- Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible 2017 Onidajọ Ìwé àwọn Onidajọ Onidajọ On Ìwé àwọn Onidajọ Orílẹ̀-èdè Israẹli bá àwọn ará Kenaani tókù jagun Lẹ́yìn ikú Joṣua, ni orílẹ̀-èdè Israẹli béèrè lọ́wọ́ Olúwa pé, “Èwo nínú ẹ̀yà wa ni yóò kọ́kọ́ gòkè lọ bá àwọn ará Kenaani jagun fún wa?” Olúwa sì dáhùn pé, “Juda ni yóò lọ; nítorí pé èmi ti fi ilẹ̀ náà lé e lọ́wọ́.” Nígbà náà ni àwọn olórí ẹ̀yà Juda béèrè ìrànlọ́wọ́ láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Simeoni arákùnrin wọn pé, “Ẹ wá bá wa gòkè lọ sí ilẹ̀ tí a ti fi fún wa, láti bá àwọn ará Kenaani jà kí a sì lé wọn kúrò, àwa pẹ̀lú yóò sì bá a yín lọ sí ilẹ̀ tiyín bákan náà láti ràn yín lọ́wọ́.” Àwọn ọmọ-ogun Simeoni sì bá àwọn ọmọ-ogun Juda lọ. Nígbà tí àwọn ọmọ-ogun Juda sì kọlu wọ́n, Olúwa sì fi àwọn ará Kenaani àti àwọn ará Peresi lé wọn lọ́wọ́, wọ́n sì pa ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) ọkùnrin ní Beseki. Ní Beseki ni wọ́n ti rí Adoni-Beseki, wọ́n sì bá a jagun, wọ́n sì ṣẹ́gun àwọn ará Kenaani àti Peresi. Ọba Adoni-Beseki sá àsálà, ṣùgbọ́n ogun Israẹli lépa rẹ̀ wọ́n sì bá a, wọ́n sì gé àwọn àtàǹpàkò ọwọ́ àti ẹsẹ̀ rẹ̀. Nígbà náà ni Adoni-Beseki wí pé, “Àádọ́rin ọba ni èmi ti gé àtàǹpàkò wọn tí wọ́n sì ń ṣa èérún oúnjẹ jẹ lábẹ́ tábìlì mi. Báyìí Ọlọ́run ti san án fún mi gẹ́gẹ́ bí ohun tí mo ṣe sí wọn.” Wọ́n sì mú un wá sí Jerusalẹmu, ó sì kú síbẹ̀. Àwọn ológun Juda sì ṣẹ́gun Jerusalẹmu, wọ́n sì kó o, wọ́n sì fi ojú idà kọlù ú, wọ́n sì dáná sun ìlú náà. Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí ni àwọn ogun Juda sọ̀kalẹ̀ lọ láti bá àwọn ará Kenaani tí ń gbé ní àwọn ìlú orí òkè ní gúúsù àti ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ òkè lápá ìwọ̀-oòrùn Juda jagun. Ogun Juda sì tún ṣígun tọ ará Kenaani tí ń gbé Hebroni (tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Kiriati-Arba) ó sì ṣẹ́gun Ṣeṣai, Ahimani àti Talmai. Láti ibẹ̀, wọ́n sì wọ́de ogun láti ibẹ̀ lọ bá àwọn ènìyàn tí ń gbé ní Debiri (tí à ń pè ní Kiriati-Seferi nígbà kan rí). Kalebu sì wí pé, “Èmi yóò fi ọmọbìnrin mi Aksa fún ọkùnrin tí ó bá kọlu Kiriati-Seferi, tí ó sì gbà á ní ìgbéyàwó.” Otnieli ọmọ Kenasi, àbúrò Kalebu sì gbà á, báyìí ni Kalebu sì fi ọmọbìnrin rẹ̀ Aksa fún un ní ìyàwó. Ní ọjọ́ kan, nígbà tí Aksa lọ sí ọ̀dọ̀ Otnieli, ó rọ̀ ọ́ kí ó béèrè ilẹ̀ oko lọ́wọ́ baba rẹ̀. Nígbà náà ni Aksa sọ̀kalẹ̀ ní orí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀, Kalebu sì béèrè pé, “Kí ni kí èmi ṣe fún ọ?” Aksa sì dáhùn pé, “Mo ń fẹ́ kí o ṣe ojúrere kan fún mi, nígbà ti o ti fún mi ní ilẹ̀ ní gúúsù, fún mi ní ìsun omi náà pẹ̀lú.” Kalebu sì fún un ní ìsun òkè àti ìsun ìsàlẹ̀. Àwọn ìran Keni tí wọ́n jẹ́ àna Mose bá àwọn ọmọ Juda gòkè láti ìlú ọ̀pẹ lọ sí aginjù Juda ní gúúsù Aradi; wọ́n sì lọ, orílẹ̀-èdè méjèèjì sì jùmọ̀ ń gbé pọ̀ láti ìgbà náà. Ó sì ṣe, àwọn ológun Juda tẹ̀lé àwọn ológun Simeoni arákùnrin wọn, wọ́n sì lọ bá àwọn ará Kenaani tí ń gbé Sefati jagun, wọ́n sì run ìlú náà pátápátá, ní báyìí àwa yóò pe ìlú náà ní Horma (Horma èyí tí ń jẹ́ ìparun). Àwọn ogun Juda sì ṣẹ́gun Gasa àti àwọn agbègbè rẹ̀, Aṣkeloni àti Ekroni pẹ̀lú àwọn ìlú tí ó yí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ká. Olúwa sì wà pẹ̀lú ẹ̀yà Juda, wọ́n gba ilẹ̀ òkè, ṣùgbọ́n wọn kò le lé àwọn ènìyàn tí ó wà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀, nítorí wọ́n ní kẹ̀kẹ́ ogun onírin. Gẹ́gẹ́ bí Mose ti ṣèlérí, wọ́n fún Kalebu ní Hebroni, ó sì lé àwọn tí ń gbé ibẹ̀ kúrò; àwọn náà ni ìran àwọn ọmọ Anaki mẹ́ta. Àwọn ẹ̀yà Benjamini ni wọn kò le lé àwọn Jebusi tí wọ́n ń gbé Jerusalẹmu, nítorí náà wọ́n ń gbé àárín àwọn Israẹli títí di òní. Àwọn ẹ̀yà Josẹfu sì bá Beteli jagun, Olúwa síwájú pẹ̀lú wọn. Nígbà tí ẹ̀yà Josẹfu rán àwọn ènìyàn láti lọ yọ́ Beteli wò (orúkọ ìlú náà tẹ́lẹ̀ rí ni Lusi). Àwọn ayọ́lẹ̀wò náà rí ọkùnrin kan tí ń jáde láti inú ìlú náà wá, wọ́n sì wí fún un pé, “Fi ọ̀nà àtiwọ ìlú yìí hàn wá, àwa ó sì dá ẹ̀mí rẹ sí, a ó sì ṣe àánú fún ọ.” Ó sì fi ọ̀nà ìlú náà hàn wọ́n, wọ́n sì fi ojú idà kọlu ìlú náà, ṣùgbọ́n wọ́n dá ọkùnrin náà àti gbogbo ìdílé rẹ̀ si. Ọkùnrin náà sí lọ sí ilẹ̀ àwọn ará Hiti, ó sì tẹ ìlú kan dó, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Lusi, èyí sì ni orúkọ rẹ̀ títí di òní. Ṣùgbọ́n Manase kò lé àwọn ará Beti-Ṣeani àti ìlú rẹ̀ wọ̀n-ọn-nì jáde, tàbí àwọn ará Taanaki àti àwọn ìgbèríko rẹ̀, tàbí àwọn ará Dori àti àwọn ìgbèríko rẹ̀, tàbí àwọn ará Ibleamu àti àwọn ìgbèríko rẹ̀, tàbí àwọn ará Megido àti àwọn ìgbèríko tí ó yí i ká, torí pé àwọn ará Kenaani ti pinnu láti máa gbé ìlú náà. Nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli di alágbára, wọ́n mú àwọn ará Kenaani sìn bí i ẹrú, ṣùgbọ́n wọn kò fi agbára lé wọn jáde kúrò ní ilẹ̀ náà. Efraimu náà kò lé àwọn ará Kenaani tí ó ń gbé Geseri jáde, ṣùgbọ́n àwọn ará Kenaani sì ń gbé láàrín àwọn ẹ̀yà Efraimu. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn Sebuluni kò lé àwọn ará Kenaani tí ń gbé Kitironi jáde tàbí àwọn ará Nahalali, ṣùgbọ́n wọ́n sọ wọ́n di ẹrú. Wọ́n sì ń sin àwọn ará Sebuluni. Bẹ́ẹ̀ ni Aṣeri kò lé àwọn tí ń gbé ní Akko tàbí ní Sidoni tàbí ní Ahlabu tàbí ní Aksibu tàbí ní Helba tàbí ní Afiki tàbí ní Rehobu. Ṣùgbọ́n nítorí àwọn ará Aṣeri ń gbé láàrín àwọn ará Kenaani tí wọ́n ni ilẹ̀ náà. Àwọn ẹ̀yà Naftali pẹ̀lú kò lé àwọn ará Beti-Ṣemeṣi àti Beti-Anati jáde; ṣùgbọ́n àwọn ẹ̀yà Naftali náà ń gbé àárín àwọn ará Kenaani tí ó ti ní ilẹ̀ náà rí, ṣùgbọ́n àwọn tí ń gbé Beti-Ṣemeṣi àti Beti-Anati ń sìn ìsìn tipátipá. Àwọn ará Amori fi agbára dá àwọn ẹ̀yà Dani dúró sí àwọn ìlú orí òkè, wọn kò sì jẹ́ kí wọn sọ̀kalẹ̀ wá sí pẹ̀tẹ́lẹ̀. Àwọn ará Amori ti pinnu láti dúró lórí òkè Heresi àti òkè Aijaloni àti ti Ṣaalbimu, ṣùgbọ́n nígbà tí ẹ̀yà Josẹfu di alágbára wọ́n borí Amori wọ́n sì mú wọn sìn. Ààlà àwọn ará Amori sì bẹ̀rẹ̀ láti ìgòkè Akrabbimu kọjá lọ sí Sela àti síwájú sí i. Angẹli Olúwa ní Bokimu Ní ọjọ́ kan angẹli Olúwa dìde kúrò láti Gilgali lọ sí Bokimu ó sì wí pé, “Èmi mú un yín gòkè láti ilẹ̀ Ejibiti wá, èmi sì síwájú yín wá sí ilẹ̀ tí mo ti búra láti fi fún àwọn baba ńlá yín. Èmi sì wí pé, ‘Èmi kì yóò yẹ májẹ̀mú mi pẹ̀lú yín, ẹ̀yin kò gbọdọ̀ bá àwọn ènìyàn ilẹ̀ yí dá májẹ̀mú àlàáfíà, ṣùgbọ́n ẹ̀yin yóò wó pẹpẹ ibi ìsin òrìṣà wọn lulẹ̀.’ Síbẹ̀ ẹ̀yin ṣe àìgbọ́ràn sí mi. Èéṣe tí ẹ̀yin fi ṣe èyí? Ní báyìí, èmi wí fún un yín pé, èmi kì yóò lé àwọn ènìyàn jáde kúrò níwájú yín; ṣùgbọ́n wọn yóò jẹ́ ẹ̀gún ní ìhà yín, àwọn òrìṣà wọn yóò sì jẹ́ ìdánwò fún un yín.” Bí angẹli Olúwa sì ti sọ gbogbo ọ̀rọ̀ wọ̀nyí fún àwọn ará Israẹli tan, àwọn ènìyàn náà sì gbé ohùn wọn sókè wọ́n sì sọkún kíkorò, wọ́n sì pe orúkọ ibẹ̀ ní Bokimu (ibi tí àwọn ènìyàn ti sọkún). Wọ́n sì rú ẹbọ sí Olúwa níbẹ̀. Àìgbọ́ràn àti ìkùnà ní ogun Lẹ́yìn tí Joṣua ti tú àwọn ènìyàn Israẹli ká, àwọn ẹ̀yà Israẹli kọ̀ọ̀kan lọ sí ilẹ̀ tí a fi fún wọn láti lọ gbà á ní ìní wọn. Àwọn ènìyàn náà sin Olúwa ní gbogbo ìgbà ayé Joṣua àti ní gbogbo ọjọ́ àwọn àgbàgbà tí ó wà lẹ́yìn ikú rẹ̀ tí wọ́n sì rí gbogbo iṣẹ́ ńlá tí Olúwa ṣe fún Israẹli. Joṣua ọmọ Nuni, ìránṣẹ́ Olúwa, kú ní ẹni àádọ́fà ọdún. Wọ́n sì sìnkú rẹ̀ sí ààlà ilẹ̀ ìní rẹ̀ ní Timnati-Hereki ní ilẹ̀ òkè Efraimu ní àríwá òkè Gaaṣi. Ní ìgbẹ̀yìn, gbogbo ìran náà sì kú; àwọn ìran tí ó tẹ̀lé wọn kò sì sin Olúwa nítorí wọn kò mọ Olúwa, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò mọ ohun tí Olúwa ṣe fún Israẹli. Àwọn ọmọ Israẹli sì ṣe ohun tí ó burú níwájú Olúwa, wọ́n sì ń sin òrìṣà Baali. Wọ́n kọ Olúwa Ọlọ́run àwọn baba wọn sílẹ̀, ẹni tí ó mú wọn jáde kúrò ní ilẹ̀ Ejibiti, wọ́n ń tọ àwọn òrìṣà lẹ́yìn, wọ́n sì ń sin àwọn oríṣìíríṣìí òrìṣà àwọn ará ilẹ̀ ibi tí wọ́n ń gbé, wọ́n sì mú Olúwa bínú, nítorí tí wọ́n kọ̀ Olúwa sílẹ̀ àti nítorí pé wọ́n ń sin Baali àti Aṣtoreti. Nínú ìbínú rẹ̀ sí àwọn ọmọ Israẹli Olúwa fi wọ́n lé àwọn akónisìn lọ́wọ́ tí ó kó wọn ní ẹrú, tí ó sì bà wọ́n jẹ́. Ó sì tà wọ́n fún àwọn ọ̀tá wọn tí ó yí wọn ká àwọn ẹni tí wọn kò le dúró dè láti kọ ojú ìjà sí. Nígbàkígbà tí àwọn Israẹli bá jáde lọ sí ojú ogun láti jà, ọwọ́ Olúwa sì wúwo ní ara wọn, àwọn ọ̀tá a sì borí wọn, àní gẹ́gẹ́ bí ó ti búra fún wọn. Wọ́n sì wà nínú ìpọ́njú púpọ̀. Olúwa sì gbé àwọn onídàájọ́ dìde tí ó gbà wọ́n sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn tí ń kó wọn lẹ́rú. Síbẹ̀síbẹ̀ wọn kò fi etí sí ti àwọn onídàájọ́ wọn, ṣùgbọ́n wọ́n ṣe àgbèrè, wọ́n ń sin òrìṣà. Wọn kò dàbí àwọn baba wọn, kíákíá ni wọ́n yípadà kúrò lọ́nà tí àwọn baba wọ́n ń tọ̀, ọ̀nà ìgbọ́ràn sí àwọn òfin Olúwa. Nígbà kí ìgbà tí Olúwa bá gbé onídàájọ́ dìde fún wọn, Olúwa máa ń wà pẹ̀lú onídàájọ́ náà, a sì gbà wọ́n kúrò ní ọwọ́ àwọn ọ̀tá wọn ní ìwọ̀n ìgbà tí onídàájọ́ náà bá wà láààyè nítorí àánú Olúwa wà ní ara wọn, nígbà tí wọ́n bá ké ìrora lábẹ́ àwọn tí ń tẹrí wọn ba, tí sì ń fi ìyà jẹ wọ́n. Ṣùgbọ́n ní kété tí onídàájọ́ bá ti kú, àwọn ènìyàn náà a sì tún padà sí ọ̀nà ìbàjẹ́ àní ju ti àwọn baba wọn lọ, wọn a tẹ̀lé òrìṣà, wọ́n ń sìn wọ́n, wọn a sì foríbalẹ̀ fún wọn, wọ́n kọ̀ láti yàgò kúrò ní ọ̀nà ibi wọn àti agídí ọkàn wọn. Ìbínú Olúwa yóò sì tún ru sí Israẹli a sì wí pé, “Nítorí tí orílẹ̀-èdè yìí ti yẹ májẹ̀mú tí mo fi lélẹ̀ fún àwọn baba ńlá wọn, tí wọn kò sì fetí sí mi, Èmi kì yóò lé ọ̀kankan nínú àwọn orílẹ̀-èdè tí Joṣua fi sílẹ̀ nígbà tí ó kú jáde. Ṣùgbọ́n dípò bẹ́ẹ̀ èmi yóò lo àwọn orílẹ̀-èdè yìí láti fi dán Israẹli wò, láti mọ̀ bóyá wọ́n yóò pa ọ̀nà Olúwa mọ́ àti pé bóyá wọn ó rìn nínú rẹ̀ bí àwọn baba ńlá wọn ti rìn.” Nítorí náà Olúwa fi àwọn orílẹ̀-èdè náà sílẹ̀ ní ilẹ̀ náà kò sì lé wọn jáde, tàbí kí ó jẹ́ kí àwọn Israẹli pa wọ́n run, bẹ́ẹ̀ kò sì fi wọ́n lé Joṣua lọ́wọ́. Àwọn wọ̀nyí ni àwọn orílẹ̀-èdè tí Olúwa fi sílẹ̀ láti dán àwọn ìran tuntun ní Israẹli wò, àwọn ìran tí kò ì tí ì ní ìrírí ogun àwọn ará Kenaani. (Ó ṣe èyí láti fi kọ́ àwọn ìran Israẹli tí kò rí ogun rí níbí a ti ṣe ń jagun). Àwọn ìjòyè ìlú Filistini márààrún, gbogbo àwọn ará Kenaani, àwọn ará Sidoni, àti àwọn ará Hifi tí ń gbé ní àwọn òkè Lebanoni bẹ̀rẹ̀ láti òkè Baali-Hermoni títí dé Lebo-Hamati. A fi àwọn ènìyàn náà sílẹ̀ láti dán àwọn Israẹli wò bóyá wọn yóò gbọ́rọ̀ sí àwọn òfin Olúwa, èyí tí ó ti fi fún àwọn baba wọn láti ipasẹ̀ Mose. Àwọn ọmọ Israẹli gbé láàrín àwọn ará Kenaani, àwọn ará Hiti àwọn ará Amori, àwọn ará Peresi, àwọn ará Hifi àti àwọn ará Jebusi. Dípò kí wọ́n run àwọn ènìyàn wọ̀nyí, Israẹli ń fẹ́ àwọn ọmọbìnrin wọn, wọ́n sì ń fi àwọn ọmọbìnrin Israẹli fún àwọn ará ilẹ̀ náà ní aya, wọ́n sì ń sin àwọn òrìṣà wọn. Otnieli Àwọn ọmọ Israẹli sì ṣe èyí tí ó burú níwájú Olúwa, wọ́n gbàgbé Olúwa Ọlọ́run wọn, wọ́n sì ń sin Baali àti Aṣerah. Ìbínú Olúwa sì ru sí Israẹli tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi jẹ́ kí Kuṣani-Riṣataimu ọba Aramu-Naharaimu bá wọn jà kí ó sì ṣẹ́gun wọn, Israẹli sì ṣe ẹrú rẹ̀ fún ọdún mẹ́jọ. Ṣùgbọ́n nígbà tí Israẹli kígbe sí Olúwa, Òun gbé olùgbàlà kan dìde fún wọn, ẹni náà ni Otnieli ọmọ Kenasi àbúrò Kalebu tí ó jẹ́ ọkùnrin, ẹni tí ó gbà wọ́n sílẹ̀. Ẹ̀mí Olúwa bà lé e, òun sì ṣe ìdájọ́ Israẹli, ó sì síwájú wọn lọ sí ogun. Olúwa sì fi Kuṣani-Riṣataimu ọba Aramu lé Otnieli lọ́wọ́, ẹni tí ọwọ́ rẹ̀ sì borí Kuṣani-Riṣataimu. Ilẹ̀ náà sì wà ní àlàáfíà fún ogójì ọdún títí tí Otnieli ọmọ Kenasi sì kú. Ehudu Àwọn ọmọ Israẹli sì tún padà sí ìwà ẹ̀ṣẹ̀ wọn, wọ́n sì ṣe èyí tí ó burú ní iwájú Olúwa, fún ìdí iṣẹ́ búburú yìí, Olúwa fún Egloni, ọba àwọn Moabu ní agbára ní orí Israẹli. Pẹ̀lú ìfi ọwọ́ ṣowọ́pọ̀ ogun àwọn Ammoni àti àwọn ọmọ-ogun Amaleki ní Egloni gbógun ti àwọn ọmọ Israẹli, wọ́n sì gba ìlú Ọ̀pẹ tí i se Jeriko. Àwọn ọmọ Israẹli sì sin Egloni ọba Moabu fún ọdún méjìdínlógún. Ṣùgbọ́n nígbà tí Israẹli tún ké pe Olúwa, Olúwa rán olùgbàlà kan sí wọn, Ehudu ẹni tí ń lo ọwọ́ òsì, ọmọ Gera ti ẹ̀yà Benjamini. Àwọn ọmọ Israẹli fi ẹ̀bùn rán sí Egloni ọba Moabu. Ehudu sì rọ idà kan olójú méjì, ìgbọ̀nwọ́ kan ní gígùn; òun sì sán an ní abẹ́ aṣọ rẹ̀ ní itan rẹ̀ ọ̀tún. Ó sì mú ọrẹ náà wá fún Egloni ọba Moabu, Egloni ẹni tí ó sanra púpọ̀. Lẹ́yìn tí Ehudu ti fi ẹ̀bùn náà fún ọba tan, ó rán àwọn tí ó kó ẹrú náà wá lọ sí ọ̀nà wọn. Ṣùgbọ́n nígbà tí òun fúnra rẹ̀ dé ibi ère fínfín tí ó wà létí Gilgali, ó padà sí Egloni, ó sì wí pé, “Ọba, mo ní ọ̀rọ̀ àṣírí láti bá ọ sọ.” Ọba sì wí pé, “Ẹ dákẹ́!” Gbogbo àwọn tí ń ṣọ sì jáde síta kúrò ní ọ̀dọ̀ rẹ̀. Ehudu lọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ níbi tí ó ti jókòó ní iyàrá ìtura rẹ̀, Ehudu sì wí fún un pé, “Mo ní ọ̀rọ̀ kan fún ọ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.” Bí ọba sì ti dìde ní orí ìtẹ́ rẹ̀, Ehudu fi ọwọ́ òsì rẹ̀ yọ idà láti ibi itan ọ̀tún rẹ̀ ó sì fi gún ọba nínú ikùn rẹ̀. Àti idà àti èèkù rẹ̀ sì wọlé ó sì yọ ní ẹ̀yìn rẹ̀. Ehudu kò yọ idà náà, ọ̀rá sì bo idà náà. Ehudu ti àwọn ìlẹ̀kùn ní àtì-sínú òun sì bá yàrá òkè jáde, ó sì sálọ. Lẹ́yìn tí ó ti lọ àwọn ìránṣẹ́ ọba dé, ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n rí ìlẹ̀kùn yàrá òkè ní títì, wọ́n rò pé, “Bóyá ó wà ní ilé ìyàgbẹ́ ní yàrá nínú ilé.” Nígbà tí wọ́n dúró dé ibi pé ó jẹ́ ìyanu fún wọn, wọ́n mú kọ́kọ́rọ́, wọ́n sì ṣí ìlẹ̀kùn. Níbẹ̀ ni wọ́n ti rí Olúwa wọn tí ó ti ṣubú, ó sì ti kú. Nígbà tí wọ́n dúró tí wọn sì ń retí, Ehudu ti sálọ. Ó ti gba ibi tí wọ́n ti ń gbẹ́ òkúta lére, ó sì sálọ sí Seira. Nígbà tí ó dé ibẹ̀, ó fọn ìpè ní orí òkè Efraimu, àwọn ọmọ Israẹli sì ba sọ̀kalẹ̀ lọ láti òkè náà wá, òun sì wà níwájú wọn. Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ máa tẹ̀lé mi, nítorí Olúwa ti fi Moabu ọ̀tá yín lé yín lọ́wọ́.” Wọ́n sì tẹ̀lé e, wọ́n sì gba ìwọdò Jordani tí ó lọ sí ilẹ̀ Moabu, wọn ò jẹ́ kí ẹnikẹ́ni kọjá. Ní báyìí, wọ́n ti pa tó ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) ọkùnrin ará Moabu tí wọ́n jẹ́ alágbára àti onígboyà ènìyàn, kò sí ènìyàn tí ó sálà. Ní ọjọ́ náà ni Israẹli ṣẹ́gun àwọn ará Moabu, ilẹ̀ náà sì wà ní àlàáfíà fún ọgọ́rin ọdún. Ṣamgari Lẹ́yìn Ehudu, ni Ṣamgari ọmọ Anati ẹni tí ó pa ẹgbẹ̀ta (600) Filistini pẹ̀lú ọ̀pá tí a fi ń da akọ màlúù, òun pẹ̀lú sì gba Israẹli kúrò nínú ìpọ́njú. Debora Lẹ́yìn ikú Ehudu, àwọn ènìyàn Israẹli sì tún ṣẹ̀, wọ́n ṣe ohun tí ó burú ní ojú Olúwa. Nítorí náà Olúwa jẹ́ kí Jabini, ọba àwọn Kenaani, ẹni tí ó jẹ ọba ní Hasori, ṣẹ́gun wọn. Orúkọ olórí ogun rẹ̀ ni Sisera ẹni tí ń gbé Haroseti-Hagoyimu. Nítorí tí ó ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún (900) kẹ̀kẹ́ ogun irin, ó sì ń pọ́n Israẹli lójú gidigidi fún ogún ọdún, Israẹli ké pe Olúwa fún ìrànlọ́wọ́. Debora, wòlíì obìnrin, aya Lapidoti ni olórí àti aṣíwájú àwọn ará Israẹli ní àsìkò náà. Òun a máa jókòó ṣe ìdájọ́ ní abẹ́ igi ọ̀pẹ tí a sọ orúkọ rẹ̀ ní ọ̀pẹ Debora láàrín Rama àti Beteli ní ilẹ̀ òkè Efraimu, àwọn ará Israẹli a sì máa wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ láti yanjú èdè-àìyedè tí wọ́n bá ní sí ara wọn, tàbí láti gbọ́ ohùn Olúwa láti ẹnu rẹ̀. Ní ọjọ́ kan, ó ránṣẹ́ pe Baraki ọmọ Abinoamu, ẹni tí ń gbé ní Kedeṣi ní ilẹ̀ Naftali, ó sì wí fún un pé, “Olúwa, Ọlọ́run Israẹli pa á ní àṣẹ fún un pé, ‘Kí ó kó ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) àwọn akọni ọkùnrin jọ láti ẹ̀yà Naftali àti ẹ̀yà Sebuluni bí ẹgbẹ́ ogun, kí o sì síwájú wọn lọ sí òkè Tabori. Èmi yóò sì fa Sisera olórí ogun Jabini, pẹ̀lú kẹ̀kẹ́ ogun rẹ àti àwọn ogun rẹ, sí odò Kiṣoni èmi yóò sì fi lé ọ lọ́wọ́ ìwọ yóò sì ṣẹ́gun wọn níbẹ̀.’ ” Baraki sì dá a lóhùn pé, “Èmi yóò lọ tí ìwọ ó bá bá mi lọ, ṣùgbọ́n tí ìwọ kì yóò bá bá mi lọ, èmi kì yóò lọ.” Debora dá a lóhùn pé, “ó dára, èmi yóò bá ọ lọ. Ṣùgbọ́n ọlá ìṣẹ́gun tí o ń lọ yìí kò ní jẹ́ tìrẹ, nítorí Olúwa yóò fi Sisera lé obìnrin lọ́wọ́,” báyìí Debora bá Baraki lọ sí Kedeṣi. Nígbà tí Baraki pe ẹ̀yà Sebuluni àti ẹ̀yà Naftali sí Kedeṣi ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) akíkanjú ọkùnrin ogun tẹ̀lé e, Debora pẹ̀lú bá wọn lọ. Ǹjẹ́ Heberi ọmọ Keni, ti ya ara rẹ́ kúrò lọ́dọ̀ àwọn ọmọ Keni, àní àwọn ọmọ Hobabu, àna Mose, ó sì pa àgọ́ rẹ̀ títí dé ibi igi óákù Saananimu, tí ó wà ni agbègbè Kedeṣi. Nígbà tí a sọ fún Sisera pé Baraki ọmọ Abinoamu ti kó ogun jọ sí òkè Tabori, Sisera kó gbogbo kẹ̀kẹ́ ogun irin rẹ̀ tí ṣe ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún (900) àti gbogbo àwọn ọmọ-ogun tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀, láti Haroseti tí àwọn orílẹ̀-èdè wá sí odò Kiṣoni. Debora sì wí fún Baraki pé, “Lọ! Lónìí ni Olúwa fi Sisera lé ọ lọ́wọ́, Olúwa ti lọ síwájú rẹ.” Baraki sì síwájú, àwọn ọmọ-ogun rẹ̀ ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) sì tẹ̀lé e lẹ́yìn, wọ́n sì kọjá sí òkè Tabori. Olúwa sì mú ìdàrúdàpọ̀ wá sí àárín ogun Sisera, Olúwa sì fi ojú idà ṣẹ́gun Sisera àti àwọn oníkẹ̀kẹ́ ogun àti ọmọ-ogun orí ilẹ̀ ní iwájú Baraki. Sisera sì sọ̀kalẹ̀ lórí kẹ̀kẹ́-ẹṣin rẹ̀ ó sì fi ẹsẹ̀ sálọ. Baraki àti àwọn ogun rẹ̀ sì lé àwọn ọ̀tá náà, àwọn ọmọ-ogun orílẹ̀ àti àwọn kẹ̀kẹ́ ogun wọn títí dé Haroseti ti àwọn orílẹ̀-èdè, gbogbo ogun Sisera sì ti ojú idà ṣubú, kò sí ọ̀kan tí ó lè sálà tàbí tí ó wà láààyè. Ṣùgbọ́n Sisera ti fi ẹsẹ̀ sálọ sí àgọ́ Jaeli aya Heberi ẹ̀yà Keni: nítorí ìbá dá ọ̀rẹ́ àlàáfíà wà láàrín Jabini ọba Hasori àti ìdílé Heberi ti ẹ̀yà Keni. Jaeli sì jáde síta láti pàdé Sisera, ó sì wí fún un pé, “Wọlé sínú àgọ́ mi, Olúwa mi, wọlé wá má ṣe bẹ̀rù nítorí pé ààbò ń bẹ fún ọ.” Ó sì yà sínú àgọ́ rẹ̀, ó sì fi aṣọ bò ó. Sisera wí pé, “Òrùngbẹ ń gbẹ́ mí, jọ̀wọ́ fún mi ní omi mu.” Ó sì ṣí awọ wàrà kan, ó sì fún un mu ó sì tún daṣọ bò ó padà. Sisera sọ fún Jaeli pé, “Kí ó dúró ní ẹnu-ọ̀nà àgọ́, àti pé bí ẹnikẹ́ni bá béèrè bóyá òun wà níbẹ̀ kí ó sọ pé, ‘Kò sí ẹnìkankan ní ibẹ̀.’ ” Ṣùgbọ́n Jaeli ìyàwó Heberi mú ìṣó àgọ́ tí ó mú àti òòlù ní ọwọ́ rẹ̀, ó sì yọ́ wọ inú ibi tí ó sùn, nígbà tí ó ti sùn fọnfọn, nígbà náà ni ó kan ìṣó náà mọ́ òkè ìpéǹpéjú rẹ̀, ó sì wọlé ṣinṣin, ó sì kú. Nígbà tí Baraki dé bí ó ti ń lépa Sisera, Jaeli láti pàdé rẹ̀, wá, èmi yóò fi ẹni tí ìwọ ń wá hàn ọ́, báyìí ni ó tẹ̀lé e wọ inú àgọ́ lọ, kíyèsi Sisera dùbúlẹ̀ síbẹ̀ pẹ̀lú ìṣó àgọ́ ní agbárí rẹ̀ tí a ti kàn mọ́lẹ̀ ṣinṣin tí ó sì ti kú. Ní ọjọ́ náà ni Ọlọ́run ṣẹ́gun Jabini ọba àwọn ará Kenaani ní iwájú àwọn ẹ̀yà Israẹli. Ọwọ́ àwọn ọmọ Israẹli sì le, ó sì ń lágbára síwájú àti síwájú sí i lára Jabini ọba Kenaani, títí wọ́n fi run òun àti àwọn ènìyàn rẹ̀. Orin Debora Nígbà náà ni Debora àti Baraki ọmọ Abinoamu kọ orin ní ọjọ́ náà wí pé, “Nítorí bí àwọn olórí ti síwájú ní Israẹli, nítorí bi àwọn ènìyàn ti fi tọkàntọkàn wa, ẹ fi ìbùkún fún Olúwa! “Ẹ gbọ́ ẹ̀yin ọba! Ẹ fetí yín sílẹ̀ ẹ̀yin ọmọ-aládé! Èmi yóò kọrin sí Olúwa, èmi yóò kọrin ìyìn sí Olúwa: Ọlọ́run Israẹli. Olúwa nígbà tí o jáde kúrò ní Seiri, nígbà tí ìwọ ń yan jáde wá láti pápá Edomu, ilẹ̀ mì tìtì, àwọn ọ̀run sì kán sílẹ̀, àní àwọsánmọ̀ pẹ̀lú kàn omi sílẹ̀. Àwọn òkè ńlá wárìrì ní iwájú Olúwa, bẹ́ẹ̀ ni Sinai ní iwájú Olúwa Ọlọ́run Israẹli. “Ní ọjọ́ Ṣamgari ọmọ Anati, ní ọjọ́ Jaeli, àwọn ọ̀nà òpópó dá; àwọn arìnrìn-àjò sì ń gba ọ̀nà ìkọ̀kọ̀. Àwọn olórí tán ní Israẹli, wọ́n tán, títí èmi Debora fi dìde bí ìyá ní Israẹli. Wọ́n ti yan ọlọ́run tuntun, nígbà náà ni ogun wà ní ibodè a ha rí asà tàbí ọ̀kọ̀ kan láàrín ọ̀kẹ́ méjì (40,000) ní Israẹli bí. Àyà mi fà sí àwọn aláṣẹ Israẹli àwọn tí wọ́n yọ̀ǹda ara wọn tinútinú láàrín àwọn ènìyàn. Ẹ fi ìbùkún fún Olúwa! “Ẹ kéde rẹ̀: ẹ̀yin tí ń gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ funfun, ẹ̀yin tí ń jókòó lórí ẹní dáradára, àti ẹ̀yin tí ó ń rìn ní ọ̀nà. Ní ọ̀nà jíjìn sí ariwo àwọn tafàtafà, ní ibi tí a gbé ń fa omi. Níbẹ̀ ni wọ́n gbé ń sọ ti iṣẹ́ òdodo Olúwa, àní iṣẹ́ òdodo ìjọba rẹ̀ ní Israẹli. “Nígbà náà ni àwọn ènìyàn Olúwa sọ̀kalẹ̀ lọ sí ibodè. ‘Jí, jí, Debora! Jí, jí, kọ orin dìde! Dìde ìwọ Baraki! Kó àwọn ìgbèkùn rẹ ní ìgbèkùn ìwọ ọmọ Abinoamu.’ “Nígbà náà ni àwọn tókù sọ̀kalẹ̀ àwọn ọlọ́lá lọ; àwọn ènìyàn Olúwa tọ̀ mí wá pẹ̀lú àwọn alágbára. Àwọn kan jáde wá láti Efraimu, àwọn tí gbòǹgbò wọn wà ní Amaleki; Benjamini wà pẹ̀lú àwọn tí ó tẹ̀lé ọ. Láti Makiri ni àwọn aláṣẹ ti sọ̀kalẹ̀ wá, láti Sebuluni ni àwọn ẹni tí ń mú ọ̀pá oyè lọ́wọ́. Àwọn ọmọ-aládé Isakari wá pẹ̀lú Debora; bí Isakari ti ṣe olóòtítọ́ sí Baraki, wọ́n fi ẹsẹ̀ súré tẹ̀lé wọn lọ sí àfonífojì náà. Ní ipadò Reubeni ni ìgbèrò púpọ̀ wà. Èéṣe tí ìwọ fi dúró pẹ́ láàrín agbo àgùntàn láti máa gbọ́ fèrè olùṣọ́-àgùntàn? Ní ipadò Reubeni ni ìgbèrò púpọ̀ wà. Gileadi dúró ní òkè odò Jordani. Èéṣe tí Dani fi dúró nínú ọkọ̀ ojú omi? Aṣeri jókòó ní etí bèbè Òkun, ó sì ń gbé èbúté rẹ̀. Àwọn ènìyàn Sebuluni fi ẹ̀mí wọn wéwu ikú; bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn ènìyàn Naftali ní ibi gíga pápá. “Àwọn ọba wá, wọ́n sì jà; àwọn ọba Kenaani jà ní Taanaki ní etí odo Megido, ṣùgbọ́n wọn kò sì gba èrè owó. Àwọn ìràwọ̀ já láti ojú ọ̀run wá láti inú ipa ọ̀nà wọn ni wọ́n bá Sisera jà. Odò Kiṣoni gbá wọn lọ, odò ìgbàanì, odò Kiṣoni. Máa yan lọ, ìwọ ọkàn mi, nínú agbára! Nígbà náà ni pátákò ẹsẹ̀ ẹṣin ki ilẹ̀, nítorí eré sísá, eré sísá àwọn alágbára wọn. ‘Ẹ fi Merosi bú,’ ni angẹli Olúwa wí. ‘Ẹ fi àwọn ènìyàn inú rẹ̀ bú ìbú kíkorò, nítorí wọn kò wá sí ìrànlọ́wọ́ Olúwa, láti dojúkọ àwọn alágbára.’ “Ìbùkún ni fún Jaeli, aya Heberi ará Keni ju àwọn obìnrin lọ, ìbùkún ni fún un ju àwọn obìnrin tí ń gbé nínú àgọ́. Ó béèrè omi, ó fún un ní wàrà; ó mú òrí-àmọ́ tọ̀ ọ́ wá nínú àwo iyebíye tí ó yẹ fún àwọn ọlọ́lá. Ó na ọwọ́ rẹ̀ mú ìṣó àgọ́, ó fi ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ mú òòlù awọ gbẹ́nàgbẹ́nà, òòlù náà ni ó sì fi lu Sisera, ó gbá a mọ́ ọn ní orí, ó sì gun, ó sì kàn ẹ̀bátí rẹ̀ mọ́lẹ̀ ṣinṣin. Ní ẹsẹ̀ rẹ̀ ó wólẹ̀, ó ṣubú; ó dùbúlẹ̀. Ó wólẹ̀ ní ẹsẹ̀ rẹ̀, ó ṣubú níbi tí ó gbé ń wólẹ̀; níbẹ̀ náà ni ó ṣubú kú sí. “Ìyá Sisera yọjú láti ojú fèrèsé, ó sì kígbe, ó kígbe ní ojú fèrèsé ọlọ́nà pé, ‘Èéṣe tí kẹ̀kẹ́-ẹṣin rẹ fi pẹ́ bẹ́ẹ̀ láti dé? Èéṣe tí ẹsẹ̀ kẹ̀kẹ́-ẹṣin rẹ̀ fi dúró lẹ́yìn?’ Àwọn amòye obìnrin rẹ̀ dá a lóhùn; àní òun náà pẹ̀lú ti dá ara rẹ̀ lóhùn pé, ‘Wọn kò ha ń wa kiri, wọn kò ha ti pín ìkógun bi: ọmọbìnrin kan tàbí méjì fún ọkùnrin kan, fún Sisera ìkógun aṣọ aláràbarà, ìkógun aṣọ aláràbarà àti ọlọ́nà, àwọn aṣọ ọlọ́nà iyebíye fún ọrùn mi, gbogbo èyí tí a kó ní ogun?’ “Bẹ́ẹ̀ ni kí ó jẹ́ kí gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ kí ó ṣègbé Olúwa! Ṣùgbọ́n jẹ́ kí àwọn tí ó fẹ́ ọ ràn bí oòrùn, nígbà tí ó bá yọ nínú agbára rẹ̀.” Ilẹ̀ náà sì sinmi ní ogójì ọdún. Gideoni Àwọn ọmọ Israẹli sì túnṣe ohun tí ó burú ní ojú Olúwa, Ó sì fi wọ́n lé àwọn ará Midiani lọ́wọ́ fún ọdún méje. Agbára àwọn ará Midiani sì pọ̀ púpọ̀ lórí àwọn Israẹli, wọ́n sì hùwà ipá sí wọn, nítorí ìdí èyí, àwọn Israẹli sálọ sí àwọn orí òkè, wọ́n sì kọ́ àgọ́ fún ara wọn nínú ihò àpáta, àti nínú ọ̀gbun àti ní ibi agbára nínú àpáta. Ní ìgbàkúgbà tí àwọn ọmọ Israẹli bá ti gbin ọ̀gbìn wọn, àwọn ará Midiani, àwọn ará Amaleki àti àwọn ará ìlà-oòrùn mìíràn yóò wá láti bá wọn jà. Wọn yóò tẹ̀dó sí orí ilẹ̀ náà, wọn a sì bá irúgbìn wọ̀nyí jẹ́ títí dé Gasa, wọn kì í sì í fi ohun alààyè kankan sílẹ̀ fún àwọn ọmọ Israẹli, kì bá à ṣe àgùntàn, màlúù tàbí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́. Wọn a máa wá pẹ̀lú ohun ọ̀sìn wọn àti àwọn àgọ́ wọn, wọn a sì dàbí eṣú nítorí i púpọ̀ wọn. Ènìyàn kò sì lè ka iye àwọn ènìyàn náà bẹ́ẹ̀ ni àwọn ìbákasẹ, wọ́n pọ̀ dé bi pé wọn kò ṣe é kà ní iye, wọn a bo ilẹ̀ náà wọn a sì jẹ ẹ́ run. Àwọn ará Midiani sì pọ́n àwọn ọmọ Israẹli lójú, wọ́n sọ wọ́n di òtòṣì àti aláìní, fún ìdí èyí wọ́n ké pe Olúwa nínú àdúrà fún ìrànlọ́wọ́. Nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli ké pe Olúwa nítorí àwọn ará Midiani. Olúwa fi etí sí igbe wọn, ó sì rán wòlíì kan sí wọn, ẹni tí ó wí pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run Israẹli wí: mo mú yín gòkè ti Ejibiti wá, láti oko ẹrú. Mo gbà yín kúrò nínú agbára Ejibiti àti kúrò ní ọwọ́ gbogbo àwọn aninilára yín. Mo lé wọn kúrò ní iwájú yín, mo sì fi ilẹ̀ wọn fún yín. Mo wí fún un yín pé, ‘Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín; ẹ má ṣe sin àwọn òrìṣà àwọn ará Amori, ní ilẹ̀ ẹni tí ẹ̀yin ń gbé.’ Ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò gbọ́rọ̀ sí ohun tí mo sọ.” Ní ọjọ́ kan angẹli Olúwa wá, ó sì jókòó ní abẹ́ igi óákù Ofira èyí ti ṣe ti Joaṣi ará Abieseri, níbi tí Gideoni ọmọ rẹ̀ ti ń lu ọkà jéró, níbi ìpọntí wáìnì láti fi pamọ́ kúrò níwájú àwọn ará Midiani. Nígbà tí angẹli Olúwa fi ara han Gideoni, ó wí fún un pé, “Olúwa wà pẹ̀lú rẹ, akọni ológun.” Gideoni dáhùn pé, “Alàgbà, bí Olúwa bá wà pẹ̀lú wa, kí ló dé tí gbogbo ìwọ̀nyí fi ń ṣẹlẹ̀ sí wa? Níbi gbogbo àwọn iṣẹ́ ìyanu rẹ tí àwọn baba wa ròyìn rẹ̀ fún wa nígbà tí wọ́n wí pé, ‘Olúwa kò ha mú wa gòkè láti ilẹ̀ Ejibiti wá?’ Ṣùgbọ́n nísinsin yìí Olúwa ti kọ̀ wá sílẹ̀, ó sì ti fi wá lé àwọn ará Midiani lọ́wọ́.” Olúwa sì yípadà sí i, ó sì wí fún un pé, “Lọ nínú agbára tí o ní yìí, kí o sì gba àwọn ará Israẹli sílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ àwọn ará Midiani. Èmi ni ó ń rán ọ lọ.” Gideoni sì dáhùn pé, “Yéè olúwa mi, ọ̀nà wo ni èmi yóò fi gba Israẹli là? Ìdílé mi ni ó jẹ́ aláìlera jù ní Manase, àti pé èmi ni ó sì kéré jù ní ìdílé baba mi.” Olúwa sì dáhùn pé, “Èmi yóò wà pẹ̀lú rẹ, ìwọ yóò sì pa gbogbo àwọn ará Midiani láì ku ẹnìkankan.” Gideoni sì dáhùn pé, nísinsin yìí tí mo bá bá ojúrere rẹ pàdé, fún mi ní àmì pé ìwọ ni ń bá mi sọ̀rọ̀. Jọ̀wọ́ má ṣe kúrò níbí títí èmi yóò fi mú ọrẹ wá fún ọ kí n sì gbé e sí iwájú rẹ. Olúwa sì wí pé, “Èmi yóò dúró títí ìwọ yóò fi dé.” Gideoni sì yára wọ ilé lọ, ó sì pa ọ̀dọ́ ewúrẹ́ kan, wọ́n sì sè é, ó sì mú ìyẹ̀fun efa kan, ó fi ṣe àkàrà aláìwú. Ó gbé ẹran náà sínú agbọ̀n, ṣùgbọ́n ó fi ọbẹ̀ rẹ̀ sínú ìkòkò, ó gbé wọn jáde tọ angẹli náà wá bí ọrẹ lábẹ́ igi óákù. Angẹli Ọlọ́run náà sì wí fún un pé, “Gbé ẹran náà àti àkàrà àìwú náà, sí orí àpáta yìí, kí o sì da omi ọbẹ̀ rẹ̀ sí orí rẹ̀.” Gideoni sì ṣe bẹ́ẹ̀. Angẹli Olúwa sì fi orí ọ̀pá tí ó wà ní ọwọ́ rẹ̀ kan ẹran àti àkàrà àìwú náà. Iná sì jáde láti inú àpáta, ó sì jó ẹran àti àkàrà náà, kò sì rí angẹli náà mọ́. Nígbà tí Gideoni sì ti mọ̀ dájúdájú pé angẹli Olúwa ni, ó ké wí pé, “Háà! Olúwa Olódùmarè! Mo ti rí angẹli Olúwa ní ojúkorojú!” Ṣùgbọ́n Olúwa wí fún un pé, “Àlàáfíà! Má ṣe bẹ̀rù, ìwọ kì yóò kùú.” Báyìí ni Gideoni mọ pẹpẹ kan fún Olúwa níbẹ̀, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní “Àlàáfíà ni Olúwa.” Ó sì wà ní Ofira ti Abieseri títí di òní. Ní òru ọjọ́ náà Olúwa wí fún un pé, mú akọ màlúù baba rẹ, àní akọ màlúù kejì ọlọ́dún méje. Wó pẹpẹ Baali baba rẹ lulẹ̀, kí o sì bẹ́ igi ère òrìṣà Aṣerah tí ó wà ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ lulẹ̀. Lẹ́yìn èyí kí o wá mọ pẹpẹ èyí tí ó yẹ fún Olúwa Ọlọ́run rẹ lórí òkè yìí. Kí o sì mú akọ màlúù kejì, kí o sì mú igi ère òrìṣà Aṣerah tí ìwọ bẹ́ lulẹ̀ rú ẹbọ sísun sí Olúwa. Gideoni mú mẹ́wàá nínú àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, ó sì ṣe bí Olúwa ti pàṣẹ fún un ṣùgbọ́n, nítorí ó bẹ̀rù àwọn ará ilé baba rẹ̀ àti àwọn ènìyàn ìlú náà kò ṣe é ní ọ̀sán, òru ni ó ṣe. Nígbà tí ilẹ̀ ọjọ́ kejì mọ́, tí àwọn ènìyàn ìlú náà jí, wọ́n rí i pé àti fọ́ pẹpẹ Baali àti pé a ti bẹ́ igi ère òrìṣà Aṣerah tí ó wà ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀, a sì ti fi akọ màlúù kejì rú ẹbọ lórí pẹpẹ tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ mọ. Àwọn ènìyàn ìlú náà bi ara wọn wí pé, “Ta ni ó ṣe èyí?” Lẹ́yìn tí wọn fi ara balẹ̀ ṣe ìwádìí, wọ́n gbọ́ wí pé, “Gideoni ọmọ Joaṣi ni ó ṣe é.” Àwọn ọkùnrin ìlú náà sì wí fún Joaṣi wí pé, “Mú ọmọ rẹ jáde wá. Ó ní láti kú nítorí pé ó ti wó pẹpẹ Baali lulẹ̀ ó sì ti ké ère òrìṣà Aṣerah tí ó wà ní ẹ̀bá rẹ̀ lulẹ̀.” Ṣùgbọ́n Joaṣi bi àwọn èrò tí wọ́n fi ìbínú dúró tì í wí pé, “Ẹ̀yin yóò ha gbìjà Baali bí? Ẹ̀yin yóò ha gbà á sílẹ̀ bí? Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbìjà rẹ̀ kíkú ni olúwa rẹ̀ yóò kú ní òwúrọ̀. Bí Baali bá ṣe Ọlọ́run nítòótọ́ yóò jà fún ara rẹ̀ bí ẹnikẹ́ni bá wó pẹpẹ rẹ̀ lulẹ̀.” Fún ìdí èyí ní ọjọ́ náà wọ́n pe Gideoni ní “Jerubbaali” wí pé, “Jẹ́ kí Baali bá a jà,” nítorí pé ó ti wó pẹpẹ Baali. Láìpẹ́ jọjọ, àwọn ogun àwọn Midiani, ti àwọn Amaleki àti ti àwọn ènìyàn ìhà ìlà-oòrùn yòókù kó ara wọn jọ pọ̀ ní ìṣọ̀kan, wọ́n sì kọjá Jordani wọ́n sì tẹ̀dó sí àfonífojì Jesreeli. Ẹ̀mí Olúwa sì bà lé Gideoni, ó sì fun fèrè ìpè, láti pe àwọn ará Abieseri láti tẹ̀lé òun. Ó rán àwọn oníṣẹ́ la ilẹ̀ Manase já pé kí wọ́n dira ogun, àti sí Aṣeri, Sebuluni àti Naftali gbogbo pẹ̀lú sì lọ láti pàdé wọn. Gideoni wí fún Ọlọ́run pé, “Bí ìwọ yóò bá gba Israẹli là nípasẹ̀ mi bí ìwọ ti ṣe ìlérí— kíyèsi, èmi yóò fi awọ irun àgùntàn lé ilẹ̀ ìpakà ní alẹ́ òní. Bí ìrì bá sẹ̀ sí orí awọ yìí nìkan tí gbogbo ilẹ̀ yòókù sì gbẹ, nígbà náà ni èmi yóò mọ̀ lóòótọ́ pé ìwọ yóò gba Israẹli là nípasẹ̀ mi bí ìwọ ti sọ.” Èyí ni ó sì ṣẹlẹ̀. Nígbà tí Gideoni jí ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, ó sì fún irun àgùntàn náà, ọpọ́n omi kan sì kún. Gideoni sì tún wí fún Ọlọ́run pé, “Jọ̀wọ́ má ṣe bínú sí mi, ṣùgbọ́n jẹ́ kí n tún wá ìdánilójú kan sí i, èmi bẹ̀ ọ́ jẹ́ kí n fi awọ irun yìí ṣe ìdánwò kan sí i. Ní àsìkò yìí, jẹ́ kí awọ irun yìí gbẹ kí gbogbo ilẹ̀ sì tutù pẹ̀lú ìrì.” Ní òru náà Ọlọ́run ṣe bẹ́ẹ̀, awọ irun àgùntàn nìkan ni ó gbẹ; gbogbo ilẹ̀ yòókù sì tutù nítorí ìrì. Gideoni ṣẹ́gun àwọn ará Midiani Ní òwúrọ̀ kùtùkùtù Jerubbaali (èyí ni Gideoni) pẹ̀lú gbogbo àwọn ọmọ-ogun tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ kó ogun jọ lẹ́bàá a orísun Harodi. Àwọn ogun Midiani sì wà ní apá àríwá tí wọ́n ní àfonífojì tí ó wà ní ẹ̀bá òkè More. Olúwa wí fún Gideoni pé, “Àwọn ọmọ-ogun tí o kójọ sọ́dọ̀ ti pọ̀jù fún mi láti fi àwọn ogun Midiani lé wọn lọ́wọ́, kí Israẹli má ba à gbé ara rẹ̀ ga sí mi wí pé agbára òun ni ó gbà á là, sì kéde sí àwọn ènìyàn nísinsin yìí pé, ‘Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń gbọ̀n, tí ó sì ń bẹ̀rù lè padà sẹ́yìn, kí ó sì kúrò lórí òkè Gileadi.’ ” Báyìí ni Gideoni ṣe ya àwọn ènìyàn náà. Ẹgbẹ̀rún méjìlélógún (22,000) ọkùnrin sì padà sẹ́yìn àwọn ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) sì dúró. Olúwa sì tún sọ fún Gideoni pé, “Àwọn ènìyàn yìí sì tún pọ̀jù. Kó wọn lọ sí ibi tí omi wà, èmi yóò sì yọ̀rọ̀ wọn níbẹ̀ fún ọ. Bí mo bá wí pé eléyìí yóò bá ọ lọ yóò lọ, ṣùgbọ́n tí mo bá sọ pé, ‘Eléyìí kò ní bá ọ lọ,’ òun kò gbọdọ̀ lọ.” Gideoni sì kó àwọn ọkùnrin náà lọ sí ibi ìsun omi. Níbẹ̀ ni Olúwa ti wí fún un pé, “Kí ó pín àwọn ènìyàn náà sí ọ̀nà méjì. Ya àwọn tí ó fi ahọ́n wọn lá omi bí ajá kúrò lára àwọn tí ó kúnlẹ̀ láti mu omi pẹ̀lú ọwọ́ wọn.” Ọ̀ọ́dúnrún (300) ọkùnrin ni ó lá omi pẹ̀lú ahọ́n wọn. Gbogbo àwọn ìyókù ni ó kúnlẹ̀ láti mu mi. Olúwa wí fún Gideoni pé, “Àwọn ọ̀ọ́dúnrún (300) ọkùnrin tí ó lá omi ni èmi yóò lò láti gbà yín là àti láti fi ogun Midiani lé yín lọ́wọ́. Jẹ́ kí àwọn tókù padà sí ilé wọn.” Báyìí ni Gideoni ṣe dá àwọn Israẹli tí ó kù padà sí àgọ́ wọn, ṣùgbọ́n ó dá àwọn ọ̀ọ́dúnrún (300) ọkùnrin náà dúró. Àwọn wọ̀nyí sì gba gbogbo ohun èlò àti fèrè àwọn tí ó ti padà. Ibùdó ogun àwọn Midiani wà ní àfonífojì ní ìsàlẹ̀. Ibi tí ó wà. Ní òru ọjọ́ náà Olúwa sọ fún Gideoni pé, “Dìde, dojú ogun kọ ibùdó ogun àwọn ará Midiani nítorí èmi yóò fi lé ọ lọ́wọ́. Ṣùgbọ́n bí ẹ̀rù àti kọlù wọ́n bá ń bà ọ́, yọ́ wọ ibùdó wọn lọ kí o mú Pura ìránṣẹ́ rẹ lọ́wọ́ kí o sì fi ara balẹ̀ gbọ́ ohun tí wọ́n ń sọ nínú ibùdó náà. Lẹ́yìn èyí ọkàn rẹ̀ yóò le láti kọlù ibùdó náà.” Báyìí ni òun àti Pura ìránṣẹ́ rẹ̀ wọ ẹnu-ọ̀nà ibùdó yìí. Àwọn ará Midiani, àwọn ará Amaleki àti gbogbo ènìyàn ìlà-oòrùn tó lọ ní àfonífojì bí eṣú ni wọ́n rí nítorí púpọ̀ wọn. Àwọn ìbákasẹ wọn kò sì lóǹkà, wọ́n sì pọ̀ bí yanrìn inú Òkun. Gideoni dé sí àsìkò tí ọkùnrin kan bẹ̀rẹ̀ sí í rọ́ àlá tí ó lá sí ọ̀kan nínú àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀. Ó ní, “Mo lá àlá kan, nínú àlá náà mo rí àkàrà kan tó ṣe róbótó tí a fi barle ṣe ń yí wọ inú ibùdó àwọn ará Midiani, ó sì kọlu àgọ́ pẹ̀lú agbára ńlá dé bi wí pé àgọ́ náà dojúdé, ó sì ṣubú.” Ọ̀rẹ́ rẹ̀ dá a lóhùn pé, “Èyí kò le túmọ̀ sí ohun mìíràn ju idà Gideoni ọmọ Joaṣi ará Israẹli lọ: Ọlọ́run ti fi àwọn ará Midiani àti gbogbo ogun ibùdó lé e lọ́wọ́.” Nígbà tí Gideoni gbọ́ àlá náà àti ìtumọ̀ rẹ̀, ó wólẹ̀ sin Ọlọ́run: lẹ́yìn náà ni ó padà sí ibùdó àwọn ọmọ Israẹli ó sì pè wọ́n pé, “Ẹ dìde! Nítorí pé Olúwa yóò lò yín láti ṣẹ́gun gbogbo ogun Midiani.” Nígbà tí ó ti pín àwọn ọ̀ọ́dúnrún (300) ọkùnrin wọ̀n-ọn-nì sí ọ̀nà mẹ́ta, ó fi fèrè, pẹ̀lú àwọn òfìfo ìkòkò lé ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn lọ́wọ́, iná sì wà nínú àwọn ìkòkò náà. Ó sọ fún wọn pé, “Ẹ máa wò mí, kí ẹ sì máa ṣe ohun tí mo bá ṣe. Nígbà tí mo bá dé igun ibùdó wọn ẹ ṣe ohun tí mo bá ṣe. Nígbà tí èmi àti àwọn ọkùnrin tí ó wà pẹ̀lú mi bá fun fèrè wa, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ̀yin náà ni gbogbo igun ibùdó tí ẹ̀ bá wà kí ẹ fun àwọn fèrè yín kí ẹ sì hó pé, ‘Fún Olúwa àti fún Gideoni.’ ” Gideoni àti àwọn ọgọ́rùn-ún ọkùnrin tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ dé òpin ibùdó àwọn ará Midiani ní nǹkan bí agogo méjìlá padà. Wọ́n fun fèrè wọn, wọ́n sì tún fọ́ àwọn ìkòkò tí ó wà ní ọwọ́ mọ́lẹ̀. Àwọn ẹgbẹ́ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta fun fèrè wọn, wọ́n tún fọ́ àwọn ìkòkò wọn mọ́lẹ̀. Wọ́n mú àwọn fìtílà iná wọn ní ọwọ́ òsì wọn àti fèrè tí wọ́n ń fun ní ọwọ́ ọ̀tún wọn. Wọ́n pariwo hé è pé, “Idà kan fún Olúwa àti fún Gideoni!” Nígbà tí ọkùnrin kọ̀ọ̀kan dúró ní ipò rẹ̀ yí ibùdó àwọn Midiani ká, gbogbo àwọn ọmọ-ogun Midiani ń sá káàkiri, wọ́n ń pariwo bí wọ́n ṣe ń sálọ. Nígbà tí àwọn ọ̀ọ́dúnrún (300) ọkùnrin wọ̀n-ọn-nì fun fèrè wọn, Olúwa sì yí ojú idà ọkùnrin kọ̀ọ̀kan padà sí ẹnìkejì rẹ̀ àti sí gbogbo ogun wọn. Àwọn ọmọ-ogun sì sá títí dé Beti-Sitta ní ọ̀nà Serera títí lọ dé ìpínlẹ̀ Abeli-Mehola ní ẹ̀bá Tabbati. Gbogbo àwọn ọmọ-ogun Israẹli láti ẹ̀yà Naftali, Aṣeri àti gbogbo Manase ni Gideoni ránṣẹ́ si, wọ́n wá wọ́n sì lé àwọn ará Midiani. Gideoni tún ránṣẹ́ sí gbogbo àwọn ìlú tí ó wà ní orí òkè Efraimu wí pé, “Ẹ jáde wá bá àwọn ará Midiani jà, kí ẹ tètè gba àwọn omi Jordani títí dé Beti-Bara kí wọ́n tó dé bẹ̀.” Báyìí ni a ṣe pe gbogbo ọkùnrin ológun Efraimu jáde tí wọ́n sì gba gbogbo àwọn à bá wọ odò Jordani títí dé Beti-Bara. Wọ́n mú méjì nínú àwọn olórí àwọn ará Midiani, àwọn náà ni Orebu àti Seebu. Wọ́n pa Horebu nínú àpáta Orebu, wọ́n sì pa Seebu níbi tí àwọn ènìyàn ti mọ̀ fún wáìnì tí a ń pè ní ìfúntí Seebu. Wọ́n lé àwọn ará Midiani, nígbà tí wọ́n gbé orí Orebu àti Seebu tọ Gideoni wá ẹni tí ó wà ní apá kejì Jordani. Seba àti Salmunna Àwọn àgbàgbà ẹ̀yà Efraimu sì bínú gidigidi sí Gideoni wọ́n bi í léèrè pé, kí ló dé tí o fi ṣe irú èyí sí wa? Èéṣe tí ìwọ kò fi pè wá nígbà tí ìwọ kọ́kọ́ jáde lọ láti bá àwọn ará Midiani jagun? Ohùn ìbínú ni wọ́n fi bá a sọ̀rọ̀. Ṣùgbọ́n Gideoni dá wọn lóhùn pé, “Àṣeyọrí wo ni mo ti ṣe tí ó tó fiwé tiyín? Àṣàkù àjàrà Efraimu kò ha dára ju gbogbo ìkórè àjàrà Abieseri lọ bí? Ọlọ́run ti fi Orebu àti Seebu àwọn olórí àwọn ará Midiani lé yín lọ́wọ́. Kí ni ohun tí Mose ṣe tí ó tó fiwé e yín tàbí tí ó tó àṣeyọrí i yín?” Nígbà tí ó wí èyí ríru ìbínú wọn rọlẹ̀. Gideoni àti àwọn ọ̀ọ́dúnrún (300) ọkùnrin tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ tẹ̀síwájú láti lépa àwọn ọ̀tá bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti rẹ̀ wọ́n, wọ́n dé Jordani wọ́n sì kọjá sí òdìkejì. Ó wí fún àwọn ọkùnrin Sukkoti pé, “Ẹ fún àwọn ọmọ-ogun mi ní oúnjẹ díẹ̀, nítorí ó ti rẹ̀ wọ́n, èmi sì ń lépa Seba àti Salmunna àwọn ọba Midiani.” Ṣùgbọ́n àwọn ìjòyè Sukkoti fèsì pé ṣé ọwọ́ rẹ ti tẹ Seba àti Salmunna náà ni? Èéṣe tí àwa yóò ṣe fún àwọn ológun rẹ ní oúnjẹ? Gideoni dá wọn lóhùn pé, “Ó dára, nígbà tí Olúwa bá fi Seba àti Salmunna lé mi lọ́wọ́ tán èmi yóò fi ẹ̀gún ijù àti ẹ̀gún òṣùṣú ya ẹran-ara yín.” Láti ibẹ̀, ó lọ sí Penieli ó sì bẹ̀ wọ́n bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, ṣùgbọ́n àwọn náà dá a lóhùn bí àwọn ará Sukkoti ti dá a lóhùn. Nígbà náà ni ó sọ fún àwọn ọkùnrin Penieli pé, “Nígbà tí mo bá ṣẹ́gun tí mo sì padà dé ní àlàáfíà, èmi yóò wó ilé ìṣọ́ yìí.” Ní àsìkò náà Seba àti Salmunna wà ní Karkori pẹ̀lú ọmọ-ogun wọn tí ó tó ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (15,000) ọkùnrin, àwọn wọ̀nyí ni ó ṣẹ́kù nínú gbogbo ogun àwọn ènìyàn apá ìlà-oòrùn, nítorí ọ̀kẹ́ mẹ́fà (120,000) ọkùnrin tí ó fi idà jà ti kú ní ojú ogun. Gideoni gba ọ̀nà tí àwọn darandaran máa ń rìn ní apá ìhà ìlà-oòrùn Noba àti Jogbeha ó sì kọjú ogun sí àwọn ọmọ-ogun náà nítorí wọ́n ti túra sílẹ̀. Seba àti Salmunna, àwọn ọba Midiani méjèèjì sá, ṣùgbọ́n Gideoni lépa wọn ó sì mú wọn, ó run gbogbo ogun wọn. Gideoni ọmọ Joaṣi gba ọ̀nà ìgòkè Heresi padà sẹ́yìn láti ojú ogun. Ó mú ọ̀dọ́mọkùnrin kan ará Sukkoti, ó sì béèrè àwọn ìbéèrè ní ọwọ́ rẹ̀, ọ̀dọ́mọkùnrin náà sì kọ orúkọ àwọn ìjòyè Sukkoti mẹ́tàdínlọ́gọ́rin fún un tí wọ́n jẹ́ àgbàgbà ìlú náà. Nígbà náà ni Gideoni wá ó sọ fún àwọn ọkùnrin Sukkoti pé, “Seba àti Salmunna nìwọ̀nyí nípa àwọn tí ẹ̀yin fi mí ṣẹ̀fẹ̀ nígbà tí ẹ wí pé, ‘Ṣé ó ti ṣẹ́gun Seba àti Salmunna? Èéṣe tí àwa ó fi fún àwọn ọmọ-ogun rẹ tí ó ti rẹ̀ ní oúnjẹ?’ ” Ó mú àwọn àgbàgbà ìlú náà, ó sì fi kọ́ àwọn Sukkoti lọ́gbọ́n nípa jíjẹ wọ́n ní yà pẹ̀lú àwọn ẹ̀gún ijù àti ẹ̀gún ọ̀gàn. Ó wó ilé ìṣọ́ Penieli, ó sì pa àwọn ọkùnrin ìlú náà. Gideoni bi Seba àti Salmunna pé, “Irú ọkùnrin tí ẹ pa ní Tabori, báwo ni wọ́n ṣe rí?” “Àwọn ọkùnrin náà dàbí rẹ ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn dàbí ọmọ ọba,” ní ìdáhùn wọn. Gideoni dáhùn pé, “Arákùnrin mi ni wọ́n, àwọn ọmọ ìyá mi. Mo fi Olúwa búra, bí ó bá ṣe pé ẹ dá ẹ̀mí wọn sí, èmi náà ò nípa yín.” Ó yí padà sí Jeteri, ọmọ rẹ̀ tí ó dàgbà jùlọ, ó wí fún un pé, “Pa wọ́n!” Ṣùgbọ́n Jeteri kò fa idà rẹ̀ yọ láti pa wọ́n nítorí ó jẹ́ ọ̀dọ́mọdé ẹ̀rù sì bà á láti pa wọ́n. Seba àti Salmunna dá Gideoni lóhùn pé, “Wá pa wá fún raàrẹ, ‘Nítorí bí ènìyàn bá ti rí bẹ́ẹ̀ ni agbára rẹ̀ yóò rí.’ ” Gideoni bọ́ síwájú ó sì pa wọ́n, ó sì mú ohun ọ̀ṣọ́ tí ó wà ní ọrùn àwọn ìbákasẹ wọn. Efodu Gideoni Àwọn ará Israẹli wí fún Gideoni pé, “Jọba lórí wa—ìwọ, àwọn ọmọ rẹ àti àwọn ọmọ ọmọ rẹ pẹ̀lú, nítorí tí ìwọ ti gbà wá lọ́wọ́ àwọn ará Midiani.” Ṣùgbọ́n Gideoni dá wọn lóhùn pé, “Èmi kì yóò jẹ ọba lórí yín, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ mi kì yóò jẹ ọba lórí yín. Olúwa ni yóò jẹ ọba lórí yín.” Gideoni sì wí pé, “Mo ní ẹ̀bẹ̀ kan tí mo fẹ́ bẹ̀ yín kí ẹnìkọ̀ọ̀kan yín fún mi ní yẹtí kọ̀ọ̀kan láti inú ohun ti ó kàn yín láti inú ìkógun.” (Àṣà àwọn ará Iṣmaeli ni láti máa fi yẹtí wúrà sétí.) Wọ́n dáhùn pé, “Tayọ̀tayọ̀ ni àwa yóò fi wọ́n sílẹ̀.” Wọ́n tẹ́ aṣọ kan sílẹ̀ ọkùnrin kọ̀ọ̀kan sì ń sọ yẹtí kọ̀ọ̀kan tí ó kàn wọ́n láti ibi ìkógun síbẹ̀. Ìwọ̀n òrùka wúrà tí ó béèrè fún tó ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀sán (1,700) ìwọ̀n ṣékélì, láìka àwọn ohun ọ̀ṣọ́ àti ohun sísorọ̀ tí ó wà lára ìlẹ̀kẹ̀ ọrùn àti aṣọ elése àlùkò tí àwọn ọba Midiani ń wọ̀ tàbí àwọn ẹ̀wọ̀n tí ó wà ní ọrùn àwọn ìbákasẹ wọn. Gideoni fi àwọn wúrà náà ṣe efodu èyí tí ó gbé kalẹ̀ ní Ofira ìlú rẹ̀. Àwọn ọmọ Israẹli sì sọ ara wọn di àgbèrè nípa sínsin-ín ní ibẹ̀. Ó sì di ìdẹ̀kùn fún Gideoni àti ìdílé rẹ̀. Ikú Gideoni Báyìí ni a ṣe tẹrí àwọn ará Midiani ba níwájú àwọn ọmọ Israẹli bẹ́ẹ̀ ni wọn kò tún gbé orí mọ́. Ní ọjọ́ Gideoni, Israẹli wà ní àlàáfíà fún ogójì ọdún. Jerubbaali ọmọ Joaṣi padà lọ láti máa gbé ní ìlú rẹ̀. Àádọ́rin ọmọ ni Gideoni bí, nítorí ó ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìyàwó. Àlè rẹ̀, tó ń gbé ní Ṣekemu, pàápàá bí ọmọkùnrin kan fún un tí ó pe orúkọ rẹ̀ ní Abimeleki. Gideoni ọmọ Joaṣi kú ní ògbólógbòó ọjọ́ rẹ̀, ó sì pọ̀ ní ọjọ́ orí, wọ́n sì sin ín sí ibojì baba rẹ̀ ní Ofira ti àwọn ará Abieseri. Láìpẹ́ jọjọ lẹ́yìn ikú Gideoni ni àwọn ará Israẹli ṣe àgbèrè tọ Baali lẹ́yìn, wọ́n fi Baali-Beriti ṣe òrìṣà wọn. Wọn kò sì rántí Olúwa Ọlọ́run wọn, ẹni tí ó gbà wọ́n kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wọn gbogbo tí ó wà ní gbogbo àyíká wọn. Wọ́n kùnà láti fi inú rere hàn sí ìdílé Jerubbaali (èyí ni Gideoni) fún gbogbo oore tí ó ṣe fún wọn. Abimeleki Ní ọjọ́ kan Abimeleki ọmọ Jerubbaali lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn arákùnrin ìyá rẹ̀ ní Ṣekemu ó sì bá wọn sọ̀rọ̀ àti gbogbo àwọn ìbátan ìyá rẹ̀ wí pé, “Ẹ bi gbogbo àwọn ará Ṣekemu léèrè, ‘Èwo ló sàn fún un yín, ṣé kí gbogbo àwọn àádọ́rin ọmọ Jerubbaali jẹ ọba lórí yín ni tàbí kí ẹnìkan ṣoṣo ṣe àkóso yín?’ Ṣùgbọ́n ẹ rántí pé ẹran-ara yín àti ẹ̀jẹ̀ yín ni èmi ń ṣe.” Nígbà tí àwọn arákùnrin rẹ̀ sọ èyí ní etí àwọn ará Ṣekemu, ọkàn wọn fà sí àti tẹ̀lé Abimeleki torí, wọ́n sọ wí pé, “Arákùnrin wa ní í ṣe.” Wọ́n fún un ní àádọ́rin ṣékélì fàdákà láti ilé òrìṣà Baali-Beriti, Abimeleki fi owó náà gba àwọn jàǹdùkú àti aláìníláárí ènìyàn tí wọ́n sì di olùtẹ̀lé rẹ̀. Ó kó wọn lọ sí ilé baba rẹ̀ ní Ofira, níbẹ̀ ní orí òkúta kan ṣoṣo ni ó ti pa àádọ́rin nínú àwọn arákùnrin rẹ̀, àwọn Jerubbaali, ṣùgbọ́n Jotamu, àbíkẹ́yìn nínú àwọn ọmọ Jerubbaali, bọ́ yọ nítorí pé ó sá pamọ́. Gbogbo àwọn ará Ṣekemu àti àwọn ará Beti-Milo pàdé pọ̀ ní ẹ̀bá igi óákù ní ibi òpó ní Ṣekemu láti fi Abimeleki jẹ ọba. Nígbà tí wọ́n sọ ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀ yìí fún Jotamu, ó gun orí ṣóńṣó òkè Gerisimu lọ, ó sì ké lóhùn rara pé, “Ẹ tẹ́tí sí mi, ẹ̀yin àgbàgbà Ṣekemu, kí Ọlọ́run le tẹ́tí sí yín. Ní ọjọ́ kan àwọn igi jáde lọ láti fi òróró yan ọba fún ara wọn. Wọ́n pe igi Olifi pé, ‘Wá ṣe ọba wa.’ “Ṣùgbọ́n igi Olifi dá wọn lóhùn pé, ‘Èmi yóò ha fi òróró mi sílẹ̀ èyí tí a ń lò láti fi ọ̀wọ̀ fún àwọn ọlọ́run àti ènìyàn kí èmi sì wá ṣe olórí àwọn igi?’ “Àwọn igi sọ fún igi ọ̀pọ̀tọ́ pé, ‘Wá jẹ ọba ní orí wa.’ “Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀tọ́ dá wọn lóhùn pé, ‘Kí èmi fi èso mi tí ó dára tí ó sì dùn sílẹ̀ láti wá ṣe olórí àwọn igi?’ “Àwọn igi sì tún sọ fún àjàrà pé, ‘Wá, kí o ṣe ọba wa.’ “Ṣùgbọ́n àjàrà dáhùn pé, ‘Ṣé kí èmi dẹ́kun àti máa so èso wáìnì mi èyí tí ó ń mú inú Ọlọ́run àti àwọn ènìyàn dùn láti máa ṣe olórí àwọn igi?’ “Ní ìparí gbogbo àwọn igi lọ bá igi ẹ̀gún wọ́n sì sọ fún un pé, ‘Wá kí ó ṣe ọba wa.’ “Igi ẹ̀gún dá àwọn igi lóhùn pé, ‘Bí olóòtítọ́ ni ẹ bá fẹ́ yàn mí ní ọba yín. Ẹ sá àsálà sí abẹ́ ibòòji mi; ṣùgbọ́n tí kì í bá ṣe bẹ́ẹ̀ jẹ́ kí iná jáde láti inú igi ẹ̀gún kí ó sì jó àwọn igi kedari àti ti Lebanoni run!’ “Báyìí tí ó bá jẹ́ pé ẹ̀yin ṣe ohun tí ó ní ọlá àti pẹ̀lú ẹ̀mí òtítọ́ ní fífi Abimeleki jẹ ọba, tí ó bá ṣe pé ohun tí ó tọ́ ni ẹ ṣe sí Jerubbaali àti ìdílé rẹ̀, bí ẹ bá san ẹ̀san tó yẹ fún un. Nítorí pé baba mi jà nítorí yín, ó fi ẹ̀mí rẹ̀ wéwu láti gbà yín sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ará Midiani; ṣùgbọ́n lónìí ẹ̀yin ṣọ̀tẹ̀ sí ilé baba mi, ní orí òkúta kan ṣoṣo ni ẹ ti pa àwọn àádọ́rin ọmọ rẹ̀, ẹ̀yin sì ti fi Abimeleki ọmọ ẹrúbìnrin rẹ̀ jẹ ọba lórí àwọn ènìyàn Ṣekemu nítorí tí ó jẹ́ arákùnrin yín. Bí ohun tí ẹ ṣe sí Jerubbaali àti ìdílé rẹ̀ bá jẹ́ ohun tí ó yẹ, tí ẹ sì ṣe òtítọ́ inú sí i, kí ẹ ní ayọ̀ nínú Abimeleki kí òun náà sì ní ayọ̀ nínú yín. Ṣùgbọ́n tí kò bá ṣe bẹ́ẹ̀ jẹ́ kí iná jó jáde wá láti ọ̀dọ̀ Abimeleki kí ó sì jó yín run. Ẹ̀yin ará Ṣekemu àti ará Beti-Milo, kí iná pẹ̀lú jáde láti ọ̀dọ̀ yín wá ẹ̀yin ará Ṣekemu àti ará Beti-Milo kí ó sì jó Abimeleki run.” Lẹ́yìn tí Jotamu ti sọ èyí tan, ó sá àsálà lọ sí Beeri, ó sì gbé níbẹ̀ nítorí ó bẹ̀rù arákùnrin rẹ̀ Abimeleki. Lẹ́yìn tí Abimeleki ti ṣe àkóso Israẹli fún ọdún mẹ́ta, Ọlọ́run rán ẹ̀mí búburú sáàárín Abimeleki àti àwọn ará Ṣekemu, àwọn ẹni tí ó hu ìwà ọ̀tẹ̀. Ọlọ́run ṣe èyí láti gbẹ̀san àwọn ìwà búburú, àti ìtàjẹ̀ sílẹ̀ àwọn àádọ́rin ọmọ Jerubbaali lára Abimeleki arákùnrin wọn àti lára àwọn ènìyàn Ṣekemu, ẹni tí ó ràn án lọ́wọ́ láti pa àwọn arákùnrin rẹ̀. Nítorí ìkórìíra tí wọ́n ni sí àwọn olórí, ni Ṣekemu dẹ àwọn ènìyàn sí àwọn orí òkè láti máa dá àwọn ènìyàn tó ń kọjá lọ́nà, kí wọn sì máa jà wọ́n lólè, àwọn kan ló sọ èyí fún Abimeleki. Gaali ọmọ Ebedi àti àwọn arákùnrin rẹ̀ wá sí Ṣekemu, àwọn ará Ṣekemu sì gbẹ́kẹ̀lé wọn, wọ́n sì fi inú tán wọn. Lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n jáde lọ sí oko, wọ́n sì ṣa èso àjàrà wọn jọ, wọ́n fún èso àjàrà náà, wọ́n sì ṣe àjọ̀dún nínú ilé òrìṣà wọn. Nígbà tí wọ́n ń jẹ tí wọ́n ń mu wọ́n fi Abimeleki ré. Gaali ọmọ Ebedi dáhùn pé, “Ta ni Abimeleki tàbí ta ni Ṣekemu tí àwa ó fi sìn ín? Ọmọ Jerubbaali kọ́ ní ṣe tàbí Sebulu kọ́ ní igbákejì rẹ̀? Ẹ má sin àwọn ará Hamori baba àwọn ará Ṣekemu, èéṣe tí a ó fi sin Abimeleki? Ìbá se pé àwọn ènìyàn yìí wà ní abẹ́ ìṣàkóso mi ni! Èmi ìbá bọ́ àjàgà rẹ̀ kúrò ní ọrùn yín. Èmi yóò wí fún Abimeleki pé, ‘Kó gbogbo àwọn ogun rẹ jáde láti jà.’ ” Nígbà tí Sebulu, alákòóso ìlú náà gbọ́ ohun tí Gaali ọmọ Ebedi sọ, inú bí i gidigidi. Ó ránṣẹ́ sí Abimeleki pé, “Gaali ọmọ Ebedi àti àwọn arákùnrin rẹ̀ wá láti máa gbé ní Ṣekemu ṣùgbọ́n, wọ́n ń rú àwọn ènìyàn sókè láti ṣọ̀tẹ̀ sí ọ. Wá ní òru kí ìwọ àti àwọn ogun rẹ sá pamọ́ dè wọ́n nínú igbó. Ní òwúrọ̀ kùtùkùtù bí oòrùn ti ń yọ ìwọ yóò wọ inú ìlú náà lọ láti bá a jà. Yóò sì ṣe nígbà tí Gaali àti àwọn ogun rẹ̀ tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ bá jáde sí ọ láti bá ọ jà, ìwọ yóò ṣe ohunkóhun tí o bá fẹ́ sí wọn.” Abimeleki àti gbogbo àwọn ogun rẹ̀ sì jáde ní òru, wọ́n sì sá pamọ́ sí ọ̀nà mẹ́rin yí Ṣekemu ká. Gaali ọmọ Ebedi jáde síta, ó sì dúró ní ẹnu-ọ̀nà ibodè ìlú náà ní àkókò tí Abimeleki àti àwọn ọmọ-ogun rẹ̀ jáde kúrò níbi tí wọn sá pamọ́ sí. Nígbà tí Gaali rí àwọn ènìyàn náà, ó sọ fún Sebulu pé, “Wò ó, àwọn ènìyàn ń ti orí òkè sọ̀kalẹ̀ wá!” Sebulu sì wí fún un pé, “Òjìji òkè wọ̀n-ọn-nì ni ìwọ rí bi ẹni pé ènìyàn.” Gaali ké ó ní, “Wòkè, àwọn ènìyàn ń tọ̀ wá bọ̀ láti agbede-méjì ilẹ̀ wá àti ẹ̀gbẹ́ kan sì ń ti ọ̀nà igi óákù Meonenimu wá.” Nígbà náà ni Sebulu dá a lóhùn pé, “Níbo ni ẹnu tí ó ń ṣe ni wà báyìí. Ṣe bí o wí pé, ‘Ta ni Abimeleki tí àwa ó fi máa sìn ín?’ Àwọn ẹni tí ó gàn án kọ́ nìyí? Jáde lọ kí o sì bá wọn jà!” Gaali sì síwájú àwọn ogun ará Ṣekemu lọ kọjú Abimeleki láti bá wọn jagun. Abimeleki sì lé e, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọmọ-ogun ṣubú wọ́n sì gbọgbẹ́ bí wọ́n ṣe ń sálọ, títí dé ẹnu-ọ̀nà ibùdó ìlú náà. Abimeleki dúró sí Aruma, nígbà tí Sebulu lé Gaali àti àwọn arákùnrin rẹ̀ kúrò ni Ṣekemu, kò sì jẹ́ kí wọ́n gbé Ṣekemu mọ́. Ní ọjọ́ kejì àwọn ará Ṣekemu sì jà lọ́ sí oko, ẹnìkan ló ṣe òfófó rẹ̀ fún Abimeleki. Ó kó àwọn ènìyàn rẹ̀, ó pín wọn sí ẹgbẹ́ mẹ́ta ó sì sá pamọ́ sí inú oko. Nígbà tí ó sì rí tí àwọn ènìyàn náà ń jáde kúrò nínú ìlú, ó dìde ó gbóguntì wọ́n. Abimeleki àti àwọn ọmọ-ogun tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ sáré síwájú, wọ́n gba ẹnu ibodè ìlú náà, wọ́n sì dúró níbẹ̀. Àwọn ẹgbẹ́ méjì tókù sì sáré sí àwọn tó wà ní oko wọ́n sì gbóguntì wọ́n. Ní gbogbo ọjọ́ náà ni Abimeleki fi bá àwọn ará ìlú náà jà, ó sì ṣẹ́gun wọn, ó sì pa àwọn ènìyàn ìlú náà ó wó ìlú náà palẹ̀ pátápátá ó sì fọ́n iyọ̀ sí i. Àwọn ènìyàn ilé ìṣọ́ Ṣekemu gbọ́ ohun tí ó ṣẹlẹ̀, wọ́n sálọ fún ààbò sí inú ilé ìṣọ́ òrìṣà El-Beriti. Nígbà tí wọ́n sọ fún Abimeleki pé gbogbo àwọn ènìyàn ilé ìṣọ́ Ṣekemu kó ara wọn jọ pọ̀. Abimeleki àti gbogbo àwọn ọmọ-ogun rẹ̀ gun òkè Salmoni lọ. Ó gé àwọn ẹ̀ka díẹ̀ pẹ̀lú àáké, ó gbé àwọn ẹ̀ka wọ̀nyí sí èjìká rẹ̀. Ó sọ fún àwọn ọmọ-ogun rẹ̀ pé, “Ẹ ṣe ohun tí ẹ rí tí mo ń ṣe yìí ní kíákíá.” Báyìí gbogbo àwọn ọkùnrin tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ gé àwọn ẹ̀ka igi wọn tẹ̀lé Abimeleki. Wọ́n kó wọn ti ilé ìṣọ́ agbára níbi tí àwọn ènìyàn sá pamọ́ sí wọ́n sì fi iná sí i, tóbẹ́ẹ̀ tí gbogbo àwọn ọkùnrin ilé ìṣọ́ Ṣekemu fi kú pẹ̀lú. Gbogbo àwọn ènìyàn náà tí ó tó ẹgbẹ̀rún (1,000) ènìyàn lọ́kùnrin àti lóbìnrin sì kú. Abimeleki tún lọ sí Tebesi, ó yí ìlú náà ká pẹ̀lú àwọn ọmọ-ogun, ó sì ṣẹ́gun rẹ̀. Ilé ìṣọ́ kan tí ó ní agbára sì wà nínú ìlú náà. Gbogbo àwọn ènìyàn ìlú náà ọkùnrin àti obìnrin sá sínú ilé ìṣọ́ náà. Wọ́n ti ara wọn mọ́ ibẹ̀ wọ́n sì sálọ sí inú àjà ilé ìṣọ́ náà. Abimeleki lọ sí ìsàlẹ̀ ilé ìṣọ́ náà, ó sì ń bá a jà. Ṣùgbọ́n bí ó ti súnmọ́ ẹnu-ọ̀nà ilé ìṣọ́ náà láti dáná sun ún, obìnrin kan sọ ọmọ ọlọ lu Abimeleki lórí, ó sì fọ́ ọ ní agbárí. Ní ojú kan náà ni ó pe ẹni tí ó ru àpáta rẹ̀ pé, “Yára yọ idà rẹ kí o sì pa mí, kí wọn má ba à sọ pé, ‘Obìnrin ni ó pa á.’ ” Ọ̀dọ́mọkùnrin náà sì fi ọ̀kọ̀ gún un, ó sì kú. Nígbà tí àwọn ará Israẹli rí i pé Abimeleki kú, olúkúlùkù wọn padà sí ilé rẹ̀. Báyìí ni Ọlọ́run san ẹ̀san ìwà búburú ti Abimeleki hù sí baba rẹ̀ ní ti pípa tí ó pa, àwọn àádọ́rin arákùnrin rẹ̀. Ọlọ́run jẹ́ kí ìwà búburú àwọn ará Ṣekemu pẹ̀lú padà sí orí wọn. Ègún Jotamu ọmọ Jerubbaali pàápàá wá sí orí wọn. Tola Lẹ́yìn ikú Abimeleki, ọkùnrin kan láti ẹ̀yà Isakari tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Tola ọmọ Pua, ọmọ Dodo, dìde láti gba Israẹli sílẹ̀. Ní Ṣamiri tí ó wà ní òkè Efraimu ni ó gbé. Ó ṣe àkóso Israẹli ní ọdún mẹ́tàlélógún. Nígbà tí ó kú wọ́n sìn ín sí Ṣamiri. Jairi Jairi ti ẹ̀yà Gileadi ni ó dìde lẹ́yìn rẹ̀, ó ṣàkóso Israẹli ní ọdún méjìlélógún. Àwọn ọgbọ̀n ọmọ tí ó n gun ọgbọ̀n kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́. Wọ́n ṣe àkóso ọgbọ̀n ìlú ní Gileadi, tí a pe orúkọ wọn ní Hafoti-Jairi títí di òní. Nígbà tí Jairi kú wọ́n sin ín sí Kamoni. Jefta Àwọn ọmọ Israẹli sì túnṣe ohun tí ó burú lójú Olúwa. Wọ́n sin Baali àti Aṣtoreti àti àwọn òrìṣà Aramu, òrìṣà Sidoni, òrìṣà Moabu, òrìṣà àwọn ará Ammoni àti òrìṣà àwọn ará Filistini. Nítorí àwọn ará Israẹli kọ Olúwa sílẹ̀ tí wọn kò sì sìn ín mọ́, ó bínú sí wọn, ó fi wọ́n sílẹ̀ fún àwọn ará Filistini àti Ammoni láti jẹ ẹ́ ní ìyà. Ní ọdún náà, wọ́n tú wọn ká wọ́n sì pọ́n wọn lójú. Fún ọdún méjìdínlógún ni wọ́n fi ni gbogbo àwọn ọmọ Israẹli tí ó wà ní ìlà-oòrùn odò Jordani ní ilẹ̀ àwọn ará Amori lára (èyí nì ní Gileadi). Àwọn ará Ammoni sì la odò Jordani kọjá láti bá Juda, Benjamini àti àwọn ará ilé Efraimu jagun: Israẹli sì dojúkọ ìpọ́njú tó lágbára. Nígbà tí èyí ti ṣẹlẹ̀ àwọn ọmọ Israẹli ké pe Olúwa wí pé, “Àwa ti ṣẹ̀ sí ọ, nítorí pé àwa ti kọ Ọlọ́run wa sílẹ̀, àwa sì ń sin Baali.” Olúwa sì dáhùn pé, “Ǹjẹ́ nígbà tí àwọn ará Ejibiti, Amori, Ammoni, Filistini, àwọn ará Sidoni, Amaleki pẹ̀lú Maoni ni yín lára, tí ẹ sì ké pè mí fún ìrànlọ́wọ́, ǹjẹ́ èmi kò gbà yín sílẹ̀ kúrò ní ọwọ́ wọn? Síbẹ̀síbẹ̀ ẹ̀yin kọ̀ mí sílẹ̀ láti sin àwọn ọlọ́run mìíràn, torí ìdí èyí, èmi kì yóò sì tún gbà yín mọ́. Ẹ lọ kí ẹ sì ké pe àwọn òrìṣà tí ẹ̀yin ti yàn fún ara yín. Jẹ́ kí wọn gbà yín sílẹ̀ ní àsìkò ìpọ́njú yín!” Àwọn ọmọ Israẹli sì dá Olúwa lóhùn pé, “Àwa ti ṣẹ̀, ṣe ohun tí ó bá fẹ́ pẹ̀lú wa, ṣùgbọ́n, jọ̀wọ́ gbà wá sílẹ̀ náání àsìkò yìí.” Nígbà náà ni wọ́n kó gbogbo ọlọ́run àjèjì tí ó wà láàrín wọn kúrò wọ́n sì sin Olúwa nìkan, ọkàn rẹ̀ kò sì le gbàgbé ìrora Israẹli mọ́. Nígbà tí àwọn ará Ammoni kógun jọ ní Gileadi láti bá Israẹli jà, àwọn ọmọ Israẹli gbárajọpọ̀, wọ́n sì tẹ̀dó ogun ní Mispa. Àwọn ìjòyè: aṣíwájú àwọn ará Gileadi wí fún ará wọn pé, “Ẹnikẹ́ni tí yóò kọ́ ṣígun si àwọn ará Ammoni ni yóò jẹ́ orí fún gbogbo àwọn tí ń gbé ní Gileadi.” Jefta ará Gileadi jẹ́ akọni jagunjagun. Gileadi ni baba rẹ̀; ṣùgbọ́n ìyá rẹ̀ jẹ́ panṣágà. Ìyàwó Gileadi sì bí àwọn ọmọkùnrin fún un, nígbà tí àwọn ọmọkùnrin wọ̀nyí dàgbà, wọ́n rán Jefta jáde kúrò nílé, wọ́n wí pé, “Ìwọ kì yóò ní ogún kankan ní ìdílé wa, nítorí pé ìwọ jẹ́ ọmọ obìnrin mìíràn.” Jefta sì sá kúrò lọ́dọ̀ àwọn arákùnrin rẹ̀, ó sì pàgọ́ sí ilẹ̀ Tobu, ó sì ń gbé níbẹ̀, níbẹ̀ ni àwọn ènìyàn kan ti ń tẹ òfin lójú parapọ̀ láti máa tẹ̀lé e kiri. Ní àsìkò kan, nígbà tí àwọn ará Ammoni dìde ogun sí àwọn Israẹli, Ó sì ṣe nígbà tí àwọn Ammoni bá Israẹli jagun, àwọn àgbàgbà Gileadi tọ Jefta lọ láti pè é wá láti ilẹ̀ Tobu. Wọ́n wí fún Jefta wí pé, “Wá kí o sì jẹ́ olórí ogun wa kí a lè kọjú ogun sí àwọn ará Ammoni.” Jefta sì wí fún àwọn àgbàgbà Gileadi pé, “Ṣé kì í ṣe pé ẹ kórìíra mi tí ẹ sì lé mi kúrò ní ilé baba mi? Kí ló dé tí ẹ fi tọ̀ mí wá báyìí nígbà tí ẹ wà nínú wàhálà?” Àwọn àgbà Gileadi sì wí fún Jefta pé, “Nítorí rẹ̀ ni àwa fi yípadà sí ọ báyìí: tẹ̀lé wa, kí a lè dojú ìjà kọ àwọn ará Ammoni, ìwọ yóò sì jẹ olórí wa àti gbogbo àwa tí ń gbé ní Gileadi.” Jefta sì wí fún àwọn àgbàgbà Gileadi pé, “Bí ẹ̀yin bá mú mi padà láti bá àwọn ará Ammoni jà àti tí Olúwa bá fi wọ́n lé mi lọ́wọ́: ṣe èmi yóò jẹ́ olórí yín nítòótọ́?” Àwọn àgbàgbà Gileadi sì wí fún Jefta pé, “Àwa fi Olúwa ṣe ẹlẹ́rìí: àwa yóò ṣe ohunkóhun tí o bá wí.” Jefta sì tẹ̀lé àwọn àgbàgbà Gileadi lọ, àwọn ènìyàn náà sì fi ṣe olórí àti ọ̀gágun wọn. Jefta sì tún sọ gbogbo àwọn ọ̀rọ̀ tí ó ti sọtẹ́lẹ̀ níwájú Olúwa ní Mispa. Jefta sì rán àwọn oníṣẹ́ sí ọba àwọn ará Ammoni pé, “Kí ni ẹ̀sùn tí o ní sí wa láti fi kàn wá tí ìwọ fi dojú ìjà kọ ilẹ̀ wa?” Ọba àwọn Ammoni dá àwọn oníṣẹ́ Jefta lóhùn pé, “Nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli jáde ti Ejibiti wá. Wọ́n gba ilẹ̀ mi láti Arnoni dé Jabbok, àní dé Jordani, nítorí náà dá wọn padà lọ ní àlàáfíà àti ní pẹ̀lẹ́ kùtù.” Jefta sì tún ránṣẹ́ padà sí ọba àwọn ará Ammoni ó sì wí fún un pé, “Báyìí ni Jefta wí: àwọn ọmọ Israẹli kò gba ilẹ̀ Moabu tàbí ilẹ̀ àwọn ará Ammoni. Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n jáde kúrò ní Ejibiti àwọn ọmọ Israẹli la aginjù kọjá lọ sí ọ̀nà Òkun Pupa wọ́n sì lọ sí Kadeṣi. Nígbà náà Israẹli rán àwọn oníṣẹ́ sí ọba Edomu pé, ‘Gbà fún wa láti gba ilẹ̀ rẹ̀ kọjá,’ ṣùgbọ́n ọba Edomu kò fetí sí wọn. Wọ́n tún ránṣẹ́ sí ọba Moabu bákan náà òun náà kọ̀. Nítorí náà Israẹli dúró sí Kadeṣi. “Wọ́n rin aginjù kọjá, wọ́n pẹ́ àwọn ilẹ̀ Edomu àti ti Moabu sílẹ̀, nígbà tí wọ́n gba apá ìlà-oòrùn Moabu, wọ́n sì tẹ̀dó sí apá kejì Arnoni. Wọn kò wọ ilẹ̀ Moabu, nítorí pé ààlà rẹ̀ ni Arnoni wà. “Nígbà náà ni Israẹli rán àwọn oníṣẹ́ sí Sihoni ọba àwọn ará Amori, ẹni tí ń ṣe àkóso ní Heṣboni, wọ́n sì wí fún un pé, ‘Jẹ́ kí a la ilẹ̀ rẹ kọjá lọ sí ibùgbé wa.’ Ṣùgbọ́n Sihoni kò gba Israẹli gbọ́ (kò fọkàn tán an) láti jẹ́ kí ó kọjá. Ó kó gbogbo àwọn ènìyàn rẹ̀ jọ, ó sì tẹ̀dó sí Jahisa láti bá Israẹli jagun. Olúwa Ọlọ́run Israẹli sì fi Sihoni àti àwọn ọmọ-ogun rẹ̀ lé Israẹli lọ́wọ́, wọ́n sì ṣẹ́gun wọn. Israẹli sì gba gbogbo ilẹ̀ àwọn ará Amori tí wọ́n ń gbé ní agbègbè náà, wọ́n gbà gbogbo agbègbè àwọn ará Amori, láti Arnoni tí ó fi dé Jabbok, àti láti aginjù dé Jordani. “Wàyí o, nígbà tí Olúwa Ọlọ́run Israẹli, ti lé àwọn ará Amori kúrò níwájú àwọn ènìyàn rẹ̀; Israẹli, ẹ̀tọ́ wo ni ẹ ní láti gba ilẹ̀ náà? Ǹjẹ́ ìwọ kì yóò ha gba èyí tí Kemoṣi òrìṣà rẹ fi fún ọ? Bákan náà àwa yóò gba èyíkéyìí tí Olúwa Ọlọ́run wa fi fún wa. Ǹjẹ́ ìwọ ha sàn ju Balaki ọmọ Sippori, ọba Moabu lọ? Ǹjẹ́ òun ha ṣe gbólóhùn asọ̀ pẹ̀lú Israẹli bí? Tàbí òun dojú ìjà kọ wọ́n rí bí? Fún ọ̀ọ́dúnrún (300) ọdún ni Israẹli fi ṣe àtìpó ní Heṣboni, Aroeri àti àwọn ìgbèríko àti àwọn ìlú tí ó yí Arnoni ká. Èéṣe tí ìwọ kò fi gbà wọ́n padà ní àsìkò náà? Èmi kọ́ ni ó ṣẹ̀ ọ́, ṣùgbọ́n ìwọ ni ó ṣẹ̀ mí nípa kíkógun tọ̀ mí wá. Jẹ́ kí Olúwa olùdájọ́, ṣe ìdájọ́ lónìí láàrín àwọn ọmọ Israẹli àti àwọn ará Ammoni.” Ṣùgbọ́n ọba àwọn Ammoni kò fetí sí iṣẹ́ tí Jefta rán sí i. Ẹ̀mí Olúwa sì bà lé Jefta òun sì la Gileadi àti Manase kọjá. Ó la Mispa àti Gileadi kọjá láti ibẹ̀, ó tẹ̀síwájú láti bá àwọn ará Ammoni jà. Jefta sì jẹ́ ẹ̀jẹ́ fún Olúwa pé, “Bí ìwọ bá fi àwọn ará Ammoni lé mi lọ́wọ́, yóò sì ṣe, ohunkóhun tí ó bá jáde láti ẹnu-ọ̀nà ilé mi láti wá pàdé mi, nígbà tí èmi bá ń padà bọ̀ láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Ammoni ní àlàáfíà, yóò jẹ́ ti Olúwa, èmi yóò sì fi rú ẹbọ bí ọrẹ ẹbọ sísun.” Jefta sì jáde lọ láti bá àwọn ará Ammoni jagun, Olúwa sì fi wọ́n lé e lọ́wọ́. Òun sì ṣẹ́gun wọn, ó sì pa wọ́n ní à pa tán láti Aroeri títí dé agbègbè Minniti, ó jẹ́ ogún ìlú, títí dé Abeli-Keramimu. Báyìí ni Israẹli ti ṣẹ́gun àwọn ará Ammoni. Nígbà tí Jefta padà sí ilé rẹ̀ ní Mispa, wò ó, ọmọ rẹ̀ obìnrin ń jáde bọ̀ wá pàdé rẹ̀ pẹ̀lú timbrili àti ijó. Òun ni ọmọ kan ṣoṣo tí ó ní: kò ní ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin mìíràn yàtọ̀ sí òun nìkan. Ní ìgbà tí ó rí i ó fa aṣọ rẹ̀ ya ní ìbànújẹ́, ó sì ké wí pé, “Háà! Ọ̀dọ́mọbìnrin mi, ìwọ fún mi ní ìbànújẹ́ ọkàn ìwọ sì rẹ̀ mí sílẹ̀ gidigidi, nítorí pé èmi ti ya ẹnu mi sí Olúwa ní ẹ̀jẹ́, èmi kò sì le sẹ́ ẹ̀jẹ́ mi.” Ọmọ náà sì dáhùn pé, “Baba mi bí ìwọ bá ti jẹ́ ẹ̀jẹ́ fún Olúwa, ṣe sí mi gẹ́gẹ́ bí ìlérí rẹ, ní báyìí tí Olúwa ti gba ẹ̀san fún ọ lára àwọn ọ̀tá rẹ, àwọn ará Ammoni. Ṣùgbọ́n yọ̀ǹda ìbéèrè kan yìí fún mi, gbà mí láààyè oṣù méjì láti rìn ká orí àwọn òkè, kí n sọkún pẹ̀lú àwọn ẹlẹgbẹ́ mi torí mo jẹ́ wúńdíá tí n kò sì ní lè ṣe ìgbéyàwó.” Jefta dá lóhùn pé, “Ìwọ lè lọ.” Ó sì gbà á láààyè láti lọ fún oṣù méjì. Òun àti àwọn ọmọbìnrin yòókù lọ sí orí àwọn òkè, wọ́n sọkún nítorí pé kì yóò lè ṣe ìgbéyàwó. Lẹ́yìn oṣù méjì náà, ó padà tọ baba rẹ̀ wá òun sì ṣe sí i bí ẹ̀jẹ́ tí ó ti jẹ́. Ọmọ náà sì jẹ́ wúńdíá tí kò mọ ọkùnrin rí. Èyí sì bẹ̀rẹ̀ àṣà kan ní Israẹli wí pé ní ọjọ́ mẹ́rin láàrín ọdún àwọn obìnrin Israẹli a máa lọ láti ṣọ̀fọ̀ àti ṣe ìrántí ọmọbìnrin Jefta ti Gileadi. Jefta àti Efraimu Àwọn ọkùnrin Efraimu pe àwọn ológun wọn jáde, wọ́n sì rékọjá sí ìhà àríwá, wọ́n sì bi Jefta pé, “Èéṣe tí o fi lọ bá àwọn ará Ammoni jagun láì ké sí wa láti bá ọ lọ? Àwa yóò sun ilé rẹ mọ́ ọ lórí.” Jefta dáhùn pé, “Èmi àti àwọn ènìyàn ní ìyọnu ńlá pẹ̀lú àwọn ará Ammoni, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo pè yín, ẹ̀yin kò gbà mí sílẹ̀ ní ọwọ́ wọn. Nígbà tí mo rí i pé ẹ̀yin kò gbà mí, mo fi ẹ̀mí mi wéwu. Mó sì gòkè lọ láti bá àwọn ará Ammoni jà, Olúwa sì fún mi ní ìṣẹ́gun lórí wọn, èéṣe báyìí tí ẹ fi dìde wá lónìí láti bá mi jà?” Nígbà náà ni Jefta kó gbogbo ọkùnrin Gileadi jọ, ó sì bá Efraimu jà. Àwọn ọkùnrin Gileadi sì kọlù Efraimu, nítorí wọ́n ti sọtẹ́lẹ̀ pé, “Ẹ̀yin ará Gileadi jẹ́ àsáwọ̀ àwọn ará Efraimu àti ti Manase.” Àwọn ará Gileadi gba à bá wọ odò Jordani tí wọ́n máa gbà lọ sí Efraimu, nígbàkígbà tí àwọn ará Efraimu bá wí pé, “Jẹ́ kí ń sálọ sí òkè,” lọ́hùn ún àwọn ará Gileadi yóò bi í pé, “Ṣé ará Efraimu ni ìwọ ń ṣe?” Tí ó bá wí pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́,” wọ́n ó wí fún un pé, “Ó dá à wí pé ‘Ṣibolẹti.’ ” Tí ó bá ní, “Sibolẹti,” torí pé kò ní mọ̀ ọ́n pé dáradára, wọ́n á mú un wọn, a sì pa á ni à bá wọ odò Jordani. Àwọn ará Efraimu tí wọn pa ní àkókò yìí jẹ́ ẹgbẹ̀rún méjìlélógójì (42,000) ọkùnrin. Jefta ṣe ìdájọ́ Israẹli ní ọdún mẹ́fà. Lẹ́yìn náà Jefta ará Gileadi kú, wọ́n sì sin ín sí ọ̀kan nínú àwọn ìlú Gileadi. Ibsani, Eloni àti Abdoni Lẹ́yìn Jefta, Ibsani ará Bẹtilẹhẹmu ṣe ìdájọ́ àwọn ọmọ Israẹli. Ó ní ọgbọ̀n ọmọkùnrin àti ọgbọ̀n ọmọbìnrin fún àwọn tí kì í ṣe ẹ̀yà rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìyàwó, ó sì fẹ́ ọgbọ̀n àwọn ọmọbìnrin fún àwọn ọmọ rẹ̀ ọkùnrin lára àwọn tí kì í ṣe ẹ̀yà rẹ̀. Ibsani ṣe ìdájọ́ Israẹli fún ọdún méje. Lẹ́yìn náà ni Ibsani kú, wọ́n sì sin ín sí Bẹtilẹhẹmu. Lẹ́yìn rẹ̀, Eloni ti ẹ̀yà Sebuluni ṣe àkóso Israẹli fún ọdún mẹ́wàá. Eloni sì kú, wọ́n sì sin ín sí Aijaloni ní ilẹ̀ Sebuluni. Lẹ́yìn rẹ̀ ni Abdoni ọmọ Hileli tí Piratoni n ṣe àkóso Israẹli. Òun ní ogójì ọmọkùnrin àti ọgbọ̀n ọmọ ọmọ àwọn tí ó ń gun àádọ́rin kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́. Ó ṣe ìdájọ́ Israẹli ní ọdún mẹ́jọ. Abdoni ọmọ Hileli sì kú, wọ́n sin ín sí Piratoni ní ilé Efraimu ní ìlú òkè àwọn ará Amaleki. Ìbí Samsoni Àwọn ọmọ Israẹli sì túnṣe ohun tí ó burú ní ojú Olúwa, Olúwa sì fi wọ́n lé àwọn ará Filistini lọ́wọ́ fún ogójì ọdún. Ọkùnrin ará Sora kan wà, orúkọ rẹ̀ a máa jẹ́ Manoa láti ẹ̀yà Dani. Aya rẹ̀ yàgàn kò sì bímọ. Angẹli Olúwa fi ara han obìnrin náà, ó sì wí fún un pé, “Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwọ yàgàn, ìwọ kò sì tí ì bímọ, ìwọ yóò lóyún, ìwọ yóò sì bí ọmọkùnrin kan. Báyìí rí i dájúdájú pé ìwọ kò mu wáìnì tàbí ọtí líle kankan àti pé ìwọ kò jẹ ohun aláìmọ́ kankan, nítorí ìwọ yóò lóyún, ìwọ yóò sì bí ọmọkùnrin kan. Má ṣe fi abẹ kan orí rẹ̀, nítorí pé Nasiri, ẹni ìyàsọ́tọ̀ fún Ọlọ́run ni ọmọ náà yóò jẹ́ láti ọjọ́ ìbí rẹ̀. Òun ni yóò bẹ̀rẹ̀ ìdáǹdè àwọn ọmọ Israẹli kúrò ní ọwọ́ àwọn ará Filistini.” Nígbà náà ni obìnrin náà tọ ọkọ rẹ̀ lọ, o sì sọ fún un wí pé, “Ènìyàn Ọlọ́run kan tọ̀ mí wá. Ó jọ angẹli Ọlọ́run, ó ba ènìyàn lẹ́rù gidigidi. Èmi kò béèrè ibi tí ó ti wá, òun náà kò sì sọ orúkọ rẹ̀ fún mi. Ṣùgbọ́n ó sọ fún mi wí pé, ‘Ìwọ yóò lóyún, ìwọ yóò sì bí ọmọkùnrin kan, fún ìdí èyí, má ṣe mu wáìnì tàbí àwọn ọtí líle mìíràn bẹ́ẹ̀ ni kí ìwọ má ṣe jẹ ohunkóhun tí í ṣe aláìmọ́, nítorí pé Nasiri Ọlọ́run ni ọmọ náà yóò jẹ́ láti ọjọ́ ìbí rẹ̀ títí di ọjọ́ ikú rẹ̀.’ ” Nígbà náà ni Manoa gbàdúrà sí Olúwa wí pé, “Háà Olúwa, èmi bẹ̀ ọ́, jẹ́ kí ènìyàn Ọlọ́run tí ìwọ rán sí wa padà tọ̀ wá wá láti kọ́ wa bí àwa yóò ti ṣe tọ́ ọmọ tí àwa yóò bí náà.” Ọlọ́run fetí sí ohùn Manoa, angẹli Ọlọ́run náà tún padà tọ obìnrin náà wá nígbà tí ó wà ní oko ṣùgbọ́n ọkọ rẹ̀ Manoa kò sí ní ọ̀dọ̀ rẹ̀. Nítorí náà ni obìnrin náà ṣe yára lọ sọ fún ọkọ rẹ̀ pé, “Ọkùnrin tí ó fi ara hàn mí ní ọjọ́sí ti tún padà wá.” Manoa yára dìde, ó sì tẹ̀lé aya rẹ̀, nígbà tí ó dé ọ̀dọ̀ ọkùnrin náà ó ní, “Ǹjẹ́ ìwọ ni o bá obìnrin yìí sọ̀rọ̀?” Ọkùnrin náà dáhùn pé, “Èmi ni.” Manoa bi ọkùnrin náà pé, “Nígbà tí ọ̀rọ̀ rẹ bá ṣẹ kí ni yóò jẹ́ ìlànà fún ìgbé ayé àti iṣẹ́ ọmọ náà?” Angẹli Olúwa náà dáhùn wí pé, “Aya rẹ gbọdọ̀ ṣe gbogbo ohun tí mo ti sọ fún un kò gbọdọ̀ jẹ ohunkóhun tí ó bá ti inú èso àjàrà jáde wá, bẹ́ẹ̀ ni kò gbọdọ̀ mu wáìnì tàbí àwọn ọtí líle mìíràn tàbí jẹ ohunkóhun tí ó bá jẹ́ aláìmọ́. Ó ní láti ṣe ohun gbogbo tí mo ti pàṣẹ fún un.” Manoa sọ fún angẹli Olúwa náà pé, “Jọ̀wọ́ dára dúró títí àwa yóò fi pèsè ọ̀dọ́ ewúrẹ́ kan fún ọ.” Angẹli Olúwa náà dá Manoa lóhùn pé, “Bí ẹ̀yin tilẹ̀ dá mi dúró, èmi kì yóò jẹ ọ̀kankan nínú oúnjẹ tí ẹ̀yin yóò pèsè. Ṣùgbọ́n tí ẹ̀yin bá fẹ́ ẹ pèsè ọrẹ ẹbọ sísun, kí ẹ sì fi rú ẹbọ sí Olúwa.” (Manoa kò mọ̀ pé angẹli Olúwa ní i ṣe.) Manoa sì béèrè lọ́wọ́ angẹli Olúwa náà pé, “Kí ni orúkọ rẹ, kí àwa bá à lè fi ọlá fún ọ nígbà tí ọ̀rọ̀ rẹ bá ṣẹ?” Ṣùgbọ́n angẹli Olúwa náà dáhùn pé, “Èéṣe tí ìwọ ń béèrè orúkọ mi? Ìyanu ni, ó kọjá ìmọ̀.” Lẹ́yìn náà ni Manoa mú ọ̀dọ́ ewúrẹ́, pẹ̀lú ẹbọ ọkà, ó sì fi rú ẹbọ lórí àpáta kan sí Olúwa. Nígbà tí Manoa àti ìyàwó dúró tí wọn ń wò Olúwa ṣe ohun ìyanu kan. Bí ẹ̀là ahọ́n iná ti là jáde láti ibi pẹpẹ ìrúbọ náà sí ọ̀run, angẹli Olúwa gòkè re ọ̀run láàrín ahọ́n iná náà. Nígbà tí wọ́n rí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí, Manoa àti aya rẹ̀ wólẹ̀ wọ́n sì dojúbolẹ̀. Nígbà tí angẹli Olúwa náà kò tún fi ara rẹ̀ han Manoa àti aya rẹ̀ mọ́, Manoa wá mọ̀ pé angẹli Olúwa ni. Manoa sọ fún aya rẹ̀ pé, “Dájúdájú àwa yóò kú nítorí àwa ti fi ojú rí Ọlọ́run.” Ṣùgbọ́n ìyàwó rẹ̀ dáhùn pé, “Bí Olúwa bá ní èrò àti pa wá kò bá tí gba ẹbọ sísun àti ọrẹ ọkà wa, tàbí fi gbogbo nǹkan wọ̀nyí hàn wá tó sọ nǹkan ìyanu yìí fún wa.” Obìnrin náà sì bí ọmọkùnrin kan, ó sì sọ orúkọ rẹ̀ ní Samsoni. Ọmọ náà dàgbà Olúwa sì bùkún un. Ẹ̀mí Olúwa sì bẹ̀rẹ̀ sí ru sókè nígbà tí ó wà ní Mahane-Dani ní agbede-méjì Sora àti Eṣtaoli. Ìgbéyàwó Samsoni Nígbà kan Samsoni gòkè lọ sí Timna níbẹ̀ ni ó ti rí ọmọbìnrin Filistini kan. Nígbà tí ó darí dé, ó sọ fún àwọn òbí rẹ̀ pé, “Mo rí obìnrin Filistini kan ní Timna: báyìí ẹ fẹ́ ẹ fún mi bí aya mi.” Baba àti ìyá rẹ̀ dáhùn pé, “Ṣé kò sí obìnrin tí ó dára tí ó sì tẹ́ ọ lọ́rùn ní àárín àwọn ìbátan rẹ, tàbí láàrín gbogbo àwọn ènìyàn wa? Ṣé ó di dandan fún ọ láti lọ sí àárín àwọn Filistini aláìkọlà kí o tó fẹ́ ìyàwó?” Ṣùgbọ́n Samsoni wí fún baba rẹ̀ pé, “Fẹ́ ẹ fún mi torí pé inú mi yọ́ sí i púpọ̀púpọ̀.” (Àwọn òbí rẹ̀ kò mọ̀ pé ọ̀dọ̀ Olúwa ni nǹkan yìí ti wá, ẹni tí ń wá ọ̀nà àti bá Filistini jà; nítorí àwọn ni ń ṣe àkóso Israẹli ní àkókò náà.) Samsoni sọ̀kalẹ̀ lọ sí Timna òun àti baba àti ìyá rẹ̀. Bí wọ́n ṣe ń súnmọ́ àwọn ọgbà àjàrà tí ó wà ní Timna, láìròtẹ́lẹ̀, ọ̀dọ́ kìnnìún kan jáde síta tí ń ké ramúramù bọ̀ wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀. Ẹ̀mí Olúwa sì bà lé e pẹ̀lú agbára tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi fa kìnnìún náà ya pẹ̀lú ọwọ́ rẹ̀ lásán bí ẹní ya ọmọ ewúrẹ́, ṣùgbọ́n òun kò sọ ohun tí ó ṣe fún baba tàbí ìyá rẹ̀. Ó sì lọ bá obìnrin náà sọ̀rọ̀, inú Samsoni sì yọ́ sí i. Lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, nígbà tí ó padà lọ láti gbé e níyàwó, ó yà lọ láti wo òkú kìnnìún náà. Inú rẹ̀ ni ó ti bá ọ̀pọ̀ ìṣù oyin àti oyin, ó fi ọwọ́ ha jáde, ó sì ń jẹ ẹ́ bí ó ti ń lọ. Nígbà tí ó dé ọ̀dọ̀ àwọn òbí rẹ̀, ó fún wọn ní díẹ̀, àwọn náà sì jẹ, ṣùgbọ́n kò sọ fún wọn pé ara òkú kìnnìún ni òun ti rí oyin náà. Baba rẹ̀ sì sọ̀kalẹ̀ lọ láti kí obìnrin náà. Samsoni sì ṣe àsè gẹ́gẹ́ bí àṣà ọkọ ìyàwó ní àkókò náà. Nígbà tí ó fi ara hàn, tí àwọn ènìyàn náà rí i wọ́n fún un ní ọgbọ̀n àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ láti wá bá a kẹ́gbẹ́. Samsoni sọ fún wọn pé, “Ẹ jẹ́ kí n pa àlọ́ kan fún un yín, bí ẹ̀yin bá lè fún mi ní ìtumọ̀ rẹ̀ láàrín ọjọ́ méje àsè yìí, tàbí ṣe àwárí àlọ́ náà èmi yóò fún un yín ní ọgbọ̀n aṣọ tí a fi òwú ọ̀gbọ̀ hun, àti ọgbọ̀n ìpààrọ̀ aṣọ ìyàwó. Ṣùgbọ́n tí ẹ̀yin kò bá le sọ ìtumọ̀ rẹ̀ fún mi, ẹ̀yin yóò fún mi ní ọgbọ̀n aṣọ tí a fi òwú ọ̀gbọ̀ hun àti ọgbọ̀n ìpààrọ̀ aṣọ ìgbéyàwó.” Wọ́n dáhùn pé, “Sọ àlọ́ rẹ fún wa jẹ́ kí a gbọ́.” Ó dáhùn pé, “Láti inú ọ̀jẹun ni ohun jíjẹ ti jáde wá; láti inú alágbára ni ohun dídùn ti jáde wá.” Ṣùgbọ́n fún odidi ọjọ́ mẹ́ta ni wọn kò fi rí ìtumọ̀ sí àlọ́ náà. Ní ọjọ́ kẹrin, wọ́n wí fún ìyàwó Samsoni, pé, “Tan ọkọ rẹ kí ó lè ṣe àlàyé àlọ́ náà fún wa, bí bẹ́ẹ̀ kọ́ àwa yóò sun ìwọ àti ìdílé baba rẹ̀ ní iná. Tàbí ṣe o pè wá sí ibi àsè yìí láti sọ wá di òtòṣì tàbí kó wa lẹ́rú ni?” Nígbà náà ni ìyàwó Samsoni ṣubú lé e láyà, ó sì sọkún ní iwájú rẹ̀ pé, “O kórìíra mi! O kò sì ní ìfẹ́ mi nítòótọ́, o pàlọ́ fún àwọn ènìyàn mi, ìwọ kò sì sọ ìtumọ̀ rẹ̀ fún mi.” “Èmi kò tí ì ṣe àlàyé rẹ̀ fún baba àti ìyá mi, báwo ni èmi ó ṣe sọ ìtumọ̀ rẹ̀ fún ọ.” Fún gbogbo ọjọ́ méje tí wọ́n fi ṣe àsè náà ni ó fi sọkún, nítorí náà ní ọjọ́ keje ó sọ ìtumọ̀ àlọ́ fún un nítorí pé ó yọ ọ́ lẹ́nu ní ojoojúmọ́. Òun náà sì sọ ìtumọ̀ àlọ́ náà fún àwọn ènìyàn rẹ̀. Kí ó tó di àṣálẹ́ ọjọ́ keje àwọn ọkùnrin ìlú náà sọ fún un pé, “Kí ni ó dùn ju oyin lọ? Kí ni ó sì lágbára ju kìnnìún lọ?” Samsoni dá wọn lóhùn pé, “Bí kì í bá ṣe pé ẹ fi ọ̀dọ́ abo màlúù mi kọ ilẹ̀, ẹ̀yin kò bá tí mọ ìtumọ̀ sí àlọ́ mi.” Lẹ́yìn èyí, ẹ̀mí Olúwa bà lé e pẹ̀lú agbára. Ó lọ sí Aṣkeloni, ó pa ọgbọ̀n nínú àwọn ọkùnrin wọn, ó gba àwọn ohun ìní wọn, ó sì fi àwọn aṣọ wọn fún àwọn tí ó sọ ìtumọ̀ àlọ́ náà. Ó sì padà sí ilé baba rẹ̀ pẹ̀lú ìbínú ríru. Wọ́n sì fi ìyàwó Samsoni fún ẹlẹgbẹ́ rẹ̀, tí ó jẹ́ ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ rẹ̀ nígbà ìgbéyàwó rẹ̀. Ẹ̀san Samsoni lára àwọn ará Filistini Lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, ní àkókò ìkórè alikama, Samsoni mú ọ̀dọ́ ewúrẹ́ kan láti bẹ ìyàwó rẹ̀ wò. Ó ní, “Èmi yóò wọ yàrá ìyàwó mi lọ.” Ṣùgbọ́n baba rẹ̀ kò gbà á láààyè láti wọlé. Baba ìyàwó dá a lóhùn pé, “Ó dá mi lójú pé o kórìíra rẹ̀, torí náà mo ti fi fún ọ̀rẹ́ rẹ, ṣe bí àbúrò rẹ̀ obìnrin kò ha lẹ́wà jùlọ? Fẹ́ ẹ dípò rẹ̀.” Samsoni dáhùn pé, “Ní àkókò yìí tí mo bá ṣe àwọn Filistini ní ibi èmi yóò jẹ́ aláìjẹ̀bi.” Samsoni sì jáde lọ, ó mú ọ̀ọ́dúnrún (300) kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ ó so ìrù wọn mọ́ ara wọn ní méjì méjì. Ó mú ètùfù iná, ó so ó mọ́ àwọn ìrù tí ó so pọ̀. Ó fi iná ran àwọn ètùfù tí ó so náà, ó sì jọ̀wọ́ wọn lọ́wọ́ lọ sínú àwọn oko ọkà àwọn Filistini. Ó jó àwọn pòpóòrò ọkà tí ó dúró àti àwọn tí a dì ní ìtí, ìtí, pẹ̀lú àwọn ọgbà àjàrà àti olifi. Nígbà tí àwọn Filistini béèrè pé, “Ta ni ó ṣe èyí?” Wọ́n dá wọn lóhùn pé, “Samsoni ará Timna ni, nítorí a gba ìyàwó rẹ̀ fún ọ̀rẹ́ rẹ̀.” Nítorí náà àwọn Filistini lọ wọ́n sì sun obìnrin náà àti baba rẹ̀. Samsoni sọ fún un pé, “Nítorí pé ẹ̀yin ṣe èyí, èmi ó gbẹ̀san lára yín, lẹ́yìn náà èmi yóò sì dẹ́kun.” Ó kọlù wọ́n pẹ̀lú ìbínú àti agbára ńlá, ó sì pa ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú wọn. Lẹ́yìn náà ni ó lọ, ó sì dúró nínú ihò àpáta kan nínú àpáta Etamu. Àwọn ará Filistini sì dìde ogun sí Juda, wọ́n ti tan ara wọn ká sí agbègbè Lehi. Àwọn ọkùnrin Juda sì béèrè pé, “Èéṣe tí ẹ fi wá gbóguntì wá?” Ìdáhùn wọn ni pé, “A wá láti mú Samsoni ní ìgbèkùn, kí a ṣe sí i bí òun ti ṣe sí wa.” Nígbà náà ni ẹgbẹ̀rún mẹ́ta (3,000) ọkùnrin láti Juda sọ̀kalẹ̀ lọ sí ihò àpáta nínú àpáta Etamu, wọ́n sì sọ fún Samsoni pé, “Kò ti yé ọ pé àwọn Filistini ní ń ṣe alákòóso lórí wa? Kí ni o ṣe sí wa?” Òun sì dáhùn pé, “Ohun tí wọ́n ṣe sí mi ni èmi náà ṣe sí wọn.” Wọ́n wí pé, “Àwa wá láti dè ọ́, kí a sì fi ọ́ lé àwọn Filistini lọ́wọ́.” Samsoni wí pé, “Ẹ búra fún mi pé, ẹ̀yin kì yóò fúnra yín pa mí.” “Àwa gbà,” ni ìdáhùn wọn. “Àwa yóò kàn dè ọ́, àwa yóò sì fi ọ́ lé wọn lọ́wọ́, àwa kì yóò pa ọ́.” Wọ́n sì dé pẹ̀lú okùn tuntun méjì, wọ́n sì mú u jáde wá láti ihò àpáta náà. Bí ó ti súnmọ́ Lehi, àwọn Filistini ń pariwo bí wọ́n ṣe ń tò bọ̀. Ẹ̀mí Olúwa bà lé e pẹ̀lú agbára. Àwọn okùn ọwọ́ rẹ̀ dàbí òwú tí ó jóná, ìdè ọwọ́ rẹ̀ já kúrò ní ọwọ́ rẹ̀. Nígbà tí ó rí egungun àgbọ̀n ìsàlẹ̀ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tuntun kan, ó mú un, ó sì fi pa ẹgbẹ̀rún (1,000) ọkùnrin. Samsoni sì wí pé, “Pẹ̀lú egungun àgbọ̀n ìsàlẹ̀ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kan, mo sọ wọ́n di òkìtì kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́. Pẹ̀lú egungun àgbọ̀n ìsàlẹ̀ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kan, mo ti pa ẹgbẹ̀rún (1,000) ọkùnrin.” Nígbà tí ó dákẹ́ ọ̀rọ̀ í sọ, ó ju egungun àgbọ̀n ìsàlẹ̀ náà nù, wọ́n sì pe ibẹ̀ ní Ramati-Lehi (ìtumọ̀ rẹ̀ jẹ́ egungun àgbọ̀n ìsàlẹ̀ pa). Nítorí tí òǹgbẹ gbẹ ẹ́ gidigidi, ó ké pe Olúwa, wí pé, “Ìwọ ti fún ìránṣẹ́ ní ìṣẹ́gun tí ó tóbi yìí. Ṣé èmi yóò ha kú pẹ̀lú òǹgbẹ, kí èmi sì ṣubú sí ọwọ́ àwọn aláìkọlà ènìyàn?” Nígbà náà ni Ọlọ́run la kòtò ìsun omi tí ó wà ní Lehi, omi sì tú jáde láti inú rẹ̀. Nígbà tí Samsoni mú mi tan, agbára rẹ̀ sì padà, ọkàn sì sọjí, fún ìdí èyí wọ́n pe ìsun omi náà ni. Ẹni Hakkore (orísun ẹni tí ó pe Ọlọ́run) èyí tí ó sì wà ní Lehi di òní. Samsoni ṣe ìdájọ́ Israẹli fún ogún ọdún ní àkókò àwọn ará Filistini. Samsoni àti Dẹlila Ní ọjọ́ kan Samsoni lọ sí Gasa níbi tí ó ti rí obìnrin panṣágà kan. Ó wọlé tọ̀ ọ́ láti sun ọ̀dọ̀ rẹ̀ ní òru ọjọ́ náà. Àwọn ará Gasa sì gbọ́ wí pé, “Samsoni wà níbí.” Wọ́n sì yí agbègbè náà ká, wọ́n ń ṣọ́ ọ ní gbogbo òru náà ní ẹnu-bodè ìlú náà. Wọn kò mira ní gbogbo òru náà pé ní “àfẹ̀mọ́júmọ́ àwa yóò pa á.” Ṣùgbọ́n Samsoni sùn níbẹ̀ di àárín ọ̀gànjọ́. Òun sì dìde ní ọ̀gànjọ́, ó fi ọwọ́ di àwọn ìlẹ̀kùn odi ìlú náà mú, pẹ̀lú òpó méjèèjì, ó sì fà wọ́n tu, pẹ̀lú ìdábùú àti ohun gbogbo tí ó wà lára rẹ̀. Ó gbé wọn lé èjìká rẹ̀ òun sì gbé wọn lọ sí orí òkè tí ó kọjú sí Hebroni. Lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, ó sì ní ìfẹ́ obìnrin kan ní àfonífojì Soreki, orúkọ ẹni tí í ṣe Dẹlila. Àwọn ìjòyè Filistini sì lọ bá obìnrin náà, wọ́n sọ fún un wí pé, “Bí ìwọ bá le tàn án kí òun sì fi àṣírí agbára rẹ̀ hàn ọ́, àti bí àwa ó ti lè borí rẹ̀, kí àwa sì dè é kí àwa sì ṣẹ́gun rẹ̀. Ẹnìkọ̀ọ̀kan nínú wa yóò sì fún ọ ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀fà fàdákà.” Torí náà Dẹlila sọ fún Samsoni pé, “Sọ àṣírí agbára ńlá rẹ fún mi àti bí wọ́n ti le dè ọ́, àti bí wọ́n ṣe lè borí rẹ.” Samsoni dá a lóhùn wí pé, “Bí ẹnikẹ́ni bá fi okùn tútù méje tí ẹnìkan kò sá gbẹ dè mí, èmi yóò di aláìlágbára bí i gbogbo àwọn ọkùnrin yòókù.” Àwọn olóyè Filistini sì mú okùn tútù méje tí ẹnikẹ́ni kò sá gbẹ wá fún Dẹlila òun sì fi wọ́n dè é. Nígbà tí àwọn ènìyàn tí sá pamọ́ sínú yàrá, òun pè pé, “Samsoni àwọn Filistini ti dé láti mú ọ.” Ṣùgbọ́n òun já àwọn okùn náà bí òwú ti í já nígbà tí ó bá wà lẹ́bàá iná. Torí náà wọn kò mọ àṣírí agbára rẹ̀. Dẹlila sì sọ fún Samsoni pé, ìwọ ti tàn mí; o sì purọ́ fún mi. Wá báyìí kí o sì sọ bí a ti ṣe le dè ọ́. Òun dáhùn pé, “Bí wọ́n bá lè fi okùn tuntun tí ẹnikẹ́ni kò tí ì lò rí dì mí dáradára, èmi yóò di aláìlágbára, èmi yóò sì dàbí àwọn ọkùnrin yòókù.” Dẹlila sì mú àwọn okùn tuntun, ó fi wọ́n dì í. Nígbà tí àwọn ọkùnrin Filistini ti fi ara pamọ́ sínú yàrá, òun kígbe sí i pé, “Samsoni àwọn Filistini dé láti mú ọ,” òun sì já okùn náà kúrò ní ọwọ́ rẹ̀ bí òwú. Dẹlila sì tún sọ fún Samsoni pé, “Títí di ìsinsin yìí ìwọ sì ń tún tàn mí, o sì tún purọ́ fún mi. Sọ fún mi ọ̀nà tí wọ́n fi le dè ọ́.” Samsoni dá a lóhùn pé, “Bí ìwọ bá hun ìdí irun méjèèje tí ó wà ní orí mi pẹ̀lú okùn, tí ó sì le dáradára kí o sì fi ẹ̀mú mú un mọ́lẹ̀, èmi yóò di aláìlágbára bí àwọn ọkùnrin yòókù.” Nígbà tí òun ti sùn, Dẹlila hun àwọn ìdí irun méjèèje tí ó wà ní orí rẹ̀, ó sì fi ìhunṣọ dè wọ́n. Ó sì tún pè é pé, “Samsoni àwọn Filistini dé láti mú ọ.” Òun sì jí ní ojú oorun, ó sì fa ìdè ìhunṣọ náà tu pẹ̀lú ohun gbogbo tí wọ́n fi kàn án mọ́lẹ̀. Dẹlila sì sọ fún un pé, “Èéṣe tí ìwọ fi wí pé, ‘Èmi fẹ́ràn rẹ,’ nígbà tí ìwọ kò fi ọkàn tán mi. Èyí ni ìgbà kẹta tí ìwọ ti tàn mí jẹ, tí ìwọ kò sì sọ àṣírí ibi tí agbára ńlá rẹ gbé wà fún mi.” Ó sì ṣe nígbà tí ó fi ọ̀rọ̀ rẹ̀ rọ̀ ọ́ ní ojoojúmọ́ pẹ̀lú ọ̀rọ̀ rẹ̀ títí dé bi pé ó sú dé òpin ẹ̀mí rẹ̀. Òun sì sọ ohun gbogbo tí ó wà ní ọkàn rẹ̀ fún un. Ó ní, “Abẹ kò tí ì kan orí mi rí, nítorí pé Nasiri, ẹni ìyàsọ́tọ̀ fún Ọlọ́run ni mo jẹ́ láti ìgbà ìbí mi wá. Bí a bá fá irun orí mi, agbára mi yóò fi mí sílẹ̀, èmi yóò sì di aláìlágbára bí àwọn ọkùnrin yòókù.” Nígbà tí Dẹlila rí i pé ó ti sọ ohun gbogbo fún òun tan, Dẹlila ránṣẹ́ sí àwọn ìjòyè Filistini pé, “Ẹ wá lẹ́ẹ̀kan sí i, ó ti sọ ohun gbogbo fún mi.” Torí náà àwọn olóyè Filistini padà, wọ́n sì mú owó ìpinnu náà lọ́wọ́. Òun sì mú kí Samsoni sùn lórí itan rẹ̀, òun sì pe ọkùnrin kan láti fá àwọn ìdì irun orí rẹ̀ méjèèje, òun sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣẹ́gun rẹ̀. Agbára rẹ̀ sì fi í sílẹ̀ lọ. Òun pè é wí pé, “Samsoni àwọn Filistini dé láti mú ọ.” Òun jí ní ojú oorun rẹ̀, ó sì sọ pé, “Èmi yóò jáde lọ bí í ti àtẹ̀yìnwá, kí èmi sì gba ara mi, kí n di òmìnira.” Ṣùgbọ́n òun kò mọ̀ pé Olúwa ti fi òun sílẹ̀. Nígbà náà ni àwọn Filistini mú un, wọ́n yọ ojú rẹ̀ méjèèjì wọ́n sì mú un lọ sí Gasa. Wọ́n fi ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ idẹ dè é, wọ́n sì fi sí ibi iṣẹ́ ọlọ lílọ̀ nínú ilé túbú. Ṣùgbọ́n irun orí rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í tún hù lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n ti fá a. Ikú Samsoni Àwọn ìjòyè, àwọn ará Filistini sì péjọpọ̀ láti ṣe ìrúbọ ńlá sí Dagoni ọlọ́run wọn àti láti ṣe ayẹyẹ wọ́n wí pé, ọlọ́run wa ti fi Samsoni ọ̀tá wa lé wa lọ́wọ́. Nígbà tí àwọn ènìyàn rí Samsoni wọ́n yin ọlọ́run wọn wí pé, “Ọlọ́run wa ti fi ọ̀tá wa lé wa lọ́wọ́. Àní ẹni tí ó ti run ilẹ̀ wa ẹni tí ó ti pa ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú wa.” Nígbà tí inú wọn dùn gidigidi tí wọ́n ń yọ ayọ̀ ńlá, wọ́n pariwo pé, ẹ mú Samsoni wá kí ó wá dá wa lára yá. Wọ́n sì pe Samsoni jáde láti ọgbà ẹ̀wọ̀n náà, òun sì ń ṣeré fún wọn. Nígbà tí wọ́n mú un dúró láàrín àwọn òpó. Samsoni sọ fún àwọn ìránṣẹ́ tí ó di ọwọ́ rẹ̀ mú pé, “Ẹ fi mí si ibi tí ọwọ́ mi yóò ti le tó àwọn òpó tí ó gbé tẹmpili dúró mú, kí èmi lè fẹ̀yìn tì wọ́n.” Ní àsìkò náà, tẹmpili yìí kún fún àwọn ọkùnrin àti obìnrin; gbogbo àwọn ìjòyè Filistini wà níbẹ̀, ní òkè ilé náà, níbi tí ẹgbẹ̀rún mẹ́ta (3,000) àwọn ọkùnrin àti obìnrin tí ń wòran Samsoni bí òun ti ń ṣeré. Nígbà náà ni Samsoni ké pe Olúwa wí pé, “Olúwa Olódùmarè, rántí mi. Háà Ọlọ́run jọ̀wọ́ fi agbára fún mi lẹ́ẹ̀kan yìí sí i, kí èmi lè gbẹ̀san lára àwọn Filistini nítorí àwọn ojú mi méjèèjì.” Samsoni sì na ọwọ́ mú àwọn òpó méjèèjì tí ó wà láàrín gbùngbùn, orí àwọn tí tẹmpili náà dúró lé, ó fi ọwọ́ ọ̀tún mú ọ̀kan àti ọwọ́ òsì mú èkejì, ó fi ara tì wọ́n, Samsoni sì wí pé, “Jẹ́ kí èmi kú pẹ̀lú àwọn Filistini!” Òun sì fi agbára ńlá tì wọ́n, bẹ́ẹ̀ ni ilé náà wó lu àwọn ìjòyè àti gbogbo àwọn tí ó wà nínú rẹ̀. Báyìí ni ó pa ọ̀pọ̀lọpọ̀ nígbà ikú rẹ̀ ju ìgbà ayé rẹ̀ lọ. Nígbà náà ni àwọn arákùnrin rẹ̀ àti gbogbo ìdílé baba rẹ̀ ní àpapọ̀ gòkè lọ wọ́n sì gbé e, wọ́n gbé e padà wá, wọ́n sì sin ín sí agbede-méjì Sora àti Eṣtaoli, sínú ibojì Manoa baba rẹ̀. Òun ti ṣe àkóso Israẹli ní ogún ọdún. Ìbọ̀rìṣà Mika Nígbà náà ni ọkùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Mika láti agbègbè òkè Efraimu sọ fún ìyá rẹ̀ pé, “Ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀fà ṣékélì fàdákà èyí tí wọ́n jí mọ́ ọ lọ́wọ́, àti nípa èyí tí mo gbọ́ tí ìwọ ń ṣẹ́ èpè. Kíyèsi fàdákà náà wà ní ọ̀dọ̀ mi, èmi ni mo kó o.” Nígbà náà ni ìyá rẹ̀ dáhùn pé, “Kí Olúwa bùkún ọ ọmọ mi!” Nígbà tí ó da ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀fà ṣékélì fàdákà náà padà fún ìyá rẹ̀, ìyá rẹ̀ dáhùn pé, “Èmi ti fi òtítọ́ inú ya sílífà náà sọ́tọ̀ sí Olúwa fún ọmọ mi láti fi dá ère dídá àti ère gbígbẹ́. Èmi yóò dá a padà fún ọ.” Nítorí náà òun dá sílífà náà padà fún ìyá rẹ̀, ìyá rẹ̀ sì mú igba ṣékélì fàdákà, ó sì fún alágbẹ̀dẹ fàdákà ẹni tí ó fi wọ́n rọ ère fínfín àti ère dídà. Wọ́n sì kó wọn sí ilé Mika. Ọkùnrin náà, Mika sì ní ojúbọ kan. Òun sì ra ẹ̀wù efodu kan, ó sì ṣe àwọn ère kan, ó sì fi ọ̀kan nínú àwọn ọmọ rẹ̀ ọkùnrin ṣe àlùfáà rẹ̀. Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì àwọn ọmọ Israẹli kò ní ọba; olúkúlùkù ṣe bí ó ti rò pé ó tọ́ ní ojú ara rẹ́. Ọ̀dọ́mọkùnrin kan sì ti Bẹtilẹhẹmu ti Juda wá, tí í ṣe ìdílé Juda, ẹni tí í ṣe ẹ̀yà Lefi, òun sì ṣe àtìpó níbẹ̀, ọkùnrin náà sì ti ìlú Bẹtilẹhẹmu ti Juda lọ, láti ṣe àtìpó ní ibikíbi tí ó bá rí. Ní ojú ọ̀nà àjò rẹ̀, ó dé ilẹ̀ Mika nínú àwọn ilẹ̀ òkè Efraimu. Mika bi í pé, “Níbo ni ó ti ń bọ̀?” Ó dáhùn pé, “Ọmọ Lefi ni mí láti Bẹtilẹhẹmu Juda, mo sì ń wá ibi tí èmi yóò máa gbé.” Mika sì sọ fún un wí pé, “Dúró lọ́dọ̀ mi kí ìwọ sì jẹ́ baba mi àti àlùfáà fún mi, èmi ó sì máa fún ọ ní ṣékélì mẹ́wàá fàdákà ní ọdọọdún, pẹ̀lú aṣọ àti oúnjẹ rẹ̀.” Ọmọ Lefi náà sì gbà láti máa bá a gbé, ọ̀dọ́mọkùnrin náà sì dàbí ọ̀kan nínú àwọn ọmọ rẹ̀. Nígbà náà ni Mika ya ará Lefi náà sí mímọ́, ọ̀dọ́mọkùnrin náà sì di àlùfáà rẹ̀, ó sì ń gbé ilé rẹ̀. Mika sì wí pé, “Báyìí, èmi mọ̀ pé Olúwa yóò ṣe mi ní oore nítorí pé mo ní ọmọ Lefi ní àlùfáà mi.” Àwọn ìran Dani tẹ̀dó sí Laiṣi Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì, àwọn ọmọ Israẹli kò ní ọba. Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì, àwọn ẹ̀yà Dani ń wá ilẹ̀ tiwọn, níbi tí wọn yóò máa gbé, nítorí pé títí di àkókò náà wọn kò ì tí ì pín ogún ilẹ̀ fún wọn ní ìní láàrín àwọn ọmọ Israẹli. Nítorí náà àwọn ẹ̀yà Dani rán àwọn jagunjagun márùn-ún lọ láti Sora àti Eṣtaoli láti yọ́ ilẹ̀ náà wò àti láti rìn ín wò. Àwọn ènìyàn wọ̀nyí ṣe ojú fún gbogbo àwọn ẹ̀yà wọn. Wọ́n wí fún wọn pé, “Ẹ lọ kí ẹ rin ilẹ̀ náà ká, kí ẹ sì wò ó fínní fínní.” Àwọn ọkùnrin náà wọ àwọn ìlú tí ó wà ní agbègbè òkè Efraimu, wọ́n sì dé ilé Mika, níbi tí wọ́n sùn ní òru náà. Nígbà tí wọ́n súnmọ́ tòsí ilé e Mika, wọ́n dá ohùn ọ̀dọ́mọkùnrin Lefi náà mọ̀, torí náà wọ́n yípadà, wọ́n sì wọ inú ilé náà lọ wọ́n sì bi í pé, “Tá ni ó mú ọ wa sí ibi? Kí ni ìwọ ń ṣe níhìn-ín yìí? Èéṣe tí o fi wà ní ibí?” Ó sọ ohun tí Mika ti ṣe fún un, ó fi kún un fún wọn pé, “Ó gbà mí sí iṣẹ́, èmi sì ni àlùfáà rẹ̀.” Wọ́n wí fún un pé, “Jọ̀wọ́ béèrè ní ọwọ́ Ọlọ́run, kí àwa lè mọ̀ bí ìrìnàjò wa yóò yọrí sí rere.” Àlùfáà náà dá wọn lóhùn pé, “Ẹ máa lọ ní àlàáfíà. Ìrìnàjò yín tí ẹ̀yin ń rìn bá ojúrere Olúwa pàdé.” Àwọn ọkùnrin márààrún náà kúrò, wọ́n sì wá sí Laiṣi, níbi tí wọ́n ti rí i pé àwọn ènìyàn tí ń gbé ibẹ̀ ní ààbò, bí àwọn ará Sidoni, láìsí ìfòyà àti ní ìpamọ́. Ní ìgbà tí ilẹ̀ wọn kò ṣe aláìní ohunkóhun, wọ́n ní ọrọ̀ púpọ̀. Ibùgbé wọn tún jìnnà sí ti àwọn ará Sidoni, wọn kò fi ohunkóhun bá ẹnikẹ́ni dàpọ̀. Nígbà tí wọ́n padà sí Sora àti Eṣtaoli, àwọn arákùnrin wọn bi wọ́n léèrè pé, “Báwo ni ibi tí ẹ lọ ti rí? Kí ni ìròyìn tí ẹ mú wá?” Wọ́n dáhùn pé, “Ẹ dìde ẹ jẹ́ kí a lọ kọlù wọ́n! A wá rí i pé ilẹ̀ náà dára gidigidi. Ṣé ẹ̀yin ó sì jókòó láìsí nǹkan nípa rẹ̀? Ẹ má ṣe lọ́ra láti lọ síbẹ̀ kí ẹ sì gba ilẹ̀ náà. Nígbà tí ẹ̀yin bá dé ibẹ̀, ẹ yóò rí àwọn ènìyàn tí ọkàn wọn balẹ̀ àti ilẹ̀ tí ó tẹ́jú tí Ọlọ́run ti fi fún yín, ilẹ̀ tí kò ṣe aláìní nǹkan kan.” Nígbà náà ni ẹgbẹ̀ta (600) ọkùnrin tí ó múra ogun láti ìran Dani, jáde lọ láti Sora àti Eṣtaoli ní mímú ra láti jagun. Wọ́n sì jáde lọ, ní ojú ọ̀nà wọn, wọ́n tẹ̀dó ogun sí ẹ̀bá Kiriati-Jearimu ní Juda. Ìdí nìyí tí wọ́n fi ń gbé ìwọ̀-oòrùn Kiriati-Jearimu ni Mahane-Dani títí di òní yìí. Láti ibẹ̀ wọ́n kọjá lọ sí àwọn ìlú agbègbè òkè Efraimu, wọ́n sì dé ilé Mika. Nígbà náà ni àwọn ọkùnrin márùn-ún tí ó lọ yọ́ ilẹ̀ Laiṣi wò sọ fún àwọn arákùnrin wọn pé, “Ǹjẹ́ ẹ̀yin mọ̀ pé ọ̀kan nínú àwọn ilé yìí ní ẹ̀wù efodu, àwọn yòókù ní òrìṣà, ère gbígbẹ́ àti ère dídà? Ẹ mọ ohun tí ó yẹ kí ẹ ṣe báyìí.” Wọ́n sì yà sí ibẹ̀, wọ́n sì wọ ilé ọ̀dọ́mọkùnrin Lefi náà, sí ilé Mika, wọ́n sì béèrè àlàáfíà rẹ̀. Àwọn ẹgbẹ̀ta (600) ọkùnrin ará Dani náà tí ó hámọ́ra ogun, dúró ní àbáwọlé ẹnu odi. Àwọn ọkùnrin márùn-ún tí wọ́n lọ yọ́ ilẹ̀ náà wò wọlé lọ wọ́n sì kó ère gbígbẹ́ náà, efodu náà, àwọn òrìṣà ìdílé àti ère dídà náà nígbà tí àlùfáà náà àti àwọn ẹgbẹ̀ta (600) ọkùnrin tí ó hámọ́ra ogun dúró ní à bá wọ ẹnu odi náà. Nígbà tí àwọn ọkùnrin yìí wọ ilé e Mika lọ tí wọ́n sì kó ère fínfín náà, efodu náà, àwọn òrìṣà ìdílé mìíràn àti ère dídà náà, àlùfáà náà béèrè lọ́wọ́ wọn wí pé, “Kí ni ẹ̀yin ń ṣe?” Wọ́n dá a lóhùn pé, “Dákẹ́! Ma sọ nǹkan kan, tẹ̀lé wa kí o sì di baba àti àlùfáà wa. Kò ha sàn fún ọ láti máa ṣe ìránṣẹ́ ẹ̀yà àti ìdílé kan tí ó wá láti Israẹli bí àlùfáà ju ilé ẹnìkan ṣoṣo lọ?” Nígbà náà ni inú àlùfáà náà sì dùn, òun mú efodu náà, àwọn òrìṣà ìdílé mìíràn àti ère fínfín náà, ó sì bá àwọn ènìyàn náà lọ. Wọ́n kó àwọn ọmọdé wọn, àwọn ohun ọ̀sìn wọn àti gbogbo ohun ìní wọn síwájú, wọ́n yípadà wọ́n sì lọ. Nígbà tí wọ́n ti rìn jìnnà díẹ̀ sí ilé Mika, àwọn ọkùnrin tí ó wà ní agbègbè Mika kó ara wọn jọ, wọ́n sì lé àwọn ará Dani bá. Bí wọ́n ṣe ń pariwo tẹ̀lé wọn lẹ́yìn, àwọn ará Dani yípadà wọ́n sì bi Mika pé, “Kí ló ṣe ọ́ tí o fi pe àwọn ọkùnrin rẹ jáde láti jà?” Ó dáhùn pé, “Ẹ̀yin kó àwọn ère tí mo ṣe, àti àlùfáà mi lọ. Kí ni ó kù tí mo ní? Báwo ni ẹ̀yin ò ṣe béèrè pé, ‘Kí ló ṣe ọ́?’ ” Àwọn ọkùnrin Dani náà dáhùn pé, “Má ṣe bá wa jiyàn, tàbí àwọn oníbìínú fùfù ènìyàn lè kọlù yín, ìwọ àti àwọn ìdílé yóò sì sọ ẹ̀mí yín nù.” Àwọn ọkùnrin Dani náà sì bá ọ̀nà wọn lọ. Nígbà tí Mika rí í pé wọ́n lágbára púpọ̀ fún òun, ó sì padà sí ilé rẹ̀. Wọ́n sì kó àwọn ohun tí Mika ti ṣe àti àlùfáà rẹ̀, wọ́n sì kọjá lọ sí Laiṣi, ní ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn tí ó ní ìbàlẹ̀ ọkàn tí wọ́n sì wà ní àlàáfíà. Wọ́n fi ojú idà kọlù wọ́n, wọ́n sì jó ìlú wọn run. Kò sì sí ẹnikẹ́ni tí yóò gbà wọ́n sílẹ̀ nítorí pé ibi tí wọ́n ń gbé jìnà sí àwọn ará Sidoni, wọn kò sì ní àṣepọ̀ pẹ̀lú ẹnikẹ́ni. Ìlú náà wà ní inú àfonífojì lẹ́bàá a Beti-Rehobu. Àwọn ará Dani sì tún ìlú náà kọ́, wọ́n sì ń gbé inú rẹ̀. Wọ́n sọ orúkọ ìlú náà ní Dani gẹ́gẹ́ bí orúkọ baba ńlá wọn Dani, ẹni tí wọ́n bí fún Israẹli: bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Laiṣi ni orúkọ ìlú náà tẹ́lẹ̀ rí. Àwọn ọmọ Dani sì gbé àwọn ère kalẹ̀ fún ara wọn níbẹ̀; Jonatani ọmọ Gerṣomu, ọmọ Mose, àti àwọn ọmọ rẹ̀ ni àlùfáà fún àwọn ẹ̀yà Dani títí di àkókò tí a kó ilẹ̀ náà ní ìgbèkùn. Wọ́n tẹ̀síwájú láti lo àwọn ère tí Mika ṣe, ní gbogbo àkókò tí ilé Ọlọ́run wà ní Ṣilo. Ọmọ Lefi kan àti àlè rẹ̀ Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì Israẹli kò ní ọba. Ọ̀kan nínú àwọn ọmọ Lefi tí ń gbé ibi tí ó sá pamọ́ nínú àwọn agbègbè òkè Efraimu, mú àlè kan láti Bẹtilẹhẹmu ní Juda. Ṣùgbọ́n àlè rẹ̀ náà sì ṣe panṣágà sí i, òun fi sílẹ̀, ó sì padà lọ sí ilé baba rẹ̀ ní Bẹtilẹhẹmu ti Juda, ó sì wà ní ibẹ̀ ní ìwọ̀n oṣù mẹ́rin, ọkọ rẹ̀ lọ sí ibẹ̀ láti rọ̀ ọ́ pé kí ó padà sí ọ̀dọ̀ òun. Nígbà tí ó ń lọ ó mú ìránṣẹ́ àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ méjì lọ́wọ́, obìnrin náà mú un wọ inú ilé baba rẹ̀ lọ, nígbà tí baba obìnrin náà rí i ó fi tayọ̀tayọ̀ gbà á. Àna rẹ̀, baba ọmọbìnrin náà rọ̀ ọ́, ó sì borí rẹ̀ láti dá a dúró fún ìgbà díẹ̀, òun sì dúró fún ọjọ́ mẹ́ta, ó ń jẹ, ó ń mu, ó sì ń sùn níbẹ̀. Ní ọjọ́ kẹrin, wọ́n dìde ní òwúrọ̀ kùtùkùtù òun sì múra láti padà lọ, ṣùgbọ́n baba ọmọbìnrin náà wí fún àna rẹ̀ pé, “Fi ohun jíjẹ díẹ̀ gbé inú ró nígbà náà kí ìwọ máa lọ.” Àwọn méjèèjì sì jùmọ̀ jókòó láti jọ jẹun àti láti jọ mu. Lẹ́yìn èyí ni baba ọmọbìnrin wí pé, “Jọ̀wọ́ dúró ní alẹ́ yìí kí o sì gbádùn ara rẹ.” Nígbà tí ọkùnrin náà dìde láti máa lọ, baba ìyàwó rẹ̀ rọ̀ ọ́, torí náà ó sùn níbẹ̀ ní alẹ́ ọjọ́ náà. Ní òwúrọ̀ ọjọ́ karùn-ún nígbà tí ó dìde láti lọ, baba ọmọbìnrin wí pé, “Fi oúnjẹ gbé ara ró. Dúró de ọ̀sán!” Àwọn méjèèjì sì jùmọ̀ jọ jẹun. Nígbà tí ọkùnrin náà, pẹ̀lú àlè àti ìránṣẹ́ rẹ̀, dìde láti máa lọ, àna rẹ̀, baba ọmọbìnrin náà ní, “Wò ó ilẹ̀ ti ń ṣú lọ, dúró níbí, ọjọ́ ti lọ. Dúró kí o sì gbádùn ara rẹ. Ìwọ lè jí ní àárọ̀ kùtùkùtù ọ̀la kí ìwọ sì máa lọ ilé.” Ṣùgbọ́n nítorí pé òun kò fẹ́ dúró mọ́ níbẹ̀ ní òru náà ọkùnrin náà kúrò ó sì gba ọ̀nà Jebusi: ọ̀nà Jerusalẹmu pẹ̀lú àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ méjèèjì tí ó fi dì í ní gàárì àti àlè rẹ̀. Nígbà tí wọ́n súnmọ́ Jebusi tí ilẹ̀ ti fẹ́ ṣú tan, ìránṣẹ́ náà sọ fún ọ̀gá rẹ̀ pé, “Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a dúró ní ìlú yìí tí í ṣe ti àwọn ará Jebusi kí a sì sùn níbẹ̀.” Ọ̀gá rẹ̀ dá a lóhùn pé, “Rárá o, àwa kì yóò wọ ìlú àwọn àjèjì, àwọn tí olùgbé ibẹ̀ kì í ṣe ọmọ Israẹli, a yóò dé Gibeah.” Ó fi kún un pé, ẹ wá ẹ jẹ́ kí a gbìyànjú kí a dé Gibeah tàbí Rama kí a sùn ní ọ̀kan nínú wọn. Wọ́n sì tẹ̀síwájú nínú ìrìnàjò wọn, oòrùn wọ̀ bí wọ́n ti súnmọ́ Gibeah tí ṣe ti àwọn Benjamini. Wọ́n yípadà wọ́n lọ sí inú ìlú Gibeah láti wọ̀ síbẹ̀ ní òru náà, wọ́n lọ wọ́n sì jókòó níbi gbọ̀ngàn ìlú náà, ṣùgbọ́n kò sí ẹni tí ó gbà wọ́n sínú ilé rẹ̀ láti wọ̀ sí. Ní alẹ́ ọjọ́ náà ọkùnrin arúgbó kan láti àwọn òkè Efraimu, ṣùgbọ́n tí ń gbé ní Gibeah (ibẹ̀ ni àwọn ẹ̀yà Benjamini ń gbé) ń ti ibi iṣẹ́ rẹ̀ bọ̀ láti inú oko. Nígbà tí ó wòkè ó rí arìnrìn-àjò náà ní gbọ̀ngàn ìlú náà, ọkùnrin arúgbó yìí bi í léèrè pé, “Níbo ni ò ń lọ? Níbo ni o ti ń bọ̀?” Ọmọ Lefi náà dá a lóhùn pé, “Bẹtilẹhẹmu ti Juda ni àwa ti ń bọ̀, àwa sì ń lọ sí agbègbè tí ó sá pamọ́ ní àwọn òkè Efraimu níbi ti mo ń gbé. Mo ti lọ sí Bẹtilẹhẹmu ti Juda, èmi sì ń lọ sí ilé Olúwa nísinsin yìí. Kò sí ẹni tí ó gbà mí sí ilé rẹ̀. Àwa ní koríko àti oúnjẹ tó tó fún àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wa àti oúnjẹ àti wáìnì fún àwa ìránṣẹ́ rẹ—èmi, ìránṣẹ́bìnrin rẹ àti ọ̀dọ́mọkùnrin tí ó wà pẹ̀lú wa. A ò ṣe aláìní ohun kankan.” Ọkùnrin arúgbó náà sì wí pé. “Àlàáfíà fún ọ, bí ó ti wù kí ó rí, èmi yóò pèsè gbogbo ohun tí o nílò, kìkì pé kí ìwọ má ṣe sun ní ìgboro.” Òun sì mú wa sí ilé rẹ̀, ó ń bọ́ àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀. Lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n ti wẹ ẹsẹ̀ wọn, àwọn àlejò náà jẹ, wọ́n mu. Ǹjẹ́ bí wọ́n ti ń ṣe àríyá, kíyèsi i, àwọn ọkùnrin ìlú náà, àwọn ọmọ Beliali kan, yí ilé náà ká, wọ́n sì ń lu ìlẹ̀kùn; wọ́n sì sọ fún baálé ilé náà ọkùnrin arúgbó náà pé, “Mú ọkùnrin tí ó wọ̀ sínú ilé rẹ wá, kí àwa lè mọ̀ ọ́n.” Ọkùnrin, baálé ilé náà sì jáde tọ̀ wọ́n lọ, ó sì wí fún un pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́ ẹ̀yin arákùnrin mi, èmi bẹ̀ yín, ẹ má ṣe hùwà búburú; nítorí tí ọkùnrin yìí ti wọ ilé mi, ẹ má ṣe hùwà òmùgọ̀ yìí. Kíyèsi i, ọmọbìnrin mi ni èyí, wúńdíá, àti àlè rẹ̀; àwọn ni èmi ó mú jáde wá nísinsin yìí, kí ẹ̀yin tẹ̀ wọ́n lógo, kí ẹ̀yin ṣe sí wọn bí ó ti tọ́ lójú yín: ṣùgbọ́n ọkùnrin yìí ni kí ẹ̀yin má ṣe hùwà òmùgọ̀ yìí sí.” Ṣùgbọ́n àwọn ọkùnrin náà kò fetí sí tirẹ̀. Nítorí náà ọkùnrin náà mú àlè rẹ̀ ó sì tari rẹ̀ jáde sí wọn, wọ́n sì bá a fi ipá lòpọ̀, wọ́n sì fi gbogbo òru náà bá a lòpọ̀, nígbà tí ó di àfẹ̀mọ́júmọ́ wọ́n jọ̀wọ́ rẹ̀ lọ́. Nígbà tí ojúmọ́ bẹ̀rẹ̀ sí là obìnrin náà padà lọ sí ilé tí ọ̀gá rẹ̀ wà, ó ṣubú lulẹ̀ lọ́nà, ó sì wà níbẹ̀ títí ó fi di òwúrọ̀. Nígbà tí ọ̀gá rẹ̀ jí tí ó sì dìde ní òwúrọ̀ tí ó sì ṣí ìlẹ̀kùn ilé náà, tí ó sì bọ́ sí òde láti tẹ̀síwájú nínú ìrìnàjò rẹ̀, kíyèsi i àlè rẹ̀ wà ní ṣíṣubú ní iwájú ilé, tí ọwọ́ rẹ̀ sì di òpó ẹnu-ọ̀nà ibẹ̀ mú, òun sì wí fún obìnrin náà pé, “Dìde jẹ́ kí a máa bá ọ̀nà wa lọ.” Ṣùgbọ́n òun kò dá a lóhùn. Nígbà náà ni ọkùnrin náà gbé e lé orí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀, ó sì kọjá lọ sí ilé e rẹ̀. Nígbà tí ó dé ilé, ó mú ọ̀bẹ ó sì gé àlè rẹ̀ ní oríkeríke sí ọ̀nà méjìlá, ó sì fi wọ́n ránṣẹ́ sí gbogbo agbègbè Israẹli. Gbogbo ẹni tí ó rí i sì wí pé, “A kò ti rí i, bẹ́ẹ̀ a kò tí ì ṣe irú nǹkan yìí rí, kì í ṣe láti ọjọ́ tí Israẹli ti jáde tí Ejibiti wá títí di òní olónìí. Ẹ rò ó wò, ẹ gbìmọ̀ràn, kí ẹ sọ fún wa ohun tí a yóò ṣe!” Àwọn ọmọ Israẹli bá ará Benjamini jà Gbogbo àwọn ọmọ Israẹli láti Dani dé Beerṣeba, àti láti ilẹ̀ Gileadi jáde bí ẹnìkan ṣoṣo wọ́n sì péjọ síwájú Olúwa ni Mispa. Àwọn olórí gbogbo àwọn ènìyàn láti gbogbo ẹ̀yà Israẹli dúró ní ipò wọn ní àpéjọ àwọn ènìyàn Ọlọ́run, ogún ọ̀kẹ́ (400,000) ọkùnrin ológun ti àwọn àti idà wọn. (Àwọn ẹ̀yà Benjamini gbọ́ wí pé àwọn ọmọ Israẹli yòókù ti gòkè lọ sí Mispa.) Nígbà náà ni àwọn ọmọ Israẹli wí pé, “Ẹ sọ fún wa báwo ni iṣẹ́ búburú ṣe ṣẹlẹ̀.” Ará Lefi náà, ọkọ obìnrin tí wọ́n pa fèsì pé, “Èmi àti àlè mi wá sí Gibeah ti àwọn ará Benjamini láti sùn di ilẹ̀ mọ́ níbẹ̀. Ṣùgbọ́n ní òru àwọn ọkùnrin Gibeah lépa mi wọ́n sì yí ilé náà po pẹ̀lú èrò láti pa mí. Wọ́n fi ipá bá àlè mi lòpọ̀, òun sì kú. Mo mú àlè mi náà, mo sì gé e sí ekìrí ekìrí, mo sì fi ekìrí kọ̀ọ̀kan ránṣẹ́ sí agbègbè ìní Israẹli kọ̀ọ̀kan, nítorí pé wọ́n ti ṣe ohun tí ó jẹ́ èèwọ̀ àti ohun ìtìjú yìí ní ilẹ̀ Israẹli. Nísinsin yìí, gbogbo ẹ̀yin ọmọ Israẹli, ẹ sọ ìmọ̀ràn yín, kí ẹ sì ṣe ìdájọ́ yín.” Gbogbo àwọn ènìyàn náà sì dìde bí ẹnìkan pẹ̀lú gbólóhùn kan wí pé, “Kò sí ẹnikẹ́ni nínú wa tí yóò lọ sí àgọ́ rẹ̀. Rárá o, kò sí ẹyọ ẹnìkan tí yóò padà lọ sí ilé rẹ̀. Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, ohun tí àwa yóò ṣe sí Gibeah ní yìí. Àwa yóò lọ kọlù ú bí ìbò bá ṣe darí wa. A yóò mú ọkùnrin mẹ́wàá nínú ọgọ́rùn-ún nínú gbogbo ẹ̀yà Israẹli àti ọgọ́rùn-ún láti inú ẹgbẹ̀rún (1,000) kan àti ẹgbẹ̀rún kan láti inú ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) láti máa pèsè oúnjẹ fún àwọn ọmọ-ogun. Yóò sì ṣe nígbà tí àwọn jagunjagun bá dé Gibeah ti àwọn ará Benjamini, wọn yóò fún wọn ní ohun tí ó bá tọ́ sí wọn fún gbogbo ìwà búburú àti ìwà ìtìjú tí wọ́n ṣe yìí ní ilẹ̀ Israẹli.” Báyìí ni gbogbo àwọn ọkùnrin Israẹli parapọ̀ ṣọ̀kan bí ọkùnrin kan ṣoṣo wọ́n sì dìde sí ìlú náà. Àwọn ẹ̀yà Israẹli rán àwọn ọkùnrin sí gbogbo ẹ̀yà Benjamini wí pé, “Kí ni ẹ̀rí sí ìwà búburú yìí tí ó ṣẹlẹ̀ ní àárín yín? Nítorí náà ẹ mú àwọn ẹni ibi ti Gibeah yìí wá fún wa, kí àwa lé pa, kí a sì fọ ìṣe búburú yìí mọ́ kúrò ní Israẹli.” Ṣùgbọ́n àwọn ẹ̀yà Benjamini kò fetí sí ti àwọn arákùnrin wọn ọmọ Israẹli. Àwọn ẹ̀yà Benjamini sì kó ara wọn jọ láti àwọn ìlú wọn sí Gibeah láti bá àwọn ọmọ Israẹli jà. Ní ẹsẹ̀kẹsẹ̀ àwọn ará Benjamini kó ẹgbàá mẹ́tàlá (26,000) àwọn ọmọ-ogun tí ń lọ dájọ́ láti àwọn ìlú wọn, yàtọ̀ sí àwọn ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin (700) àṣàyàn ọkùnrin nínú àwọn tí ń gbé Gibeah. Ní àárín àwọn ọmọ-ogun wọ̀nyí ni ó ti ní àwọn ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin (700) àṣàyàn ọkùnrin tí wọ́n ń lo ọwọ́ òsì, tí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn dára dé bi pé wọ́n lè fi kànnàkànnà ba fọ́nrán òwú ní àìtàsé (wọ́n jẹ́ atamọ́tàsé). Àwọn ọkùnrin Israẹli, yàtọ̀ sí àwọn ará Benjamini, ka ogún ọ̀kẹ́ (400,000) àwọn tí ń fi idà jagun, gbogbo wọn jẹ́ akọni ní ogun jíjà. Àwọn ọmọ Israẹli lọ sí Beteli, wọ́n sì béèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run. Wọ́n wí pé, “Ta ni nínú wa tí yóò kọ́ kojú àwọn ará Benjamini láti bá wọn jà?” Olúwa dáhùn pé, “Juda ni yóò kọ́ lọ.” Àwọn ọmọ Israẹli dìde ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, wọ́n sì dó ti Gibeah (wọ́n tẹ̀gùn sí ẹ̀bá Gibeah). Àwọn ọkùnrin Israẹli jáde lọ láti bá àwọn ará Benjamini jà wọ́n sì dúró ní ipò ogun sí wọn ní Gibeah. Àwọn ọmọ Benjamini sì jáde láti Gibeah wá wọ́n sì pa àwọn ọmọ ẹgbẹ̀rún méjìlélógún (22,000) ọkùnrin nínú àwọn ọmọ Israẹli ní ojú ogun ní ọjọ́ náà. Ṣùgbọ́n àwọn ọkùnrin Israẹli mú ara wọn lọ́kàn le, wọ́n sì tún dúró sí ipò wọn ní ibi tí wọ́n dúró sí ní ọjọ́ àkọ́kọ́. Àwọn ọmọ Israẹli sì lọ wọ́n sọkún ní iwájú Olúwa títí oòrùn fi wọ̀, wọ́n sì béèrè lọ́wọ́ Olúwa. Wọ́n ni, “Ṣé kí àwa tún gòkè lọ kí a sì bá àwọn ará Benjamini arákùnrin wa jà?” Olúwa dáhùn pé, “Lọ bá wọn jà.” Àwọn ọmọ Israẹli sì tún súnmọ́ tòsí àwọn ará Benjamini ní ọjọ́ kejì. Ní ọjọ́ yìí nígbà tí ará Benjamini jáde sí wọn láti Gibeah, láti dojúkọ wọn, wọ́n pa ẹgbàá mẹ́sàn (18,000) ọkùnrin Israẹli, gbogbo wọn jẹ́ jagunjagun tí ń lo idà. Nígbà náà ni gbogbo àwọn ọmọ Israẹli àní gbogbo àwọn ènìyàn, gòkè lọ sí Beteli, níbẹ̀ ni wọ́n jókòó tí wọ́n sì ń sọkún níwájú Olúwa. Wọ́n gbààwẹ̀ ní ọjọ́ náà títí di àṣálẹ́, wọ́n sì rú ọrẹ ẹbọ sísun àti ọrẹ àlàáfíà sí Olúwa. Àwọn ọmọ Israẹli sì béèrè lọ́wọ́ Olúwa. (Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run wà níbẹ̀, Finehasi ọmọ Eleasari ọmọ Aaroni, ní ń ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ ní iwájú rẹ̀.) wọ́n béèrè pé, “Ṣe àwa tún le lọ sí ogun pẹ̀lú Benjamini arákùnrin wa tàbí kí a má lọ?” Olúwa dáhùn pé, “Ẹ lọ nítorí ní ọ̀la ni èmi yóò fi wọ́n lé e yín lọ́wọ́.” Àwọn ọmọ Israẹli sì yàn àwọn ènìyàn tí ó sá pamọ́ yí Gibeah ká. Wọ́n jáde tọ àwọn ọmọ Benjamini lọ ní ọjọ́ kẹta wọ́n sì dúró ní ipò wọn, wọ́n sì dìde ogun sí Gibeah bí wọ́n ti ṣe tẹ́lẹ̀ rí. Àwọn ọmọ Benjamini sì jáde láti pàdé wọn, àwọn ọmọ Israẹli sì tàn wọ́n jáde kúrò ní ìlú náà. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣẹ́gun àwọn ọmọ Israẹli bí i ti àtijọ́ dé bi pé wọ́n pa bí ọgbọ̀n ọkùnrin ní pápá àti ní àwọn òpópó náà—àwọn ọ̀nà tí ó lọ sí Beteli àti èkejì sí Gibeah. Nígbà tí àwọn Benjamini ń wí pé, “Àwa ti ń ṣẹ́gun wọn bí i ti ìṣáájú,” àwọn ọmọ Israẹli ń wí pé, “Ẹ jẹ́ kí a sá kí a lè fà wọ́n kúrò ní ìlú sí ojú òpópó náà.” Gbogbo àwọn ọkùnrin Israẹli dìde kúrò ní ipò wọn, wọ́n sì tẹ̀dó ogun ní Baali-Tamari, àwọn ọmọ-ogun Israẹli tí wọ́n sá pamọ́ sínú igbó jáde kúrò níbi tí wọ́n wà ní ìwọ̀-oòrùn Gibeah. Nígbà náà ni ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) àwọn àṣàyàn ológun àwọn ọmọ Israẹli gbógun ti Gibeah láti iwájú ogun náà le gidigidi dé bí i pé àwọn ẹ̀yà Benjamini kò funra pé ìparun wà nítòsí. Olúwa ṣẹ́gun Benjamini níwájú àwọn ọmọ Israẹli, ní ọjọ́ náà àwọn ọmọ Israẹli pa ẹgbàá méjìlá ó lé lẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀fà (25,100) ọkùnrin Benjamini, gbogbo wọn fi idà dìhámọ́ra ogun. Àwọn ẹ̀yà Benjamini sì rí pé wọ́n ti ṣẹ́gun àwọn. Àwọn ọkùnrin Israẹli fàsẹ́yìn níwájú àwọn ẹ̀yà Benjamini nítorí pé wọ́n fọkàn tán àwọn tí ó wà ní ibùba ní ẹ̀bá Gibeah. Àwọn ọkùnrin tí wọ́n lúgọ yára jáde wọ́n sì tètè wọ Gibeah, wọ́n fọ́nká wọ́n sì fi idà pa gbogbo àwọn tí ó wà nínú ìlú náà. Àwọn ọkùnrin Israẹli àti àwọn tí o ba ní ibùba sínú igbó ti fún ara wọn ní àmì pé, kí àwọn tí ó ba ní ibùba fi èéfín ṣe ìkùùkuu ńlá láti inú ìlú náà, nígbà náà ni àwọn ọkùnrin Israẹli yípadà, wọ́n sá gun. Àwọn ọmọ Benjamini sì ti bẹ̀rẹ̀ sí ṣẹ́gun àti ní pípa àwọn ọkùnrin Israẹli tí ó to ọgbọ̀n, wọ́n sì wí pé, “Àwa ń ṣẹ́gun wọn bí ìgbà ìjà àkọ́kọ́.” Ṣùgbọ́n nígbà tí ìkùùkuu èéfín bẹ̀rẹ̀ sí ní rú sókè láti inú ìlú náà wá, àwọn ẹ̀yà Benjamini yípadà wọ́n sì rí èéfín gbogbo ìlú náà ń gòkè sí ojú ọ̀run. Àwọn ọkùnrin Israẹli sì yípadà sí wọn, ẹ̀rù gidigidi sì ba àwọn ará Benjamini nítorí pé wọ́n mọ̀ pé àwọn wà nínú ewu. Wọ́n sì sá níwájú àwọn ọmọ Israẹli sí apá àṣálẹ́, ṣùgbọ́n wọn kò le sálà kúrò lọ́wọ́ ogun náà. Àwọn ọkùnrin Israẹli tí ó jáde láti inú àwọn ìlú wọn wá pa wọ́n run níbẹ̀. Wọ́n yí àwọn ẹ̀yà Benjamini ká, wọ́n lépa wọn, wọ́n sì pa wọ́n run pẹ̀lú ìrọ̀rùn ní ibi ìsinmi wọn ní agbègbè ìlà-oòrùn Gibeah. Ẹgbàá mẹ́sàn (18,000) àwọn ẹ̀yà Benjamini ṣubú, gbogbo wọn jẹ́ akọni jagunjagun. Bí wọ́n ṣe síjú padà tí wọ́n sì ń sálọ sí apá ijù lọ sí ọ̀nà àpáta Rimoni ni àwọn ọmọ Israẹli pa ẹgbẹ̀rún márùn-ún (5,000) ọkùnrin ní àwọn òpópónà. Wọ́n lépa àwọn ẹ̀yà Benjamini títí dé Gidomu, wọ́n sì tún bi ẹgbẹ̀rún méjì (2,000) ọkùnrin ṣubú. Ní ọjọ́ náà ẹgbàá méjìlá ó lé ẹgbẹ̀rún (25,000) jagunjagun Benjamini tí ń fi idà jagun ní ó ṣubú, gbogbo wọn jẹ́ akọni ológun. Ṣùgbọ́n ẹgbẹ̀ta (600) ọkùnrin yípadà wọ́n sì sá nínú ààlà lọ sí àpáta Rimoni, níbi tí wọ́n wà fún oṣù mẹ́rin. Àwọn ọkùnrin Israẹli sì padà sí àwọn ìlú Benjamini wọn sì fi idà pa gbogbo ohun tí ó wà nínú àwọn ìlú wọn àti àwọn ẹran àti gbogbo ohun tí wọn ba níbẹ̀. Gbogbo ìlú tí wọ́n bá ní ojú ọ̀nà ni wọ́n fi iná sun. Àwọn aya fún àwọn ẹ̀yà Benjamini Àwọn ọkùnrin Israẹli ti búra ní Mispa pé, “Kò sí ẹnìkan nínú wa tí yóò fi ọmọ obìnrin rẹ̀ fún ẹ̀yà Benjamini ní ìyàwó.” Àwọn ènìyàn náà lọ sí Beteli: ilé Ọlọ́run, níbi tí wọ́n jókòó níwájú Ọlọ́run títí di àṣálẹ́, wọ́n gbé ohùn wọn sókè, wọ́n sì sọkún kíkorò. Wọ́n sọkún wí pé, “Háà! Olúwa Ọlọ́run Israẹli, èéṣe tí nǹkan yìí fi ṣẹlẹ̀ sí Israẹli? Èéṣe tí ẹ̀yà kan yóò fi run nínú Israẹli lónìí?” Ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì àwọn ènìyàn náà mọ pẹpẹ kan wọ́n sì rú ẹbọ sísun àti ọrẹ àlàáfíà. Àwọn ọmọ Israẹli sì béèrè wí pé, “Èwo nínú ẹ̀yà Israẹli ni ó kọ̀ láti péjọ síwájú Olúwa?” Torí pé wọ́n ti fi ìbúra ńlá búra pé, ẹnikẹ́ni tí ó bá kọ̀ láti péjọ níwájú Olúwa ní Mispa pípa ni àwọn yóò pa á. Àwọn ọmọ Israẹli sì banújẹ́ fún àwọn arákùnrin wọn, àwọn ẹ̀yà Benjamini. Wọ́n wí pé, “A ti ké ẹ̀yà kan kúrò lára Israẹli lónìí.” Báwo ni a yóò ṣe rí aya fún àwọn tí ó ṣẹ́kù, nítorí àwa ti fi Olúwa búra láti má fi ọ̀kankan nínú àwọn ọmọbìnrin wa fún wọn ní aya. Wọ́n sì béèrè wí pé, “Èwo ni nínú ẹ̀yà Israẹli ni ó kọ̀ láti bá àwọn ènìyàn péjọ níwájú Olúwa ní Mispa?” Wọ́n rí i pé kò sí ẹnikẹ́ni tí ó wa láti Jabesi Gileadi tí ó wá sí ibùdó fún àjọ náà. Nítorí pé nígbà tí wọ́n ka àwọn ènìyàn, wọ́n rí i pé kò sí ẹnìkankan láti inú àwọn ará Jabesi Gileadi tí ó wà níbẹ̀. Àwọn ìjọ ènìyàn náà sì rán ẹgbàá mẹ́fà (12,000) àwọn jagunjagun ọkùnrin, lọ sí Jabesi Gileadi wọ́n fún wọn ní àṣẹ pé, ẹ lọ fi idà kọlu gbogbo àwọn tí ó wà níbẹ̀, pẹ̀lú àwọn obìnrin àti àwọn ọmọ wẹ́wẹ́. Wọ́n ní, “Èyí ni ẹ̀yin yóò ṣe, ẹ pa gbogbo ọkùnrin àti gbogbo obìnrin tí kì í ṣe wúńdíá.” Wọ́n rí àwọn irinwó (400) ọ̀dọ́bìnrin tí kò mọ ọkùnrin rí nínú àwọn olùgbé Jabesi Gileadi, wọ́n sì mú wọn lọ sí ibùdó ní Ṣilo àwọn ará Kenaani. Gbogbo ìjọ àwọn ènìyàn sì ránṣẹ́ àlàáfíà sí àwọn Benjamini ní ihò àpáta Rimoni. Àwọn ẹ̀yà Benjamini náà sì padà ní àkókò náà, wọ́n sì fún wọn ní àwọn obìnrin Jabesi Gileadi. Ṣùgbọ́n wọn kò kárí gbogbo wọn. Àwọn ènìyàn náà sì káàánú nítorí ẹ̀yà Benjamini, nítorí Olúwa fi àlàfo kan sílẹ̀ nínú àwọn ẹ̀yà Israẹli. Àwọn olórí ìjọ àwọn ènìyàn náà wí pé, “Kí ni àwa yóò ṣe láti rí aya fún àwọn ọkùnrin tí ó kù nígbà tí a ti pa gbogbo àwọn obìnrin Benjamini run?” Wọ́n sì wí pé, “Àwọn tí ó ṣẹ́kù tí wọ́n là nínú àwọn ẹ̀yà Benjamini ní láti ní ogún àti àrólé, kí ẹ̀yà kan nínú Israẹli má ṣe di píparun kúrò ní orí ilẹ̀. Àwa kò le fi àwọn ọmọbìnrin wa fún wọn ní aya, nítorí tí àwa ọmọ Israẹli ti ṣe ìbúra yìí pé, ‘Ègún ni fún ẹnikẹ́ni tí ó fi aya fún ẹnikẹ́ni nínú ẹ̀yà Benjamini.’ ” Wọ́n sì wí pé, “Kíyèsi i ayẹyẹ ọlọ́dọọdún fún Olúwa wà ní Ṣilo ní ìhà àríwá Beteli àti ìhà ìlà-oòrùn òpópó náà tí ó gba Beteli kọjá sí Ṣekemu, àti sí ìhà gúúsù Lebona.” Wọ́n sì fi àṣẹ fún àwọn ará Benjamini pé, “Ẹ lọ kí ẹ sì fi ara pamọ́ nínú àwọn ọgbà àjàrà kí ẹ sì wà ní ìmúrasílẹ̀. Nígbà tí àwọn ọmọbìnrin Ṣilo bá jáde láti lọ darapọ̀ fún ijó, kí ẹ yára jáde láti inú àwọn ọgbà àjàrà wọ̀n-ọn-nì kí ẹnìkọ̀ọ̀kan yín gbé aya kan nínú àwọn ọmọbìnrin Ṣilo kí ẹ padà sí ilẹ̀ Benjamini. Nígbà tí àwọn baba wọn tàbí àwọn arákùnrin wọn bá fi ẹjọ́ sùn wá, àwa yóò wí fún wọn pé, ‘Ẹ ṣe wá ní oore nípa ríràn wọ́n lọ́wọ́, nítorí àwa kò rí aya fún wọn ní àkókò ogun, ẹ̀yin kò sì ní jẹ̀bi, nítorí pé ẹ̀yin kọ́ ni ó fi àwọn ọmọbìnrin yín fún wọn bí aya.’ ” Èyí sì ni ohun tí àwọn ẹ̀yà Benjamini ṣe. Nígbà tí àwọn ọmọbìnrin náà ń jó lọ́wọ́, ọkùnrin kọ̀ọ̀kan mú ọmọbìnrin kọ̀ọ̀kan, wọ́n sì gbé e lọ láti di aya rẹ̀. Wọ́n sì padà sí ilẹ̀ ìní wọn, wọ́n sì tún àwọn ìlú náà kọ́, wọ́n sì tẹ̀dó sínú wọn. Ní àkókò náà, àwọn ọmọ Israẹli kúrò ní ibẹ̀, wọ́n lọ sí ilé àti ẹ̀yà rẹ̀ olúkúlùkù sí ilẹ̀ ìní rẹ̀. Ní àwọn ọjọ́ wọ̀nyí, kò sí ọba ní ilẹ̀ Israẹli; olúkúlùkù sì ń ṣe bí ó ti tọ́ ní ojú ara rẹ̀.