹ̀ fi ara pamọ́ fún,
tí Ọlọ́run sì ṣọgbà dí mọ́ ká?
Nítorí pé èémí-ẹ̀dùn wà ṣáájú oúnjẹ mi;
ìkérora mi sì tú jáde bí omi.
Nítorí pé ohun náà tí mo bẹ̀rù gidigidi ni ó dé bá mi yìí,
àti ohun tí mo fòyà rẹ̀ bá mi ó sì ṣubú lù mí.
Èmi wà láìní àlàáfíà, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò ní ìsinmi;
bẹ́ẹ̀ ni èmi kò ni ìfàyàbalẹ̀, bí kò ṣe ìdààmú.”
Ọ̀rọ̀ Elifasi: Ọlọ́run kì í fi ìyà jẹ olódodo
Ìgbà náà ni Elifasi, ará Temani dáhùn wí pé,
“Bí àwa bá fi ẹnu lé e, láti bá ọ sọ̀rọ̀, ìwọ o ha banújẹ́?
Ṣùgbọ́n ta ni ó lè pa ọ̀rọ̀ mọ́ ẹnu láìsọ?
Kíyèsi i, ìwọ sá ti kọ́ ọ̀pọ̀ ènìyàn,
ìwọ ṣá ti mú ọwọ́ aláìlera le.
Ọ̀rọ̀ rẹ ti gbé àwọn tí ń ṣubú lọ dúró,
ìwọ sì ti mú eékún àwọn tí ń wárìrì lera.
Ṣùgbọ́n nísinsin yìí ó dé bá ọ, ó sì rẹ̀ ọ́, ó kọlù ọ́;
ara rẹ kò lélẹ̀.
Ìbẹ̀rù Ọlọ́run rẹ kò ha jẹ́ ìgbẹ́kẹ̀lé rẹ
àti ìdúró ọ̀nà rẹ kò ha sì jẹ́ ìrètí rẹ?
“Èmi bẹ̀ ọ́ rántí, ta ni ó ṣègbé rí láìṣẹ̀?
Tàbí níbo ni a gbé gé olódodo kúrò rí?
Àní bí èmi ti rí i pé, àwọn tí ń ṣe ìtulẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀,
tí wọ́n sì fún irúgbìn ìwà búburú, wọn a sì ká èso rẹ̀ náà.
Nípa ìfẹ́ sí Ọlọ́run wọn a ṣègbé,
nípa èémí ìbínú rẹ̀ wọn a parun.
Bíbú ramúramù kìnnìún àti ohùn òǹrorò kìnnìún
àti eyín àwọn ẹgbọrọ kìnnìún ní a ká.
Kìnnìún kígbe, nítorí àìrí ohun ọdẹ,
àwọn ẹgbọrọ kìnnìún sísanra ni a túká kiri.
“Ǹjẹ́ nísinsin yìí a fi ohun àṣírí kan hàn fún mi,
etí mi sì gbà díẹ̀ nínú rẹ̀.
Ní ìrò inú lójú ìran òru,
nígbà tí oorun èjìká kùn ènìyàn.
Ẹ̀rù bà mí àti ìwárìrì
tí ó mú gbogbo egungun mi jí pépé.
Nígbà náà ni ẹ̀mí kan kọjá lọ ní iwájú mi,
irun ara mi dìde dúró ṣánṣán.
Ó dúró jẹ́ẹ́,
ṣùgbọ́n èmi kò le wo àpẹẹrẹ ìrí rẹ̀,
àwòrán kan hàn níwájú mi,
ìdákẹ́rọ́rọ́ wà, mo sì gbóhùn kan wí pé,
‘Ẹni kíkú le jẹ́ olódodo ju Ọlọ́run,
ènìyàn ha le mọ́ ju ẹlẹ́dàá rẹ̀ bí?
Kíyèsi i, òun kò gbẹ́kẹ̀lé àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀,
nínú àwọn angẹli rẹ̀ ní ó sì rí ẹ̀ṣẹ̀.
Mélòó mélòó àwọn tí ń gbé inú ilé amọ̀,
ẹni tí ìpìlẹ̀ wọ́n jásí erùpẹ̀
tí yóò di rírun kòkòrò.
A pa wọ́n run láàrín òwúrọ̀ àti àṣálẹ́
wọ́n sì parun títí láé, láìrí ẹni kà á sí.
A kò ha ké okùn iye wọ́n kúrò bí?
Wọ́n kú, àní láìlọ́gbọ́n?’
Ìjìyà jẹ́ èso àìṣòdodo
“Ó jẹ́ pé nísinsin yìí bí ẹnìkan bá wà tí yóò dá wa lóhùn?
Tàbí ta ni nínú àwọn ènìyàn mímọ́ tí ìwọ ó yípadà sí?
Nítorí pé ìbínú pa aláìmòye,
ìrunú a sì pa òpè ènìyàn.
Èmi ti rí aláìmòye ti ó ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n lulẹ̀,
ṣùgbọ́n lójúkan náà mo fi ibùjókòó rẹ̀ bú.
Àwọn ọmọ rẹ̀ kò jìnnà sí ewu,
a sì tẹ̀ wọ́n mọ́lẹ̀ lójú ibodè,
bẹ́ẹ̀ ni kò sí aláàbò kan.
Ìkórè oko ẹni tí àwọn tí ebi ń pa sọ̀ di jíjẹ,
tí wọ́n sì wọ inú ẹ̀gún lọ kó,
àwọn ìgárá ọlọ́ṣà sì gbé ohun ìní wọn mì.
Bí ìpọ́njú kò bá ti inú erùpẹ̀ jáde wá ni,
tí ìyọnu kò ti ilẹ̀ jáde wá.
Ṣùgbọ́n a bí ènìyàn sínú wàhálà,
gẹ́gẹ́ bí ìpẹ́pẹ́ iná ti máa ń ta sókè.
“Ṣùgbọ́n bí ó ṣe tèmi, ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ní èmi yóò ti ṣìpẹ̀,
ní ọwọ́ Ọlọ́run ní èmi yóò máa fi ọ̀rọ̀ mi lé.
Ẹni tí ó ṣe ohun tí ó tóbi tí a kò lè ṣe àwárí,
ohun ìyanu láìní iye.
Tí ń rọ̀jò sí orí ilẹ̀ ayé
tí ó sì ń rán omi sínú ilẹ̀kílẹ̀.
Láti gbé àwọn orílẹ̀-èdè lékè
kí á lè gbé àwọn ẹni ìbànújẹ́ ga sí ibi aláìléwu.
Ó yí ìmọ̀ àwọn alárékérekè po,
bẹ́ẹ̀ ní ọwọ́ wọn kò lè mú ìdáwọ́lé wọn ṣẹ.
Ó mú àwọn ọlọ́gbọ́n nínú àrékérekè ara wọn,
àti ìmọ̀ àwọn òǹrorò ní ó tì ṣubú ní ògèdèǹgbé.
Wọ́n sáré wọ inú òkùnkùn ní ọ̀sán;
wọ́n sì fọwọ́ tálẹ̀ ní ọ̀sán gangan bí ẹni pé ní òru ni.
Ṣùgbọ́n ó gba tálákà là ní ọwọ́ idà,
lọ́wọ́ ẹnu wọn àti lọ́wọ́ àwọn alágbára.
Bẹ́ẹ̀ ni ìrètí wà fún tálákà,
àìṣòótọ́ sì pa ẹnu rẹ̀ mọ́.
“Kíyèsi i, ìbùkún ni fún ẹni tí Ọlọ́run bá wí,
nítorí náà, má ṣe gan ìbáwí Olódùmarè.
Nítorí pé òun a máa pa ni lára, síbẹ̀ òun a sì tún dì í ní ìdì ìtura,
ó sá lọ́gbẹ́, a sì fi ọwọ́ rẹ̀ di ojú ọgbẹ̀ náà jiná.
Yóò gbà ọ́ nínú ìpọ́njú mẹ́fà,
àní nínú méje, ibi kan kì yóò bá ọ.
Nínú ìyanu yóò gbà ọ́ lọ́wọ́ ikú
àti nínú ogun, yóò gbà ọ́ lọ́wọ́ idà.
A ó pa ọ́ mọ́ kúrò lọ́wọ́ iná ahọ́n,
bẹ́ẹ̀ ní ìwọ kì yóò bẹ̀rù ìparun tí ó bá dé.
Ìwọ yóò rẹ́rìn-ín nínú ìparun àti ìyàn,
bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kì yóò bẹ̀rù ẹranko ilẹ̀ ayé.
Nítorí pé ìwọ ti bá òkúta igbó mulẹ̀,
àwọn ẹranko igbó yóò wà pẹ̀lú rẹ ní àlàáfíà.
Ìwọ ó sì mọ̀ pé àlàáfíà ni ibùjókòó rẹ wà,
ìwọ yóò sì máa ṣe ìbẹ̀wò ibùjókòó rẹ, ìwọ kì yóò ṣìnà.
Ìwọ ó sì mọ̀ pẹ̀lú pé irú-ọmọ rẹ ó sì pọ̀
àti àwọn ọmọ ọmọ rẹ yóò rí bí koríko igbó.
Ìwọ yóò wọ isà òkú rẹ ní ògbólógbòó ọjọ́,
bí síírí ọkà tí ó gbó tí á sì kó ní ìgbà ìkórè rẹ̀.
“Kíyèsi i, àwa ti wádìí rẹ̀ bẹ́ẹ̀ ní ó rí!
Gbà á gbọ́, kí o sì mọ̀ pé fún ìre ara rẹ ni.”
Ìdáhùn Jobu
Jobu sì dáhùn ó si wí pé,
“Háà! À bá lè wọ́n ìbìnújẹ́ mi nínú òsùwọ̀n,
kí a sì le gbé ọ̀fọ̀ mi lé orí òsùwọ̀n ṣọ̀kan pọ̀!
Ǹjẹ́ nísinsin yìí, ìbá wúwo jú iyanrìn òkun lọ,
nítorí náà ni ọ̀rọ̀ mi ṣe ń tàsé.
Nítorí pé ọfà Olódùmarè wọ̀ mi nínú,
oró èyí tí ọkàn mi mú;
ìpayà-ẹ̀rù Ọlọ́run dúró tì mí.
Ǹjẹ́ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ igbó á máa dún nígbà tí ó bá ní koríko,
tàbí ọ̀dá màlúù a máa dún lórí ìjẹ rẹ̀?
A ha lè jẹ ohun tí kò ní adùn ní àìní iyọ̀,
tàbí adùn ha wà nínú funfun ẹyin?
Ohun ti ọ̀kan mi kọ̀ láti tọ́wò,
òun ni ó dàbí oúnjẹ tí ó mú mi ṣàárẹ̀.
“Háà! èmi ìbá lè rí ìbéèrè mi gbà;
àti pé, kí Ọlọ́run lè fi ohun tí èmi ṣàfẹ́rí fún mi.
Àní Ọlọ́run ìbá jẹ́ pa mí run,
tí òun ìbá jẹ́ ṣíwọ́ rẹ̀ kì ó sì ké mi kúrò.
Nígbà náà ní èmi ìbá ní ìtùnú síbẹ̀,
àní, èmi ìbá mú ọkàn mi le nínú ìbànújẹ́ mi ti kò dá ni sí:
nítorí èmi kò fi ọ̀rọ̀ ẹni mímọ́ ni sin rí.
“Kí ní agbára mi tí èmi ó fi retí?
Kí sì ní òpin mi tí èmi ó fi ní sùúrù?
Agbára mi ha ṣe agbára òkúta bí?
Ẹran-ara mi í ṣe idẹ?
Ìrànlọ́wọ́ mi kò ha wà nínú mi:
ọgbọ́n kò ha ti sálọ kúrò lọ́dọ̀ mi bí?
“Ẹni tí àyà rẹ̀ yọ́ dànù, ta ni a bá máa ṣàánú fún láti ọ̀dọ̀ ọ̀rẹ́ rẹ̀ wá,
kí ó má ba à kọ ìbẹ̀rù Olódùmarè sílẹ̀?
Àwọn ará mi dàbí odò tí kò ṣe gbẹ́kẹ̀lé
bí ìṣàn omi odò, wọ́n sàn kọjá lọ.
Tí ó dúdú nítorí omi dídì,
àti níbi tí yìnyín dídì gbé di yíyọ́.
Nígbàkígbà tí wọ́n bá gbóná wọn a sì yọ́ sàn lọ,
nígbà tí oòrùn bá mú, wọn a sì gbẹ kúrò ni ipò wọn.
Àwọn oníṣòwò yà kúrò ní ọ̀nà wọn,
wọ́n gòkè sí ibi asán, wọ́n sì run.
Ẹgbẹ́ oníṣòwò Tema ń wá omi,
àwọn oníṣòwò Ṣeba ń dúró dè wọ́n ní ìrètí.
Wọ́n káàárẹ̀, nítorí tí wọ́n gbẹ́kẹ̀ wọn lé e;
wọ́n dé bẹ̀, wọ́n sì dààmú.
Ǹjẹ́ nísinsin yìí, ẹ̀yin dàbí wọn;
ẹ̀yin rí ìrẹ̀sílẹ̀ mi àyà sì fò mí.
Èmi ó ha wí pé, ‘Ẹ mú ohun fún mi wá,
tàbí pé ẹ fún mi ní ẹ̀bùn nínú ohun ìní yín?
Tàbí, ẹ gbà mí lọ́wọ́ ọ̀tá ni,
tàbí, ẹ rà mí padà kúrò lọ́wọ́ alágbára nì’?
“Ẹ kọ́ mi, èmi ó sì pa ẹnu mi mọ́
kí ẹ sì mú mi wòye níbi tí mo gbé ti ṣìnà.
Wò ó! Bí ọ̀rọ̀ òtítọ́ ti lágbára tó
ṣùgbọ́n kí ni àròyé ìbáwí yín jásí?
Ẹ̀yin ṣè bí ẹ tún ọ̀rọ̀ mi ṣe
àti ohùn ẹnu tí ó dàbí afẹ́fẹ́ ṣe àárẹ̀.
Àní ẹ̀yin ṣe gẹ́gẹ́ bí aláìní baba,
ẹ̀yin sì da iye lé ọ̀rẹ́ yín.
“Nítorí náà, kí èyí kí ó tó fún yín.
Ẹ má wò mi! Nítorí pé ó hàn gbangba pé,
ní ojú yín ni èmi kì yóò ṣèké.
Èmi ń bẹ̀ yín, ẹ padà, kí ó má sì ṣe jásí ẹ̀ṣẹ̀;
àní, ẹ sì tún padà, àre mi ń bẹ nínú ọ̀rọ̀ yìí.
Àìṣedéédéé ha wà ní ahọ́n mi?
Ǹjẹ́ ìtọ́wò ẹnu mi kò kúkú le mọ ohun ti ó burú jù?
Jobu ha ni ìrètí bí?
“Ṣé ìjà kò ha si fún ènìyàn lórí ilẹ̀?
Ọjọ́ rẹ̀ pẹ̀lú kò ha dàbí ọjọ́ alágbàṣe?
Bí ọmọ ọ̀dọ̀ tí máa ń kánjú bojú wo òjìji,
àti bí alágbàṣe ti í kánjú wo ọ̀nà owó iṣẹ́ rẹ̀.
Bẹ́ẹ̀ ni a mú mi ní ìbànújẹ́ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ oṣù,
òru ìdáni-lágara ni a sì là sílẹ̀ fún mi.
Nígbà ti mo dùbúlẹ̀, èmi wí pé, ‘Nígbà wo ni èmi ó dìde?’
Tí òru yóò sì kọjá, ó sì tó fún mi láti yí síyìn-ín yí sọ́hùn-ún, títí yóò fi di àfẹ̀mọ́júmọ́.
Kòkòrò àti ògúlùtu erùpẹ̀ ni á fi wọ̀ mi ni aṣọ,
awọ ara mi bù, o sì di bíbàjẹ́.
“Ọjọ́ mi yára jù ọkọ̀ ìhunṣọ lọ,
o sì di lílò ní àìní ìrètí.
Háà! Rántí pé afẹ́fẹ́ ni ẹ̀mí mi;
ojú mi kì yóò padà rí rere mọ́.
Ojú ẹni tí ó rí mi, kì yóò rí mi mọ́;
ojú rẹ̀ tẹ̀ mọ́ra mi, èmi kò sí mọ́.
Bí ìkùùkuu tí i túká, tí í sì fò lọ,
bẹ́ẹ̀ ni ẹni tí ń lọ sí ipò òkú tí kì yóò padà wa mọ́.
Kì yóò padà sínú ilé rẹ̀ mọ́,
bẹ́ẹ̀ ní ipò rẹ̀ kì yóò mọ̀ ọn mọ́.
“Nítorí náà èmi kì yóò pa ẹnu mi mọ́,
èmi yóò máa sọ nínú ìrora ọkàn mi,
èmi yóò máa ṣe ìráhùn nínú kíkorò ọkàn mi.
Èmi a máa ṣe Òkun tàbí ẹ̀mí búburú,
tí ìwọ fi ń yan olùṣọ́ tì mi?
Nígbà tí mo wí pé, ibùsùn mi yóò tù mí lára,
ìtẹ́ mi yóò mú ara mi fúyẹ́ pẹ̀lú.
Nígbà náà ni ìwọ fi àlá da yọ mi lénu bò mi,
ìwọ sì fi ìran òru dẹ́rùbà mí.
Bẹ́ẹ̀ ni ọkàn mí yàn láti fún pa
àti ikú ju kí ń wà láààyè ní ipò tí ara mí wà yìí lọ.
O sú mi, èmi kò le wà títí:
jọ̀wọ́ mi jẹ́, nítorí pé asán ni ọjọ́ mi.
“Kí ni ènìyàn tí ìwọ o máa kókìkí rẹ̀?
Àti tí ìwọ ìbá fi gbé ọkàn rẹ lé e?
Àti ti ìwọ ó fi máa wá í bẹ̀ ẹ́ wò ni òròòwúrọ̀,
ti ìwọ o sì máa dán an wò nígbàkígbà!
Yóò ti pẹ́ tó kí ìwọ kí ó tó fi mí sílẹ̀ lọ,
tí ìwọ o fi mí sílẹ̀ jẹ́ẹ́ títí èmi yóò fi lè dá itọ́ mi mì.
Èmi ti ṣẹ̀, ki ní èmi ó ṣe sí ọ.
Ìwọ Olùsójú ènìyàn?
Èéṣe tí ìwọ fi fi mí ṣe àmì itasi níwájú rẹ,
bẹ́ẹ̀ ni èmi sì di ẹrẹ̀ wíwo fún ọ?
Èéṣe tí ìwọ kò sì dárí ìrékọjá mi jìn,
kí ìwọ kí ó sì mú àìṣedéédéé mi kúrò?
Ǹjẹ́ nísinsin yìí ni èmi ìbá sùn nínú erùpẹ̀,
ìwọ ìbá sì wá mi kiri ní òwúrọ̀, èmi kì bá tí sí.”
Bilidadi
Ìgbà náà ni Bilidadi, ará Ṣuhi, sì dáhùn wí pé,
“Ìwọ yóò ti máa sọ nǹkan wọ̀nyí pẹ́ tó?
Tí ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ yóò sì máa bí ẹ̀fúùfù ńlá?
Ọlọ́run a ha máa yí ìdájọ́ po bí?
Tàbí Olódùmarè a máa gbé ẹ̀bi fún aláre?
Nígbà tí àwọn ọmọ rẹ̀ ṣẹ̀ sí i,
ó sì gbá wọn kúrò nítorí ìrékọjá wọn.
Bí ìwọ bá sì ké pe Ọlọ́run ní àkókò,
tí ìwọ sì gbàdúrà ẹ̀bẹ̀ sí Olódùmarè.
Ìwọ ìbá jẹ́ mímọ, kí ó sì dúró ṣinṣin:
ǹjẹ́ nítòótọ́ nísinsin yìí òun yóò tají fún ọ,
òun a sì sọ ibùjókòó òdodo rẹ di púpọ̀.
Ìpilẹ̀ṣẹ̀ rẹ ìbá tilẹ̀ kéré si í,
bẹ́ẹ̀ ìgbẹ̀yìn rẹ ìbá pọ̀ sí i gidigidi.
“Èmi bẹ̀ ọ́ ǹjẹ́, béèrè lọ́wọ́ àwọn ará ìgbà nì
kí o sì kíyèsi ìwádìí àwọn baba wọn.
Nítorí pé ọmọ-àná ni àwa, a kò sì mọ nǹkan,
nítorí pé òjìji ni ọjọ́ wa ni ayé.
Àwọn kì yóò wa kọ ọ́, wọn kì yóò sì sọ fún ọ?
Wọn kì yóò sì sọ̀rọ̀ láti inú òye wọn jáde wá?
Papirusi ha lè dàgbà láìní ẹrẹ̀
tàbí eèsún ha lè dàgbà láìlómi?
Nígbà tí ó wà ní tútù, tí a kò ké e lulẹ̀,
ó rọ dànù, ewéko gbogbo mìíràn hù dípò rẹ̀.
Bẹ́ẹ̀ ni ipa ọ̀nà gbogbo àwọn tí ó gbàgbé Ọlọ́run,
bẹ́ẹ̀ ni ìrètí àwọn àgàbàgebè yóò di òfo.
Àbá ẹni tí a ó kèé kúrò,
àti ìgbẹ́kẹ̀lé ẹni tí ó dàbí ilé aláǹtakùn.
Yóò fi ara ti ilé rẹ̀, ṣùgbọ́n kì yóò lè dúró,
yóò fi di ara rẹ̀ mú ṣinṣin ṣùgbọ́n kì yóò lè dúró pẹ́.
Ó tutù bí irúgbìn tí a bomirin níwájú oòrùn,
ẹ̀ka rẹ̀ sì yọ jáde nínú ọgbà rẹ̀.
Gbòǹgbò rẹ̀ ta yí ebè ká,
ó sì wó ibi òkúta wọ̀n-ọn-nì.
Bí ó bá sì pa á run kúrò ní ipò rẹ̀,
nígbà náà ni ipò náà yóò sọ, ‘Èmi kò ri ọ rí!’
Kíyèsi i, ayé rẹ̀ gbẹ dànù
àti láti inú ilẹ̀ ní irúgbìn òmíràn yóò hù jáde wá.
“Kíyèsi i, Ọlọ́run kì yóò ta ẹni òtítọ́ nù,
bẹ́ẹ̀ ni kì yóò ran oníwà búburú lọ́wọ́
títí yóò fi fi ẹ̀rín kún ọ ní ẹnu,
àti ètè rẹ pẹ̀lú ìhó ayọ̀,
ìtìjú ní a o fi bo àwọn tí ó kórìíra rẹ̀,
àti ibùjókòó ènìyàn búburú kì yóò sí mọ́.”
Jobu Fún Bilidadi lésì Nípa Ẹ̀kọ́ àti Ẹ̀rí Ìdájọ́ Ọlọ́run
Jobu sì dáhùn ó sì wí pé,
“Èmi mọ̀ pe bẹ́ẹ̀ ni ní òtítọ́.
Báwo ní ènìyàn yóò ha ti ṣe jẹ́ aláre níwájú Ọlọ́run?
Bí ó bá ṣe pé yóò bá a jà,
òun kì yóò lè dalóhùn kan nínú ẹgbẹ̀rún (1,000) ọ̀rọ̀.
Ọlọ́gbọ́n nínú àwọn alágbára ní ipa ní Òun.
Ta ni ó ṣe agídí sí i tí ó sì gbé fún rí?
Ẹni tí ó sí òkè nídìí tí wọn kò sì mọ́:
tí ó taari wọn ṣubú ní ìbínú rẹ̀.
Tí ó mi ilẹ̀ ayé tìtì kúrò ní ipò rẹ̀,
ọwọ̀n rẹ̀ sì mì tìtì.
Ó pàṣẹ fún oòrùn kò sì le è ràn,
kí ó sì dí ìmọ́lẹ̀ ìràwọ̀ mọ́.
Òun nìkan ṣoṣo ni ó ta ojú ọ̀run,
ti ó sì ń rìn lórí ìgbì Òkun.
Ẹni tí ó dá ìràwọ̀ Beari àti Orioni,
Pleiadesi àti ìràwọ̀ púpọ̀ ti gúúsù.
Ẹni tí ń ṣe ohun tí ó tóbi jù àwárí lọ,
àní ohun ìyanu láìní iye.
Kíyèsi i, ó ń kọjá lọ ní ẹ̀bá ọ̀dọ̀ mi, èmi kò sì rí i,
ó sì kọjá síwájú, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò rí ojú rẹ̀.
Kíyèsi i, ó já a gbà lọ, ta ni ó lè fà á padà?
Ta ni yóò bi í pé kí ni ìwọ ń ṣe nì?
Ọlọ́run kò ní fa ìbínú rẹ̀ sẹ́yìn,
àwọn onírànlọ́wọ́ ti Rahabu a sì tẹríba lábẹ́ rẹ̀.
“Kí ní ṣe tí èmi ti n o fi ba ṣàròyé?
Tí èmi yóò fi ma ṣe àwáwí?
Bí ó tilẹ̀ ṣe pé mo ṣe aláìlẹ́bi, èmi kò gbọdọ̀ dá a lóhùn;
ṣùgbọ́n èmi ó gbàdúrà fún àánú.
Bí èmi bá sì ké pè é, tí Òun sì dá mi lóhùn,
èmi kì yóò sì gbàgbọ́ pé, Òun ti fetí sí ohùn mi.
Nítorí pé òun yóò lọ̀ mí lúúlúú pẹ̀lú ìjì ńlá,
ó sọ ọgbẹ́ mi di púpọ̀ láìnídìí.
Òun kì yóò jẹ́ kí èmi kí ó rí ẹ̀mí mi,
ṣùgbọ́n ó mú ohun kíkorò kún un fún mi.
Bí mo bá sọ ti agbára, wò ó!
Alágbára ni, tàbí ní ti ìdájọ́, ta ni yóò dá àkókò fún mi láti rò?
Bí mo tilẹ̀ dá ara mi láre, ẹnu ara mi yóò dá mi lẹ́bi;
bí mo wí pé olódodo ni èmi yóò sì fi mí hàn ní ẹni ẹ̀bi.
“Olóòótọ́ ni mo ṣe,
síbẹ̀ èmi kò kíyèsi ara mi,
ayé mi ní èmi ìbá máa gàn.
Ohùn kan náà ni, nítorí náà ni èmi ṣe sọ:
‘Òun a pa ẹni òtítọ́ àti ènìyàn búburú pẹ̀lú.’
Bí ìjàǹbá bá pa ni lójijì,
yóò rẹ́rìn-ín nínú ìdààmú aláìṣẹ̀.
Nígbà tí a bá fi ayé lé ọwọ́ ènìyàn búburú;
ó sì bo àwọn onídàájọ́ rẹ̀ lójú;
bí kò bá rí bẹ́ẹ̀ ǹjẹ́ ta ni?
“Ǹjẹ́ nísinsin yìí ọjọ́ mi yára ju oníṣẹ́ lọ,
wọ́n fò lọ, wọn kò rí ayọ̀.
Wọ́n kọjá lọ bí ọkọ̀ eèsún papirusi tí ń sáré lọ;
bí idì tí ń yára si ohùn ọdẹ.
Bí èmi bá wí pé, ‘Èmi ó gbàgbé arò ìbìnújẹ́ mi,
èmi ó fi ọkàn lélẹ̀, èmi ó sì rẹ ara mi lẹ́kún.’
Ẹ̀rù ìbànújẹ́ mi gbogbo bà mí,
èmi mọ̀ pé ìwọ kì yóò mú mi bí aláìṣẹ̀.
Bí ó bá ṣe pé ènìyàn búburú ni èmi,
ǹjẹ́ kí ni èmi ń ṣe làálàá lásán sí?
Bí mo tilẹ̀ fi ọṣẹ dídì wẹ ara mi,
tí mo fi omi aró wẹ ọwọ́ mi mọ́,
síbẹ̀ ìwọ ó gbé mi wọ inú ihò
ọ̀gọ̀dọ̀ aṣọ ara mi yóò sọ mi di ìríra.
“Nítorí Òun kì í ṣe ènìyàn bí èmi,
tí èmi ó fi dá a lóhùn tí àwa o fi pàdé ní ìdájọ́.
Bẹ́ẹ̀ ni kò sí alátúnṣe kan ní agbede-méjì wa
tí ìbá fi ọwọ́ rẹ̀ lé àwa méjèèjì lára.
Kí ẹnìkan sá à mú ọ̀pá Ọlọ́run kúrò lára mi,
kí ìbẹ̀rù rẹ̀ kí ó má sì ṣe dáyà fò mí.
Nígbà náà ni èmi ìbá sọ̀rọ̀, èmi kì bá sì bẹ̀rù rẹ̀;
ṣùgbọ́n bí ó tí dúró tì mí, kò ri bẹ́ẹ̀ fún mi.
Àròyé Jobu Tẹ̀síwájú
“Agara ìwà ayé mi dá mi tán;
èmi yóò tú àròyé mi sókè lọ́dọ̀ mi
èmi yóò máa sọ̀rọ̀ nínú kíkorò ìbìnújẹ́ ọkàn mi.
Èmi yóò wí fún Ọlọ́run pé, má ṣe dá mi lẹ́bi;
fihàn mí nítorí ìdí ohun tí ìwọ fi ń bá mi jà.
Ó ha tọ́ tí ìwọ ìbá fi máa ni mí lára,
tí ìwọ ìbá fi máa gan iṣẹ́ ọwọ́ rẹ,
tí ìwọ yóò fi máa tàn ìmọ́lẹ̀ sí ìmọ̀ ènìyàn búburú?
Ojú rẹ kì ha ṣe ojú ènìyàn bí?
Tàbí ìwọ a máa ríran bí ènìyàn ti í ríran?
Ọjọ́ rẹ ha dàbí ọjọ́ ènìyàn,
ọdún rẹ ha dàbí ọjọ́ ènìyàn,
tí ìwọ fi ń béèrè àìṣedéédéé mi,
tí ìwọ sì fi wá ẹ̀ṣẹ̀ mi rí?
Ìwọ mọ̀ pé èmi kì í ṣe oníwà búburú,
kò sì sí ẹni tí ó le gbà mí kúrò ní ọwọ́ rẹ?
“Ọwọ́ rẹ ni ó mọ mi, tí ó sì da mi.
Síbẹ̀ ìwọ tún yípadà láti jẹ mí run.
Èmi bẹ̀ ọ́ rántí pé ìwọ ti mọ mí bí amọ̀.
Ìwọ yóò ha sì tún mú mi padà lọ sínú erùpẹ̀?
Ìwọ kò ha ti tú mí dà jáde bí i wàrà,
ìwọ kò sì mú mí dìpọ̀ bí i wàràǹkàṣì?
Ìwọ sá ti fi àwọ̀ ẹran-ara wọ̀ mí,
ìwọ sì fi egungun àti iṣan ṣọgbà yí mi ká.
Ìwọ ti fún mi ní ẹ̀mí àti ojúrere,
ìbẹ̀wò rẹ sì pa ọkàn mi mọ́.
“Nǹkan wọ̀nyí ni ìwọ sì ti fi pamọ́ nínú rẹ;
èmi mọ̀ pé, èyí ń bẹ ní ọkàn rẹ.
Bí mo bá ṣẹ̀, nígbà náà ni ìwọ yóò máa ṣọ́ mi
ìwọ kì yóò sì dárí àìṣedéédéé mi jì.
Bí mo bá ṣe ẹni búburú, ègbé ni fún mi!
Bí mo bá sì ṣe ẹni rere, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò sì le gbe orí mi sókè,
èmi dààmú
mo si wo ìpọ́njú mi.
Bí mo bá gbé orí mi ga, ìwọ ń dẹ mí kiri bi i kìnnìún
àti pẹ̀lú, ìwọ a sì fi ara rẹ hàn fún mi ní ìyànjú.
Ìwọ sì tún mu àwọn ẹlẹ́rìí rẹ dìde sí mi di ọ̀tún
ìwọ sì sọ ìrunú rẹ di púpọ̀ sí mi;
àwọn ogun rẹ si dìde sinmi bi igbe omi Òkun.
“Nítorí kí ni ìwọ ṣe mú mi jáde láti inú wá?
Háà! Èmi ìbá kúkú ti kú, ojúkójú kì bá tí rí mi.
Tí kò bá le jẹ́ pé èmi wà láààyè,
à bá ti gbé mi láti inú lọ isà òkú.
Ọjọ́ mi kò ha kúrú bí? Rárá!
Dáwọ́ dúró, kí ó sì yí padà kúrò lọ́dọ̀ mi.
Nítorí kí èmi lè ni ayọ̀ ní ìṣẹ́jú kan.
Kí èmi kí ó tó lọ sí ibi tí èmi kì yóò padà sẹ́yìn mọ́,
àní si ilẹ̀ òkùnkùn àti òjìji ikú,
ilẹ̀ òkùnkùn bí òkùnkùn tìkára rẹ̀,
àti ti òjìji ikú àti rúdurùdu,
níbi tí ìmọ́lẹ̀ dàbí òkùnkùn.”
Sofari fi ẹ̀sùn irọ́ pípa àti àìṣòótọ́ kan Jobu
Ìgbà náà ni Sofari, ará Naama, dáhùn, ó sì wí pé,
“A ha lè ṣe kí a máa dáhùn sí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀rọ̀?
A ha lè fi gbogbo ọ̀rọ̀ wọ̀nyí da ènìyàn láre?
Ṣé àmọ̀tán rẹ le mú ènìyàn pa ẹnu wọn mọ́ bí?
Ṣé ẹnikẹ́ni kò ní bá ọ wí bí ìwọ bá yọ ṣùtì sí ni?
Ìwọ sá à ti wí fún Ọlọ́run pé, ‘Ìṣe mi jẹ́ aláìléérí,
èmi sì mọ́ ní ojú rẹ.’
Ṣùgbọ́n Ọlọ́run ìbá jẹ́ sọ̀rọ̀,
kí ó sì ya ẹnu rẹ̀ sí ọ
kí ó sì fi àṣírí ọgbọ́n hàn ọ́ pé, ó pọ̀ ju òye ènìyàn lọ,
nítorí náà, mọ̀ pé Ọlọ́run ti
gbàgbé àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ kan.
“Ìwọ ha le ṣe àwárí ohun ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run bí?
Ìwọ ha le ṣe àwárí ibi tí Olódùmarè dé bi?
Ó ga ju àwọn ọ̀run lọ; kí ni ìwọ le è ṣe?
Ó jìn ju jíjìn isà òkú lọ; kí ni ìwọ le mọ̀?
Ìwọ̀n rẹ̀ gùn ju ayé lọ,
ó sì ní ibú ju òkun lọ.
“Bí òun bá rékọjá, tí ó sì sé ọnà
tàbí tí ó sì mú ni wá sí ìdájọ́, ǹjẹ́, ta ni ó lè dí i lọ́wọ́?
Òun sá à mọ ẹlẹ́tàn ènìyàn;
àti pé ṣé bí òun bá rí ohun búburú, ṣé òun kì i fi iyè sí i?
Ṣùgbọ́n òmùgọ̀ ènìyàn ki yóò di ọlọ́gbọ́n
bi ko ti rọrùn fún ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ igbó láti bí ènìyàn.
“Bí ìwọ bá fi ọkàn rẹ fún un,
tí ìwọ sì na ọwọ́ rẹ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀,
bí ìwọ bá gbé ẹ̀ṣẹ̀ tí ń bẹ ní ọwọ́ rẹ jù sọnù
tí ìwọ kò sì jẹ́ kí aburú gbé nínú àgọ́ rẹ,
nígbà náà ni ìwọ ó gbé ojú rẹ sókè láìní àbàwọ́n,
àní ìwọ yóò dúró ṣinṣin, ìwọ kì yóò sì bẹ̀rù.
Nítorí pé ìwọ ó gbàgbé ìṣòro rẹ;
ìwọ ó sì rántí rẹ̀ bí omi tí ó ti sàn kọjá lọ.
Ọjọ́ ayé rẹ yóò sì mọ́lẹ̀ ju ọ̀sán gangan lọ,
bí òkùnkùn tilẹ̀ bò ọ́ mọ́lẹ̀ nísinsin yìí, ìwọ ó dàbí òwúrọ̀.
Ìwọ ó sì wà láìléwu, nítorí pé ìrètí wà;
àní ìwọ ó rin ilé rẹ wò, ìwọ ó sì sinmi ní àlàáfíà.
Ìwọ ó sì dùbúlẹ̀ pẹ̀lú, kì yóò sì sí ẹni tí yóò dẹ́rùbà ọ́,
àní ènìyàn yóò máa wá ojúrere rẹ.
Ṣùgbọ́n ojú ìkà ènìyàn yóò mófo;
gbogbo ọ̀nà àbáyọ ni yóò nù wọ́n,
ìrètí wọn a sì dàbí ẹni tí ó jọ̀wọ́ ẹ̀mí rẹ̀ lọ́wọ́.”
Ìdáhùn Jobu
Jobu sì dáhùn, ó sì wí pé,
“Kò sí àní àní níbẹ̀, ṣùgbọ́n ẹ̀yin ni àwọn ènìyàn náà,
ọgbọ́n yóò sì kú pẹ̀lú yín!
Ṣùgbọ́n èmi ní ìyè nínú gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin;
èmi kò kéré sí i yín.
Àní, ta ni kò mọ gbogbo nǹkan wọ̀nyí?
“Èmi dàbí ẹni tí a ń fi ṣe ẹlẹ́yà lọ́dọ̀ aládùúgbò rẹ̀,
tí ó ké pe Ọlọ́run, tí ó sì dá a lóhùn,
à ń fi olóòtítọ́ ẹni ìdúró ṣinṣin rẹ́rìn-ín ẹlẹ́yà!
Ó rọrùn fún ènìyàn láti fi ìbànújẹ́ ẹlòmíràn ṣe ẹlẹ́yà
gẹ́gẹ́ bí ìpín àwọn ẹni tí ẹsẹ̀ wọn ṣetán láti yọ̀.
Àgọ́ àwọn ìgárá ọlọ́ṣà wá láìní ìbẹ̀rù;
àwọn tí ó sì ń mú Ọlọ́run bínú wà láìléwu,
àwọn ẹni tí ó sì gbá òrìṣà mú ní ọwọ́ wọn.
“Ṣùgbọ́n nísinsin yìí bí àwọn ẹranko léèrè, wọn o kọ́ ọ ní ẹ̀kọ́,
àti ẹyẹ ojú ọ̀run, wọn ó sì sọ fún ọ.
Tàbí ba ilẹ̀ ayé sọ̀rọ̀, yóò sì kọ́ ọ,
àwọn ẹja inú òkun yóò sì sọ fún ọ.
Ta ni kò mọ̀ nínú gbogbo nǹkan wọ̀nyí pé,
ọwọ́ Olúwa ni ó ṣe nǹkan yìí?
Ní ọwọ́ ẹni tí ẹ̀mí ohun alààyè gbogbo gbé wà,
àti ẹ̀mí gbogbo aráyé.
Etí kì í dán ọ̀rọ̀ wò bí
tàbí adùn ẹnu kì í sì í tọ́ oúnjẹ rẹ̀ wò bí?
Àwọn arúgbó ni ọgbọ́n wà fún,
àti nínú gígùn ọjọ́ ni òye.
“Ti Ọlọ́run ni ọgbọ́n àti agbára;
òun ló ni ìmọ̀ àti òye.
Kíyèsi i, ó bì wó, a kò sì lè gbe ró mọ́;
Ó sé ènìyàn mọ́, kò sì sí ìtúsílẹ̀ kan.
Kíyèsi i, ó dá àwọn omi dúró, wọ́n sì gbẹ;
Ó sì rán wọn jáde, wọ́n sì ṣẹ̀ bo ilẹ̀ ayé yípo.
Tìrẹ ni agbára àti ìṣẹ́gun;
ẹni tí ń ṣìnà àti ẹni tí ń mú ni ṣìnà, tirẹ̀ ni wọ́n ń ṣe.
Ó mú àwọn ìgbìmọ̀ lọ ní ìhòhò
a sì sọ àwọn onídàájọ́ di òmùgọ̀.
Ó tú ìdè ọba
ó sì fi àmùrè gbà wọ́n ní ọ̀já.
Ó mú àwọn àlùfáà lọ ní ìhòhò
ó sì tẹ orí àwọn alágbára ba.
Ó mú ọ̀rọ̀ ẹnu ẹni ìgbẹ́kẹ̀lé kúrò
ó sì ra àwọn àgbàgbà ní iyè.
Ó bu ẹ̀gàn lu àwọn ọmọ ọlọ́lá
ó sì tú àmùrè àwọn alágbára.
Ó hú ìdí ohun ìjìnlẹ̀ jáde láti inú òkùnkùn wá
ó sì mú òjìji ikú wá sínú ìmọ́lẹ̀.
Òun a mú orílẹ̀-èdè bí sí i, a sì run wọ́n;
òun a sọ orílẹ̀-èdè di ńlá, a sì tún ṣẹ̀ wọn kù.
Òun a gba òye àwọn olórí àwọn ènìyàn aráyé,
a sì máa mú wọn rin kiri nínú ijù níbi tí ọ̀nà kò sí.
Wọn a máa fi ọwọ́ ta ilẹ̀ nínú òkùnkùn níbi tí kò sí ìmọ́lẹ̀;
òun a sì máa mú ìrìn ìsìn wọn bí ọ̀mùtí.
Jobu gbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run
“Wò ó, ojú mi ti rí gbogbo èyí rí,
etí mí sì gbọ́, ó sì ti yé mi.
Ohun tí ẹ̀yin mọ̀, èmi mọ̀ pẹ̀lú,
èmi kò kéré sí i yin.
Nítòótọ́ èmi ó bá Olódùmarè sọ̀rọ̀,
èmi sì ń fẹ́ bá Ọlọ́run sọ àsọyé.
Ẹ̀yin fi irọ́ bá mi sọ̀rọ̀,
oníṣègùn lásán ni gbogbo yín.
Háà! ẹ̀yin kì bá kúkú dákẹ́!
Èyí ni kì bá sì ṣe ọgbọ́n yín.
Ẹ gbọ́ àwíyé mi nísinsin yìí;
ẹ sì fetísílẹ̀ sí àròyé ẹnu mi.
Ẹ̀yin fẹ́ sọ ìsọkúsọ fún Ọlọ́run?
Ki ẹ sì fi ẹ̀tàn sọ̀rọ̀ gbè é?
Ẹ̀yin fẹ́ ṣe ojúsàájú rẹ̀?
Ẹ̀yin fẹ́ gbèjà fún Ọlọ́run?
Ó ha dára to tí yóò hú àṣírí yín síta,
tàbí kí ẹ̀yin tàn án bí ẹnìkan ti í tan ẹnìkejì?
Yóò máa bá yín wí nítòótọ́,
bí ẹ̀yin bá ṣe ojúsàájú ènìyàn níkọ̀kọ̀.
Ìwà ọlá rẹ̀ kì yóò bà yín lẹ́rù bí?
Ìpayà rẹ̀ kì yóò pá yín láyà?
Àwọn òwe yín dàbí eérú,
bẹ́ẹ̀ ni àwọn odi ìlú yin dàbí amọ̀.
“Ẹ pa ẹnu yín mọ́ kúrò lára mi, kí èmi kí ó lè sọ̀rọ̀,
ki ohun tí ń bọ̀ wá í bá mi, le è máa bọ̀.
Ǹjẹ́ nítorí kí ni èmi ṣe ń fi eyín mi bu ẹran-ara mi jẹ,
tí mo sì gbé ẹ̀mí mi lé ara mi lọ́wọ́?
Bí ó tilẹ̀ pa mí, síbẹ̀ èmi ó máa gbẹ́kẹ̀lé e,
èmi ó máa tẹnumọ́ ọ̀nà mi níwájú rẹ̀.
Èyí ni yóò sì ṣe ìgbàlà mi,
àgàbàgebè kì yóò wá síwájú rẹ̀.
Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ ẹnu mi ní ìfarabalẹ̀,
jẹ́ kí ọ̀rọ̀ mí dún ni etí yín.
Wò ó nísinsin yìí, èmi ti mura ọ̀ràn mi sílẹ̀;
èmi mọ̀ pé a ó dá mi láre.
Ta ni òun ti yóò bá mi ṣàròyé?
Ǹjẹ́ nísinsin yìí, èmi fẹ́ pa ẹnu mi mọ́,
èmi ó sì jọ̀wọ́ ẹ̀mí mi lọ́wọ́.
“Ṣùgbọ́n, má ṣe ṣe ohun méjì yìí sí mi,
nígbà náà ni èmi kì yóò sì fi ara mi pamọ́ kúrò fún ọ.
Fa ọwọ́ rẹ sẹ́yìn kúrò lára mi,
má sì jẹ́ kí ẹ̀rù rẹ kí ó pá mi láyà.
Nígbà náà ni kí ìwọ kí ó pè, èmi o sì dáhùn,
tàbí jẹ́ kí ń máa sọ̀rọ̀, ki ìwọ kí ó sì dá mi lóhùn.
Mélòó ní àìṣedéédéé àti ẹ̀ṣẹ̀ mi?
Mú mi mọ̀ ìrékọjá àti ẹ̀ṣẹ̀ mi.
Nítorí kí ni ìwọ ṣe pa ojú rẹ mọ́,
tí o sì yàn mí ní ọ̀tá rẹ?
Ìwọ ó fa ewé ti afẹ́fẹ́ ń fẹ́ síyìn-ín sọ́hùn-ún ya bi?
Ìwọ a sì máa lépa ìyàngbò?
Nítorí pé ìwọ kọ̀wé ohun kíkorò sí mi,
o sì mú mi jogún àìṣedéédéé èwe mi.
Ìwọ kàn àbà mọ́ mi lẹ́sẹ̀ pẹ̀lú,
ìwọ sì ń wò ipa ọ̀nà ìrìn mi ní àwòfín;
nípa fífi ìlà yí gígísẹ̀ mi ká.
“Bẹ́ẹ̀ ni ènìyàn ń ṣègbé bí ohun ìdíbàjẹ́,
bi aṣọ tí kòkòrò jẹ.
Jobu tẹ̀síwájú nínú àròyé rẹ̀
“Ènìyàn tí a bí nínú obìnrin,
ọlọ́jọ́ díẹ̀ ni, ó sì kún fún ìpọ́njú.
Ó jáde wá bí ìtànná ewéko, a sì ké e lulẹ̀;
ó sì ń fò lọ bí òjìji, kò sì dúró pẹ́.
Ìwọ sì ń síjú rẹ wò irú èyí ni?
Ìwọ sì mú mi wá sínú ìdájọ́ pẹ̀lú rẹ?
Ta ni ó lè mú ohun mímọ́ láti inú àìmọ́ jáde wá?
Kò sí ẹnìkan!
Ǹjẹ́ a ti pinnu ọjọ́ rẹ̀,
iye oṣù rẹ̀ ń bẹ ní ọwọ́ rẹ,
ìwọ ti pààlà rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ní òun kò le kọjá rẹ̀.
Yípadà kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀, kí ó lè sinmi,
títí yóò fi pé ọjọ́ rẹ̀ bí alágbàṣe.
“Nítorí pé ìrètí wà fún igi, bí a bá
ké e lulẹ̀, pé yóò sì tún sọ,
àti pé ẹ̀ka rẹ̀ tuntun kì yóò gbẹ.
Bí gbòǹgbò rẹ̀ tilẹ̀ di ogbó nínú ilẹ̀,
tí kùkùté rẹ̀ si kú ni ilẹ̀,
síbẹ̀ nígbà tí ó bá gbóòórùn omi,
yóò sọ, yóò sì yọ ẹ̀ka jáde bí irúgbìn.
Ṣùgbọ́n ènìyàn kú, a sì dàánù,
àní ènìyàn jọ̀wọ́ ẹ̀mí rẹ̀ lọ́wọ́: Òun kò sì sí mọ́.
Àgékúrú ọjọ́ ọmọ ènìyàn
“Bí omi ti í tán nínú ipa odò,
àti bí odò ṣì tí í fà tí sì gbẹ,
bẹ́ẹ̀ ni ènìyàn dùbúlẹ̀ tí kò sì dìde mọ́;
títí ọ̀run kì yóò fi sí mọ́,
wọ́n kì yóò jí, a kì yóò jí wọn kúrò lójú oorun wọn.
“Háà! ìwọ ìbá fi mí pamọ́ ní ipò òkú,
kí ìwọ kí ó fi mí pamọ́ ní ìkọ̀kọ̀,
títí ìbínú rẹ yóò fi rékọjá,
ìwọ ìbá lànà ìgbà kan sílẹ̀ fún mi, kí ó si rántí mi!
Bí ènìyàn bá kú yóò sì tún yè bí?
Gbogbo ọjọ́ ìgbà tí a là sílẹ̀
fún mi ni èmi dúró dè, títí àmúdọ̀tún mi yóò fi dé.
Ìwọ ìbá pè, èmi ìbá sì dá ọ lóhùn;
ìwọ ó sì ní ìfẹ́ sì iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.
Ṣùgbọ́n nísinsin yìí ìwọ ń kaye ìṣísẹ̀ mi;
ìwọ kò fa ọwọ́ rẹ kúrò nítorí ẹ̀ṣẹ̀ mi?
A fi èdìdì di ìrékọjá mi sínú àpò,
ìwọ sì rán àìṣedéédéé mi pọ̀.
“Àti nítòótọ́ òkè ńlá tí ó ṣubú, ó dasán,
a sì ṣí àpáta kúrò ní ipò rẹ̀.
Omi a máa yinrin òkúta, ìwọ a sì
mú omi sàn bo ohun tí ó hù jáde lórí ilẹ̀,
ìwọ sì sọ ìrètí ènìyàn dí òfo.
Ìwọ ṣẹ́gun rẹ̀ láéláé, òun sì kọjá lọ!
Ìwọ pa awọ ojú rẹ̀ dà, o sì rán an lọ kúrò.
Àwọn ọmọ rẹ̀ bọ́ sí ipò ọlá, òun kò sì mọ̀;
wọ́n sì rẹ̀ sílẹ̀, òun kò sì kíyèsi i lára wọn.
Ṣùgbọ́n ẹran-ara rẹ̀ ni yóò rí ìrora
ọkàn rẹ̀ ni yóò sì máa ní ìbìnújẹ́ nínú rẹ̀.”
Elifasi tako ọrọ̀ Jobu
Ìgbà náà ní Elifasi, ará Temani, dáhùn wí pé,
“Ọlọ́gbọ́n a máa sọ̀rọ̀ ìmọ̀ asán
kí ó sì máa fi afẹ́fẹ́ ìlà-oòrùn kún ara rẹ̀ nínú?
Òun lè máa fi àròyé sọ̀rọ̀ tí kò ní èrè,
tàbí pẹ̀lú ọ̀rọ̀ nínú èyí tí kò lè fi ṣe rere?
Ṣùgbọ́n ìwọ ṣá ìbẹ̀rù tì,
ìwọ sì dí iṣẹ́ ìsìn lọ́nà níwájú Ọlọ́run.
Nítorí pé ẹnu ara rẹ̀ ni ó jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀,
ìwọ sì yàn ahọ́n alárékérekè ni ààyò.
Ẹnu ara rẹ̀ ni ó dá lẹ́bi, kì í ṣe èmi;
àní ètè ara rẹ̀ ni ó jẹ́rìí gbè ọ́.
“Ìwọ ha í ṣe ọkùnrin tí a kọ́ bí?
Tàbí a ha dá ọ ṣáájú àwọn òkè?
Ìwọ gbúròó àṣírí Ọlọ́run rí?
Tàbí ìwọ ha dá ọgbọ́n dúró sọ́dọ̀ ara rẹ?
Kí ni ìwọ mọ̀ tí àwa kò mọ̀?
Òye kí ní ó yé ọ tí kò sí nínú wa?
Àwọn arúgbó àti ògbólógbòó ènìyàn wà pẹ̀lú wa,
tí wọ́n dàgbà ju baba rẹ lọ.
Ìtùnú Ọlọ́run ha kéré lọ́dọ̀ rẹ?
Ọ̀rọ̀ kan sì ṣe jẹ́jẹ́ jù lọ́dọ̀ rẹ?
Èéṣe ti ọkàn rẹ fi ń ti ọ kiri,
kí ni ìwọ tẹjúmọ́ tóbẹ́ẹ̀.
Tí ìwọ fi yí ẹ̀mí rẹ padà lòdì sí Ọlọ́run,
tí ó fi ń jẹ́ ki ọ̀rọ̀kọ́rọ̀ kí ó máa bọ́ ní ẹnu rẹ̀ bẹ́ẹ̀?
“Kí ni ènìyàn tí ó fi jẹ mímọ́,
àti ẹni tí a tinú obìnrin bí tí yóò fi ṣe olódodo?
Kíyèsi i, bi Ọlọ́run ko ba gbẹ́kẹ̀lé àwọn ẹni mímọ́ rẹ̀,
àní àwọn ọ̀run kò mọ́ ní ojú rẹ̀,
mélòó mélòó ni ènìyàn, ẹni ìríra àti eléèérí,
tí ń mu ẹ̀ṣẹ̀ bi ẹní mu omi.
“Èmi ó fihàn ọ́, gbọ́ ti èmi;
èyí tí èmi sì rí, òun ni èmi ó sì sọ,
ohun tí àwọn ọlọ́gbọ́n ti pa ní ìtàn láti
ọ̀dọ̀ àwọn baba wọn wá, ti wọ́n kò sì fi pamọ́.
Àwọn tí a fi ilẹ̀ ayé fún nìkan,
ti àlejò kan kò sì là wọ́n kọjá.
Ènìyàn búburú ń ṣe làálàá,
pẹ̀lú ìrora, ní ọjọ́ rẹ̀ gbogbo,
àti iye ọdún ní a dá sílẹ̀ fún aninilára.
Ìró ìbẹ̀rù ń bẹ ní etí rẹ̀;
nínú ìrora ni apanirun yóò dìde sí i.
Kò gbàgbọ́ pé òun ó jáde kúrò nínú òkùnkùn;
a sì ṣà á sápá kan fún idà.
Ó ń wò káàkiri fún oúnjẹ wí pé, níbo ní ó wà?
Ó mọ̀ pé ọjọ́ òkùnkùn súnmọ́ tòsí.
Ìpọ́njú pẹ̀lú ìrora ọkàn yóò mú un bẹ̀rù,
wọ́n ó sì ṣẹ́gun rẹ̀ bi ọba ti ìmúra ogun.
Nítorí pé ó ti nawọ́ rẹ̀ jáde lòdì sí Ọlọ́run,
ó sì múra rẹ̀ le lòdì sí Olódùmarè,
ó súre, ó sì fi ẹ̀yìn gíga,
àní fi ike-kókó àpáta rẹ̀ tí ó nípọn kọlù ú.
“Nítorí tí òun fi ọ̀rá rẹ̀ bo ara rẹ̀ lójú,
o sì ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹran sí ẹ̀gbẹ́ rẹ̀.
Òun sì gbé inú ahoro ìlú,
àti nínú ilẹ̀ tí ènìyàn kò gbé mọ́,
tí ó múra tán láti di àlàpà.
Òun kò lé di ọlọ́rọ̀, bẹ́ẹ̀ ohun ìní rẹ̀ kò
lè dúró pẹ́; bẹ́ẹ̀ kò lè mú pípé rẹ̀ dúró pẹ́ lórí ilẹ̀.
Òun kì yóò jáde kúrò nínú òkùnkùn;
ọ̀wọ́-iná ni yóò jó ẹ̀ka rẹ̀,
àti nípasẹ̀ ẹ̀mí ẹnu Ọlọ́run ní a ó gba kúrò.
Kí òun kí ó má ṣe gbẹ́kẹ̀lé asán, kí ó má sì ṣe tan ara rẹ̀ jẹ.
Nítorí pé asán ní yóò jásí èrè rẹ̀.
A ó mú un ṣẹ ṣáájú pípé ọjọ́ rẹ̀,
ẹ̀ka rẹ̀ kì yóò sì tutù.
Yóò dàbí àjàrà tí a gbọn èso àìpọ́n rẹ̀ dànù,
yóò sì rẹ̀ ìtànná rẹ̀ dànù bí i ti igi Olifi.
Nítorí pé ayọ̀ àwọn àgàbàgebè yóò túká,
iná ní yóò sì jó àgọ́ àwọn tí ó fẹ́ràn àbẹ̀tẹ́lẹ̀.
Wọ́n lóyún ìwà ìkà, wọ́n sì bí ẹ̀ṣẹ̀,
ikùn wọn sì pèsè ẹ̀tàn.”
Ìdáhùn Jobu fún Elifasi
Ìgbà náà ní Jobu dáhùn, ó sì wí pé,
“Èmi ti gbọ́ irú ohun púpọ̀ bẹ́ẹ̀ rí
ayọnilẹ́nu onítùnú ènìyàn ní gbogbo yín.
Ọ̀rọ̀ asán lè ni òpin?
Tàbí kí ni ó gbó ọ láyà tí ìwọ fi dáhùn?
Èmi pẹ̀lú le sọ bí ẹ̀yin;
bí ọkàn yín bá wà ní ipò ọkàn mi,
èmi le sọ ọ̀rọ̀ dáradára púpọ̀ sí yín ní ọrùn,
èmi a sì mi orí mi sí i yín.
Èmi ìbá fi ọ̀rọ̀ ẹnu mi gbà yín ni ìyànjú,
àti ṣíṣí ètè mi ìbá sì tu ìbìnújẹ́ yín.
“Bí èmi tilẹ̀ sọ̀rọ̀, ìbìnújẹ́ mi kò lọ;
bí mo sì tilẹ̀ dákẹ́, níbo ni ìtùnú mí ko kúrò?
Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, ó dá mi lágara;
ìwọ Ọlọ́run mú gbogbo ẹgbẹ́ mi takété.
Ìwọ fi ìhunjọ kùn mí lára, èyí tí o jẹ́rìí tì mí;
àti rírù tí ó hàn lára mi, ó jẹ́rìí tì mí ní ojú.
Ọlọ́run fi i ìbínú rẹ̀ fà mí ya, ó sì gbóguntì mí;
ó pa eyín rẹ̀ keke sí mi,
ọ̀tá mi sì gbójú rẹ̀ sí mi.
Wọ́n ti fi ẹnu wọn yẹ̀yẹ́ mi;
Wọ́n gbá mi ní ẹ̀rẹ̀kẹ́ ni ìgbá ẹ̀gàn;
wọ́n kó ara wọn pọ̀ sí mi.
Ọlọ́run ti fi mí lé ọwọ́ ẹni búburú,
ó sì mú mi ṣubú sí ọwọ́ ènìyàn ìkà.
Mo ti jókòó jẹ́ẹ́, ṣùgbọ́n ó fà mí já;
ó sì dì mí ni ọrùn mú, ó sì gbọ̀n mí túútúú,
ó sì gbé mi kalẹ̀ láti ṣe àmì ìtafàsí rẹ̀;
àwọn tafàtafà rẹ̀ dúró yí mi káàkiri.
Ó là mí láyà pẹ̀rẹ̀, kò si dá sí,
ó sì tú òróòro ara mi dà sílẹ̀.
Ìbàjẹ́ lórí ìbàjẹ́ ní ó fi bà mí jẹ́;
ó súré kọlù mi bí jagunjagun.
“Mo rán aṣọ ọ̀fọ̀ bò ara mi,
mo sì rẹ̀ ìwo mi sílẹ̀ nínú erùpẹ̀.
Ojú mi ti pọ́n fún ẹkún,
òjìji ikú sì ṣẹ́ sí ìpéǹpéjú mi.
Kì í ṣe nítorí àìṣòótọ́ kan ní ọwọ́ mi;
àdúrà mi sì mọ́ pẹ̀lú.
“Háà! Ilẹ̀ ayé, ìwọ má ṣe bò ẹ̀jẹ̀ mi,
kí ẹkún mi má ṣe wà ní ipò kan.
Ǹjẹ́ nísinsin yìí kíyèsi i, ẹlẹ́rìí mi ń bẹ ní ọ̀run,
ẹ̀rí mi sì ń bẹ lókè ọ̀run.
Àwọn ọ̀rẹ́ mi ń fi mí ṣẹ̀sín,
ṣùgbọ́n ojú mi ń da omijé sọ́dọ̀ Ọlọ́run,
ìbá ṣe pé ẹnìkan le è máa ṣe alágbàwí fún ẹnìkejì lọ́dọ̀ Ọlọ́run,
bí ènìyàn kan ti í ṣe alágbàwí fún ẹnìkejì rẹ̀.
“Nítorí nígbà tí iye ọdún díẹ̀ rékọjá tán,
nígbà náà ni èmi ó lọ sí ibi tí èmi kì yóò padà bọ̀.”
Ìdáhùn Jobu
“Ẹ̀mí mi bàjẹ́,
ọjọ́ mi ni a ti gé kúrú,
isà òkú dúró dè mí.
Nítòótọ́ àwọn ẹlẹ́yà wà lọ́dọ̀ mi,
ojú mi sì tẹ̀mọ́ ìmúnibínú wọn.
“Fi fún mi Olúwa, ìlérí tí ìwọ fẹ́;
ta ni yóò le ṣe ààbò fún mi?
Nítorí pé ìwọ ti sé wọ́n láyà kúrò nínú òye;
nítorí náà ìwọ kì yóò gbé wọn lékè.
Ẹni tí ó sọ ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn dídún fún àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ fún èrè,
òun ni ojú àwọn ọmọ rẹ̀ yóò mú òfo.
“Ọlọ́run ti sọ mi di ẹni òwe fún àwọn ènìyàn;
níwájú wọn ni mo dàbí ẹni ìtutọ́ sí ní ojú.
Ojú mí ṣú bàìbàì nítorí ìbìnújẹ́,
gbogbo ẹ̀yà ara mi sì dàbí òjìji.
Àwọn olódodo yóò yanu sí èyí,
ẹni aláìṣẹ̀ sì bínú sí àwọn àgàbàgebè.
Olódodo pẹ̀lú yóò di ọ̀nà rẹ̀ mú,
àti ọlọ́wọ́ mímọ́ yóò máa lera síwájú.
“Ṣùgbọ́n bí ó ṣe ti gbogbo yín,
ẹ yípadà, kí ẹ si tún padà nísinsin yìí;
èmi kò le rí ọlọ́gbọ́n kan nínú yín.
Ọjọ́ tí èmi ti kọjá, ìrò mi ti fà yá,
àní ìrò ọkàn mi.
Àwọn ènìyàn wọ̀nyí ń ṣọ́ òru di ọ̀sán;
wọ́n ní, ìmọ́lẹ̀ súnmọ́ ibi tí òkùnkùn dé.
Bí mo tilẹ̀ ní ìrètí, ipò òku ní ilé mi;
mo ti tẹ́ ibùsùn mi sínú òkùnkùn.
Èmi ti wí fún ìdíbàjẹ́ pé, ìwọ ni baba mi,
àti fún kòkòrò pé, ìwọ ni ìyá mi àti arábìnrin mi,
ìrètí mi ha dà nísinsin yìí?
Bí ó ṣe ti ìrètí mi ni, ta ni yóò rí i?
Yóò sọ̀kalẹ̀ lọ sínú ipò òkú,
nígbà tí a jùmọ̀ sinmi pọ̀ nínú erùpẹ̀ ilẹ̀?”
Ìdáhùn Bilidadi
Ìgbà náà ni Bilidadi, ará Ṣuhi, dáhùn, ó sì wí pé,
“Nígbà wo ni ẹ̀yin yóò tó fi ìdí ọ̀rọ̀ tì;
ẹ rò ó, nígbẹ̀yìn rẹ̀ ni àwa ó tó máa sọ.
Nítorí kí ni a ṣe ń kà wá sí bí ẹranko,
tí a sì ń kà wá si bí ẹni ẹ̀gàn ní ojú yín?
Ìwọ fa ara rẹ ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ nínú ìbínú rẹ̀;
kí a ha kọ ayé sílẹ̀ nítorí rẹ̀ bi?
Tàbí kí a sí àpáta kúrò ní ipò rẹ̀?
“Nítòótọ́ ìmọ́lẹ̀ ènìyàn búburú ni a ó pa kúrò,
ọ̀wọ́-iná rẹ̀ kì yóò sì tan ìmọ́lẹ̀.
Ìmọ́lẹ̀ yóò di òkùnkùn nínú àgọ́ rẹ̀,
fìtílà ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ ni a ó sì pa pẹ̀lú.
Ìrìn ẹsẹ̀ agbára rẹ̀ yóò di fífọ;
ète òun tìkára rẹ̀ ni yóò bí i ṣubú.
Nípa ẹ̀ṣẹ̀ òun tìkára rẹ̀ ó ti bọ́ sínú àwọ̀n,
ó sì rìn lórí okùn dídẹ.
Tàkúté ni yóò mú un ní gìgísẹ̀,
àwọn àwọ̀n tí a dẹ yóò sì ṣẹ́gun rẹ̀.
A dẹkùn sílẹ̀ fún un lórí ilẹ̀,
a sì wà ọ̀fìn fún un lójú ọ̀nà.
Ẹ̀rù ńlá yóò bà á ní ìhà gbogbo,
yóò sì lé e dé ẹsẹ̀ rẹ̀.
Àìlera rẹ̀ yóò di púpọ̀ fún ebi,
ìparun yóò dìde dúró sí i nígbà tí ó bá ṣubú.
Yóò jẹ ẹ̀yà ara rẹ̀;
ikú àkọ́bí ni yóò jẹ agbára rẹ̀ run.
A ó fà á tu kúrò nínú àgọ́ tí ó gbẹ́kẹ̀lé,
a ó sì mú un tọ ọba ẹ̀rù ńlá nì lọ.
Yóò sì máa jókòó nínú àgọ́ rẹ̀ èyí tí í ṣe tirẹ̀;
sulfuru ti o jóná ni a ó fún káàkiri ibùgbé rẹ̀.
Gbòǹgbò rẹ̀ yóò gbẹ níṣàlẹ̀,
a ó sì ké ẹ̀ka rẹ̀ kúrò lókè.
Ìrántí rẹ̀ yóò parun kúrò ni ayé,
kì yóò sí orúkọ rẹ̀ ní ìgboro ìlú.
A ó sì lé e láti inú ìmọ́lẹ̀ sí inú òkùnkùn,
a ó sì lé e kúrò ní ayé.
Kì yóò ní ọmọ tàbí ọmọ ọmọ nínú àwọn ènìyàn rẹ̀,
bẹ́ẹ̀ ni kò sí ẹnikẹ́ni tí yóò kù nínú agbo ilé rẹ̀.
Ẹnu yóò ya àwọn ìran ti ìwọ̀-oòrùn sí ìgbà ọjọ́ rẹ̀,
gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rù ìwárìrì ti í bá àwọn ìran ti ìlà-oòrùn.
Nítòótọ́ irú bẹ́ẹ̀ ni ibùgbé àwọn
ènìyàn búburú, èyí sì ni ipò ẹni tí kò mọ̀ Ọlọ́run.”
Ìdáhùn Jobu fún Bilidadi
Ìgbà náà ni Jobu dáhùn, ó sì wí pé:
“Yóò ti pẹ́ tó tí ẹ̀yin ó fi máa fi ìyà jẹ mí,
tí ẹ̀yin ó fi máa fi ọ̀rọ̀ yìí?
Ìgbà mẹ́wàá ní yin yọ mi lénu ẹ̀yin ti ń gàn mí;
ojú kò tì yín tí ẹ fi jẹ mí ní yà.
Kí a sì wí bẹ́ẹ̀ pé, mo ṣìnà nítòótọ́,
ìṣìnà mi wà lára èmi tìkára mi.
Bí ó tilẹ̀ ṣe pé ẹ̀yin ó ṣògo si mi lórí nítòótọ́,
tí ẹ ó sì máa fi ẹ̀gàn mi gún mí lójú,
kí ẹ mọ̀ nísinsin yìí pé, Ọlọ́run ni ó bì mí ṣubú,
ó sì nà àwọ̀n rẹ̀ yí mi ká.
“Kíyèsi, èmi ń kígbe pe, ‘Ọwọ́ alágbára!’ Ṣùgbọ́n a kò gbọ́ ti èmi;
mo kígbe fún ìrànlọ́wọ́, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ìdájọ́.
Ó ṣọgbà dí ọ̀nà mi tí èmi kò le è kọjá,
Ó sì mú òkùnkùn ṣú sí ipa ọ̀nà mi.
Ó ti bọ́ ògo mi,
ó sì ṣí adé kúrò ní orí mi.
Ó ti bà mí jẹ́ ní ìhà gbogbo,
ẹ̀mí sì pin; ìrètí mi ni a ó sì fàtu bí igi.
Ó sì tiná bọ ìbínú rẹ̀ sí mi,
ó sì kà mí sí bí ọ̀kan nínú àwọn ọ̀tá rẹ̀.
Ẹgbẹ́ ogun rẹ̀ sì dàpọ̀ sí mi,
wọ́n sì mọ odi yí mi ká,
wọ́n sì yí àgọ́ mi ká.
“Ó mú àwọn arákùnrin mi jìnà sí mi réré,
àti àwọn ojúlùmọ̀ mi di àjèjì sí mi pátápátá.
Àwọn alájọbí mi fàsẹ́yìn,
àwọn ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ mi sì di onígbàgbé mi.
Àwọn ará inú ilé mi àti àwọn ìránṣẹ́bìnrin mi kà mí sí àjèjì;
èmi jásí àjèjì ènìyàn ní ojú wọn.
Mo pe ìránṣẹ́ mi, òun kò sì dá mi lóhùn;
mo fi ẹnu mi bẹ̀ ẹ́.
Ẹ̀mí mi ṣú àyà mi, àti òórùn mi
ṣú àwọn ọmọ inú ìyá mi.
Àní àwọn ọmọdékùnrin fi mí ṣẹ̀sín,
mo dìde, wọ́n sì sọ̀rọ̀ ẹ̀gàn sí mi.
Gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ kòríkòsùn mi kórìíra mi,
àwọn olùfẹ́ mi sì kẹ̀yìndà mí.
Egungun mi lẹ̀ mọ́ ara mi àti mọ́ ẹran-ara mi,
mo sì yọ́ pẹ̀lú awọ eyín mi.
“Ẹ ṣàánú fún mi, ẹ ṣàánú fún mi,
ẹ̀yin ọ̀rẹ́ mi, nítorí ọwọ́ Ọlọ́run ti bà mí.
Nítorí kí ni ẹ̀yin ṣe lépa mi bí
Ọlọ́run, tí ẹran-ara mi kò tẹ́ yín lọ́rùn?
“Háà! Ìbá ṣe pé a le kọ̀wé ọ̀rọ̀ mi nísinsin yìí,
ìbá ṣe pé a le kọ ọ sínú ìwé!
Kí a fi kálámù irin àti ti òjé kọ
wọ́n sínú àpáta fún láéláé.
Nítorí èmi mọ̀ pé olùdáǹdè mi ń bẹ láààyè
àti pe òun ni yóò dìde dúró lórí ilẹ̀ ní ìkẹyìn;
àti lẹ́yìn ìgbà tí a pa àwọ̀ ara mi run,
síbẹ̀ láìsí ẹran-ara mi ni èmi ó rí Ọlọ́run,
ẹni tí èmi ó rí fún ara mi,
tí ojú mi ó sì wo, kì sì í ṣe ti ẹlòmíràn;
ọkàn mi sì dákú ní inú mi.
“Bí ẹ̀yin bá wí pé, ‘Àwa ó ti lépa rẹ̀ tó!
Àti pé, gbogbo ọ̀rọ̀ náà ni a sá à rí ní ọwọ́ rẹ̀,’
kí ẹ̀yin kí ó bẹ̀rù,
nítorí ìbínú ní í mú ìjìyà wá nípa idà,
kí ẹ̀yin kí ó lè mọ̀ pé ìdájọ́ kan ń bẹ.”
Ìdáhùn Sofari
Ìgbà náà ní Sofari, ará Naama dáhùn, ó sì wí pé,
“Nítorí náà ní ìrò inú mi dá mi lóhùn,
àti nítorí èyí náà ní mo sì yára si gidigidi.
Mo ti gbọ́ ẹ̀san ẹ̀gàn mi,
ẹ̀mí òye mi sì dá mi lóhùn.
“Ìwọ kò mọ̀ èyí rí ní ìgbà àtijọ́,
láti ìgbà tí a sọ ènìyàn lọ́jọ̀ sílé ayé,
pé, orin ayọ̀ ènìyàn búburú, ìgbà kúkúrú ni,
àti pé, ní ìṣẹ́jú kan ní ayọ̀ àgàbàgebè?
Bí ọláńlá rẹ̀ tilẹ̀ gòkè dé ọ̀run,
ti orí rẹ̀ sì kan àwọsánmọ̀;
ṣùgbọ́n yóò ṣègbé láéláé bí ìgbẹ́ ara rẹ̀;
àwọn tí ó ti rí i rí yóò wí pé, ‘Òun ha dà?’
Yóò fò lọ bí àlá, a kì yóò sì rí i,
àní a ó lé e lọ bi ìran òru.
Ojú tí ó ti rí i rí kì yóò sì rí i mọ́,
bẹ́ẹ̀ ni ibùjókòó rẹ̀ kì yóò sì ri i mọ́.
Àwọn ọmọ rẹ̀ yóò máa wá àti rí ojúrere lọ́dọ̀ tálákà,
ọwọ́ rẹ̀ yóò sì kó ọrọ̀ wọn padà.
Egungun rẹ̀ kún fún agbára ìgbà èwe rẹ̀,
tí yóò bá a dùbúlẹ̀ nínú erùpẹ̀.
“Bí ìwà búburú tilẹ̀ dún ní ẹnu rẹ̀,
bí ó tilẹ̀ pa á mọ́ nísàlẹ̀ ahọ́n rẹ̀,
bí ó tilẹ̀ dá a sì, tí kò si kọ̀ ọ́ sílẹ̀,
tí ó pa á mọ́ síbẹ̀ ní ẹnu rẹ̀,
ṣùgbọ́n oúnjẹ rẹ̀ nínú ikùn rẹ̀ ti yípadà,
ó jásí òróró paramọ́lẹ̀ nínú rẹ̀;
Ó ti gbé ọrọ̀ mì, yóò sì tún bí i jáde;
Ọlọ́run yóò pọ̀ ọ́ yọ jáde láti inú rẹ̀ wá.
Ó ti fà oró paramọ́lẹ̀ mú;
ahọ́n ejò olóró ní yóò pa á.
Kì yóò rí odò wọ̀n-ọn-nì,
ìṣàn omi, odò tí ń ṣàn fún oyin àti ti òrí-àmọ́.
Ohun tí ó ṣiṣẹ́ fún ni yóò mú un padà, kí yóò sì gbé e mì;
gẹ́gẹ́ bí ọrọ̀ tí ó ní, kì yóò sì ìgbádùn nínú rẹ̀.
Nítorí tí ó fi owó rẹ̀ ni tálákà lára, ó sì ti pẹ̀yìndà si wọ́n;
nítorí ti ó fi agbára gbé ilé tí òun kò kọ́.
“Nítorí òun kò mọ̀ ìwà pẹ̀lẹ́ nínú ara rẹ̀,
kì yóò sì gbà nínú èyí tí ọkàn rẹ̀ fẹ́ sílẹ̀.
Ohun kan kò kù fún jíjẹ́ rẹ̀;
nítorí náà ọ̀rọ̀ rẹ̀ kì yóò dúró pẹ́.
Nínú ànító rẹ̀, ìdààmú yóò dé bá a;
àwọn ènìyàn búburú yóò dáwọ́jọ lé e lórí.
Yóò sì ṣe, nígbà tí ó bá fẹ́ jẹun,
Ọlọ́run yóò fà ríru ìbínú rẹ̀ sí í lórí, nígbà tó bá ń jẹun lọ́wọ́,
yóò sì rọ òjò ìbínú rẹ̀ lé e lórí.
Bi o tilẹ̀ sá kúrò lọ́wọ́ ohun ìjà ìrìn;
ọrun akọ irin ní yóò ta a po yọ.
O fà á yọ, ó sì jáde kúrò lára;
idà dídán ní ń jáde láti inú òróòro wá.
Ẹ̀rù ńlá ń bẹ ní ara rẹ̀;
òkùnkùn biribiri ní a ti pamọ́ fún ìṣúra rẹ̀.
Iná ti a kò fẹ́ ní yóò jó o run
yóò sì jẹ èyí tí ó kù nínú àgọ́ rẹ̀ run.
Ọ̀run yóò fi ẹ̀ṣẹ̀ rẹ hàn,
ayé yóò sì dìde dúró sí i.
Ìbísí ilé rẹ̀ yóò kọjá lọ,
àti ohun ìní rẹ̀ yóò sàn dànù lọ ni ọjọ́ ìbínú Ọlọ́run.
Èyí ni ìpín ènìyàn búburú láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá,
àti ogún tí a yàn sílẹ̀ fún un láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.”
Jobu dá Sofari lóhùn
Jobu wá dáhùn, ó sì wí pé,
“Ẹ tẹ́tí sílẹ̀ dáradára sì àwọn ọ̀rọ̀ mi,
kí èyí kí ó jásí ìtùnú fún mi.
Ẹ jọ̀wọ́ mi ki èmi sọ̀rọ̀;
lẹ́yìn ìgbà ìwọ le máa fi mi ṣẹ̀sín ń ṣo.
“Àròyé mi ha ṣe sí ènìyàn bí?
Èétise tí ọkàn mi kì yóò fi ṣe àìbalẹ̀?
Ẹ wò mí fín, kí ẹnu kí ó sì yà yín,
kí ẹ sì fi ọwọ́ lé ẹnu yín.
Àní nígbà tí mo rántí, ẹ̀rù bà mí,
ìwárìrì sì mú mi lára.
Nítorí kí ní ènìyàn búburú fi wà ní ayé,
tí wọ́n gbó, àní tí wọ́n di alágbára ní ipa?
Irú-ọmọ wọn fi ìdí kalẹ̀ ní ojú
wọn pẹ̀lú wọn, àti ọmọ ọmọ wọn ní ojú wọn.
Ilé wọn wà láìní ewu àti ẹ̀rù,
bẹ́ẹ̀ ni ọ̀pá ìbínú Ọlọ́run kò sí lára wọn.
Akọ màlúù wọn a máa gùn, kì í sì tàsé;
abo màlúù wọn a máa bí, kì í sì í ṣẹ́yun.
Wọn a máa rán àwọn ọmọ wọn
wẹ́wẹ́ jáde bí agbo ẹran, àwọn ọmọ wọn a sì máa jo kiri.
Wọ́n mú ohun ọ̀nà orin, ìlù àti haapu;
wọ́n sì ń yọ̀ sí ohùn fèrè.
Wọ́n n lo ọjọ́ wọn nínú ọrọ̀;
wọn sì lọ sí ipò òkú ní àlàáfíà.
Nítorí náà ni wọ́n ṣe wí fún Ọlọ́run pé, ‘Lọ kúrò lọ́dọ̀ wa!’
Nítorí pé wọn kò fẹ́ ìmọ̀ ipa ọ̀nà rẹ.
Kí ni Olódùmarè tí àwa ó fi máa sìn in?
Èrè kí ni a ó sì jẹ bí àwa ba gbàdúrà sí i?
Kíyèsi i, àlàáfíà wọn kò sí nípa ọwọ́ wọn;
ìmọ̀ ènìyàn búburú jìnnà sí mi réré.
“Ìgbà mélòó mélòó ní a ń pa fìtílà ènìyàn búburú kú?
Ìgbà mélòó mélòó ní ìparun wọn dé bá wọn,
tí Ọlọ́run sì í máa pín ìbìnújẹ́ nínú ìbínú rẹ̀?
Wọ́n dàbí àgékù koríko níwájú afẹ́fẹ́,
àti bí ìyàngbò, tí ẹ̀fúùfù ńlá fẹ́ lọ.
Ẹ̀yin wí pé, ‘Ọlọ́run to ìyà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ jọ fún àwọn ọmọ rẹ̀.’
Jẹ́ kí ó san án fún un, yóò sì mọ̀ ọ́n.
Ojú rẹ̀ yóò rí ìparun ara rẹ̀,
yóò sì máa mu nínú ríru ìbínú Olódùmarè.
Nítorí pé àlàáfíà kí ni ó ní nínú ilé rẹ̀ lẹ́yìn rẹ̀,
nígbà tí a bá ké iye oṣù rẹ̀ kúrò ní agbede-méjì?
“Ǹjẹ́ ẹnikẹ́ni le kọ Ọlọ́run ní ìmọ̀?
Òun ní í sá à ń ṣe ìdájọ́ ẹni ibi gíga.
Ẹnìkan a kú nínú pípé agbára rẹ̀,
ó wà nínú ìrora àti ìdákẹ́ pátápátá.
Ọpọ́n rẹ̀ kún fún omi ọmú,
egungun rẹ̀ sì tutù fún ọ̀rá.
Ẹlòmíràn a sì kú nínú kíkorò ọkàn rẹ̀,
tí kò sì fi inú dídùn jẹun.
Wọ́n o dùbúlẹ̀ bákan náà nínú erùpẹ̀,
kòkòrò yóò sì ṣùbò wọ́n.
“Kíyèsi i, èmi mọ̀ èrò inú yín àti
àrékérekè ọkàn yín láti ṣe ìlòdì sí mi.
Nítorí tí ẹ̀yin wí pé, ‘Níbo ní ilé ọmọ-aládé,
àti níbo ní àgọ́ àwọn ènìyàn búburú nì gbé wà?’
Ẹ̀yin kò béèrè lọ́wọ́ àwọn tí ń kọjá lọ ní ọ̀nà?
Ẹ̀yin kò mọ̀ àmì wọn,
pé ènìyàn búburú ní a fi pamọ́ fún ọjọ́ ìparun.
A ó sì mú wọn jáde ní ọjọ́ ríru ìbínú.
Ta ni yóò tako ipa ọ̀nà rẹ̀ lójúkojú,
ta ni yóò sì san án padà fún un ní èyí tí ó ti ṣe?
Síbẹ̀ a ó sì sin ín ní ọ̀nà ipò òkú,
a ó sì máa ṣọ́ ibojì òkú.
Ògúlùtu àfonífojì yóò dùn mọ́ ọn.
Gbogbo ènìyàn yóò sì máa tọ̀ ọ́ lẹ́yìn,
bí ènìyàn àìníye ti lọ síwájú rẹ̀.
“Èéha ti ṣe tí ẹ̀yin fi ń tù mí nínú lásán,
bí ò ṣe pé ní ìdáhùn yín, àrékérekè wa níbẹ̀!”
Èsì Elifasi
Ìgbà náà ni Elifasi, ará Temani, dáhùn wí pé,
“Ènìyàn lè è ṣe rere fún Ọlọ́run?
Bí ọlọ́gbọ́n ti í ṣe rere fún ara rẹ̀?
Ohun ayọ̀ ha ni fún Olódùmarè pé olódodo ni ìwọ?
Tàbí èrè kí ni fún un ti ìwọ mú ọ̀nà rẹ̀ pé?
“Yóò ha bá ọ wí bí, nítorí ìbẹ̀rù
Ọlọ́run rẹ? Yóò ha bá ọ lọ sínú ìdájọ́ bí?
Ìwà búburú rẹ kò ha tóbi,
àti ẹ̀ṣẹ̀ rẹ láìníye?
Nítòótọ́ ìwọ béèrè fún ààbò ni ọwọ́ arákùnrin rẹ láìnídìí,
ìwọ sì tú oníhòhò ní aṣọ wọn.
Ìwọ kò fi omi fún aláàárẹ̀ mu,
ìwọ sì háwọ́ oúnjẹ fún ẹni tí ebi ń pa.
Bí ó ṣe ti alágbára nì, òun ni ó ní ilẹ̀,
ọlọ́lá sì tẹ̀dó sínú rẹ̀.
Ìwọ ti rán àwọn opó padà lọ ní ọwọ́ òfo,
apá àwọn ọmọ aláìní baba ti di ṣiṣẹ́.
Nítorí náà ni ìdẹ̀kùn ṣe yí ọ káàkiri,
àti ìbẹ̀rù òjijì ń yọ ọ́ lẹ́nu.
Èéṣe tí òkùnkùn fi pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ tí ìwọ kò fi lè ríran.
Èéṣe tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ omi sì bò ọ́ mọ́lẹ̀.
“Ọlọ́run kò ha jẹ́ ẹni gíga ọ̀run?
Sá wo orí àwọn ìràwọ̀ bí wọ́n ti ga tó!
Ìwọ sì wí pé, Ọlọ́run ti ṣe mọ̀?
Òun ha lè ṣe ìdájọ́ láti inú òkùnkùn wá bí?
Ǹjẹ́ àwọsánmọ̀ tí ó nípọn jẹ ìbora fún un,
tí kò fi lè ríran; ó sì ń rìn nínú àyíká ọ̀run.
Ǹjẹ́ ìwọ fẹ́ rin ipa ọ̀nà ìgbàanì tí àwọn
ènìyàn búburú tí rìn?
A ké wọn lulẹ̀ kúrò nínú ayé láìpé ọjọ́ wọn,
ìpìlẹ̀ wọn ti da bí odò ṣíṣàn.
Àwọn ẹni tí ó wí fún Ọlọ́run pé, ‘Lọ kúrò lọ́dọ̀ wa!
Kí ni Olódùmarè yóò ṣe fún wọn?’
Síbẹ̀ ó fi ohun rere kún ilé wọn!
Ṣùgbọ́n ìmọ̀ ènìyàn búburú jìnnà sí mi!
Àwọn olódodo rí ìparun wọn, wọ́n sì yọ̀,
àwọn aláìlẹ́ṣẹ̀ sì fi wọ́n rẹ́rìn-ín ẹlẹ́yà pé,
‘Lóòtítọ́ àwọn ọ̀tá wa ni a ké kúrò,
iná yóò sì jó oró wọn run.’
“Fa ara rẹ súnmọ́ Ọlọ́run, ìwọ ó sì rí àlàáfíà;
nípa èyí ni rere yóò wá bá ọ.
Èmi bẹ̀ ọ́, gba òfin láti ẹnu rẹ̀ wá,
kí o sì to ọ̀rọ̀ rẹ̀ sí àyà rẹ.
Bí ìwọ bá yípadà sọ́dọ̀ Olódùmarè, a sì gbé ọ ró.
Bí ìwọ bá sì mú ẹ̀ṣẹ̀ jìnnà réré kúrò nínú àgọ́ rẹ,
tí ìwọ bá tẹ́ wúrà dáradára sílẹ̀,
lórí erùpẹ̀ àti wúrà Ofiri lábẹ́ òkúta odò,
nígbà náà ní Olódùmarè yóò jẹ́ wúrà rẹ,
àní yóò sì jẹ́ fàdákà fún ọ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀.
Lóòtítọ́ nígbà náà ní ìwọ ó ní inú dídùn nínú Olódùmarè,
ìwọ ó sì gbé ojú rẹ sókè sọ́dọ̀ Ọlọ́run.
Bí ìwọ bá gbàdúrà rẹ sọ́dọ̀ rẹ̀, yóò sì gbọ́ tìrẹ,
ìwọ ó sì san ẹ̀jẹ́ rẹ.
Ìwọ ó sì gbìmọ̀ ohun kan pẹ̀lú, yóò sì fi ìdí múlẹ̀ fún ọ;
ìmọ́lẹ̀ yóò sì mọ́ sípa ọ̀nà rẹ.
Nígbà tí ipa ọ̀nà rẹ bá lọ sísàlẹ̀,
nígbà náà ni ìwọ o wí pé, ‘Ìgbésókè ń bẹ!’
Ọlọ́run yóò sì gba onírẹ̀lẹ̀ là!
Yóò gba ẹni tí kì í ṣe aláìjẹ̀bi là,
a ó sì gbà á nípa mímọ́ ọwọ́ rẹ̀.”
Èsì Jobu
Ìgbà náà ni Jobu sì dáhùn wí pé,
“Àní lónìí ni ọ̀ràn mi korò;
ọwọ́ mí sì wúwo sí ìkérora mi.
Háà! èmi ìbá mọ ibi tí èmí ìbá wá
Ọlọ́run rí, kí èmí kí ó tọ̀ ọ́ lọ sí ibùgbé rẹ̀!
Èmi ìbá sì to ọ̀ràn náà níwájú rẹ̀,
ẹnu mi ìbá sì kún fún àròyé.
Èmi ìbá sì mọ ọ̀rọ̀ tí òun ìbá fi dá mi lóhùn;
òye ohun tí ìbáwí a sì yé mi.
Yóò ha fi agbára ńlá bá mi wíjọ́ bí?
Àgbẹdọ̀, kìkì pé òun yóò sì kíyèsi mi.
Níbẹ̀ ni olódodo le è bá a wíjọ́,
níwájú rẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò sì bọ́ ni ọwọ́ onídàájọ́ mi láéláé.
“Sì wò ó, bí èmi bá lọ sí iwájú,
òun kò sí níbẹ̀, àti sí ẹ̀yìn, èmi kò sì rí òye rẹ̀.
Ni apá òsì bí ó bá ṣiṣẹ́ níbẹ̀, èmi kò rí i,
ó fi ara rẹ̀ pamọ́ ni apá ọ̀tún, tí èmi kò le è rí i.
Ṣùgbọ́n òun mọ ọ̀nà tí èmi ń tọ̀,
nígbà tí ó bá dán mí wò, èmi yóò jáde bí wúrà.
Ẹsẹ̀ mí ti tẹ̀lé ipasẹ̀ ìrìn rẹ̀;
ọ̀nà rẹ̀ ni mo ti kíyèsi, tí ń kò sì yà kúrò.
Bẹ́ẹ̀ ni èmi kò padà sẹ́yìn kúrò nínú òfin ẹnu rẹ̀,
èmi sì pa ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ mọ́ ju oúnjẹ òòjọ́ lọ.
“Ṣùgbọ́n onínú kan ni òun, ta ni yóò sì yí i padà?
Èyí tí ọkàn rẹ̀ sì ti fẹ́, èyí náà ní í ṣe.
Nítòótọ́ ohun tí a ti yàn fún mi ní í ṣe;
ọ̀pọ̀lọpọ̀ irú ohun bẹ́ẹ̀ ni ó wà ní ọwọ́ rẹ̀.
Nítorí náà ni ara kò ṣe rọ̀ mí níwájú rẹ̀;
nígbà tí mo bá rò ó, ẹ̀rù a bà mi.
Nítorí pé Ọlọ́run ti pá mi ní àyà,
Olódùmarè sì ń dààmú mi.
Nítorí tí a kò tí ì ké mi kúrò níwájú òkùnkùn,
bẹ́ẹ̀ ni kò pa òkùnkùn biribiri mọ́ kúrò níwájú mi.
Ìbéèrè Jobu
“Ṣe bí ìgbà kò pamọ́ lọ́dọ̀ Olódùmarè fún ìdájọ́?
Èéṣe tí ojúlùmọ̀ rẹ̀ kò fi rí ọjọ́ rẹ̀?
Wọ́n a sún àmì ààlà ilẹ̀,
wọ́n á fi agbára kó agbo ẹran lọ, wọ́n a sì bọ́ wọn.
Wọ́n á sì da kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ aláìní baba lọ,
wọ́n a sì gba ọ̀dá màlúù opó ní ohun ògo.
Wọ́n á bi aláìní kúrò lójú ọ̀nà,
àwọn tálákà ayé a fi agbára sá pamọ́.
Kíyèsi i, bí i kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ igbó nínú ijù ni àwọn tálákà jáde lọ sí iṣẹ́ wọn,
wọ́n a tètè dìde láti wá ohun ọdẹ;
ijù pèsè oúnjẹ fún wọn àti fún àwọn ọmọ wọn.
Olúkúlùkù a sì sá ọkà oúnjẹ ẹran rẹ̀ nínú oko,
wọn a sì ká ọgbà àjàrà ènìyàn búburú.
Ní ìhòhò ni wọn máa sùn láìní aṣọ,
tí wọn kò ní ìbora nínú òtútù.
Ọ̀wààrà òjò òkè ńlá sì pa wọ́n,
wọ́n sì lẹ̀ mọ́ àpáta nítorí tí kò sí ààbò.
Wọ́n já ọmọ aláìní baba kúrò ní ẹnu ọmú,
wọ́n sì gbà ọmọ tálákà nítorí gbèsè.
Wọ́n rìn kiri ní ìhòhò láìní aṣọ;
àwọn tí ebi ń pa rẹrù ìdì ọkà.
Àwọn ẹni tí ń fún òróró nínú àgbàlá wọn,
tí wọ́n sì ń tẹ ìfúntí àjàrà, síbẹ̀ òǹgbẹ sì ń gbẹ wọn.
Àwọn ènìyàn ń kérora láti ìlú wá,
ọkàn àwọn ẹni tí ó gbọgbẹ́ kígbe sókè fún ìrànlọ́wọ́
síbẹ̀ Ọlọ́run kò kíyèsi àṣìṣe náà.
“Àwọn ni ó wà nínú àwọn tí ó ṣọ̀tẹ̀ sí ìmọ́lẹ̀,
wọn kò mọ̀ ipa ọ̀nà rẹ̀,
bẹ́ẹ̀ ni wọn kò dúró nípa ọ̀nà rẹ̀.
Apànìyàn a dìde ní àfẹ̀mọ́júmọ́,
a sì pa tálákà àti aláìní,
àti ní òru a di olè.
Ojú alágbèrè pẹ̀lú dúró kí ilẹ̀ ṣú díẹ̀;
‘Ó ní, ojú ẹnìkan kì yóò rí mi,’
ó sì fi ìbòjú bojú rẹ̀.
Ní òkùnkùn wọn á rúnlẹ̀ wọlé,
tí wọ́n ti fi ojú sọ fún ara wọn ní ọ̀sán,
wọn kò mọ̀ ìmọ́lẹ̀.
Nítorí pé bí òru dúdú ní òwúrọ̀ fún gbogbo wọn;
nítorí tí wọn sì mọ̀ ìbẹ̀rù òkùnkùn.
“Ó yára lọ bí ẹni lójú omi;
ìpín wọn ní ilé ayé ni a ó parun;
òun kò rìn lọ mọ́ ní ọ̀nà ọgbà àjàrà.
Gẹ́gẹ́ bi ọ̀dá àti òru ní í mú omi òjò-dídì yọ́,
bẹ́ẹ̀ ní isà òkú í run àwọn tó dẹ́ṣẹ̀.
Inú ìbímọ yóò gbàgbé rẹ̀,
kòkòrò ní yóò máa fi adùn jẹun lára rẹ̀;
a kì yóò rántí ènìyàn búburú mọ́;
bẹ́ẹ̀ ní a ó sì ṣẹ ìwà búburú bí ẹní ṣẹ́ igi.
Ẹni tí o hù ìwà búburú sí àgàn
tí kò ṣe rere sí opó.
Ọlọ́run fi ipá agbára rẹ̀ fa alágbára,
bí wọ́n tilẹ̀ fìdímúlẹ̀, kò sí ìrètí ìyè fún wọn.
Ọlọ́run sì fi àìléwu fún un,
àti nínú èyí ni a ó sì tì i lẹ́yìn,
ojú rẹ̀ sì wà ní ipa ọ̀nà wọn.
A gbé wọn lékè nígbà díẹ̀, wọ́n kọjá lọ;
a sì rẹ̀ wọ́n sílẹ̀, a sì mú wọn kúrò ní ọ̀nà bí àwọn ẹlòmíràn,
a sì ké wọn kúrò bí orí síírí ọkà bàbà.
“Ǹjẹ́, bí kò bá rí bẹ́ẹ̀ nísinsin yìí, ta ni yóò mú mi ní èké,
tí yóò sì sọ ọ̀rọ̀ mi di aláìníláárí?”
Ìdáhùn Bilidadi
Nígbà náà ní Bilidadi, ará Ṣuhi, dáhùn wí pé,
“Ìjọba àti ẹ̀rù ń bẹ lọ́dọ̀ Ọlọ́run rẹ̀,
òun ní i ṣe ìlàjà ní ibi gíga gíga ọ̀run.
Àwọn ọmọ-ogun rẹ̀ ha ní ìyè bí,
tàbí ara ta ni ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ kò tàn sí?
Èéha ti ṣe tí a ó fi dá ènìyàn láre lọ́dọ̀ Ọlọ́run?
Tàbí ẹni tí a bí láti inú obìnrin wá yóò ha ṣe mọ́?
Kíyèsi i, òṣùpá kò sì lè tàn ìmọ́lẹ̀,
àní àwọn ìràwọ̀ kò mọ́lẹ̀ ní ojú rẹ̀,
kí a má sọ ènìyàn tí i ṣe ìdin,
àti ọmọ ènìyàn tí í ṣe kòkòrò!”
Ìdáhùn Jobu
Ṣùgbọ́n Jobu sì dáhùn wí pé,
“Báwo ni ìwọ ń ṣe ìrànlọ́wọ́ ẹni tí kò ní ipá,
báwo ní ìwọ ń ṣe gbe apá ẹni tí kò ní agbára?
Báwo ni ìwọ ń ṣe ìgbìmọ̀ fun ẹni tí kò ní ọgbọ́n,
tàbí báwo òye rẹ to pọ to bẹ́ẹ̀?
Ta ni ó ràn ọ́ lọ́wọ́ láti sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí,
àti ẹ̀mí ta ni ó gba ẹnu rẹ sọ̀rọ̀?”
“Àwọn aláìlágbára ti isà òkú wárìrì,
lábẹ́ omi pẹ̀lú àwọn tí ń gbé inú rẹ̀.
Ìhòhò ni ipò òkú níwájú Ọlọ́run,
ibi ìparun kò sí ní ibojì.
Òun ní o nà ìhà àríwá ọ̀run ní ibi òfúrufú,
ó sì so ayé rọ̀ ní ojú asán.
Ó di omi pọ̀ nínú ìkùùkuu àwọsánmọ̀ rẹ̀ tí ó nípọn;
àwọsánmọ̀ kò sì ya nísàlẹ̀ wọn.
Ó sì fa ojú ìtẹ́ rẹ̀ sẹ́yìn,
ó sì tẹ àwọsánmọ̀ rẹ̀ sí i lórí.
Ó fi ìdè yí omi òkun ká,
títí dé ààlà ìmọ́lẹ̀ àti òkùnkùn.
Ọ̀wọ́n òpó ọ̀run wárìrì,
ẹnu sì yà wọ́n sì ìbáwí rẹ̀.
Ó fi ipá rẹ̀ dààmú omi Òkun;
nípa òye rẹ̀, ó gé agbéraga sí wẹ́wẹ́.
Nípa ẹ̀mí rẹ̀ ni ó ti ṣe ọ̀run ní ọ̀ṣọ́;
ọwọ́ rẹ̀ ni ó fi dá ejò wíwọ́ nì.
Kíyèsi i, èyí ní òpin ọ̀nà rẹ̀;
ohùn èyí tí a gbọ́ ti kéré tó!
Ta ni ẹni náà tí òye àrá agbára rẹ̀ lè yé?”
Pẹ̀lúpẹ̀lú Jobu sì tún sọkún ọ̀rọ̀ òwe rẹ̀, ó sì wí pé,
“Bí Ọlọ́run ti ń bẹ, ẹni tí ó gba ìdájọ́ mi lọ,
àti Olódùmarè tí ó bà mi ní ọkàn jẹ́,
níwọ́n ìgbà tí ẹ̀mí mi ń bẹ nínú mi,
àti tí ẹ̀mí Ọlọ́run ń bẹ nínú ihò imú mi.
Ètè mi kì yóò sọ̀rọ̀ èké,
bẹ́ẹ̀ ni ahọ́n mi kì yóò sọ̀rọ̀ ẹ̀tàn.
Kí a má rí i pé èmi ń dá yín láre;
títí èmi ó fi kú, èmi kì yóò ṣí ìwà òtítọ́ mi kúrò lọ́dọ̀ mi.
Òdodo mi ni èmi dìímú ṣinṣin, èmi kì yóò sì jọ̀wọ́ rẹ̀ lọ́wọ́;
àyà mi kì yóò sì gan ọjọ́ kan nínú ọjọ́ ayé mi.
“Kí ọ̀tá mi kí ó dàbí ènìyàn búburú,
àti ẹni tí ń dìde sí mi kí ó dàbí ẹni aláìṣòdodo.
Nítorí kí ni ìrètí àgàbàgebè,
nígbà tí Ọlọ́run bá ké ẹ̀mí rẹ̀ kúrò, nígbà tí ó sì fà á jáde?
Ọlọ́run yóò ha gbọ́ àdúrà rẹ̀,
nígbà tí ìpọ́njú bá dé sí i?
Òun ha le ní inú dídùn sí Olódùmarè?
Òun ha lé máa ké pe Ọlọ́run nígbà gbogbo?
“Èmi ó kọ́ yín ní ẹ̀kọ́ ní ti ọwọ́ Ọlọ́run:
ọ̀nà tí ń bẹ lọ́dọ̀ Olódùmarè ni èmi kì yóò fi pamọ́.
Kíyèsi i, gbogbo yín ni ó ti rí i;
kín ni ìdí ọ̀rọ̀ asán yín?
“Ẹ̀yin ni ìpín ènìyàn búburú lọ́dọ̀ Ọlọ́run,
àti ogún àwọn aninilára, tí wọ́n ó gbà lọ́wọ́ Olódùmarè.
Bí àwọn ọmọ rẹ bá di púpọ̀, fún idà ni;
àwọn ọmọ ọmọ rẹ̀ kì yóò yó fún oúnjẹ.
Àwọn tí ó kù nínú tirẹ̀ ni a ó sìnkú nínú àjàkálẹ̀-ààrùn:
àwọn opó rẹ̀ kì yóò sì sọkún fún wọn.
Bí ó tilẹ̀ kó fàdákà jọ bí erùpẹ̀,
tí ó sì dá aṣọ jọ bí amọ̀;
àwọn ohun tí ó tò jọ àwọn olóòtítọ́ ni yóò lò ó;
àwọn aláìṣẹ̀ ni yóò sì pín fàdákà rẹ̀.
Òun kọ́ ilé rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí kòkòrò aṣọ,
àti bí ahéré tí olùṣọ́ kọ́.
Ọlọ́rọ̀ yóò dùbúlẹ̀, ṣùgbọ́n òun kì yóò túnṣe bẹ́ẹ̀ mọ́,
nígbà tí ó bá la ojú rẹ̀, gbogbo rẹ̀ a lọ.
Ẹ̀rù ńlá bà á bí omi ṣíṣàn;
ẹ̀fúùfù ńlá jí gbé lọ ní òru.
Ẹ̀fúùfù ìlà-oòrùn gbé e lọ, òun sì lọ;
àti bí ìjì ńlá ó sì fà á kúrò ní ipò rẹ̀.
Nítorí pé Olódùmarè yóò kọlù ú, kì yóò sì dá sí;
òun ìbá yọ̀ láti sá kúrò ní ọwọ́ rẹ̀.
Àwọn ènìyàn yóò sì ṣápẹ́ sí i lórí,
wọn yóò sì ṣe síọ̀ sí i kúrò ní ipò rẹ̀.”
Ọ̀rọ̀ ọgbọ́n àti òye Jobu
Nítòótọ́, koto fàdákà ń bẹ,
àti ibi tí wọ́n ti máa ń da wúrà.
Nínú ilẹ̀ ni à ń gbé ń wa irin,
bàbà ni a sì ń dà láti inú òkúta wá.
Ènìyàn ni ó fi òpin si òkùnkùn,
ó sì ṣe àwárí ìṣúra
láti inú òjìji ikú sí ìhà gbogbo.
Wọ́n wa ihò ilẹ̀ tí ó jì sí àwọn tí ń gbé òkè,
àwọn tí ẹsẹ̀ ènìyàn gbàgbé wọ́n rọ́ sí ìsàlẹ̀,
wọ́n rọ́ sí ìsàlẹ̀ jìnnà sí àwọn ènìyàn.
Bí ó ṣe ti ilẹ̀ ni, nínú rẹ̀ ni oúnjẹ ti ń jáde wá,
àti ohun tí ó wà ní ìsàlẹ̀ ni ó yí padà bi iná;
òkúta ibẹ̀ ni ibi òkúta safire,
o sì ní erùpẹ̀ wúrà.
Ipa ọ̀nà náà ni ẹyẹ kò mọ̀,
àti ojú gúnnugún kò rí i rí.
Àwọn ẹranko agbéraga kò rìn ibẹ̀ rí,
bẹ́ẹ̀ ni kìnnìún tí ń ké ramúramù kò kọjá níbẹ̀ rí.
Ó fi ọwọ́ rẹ̀ lé akọ òkúta,
ó yí òkè ńlá po láti ìdí rẹ̀ wá.
Ó sì la ipa odò ṣíṣàn nínú àpáta,
ojú inú rẹ̀ sì rí ohun iyebíye gbogbo.
Ó sì ṣe ìṣàn odò kí ó má ṣe kún àkúnya,
ó sì mú ohun tí ó pamọ́ hàn jáde wá sí ìmọ́lẹ̀.
Ṣùgbọ́n níbo ni á ó gbé wá ọgbọ́n rí,
níbo sì ni òye ń gbe?
Ènìyàn kò mọ iye rẹ̀,
bẹ́ẹ̀ ni a kò le è rí i ní ilẹ̀ àwọn alààyè.
Ọ̀gbun wí pé, “Kò sí nínú mi”;
omi òkun sì wí pé, “Kò si nínú mi.”
A kò le è fi wúrà rà á,
bẹ́ẹ̀ ni a kò le è fi òsùwọ̀n wọn fàdákà ní iye rẹ̀.
A kò le è fi wúrà Ofiri, tàbí òkúta óníkìsì iyebíye,
tàbí òkúta safire díye lé e.
Wúrà àti òkúta kristali kò tó ẹgbẹ́ rẹ̀;
bẹ́ẹ̀ ni a kò le è fi ohun èlò wúrà ṣe pàṣípàrọ̀ rẹ̀.
A kò lè dárúkọ iyùn tàbí òkúta jasperi;
iye ọgbọ́n sì ju iyùn lọ.
Òkúta topasi ti Kuṣi kò tó ẹgbẹ́ rẹ̀;
bẹ́ẹ̀ ni a kò le fi wúrà dáradára díwọ̀n iye rẹ̀.
Níbo ha ni ọgbọ́n ti jáde wá?
Tàbí níbo ni òye ń gbé?
A rí i pé, ó fi ara sinko kúrò ní ojú àwọn alààyè gbogbo,
ó sì fi ara sin fún ẹyẹ ojú ọ̀run.
Ibi ìparun àti ikú wí pé,
àwa ti fi etí wa gbúròó rẹ̀.
Ọlọ́run ni ó mọ òye ipa ọ̀nà rẹ̀,
òun ni ó sì mọ ibi tí ó ń gbé.
Nítorí pé ó wòye dé òpin ayé,
ó sì rí gbogbo ìsàlẹ̀ ọ̀run,
láti dà òsùwọ̀n fún afẹ́fẹ́,
ó sì fi òsùwọ̀n wọ́n omi.
Nígbà tí ó pàṣẹ fún òjò,
tí ó sì la ọ̀nà fún mọ̀nàmọ́ná àrá,
nígbà náà ni ó rí i, ó sì sọ ọ́ jáde;
ó pèsè rẹ̀ sílẹ̀, ó sì ṣe ìwádìí rẹ̀ rí.
Àti fún ènìyàn ni ó wí pé,
“Kíyèsi i, ẹ̀rù Olúwa èyí ni ọgbọ́n,
àti láti jáde kúrò nínú ìwà búburú èyí ni òye.”
Jobu rántí ìbùkún rẹ̀ àtẹ̀yìnwá
Pẹ̀lúpẹ̀lú, Jobu sì tún tẹ̀síwájú nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, ó sì wí pé,
“Háà! ìbá ṣe pé èmi wà bí ìgbà oṣù tí ó kọjá,
bí ọjọ́ tí Ọlọ́run pa mí mọ́,
nígbà tí fìtílà rẹ tàn sí mi ní orí,
àti nípa ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ èmi rìn nínú òkùnkùn já.
Bí mo ti rí nígbà ọ̀dọ́ mi,
nígbà tí ọ̀rẹ́ Ọlọ́run tímọ́tímọ́ bùkún ilé mi,
nígbà tí Olódùmarè wà pẹ̀lú mi,
nígbà tí àwọn ọmọ mi wà yí mi ká;
nígbà tí èmi fi òrí-àmọ́ n wẹ ìṣísẹ̀ mi,
àti tí àpáta ń tú ìṣàn òróró jáde fún mi wá.
“Nígbà tí mo jáde la àárín ìlú lọ sí ẹnu ibodè,
nígbà tí mo tẹ́ ìtẹ́ mi ní ìgboro,
nígbà náà ni àwọn ọmọkùnrin rí mi,
wọ́n sì sá pamọ́, àwọn àgbà dìde dúró ní ẹsẹ̀ wọn,
àwọn ọmọ-aládé dákẹ́ ọ̀rọ̀ sísọ,
wọn a sì fi ọwọ́ wọn lé ẹnu.
Àwọn ọlọ́lá dákẹ́,
ahọ́n wọn sì lẹ̀ mọ́ èrìgì ẹnu wọn.
Nígbà tí etí gbọ́, ó sì súre fún mi,
àti nígbà tí ojú sì rí mi, ó jẹ́rìí mi,
nítorí mo gbà tálákà tí n fẹ́ ìrànlọ́wọ́,
àti aláìní baba tí kò sí olùrànlọ́wọ́ fún un.
Ẹni tí ó ń kìlọ̀ súre fún mi,
èmi sì mú àyà opó kọrin fún ayọ̀.
Èmi sì mú òdodo wọ̀ bí aṣọ,
ẹ̀tọ́ mi dàbí aṣọ ìgúnwà àti adé ọba.
Mo ṣe ojú fún afọ́jú mo sì ṣe ẹsẹ̀
fún amúnkùn ún.
Mo ṣe baba fún tálákà;
mo ṣe ìwádìí ọ̀ràn àjèjì tí èmi kò mọ̀ rí.
Mo sì ká eyín ẹ̀rẹ̀kẹ́ ènìyàn búburú,
mo sì já ohun ọdẹ náà kúrò ní eyín rẹ̀.
“Nígbà náà ni mo rò pé, ‘Èmi yóò kú nínú ilé mi,
èmi yóò sì mú ọjọ́ mi pọ̀ sí i bí iyanrìn.
Gbòǹgbò mi yóò ta kan omi,
ìrì yóò sì sẹ̀ ní gbogbo òru sí ara ẹ̀ka mi.
Ògo mi yóò wà ní ọ̀tún ní ọ̀dọ̀ mi,
ọrun mi sì padà di tuntun ní ọwọ́ mi.’
“Èmi ni ènìyàn ń dẹtí sílẹ̀ sí,
wọn a sì dúró, wọn a sì dákẹ́ rọ́rọ́ ní ìmọ̀ràn mi.
Lẹ́yìn ọ̀rọ̀ mi, wọn kò tún sọ̀rọ̀ mọ́;
ọ̀rọ̀ mi wọ̀ wọ́n ní etí ṣinṣin.
Wọn a sì dúró dè mí bí ẹni wí pé wọ́n dúró fún ọ̀wọ́ òjò;
wọn a sì mu nínú ọ̀rọ̀ mi bí ẹní mu nínú òjò àrọ̀kúrò.
Èmi sì rẹ́rìn-ín sí wọn nígbà tí wọn kò bá gbà á gbọ́;
ìmọ́lẹ̀ ojú mi jẹ́ iyebíye sí wọn.
Mo la ọ̀nà sílẹ̀ fún wọn, mo sì jókòó bí olóyè wọn.
Mo jókòó bí ọba ní àárín ológun rẹ,
mo sì rí bí ẹni tí ń tu ẹni tí ń ṣọ̀fọ̀ nínú.
Ọ̀rọ̀ ìbànújẹ́ Jobu
“Ṣùgbọ́n nísinsin yìí,
àwọn tí mo gbà ní àbúrò ń fi mí ṣe ẹlẹ́yà
baba ẹni tí èmi kẹ́gàn
láti tò pẹ̀lú àwọn ajá nínú agbo ẹran mi.
Kí ni ìwúlò agbára ọwọ́ wọn sí mi,
níwọ̀n ìgbà tí agbára wọn ti fi wọ́n sílẹ̀?
Wọ́n rù nítorí àìní àti ìyàn
wọ́n ń rìn káàkiri ní ilẹ̀ gbígbẹ
ní ibi ìkọ̀sílẹ̀ ní òru.
Àwọn ẹni tí ń já ewé iyọ̀ ní ẹ̀bá igbó;
gbogbo igikígi ni oúnjẹ jíjẹ wọn.
A lé wọn kúrò láàrín ènìyàn,
àwọn ènìyàn sì pariwo lé wọn lórí bí ẹní pariwo lé olè lórí.
A mú wọn gbe inú pàlàpálá òkúta àfonífojì,
nínú ihò ilẹ̀ àti ti òkúta.
Wọ́n ń dún ní àárín igbó
wọ́n kó ara wọn jọ pọ̀ ní abẹ́ ẹ̀gún neteli.
Àwọn ọmọ ẹni tí òye kò yé,
àní àwọn ọmọ lásán, a sì lé wọn jáde kúrò ní orí ilẹ̀.
“Ǹjẹ́ nísinsin yìí, àwọn ọmọ wọn ń fi mí ṣe ẹlẹ́yà nínú orin;
àní èmi di ẹni ìṣọ̀rọ̀ sí láàrín wọn.
Wọ́n kórìíra mi; wọ́n sá kúrò jìnnà sí mi,
wọn kò sì bìkítà láti tutọ́ sí mi lójú.
Nítorí Ọlọ́run ti tú okùn ìyè mi, ó sì pọ́n mi lójú;
àwọn pẹ̀lú sì dẹ ìdẹ̀kùn níwájú mi.
Àwọn ènìyàn lásán dìde ní apá ọ̀tún mi;
wọ́n tì ẹsẹ̀ mi kúrò,
wọ́n sì la ipa ọ̀nà ìparun sílẹ̀ dè mí.
Wọ́n da ipa ọ̀nà mi rú;
wọ́n sì sọ ìparun mi di púpọ̀,
àwọn tí kò ní olùrànlọ́wọ́.
Wọ́n ya sí mi bí i omi tí ó ya gbuuru;
ní ariwo ńlá ni wọ́n rọ́ wá.
Ẹ̀rù ńlá bà mí;
wọ́n lépa ọkàn mi bí ẹ̀fúùfù,
àlàáfíà mi sì kọjá lọ bí àwọ̀ sánmọ̀.
“Àti nísinsin yìí, ayé mi n yòrò lọ díẹ̀díẹ̀;
ọjọ́ ìpọ́njú mi dì mímú.
Òru gún mi nínú egungun mi,
èyí tí ó bù mí jẹ kò sì sinmi.
Nípa agbára ńlá rẹ̀ Ọlọ́run wà bí aṣọ ìbora fún mi,
ó sì lẹ̀ mọ́ mi ní ara yíká bí aṣọ ìlekè mi.
Ọlọ́run ti mú mi lọ sínú ẹrẹ̀,
èmi sì dàbí eruku àti eérú.
“Èmi ké pè ọ́ ìwọ Ọlọ́run, ṣùgbọ́n ìwọ kò dá mi lóhùn;
èmi dìde dúró ìwọ sì wò mí lásán.
Ìwọ padà di ẹni ìkà sí mi;
ọwọ́ agbára rẹ ni ìwọ fi dè mí ní ọ̀nà.
Ìwọ gbé mi sókè sí inú ẹ̀fúùfù, ìwọ mú mi fò lọ,
bẹ́ẹ̀ ni ìwọ sì sọ mí di asán pátápátá.
Èmi sá à mọ̀ pé ìwọ yóò mú mi lọ sínú ikú,
sí ilé ìpéjọ tí a yàn fún gbogbo alààyè.
“Bí ó ti wù kí ó rí, ẹnìkan kí yóò ha nawọ́ rẹ̀ nígbà ìṣubú rẹ̀,
tàbí kì yóò ké nínú ìparun rẹ̀.
Èmi kò ha sọkún bí fún ẹni tí ó wà nínú ìṣòro?
Ọkàn mi kò ha bàjẹ́ fún tálákà bí?
Nígbà tí mo fojú ṣọ́nà fún àlàáfíà, ibi sì dé;
nígbà tí mo dúró de ìmọ́lẹ̀, òkùnkùn sì dé.
Ikùn mí n ru kò sì sinmi,
ọjọ́ ìpọ́njú ti dé bá mi.
Èmí ń rìn kiri nínú ọ̀fọ̀, ṣùgbọ́n kì í ṣe nínú oòrùn;
èmi dìde dúró ní àwùjọ mo sì kígbe fún ìrànlọ́wọ́.
Èmi ti di arákùnrin ìkookò,
èmi di ẹgbẹ́ àwọn ògòǹgò.
Àwọ̀ mi di dúdú ní ara mi;
egungun mi sì jórun fún ooru.
Ohun èlò orin mi pẹ̀lú sì di ti ọ̀fọ̀,
àti ìpè orin mi sì di ohùn àwọn tí ń sọkún.
Àwíjàre Jobu
“Mo ti bá ojú mi dá májẹ̀mú,
èmi yó ha ṣe tẹjúmọ́ wúńdíá?
Nítorí pé kí ni ìpín Ọlọ́run láti ọ̀run wá?
Tàbí kí ni ogún Olódùmarè láti òkè ọ̀run wá.
Kò ṣe pé àwọn ènìyàn búburú ni ìparun wà fún,
àti àjàkálẹ̀-ààrùn fún àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀?
Òun kò ha ri ipa ọ̀nà mi,
òun kò ha sì ka gbogbo ìṣísẹ̀ mi?
“Bí ó bá ṣe pé èmi bá fi àìṣòótọ́ rìn,
tàbí tí ẹsẹ̀ mi sì yára sí ẹ̀tàn,
(jẹ́ kí Ọlọ́run wọ́n mí nínú ìwọ̀n òdodo,
kí Ọlọ́run le mọ ìdúró ṣinṣin mi.)
Bí ẹsẹ̀ mí bá yà kúrò lójú ọ̀nà,
tí àyà mí sì tẹ̀lé ipa ojú mi,
tàbí bí àbàwọ́n kan bá sì lẹ̀ mọ́ mi ní ọwọ́,
ǹjẹ́ kí èmi kí ó gbìn kí ẹlòmíràn kí ó sì mújẹ,
àní kí a fa irú-ọmọ mi tu.
“Bí àyà mi bá di fífà sí ipasẹ̀ obìnrin kan,
tàbí bí mo bá lọ í ba de ènìyàn ní ẹnu-ọ̀nà ilé aládùúgbò mi,
kí àyà mi kí ó lọ ọlọ fún ẹlòmíràn,
kí àwọn ẹlòmíràn kí ó tẹ̀ ara wọn ní ara rẹ̀.
Nítorí pé yóò jẹ́ ohun ìtìjú àní,
ẹ̀ṣẹ̀ tí a ó ṣe onídàájọ́ rẹ̀.
Nítorí pé iná ní èyí tí ó jó dé ibi ìparun,
tí ìbá sì fa gbòǹgbò ohun ìbísí mi gbogbo tu.
“Tí mo bá sì ṣe àìka ọ̀ràn ìránṣẹ́kùnrin mi
tàbí ìránṣẹ́bìnrin mi sí,
nígbà tí wọ́n bá ń bá mi jà;
kí ni èmi ó ha ṣe nígbà tí Ọlọ́run bá dìde?
Nígbà tí ó bá sì ṣe ìbẹ̀wò, ohùn kí ni èmi ó dá?
Ẹni tí ó dá mi ní inú kọ́ ni ó dá a?
Ẹnìkan náà kí ó mọ wá ní inú ìyá wa?
“Bí mo bá fa ọwọ́ sẹ́yìn fún ìfẹ́ inú tálákà,
tàbí bí mo bá sì mú kí ojú opó rẹ̀wẹ̀sì,
tàbí tí mo bá nìkan bu òkèlè mi jẹ,
tí aláìní baba kò jẹ nínú rẹ̀;
nítorí pé láti ìgbà èwe mi wá ni a ti tọ́ ọ dàgbà pẹ̀lú mi bí ẹni pé baba,
èmi sì ń ṣe ìtọ́jú opó láti inú ìyá mi wá:
bí èmi bá rí olùpọ́njú láìní aṣọ,
tàbí tálákà kan láìní ìbora;
bí ọkàn rẹ̀ kò bá súre fún mi,
tàbí bí ara rẹ̀ kò sì gbóná nípasẹ̀ irun àgùntàn mi;
bí mo bá sì gbé ọwọ́ mi sókè sí aláìní baba,
nítorí pé mo rí ìrànlọ́wọ́ mi ní ẹnu ibodè,
ǹjẹ́, ní apá mi kí o wọ́n kúrò ní ihò èjìká rẹ̀,
kí apá mi kí ó sì ṣẹ́ láti egungun rẹ̀ wá.
Nítorí pé ìparun láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá ni ẹ̀rù ńlá fún mi,
àti nítorí ọláńlá rẹ̀ èmi kò le è dúró.
“Bí ó bá ṣe pé mo fi wúrà ṣe ìgbẹ́kẹ̀lé mi,
tàbí tí mo bá wí fún fàdákà dídára pé, ‘Ìwọ ni ààbò mi,’
bí mo bá yọ̀ nítorí ọrọ̀ mí pọ̀,
àti nítorí ọwọ́ mi dara lọ́pọ̀lọ́pọ̀,
bí mo bá bojú wo oòrùn nígbà tí ń ràn,
tàbí òṣùpá tí ń ràn nínú ìtànmọ́lẹ̀,
bí a bá tàn ọkàn mi jẹ
láti fi ẹnu mi kò ọwọ́ mi,
èyí pẹ̀lú ni ẹ̀ṣẹ̀ ti àwọn onídàájọ́ ní láti bẹ̀wò,
nítorí pé èmí yóò jẹ́ aláìṣòótọ́ sí Ọlọ́run tí ó wà lókè.
“Bí ó bá ṣe pé mo yọ̀ sì ìparun ẹni tí ó kórìíra mi.
Tàbí bí mo bá sì gbéraga sókè, nígbà tí ibi bá a.
Bẹ́ẹ̀ èmi kò sì jẹ ki ẹnu mi ki ó ṣẹ̀
nípa fífẹ́ ègún sí ọkàn rẹ̀.
Bí àwọn ènìyàn inú àgọ́ mi kò bá lè wí pé,
‘Ta ni kò ì tí ì jẹ ẹran rẹ̀ ní àjẹyó?’
Àlejò kò wọ̀ ni ìgboro rí;
èmí ṣí ìlẹ̀kùn mi sílẹ̀ fún èrò.
Bí mo bá bò ẹ̀ṣẹ̀ mi mọ́lẹ̀ bí Adamu ni pápá,
ẹ̀bi mi pamọ́ ni àyà mi.
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ni mo ha bẹ̀rù bí?
Tàbí ẹ̀gàn àwọn ìdílé ní ń bà mí ní ẹ̀rù?
Tí mo fi pa ẹnu mọ́, tí èmí kò sì fi sọ̀rọ̀ jáde?
(“Ìbá ṣe pé ẹnìkan le gbọ́ ti èmí!
Kíyèsi i, àmì mi, kí Olódùmarè kí ó dá mi lóhùn,
kí èmí kí ó sì rí ìwé náà tí olùfisùn mi ti kọ.
Nítòótọ́ èmí ìbá gbé le èjìká mi,
èmi ìbá sì dé bí adé mọ́ orí mi.
Èmi ìbá sì sọ iye ìṣísẹ̀ mi fún un,
bí ọmọ-aládé ni èmi ìbá súnmọ́ ọ̀dọ̀ rẹ̀.)
“Bí ilẹ̀ mi bá sì ké rara lòdì sí mi
tí a sì fi omijé kún gbogbo poro rẹ̀.
Bí mo bá jẹ èso oko mi láìsan owó
tàbí tí mo sì mú ọkàn olúwa rẹ̀ fò lọ,
kí ẹ̀gún òṣùṣú kí ó hù dípò alikama,
àti èpò búburú dípò ọkà barle.”
Ọ̀rọ̀ Jobu parí.
Ọ̀rọ̀ Elihu
Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọkùnrin mẹ́tẹ̀ẹ̀ta wọ̀nyí dákẹ́ láti dá Jobu lóhùn, nítorí ó ṣe olódodo lójú ara rẹ̀. Nígbà náà ni inú bí Elihu ọmọ Barakeli ará Busi, láti ìbátan ìdílé Ramu; ó bínú si Jobu nítorí ti ó dá ara rẹ̀ láre kàkà ki ó dá Ọlọ́run láre. Inú sì bí i sí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta, nítorí tí wọn kò rí ọ̀nà láti dá Jobu lóhùn bẹ́ẹ̀ ni wọ́n dá Jobu lẹ́bi. Ǹjẹ́ Elihu ti dúró títí tí Jobu fi sọ̀rọ̀ tán nítorí tí àwọn wọ̀nyí dàgbà ju òun lọ ní ọjọ́ orí. Nígbà tí Elihu rí i pé ìdáhùn ọ̀rọ̀ kò sí ní ẹnu àwọn ọkùnrin mẹ́tẹ̀ẹ̀ta wọ̀nyí nígbà náà ni ó bínú.
Elihu, ọmọ Barakeli, ará Busi, dáhùn ó sì wí pé,
“Ọmọdé ni èmi,
àgbà sì ní ẹ̀yin;
ǹjẹ́ nítorí náà ní mo dúró,
mo sì ń bẹ̀rù láti fi ìmọ̀ mi hàn yin.
Èmi wí pé ọjọ́ orí ni ìbá sọ̀rọ̀,
àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún ní ìbá kọ́ ni ní ọgbọ́n.
Ṣùgbọ́n ẹ̀mí kan ní ó wà nínú ènìyàn
àti ìmísí Olódùmarè ní ì sì máa fún wọn ní òye.
Ènìyàn ńlá ńlá kì í ṣe ọlọ́gbọ́n,
bẹ́ẹ̀ ni àwọn àgbà ní òye ẹ̀tọ́ kò yé.
“Nítorí náà ní èmí ṣe wí pé, ẹ dẹtí sílẹ̀ sí mi;
èmí pẹ̀lú yóò fi ìmọ̀ mi hàn.
Kíyèsi i, èmí ti dúró de ọ̀rọ̀ yín;
èmi fetísí àròyé yín,
nígbà tí ẹ̀yin ń wá ọ̀rọ̀ ti ẹ̀yin yóò sọ;
àní, mo fiyèsí yín tinútinú.
Sì kíyèsi i, kò sí ẹnìkan nínú yín tí ó le já Jobu ní irọ́;
tàbí tí ó lè dá a lóhùn àríyànjiyàn rẹ̀!
Kí ẹ̀yin kí ó má ṣe wí pé, ‘Àwa wá ọgbọ́n ní àwárí;
Ọlọ́run ni ó lè bì í ṣubú kì í ṣe ènìyàn.’
Bí òun kò ti sọ̀rọ̀ sí mi,
bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò fi ọ̀rọ̀ yín dá a lóhùn.
“Ẹnu sì yà wọ́n, wọn kò sì dáhùn mọ́,
wọ́n ṣíwọ́ ọ̀rọ̀ í sọ.
Mo sì retí, nítorí wọn kò sì fọhùn, wọ́n dákẹ́ jẹ́ẹ́;
wọn kò sì dáhùn mọ́.
Bẹ́ẹ̀ ni èmí ó sì dáhùn nípa ti èmi,
èmí pẹ̀lú yóò sì fi ìmọ̀ mi hàn.
Nítorí pé èmi kún fún ọ̀rọ̀ sísọ,
ẹ̀mí ń rọ̀ mi ni inú mi.
Kíyèsi i, ikùn mi dàbí ọtí wáìnì, tí kò ní ojú-ìhò;
ó múra tán láti bẹ́ bí ìgò-awọ tuntun.
Èmí ó sọ, kí ara kí ó le rọ̀ mí,
èmí ó sí ètè mi, èmí ó sì dáhùn.
Lóòtítọ́ èmi kì yóò ṣe ojúsàájú sí ẹnìkankan,
bẹ́ẹ̀ ni èmí kì yóò sì ṣe ìpọ́nni fún ẹnìkan.
Nítorí pé èmí kò mọ̀ ọ̀rọ̀ ìpọ́nni í sọ ní ṣíṣe bẹ́ẹ̀,
ẹlẹ́dàá mi yóò mú mi kúrò lọ́gán.
Elihu bá Jobu sọ̀rọ̀
“Ǹjẹ́ nítorí náà, Jobu, èmí bẹ̀ ọ,
gbọ́ ọ̀rọ̀ mi kí o sì fetísí ọ̀rọ̀ mi!
Kíyèsi i nísinsin yìí, èmí ya ẹnu mi,
ahọ́n mi sì sọ̀rọ̀ ní ẹnu mi.
Ọ̀rọ̀ mi yóò sì jásí ìdúró ṣinṣin ọkàn mi,
ètè mi yóò sì sọ ìmọ̀ mi jáde dájúdájú.
Ẹ̀mí Ọlọ́run ni ó tí dá mi,
àti ìmísí Olódùmarè ni ó ti fún mi ní ìyè.
Bí ìwọ bá le dá mi lóhùn,
tò ọ̀rọ̀ rẹ̀ lẹ́sẹẹsẹ níwájú mi;
kíyèsi i, bí ìwọ ṣe jẹ́ ti Ọlọ́run, bẹ́ẹ̀ ni èmi náà;
láti amọ̀ wá ni a sì ti dá mi pẹ̀lú.
Kíyèsi i, ẹ̀rù ńlá mi kì yóò bà ọ;
bẹ́ẹ̀ ni ọwọ́ mi kì yóò wúwo sí ọ lára.
“Nítòótọ́ ìwọ sọ ní etí mi,
èmí sì gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ wí pé,
‘Èmi mọ́, láìní ìrékọjá, aláìṣẹ̀ ní èmi;
bẹ́ẹ̀ àìṣedéédéé kò sí ní ọwọ́ mi.
Kíyèsi i, Ọlọ́run ti rí àìṣedéédéé pẹ̀lú mi;
ó kà mí sì ọ̀tá rẹ̀.
Ó kan ẹ̀ṣẹ̀ mi sínú àbà;
o kíyèsi ipa ọ̀nà mi gbogbo.’
“Kíyèsi i, nínú èyí ìwọ ṣìnà!
Èmi ó dá ọ lóhùn pé, Ọlọ́run tóbi jù ènìyàn lọ!
Nítorí kí ni ìwọ ṣe ń bá a jà, wí pé,
òun kò ní sọ ọ̀rọ̀ kan nítorí iṣẹ́ rẹ̀?
Nítorí pe Ọlọ́run sọ̀rọ̀ lẹ́ẹ̀kan,
àní, lẹ́ẹ̀kejì, ṣùgbọ́n ènìyàn kò róye rẹ̀.
Nínú àlá, ní ojúran òru,
nígbà tí orun èjìká bá kùn ènìyàn lọ,
ní sísùn lórí ibùsùn,
nígbà náà ni ó lè sọ̀rọ̀ ní etí wọn,
yóò sì dẹ́rùbà wọ́n pẹ̀lú ìbáwí,
kí ó lè fa ènìyàn sẹ́yìn kúrò nínú ètè rẹ̀;
kí ó sì pa ìgbéraga mọ́ kúrò lọ́dọ̀ ènìyàn;
Ó sì fa ọkàn rẹ̀ padà kúrò nínú isà òkú,
àti ẹ̀mí rẹ̀ láti ṣègbé lọ́wọ́ idà.
“A sì nà án lórí ibùsùn ìrora rẹ̀;
pẹ̀lúpẹ̀lú a fi ìjà egungun rẹ̀ ti ó dúró pẹ́ nà án,
bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀mí rẹ kọ oúnjẹ,
ọkàn rẹ̀ sì kọ oúnjẹ dídùn.
Ẹran-ara rẹ̀ run, títí a kò sì fi lè rí i mọ́
egungun rẹ̀ tí a kò tí rí sì ta jáde.
Àní, ọkàn rẹ̀ sì súnmọ́ isà òkú,
ẹ̀mí rẹ̀ sì súnmọ́ ọ̀dọ̀ àwọn ìránṣẹ́ ikú.
Bí angẹli kan ba wà lọ́dọ̀ rẹ̀,
ẹni tí ń ṣe alágbàwí,
ọ̀kan nínú ẹgbẹ̀rún (1,000) láti fi ọ̀nà pípé hàn ni,
nígbà náà ni ó ṣe oore-ọ̀fẹ́ fún un ó sì wí pé,
gbà á kúrò nínú lílọ sínú isà òkú;
èmi ti rà á padà.
Ara rẹ̀ yóò sì di ọ̀tun bí i ti ọmọ kékeré,
yóò sì tún padà sí ọjọ́ ìgbà èwe rẹ̀;
Ó gbàdúrà sọ́dọ̀ Ọlọ́run, òun sì ṣe ojúrere rẹ̀,
o sì rí ojú rẹ̀ pẹ̀lú ayọ̀,
òhun o san òdodo rẹ̀ padà fún ènìyàn.
Ó wá sọ́dọ̀ ènìyàn ó sì wí pé,
‘Èmi ṣẹ̀, kò sì ṣí èyí tí o tọ́, mo sì ti yí èyí tí ó tọ́ po,
a kò sì san ẹ̀san rẹ̀ fún mi;
Ọlọ́run ti gba ọkàn mi kúrò nínú lílọ sínú ihò,
ẹ̀mí mi yóò wà láti jẹ adùn ìmọ́lẹ̀ ayé.’
“Wò ó! Nǹkan wọ̀nyí ni Ọlọ́run
máa ń ṣe fún ènìyàn nígbà méjì àti nígbà mẹ́ta,
láti mú ọkàn rẹ padà kúrò nínú isà òkú,
láti fi ìmọ́lẹ̀ alààyè han sí i.
“Jobu, kíyèsi i gidigidi, kí o sì fetí sí mi;
pa ẹnu rẹ mọ́, èmi ó sì máa sọ ọ́.
Bí ìwọ bá sì ní ohun wí, dá mi lóhùn;
máa sọ, nítorí pé èmi fẹ́ dá ọ láre.
Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, gbọ́ tèmi;
pa ẹnu rẹ mọ́, èmi ó sì kọ́ ọ ní ọgbọ́n.”
Elihu pe Jobu níjà
Nígbà náà ni Elihu dáhùn, ó sì wí pé,
“Ẹ̀yin ọlọ́gbọ́n ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ mi,
kí ẹ sì fi etí sílẹ̀ sí mi ẹ̀yin tí ẹ ní ìmòye.
Nítorí pé etí a máa dán ọ̀rọ̀ wò,
bí adùn ẹnu ti ń tọ́ oúnjẹ wò.
Ẹ jẹ́ kí a mọ òye ohun tí o tọ́ fún ara wa;
ẹ jẹ́ kí a mọ ohun tí ó dára láàrín wa.
“Nítorí pé Jobu wí pé, ‘Aláìlẹ́ṣẹ̀ ni èmi;
Ọlọ́run sì ti gba ìdájọ́ mi lọ.
Èmi ha purọ́ sí ẹ̀tọ́ mi bí,
bí mo tilẹ̀ jẹ́ aláìjẹ̀bi,
ọfà rẹ̀ kò ní àwòtán ọgbẹ́.’
Ọkùnrin wo ni ó dàbí Jobu,
tí ń mu ẹ̀gàn bí ẹní mú omi?
Tí ń bá àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ kẹ́gbẹ́ tí ó
sì ń bá àwọn ènìyàn búburú rìn.
Nítorí ó sá ti wí pé, ‘Èrè kan kò sí fún ènìyàn,
tí yóò fi máa ṣe inú dídùn sí Ọlọ́run.’
“Ǹjẹ́ nítorí náà, ẹ fetísílẹ̀ sí mi,
ẹ fi etí sí mi ẹ̀yin ènìyàn amòye:
Ó di èèwọ̀ fún Ọlọ́run ti ìbá fi hùwà búburú,
àti fún Olódùmarè, tí yóò fi ṣe àìṣedéédéé!
Nítorí pé ó ń sán fún ènìyàn fún gẹ́gẹ́ bi ohun tí a bá ṣe,
yóò sì mú olúkúlùkù kí ó rí gẹ́gẹ́ bí ipa ọ̀nà rẹ̀.
Nítòótọ́ Ọlọ́run kì yóò hùwàkiwà;
bẹ́ẹ̀ ni Olódùmarè kì yóò yí ìdájọ́ po.
Ta ni ó fi ìtọ́jú ayé lé e lọ́wọ́,
tàbí ta ni ó fi gbogbo ayé lé e lọ́wọ́?
Bí ó bá gbé ayé rẹ̀ lé kìkì ara rẹ̀
tí ó sì gba ọkàn rẹ̀ àti ẹ̀mí rẹ̀ sọ́dọ̀ ara rẹ̀,
gbogbo ènìyàn ni yóò parun pọ̀,
ènìyàn a sì tún padà di erùpẹ̀.
“Ǹjẹ́ nísinsin yìí, bí ìwọ bá ní òye,
gbọ́ èyí; fetísí ohùn ẹnu mi.
Ẹni tí ó kórìíra òtítọ́ ha le ṣe olórí bí?
Ìwọ ó ha sì dá olóòótọ́ àti ẹni ńlá lẹ́bi?
O ha tọ́ láti wí fún ọba pé, ‘Ènìyàn búburú ní ìwọ,’
tàbí fún àwọn ọmọ-aládé pé, ‘Ìkà ni ẹ̀yin,’
mélòó mélòó fún ẹni tí kì í ṣe ojúsàájú àwọn ọmọ-aládé
tàbí tí kò kà ọlọ́rọ̀ sí ju tálákà lọ,
nítorí pé iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ ni gbogbo wọn í ṣe?
Ní ìṣẹ́jú kan ni wọn ó kú,
àwọn ènìyàn á sì di yíyọ́ lẹ́nu láàrín ọ̀gànjọ́, wọn a sì kọjá lọ;
a sì mú àwọn alágbára kúrò láìsí ọwọ́ ènìyàn níbẹ̀.
“Nítorí pé ojú rẹ̀ ń bẹ ní ipa ọ̀nà ènìyàn,
òun sì rí ìrìn rẹ̀ gbogbo.
Kò sí ibi òkùnkùn, tàbí òjìji ikú,
níbi tí àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ yóò gbé sá pamọ́ sí.
Nítorí pé òun kò pẹ́ àti kíyèsi ẹnìkan,
kí òun kí ó sì mú lọ sínú ìdájọ́ níwájú Ọlọ́run.
Òun ó sì fọ́ àwọn alágbára túútúú láìní ìwádìí,
a sì fi ẹlòmíràn dípò wọn,
nítorí pé ó mọ iṣẹ́ wọn,
ó sì yí wọn po ní òru, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n di ìtẹ̀mọ́lẹ̀.
Ó kọlù wọ́n nítorí ìwà búburú wọn
níbi tí àwọn ẹlòmíràn ti lè rí i,
nítorí pé wọ́n padà pẹ̀yìndà sí i,
wọn kò sì fiyèsí ipa ọ̀nà rẹ̀ gbogbo,
kí wọn kí ó sì mú igbe ẹkún àwọn tálákà lọ dé ọ̀dọ̀ rẹ̀,
òun sì gbọ́ igbe ẹkún aláìní.
Ṣùgbọ́n nígbà tí ó bá dákẹ́ síbẹ̀, ta ni yóò dá lẹ́bi?
Nígbà tí ó bá pa ojú rẹ̀ mọ́, ta ni yóò lè rí i?
Bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe si orílẹ̀-èdè tàbí sí ènìyàn kan ṣoṣo;
kí aláìwà bi Ọlọ́run kí ó má bá à jẹ ọba
kí wọn kí ó má di ìdẹwò fún ènìyàn.
“Nítorí pé ẹnìkan ha lè wí fún Ọlọ́run pé,
èmi jẹ̀bi, èmi kò sì ní ṣẹ̀ mọ́?
Èyí tí èmi kò rí ìwọ fi kọ́ mi
bi mo bá sì dẹ́ṣẹ̀ èmi kì yóò ṣe bẹ́ẹ̀ mọ́.
Ǹjẹ́ bí ti inú rẹ̀ ni ki òun ó san ẹ̀ṣẹ̀ padà?
Ǹjẹ́ òun yóò san án padà bí ìwọ bá kọ̀ ọ́ láti jẹ́wọ́,
ìwọ gbọdọ̀ yan, kì í ṣe èmi.
Nítorí náà sọ ohun tí o mọ̀,
pẹ̀lúpẹ̀lú ohun tí ìwọ mọ̀, sọ ọ́!
“Àwọn ènìyàn amòye yóò wí fún mi,
àti pẹ̀lúpẹ̀lú ẹnikẹ́ni tí í ṣe ọlọ́gbọ́n tí ó sì gbọ́ mi pé,
‘Jobu ti fi àìmọ̀ sọ̀rọ̀,
ọ̀rọ̀ rẹ̀ sì ṣe aláìgbọ́n.’
Ìfẹ́ mi ni kí a dán Jobu wò dé òpin,
nítorí ìdáhùn rẹ̀ dàbí i ti ènìyàn búburú.
Nítorí pe ó fi ìṣọ̀tẹ̀ kún ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀;
ó pàtẹ́wọ́ ní àárín wa,
ó sì sọ ọ̀rọ̀ odi púpọ̀ sí Ọlọ́run.”
Olóòtítọ́ ni Ọlọ́run
Elihu sì wí pe:
“Ìwọ rò pé èyí ha tọ́, tí ìwọ wí pé,
òdodo mi ni èyí níwájú Ọlọ́run?
Nítorí tí ìwọ wí pé èrè kí ní yóò jásí fún ọ,
tàbí èrè kí ni èmi yóò fi jẹ́ ju èrè ẹ̀ṣẹ̀ mi lọ.
“Èmi ó dá ọ lóhùn
àti àwọn ẹgbẹ́ rẹ pẹ̀lú rẹ.
Síjú wo ọ̀run; kí o rí i, kí ó sì
bojú wo àwọsánmọ̀ tí ó ga jù ọ́ lọ.
Bí ìwọ bá dẹ́ṣẹ̀, kí ni ìwọ fi sẹ̀ sí?
Tàbí bí ìrékọjá rẹ di púpọ̀, kí ni ìwọ fi èyí nì ṣe sí i?
Bí ìwọ bá sì ṣe olódodo, kí ni ìwọ fi fún un,
tàbí kí ni òun rí gbà láti ọwọ́ rẹ wá?
Ìwà búburú rẹ ni fún ènìyàn bí ìwọ;
òdodo rẹ sì ni fún ọmọ ènìyàn.
“Nípa ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìninilára, wọ́n mú ni kígbe;
wọ́n kígbe nípa apá àwọn alágbára.
Ṣùgbọ́n kò sí ẹni tí ó wí pé,
‘Níbo ni Ọlọ́run Ẹlẹ́dàá mi wà tí ó sì fi orin fún mi ní òru;
tí òun kọ́ wa ní ẹ̀kọ́ jù àwọn ẹranko ayé lọ,
tí ó sì mú wa gbọ́n ju àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run lọ?’
Nígbà náà ni wọ́n ń ké ṣùgbọ́n Ọlọ́run kò dáhùn
nítorí ìgbéraga ènìyàn búburú.
Nítòótọ́ Ọlọ́run kì yóò gbọ́ ọ̀rọ̀ asán;
bẹ́ẹ̀ ní Olódùmarè kì yóò kà á sí.
Bí ó tilẹ̀ ṣe pé ìwọ wí pé ìwọ kì í rí i,
ọ̀rọ̀ ìdájọ́ ń bẹ níwájú rẹ,
ẹni tí ìwọ sì gbọdọ̀ dúró dè.
Ṣùgbọ́n nísinsin yìí nítorí tí ìbínú rẹ̀ kò tí fìyà jẹ ni,
òun kò ni ka ìwà búburú si?
Nítorí náà ní Jobu ṣe ya ẹnu rẹ̀
lásán ó sọ ọ̀rọ̀ di púpọ̀ láìsí ìmọ̀.”
Elihu sì tún sọ̀rọ̀ wí pé,
“Fún mi láyè díẹ̀ èmi ó sì fihàn ọ́,
nítorí ọ̀rọ̀ sísọ ní ó kún fún Ọlọ́run.
Èmi ó mú ìmọ̀ mi ti ọ̀nà jíjìn wá,
èmi ó sì fi òdodo fún Ẹlẹ́dàá mi.
Rí i dájú pé ọ̀rọ̀ mi kì yóò ṣèké nítòótọ́;
ẹni tí ó pé ní ìmọ̀ wà pẹ̀lú rẹ̀.
“Kíyèsi i, Ọlọ́run ni alágbára, òun kò i sì gàn ènìyàn;
ó ní agbára ní ipá àti òye.
Òun kì í dá ẹ̀mí ènìyàn búburú sí,
ṣùgbọ́n ó fi òtítọ́ fún àwọn tálákà.
Òun kì í mú ojú rẹ̀ kúrò lára olódodo,
ṣùgbọ́n àwọn ọba ni wọ́n wà lórí ìtẹ́;
àní ó fi ìdí wọn múlẹ̀ láéláé, a sì gbé wọn lékè.
Bí ó bá sì dè wọ́n nínú àbà,
tí a sì fi okùn ìpọ́njú dè wọ́n,
nígbà náà ni ó ń sọ àwọn ohun tí wọn ti ṣe fún wọn,
wí pé wọ́n ti ṣẹ̀ pẹ̀lú ìgbéraga wọn.
Ó sí wọn létí pẹ̀lú sí ọ̀nà ẹ̀kọ́,
ó sì pàṣẹ kí wọn kí ó padà kúrò nínú àìṣedédé.
Bí wọ́n bá gbàgbọ́ tí wọ́n sì sìn ín,
wọn ó lo ọjọ́ wọn ní ìrọ̀rùn,
àti ọdún wọn nínú afẹ́.
Ṣùgbọ́n, bí wọn kò bá gbàgbọ́,
wọ́n ó ti ọwọ́ idà ṣègbé,
wọ́n á sì kú láìní òye.
“Ṣùgbọ́n àwọn àgàbàgebè ní ayé kó ìbínú jọ;
wọn kò kígbe fún ìrànlọ́wọ́ nígbà tí ó bá wọ́n wí.
Nígbà náà ni ọkàn wọn yóò kú ní èwe,
ní àárín àwọn ọkùnrin alágbèrè ojúbọ òrìṣà.
Òun gba òtòṣì nínú ìpọ́njú wọn,
a sì sọ̀rọ̀ sí wọn ní etí nínú ìnira wọn.
“Bẹ́ẹ̀ ni pẹ̀lúpẹ̀lú ó fa wọn yọ láti inú ìhágágá sí ibi gbòòrò,
sí ibi tí ó ní ààyè tí kò ní wàhálà nínú rẹ̀,
ohun tí a sì gbé kalẹ̀ ní tábìlì rẹ̀ jẹ́ kìkì ọ̀rá oúnjẹ tí ó fẹ́.
Ṣùgbọ́n ìwọ kún fún ìdájọ́ àwọn búburú;
ìdájọ́ àti òtítọ́ dì ọ́ mú.
Nítorí ìbínú ń bẹ, ṣọ́ra kí òtítọ́ rẹ máa bá a tàn ọ;
láti jẹ́ kí títóbi rẹ mú ọ ṣìnà.
Ọrọ̀ rẹ pọ̀ tó, tí wàhálà kì yóò fi dé bá ọ bí?
Tàbí ipa agbára rẹ?
Má ṣe ìfẹ́ òru, nígbà tí a ń ké
àwọn orílẹ̀-èdè kúrò ní ipò wọn.
Máa ṣọ́ra kí ìwọ ki ó má yí ara rẹ̀ padà sí búburú,
nítorí èyí tí ìwọ rò pé ó dára jù ìpọ́njú lọ.
“Kíyèsi i, Ọlọ́run ni gbéga nípa agbára rẹ̀;
ta ni jẹ́ olùkọ́ni bí rẹ̀?
Ta ni ó là ọ̀nà iṣẹ́ rẹ̀ sílẹ̀ fún un,
tàbí ta ni ó lè wí pé ìwọ ti ń ṣe àìṣedéédéé?
Rántí kí ìwọ kí ó gbé iṣẹ́ rẹ̀ ga,
ti ènìyàn ni yín nínú orin.
Olúkúlùkù ènìyàn a máa rí i;
ẹni ikú a máa wò ó ní òkèrè.
Kíyèsi i, Ọlọ́run tóbi, àwa kò sì mọ̀ bí ó ti ní òye tó,
bẹ́ẹ̀ ni a kò lè wádìí iye ọdún rẹ̀ rí.
“Nítorí pé òun ni ó fa ìkán omi òjò sílẹ̀,
kí wọn kí ó kán bí òjò ní ìkùùkuu rẹ̀,
tí àwọsánmọ̀ ń rọ̀ ìrì rẹ̀ sílẹ̀,
tí ó sì fi ń sẹ̀ lọ́pọ̀lọ́pọ̀ lórí ènìyàn.
Pẹ̀lúpẹ̀lú ǹjẹ́ ẹnikẹ́ni lè ní ìmọ̀ ìtànká àwọsánmọ̀,
tàbí ariwo àrá láti àgọ́ rẹ̀?
Kíyèsi i, ó tan ìmọ́lẹ̀ yí ara rẹ̀ ká
ó sì bo ìsàlẹ̀ òkun mọ́lẹ̀.
Nítorí pé nípa wọn ní ń ṣe dájọ́ àwọn orílẹ̀-èdè ènìyàn;
ó sí ń pèsè oúnjẹ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀.
Ó fi ìmọ́lẹ̀ bo ọwọ́ rẹ̀ méjèèjì
ó sì rán an sí ẹni olódì.
Ariwo àrá rẹ̀ fi ìjì hàn ní;
ọ̀wọ́ ẹran pẹ̀lú wí pé, ó súnmọ́ etílé!
Ọlọ́run kì í pọ́n ni lójú láìnídìí
“Àyà sì fò mi sí èyí pẹ̀lú,
ó sì kúrò ní ipò rẹ̀.
Fetísílẹ̀! Fetísílẹ̀, kí ẹ sì gbọ́ ìró ohùn rẹ̀,
àti èyí tí ó ti ẹnu rẹ̀ jáde wá.
Ó ṣe ìlànà rẹ̀ ní ìsàlẹ̀ ọ̀run gbogbo,
mọ̀nàmọ́ná rẹ̀ ni ó sì jọ̀wọ́ rẹ̀ lọ́wọ́ dé òpin ilẹ̀ ayé.
Lẹ́yìn mọ̀nàmọ́ná ohùn kan fọ̀ ramúramù;
ó sì fi ohùn ọláńlá rẹ̀ sán àrá.
Òhun kì yóò sì dá àrá dúró,
nígbà tí ó bá ń gbọ́ ohùn rẹ̀.
Ọlọ́run fi ohùn rẹ̀ sán àrá ní ọ̀nà ìyanu;
ohùn ńlá ńlá ni í ṣe tí àwa kò le mọ̀.
Nítorí tí ó wí fún yìnyín pé, ‘Ìwọ rọ̀ sílẹ̀ ayé,’
àti pẹ̀lú fún ọwọ́ òjò, ‘Fún òjò ńlá agbára rẹ̀.’
Ó fi èdìdì di ọwọ́ gbogbo ènìyàn kí gbogbo wọn kí ó lè mọ iṣẹ́ rẹ̀,
ó sì tún dá olúkúlùkù ènìyàn dúró lẹ́nu iṣẹ́ rẹ̀.
Nígbà náà ní àwọn ẹranko wọ inú ihò lọ,
wọn a sì wà ni ipò wọn.
Láti ìhà gúúsù ni ìjì àjàyíká tí jáde wá,
àti òtútù láti inú afẹ́fẹ́ ti tú àwọsánmọ̀ ká.
Nípa ẹ̀mí Ọlọ́run a fi ìdí omi fún ni,
ibú omi á sì súnkì.
Pẹ̀lúpẹ̀lú ó fi omi púpọ̀ mú àwọsánmọ̀ wúwo,
a sì tú àwọsánmọ̀ ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ ká ara wọn.
Àwọn wọ̀nyí yí káàkiri nípa ìlànà rẹ̀,
kí wọn kí ó lè ṣe ohunkóhun
tí ó pàṣẹ fún wọn lórí ilẹ̀ ayé.
Ó mú àwọsánmọ̀ wá, ìbá ṣe fún ìkìlọ̀,
tàbí omi wá sí ayé láti fi ìfẹ́ rẹ̀ hàn.
“Jobu, dẹtí sílẹ̀ sí èyí;
dúró jẹ́ẹ́ kí o sì ro iṣẹ́ ìyanu Ọlọ́run.
Ṣe ìwọ mọ àkókò ìgbà tí Ọlọ́run ṣe wọ́n lọ́jọ̀,
tí ó sì mú ìmọ́lẹ̀ àwọsánmọ̀ rẹ̀ dán?
Ṣé ìwọ mọ ìgbà tí àwọsánmọ̀ í fò lọ,
iṣẹ́ ìyanu ẹni tí ó pé ní ìmọ̀?
Ìwọ ẹni ti aṣọ rẹ̀ ti máa n gbóná,
nígbà tí ó fi atẹ́gùn ìhà gúúsù mú ayé dákẹ́.
Ìwọ ha ba tẹ́ pẹpẹ ojú ọ̀run, tí ó dúró ṣinṣin,
tí ó sì dàbí dígí tí ó yọ̀ dà?
“Kọ́ wa ní èyí tí a lè wí fún un;
nítorí pé àwa kò le wádìí ọ̀rọ̀ náà nítorí òkùnkùn wa.
A ó ha wí fún un pé, èmi fẹ́ sọ̀rọ̀?
Tàbí ẹnìkan lè wí pé, ìfẹ́ mi ni pé kí a gbé mi mì?
Síbẹ̀ nísinsin yìí ènìyàn kò rí
oòrùn tí ń dán nínú àwọsánmọ̀,
ṣùgbọ́n afẹ́fẹ́ ń kọjá, a sì gbá wọn mọ́.
Wúrà dídán ti inú ìhà àríwá jáde wá;
lọ́dọ̀ Ọlọ́run ni ọláńlá ẹ̀rù ńlá wa.
Nípa ti Olódùmarè àwa kò le wádìí rẹ̀, ó rékọjá ní ipá;
nínú ìdájọ́ àti títí bi òun kì í ba ẹ̀tọ́ àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ òtítọ́ jẹ́.
Nítorí náà ènìyàn ha máa bẹ̀rù rẹ̀,
òun kì í ṣe ojú sájú ẹnikẹ́ni tí ó gbọ́n ní ayé?”
Ọlọ́run pe Jobu níjà
Nígbà náà ní Olúwa dá Jobu lóhùn láti inú ìjì àjàyíká wá, ó sì wí pé,
“Ta ni èyí tí ń fi ọ̀rọ̀ àìlóye
láti fi ṣókùnkùn bo ìmọ̀ mi?
Di ẹ̀gbẹ́ ara rẹ ní àmùrè bí ọkùnrin nísinsin yìí,
nítorí pé èmi yóò béèrè lọ́wọ́ rẹ
kí o sì dá mi lóhùn.
“Níbo ni ìwọ wà nígbà tí mo fi ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀?
Wí bí ìwọ bá mòye.
Ta ni ó fi ìwọ̀n rẹ lélẹ̀, dájú bí ìwọ bá mọ̀ ọ́n?
Tàbí ta ni ó ta okùn wíwọ̀n sórí rẹ?
Lórí ibo ni a gbé kan ìpìlẹ̀ rẹ̀ mọ́,
tàbí ta ni ó fi òkúta igun rẹ̀ lélẹ̀,
nígbà náà àwọn ìràwọ̀ òwúrọ̀ jùmọ̀ kọrin pọ̀,
tí gbogbo àwọn ọmọ Ọlọ́run hó ìhó ayọ̀?
“Tàbí ta ni ó fi ìlẹ̀kùn sé omi òkun mọ́,
nígbà tí ó ya padà bí ẹni pé ó ti inú jáde wá.
Nígbà tí mo fi àwọsánmọ̀ ṣe aṣọ rẹ̀,
tí mo sì fi òkùnkùn biribiri ṣe ọ̀já ìgbà inú rẹ̀.
Nígbà tí mo ti pàṣẹ ìpinnu mi fún un,
tí mo sì ṣe bèbè àti ìlẹ̀kùn.
Tí mo sì wí pé níhìn-ín ni ìwọ ó dé, kí o má sì rékọjá,
níhìn-ín sì ni ìgbéraga rẹ yóò gbé dúró mọ?
“Ìwọ pàṣẹ fún òwúrọ̀ láti ìgbà ọjọ́ rẹ̀ wá,
ìwọ sì mú ìlà-oòrùn mọ ipò rẹ̀,
í ó lè di òpin ilẹ̀ ayé mú,
ki a lè gbọ́n àwọn ènìyàn búburú kúrò nínú rẹ̀?
Kí ó yí padà bí amọ̀ fún èdìdì amọ̀,
kí gbogbo rẹ̀ kí ó sì fi ara rẹ̀ hàn bí ẹni pé nínú aṣọ ìgúnwà.
A sì fa ìmọ́lẹ̀ wọn sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ ènìyàn búburú,
apá gíga ni a sì ṣẹ́.
“Ìwọ ha wọ inú ìsun òkun lọ rí bí?
Ìwọ sì rìn lórí ìsàlẹ̀ ibú ńlá?
A ha ṣílẹ̀kùn ikú sílẹ̀ fún ọ rí bí,
ìwọ sì rí ìlẹ̀kùn òjìji òkú?
Ìwọ mòye ìbú ayé bí?
Sọ bí ìwọ bá mọ gbogbo èyí.
“Ọ̀nà wo ni ìmọ́lẹ̀ ń gbé?
Bí ó ṣe ti òkùnkùn, níbo ni ipò rẹ̀,
tí ìwọ í fi mú un lọ sí ibi àlá rẹ̀,
tí ìwọ ó sì le mọ ipa ọ̀nà lọ sínú ilé rẹ̀?
Ìwọ mọ èyí, nítorí nígbà náà ni a bí ọ?
Iye ọjọ́ rẹ sì pọ̀.
“Ìwọ ha wọ inú ìṣúra ìdì òjò lọ rí bí,
ìwọ sì rí ilé ìṣúra yìnyín rí,
tí mo ti fi pamọ́ de ìgbà ìyọnu,
dé ọjọ́ ogun àti ìjà?
Ọ̀nà wo ni ó lọ sí ibi tí ìmọ́lẹ̀ fi ń la,
tí afẹ́fẹ́ ìlà-oòrùn ń tàn káàkiri lórí ilẹ̀ ayé?
Ta ni ó la ipadò fún ẹ̀kún omi,
àti ọ̀nà fún mọ̀nàmọ́ná àrá,
láti mú u rọ̀jò sórí ayé níbi tí ènìyàn kò sí,
ní aginjù níbi tí ènìyàn kò sí;
láti mú ilẹ̀ tútù, ijù àti aláìro
láti mú àṣẹ̀ṣẹ̀yọ ewéko rú jáde?
Òjò ha ní baba bí?
Tàbí ta ni o bí ìkún ìṣe ìrì?
Láti inú ta ni ìdì omi ti jáde wá?
Ta ni ó bí ìrì dídì ọ̀run?
Nígbà tí omi di líle bí òkúta,
nígbà tí ojú ibú ńlá sì dìpọ̀.
“Ìwọ ha le fi ọ̀já de àwọn ìràwọ̀ Pleiadesi dáradára?
Tàbí ìwọ le tún di ìràwọ̀ Orioni?
Ìwọ le mú àwọn àmì méjìlá ìràwọ̀ Masaroti jáde wá nígbà àkókò wọn?
Tàbí ìwọ le ṣe amọ̀nà Beari pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀?
Ǹjẹ́ ìwọ mọ ìlànà ọ̀run?
Ìwọ le fi ìjọba Ọlọ́run lélẹ̀ lórí ayé?
“Ìwọ le gbé ohùn rẹ sókè dé àwọsánmọ̀
kí ọ̀pọ̀lọpọ̀ omi kí ó lè bò ọ́?
Ìwọ le rán mọ̀nàmọ́ná kí wọn kí ó le lọ,
ní ọ̀nà wọn kí wọn kí ó sì wí fún wọn pé, ‘Àwa nìyí’?
Ta ni ó fi ọgbọ́n pamọ́ sí odò ikùn
tàbí tí ó fi òye sínú àyà?
Ta ni ó fi ọgbọ́n ka iye àwọsánmọ̀?
Ta ni ó sì mú ìgò ọ̀run dà jáde,
nígbà tí erùpẹ̀ di líle,
àti ògúlùtu dìpọ̀?
“Ìwọ ha dẹ ọdẹ fún abo kìnnìún bí?
Ìwọ ó sì tẹ ebi ẹgbọrọ kìnnìún lọ́rùn,
nígbà tí wọ́n bá mọ́lẹ̀ nínú ihò
tí wọ́n sì ba ní ibùba de ohun ọdẹ?
Ta ni ó ń pèsè ohun jíjẹ fún ẹyẹ ìwò,
nígbà tí àwọn ọmọ rẹ ń ké pe Ọlọ́run,
tí wọ́n sì máa ń fò kiri nítorí àìní ohun jíjẹ?
Agbára Ọlọ́run
“Ìwọ mọ àkókò ìgbà tí àwọn ewúrẹ́ orí àpáta ń bímọ?
Ìwọ sì lè kíyèsi ìgbà tí abo àgbọ̀nrín ń bímọ?
Ìwọ lè ka iye òṣùpá tí wọn ń pé,
ìwọ sì mọ àkókò ìgbà tí wọn ń bímọ.
Wọ́n tẹ ara wọn ba, wọ́n bímọ,
wọ́n sì mú ìkáàánú wọn jáde.
Àwọn ọmọ wọn rí dáradára, wọ́n dàgbà nínú ọ̀dàn;
wọ́n jáde lọ, wọn kò sì tún padà wá sọ́dọ̀ wọn.
“Ta ni ó jọ̀wọ́ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ oko lọ́wọ́?
Tàbí ta ní ó tú ìdè kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ igbó,
èyí tí mo fi aginjù ṣe ilé fún,
àti ilẹ̀ iyọ̀ ní ibùgbé rẹ̀.
Ó rẹ́rìn-ín sí ariwo ìlú,
bẹ́ẹ̀ ni òun kò sì gbọ́ igbe darandaran.
Orí àtòlé òkè ńlá ni ibùjẹ oko rẹ̀,
òun a sì máa wá ewé tútù gbogbo rí.
“Àgbáǹréré ha jẹ́ sìn ọ́ bí?
Tàbí ó jẹ́ dúró ní ibùjẹ ẹran rẹ ní òru?
Ìwọ le fi òkun tata de àgbáǹréré nínú aporo?
Tàbí ó jẹ́ máa fa ìtulẹ̀ nínú aporo oko tọ̀ ọ́ lẹ́yìn?
Ìwọ ó gbẹ́kẹ̀lé e nítorí agbára rẹ̀ pọ̀?
Ìwọ ó sì fi iṣẹ́ rẹ lé e lọ́wọ́?
Ìwọ le gbẹ́kẹ̀lé pé, yóò mú èso oko rẹ̀ wá sílé,
àti pé yóò sì kó ọ jọ sínú àká rẹ?
“Ìwọ ni yóò ha fi ìyẹ́ dáradára fún ọ̀kín bí,
tàbí ìyẹ́ àti ìhùhù bo ògòǹgò?
Ó yé ẹ̀yìn rẹ̀ sílẹ̀ lórí ilẹ̀,
a sì mú wọn gbóná nínú ekuru;
tí ó sì gbàgbé pé, ẹsẹ̀ lè tẹ̀ wọ́n fọ́,
tàbí pé ẹranko igbó lè tẹ̀ wọ́n fọ́.
Kò ní àánú sí àwọn ọmọ rẹ̀ bí ẹni pé wọn kì í ṣe tirẹ̀;
asán ni iṣẹ́ rẹ̀ láìní ìbẹ̀rù;
nítorí pé Ọlọ́run kò fún un ní ọgbọ́n,
bẹ́ẹ̀ ni kò sì fi ìpín òye fún un.
Nígbà tí ó gbé ara sókè,
ó gan ẹṣin àti ẹlẹ́ṣin.
“Ìwọ ni ó fi agbára fún ẹṣin bí,
tàbí ṣé ìwọ ni ó fi gọ̀gọ̀ wọ ọrùn rẹ̀ ní aṣọ?
Ìwọ le mú fò sókè bí ẹlẹ́ǹgà?
Ògo èémí imú rẹ ní ẹ̀rù ńlá.
Ó fi ẹsẹ̀ halẹ̀ nínú àfonífojì, ó sì yọ̀ nínú agbára rẹ̀;
ó lọ jáde láti pàdé àwọn ìhámọ́ra ogun.
Ó fi ojú kékeré wo ẹ̀rù, àyà kò sì fò ó;
bẹ́ẹ̀ ni kì í sì í padà sẹ́yìn kúrò lọ́wọ́ idà.
Lọ́dọ̀ rẹ ni apó-ọfà ń mì pẹkẹpẹkẹ,
àti ọ̀kọ̀ dídán àti àpáta.
Ó fi kíkorò ojú àti ìbínú ńlá gbé ilé mi,
bẹ́ẹ̀ ni òun kò sì gbà á gbọ́ pé, ìró ìpè ni.
Ó wí nígbà ìpè pé, Háà! Háà!
Ó sì gbóhùn ogun lókèèrè réré,
igbe àwọn balógun àti ìhó ayọ̀ ogun wọn.
“Àwòdì ha máa ti ipa ọgbọ́n rẹ̀ fò sókè,
tí ó sì na ìyẹ́ apá rẹ̀ sí ìhà gúúsù?
Idì ha máa fi àṣẹ rẹ̀ fò sókè,
kí ó sì lọ tẹ́ ìtẹ́ rẹ̀ sí òkè gíga?
Ó ń gbé, ó sì ń wò ní orí àpáta,
lórí pàlàpálá òkúta àti ibi orí òkè.
Láti ibẹ̀ lọ ni ó ti ń wá oúnjẹ kiri,
ojú rẹ̀ sì ríran rí òkè réré.
Àwọn ọmọ rẹ̀ pẹ̀lú a máa mu ẹ̀jẹ̀,
níbi tí òkú bá gbé wà, níbẹ̀ ni òun wà pẹ̀lú.”
Jobu rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀
Olúwa dá Jobu lóhùn sí pẹ̀lú, ó sì wí pé,
“Ẹni tí ń bá Olódùmarè wíjọ́ yóò ha kọ ní ẹ̀kọ́?
Ẹni tí ń bá Ọlọ́run wí jẹ́ kí ó dáhùn!”
Nígbà náà ni Jobu dá Olúwa lóhùn wá ó sì wí pé,
“Kíyèsi i, ẹ̀gbin ni èmi—ohun kí ni èmi ó dà?
Èmi ó fi ọwọ́ mi le ẹnu mi.
Ẹ̀ẹ̀kan ní mo sọ̀rọ̀, ṣùgbọ́n èmi kì yóò tún sọ mọ́;
lẹ́ẹ̀kejì ni, èmi kò sì le ṣe é mọ́.”
Nígbà náà ní Olúwa dá Jobu lóhùn láti inú ìjì àyíká wá, ó sì wí pé,
“Di àmùrè gírí ní ẹgbẹ́ rẹ bí ọkùnrin,
èmi ó bi ọ léèrè,
kí ìwọ kí ó sì dá mi lóhùn.
“Ìwọ ha fẹ́ mú ìdájọ́ mi di asán?
Ìwọ ó sì dá mi lẹ́bi, kí ìwọ lè ṣe olódodo.
Ìwọ ni apá bí Ọlọ́run
tàbí ìwọ lè fi ohùn sán àrá bí òun?
Fi ọláńlá àti ọlá ìtayọ rẹ̀ ṣe ara rẹ ní ọ̀ṣọ́,
tí ó sì fi ògo àti títóbi ọ̀ṣọ́ bo ara ní aṣọ.
Mú ìrunú ìbínú rẹ jáde;
kíyèsí gbogbo ìwà ìgbéraga rẹ kí o sì rẹ̀ ẹ́ sílẹ̀.
Wo gbogbo ìwà ìgbéraga, ènìyàn kí o sì rẹ ẹ sílẹ̀
kí o sì tẹ ènìyàn búburú mọ́lẹ̀ ní ipò wọn.
Sin gbogbo wọn papọ̀ nínú erùpẹ̀,
kí o sì di ojú ìkọ̀kọ̀ wọn ní isà òkú.
Nígbà náà ní èmi ó yìn ọ́ pé,
ọwọ́ ọ̀tún ara rẹ lè gbà ọ́ là.
“Ǹjẹ́ nísinsin yìí kíyèsi Behemoti,
tí mo dá pẹ̀lú rẹ,
òun a máa jẹ koríko bí ọ̀dá màlúù.
Wò o nísinsin yìí, agbára rẹ wà ní ẹ̀gbẹ́ rẹ,
àti ipa rẹ nínú ìṣàn ìkún rẹ.
Òun a máa jù ìrù rẹ̀ bí i igi kedari,
iṣan itan rẹ̀ dìjọ pọ̀.
Egungun rẹ̀ ní ògùṣọ̀ idẹ,
Egungun rẹ̀ dàbí ọ̀pá irin.
Òun ni olórí nínú àwọn iṣẹ́ Ọlọ́run;
síbẹ̀ Ẹlẹ́dàá rẹ̀ fi idà rẹ̀ lé e lọ́wọ́.
Nítòótọ́ òkè ńlá ńlá ní i mu ohun jíjẹ fún un wá,
níbi tí gbogbo ẹranko igbó máa ṣiré ní ẹ̀gbẹ́ ibẹ̀.
Ó dùbúlẹ̀ lábẹ́ igi lótusì,
lábẹ́ eèsún àti ẹrẹ̀.
Igi lótusì síji wọn bò o;
igi arọrọ odò yí i káàkiri.
Kíyèsi i, odò ńlá sàn jọjọ, òun kò sálọ;
ó wà láìléwu bí ó bá ṣe pé odò Jordani ti ṣàn lọ sí ẹnu rẹ̀.
Ẹnìkan ha lè mú un ní ojú rẹ̀,
tàbí dẹkùn fún tàbí a máa fi ọ̀kọ̀ gún imú rẹ̀?
Ọlọ́run ń tẹ̀síwájú láti pe Jobu níjà
“Ǹjẹ́ ìwọ le è fi ìwọ̀ fa Lefitani jáde?
Tàbí ìwọ lè fi okùn so ahọ́n rẹ̀ mọ́lẹ̀?
Ìwọ lè fi okùn bọ̀ ọ́ ní í mú,
tàbí fi ìwọ̀ ẹ̀gún gun ní ẹ̀rẹ̀kẹ́?
Òun ha jẹ́ bẹ ẹ̀bẹ̀ fún àánú lọ́dọ̀
rẹ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ bí òun ha bá ọ sọ̀rọ̀ pẹ̀lẹ́?
Òun ha bá ọ dá májẹ̀mú bí?
Ìwọ ó ha máa mú ṣe ẹrú láéláé bí?
Ìwọ ha lè ba sáré bí ẹni pé ẹyẹ ni,
tàbí ìwọ ó dè é fún àwọn ọmọbìnrin ìránṣẹ́ rẹ̀?
Ẹgbẹ́ àwọn apẹja yóò ha máa tà á bí?
Wọn ó ha pín láàrín àwọn oníṣòwò?
Ìwọ ha lè fi ọ̀kọ̀-irin gun awọ rẹ̀,
tàbí orí rẹ̀ pẹ̀lú ọ̀kọ̀ ìpẹja.
Fi ọwọ́ rẹ lé e lára,
ìwọ ó rántí ìjà náà, ìwọ kì yóò sì ṣe bẹ́ẹ̀ mọ́.
Kíyèsi, ìgbìyànjú láti mú un ní asán;
ní kìkì ìrí rẹ̀ ara kì yóò ha rọ̀ ọ́ wẹ̀sì?
Kò sí ẹni aláyà lílé tí ó lè ru sókè.
Ǹjẹ́ ta ni ó lè dúró níwájú mi.
Ta ni ó kọ́kọ́ ṣe fún mi, tí èmi ìbá fi san án fún un?
Ohunkóhun ti ń bẹ lábẹ́ ọ̀run gbogbo, tèmi ni.
“Èmi kì yóò fi ẹ̀yà ara Lefitani,
tàbí ipá rẹ, tàbí ìhámọ́ra rẹ tí ó ní ẹwà pamọ́.
Ta ni yóò lè rídìí aṣọ àpáta rẹ̀?
Tàbí ta ni ó lè súnmọ́ ọ̀nà méjì eyín rẹ̀?
Ta ni ó lè ṣí ìlẹ̀kùn iwájú rẹ̀?
Àyíká ẹ̀yin rẹ ni ìbẹ̀rù ńlá.
Ìpẹ́ lílé ní ìgbéraga rẹ̀;
ó pàdé pọ̀ tímọ́tímọ́ bí àmì èdìdì.
Èkínní fi ara mọ́ èkejì tó bẹ́ẹ̀
tí afẹ́fẹ́ kò lè wọ àárín wọn.
Èkínní fi ara mọ́ èkejì rẹ̀;
wọ́n lè wọ́n pọ̀ tí a kò lè mọ̀ wọ́n.
Nípa sí sin rẹ̀ ìmọ́lẹ̀ á mọ́,
ojú rẹ̀ a sì dàbí ìpéǹpéjú òwúrọ̀.
Láti ẹnu rẹ ni ọ̀wọ́-iná ti jáde wá,
ìpẹ́pẹ́ iná a sì ta jáde.
Láti ihò imú rẹ ni èéfín ti jáde wá,
bí ẹni pé láti inú ìkòkò tí a fẹ́ iná ìfèéfèé lábẹ́ rẹ̀.
Èémí rẹ̀ tiná bọ ẹ̀yin iná,
ọ̀wọ́-iná sì ti ẹnu rẹ̀ jáde.
Ní ọrùn rẹ̀ ní agbára kù sí,
àti ìbànújẹ́ àyà sì padà di ayọ̀ níwájú rẹ̀.
Jabajaba ẹran rẹ̀ dìjọ pọ̀,
wọ́n múra gírí fún ara wọn, a kò lè sí wọn ní ipò.
Àyà rẹ̀ dúró gbagidi bí òkúta,
àní, ó le bi ìyá ọlọ.
Nígbà tí ó bá gbé ara rẹ̀ sókè, àwọn alágbára bẹ̀rù;
nítorí ìbẹ̀rù ńlá, wọ́n dààmú.
Ọ̀kọ̀ tàbí idà, tàbí ọfà,
ẹni tí ó ṣá a kò lè rán an.
Ó ká irin sí ibi koríko gbígbẹ
àti idẹ si bi igi híhù.
Ọfà kò lè mú un sá;
òkúta kànnakánná lọ́dọ̀ rẹ̀ dàbí àgékù koríko.
Ó ka ẹṣin sí bí àgékù ìdì koríko;
ó rẹ́rìn-ín sí mímì ọ̀kọ̀.
Òkúta mímú ń bẹ nísàlẹ̀ abẹ́ rẹ̀,
ó sì tẹ́ ohun mímú ṣóńṣó sórí ẹrẹ̀.
Ó mú ibú omi hó bí ìkòkò;
ó sọ̀ agbami òkun dàbí kólòbó ìkunra.
Ó mú ipa ọ̀nà tan lẹ́yìn rẹ̀;
ènìyàn a máa ka ibú sí ewú arúgbó.
Lórí ilẹ̀ ayé kò sí ẹni tí ó dàbí rẹ̀,
tí a dá láìní ìbẹ̀rù.
Ó bojú wo ohun gíga gbogbo,
ó sì nìkan jásí ọba lórí gbogbo àwọn ọmọ ìgbéraga.”
Ìrònúpìwàdà Jobu
Nígbà náà ní Jobu dá Olúwa lóhùn, ó sì wí pé,
“Èmi mọ̀ pé, ìwọ lè e ṣe ohun gbogbo,
àti pé, kò si ìrò inú tí a lè fa sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ rẹ.
Ìwọ béèrè, ta ni ẹni tí ń fi ìgbìmọ̀ pamọ́ láìní ìmọ̀?
Nítorí náà ní èmi ṣe ń sọ èyí tí èmi kò mọ̀,
ohun tí ó ṣe ìyanu jọjọ níwájú mi, ti èmi kò mòye.
“Ìwọ wí pé, ‘Gbọ́ tèmi báyìí,
èmi ó sì sọ; èmi ó béèrè lọ́wọ́ rẹ,
ìwọ yóò sì dá mi lóhùn.’
Etí mi sì ti gbọ́ nípa rẹ,
ṣùgbọ́n nísinsin yìí ojú mi ti rí ọ.
Ǹjẹ́ nítorí náà èmi kórìíra ara mi,
mo sì ronúpìwàdà nínú ekuru àti eérú.”
Ọlọ́run bùkún Jobu
Bẹ́ẹ̀ ó sì rí, lẹ́yìn ìgbà tí Olúwa ti sọ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí fún Jobu, Olúwa sì wí fún Elifasi, ará Temani pé, mo bínú sí ọ, àti sí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ méjèèjì, nítorí pé ẹ̀yin kò sọ̀rọ̀, ní ti èmi, ohun tí ó tọ́, bí Jobu ìránṣẹ́ mi ti sọ. Nítorí náà, ẹ mú akọ ẹgbọrọ màlúù méje, àti àgbò méje, kí ẹ sì tọ̀ Jobu ìránṣẹ́ mi lọ, kí ẹ sì fi rú ẹbọ sísun fún ara yín; Jobu ìránṣẹ́ mi yóò sì gbàdúrà fún yin; nítorí pé àdúrà rẹ̀ ní èmi yóò gbà; kí èmi kí ó má ba ṣe si yín bí ìṣìnà yín, ní ti pé ẹ̀yin kò sọ̀rọ̀ ohun tí ó tọ́ sí mi bi Jobu ìránṣẹ́ mi ti ṣe. Bẹ́ẹ̀ ní Elifasi, ara Temani, àti Bilidadi, ará Ṣuhi, àti Sofari, ará Naama lọ, wọ́n sì ṣe gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún wọn. Olúwa sì gbọ́ àdúrà Jobu.
Olúwa sì yí ìgbèkùn Jobu padà, nígbà tí ó gbàdúrà fún àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀; Olúwa sì bùsi ohun gbogbo ti Jobu ní rí ní ìṣẹ́po méjì ohun tí ó ní tẹ́lẹ̀ rí. Nígbà náà ní gbogbo àwọn arákùnrin rẹ̀, àti gbogbo àwọn arábìnrin rẹ̀, àti gbogbo àwọn tí ó ti ṣe ojúlùmọ̀ rẹ̀ rí; wọ́n bá a jẹun nínú ilé rẹ̀. Wọ́n sì ṣe ìdárò rẹ̀, wọ́n sì ṣìpẹ̀ fún un nítorí ibi gbogbo tí Olúwa ti mú bá a. Olúkúlùkù ènìyàn pẹ̀lú sì fún un ní ẹyọ owó kọ̀ọ̀kan àti olúkúlùkù ni òrùka wúrà etí kọ̀ọ̀kan.
Bẹ́ẹ̀ ni Olúwa bùkún ìgbẹ̀yìn Jobu ju ìṣáájú rẹ̀ lọ; ẹgbàá méje (14,000) àgùntàn, ẹgbẹ̀rún mẹ́fà (6,000) ìbákasẹ, àti ẹgbẹ̀rún (1,000) àjàgà ọ̀dá màlúù, àti ẹgbẹ̀rún (1,000) abo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́. Ó sì ní ọmọkùnrin méje àti ọmọbìnrin mẹ́ta. Ó sì sọ orúkọ àkọ́bí ní Jemima, àti orúkọ èkejì ni Kesia àti orúkọ ẹ̀kẹta ní Kereni-Happuki. Àti ní gbogbo ilẹ̀ náà, a kò rí obìnrin tí ó ní ẹwà bí ọmọ Jobu; baba wọ́n sì pínlẹ̀ fún wọn nínú àwọn arákùnrin wọn.
Lẹ́yìn èyí Jobu wà ní ayé ní ogóje ọdún, ó sì rí àwọn ọmọ rẹ̀ ọkùnrin àti ọmọ ọmọ rẹ̀ ọkùnrin, àní ìran mẹ́rin. Bẹ́ẹ̀ ni Jobu kú, ó gbó, ó sì kún fún ọjọ́ púpọ̀.