- Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible 2017
Habakuku
Ìwé Wòlíì Habakuku
Habakuku
Hk
Ìwé Wòlíì Habakuku
Àsọtẹ́lẹ̀ tí wòlíì Habakuku rí.
Ìráhùn Habakuku
Olúwa, èmi yóò ti ké pẹ́ tó fún ìrànlọ́wọ́,
ṣùgbọ́n ti ìwọ kò ni fetí sí mi?
Tàbí kígbe sí ọ ní ti, “Ìwà ipá!”
Ṣùgbọ́n tí ìwọ kò sì gbàlà?
Èéṣe tí ìwọ fi mú mi rí àìṣedéédéé?
Èéṣe tí ìwọ sì fi ààyè gba ìwà ìkà?
Ìparun àti ìwà ipá wà ní iwájú mi;
ìjà ń bẹ, ìkọlù sì wà pẹ̀lú.
Nítorí náà, òfin di ohun àìkàsí,
ìdájọ́ òdodo kò sì borí.
Àwọn ẹni búburú yí àwọn olódodo ká,
nítorí náà ni ìdájọ́ òdodo ṣe yí padà.
Ìdáhùn Olúwa
“Ẹ wo inú àwọn kèfèrí, ki ẹ sí wòye,
kí háà kí ó sì ṣe yin gidigidi.
Nítorí èmi ó ṣe ohun kan ní ọjọ́ yín
tí ẹ̀yin kò jẹ́ gbàgbọ́,
bí a tilẹ̀ sọ fún yin.
Nítorí pé, èmi yóò gbé àwọn ara Babeli dìde,
àwọn aláìláàánú àti onínú-fùfù ènìyàn
tí ó rin gbogbo ilẹ̀ ayé já
láti fi agbára gbà àwọn ibùgbé tí kì í ṣe tiwọn.
Wọn jẹ́ ènìyàn ti a bẹ̀rù, tí a sì páyà,
ìdájọ́ wọn, àti ọláńlá wọn,
yóò máa ti inú wọn jáde.
Ẹṣin wọn yára ju ẹkùn lọ,
wọ́n sì gbóná jú ìkookò àṣálẹ́ lọ
àwọn ẹlẹ́ṣin wọn yóò sí tan ara wọn ká;
wọn yóò sì wá láti ọ̀nà jíjìn réré,
wọn yóò sí fò bí ẹyẹ igún tí ń wá láti jẹrun,
gbogbo wọn sì wà fún ìwà ipá
ìwò ojú wọn yóò sì wá síwájú;
wọn sì ko ìgbèkùn jọ bí iyanrìn.
Wọn ó si máa fi àwọn ọba ṣẹ̀sín
wọn ó sì tún kẹ́gàn àwọn aládé.
Wọn yóò sì fi gbogbo ìlú odi alágbára nì rẹ́rìn-ín;
nítorí pé, wọn yóò ko erùpẹ̀ jọ, wọn yóò sì gbà á.
Nígbà náà ni inú rẹ̀ yóò yípadà,
yóò sì rékọjá, yóò si ṣẹ̀ ní kíka agbára rẹ̀ yìí sí iṣẹ́ òrìṣà rẹ̀.”
Ìráhùn lẹ́ẹ̀kejì Habakuku
Olúwa, ǹjẹ́ láti ayérayé kọ ni ìwọ tí wà?
Olúwa Ọlọ́run mi. Ẹni mímọ́ mi, àwa kì yóò kú
Olúwa, ìwọ tí yàn wọn fún ìdájọ́;
Ọlọ́run alágbára, ìwọ tí fi ẹsẹ̀ wọn múlẹ̀ fún ìbáwí.
Ojú rẹ mọ́ tónítóní láti wo ibi;
ìwọ kò le gbà ìwà ìkà
nítorí kí ni ìwọ ṣe gba àwọn alárékérekè láààyè?
Nítorí kí ni ìwọ ṣe dákẹ́ nígbà tí ẹni búburú ń pa
ẹni tí i ṣe olódodo ju wọn lọ run?
Ìwọ sì tí sọ ènìyàn di bí ẹja inú Òkun,
bí ohun tí ń rákò tí wọn ko ni alákòóso.
Àwọn ènìyàn búburú fi àwọ̀n wọn gbé wọn sókè
ó sì kó wọn jọ nínú àwọ̀n ńlá rẹ̀;
nítorí náà, ó dunnú, ó sì yọ̀ pẹ̀lú.
Nítorí náà, ó rú ẹbọ sí àwọ̀n rẹ̀,
ó sì ń sun tùràrí fún àwọ̀n ńlá rẹ̀
nítorí pẹ̀lú àwọ̀n rẹ̀ ni ó fi ń gbé ní ìgbádùn
tí ó sì ń gbádùn pẹ̀lú oúnjẹ tí ó bá wù ú.
Ǹjẹ́ wọn yóò ha máa pa àwọ̀n wọn mọ́ ní òfìfo bí,
tí wọn yóò sì pa orílẹ̀-èdè run láìsí àánú?
Ìdáhùn Ọlọ́run sí ìráhùn wòlíì Habakuku
Èmi yóò dúró lórí ibusọ́ mi láti máa wòye,
èmi yóò sì gbé ara mi ka orí alóre,
èmi yóò si ṣọ́ láti gbọ́ ohun tí yóò sọ fún mi
àti èsì ti èmi yóò fún ẹ̀sùn yìí nígbà tó bá ń bá mi wí.
Ìdáhùn Olúwa
Nígbà náà ni Olúwa dáhùn pé,
“Kọ ìṣípayá náà sílẹ̀
kí o sì fi hàn ketekete lórí wàláà
kí ẹni tí ń kà á, lè máa sáré.
Nítorí ìṣípayá náà jẹ́ tí ìgbà kan tí a múra sílẹ̀ dè;
yóò máa yára sí ìgbẹ̀yìn
kí yóò sìsọ èké.
Bí o tilẹ̀ lọ́ra, dúró dè é;
nítorí, dájúdájú, yóò dé, kí yóò sí pẹ́.”
“Kíyèsi, ọkàn rẹ tí ó gbéga,
ìfẹ́ rẹ̀ kò dúró ṣinṣin nínú rẹ̀,
ṣùgbọ́n olódodo yóò wa nípa ìgbàgbọ́ rẹ̀.
Bẹ́ẹ̀ ni pẹ̀lú, nítorí tí ọtí wáìnì ni ẹ̀tàn,
agbéraga ènìyàn òun, kò sì ní sinmi
ẹni tí ó sọ ìwọra rẹ di gbígbòòrò bí isà òkú,
ó sì dàbí ikú, a kò sì le tẹ́ ẹ lọ́rùn,
ó kó gbogbo orílẹ̀-èdè jọ sí ọ̀dọ̀
ó sì gba gbogbo ènìyàn jọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀.
“Gbogbo àwọn wọ̀nyí kì yóò máa pa òwe sí i tí wọn yóò sì máa kọ orin òwe sí i wí pé,
“ ‘Ègbé ni fún ẹni tí ń mu ohun tí kì í ṣe tirẹ̀ pọ̀ sí i!
Tí ó sì sọ ara rẹ̀ di ọlọ́rọ̀ nípasẹ̀ ìlọ́nilọ́wọ́gbà!
Eléyìí yóò ha ti pẹ́ tó?’
Ǹjẹ́ ẹni ti ó yọ ọ́ lẹ́nu, kí yóò ha dìde ní òjijì?
Àti àwọn tí ó wàhálà rẹ kì yóò jí, kí wọn ó sì dẹ́rùbà ọ́?
Nígbà náà ni ìwọ yóò wa dí ìkógun fún wọn.
Nítorí ìwọ ti kó Orílẹ̀-èdè púpọ̀,
àwọn ènìyàn tókù yóò sì kó ọ
nítorí ìwọ tí ta ẹ̀jẹ̀ ènìyàn sílẹ̀; nítorí ẹ̀jẹ̀,
ìwọ tí pa ilẹ̀ àti ìlú ńlá run
àti gbogbo ènìyàn to ń gbé inú rẹ̀.
“Ègbé ni fún ẹni tí ń jẹ èrè ìjẹkújẹ sí ilé rẹ̀,
tí o sí gbé ìtẹ́ rẹ̀ lórí ibi gíga,
kí a ba le gbà á sílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ ibi!
Ìwọ ti gbìmọ̀ ìtìjú sí ilé rẹ
nípa kíké ènìyàn púpọ̀ kúrò;
ìwọ sì ti pàdánù ẹ̀mí rẹ.
Nítorí tí òkúta yóò kígbe jáde láti inú ògiri wá,
àti ìtí igi láti inú igi rírẹ́ wá yóò sì dá a lóhùn.
“Ègbé ni fún ẹni tí ó fi ẹ̀jẹ̀ kọ́ ìlú,
tí o sì fi àìṣedéédéé tẹ ìlú ńlá dó?
Olúwa àwọn ọmọ-ogun kò ha ti ṣètò rẹ̀ pé
làálàá àwọn ènìyàn jẹ́ epo fún iná
kí àwọn orílẹ̀-èdè náà sì máa ṣe wàhálà fún asán?
Nítorí tí ayé yóò kún fún ìmọ̀ ògo Olúwa,
bí omi ti bo Òkun.
“Ègbé ni fún ẹni tí ó fi ohun mímu fún aládùúgbò rẹ̀,
tí ó sì fi ọtí-lílé rẹ̀ fún un, tí o sì jẹ́ kó mu àmupara,
kí ìwọ kí ó ba lè wo ìhòhò wọn.”
Ìtìjú yóò bò ọ́ dípò ògo, ìwọ náà mu pẹ̀lú
kí ìhòhò rẹ kí ó lè hàn,
ago ọwọ́ ọ̀tún Olúwa, yóò yípadà sí ọ,
ìtìjú yóò sì bo ògo rẹ.
Nítorí ìwà ipá tí ó tí hù sí Lebanoni yóò bò ọ́,
àti ìparun àwọn ẹranko yóò dẹ́rùbà ọ́ mọ́lẹ̀.
Nítorí ìwọ tí ta ẹ̀jẹ̀ ènìyàn sílẹ̀;
ìwọ tí pa ilẹ̀ náà àti ìlú ńlá run àti gbogbo àwọn tí ń gbé inú rẹ̀.
“Èrè kí ni òrìṣà ni, tí oníṣọ̀nà rẹ̀ fi gbẹ́ ẹ,
ère dídá ti ń kọ ni èké?
Nítorí ti ẹni ti ó dá a gbẹ́kẹ̀ rẹ̀ lé ohun tí ó fúnra rẹ̀ dá;
ó sì mọ ère tí kò le fọhùn.
Ègbé ni fún ẹni ti ń sọ fún igi pé, ‘Di alààyè?’
Fún òkúta tí kò lè fọhùn pé, ‘Dìde.’
Ǹjẹ́ òun lè tọ́ ni sí ọ̀nà?
Wúrà àti fàdákà ni a fi bò ó yíká;
kò sì sí èémí kan nínú rẹ.”
Ṣùgbọ́n Olúwa wà nínú tẹmpili mímọ́ rẹ̀;
ẹ jẹ́ kí gbogbo ayé parọ́rọ́ níwájú rẹ.
Àdúrà Habakuku
Àdúrà wòlíì Habakuku gẹ́gẹ́ bí sígónótì. Ohun èlò orin.
Olúwa mo tí gbọ́ ohùn rẹ;
ẹ̀rù sì ba mi fún iṣẹ́ rẹ Olúwa
sọ wọn di ọ̀tún ní ọjọ́ ti wa,
ní àkókò tiwa, jẹ́ kó di mí mọ̀;
ni ìbínú, rántí àánú.
Ọlọ́run yóò wa láti Temani,
ibi mímọ́ jùlọ láti òkè Parani
ògo rẹ̀ sí bo àwọn ọ̀run,
ilé ayé sì kún fún ìyìn rẹ.
Dídán rẹ sí dàbí ìmọ́lẹ̀ oòrùn
ìtànṣán ìmọ́lẹ̀ jáde wa láti ọwọ́ rẹ,
níbi tí wọn fi agbára rẹ̀ pamọ́ sí.
Àjàkálẹ̀-ààrùn ń lọ ni iwájú rẹ;
ìyọnu sí ń tọ ẹsẹ̀ rẹ lọ.
Ó dúró, ó sì mi ayé;
ó wò, ó sì mú àwọn orílẹ̀-èdè wárìrì
a sì tú àwọn òkè ńlá ayérayé ká,
àwọn òkè kéékèèké ayérayé sì tẹríba:
ọ̀nà rẹ ayérayé ni.
Mo rí àgọ́ Kuṣani nínú ìpọ́njú
àti àwọn ibùgbé Midiani nínú ìrora.
Ǹjẹ́ ìwọ ha ń bínú sí àwọn odò nì, Olúwa?
Ǹjẹ́ ìbínú rẹ wa lórí àwọn odò ṣíṣàn bí?
Ìbínú rẹ ha wá sórí Òkun
tí ìwọ fi ń gun ẹṣin,
àti kẹ̀kẹ́ ìgbàlà rẹ?
A ṣí ọrun rẹ sílẹ̀ pátápátá,
gẹ́gẹ́ bí ìbúra àwọn ẹ̀yà, àní ọ̀rọ̀ rẹ,
ìwọ sì fi odò pín ilẹ̀ ayé.
Àwọn òkè ńlá ri ọ wọn sì wárìrì
àgbàrá òjò ń sàn án kọjá lọ;
ibú ń ké ramúramù
ó sì gbé irú omi sókè.
Òòrùn àti Òṣùpá dúró jẹ́ẹ́jẹ́ ni ibùgbé wọn,
pẹ̀lú ìmọ́lẹ̀ ọfà rẹ ni wọn yára lọ,
àti ni dídán ọ̀kọ̀ rẹ ti ń kọ mànà.
Ní ìrunú ni ìwọ rin ilẹ̀ náà já,
ní ìbínú ni ìwọ tí tẹ́ àwọn orílẹ̀-èdè rẹ.
Ìwọ jáde lọ láti tú àwọn ènìyàn rẹ sílẹ̀,
àti láti gba ẹni àmì òróró rẹ là,
Ìwọ ti run àwọn olórí kúrò nínú ilẹ̀ àwọn ènìyàn búburú,
ó sì bọ ìhámọ́ra rẹ láti orí de ẹsẹ̀.
Pẹ̀lú ọ̀kọ̀ rẹ̀ kí ó fi gún orí rẹ
nígbà tí àwọn jagunjagun rẹ̀
jáde láti tú wá ká,
ayọ̀ wọn sì ni láti jẹ tálákà run ní ìkọ̀kọ̀.
Ìwọ fi ẹṣin rẹ rìn Òkun já,
ó sì da àwọn omi ńlá ru.
Mo gbọ́, ọkàn mi sì wárìrì,
ètè mi sì gbọ̀n sí ìró náà;
ìbàjẹ́ sì wọ inú egungun mi lọ,
ẹsẹ̀ mi sì wárìrì,
mo dúró ni ìdákẹ́ jẹ́ẹ́ fún ọjọ́ ìdààmú
láti de sórí àwọn ènìyàn tó ń dojúkọ wá.
Bí igi ọ̀pọ̀tọ́ ko tilẹ̀ tanná,
tí èso kò sí nínú àjàrà;
tí igi olifi ko le so,
àwọn oko ko sì mú oúnjẹ wá;
tí a sì ké agbo ẹran kúrò nínú agbo,
tí kò sì sí ọwọ́ ẹran ni ibùso mọ́,
síbẹ̀, èmi ó láyọ̀ nínú Olúwa,
èmi yóò sí máa yọ nínú Ọlọ́run ìgbàlà mi.
Olúwa Olódùmarè ni agbára mi,
òun yóò sí ṣe ẹsẹ̀ mi bí ẹsẹ̀ abo àgbọ̀nrín,
yóò sí mú mi rìn lórí ibi gíga.
Sí olórí akọrin lórí ohun èlò orin olókùn mi.