- Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible 2017 Gẹnẹsisi Ìwé Gẹnẹsisi Gẹnẹsisi Gẹ Ìwé Gẹnẹsisi Ìbẹ̀rẹ̀ dídá ayé Ní ìbẹ̀rẹ̀ ohun gbogbo Ọlọ́run dá àwọn ọ̀run àti ayé. Ayé sì wà ní rúdurùdu, ó sì ṣófo, òkùnkùn sì wà lójú ibú omi, Ẹ̀mí Ọlọ́run sì ń rábàbà lójú omi. Ọlọ́run sì wí pé, “Jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ kí ó wà,” ìmọ́lẹ̀ sì wà. Ọlọ́run rí i pé ìmọ́lẹ̀ náà dára, ó sì ya ìmọ́lẹ̀ náà sọ́tọ̀ kúrò lára òkùnkùn. Ọlọ́run sì pe ìmọ́lẹ̀ náà ní “ọ̀sán,” àti òkùnkùn ní “òru.” Àṣálẹ́ àti òwúrọ̀ sì jẹ́ ọjọ́ kìn-ín-ní. Ọlọ́run sì wí pé, “Jẹ́ kí òfúrufú kí ó wà ní àárín àwọn omi, láti pààlà sí àárín àwọn omi.” Ọlọ́run sì dá òfúrufú láti ya omi tí ó wà ní òkè òfúrufú kúrò lára omi tí ó wà ní orí ilẹ̀. Ó sì rí bẹ́ẹ̀. Ọlọ́run sì pe òfúrufú ní “ọ̀run.” Àṣálẹ́ àti òwúrọ̀ sì jẹ́ ọjọ́ kejì. Ọlọ́run sì wí pé, “Jẹ́ kí omi abẹ́ ọ̀run wọ́ papọ̀ sí ojú kan, kí ilẹ̀ gbígbẹ sì farahàn.” Ó sì rí bẹ́ẹ̀. Ọlọ́run sì pe ilẹ̀ gbígbẹ náà ní “ilẹ̀,” àti àpapọ̀ omi ní “òkun.” Ọlọ́run sì rí i wí pé ó dára. Ọlọ́run sì wí pé, “Jẹ́ kí ilẹ̀ kí ó hu ọ̀gbìn: ewéko ti yóò máa mú èso wá àti igi tí yóò máa so èso ní irú tirẹ̀, tí ó ní irúgbìn nínú.” Ó sì rí bẹ́ẹ̀. Ilẹ̀ sì hù ọ̀gbìn: ewéko tí ó ń so èso ní irú tirẹ̀, àti igi tí ń so èso, tí ó ní irúgbìn nínú ní irú tirẹ̀. Ọlọ́run sì ri pé ó dára. Àṣálẹ́ àti òwúrọ̀ sì jẹ́ ọjọ́ kẹta. Ọlọ́run sì wí pé, “Jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ kí ó wà ní ojú ọ̀run, láti pààlà sí àárín ọ̀sán àti òru, kí wọn ó sì máa wà fún àmì láti mọ àwọn àsìkò, àti àwọn ọjọ́ àti àwọn ọdún. Kí wọn ó jẹ́ ìmọ́lẹ̀ ní ojú ọ̀run láti tan ìmọ́lẹ̀ sí orí ilẹ̀.” Ó sì rí bẹ́ẹ̀. Ọlọ́run dá ìmọ́lẹ̀ ńlá ńlá méjì, ìmọ́lẹ̀ tí ó tóbi láti ṣe àkóso ọ̀sán àti ìmọ́lẹ̀ tí ó kéré láti ṣe àkóso òru. Ó sì dá àwọn ìràwọ̀ pẹ̀lú. Ọlọ́run sì ṣe wọ́n lọ́jọ̀ sí ojú ọ̀run láti máa tan ìmọ́lẹ̀ si orí ilẹ̀, láti ṣàkóso ọ̀sán àti òru àti láti pààlà sí àárín ìmọ́lẹ̀ àti òkùnkùn. Ọlọ́run sì rí i pé ó dára. Àṣálẹ́ àti òwúrọ̀ sì jẹ́ ọjọ́ kẹrin. Ọlọ́run sì wí pé, “Jẹ́ kí omi kí ó kún fún àwọn ohun alààyè, kí àwọn ẹyẹ kí ó sì máa fò ní òfúrufú.” Nítorí náà Ọlọ́run dá àwọn ẹ̀dá alààyè ńlá ńlá sí inú òkun, àwọn ohun ẹlẹ́mìí àti àwọn ohun tí ń rìn ní onírúurú tiwọn, àti àwọn ẹyẹ abìyẹ́ ní onírúurú tiwọn. Ọlọ́run sì rí i pé ó dára. Ọlọ́run súre fún wọn, ó sì wí pé, “Ẹ máa bí sí i, ẹ sì máa pọ̀ sí i, ẹ kún inú omi òkun, kí àwọn ẹyẹ náà sì máa pọ̀ sí i ní orí ilẹ̀.” Àṣálẹ́ àti òwúrọ̀ sì jẹ́ ọjọ́ karùn-ún. Ọlọ́run sì wí pé, “Kí ilẹ̀ kí ó mú ohun alààyè jáde ní onírúurú wọn: ẹran ọ̀sìn, àwọn ohun afàyàfà àti àwọn ẹran inú igbó, ọ̀kọ̀ọ̀kan ní irú tirẹ̀.” Ó sì rí bẹ́ẹ̀. Ọlọ́run sì dá ẹranko inú igbó àti ẹran ọ̀sìn gbogbo ní irú tirẹ̀ àti gbogbo ohun alààyè tí ń rìn ní ilẹ̀ ní irú tirẹ̀. Ọlọ́run sì rí i pé ó dára. Lẹ́yìn náà ni Ọlọ́run wí pé, “Ẹ jẹ́ kí a dá ènìyàn ní àwòrán ara wa, gẹ́gẹ́ bí àwa ti rí, kí wọn kí ó jẹ ọba lórí ẹja òkun, ẹyẹ ojú ọ̀run, ẹran ọ̀sìn, gbogbo ilẹ̀ àti lórí ohun gbogbo tí ń rìn lórí ilẹ̀.” Nítorí náà, Ọlọ́run dá ènìyàn ní àwòrán ara rẹ̀, ní àwòrán Ọlọ́run ni ó dá a, akọ àti abo ni ó dá wọn. Ọlọ́run sì súre fún wọn, Ọlọ́run sì wí fún wọn pé, “Ẹ máa bí sí i, kí ẹ sì máa pọ̀ sí i, kí ẹ sì gbilẹ̀, kí ẹ ṣe ìkápá ayé. Ẹ ṣe àkóso àwọn ẹja inú òkun, ẹyẹ ojú ọ̀run àti gbogbo ẹ̀dá alààyè tí ó ń rìn ní orí ilẹ̀.” Nígbà náà ni Ọlọ́run wí pé, “Mo fi gbogbo ohun ọ̀gbìn tí ń so èso fún un yín bí oúnjẹ àti àwọn igi eléso pẹ̀lú. Gbogbo rẹ̀ yóò jẹ́ oúnjẹ fún un yín. Àti fún àwọn ẹranko inú igbó àti ẹyẹ ojú ọ̀run àti àwọn ohun afàyàfà, gbogbo ohun tó ní èémí ìyè nínú ni mo fi ewéko fún bí oúnjẹ.” Ó sì rí bẹ́ẹ̀. Ọlọ́run sì rí àwọn ohun gbogbo tí ó dá, ó dára gidigidi. Àṣálẹ́ àti òwúrọ̀ sì jẹ́ ọjọ́ kẹfà. Báyìí ni Ọlọ́run parí dídá àwọn ọ̀run àti ayé, àti ohun gbogbo tí ó wà nínú rẹ̀. Ní ọjọ́ keje Ọlọ́run sì parí iṣẹ́ rẹ̀ tí ó ti ń ṣe; ó sì sinmi ní ọjọ́ keje kúrò nínú iṣẹ́ rẹ̀ gbogbo tí ó ti ń ṣe. Ọlọ́run sì súre fún ọjọ́ keje, ó sì yà á sí mímọ́, nítorí pé ní ọjọ́ náà ni ó sinmi kúrò nínú iṣẹ́ dídá ayé tí ó ti ń ṣe. Adamu àti Efa Èyí ni ìtàn bí Ọlọ́run ṣe dá àwọn ọ̀run àti ayé nígbà tí ó dá wọn. Nígbà tí Olúwa Ọlọ́run dá ayé àti àwọn ọ̀run. Kò sí igi igbó kan ní orí ilẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ewéko igbó kan tí ó tí ì hù jáde ní ilẹ̀, nítorí Olúwa Ọlọ́run kò tí ì rọ̀jò sórí ilẹ̀, kò sì sí ènìyàn láti ro ilẹ̀. Ṣùgbọ́n ìsun omi ń jáde láti ilẹ̀, ó sì ń bu omi rin gbogbo ilẹ̀. Olúwa Ọlọ́run sì fi erùpẹ̀ ilẹ̀ mọ ènìyàn, ó si mí èémí ìyè sí ihò imú rẹ̀, ènìyàn sì di alààyè ọkàn. Olúwa Ọlọ́run sì gbin ọgbà kan sí Edeni ní ìhà ìlà-oòrùn, níbẹ̀ ni ó fi ọkùnrin náà tí ó ti dá sí. Olúwa Ọlọ́run sì mú kí onírúurú igi hù jáde láti inú ilẹ̀, àwọn igi tí ó dùn ún wò lójú, tí ó sì dára fún oúnjẹ. Ní àárín ọgbà náà ni igi ìyè àti igi tí ń mú ènìyàn mọ rere àti búburú wà. Odò kan sì ń ti Edeni sàn wá láti bu omi rin ọgbà náà, láti ibẹ̀ ni odò náà gbé ya sí ipa mẹ́rin. Orúkọ èkínní ni Pisoni, òun ni ó sàn yí gbogbo ilẹ̀ Hafila ká, níbi tí wúrà gbé wà. (Wúrà ilẹ̀ náà dára, òjìá2.12 tí ó túmọ̀ sí, bedeliumu àti òkúta óníkìsì oníyebíye wà níbẹ̀ pẹ̀lú). Orúkọ odò kejì ni Gihoni, òun ni ó sàn yí gbogbo ilẹ̀ Kuṣi ká. Orúkọ odò kẹta ni Tigirisi, òun ni ó sàn ní apá ìlà-oòrùn ilẹ̀ Asiria. Odò kẹrin ni Eufurate. Olúwa Ọlọ́run mú ọkùnrin náà sínú ọgbà Edeni láti máa ṣe iṣẹ́ níbẹ̀, kí ó sì máa ṣe ìtọ́jú rẹ̀. Olúwa Ọlọ́run sì pàṣẹ fún ọkùnrin náà pé, “Ìwọ lè jẹ lára èyíkéyìí èso àwọn igi inú ọgbà; ṣùgbọ́n ìwọ kò gbọdọ̀ jẹ nínú èso igi ìmọ̀ rere àti èso igi ìmọ̀ búburú, nítorí ní ọjọ́ tí ìwọ bá jẹ ẹ́ ni ìwọ yóò kùú.” Olúwa Ọlọ́run wí pé, “Kò dára kí ọkùnrin wà ní òun nìkan. Èmi yóò ṣe olùrànlọ́wọ́ tí ó rí bí i rẹ̀ fún un.” Lẹ́yìn tí Olúwa Ọlọ́run ti dá àwọn ẹranko inú igbó àti gbogbo ẹyẹ ojú ọ̀run láti inú erùpẹ̀ ilẹ̀. Ó sì kó wọn tọ ọkùnrin náà wá láti wo orúkọ tí yóò sọ wọ́n; orúkọ tí ó sì sọ gbogbo ẹ̀dá alààyè náà ni wọ́n ń jẹ́. Gbogbo ohun ọ̀sìn, ẹyẹ ojú ọ̀run àti gbogbo ẹranko igbó ni ọkùnrin náà sọ ní orúkọ. Ṣùgbọ́n fún Adamu ni a kò rí olùrànlọ́wọ́ tí ó rí bí i rẹ̀. Nígbà náà ni Olúwa Ọlọ́run mú kí ọkùnrin náà sùn fọnfọn; nígbà tí ó sì ń sùn, Ọlọ́run yọ egungun ìhà rẹ̀ kan, ó sì fi ẹran-ara bò ó padà. Olúwa Ọlọ́run sì dá obìnrin láti inú egungun tí ó yọ ní ìhà ọkùnrin náà, Ó sì mu obìnrin náà tọ̀ ọ́ wá. Ọkùnrin náà sì wí pé, “Èyí ni egungun láti inú egungun mi àti ẹran-ara nínú ẹran-ara mi; ‘obìnrin’ ni a ó máa pè é, nítorí a mú un jáde láti ara ọkùnrin.” Nítorí ìdí èyí, ọkùnrin yóò fi baba àti ìyá rẹ̀ sílẹ̀, yóò sì dàpọ̀ mọ́ aya rẹ̀, wọn yóò sì di ara kan. Ọkùnrin náà àti aya rẹ̀ sì wà ní ìhòhò, ojú kò sì tì wọ́n. Ìṣubú ènìyàn Ejò sá à ṣe alárékérekè ju àwọn ẹranko igbó yòókù tí Olúwa Ọlọ́run dá lọ. Ó sọ fún obìnrin náà pé, “Ǹjẹ́ òtítọ́ ha ni Ọlọ́run wí pé, ‘Ẹ̀yin kò gbọdọ̀ jẹ èso èyíkéyìí lára àwọn igi tí ó wà nínú ọgbà’?” Obìnrin náà dá ejò lóhùn pé, “Àwa lè jẹ lára àwọn èso igi tí ó wà nínú ọgbà, ṣùgbọ́n Ọlọ́run sọ pé, ‘Ẹ̀yin kò gbọdọ̀ jẹ lára èso igi tí ó wà láàrín ọgbà, ẹ kò sì gbọdọ̀ fi ọwọ́ kàn án, bí ẹ̀yin bá ṣe bẹ́ẹ̀, ẹ̀yin yóò kùú.’ ” Ejò wí fún obìnrin náà pé, “Ẹ̀yin kì yóò kú ikúkíkú kan.” “Nítorí Ọlọ́run mọ̀ wí pé, bí ẹ̀yin bá jẹ nínú rẹ̀, ojú yín yóò là, ẹ̀yin yóò sì dàbí Ọlọ́run, ẹ̀yin yóò sì mọ rere yàtọ̀ sí búburú.” Nígbà tí obìnrin náà rí i wí pé èso igi náà dára fún oúnjẹ àti pé, ó sì dùn ún wò, àti pé ó ń mú ni ní ọgbọ́n, ó mú díẹ̀ níbẹ̀, ó sì jẹ ẹ́. Ó sì mú díẹ̀ fún ọkọ rẹ̀, ẹni tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀, òun náà sì jẹ ẹ́. Nígbà náà ni ojú àwọn méjèèjì sì là, wọ́n sì mọ̀ pé àwọn wà ní ìhòhò; wọ́n sì rán ewé ọ̀pọ̀tọ́ pọ̀, wọ́n sì fi bo ara wọn. Nígbà náà ni ọkùnrin náà àti aya rẹ̀ gbọ́ ìró Olúwa Ọlọ́run bí ó ti ń rìn nínú ọgbà, nígbà tí ojú ọjọ́ tura, wọ́n sì fi ara pamọ́ kúrò níwájú Olúwa Ọlọ́run sí àárín àwọn igi inú ọgbà. Ṣùgbọ́n Olúwa Ọlọ́run ké pe ọkùnrin náà pé, “Níbo ni ìwọ wà?” Ó dáhùn pé, “Mo gbúròó rẹ̀ nínú ọgbà, ẹ̀rù sì bà mí, nítorí pé, mo wà ní ìhòhò, mo sì fi ara pamọ́.” Ọlọ́run wí pé, “Ta ni ó wí fún ọ pé ìhòhò ni ìwọ wà? Ṣé ìwọ ti jẹ nínú èso igi tí mo pàṣẹ fún ọ pé ìwọ kò gbọdọ̀ jẹ nínú rẹ̀ ni?” Ọkùnrin náà wí pé, “Obìnrin tí ìwọ fi fún mi, ni ó fún mi nínú èso igi náà, mo sì jẹ ẹ́.” Nígbà náà ni Olúwa Ọlọ́run wí pé, “Èwo ni èyí tí ìwọ ṣe yìí?” Obìnrin náà dáhùn pé, “Ejò ni ó tàn mí jẹ, mo sì jẹ ẹ́.” Nígbà náà ni Olúwa Ọlọ́run wí fún ejò náà pé, “Nítorí tí ìwọ ti ṣe èyí, “Ègún ni fún ọ ju gbogbo ohun ọ̀sìn àti gbogbo ẹranko igbó tókù lọ! Àyà rẹ ni ìwọ yóò fi máa wọ́, ìwọ yóò sì máa jẹ erùpẹ̀ ilẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ. Èmi yóò sì fi ọ̀tá sí àárín ìwọ àti obìnrin náà, àti sí àárín irú-ọmọ rẹ àti irú-ọmọ obìnrin náà; òun yóò fọ́ orí rẹ, ìwọ yóò sì bù ú jẹ ní gìgísẹ̀.” Ọlọ́run wí fún obìnrin náà pé, “Èmi yóò fi kún ìrora rẹ ní àkókò ìbímọ; ni ìrora ni ìwọ yóò máa bí ọmọ. Ọ̀dọ̀ ọkọ rẹ ni ìfẹ́ rẹ yóò máa fà sí, òun ni yóò sì máa ṣe àkóso rẹ.” Ọlọ́run sì wí fún Adamu pé, “Nítorí pé ìwọ fetí sí aya rẹ, ìwọ sì jẹ nínú èso igi tí mo pàṣẹ fún ọ pé, ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ jẹ nínú rẹ̀,’ “Ègún ni fún ilẹ̀ nítorí rẹ; nínú ọ̀pọ̀ làálàá ni ìwọ yóò jẹ nínú rẹ̀, ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ. Ilẹ̀ yóò sì hu ẹ̀gún àti èṣùṣú fún ọ, ewéko igbó ni ìwọ yóò sì máa jẹ. Nínú òógùn ojú rẹ ni ìwọ yóò máa jẹun títí tí ìwọ yóò fi padà sí ilẹ̀, nítorí inú ilẹ̀ ni a ti mú ọ jáde wá; erùpẹ̀ ilẹ̀ sá à ni ìwọ, ìwọ yóò sì padà di erùpẹ̀.” Adamu sì sọ aya rẹ̀ ní Efa nítorí òun ni yóò di ìyá gbogbo alààyè. Olúwa Ọlọ́run, sì dá ẹ̀wù awọ fún Adamu àti aya rẹ̀, ó sì fi wọ̀ wọ́n. Olúwa Ọlọ́run sì wí pé, “Ọkùnrin náà ti dàbí ọ̀kan lára wa, ó mọ rere àti búburú. A kò gbọdọ̀ jẹ́ kí ó na ọwọ́ rẹ̀ kí ó mú lára èso igi ìyè kí ó sì jẹ, kí ó sì wà láààyè títí láéláé.” Nítorí náà, Olúwa Ọlọ́run lé e kúrò nínú ọgbà Edeni láti lọ máa ro ilẹ̀ nínú èyí tí a ti mú un jáde wá. Lẹ́yìn tí ó ti lé ènìyàn jáde tán, ó fi àwọn kérúbù àti idà iná tí ó ń kọ mọ̀nàmọ́ná síwájú àti sẹ́yìn láti ṣọ́ ọ̀nà tí ó lọ sí ibi igi ìyè, ní ìhà ìlà-oòrùn ọgbà Edeni. Kaini àti Abeli Adamu sì bá aya rẹ̀ Efa lòpọ̀, ó sì lóyún, ó sì bí Kaini. Ó wí pé, “Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Olúwa ni mo bí ọmọ ọkùnrin.” Lẹ́yìn náà, ó sì bí ọmọkùnrin mìíràn tí a pè ní Abeli. Abeli jẹ́ darandaran, Kaini sì jẹ́ àgbẹ̀. Ó sì ṣe lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, Kaini mú ọrẹ wá fún Olúwa nínú èso ilẹ̀ rẹ̀. Ṣùgbọ́n Abeli mú ẹran tí ó sanra wá fún Olúwa nínú àkọ́bí ẹran ọ̀sìn rẹ̀. Olúwa sì fi ojúrere wo Abeli àti ọrẹ rẹ̀, ṣùgbọ́n Olúwa kò fi ojúrere wo Kaini àti ẹbọ rẹ̀. Nítorí náà inú bí Kaini gidigidi, ojú rẹ̀ sì fàro. Nígbà náà ni Olúwa bi Kaini pé, “Èéṣe tí ìwọ ń bínú? Èéṣe tí ojú rẹ sì fàro? Bí ìwọ bá ṣe ohun tí ó tọ́, ṣé ìwọ kò ní jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà? Ṣùgbọ́n bí ìwọ kò bá ṣe ohun tí ó tọ́, ẹ̀ṣẹ̀ ń bẹ ní ẹnu-ọ̀nà rẹ, ó fẹ́ ní ọ ní ìní, ṣùgbọ́n ìwọ gbọdọ̀ ṣe àkóso rẹ̀.” Kaini wí fún Abeli arákùnrin rẹ̀ pé, “Jẹ́ kí a lọ sí oko.” Ó sì ṣe, bí wọ́n ti wà ní oko; Kaini da ojú ìjà kọ Abeli arákùnrin rẹ̀, ó sì pa á. Nígbà náà ni Olúwa béèrè lọ́wọ́ Kaini pé, “Níbo ni Abeli arákùnrin rẹ wà?” Ó sì dáhùn pé, “Èmi kò mọ ibi tí ó wà, èmí ha ń ṣe olùṣọ́ arákùnrin mi bí?” Olúwa wí pé, “Kín ni ohun tí ìwọ ṣe yìí? Gbọ́! Ẹ̀jẹ̀ arákùnrin rẹ ń kígbe pè mí láti ilẹ̀ wá. Láti ìsinsin yìí lọ, ìwọ ti wà lábẹ́ ègún, a sì ti lé ọ lórí ilẹ̀ tí ó ya ẹnu gba ẹ̀jẹ̀ arákùnrin rẹ lọ́wọ́ rẹ. Bí ìwọ bá ro ilẹ̀, ilẹ̀ kì yóò fi agbára rẹ̀ so èso rẹ̀ fún ọ mọ́. Ìwọ yóò sì jẹ́ ìsáǹsá àti alárìnkiri ni orí ilẹ̀ ayé.” Kaini wí fún Olúwa pé, “Ẹrù ìyà ẹ̀ṣẹ̀ mi pọ̀ ju èyí tí mo le rù lọ. Lónìí, ìwọ lé mi kúrò lórí ilẹ̀, mó sì di ẹni tí ó fi ara pamọ́ kúrò ní ojú rẹ, èmi yóò sì di ìsáǹsá àti alárìnkiri ní ayé, ẹnikẹ́ni tí ó bá rí mi, yóò sì pa mí.” Ṣùgbọ́n, Olúwa wí fún pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́, bí ẹnikẹ́ni bá pa Kaini, èmi yóò gbẹ̀san ní ara onítọ̀hún ní ìgbà méje.” Nígbà náà ni Ọlọ́run fi àmì sí ara Kaini, kí ẹnikẹ́ni tí ó bá ri má ba à pa á. Kaini sì kúrò níwájú Olúwa, ó sì ń gbé ilẹ̀ Nodi ní ìhà ìlà-oòrùn Edeni. Kaini sì bá aya rẹ̀ lòpọ̀, ó sì lóyún, ó sì bí Enoku. Kaini sì tẹ ìlú kan dó, ó sì fi orúkọ ọmọ rẹ̀ ọkùnrin Enoku sọ ìlú náà. Enoku sì bí Iradi, Iradi sì ni baba Mehujaeli, Mehujaeli sì bí Metuṣaeli, Metuṣaeli sì ni baba Lameki. Lameki sì fẹ́ aya méjì, orúkọ èkínní ni Adah, àti orúkọ èkejì ni Silla. Adah sì bí Jabali, òun ni baba irú àwọn tí ń gbé inú àgọ́, tí wọ́n sì ń sin ẹran ọ̀sìn. Orúkọ arákùnrin rẹ̀ ni Jubali, òun ni baba irú àwọn tí ń tẹ dùùrù tí wọ́n sì ń fọn fèrè. Silla náà sì bí ọmọkùnrin tí ń jẹ́ Tubali-Kaini, tí ó ń rọ oríṣìíríṣìí ohun èlò láti ara idẹ àti irin. Arábìnrin Tubali-Kaini ni Naama. Lameki wí fún àwọn aya rẹ̀, “Adah àti Silla, ẹ tẹ́tí sí mi; ẹ̀yin aya Lameki, ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ mi. Mo ti pa ọkùnrin kan tí ó kọlù mí, ọ̀dọ́mọkùnrin tí ó pa mí lára. Bí a ó bá gbẹ̀san Kaini ní ìgbà méje, ǹjẹ́ kí a gba ti Lameki nígbà mẹ́tàdínlọ́gọ́rin (77).” Adamu sì tún bá aya rẹ̀ lòpọ̀, ó sì bí ọmọkùnrin kan tí ó pe orúkọ rẹ̀ ní Seti, tí ó túmọ̀ sí pé, “Ọlọ́run fún mi ní ọmọkùnrin mìíràn ní ipò Abeli tí Kaini pa.” Seti náà sì bí ọmọkùnrin kan, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Enoṣi. Láti àkókò náà lọ ni àwọn ènìyàn ti bẹ̀rẹ̀ sí ní ké pe orúkọ Olúwa. Ìran Adamu títí dé ìran Noa Èyí ni àkọsílẹ̀ ìran Adamu. Nígbà tí Ọlọ́run dá ènìyàn, ní àwòrán Ọlọ́run ni ó dá a. Àti akọ àti abo ni Ó dá wọn, ó sì súre fún wọn, ó sì pe orúkọ wọ́n ní Adamu ní ọjọ́ tí ó dá wọn. Nígbà tí Adamu di ẹni àádóje ọdún, ó bí ọmọkùnrin kan tí ó jọ ọ́, tí ó jẹ́ àwòrán ara rẹ̀, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Seti. Ọjọ́ Adamu, lẹ́yìn ìgbà tí ó bí Seti, jẹ́ ẹgbẹ̀rin (800) ọdún, ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin. Àpapọ̀ ọdún tí Adamu gbé ní orí ilẹ̀ jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún ọdún ó lé ọgbọ̀n (930), ó sì kú. Nígbà tí Seti pé àrùnlélọ́gọ́rùn-ún ọdún, ó bí Enoṣi. Lẹ́yìn ìgbà tí ó bí Enoṣi, Seti sì gbé fún ẹgbẹ̀rin ọdún ó lé méje (807), ó sì bí àwọn; ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin. Àpapọ̀ ọdún Seti sì jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún ọdún ó lé méjìlá (912), ó sì kú. Nígbà tí Enoṣi di ẹni àádọ́rùn-ún ọdún ni ó bí Kenani. Lẹ́yìn tí ó bí Kenani, Enoṣi sì wà láààyè fún ẹgbẹ̀rin ọdún ó lé mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (815), ó sì bí àwọn ọkùnrin àti obìnrin. Àpapọ̀ ọdún Enoṣi jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún ọdún ó lé márùn-ún (905), ó sì kú. Nígbà tí Kenani di àádọ́rin ọdún ni ó bí Mahalaleli. Lẹ́yìn tí ó bí Mahalaleli, Kenani wà láààyè fún òjìlélẹ́gbẹ̀rin ọdún (840), ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin. Àpapọ̀ ọjọ́ Kenani jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún ọdún ó lé mẹ́wàá (910), ó sì kú. Nígbà tí Mahalaleli pé ọmọ àrùnlélọ́gọ́ta ọdún ni ó bí Jaredi. Mahalaleli sì gbé fún ẹgbẹ̀rin ọdún ó lé ọgbọ̀n (830) lẹ́yìn ìgbà tí ó bí Jaredi, ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin. Àpapọ̀ iye ọdún Mahalaleli jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún ọdún ó dín márùn-ún (895), ó sì kú. Nígbà tí Jaredi pé ọmọ ọgọ́jọ ọdún ó lé méjì ni ó bí Enoku. Lẹ́yìn èyí, Jaredi wà láààyè fún ẹgbẹ̀rin (800) ọdún Enoku sì bí àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin. Àpapọ̀ ọdún Jaredi sì jẹ́ ẹgbẹ̀rún dín méjìdínlógójì (962), ó sì kú. Nígbà tí Enoku pé ọmọ ọgọ́ta ọdún ó lé márùn ni ó bí Metusela. Lẹ́yìn tí ó bí Metusela, Enoku sì bá Ọlọ́run rìn ní ọ̀ọ́dúnrún (300) ọdún, ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin. Àpapọ̀ ọjọ́ Enoku sì jẹ́ irinwó ọdún dín márùndínlógójì (365). Enoku bá Ọlọ́run rìn; a kò sì rí i mọ́ nítorí Ọlọ́run mú un lọ. Nígbà tí Metusela pé igba ọdún dín mẹ́tàlá ní o bí Lameki. Lẹ́yìn èyí Metusela wà láààyè fún ẹgbẹ̀rin ọdún dín méjìdínlógún (782), lẹ́yìn ìgbà tí ó bí Lameki, ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin. Àpapọ̀ ọdún Metusela jẹ́ ẹgbẹ̀rún ọdún dín mọ́kànlélọ́gbọ̀n (969), ó sì kú. Nígbà tí Lameki pé ọdún méjìlélọ́gọ́sàn án ni ó bí ọmọkùnrin kan. Ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Noa, ó sì wí pé, “Eléyìí ni yóò tù wá nínú ni iṣẹ́ àti làálàá ọwọ́ wa, nítorí ilẹ̀ tí Olúwa ti fi gégùn ún.” Lẹ́yìn tí ó bí Noa, Lameki gbé fún ẹgbẹ̀ta ọdún dín márùn-ún (595), ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin. Àpapọ̀ ọdún Lameki sì jẹ́ ẹgbẹ̀rin ọdún dín mẹ́tàlélógún (777), ó sì kú. Lẹ́yìn tí Noa pé ọmọ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (500) ọdún ni ó bí Ṣemu, Hamu àti Jafeti. Ìkún omi Nígbà tí ènìyàn bẹ̀rẹ̀ sí ní pọ̀ si ní orí ilẹ̀, wọ́n sí bí àwọn ọmọbìnrin. Àwọn ọmọ Ọlọ́run rí i wí pé àwọn ọmọbìnrin ènìyàn lẹ́wà, wọ́n sì fẹ́ èyíkéyìí tí ó wù wọ́n ṣe aya. Nígbà náà ni Olúwa wí pé, “Èémí ìyè tí mo mí sínú ènìyàn kò ní máa gbé inú ènìyàn títí láé, nítorí ẹran-ara sá à ni òun, ọgọ́fà ọdún ni ọjọ́ rẹ̀ yóò jẹ́.” Àwọn òmíràn wà láyé ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì, àti lẹ́yìn ìgbà náà; nígbà tí àwọn ọmọ Ọlọ́run lọ bá àwọn ọmọbìnrin ènìyàn lòpọ̀ tí wọ́n sì bímọ fún wọn. Àwọn náà ni ó di akọni àti olókìkí ìgbà náà. Olúwa sì rí bí ìwà búburú ènìyàn ti ń gbilẹ̀ si, àti pé gbogbo èrò inú rẹ̀ kìkì ibi ni, ní ìgbà gbogbo. Inú Olúwa sì bàjẹ́ gidigidi nítorí pé ó dá ènìyàn sí ayé, ọkàn rẹ̀ sì gbọgbẹ́. Nítorí náà, Olúwa wí pé, “Èmi yóò pa ènìyàn tí mo ti dá run kúrò lórí ilẹ̀, ènìyàn àti ẹranko, àti ohun tí ń rákò, àti ẹyẹ ojú ọ̀run, nítorí inú mi bàjẹ́ pé mo ti dá wọn.” Ṣùgbọ́n, Noa rí ojúrere Olúwa. Noa àti ìkún omi Wọ̀nyí ni ìtàn Noa. Noa nìkan ni ó jẹ́ olóòótọ́ ènìyàn àti ẹni tí ó pé ní ìgbà ayé rẹ̀, ó sì fi òtítọ́ bá Ọlọ́run rìn. Noa sì bí ọmọkùnrin mẹ́ta, Ṣemu, Hamu àti Jafeti. Ayé sì kún fún ìbàjẹ́ gidigidi ní ojú Ọlọ́run, ó sì kún fún ìwà ipá pẹ̀lú. Ọlọ́run sì rí bí ayé ti bàjẹ́ tó, nítorí àwọn ènìyàn inú ayé ti bá ara wọn jẹ́ ní gbogbo ọ̀nà wọn. Ọlọ́run sì wí fún Noa pé, “Èmi yóò pa gbogbo ènìyàn run, nítorí ilẹ̀ ayé kún fún ìwà ipá nípasẹ̀ wọn. Èmi yóò pa wọ́n run àti ayé pẹ̀lú. Nítorí náà fi igi ọ̀mọ̀ kan ọkọ̀, kí o sì yọ yàrá sí inú rẹ̀, kí o sì fi ọ̀dà ilẹ̀ rẹ́ ẹ tinú-tẹ̀yìn. Báyìí ni ìwọ yóò ṣe kan ọkọ̀ náà: Gígùn rẹ̀ ní òró yóò jẹ́ ọ̀ọ́dúnrún (300) ìgbọ̀nwọ́, ìbú rẹ̀ yóò jẹ́ àádọ́ta ìgbọ̀nwọ́, nígbà tí gíga rẹ̀ yóò jẹ́ ọgbọ̀n ìgbọ̀nwọ́. Ṣe òrùlé sí orí ọkọ̀ náà ní ìgbọ̀nwọ́ kan, sì ṣe ọkọ̀ náà ní alájà mẹ́ta, ipá kan ní ìsàlẹ̀, ọ̀kan ní àárín àti ọ̀kan tí ó kù ní òkè, ẹ̀gbẹ́ ni kí ó ṣe ẹnu-ọ̀nà ọkọ̀ náà sí. Èmi yóò mú ìkún omi wá sí ayé láti pa gbogbo ohun ẹlẹ́mìí run lábẹ́ ọ̀run. Gbogbo ẹ̀dá tí ó ní èémí ìyè ní inú. Gbogbo ohun tí ó wà nínú ayé yóò parun. Ṣùgbọ́n èmi ó dá májẹ̀mú mi pẹ̀lú rẹ, ìwọ yóò sì wọ ọkọ̀, ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ pẹ̀lú aya rẹ. Ìwọ yóò mú gbogbo ohun alààyè takọ tabo wá sí inú ọkọ̀, kí wọn le wà láààyè pẹ̀lú rẹ. Mú onírúurú àwọn ẹyẹ, ẹranko àti àwọn ohun tí ń rákò ní méjì méjì, kí a bá lè pa wọ́n mọ́ láààyè. Mú onírúurú oúnjẹ wá sínú ọkọ̀, kí o pa wọ́n mọ́ fún jíjẹ gbogbo ẹ̀yin tí ẹ wà nínú ọkọ̀ àti ènìyàn àti ẹranko.” Noa sì ṣe ohun gbogbo bí Ọlọ́run ti pàṣẹ fún un. Nígbà náà ni Olúwa wí fún Noa pé, “Wọ inú ọkọ̀ lọ ìwọ àti gbogbo ìdílé rẹ, nítorí ìwọ nìkan ni mo rí bí olódodo nínú ìran yìí. Mú méje méje nínú àwọn ẹran tí ó mọ́, akọ àti abo, mú méjì méjì takọ tabo nínú àwọn ẹran aláìmọ́. Sì mú méje méje pẹ̀lú nínú onírúurú ẹyẹ, takọ tabo ni kí o mú wọn, wọlé sínú ọkọ̀ pẹ̀lú rẹ, kí á ba à lè pa wọ́n mọ́ láààyè ní gbogbo ayé. Nítorí ní ọjọ́ méje sí ìhín, èmi yóò rọ òjò sórí ilẹ̀ fún ogójì ọ̀sán àti ogójì òru, èmi yóò sì pa gbogbo ohun alààyè tí mo ti dá run kúrò lórí ilẹ̀.” Noa sì ṣe ohun gbogbo tí Olúwa pàṣẹ fún un. Noa jẹ́ ọmọ ẹgbẹ̀ta (600) ọdún nígbà tí ìkún omi dé sórí ilẹ̀. Noa àti ìyàwó rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀ àti àwọn aya ọmọ rẹ̀ sì wọ inú ọkọ láti sá àsálà fún ìkún omi. Méjì méjì ni àwọn ẹran tí ó mọ́ àti aláìmọ́, ti ẹyẹ àti ti gbogbo àwọn ẹ̀dá afàyàfà, akọ àti abo ni wọ́n wọlé pẹ̀lú Noa sínú ọkọ̀ bí Ọlọ́run ti pàṣẹ fún Noa. Lẹ́yìn ọjọ́ keje, ìkún omi sì dé sí ayé. Ní ọjọ́ kẹtàdínlógún oṣù kejì, tí Noa pé ọmọ ẹgbẹ̀ta (600) ọdún, ni gbogbo ìsun ibú ya, fèrèsé ìṣàn omi ọ̀run sì ṣí sílẹ̀. Òjò àrọ̀ìrọ̀dá sì rọ̀ fún ogójì ọ̀sán àti ogójì òru. Ní ọjọ́ tí ìkún omi yóò bẹ̀rẹ̀ gan an ni Noa àti Ṣemu, Hamu àti Jafeti pẹ̀lú aya Noa àti aya àwọn ọmọ rẹ̀ wọ inú ọkọ̀. Wọ́n mú ẹranko igbó àti ohun ọ̀sìn ní onírúurú wọn, àwọn ẹ̀dá afàyàfà àti ẹyẹ àti àwọn ohun abìyẹ́ ni onírúurú wọn. Méjì méjì ni gbogbo ẹ̀dá tí ó ní èémí ìyè nínú wọlé pẹ̀lú Noa sínú ọkọ̀. Gbogbo wọ́n wọlé ní takọ tabo bí Ọlọ́run ti pàṣẹ fún Noa, Olúwa sì tì wọn mọ́ inú ọkọ̀. Òjò náà sì rọ̀ ní àrọ̀ìrọ̀dá fún ogójì ọ̀sán àti ogójì òru, ọkọ̀ náà sì ń léfòó lórí omi, kúrò lórí ilẹ̀ bí omi náà ti ń pọ̀ sí i. Bí omi náà ti ń pọ̀ sí i, bẹ́ẹ̀ náà ni ọkọ̀ náà sì ń léfòó lójú omi. Omi náà pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ tí ó bo gbogbo àwọn òkè gíga tí ó wà lábẹ́ ọ̀run. Omi náà kún bo àwọn òkè, bí ìwọ̀n ìgbọ̀nwọ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún. Gbogbo ohun alààyè tí ó wà lórí ilẹ̀ parun: ẹyẹ, ohun ọ̀sìn, ẹranko igbó, àwọn ẹ̀dá afàyàfà àti ènìyàn. Gbogbo ohun tí ó wà lórí ìyàngbẹ ilẹ̀ tó ní èémí ìyè ní ihò imú wọn ni ó kú. Gbogbo ohun alààyè tí ó wà lórí ilẹ̀ ayé ni a parẹ́: ènìyàn àti ẹranko, àwọn ohun tí ń rìn nílẹ̀, àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run pátápátá ló ṣègbé. Noa àti àwọn tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ nínú ọkọ̀ ni ó ṣẹ́kù. Omi náà sì bo ilẹ̀ fún àádọ́jọ ọjọ́. Ìkún omi gbẹ Ọlọ́run sì rántí Noa àti ohun alààyè gbogbo tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀, bí àwọn ẹranko igbó àti ohun ọ̀sìn, ó sì mú kí afẹ́fẹ́ fẹ́ sórí ilẹ̀, omi náà sì fà. Gbogbo ìsun ibú àti fèrèsé ìṣàn ọ̀run tì, òjò pẹ̀lú sì dáwọ́ rírọ̀ dúró. Omi sì bẹ̀rẹ̀ sí ní gbẹ kúrò lórí ilẹ̀, lẹ́yìn àádọ́jọ ọjọ́, ó sì ti ń fà. Ní ọjọ́ kẹtàdínlógún oṣù kejì ni ọkọ̀ náà gúnlẹ̀ sórí òkè Ararati. Omi náà sì ń gbẹ si títí di oṣù kẹwàá. Ní ọjọ́ kìn-ín-ní oṣù kẹwàá, orí àwọn òkè sì farahàn. Lẹ́yìn ogójì ọjọ́, Noa sí fèrèsé tí ó ṣe sára ọkọ̀. Ó sì rán ẹyẹ ìwò kan jáde, tí ó ń fò káàkiri síwá àti sẹ́yìn títí omi fi gbẹ kúrò ní orí ilẹ̀. Ó sì rán àdàbà kan jáde láti wò ó bóyá omi ti gbẹ kúrò lórí ilẹ̀. Ṣùgbọ́n àdàbà náà kò rí ìyàngbẹ ilẹ̀ bà lé nítorí omi kò tí ì tan lórí ilẹ̀, ó sì padà sọ́dọ̀ Noa. Noa na ọwọ́ rẹ̀ jáde ó sì mú ẹyẹ náà wọlé sọ́dọ̀ ara rẹ̀ nínú ọkọ̀. Ó sì dúró fún ọjọ́ méje sí i; ó sì tún rán àdàbà náà jáde láti inú ọkọ̀. Nígbà tí àdàbà náà padà sọ́dọ̀ rẹ̀ ní àṣálẹ́, ó já ewé igi olifi tútù há ẹnu! Nígbà náà ni Noa mọ̀ pé omi ti ń gbẹ kúrò lórí ilẹ̀. Noa tún mú sùúrù fún ọjọ́ méje, ó sì tún rán àdàbà náà jáde, ṣùgbọ́n àdàbà náà kò padà sọ́dọ̀ rẹ̀ mọ́. Ní ọjọ́ kìn-ín-ní oṣù kìn-ín-ní, ní ọdún kọ́kànlélẹ́gbẹ̀ta (601) ni omi náà gbẹ kúrò lórí ilẹ̀; Noa sì ṣí ọkọ̀, ó sì ri pé ilẹ̀ ti gbẹ. Ní ọjọ́ kẹtàdínlọ́gbọ̀n oṣù kejì, ilẹ̀ ti gbẹ pátápátá. Nígbà náà ni Ọlọ́run wí fún Noa pé. “Jáde kúrò nínú ọkọ̀, ìwọ àti aya rẹ, pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ àti àwọn aya wọn. Kó gbogbo àwọn ẹ̀dá alààyè tí ó wà pẹ̀lú rẹ jáde: àwọn ẹyẹ, ẹranko àti gbogbo àwọn ẹ̀dá tí ń rìn nílẹ̀, kí wọn lè bí sí i, kí wọn sì pọ̀ sí i, kí wọn sì máa gbá yìn lórí ilẹ̀.” Noa, àwọn ọmọ rẹ̀, aya rẹ̀ àti àwọn aya ọmọ rẹ̀ sì jáde. Gbogbo àwọn ẹranko àti àwọn ẹ̀dá tí ń rìn nílẹ̀ àti gbogbo ẹyẹ pátápátá ni ó jáde kúrò nínú ọkọ̀, ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́ ní irú tiwọn. Noa sì mọ pẹpẹ fún Olúwa, ó sì mú lára àwọn ẹran tí ó mọ́ àti ẹyẹ tí ó mọ́, ó sì fi rú ẹbọ sísun lórí pẹpẹ. Olúwa sì gbọ́ òórùn dídùn; ó sì wí ní ọkàn rẹ̀ pé, “Èmi kì yóò tún fi ilẹ̀ ré nítorí ènìyàn mọ, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé gbogbo èrò inú rẹ̀ jẹ́ ibi láti ìgbà èwe rẹ̀ wá, èmi kì yóò pa gbogbo ohun alààyè run mọ́ láé, bí mo ti ṣe. “Níwọ́n ìgbà tí ayé bá sì wà, ìgbà ọ̀gbìn àti ìgbà ìkórè ìgbà òtútù àti ìgbà ooru, ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn àti ìgbà òjò, ìgbà ọ̀sán àti ìgbà òru, yóò wà títí láé.” Májẹ̀mú Ọlọ́run pẹ̀lú Noa Ọlọ́run sì súre fún Noa àti àwọn ọmọ rẹ̀ wí pé, “Ẹ máa bí sí i, kí ẹ sì pọ̀ ní iye, kí ẹ sì kún ayé. Ẹ̀rù yín yóò mú ojo wà lára gbogbo ẹranko àti gbogbo ẹyẹ ojú ọ̀run, àti gbogbo àwọn ẹ̀dá tí ń rìn nílẹ̀; àti gbogbo ẹja òkun; a fi wọ́n lé e yín lọ́wọ́. Gbogbo ohun tó wà láààyè tí ó sì ń rìn, ni yóò jẹ́ oúnjẹ fún un yín, bí mo ṣe fi ewéko fún un yín náà ni mo fi ohun gbogbo fún un yín. “Ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò gbọdọ̀ jẹ ẹran tòun-tẹ̀jẹ̀ rẹ̀. Nítòótọ́ ẹ̀jẹ̀ yín, àní ẹ̀mí yín, ni èmi yóò sì béèrè; lọ́wọ́ gbogbo ẹranko ni èmí yóò béèrè rẹ̀, àti lọ́wọ́ ènìyàn, lọ́wọ́ arákùnrin olúkúlùkù ènìyàn ni èmi yóò béèrè ẹ̀mí ènìyàn. “Ẹnikẹ́ni tí ó bá ta ẹ̀jẹ̀ ènìyàn sílẹ̀, láti ọwọ́ ènìyàn ni a ó gbà ta ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sílẹ̀. Nítorí ní àwòrán Ọlọ́run ni Ọlọ́run dá ènìyàn. Ṣùgbọ́n ní tiyín, ẹ máa bí sí i, kí ẹ sì máa pọ̀ sí i, ẹ máa gbá yìn lórí ilẹ̀, kí ẹ sì pọ̀ sí i lórí rẹ̀.” Ọlọ́run sì wí fún Noa àti àwọn ọmọ rẹ̀ pé, “Mo dá májẹ̀mú mi pẹ̀lú yín àti pẹ̀lú àwọn ìran yín tí ń bọ̀ lẹ́yìn. Àti pẹ̀lú gbogbo ẹ̀dá alààyè tí ó wà pẹ̀lú yín, ìbá à ṣe ẹyẹ, ẹja, ẹran ọ̀sìn, ẹranko igbó, gbogbo ohun tí ó jáde kúrò nínú ọkọ̀ pẹ̀lú yín, àní gbogbo ẹ̀dá alààyè ní ayé. Mo dá májẹ̀mú mi pẹ̀lú yín láéláé, Èmi kì yóò fi ìkún omi pa ayé run kúrò mọ láéláé, a kì yóò fi omi pa ayé run.” Ọlọ́run sì wí pé, “Èyí ni àmì májẹ̀mú tí mo ń dá yìí láàrín èmi àti ẹ̀yin àti ẹ̀dá alààyè tí ó wà pẹ̀lú yín, májẹ̀mú àtìrandíran tó ń bọ̀: Mo ti fi òṣùmàrè sí àwọsánmọ̀, yóò sì jẹ́ àmì májẹ̀mú láàrín èmi àti ayé. Nígbàkígbà tí mo bá mú kí òjò ṣú, tí òṣùmàrè bá farahàn ní àwọsánmọ̀. Èmi yóò rántí májẹ̀mú mi, tí ó wà láàrín èmi àti ẹ̀yin àti gbogbo ẹ̀dá alààyè, kì yóò sì tún sí ìkún omi mọ́ láti pa gbogbo ẹ̀dá run. Nígbàkígbà tí òṣùmàrè bá yọ ní àwọsánmọ̀, èmi yóò rí i, èmi yóò sì rántí májẹ̀mú ayérayé tí ń bẹ láàrín Ọlọ́run àti gbogbo ẹ̀dá alààyè tí ń bẹ ní ayé.” Ọlọ́run sì wí fún Noa pé, “Èyí ni àmì májẹ̀mú tí mo ti fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ láàrín èmi àti gbogbo alààyè ní ayé.” Àwọn ọmọ Noa Àwọn ọmọ Noa tí ó jáde nínú ọkọ̀ ni Ṣemu, Hamu àti Jafeti. (Hamu ni baba Kenaani.) Láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Noa mẹ́tẹ̀ẹ̀ta yìí ni gbogbo ènìyàn ti tàn ká gbogbo ilẹ̀ ayé. Noa bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ àgbẹ̀, ó sì gbin ọgbà àjàrà. Ó mu àmupara nínú ọtí wáìnì àjàrà rẹ̀, ó sì tú ara rẹ̀ sí ìhòhò, ó sì sùn nínú àgọ́ rẹ̀. Hamu tí í ṣe baba Kenaani sì rí baba rẹ̀ ní ìhòhò bẹ́ẹ̀ ni ó sì lọ sọ fún àwọn arákùnrin rẹ̀ méjèèjì ní ìta. Ṣùgbọ́n Ṣemu àti Jafeti mú aṣọ lé èjìká wọn, wọ́n sì fi ẹ̀yìn rìn, wọ́n sì bo ìhòhò baba wọn. Wọ́n kọjú sẹ́yìn kí wọn kí ó má ba à rí ìhòhò baba wọn. Nígbà tí Noa kúrò ní ojú ọtí, tí ó sì mọ ohun tí ọmọ rẹ̀ kékeré ṣe sí i. Ó wí pé, “Ègún ni fún Kenaani. Ìránṣẹ́ àwọn ìránṣẹ́ ni yóò máa ṣe fún àwọn arákùnrin rẹ̀.” Ó sì tún wí pé, “Olùbùkún ni Olúwa, Ọlọ́run Ṣemu Kenaani yóò máa ṣe ẹrú fún Ṣemu. Ọlọ́run yóò mú Jafeti gbilẹ̀, Jafeti yóò máa gbé ní àgọ́ Ṣemu Kenaani yóò sì jẹ́ ẹrú fún un.” Noa wà láààyè fún irinwó ọdún dín àádọ́ta (350) lẹ́yìn ìkún omi. Àpapọ̀ ọjọ́ ayé Noa jẹ́ ẹgbẹ̀rún ọdún dín làádọ́ta (950), ó sì kú. Ìran àwọn ọmọ Noa Èyí ni ìran àwọn ọmọ Noa: Ṣemu, Hamu àti Jafeti, tí àwọn náà sì bí ọmọ lẹ́yìn ìkún omi. Ìran Jafeti Àwọn ọmọ Jafeti ni: Gomeri, Magogu, Madai, Jafani, Tubali, Meṣeki àti Tirasi. Àwọn ọmọ Gomeri ni: Aṣkenasi, Rifati àti Togarma. Àwọn ọmọ Jafani ni: Eliṣa, Tarṣiṣi, Kittimu, àti Dodanimu. (Láti ọ̀dọ̀ àwọn wọ̀nyí ni àwọn tí ń gbé agbègbè tí omi wà ti tàn ká agbègbè wọn, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yà wọn, ìdílé wọn ní orílẹ̀-èdè wọn, olúkúlùkù pẹ̀lú èdè tirẹ̀). Ìran Hamu Àwọn ọmọ Hamu ni: Kuṣi, Ejibiti, Puti àti Kenaani. Àwọn ọmọ Kuṣi ni: Seba, Hafila, Sabta, Raama, àti Sabteka. Àwọn ọmọ Raama ni: Ṣeba àti Dedani. Kuṣi sì bí Nimrodu, ẹni tí ó di alágbára jagunjagun ní ayé. Ó sì jẹ́ ògbójú ọdẹ níwájú Olúwa; nítorí náà ni a ṣe ń wí pé, “Bí Nimrodu, ògbójú ọdẹ níwájú Olúwa.” Ìjọba rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ ni Babeli, Ereki, Akkadi, Kalne, gbogbo wọn wà ní ilẹ̀ Ṣinari. Láti ilẹ̀ náà ni ó ti lọ sí Asiria, níbi tí ó ti tẹ ìlú Ninefe, Rehoboti àti Kala, àti Resini, tí ó wà ní àárín Ninefe àti Kala, tí ó jẹ́ ìlú olókìkí. Ejibiti sì bí Ludimu, Anamimu, Lehabimu, Naftuhimu. Patrusimu, Kasluhimu (láti ọ̀dọ̀ ẹni tí àwọn ará Filistini ti wá) àti àwọn ará Kaftorimu. Kenaani sì bí Sidoni àkọ́bí rẹ̀, àti Heti. Àti àwọn ará Jebusi, àti àwọn ará Amori, àti àwọn ará Girgaṣi, àti àwọn ará Hifi, àti àwọn ará Arki, àti àwọn ará Sini, àti àwọn ará Arfadi, àti àwọn ará Semari, àti àwọn ará Hamati. Lẹ́yìn èyí ni àwọn ẹ̀yà Kenaani tànkálẹ̀. Ààlà ilẹ̀ àwọn ará Kenaani sì dé Sidoni, lọ sí Gerari títí dé Gasa, lọ sí Sodomu, Gomorra, Adma àti Seboimu, títí dé Laṣa. Àwọn wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Hamu, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yà wọn, àti èdè wọn, ní ìpínlẹ̀ wọn àti ní orílẹ̀-èdè wọn. Ìran Ṣemu A bí àwọn ọmọ fún Ṣemu tí Jafeti jẹ́ ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ọkùnrin: Ṣemu sì ni baba gbogbo àwọn ọmọ Eberi. Àwọn ọmọ Ṣemu ni: Elamu, Aṣuri, Arfakṣadi, Ludi àti Aramu. Àwọn ọmọ Aramu ni: Usi, Huli, Geteri àti Meṣeki. Arfakṣadi sì bí Ṣela, Ṣela sì bí Eberi. Eberi sì bí ọmọ méjì: ọ̀kan ń jẹ́ Pelegi, nítorí ní ìgbà ọjọ́ rẹ̀ ni ilẹ̀ ya; orúkọ arákùnrin rẹ̀ ni Joktani. Joktani sì bí Almodadi, Ṣelefi, Hasarmafeti, Jera. Hadoramu, Usali, Dikla, Obali, Abimaeli, Ṣeba. Ofiri, Hafila àti Jobabu. Gbogbo àwọn wọ̀nyí ni ọmọ Joktani. Agbègbè ibi tí wọn ń gbé bẹ̀rẹ̀ láti Meṣa títí dé Sefari, ní àwọn ilẹ̀ tó kún fún òkè ní ìlà-oòrùn. Àwọn wọ̀nyí ni àwọn ẹ̀yà ọmọ Ṣemu gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn, ní èdè wọn, ní ilẹ̀ wọn àti ní orílẹ̀-èdè wọn. Àwọn wọ̀nyí ni àwọn ẹ̀yà ọmọ Noa gẹ́gẹ́ bí ìran wọn, ní orílẹ̀-èdè wọn. Ní ipasẹ̀ wọn ni àwọn ènìyàn ti tàn ká ilẹ̀ ayé lẹ́yìn ìkún omi. Ilé ìṣọ́ Babeli Lẹ́yìn náà, gbogbo àgbáyé sì ń sọ èdè kan ṣoṣo. Bí àwọn ènìyàn ṣe ń tẹ̀síwájú lọ sí ìhà ìlà-oòrùn, wọ́n rí pẹ̀tẹ́lẹ̀ kan ní ilẹ̀ Ṣinari,11.2 tí ó túmọ̀ sí, Babeli wọ́n sì tẹ̀dó síbẹ̀. Wọ́n sì wí fún ara wọn pé, “Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a mọ bíríkì kí a sì sún wọ́n jìnà.” Bíríkì ni wọ́n ń lò ní ipò òkúta, àti ọ̀dà ilẹ̀ tí wọn ń lò láti mú wọn papọ̀ dípò ẹfun (òkúta láìmù tí wọ́n fi ń ṣe símẹ́ńtì àti omi). Nígbà náà ni wọ́n wí pé, “Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a tẹ ìlú kan dó fún ara wa, kí a sì kọ́ ilé ìṣọ́ kan tí yóò kan ọ̀run, kí a ba à lè ní orúkọ,11.4 tí ó túmọ̀ sí, òkìkí kí a má sì tú káàkiri sórí gbogbo ilẹ̀ ayé.” Ṣùgbọ́n, Olúwa sọ̀kalẹ̀ láti wo ìlú àti ilé ìṣọ́ tí àwọn ènìyàn náà ń kọ́. Olúwa wí pé, “Bí àwọn ènìyàn bá ń jẹ́ ọ̀kan àti èdè kan tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe iṣẹ́ yìí, kò sí ohun tí wọ́n gbèrò tí wọn kò ní le ṣe yọrí. Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a sọ̀kalẹ̀ lọ, kí a da èdè wọn rú kí èdè wọn má ba à yé ara wọn mọ́.” Olúwa sì tú wọn ká sórí ilẹ̀ gbogbo, wọ́n sì ṣíwọ́ ìlú náà tí wọn ń tẹ̀dó. Ìdí èyí ni a fi pè é ní Babeli11.9 Èyí ní Babiloni; Babeli ni èdé Heberu tí a mọ̀ sí ìdàrúdàpọ̀. nítorí ní ibẹ̀ ni Olúwa ti da èdè gbogbo ayé rú. Olúwa tí sì tú àwọn ènìyàn ká sí gbogbo orí ilẹ̀ ayé. Ìran Ṣemu tó fi dé ti Abramu Wọ̀nyí ni ìran Ṣemu. Ọdún méjì lẹ́yìn ìkún omi, tí Ṣemu pé ọgọ́rùn-ún ọdún ni ó bí Arfakṣadi. Lẹ́yìn tí ó bí Arfakṣadi, Ṣemu tún wà láààyè fún ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ọdún (500), ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin mìíràn. Nígbà tí Arfakṣadi pé ọdún márùndínlógójì ni ó bí Ṣela. Arfakṣadi sì wà láààyè fún ọdún mẹ́tàlénírinwó (403) lẹ́yìn tí ó bí Ṣela, ó sì bí àwọn ọmọbìnrin àti àwọn ọmọkùnrin mìíràn. Nígbà tí Ṣela pé ọmọ ọgbọ̀n ọdún ni ó bí Eberi. Ṣela sì wà láààyè fún ọdún mẹ́tàlénírinwó (403) lẹ́yìn tí ó bí Eberi tán, ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin mìíràn. Eberi sì jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n, ó sì bí Pelegi. Eberi sì wà láààyè fún irinwó ọdún ó lé ọgbọ̀n (430) lẹ́yìn tí ó bí Pelegi, ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin mìíràn. Nígbà tí Pelegi pé ọmọ ọgbọ̀n ọdún ni ó bí Reu. Pelegi sì tún wà láààyè fún igba ọdún ó lé mẹ́sàn-án (209) lẹ́yìn tí ó bí Reu, ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin mìíràn. Nígbà tí Reu pé ọdún méjìlélọ́gbọ̀n ni ó bí Serugu. Reu tún wà láààyè lẹ́yìn tí ó bí Serugu fún igba ọdún ó lé méje (207), ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin mìíràn. Nígbà tí Serugu pé ọmọ ọgbọ̀n ọdún ni ó bí Nahori. Serugu sì wà láààyè fún igba ọdún lẹ́yìn tí ó bí Nahori, ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin mìíràn. Nígbà tí Nahori pé ọmọ ọdún mọ́kàndínlọ́gbọ̀n, ó bí Tẹra. Nahori sì wà láààyè fún ọdún mọ́kàn dín lọ́gọ́fà lẹ́yìn ìbí Tẹra, ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin mìíràn. Lẹ́yìn tí Tẹra pé ọmọ àádọ́rin ọdún ó bí Abramu, Nahori àti Harani. Ìgbé ayé Abrahamu Wọ̀nyí ni ìran Tẹra. Tẹra ni baba Abramu, Nahori àti Harani. Harani sì bí Lọti. Harani sì kú ṣáájú Tẹra baba rẹ̀ ní ilẹ̀ ìbí rẹ̀ ní Uri ti ilẹ̀ Kaldea. Abramu àti Nahori sì gbéyàwó. Orúkọ aya Abramu ni Sarai, nígbà tí aya Nahori ń jẹ́ Milka, tí ṣe ọmọ Harani. Harani ni ó bí Milka àti Iska. Sarai sì yàgàn, kò sì bímọ. Tẹra sì mú ọmọ rẹ̀ Abramu àti Lọti ọmọ Harani, ọmọ ọmọ rẹ̀, ó sì mú Sarai tí i ṣe aya ọmọ rẹ̀. Abramu pẹ̀lú gbogbo wọn sì jáde kúrò ní Uri ti Kaldea láti lọ sí ilẹ̀ Kenaani. Ṣùgbọ́n nígbà tí wọn dé Harani wọ́n tẹ̀dó síbẹ̀. Nígbà tí Tẹra pé ọmọ igba ọdún ó lé márùn-ún (205) ni ó kú ní Harani. Ìpè Abramu Olúwa sì wí fún Abramu, “Jáde kúrò ní orílẹ̀-èdè rẹ àti kúrò lọ́dọ̀ àwọn ènìyàn rẹ, lọ sí ilẹ̀ kan tí èmi yóò fihàn ọ́. “Èmi yóò sọ ọ́ di orílẹ̀-èdè ńlá, èmi yóò sì bùkún fún ọ; èmi yóò sọ orúkọ rẹ di ńlá, ìbùkún ni ìwọ yóò sì jásí. Èmi yóò bùkún fún àwọn tí ó súre fún ọ, ẹni tí ó fi ọ́ ré ni Èmi yóò fi ré; nínú rẹ ni a ó bùkún gbogbo ìdílé ayé.” Bẹ́ẹ̀ ni Abramu lọ bí Olúwa ti sọ fún un. Lọti náà sì bá a lọ. Abramu jẹ́ ẹni àrùndínlọ́gọ́rin ọdún nígbà tí ó jáde kúrò ní Harani. Abramu sì mú Sarai aya rẹ̀, àti Lọti ọmọ arákùnrin rẹ̀: gbogbo ohun ìní tí wọ́n ti kójọ àti àwọn ènìyàn tí wọ́n ní ní Harani. Wọ́n sì jáde lọ sí ilẹ̀ Kenaani. Wọ́n sì gúnlẹ̀ síbẹ̀. Abramu sì rìn la ilẹ̀ náà já títí dé ibi igi ńlá kan tí à ń pè ni More ní Ṣekemu. Àwọn ará Kenaani sì wà ní ilẹ̀ náà. Olúwa sì farahan Abramu, ó sì wí fún un pé, “Irú-ọmọ rẹ ni Èmi yóò fi ilẹ̀ yìí fún.” Abramu tẹ́ pẹpẹ kan síbẹ̀ fún Olúwa tí ó fi ara hàn án. Ó sì kúrò níbẹ̀ lọ sí agbègbè àwọn òkè kan ní ìhà ìlà-oòrùn Beteli, ó sì pàgọ́ rẹ̀ síbẹ̀. Beteli wà ní ìwọ̀-oòrùn, Ai wà ní ìlà-oòrùn. Ó tẹ́ pẹpẹ kan níbẹ̀ fún Olúwa, ó sì ké pe orúkọ Olúwa. Nígbà náà ni Abramu tẹ̀síwájú sí ìhà gúúsù. Abramu ní Ejibiti Ìyàn kan sì mú ní ilẹ̀ náà, Abramu sì sọ̀kalẹ̀ lọ sí Ejibiti láti ṣe àtìpó níbẹ̀ fún ìgbà díẹ̀, nítorí ìyàn náà mú gidigidi. Bí ó ti ku díẹ̀ kí ó wọ Ejibiti, ó wí fún Sarai, aya rẹ̀ pé, “Mo mọ̀ pé arẹwà obìnrin ni ìwọ, nígbà tí àwọn ará Ejibiti bá rí ọ, wọn yóò wí pé, ‘Aya rẹ̀ nìyí.’ Wọn yóò si pa mí, ṣùgbọ́n wọn yóò dá ọ sí. Nítorí náà, sọ pé, arábìnrin mi ni ìwọ, wọn yóò sì ṣe mí dáradára, a ó sì dá ẹ̀mí mi sí nítorí tìrẹ.” Nígbà tí Abramu dé Ejibiti, àwọn ará Ejibiti ri i pé aya rẹ̀ rẹwà gidigidi. Nígbà tí àwọn ìjòyè Farao sì rí i, wọ́n ròyìn rẹ̀ níwájú Farao, wọ́n sì mú un lọ sí ààfin. Ó sì kẹ́ Abramu dáradára nítorí Sarai, Abramu sì ní àgùntàn àti màlúù, akọ àti abo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ìránṣẹ́kùnrin àti ìránṣẹ́bìnrin, pẹ̀lú ìbákasẹ. Olúwa sì rán àjàkálẹ̀-ààrùn búburú sí Farao àti ilé rẹ̀, nítorí Sarai aya Abramu. Nítorí náà Farao ránṣẹ́ pe Abramu, ó sì wí fun pé, “Èwo ni ìwọ ṣe sí mi yìí? Kí ló dé tí ìwọ kò sọ fún mi pé aya rẹ ní í ṣe? Èéṣe tí o fi wí pé, ‘Arábìnrin mi ni,’ tí èmi sì fi fẹ́ ẹ gẹ́gẹ́ bí aya? Nítorí náà nísinsin yìí, aya rẹ náà nìyí, mú un kí o sì máa lọ.” Nígbà náà ni Farao pàṣẹ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ nípa Abramu, wọ́n sì lé e jáde ti òun ti aya rẹ̀ àti ohun gbogbo tí ó ní. Ìpinyà Abramu àti Lọti Abramu sì gòkè láti Ejibiti lọ sí ìhà gúúsù, pẹ̀lú aya rẹ̀ àti ohun gbogbo tí ó ní àti Lọti pẹ̀lú. Abramu sì ti di ọlọ́rọ̀ gidigidi; ní ẹran ọ̀sìn, ó ní fàdákà àti wúrà. Láti gúúsù, ó ń lọ láti ibìkan sí ibòmíràn títí ó fi dé ilẹ̀ Beteli, ní ibi tí àgọ́ rẹ̀ ti wà ní ìṣáájú rí, lágbedeméjì Beteli àti Ai. Ní ibi pẹpẹ tí ó ti tẹ́ síbẹ̀ ní ìṣáájú, níbẹ̀ ni Abramu sì ń ké pe orúkọ Olúwa. Àti Lọti pẹ̀lú, tí ó ń bá Abramu rìn kiri, ní agbo ẹran, ọ̀wọ́ ẹran àti àgọ́. Ṣùgbọ́n ilẹ̀ náà kò le gbà wọ́n tí wọ́n bá ń gbé pọ̀, nítorí, ohun ìní wọn pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́, dé bi wí pé wọn kò le è gbé pọ̀. Èdè-àìyedè sì bẹ̀rẹ̀ láàrín àwọn darandaran Abramu àti ti Lọti. Àwọn ará Kenaani àti àwọn ará Peresi sì ń gbé ní ilẹ̀ náà nígbà náà. Abramu sì wí fún Lọti pé, “Èmi bẹ̀ ọ́, má ṣe jẹ́ kí èdè-àìyedè kí ó wà láàrín èmi àti ìrẹ, àti láàrín àwọn darandaran wa, nítorí pé ẹbí kan ni àwa ṣe. Gbogbo ilẹ̀ ha kọ́ nìyí níwájú rẹ? Jẹ́ kí a pínyà. Bí ìwọ bá lọ sí apá ọ̀tún, èmi yóò lọ sí apá òsì, bí ó sì ṣe òsì ni ìwọ lọ, èmi yóò lọ sí apá ọ̀tún.” Lọti sì gbójú sókè, ó sì ri wí pé gbogbo pẹ̀tẹ́lẹ̀ Jordani ni omi rin dáradára bí ọgbà Olúwa, bí ilẹ̀ Ejibiti, ní ọ̀nà Soari. (Èyí ní ìṣáájú kí Olúwa tó pa Sodomu àti Gomorra run.) Nítorí náà Lọti yan gbogbo pẹ̀tẹ́lẹ̀ Jordani yìí fún ara rẹ̀, ó sì ń lọ sí ọ̀nà ìlà-oòrùn. Òun àti Abramu sì pínyà. Abramu ń gbé ni ilẹ̀ Kenaani, Lọti sì jókòó ní ìlú agbègbè àfonífojì náà, ó sì pàgọ́ rẹ̀ títí dé Sodomu. Ṣùgbọ́n àwọn ọkùnrin Sodomu jẹ́ ènìyàn búburú, wọn sì ń dẹ́ṣẹ̀ gidigidi ni iwájú Olúwa. Olúwa sì wí fún Abramu lẹ́yìn ìpinyà òun àti Lọti pé, “Gbé ojú rẹ sókè nísinsin yìí, kí o sì wò láti ibi tí o gbé wà a nì lọ sí ìhà àríwá àti sí ìhà gúúsù, sí ìlà-oòrùn àti sí ìwọ̀ rẹ̀. Gbogbo ilẹ̀ tí ìwọ ń wò o nì ni èmi ó fi fún ọ àti irú-ọmọ rẹ láéláé. Èmi yóò mú kí irú-ọmọ rẹ kí ó pọ̀ bí erùpẹ̀ ilẹ̀, tó bẹ́ẹ̀ tí ó bá ṣe pé ẹnikẹ́ni bá le è ka erùpẹ̀ ilẹ̀, nígbà náà ni yóò tó lè ka irú-ọmọ rẹ. Dìde, rìn òró àti ìbú ilẹ̀ náà já, nítorí ìwọ ni Èmi yóò fi fún.” Nígbà náà ni Abramu kó àgọ́ rẹ̀, ó sì wá, ó sì jókòó ní ẹ̀gbẹ́ igi ńlá igbó Mamre, tí ó wà ní Hebroni. Níbẹ̀ ni ó gbé tẹ́ pẹpẹ kan sí fún Olúwa. Abramu gba Lọti là Ní àsìkò yìí ni Amrafeli ọba Ṣinari, Arioku ọba Ellasari, Kedorlaomeri ọba Elamu àti Tidali ọba Goyimu jáde lọ láti bá Bera ọba Sodomu, Birṣa ọba Gomorra, Ṣenabu ọba Adma, Ṣemeberi ọba Seboimu àti ọba Bela (èyí ni Soari) jagun. Gbogbo àwọn ọba wọ̀nyí ni ó kó ogun wọn jọ pọ̀ sí àfonífojì Siddimu (ti o túmọ̀ sí Òkun Iyọ̀). Fún ọdún méjìlá gbáko ni wọ́n ti ń sin Kedorlaomeri bí ẹrú. Ṣùgbọ́n nígbà tí ó di ọdún kẹtàlá wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí i. Ní ọdún kẹrìnlá, ni Kedorlaomeri àti àwọn ọba tí wọ́n ti jọ ni májẹ̀mú àṣepọ̀ wá, wọ́n ṣígun, wọ́n sì ṣẹ́gun ará Refaimu ní Aṣteroti-Karnaimu, àwọn ará Susimu ni Hamu, àwọn ará Emimu ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Kiriataimu, àti àwọn ará Hori ní orí òkè wọ̀n-ọn-nì Seiri, títí ó fi dé Eli-Parani ní etí ijù. Wọ́n sì tún yípadà lọ sí En-Miṣpati (ti o túmọ̀ sí Kadeṣi), wọ́n sì ṣẹ́gun gbogbo ilẹ̀ àwọn Amaleki, àti àwọn ará Amori tí ó tẹ̀dó sí Hasason Tamari pẹ̀lú. Nígbà náà ni ọba Sodomu, ọba Gomorra, ọba Adma, ọba Seboimu àti ọba Bela (èyí ni Soari), kó àwọn ọmọ-ogun wọn, wọ́n sì pa ibùdó ogun wọn sí Àfonífojì Siddimu, láti kojú ìjà sí Kedorlaomeri ọba Elamu, Tidali ọba Goyimu, Amrafeli ọba Ṣinari àti Arioku ọba Ellasari (ọba mẹ́rin kọjú ìjà sí ọba márùn-ún). Àfonífojì Siddimu sì kún fún kòtò ọ̀dà ilẹ̀, nígbà tí ọba Sodomu àti ọba Gomorra sì sá, díẹ̀ nínú àwọn ọkùnrin ogun náà ṣubú sínú àwọn kòtò náà, àwọn tókù sì sálọ sì orí òkè. Àwọn ọba mẹ́rẹ̀ẹ̀rin náà sì kó gbogbo ẹrù Sodomu àti Gomorra àti oúnjẹ wọn; wọ́n sì lọ. Wọ́n sì mú Lọti ọmọ arákùnrin Abramu tí ń gbé ní Sodomu àti gbogbo ohun ìní rẹ̀. Ẹnìkan tí ó sá àsálà sì wá ròyìn fún Abramu, ará Heberu ni. Abramu sá ti tẹ̀dó sí ẹ̀gbẹ́ igi ńlá igbó Mamre ará Amori, arákùnrin Eṣkolu àti Aneri: àwọn ẹni tí ó ń bá Abramu ní àṣepọ̀. Nígbà tí Abramu gbọ́ wí pé, a di Lọti ní ìgbèkùn, ó kó àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ tí a bí sí ilẹ̀ rẹ̀ tí ó sì ti kọ́ ni ogun jíjà jáde, wọ́n jẹ́ okòó lé lọ́ọ̀dúnrún ó dín méjì (318) ènìyàn, ó sì lépa wọn títí dé Dani. Ní ọ̀gànjọ́ òru, Abramu pín àwọn ọmọ-ogun rẹ̀ sí méjì, ó sì kọlù wọ́n, ó sì ṣẹ́gun wọn, ó sì lé wọn títí dé Hoba tí ó wà ní apá òsì Damasku. Gbogbo ìkógun ni ó rí gbà padà àti ọmọ arákùnrin rẹ̀, Lọti pẹ̀lú ohun ìní rẹ̀, àti àwọn obìnrin pẹ̀lú àwọn ènìyàn tókù. Nígbà tí Abramu ti ṣẹ́gun Kedorlaomeri àti àwọn ọba tí ó pẹ̀lú rẹ̀, ọba Sodomu lọ pàdé rẹ̀ ní àfonífojì Ṣafe (èyí ni àfonífojì Ọba). Melkisedeki ọba Salẹmu14.18 tí ó túmọ̀ sí, Jerusalẹmu sì mú oúnjẹ àti ọtí wáìnì jáde wá. Òun ni àlùfáà Ọlọ́run Ọ̀gá-ògo. Ó sì súre fún Abramu, wí pé, “Ìbùkún ni fún Abramu ti Ọlọ́run Ọ̀gá-ògo, Ẹni tí ó dá ọ̀run òun ayé. Ìbùkún sì ni fún Ọlọ́run Ọ̀gá-ògo jùlọ, tí ó fi àwọn ọ̀tá rẹ lé ọ lọ́wọ́.” Abramu sì fún un ní ìdámẹ́wàá ohun gbogbo. Ọba Sodomu sì wí fún Abramu pé, “Kó àwọn ènìyàn mi fún mi, ṣùgbọ́n mú àwọn ẹrù fún ara rẹ.” Ṣùgbọ́n Abramu dá ọba Sodomu lóhùn pé, “Mo ti búra fún Olúwa, Ọlọ́run Ọ̀gá-ògo, tí ó dá ọ̀run àti ayé, mo sì ti gbọ́wọ́ sókè, pé, èmi kì yóò mú láti fọ́nrán òwú títí dé okùn bàtà, àti pé, èmi kí yóò mú ohun kan tí ṣe tìrẹ, kí ìwọ kí ó má ba à wí pé, ‘Mo sọ Abramu di ọlọ́rọ̀.’ Èmi kì yóò gba ohunkóhun yàtọ̀ sí ohun tí àwọn ọkùnrin mi ti jẹ́, ṣùgbọ́n fi ìpín fún àwọn ọkùnrin tí ó bá mi lọ, Aneri, Eṣkolu àti Mamre. Jẹ́ kí wọn kí ó gba ìpín wọn.” Májẹ̀mú Ọlọ́run pẹ̀lú Abramu Lẹ́yìn èyí, ọ̀rọ̀ Olúwa tọ Abramu wá lójú ìran pé, “Abramu má ṣe bẹ̀rù. Èmi ni ààbò rẹ, Èmi sì ni èrè ńlá rẹ.” Ṣùgbọ́n Abramu wí pé, “Olúwa Olódùmarè, kí ni ìwọ yóò fi fún mi níwọ̀n ìgbà tí èmi kò bímọ, Elieseri ará Damasku ni yóò sì jogún mi,” Abramu sì tún tẹ̀síwájú pé, “Ìwọ kò fún mi ní ọmọ, nítorí náà ẹrú nínú ilé mi sì ni yóò jẹ́ àrólé mi.” Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tún tọ̀ ọ́ wá pé, “Ọkùnrin yìí kọ́ ni yóò jẹ́ àrólé rẹ bí kò ṣe ọmọ tí ìwọ bí fúnra rẹ̀ ni yóò jẹ́ àrólé rẹ.” Olúwa sì mú Abramu jáde sí ìta ó sì wí fún un pé, “Gbé ojú sókè sí ọ̀run kí o sì ka àwọn ìràwọ̀ bí ó bá ṣe pé ìwọ le è kà wọ́n.” Ó sì wí fun un pé, “Nítorí náà, báyìí ni irú-ọmọ rẹ yóò rí.” Abramu gba Olúwa gbọ́, a sì kà á sí òdodo fún un. Ó sì tún wí fún un pé, “Èmi ni Olúwa tí ó mú ọ jáde láti Uri ti Kaldea láti fún ọ ní ilẹ̀ yìí láti jogún.” Ṣùgbọ́n Abramu wí pé, “Olúwa Olódùmarè, báwo ni mo ṣe lè mọ̀ pé ilẹ̀ náà yóò jẹ́ ohun ìní mi?” Nítorí náà, Olúwa wí fún un pé, “Mú abo màlúù, ewúrẹ́ àti àgbò ọlọ́dún mẹ́ta mẹ́ta wá, àti àdàbà kan àti ọmọ ẹyẹlé kan.” Abramu sì mú gbogbo nǹkan wọ̀nyí wá, ó sì là wọ́n sí méjì méjì, ó sì fi ẹ̀là èkínní kọjú sí èkejì, ṣùgbọ́n kò la àwọn ẹyẹ ní tiwọn. Àwọn ẹyẹ igún sì ń wá sórí òkú ẹran náà, Abramu sì ń lé wọn. Bí oòrùn ti ń wọ̀, Abramu sùn lọ fọnfọn, òkùnkùn biribiri tí ó kún fún ẹ̀rù sì bò ó. Nígbà náà ni Olúwa wí fún Abramu pé, “Mọ èyí dájú pé, irú-ọmọ rẹ yóò ṣe àtìpó ní ilẹ̀ àjèjì, wọn ó sì sọ wọn di ẹrú, wọn ó sì pọ́n wọn lójú fún irinwó (400) ọdún. Ṣùgbọ́n orílẹ̀-èdè náà tí wọn yóò máa sìn, ni èmi ó dá lẹ́jọ́, lẹ́yìn náà ni wọn ó sì jáde pẹ̀lú ọrọ̀ púpọ̀. Ṣùgbọ́n ìwọ yóò tọ àwọn baba rẹ lọ ni àlàáfíà, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ yóò sì di arúgbó kí a tó gbé ọ sin. Ní ìran kẹrin àwọn ìran rẹ yóò padà wá sí ibi. Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ará Amori kò ì tí ì kún òsùwọ̀n.” Nígbà tí oòrùn wọ̀ tí ilẹ̀ sì ṣú, ìkòkò iná tí ń ṣèéfín àti ọwọ́ iná sì ń kọjá láàrín ẹ̀là ẹran náà. Ní ọjọ́ náà gan an ni Olúwa dá májẹ̀mú pẹ̀lú Abramu, ó sì wí pé, “Àwọn ìran rẹ ni èmi yóò fi ilẹ̀ yìí fún, láti odò Ejibiti dé odò ńlá Eufurate: ilẹ̀ àwọn ará Keni, àti ti ará Kenissiti, àti ará Kadmoni, àti ti ará Hiti, àti ti ará Peresi, àti ti ará Refaimu. Àti ti ará Amori, àti ti ará Kenaani, àti ti ará Girgaṣi àti ti ará Jebusi.” Hagari àti Iṣmaeli Sarai, aya Abramu kò bímọ fún un, ṣùgbọ́n ó ní ọmọ ọ̀dọ̀ obìnrin ará Ejibiti kan tí ń jẹ́ Hagari. Nítorí náà, Sarai wí fún Abramu pé, “Kíyèsi i Olúwa ti sé mi ní inú, èmi kò sì bímọ, wọlé tọ ọmọ ọ̀dọ̀ mi lọ, bóyá èmi yóò le ti ipasẹ̀ rẹ̀ ní ọmọ.” Abramu sì gba ohun tí Sarai sọ. Lẹ́yìn ọdún mẹ́wàá tí Abramu ti ń gbé ni Kenaani ni Sarai mú ọmọbìnrin, ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ Hagari, tí í ṣe ará Ejibiti fún Abramu ọkọ rẹ̀ láti fi ṣe aya. Abramu sì bá Hagari lòpọ̀, ó sì lóyún. Nígbà tí ó sì ti mọ̀ pé òun lóyún, ó bẹ̀rẹ̀ sì ní kẹ́gàn ọ̀gá rẹ̀. Nígbà náà ni Sarai wí fún Abramu pé, “Ìwọ ni ó jẹ́ kí ẹ̀gbin yìí máa jẹ mí, mo fa ọmọ ọ̀dọ̀ mi lé ọ lọ́wọ́, nígbà tí ó sì rí i pé òun lóyún, mo di ẹni ẹ̀gàn ní ojú rẹ̀. Kí Olúwa kí ó ṣe ìdájọ́ láàrín tèmi tìrẹ.” Abramu dáhùn pé, “Ìwọ ló ni ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ, ṣe ohunkóhun tí ó bá tọ́ ní ojú rẹ sí i.” Nígbà náà ni Sarai fi ìyà jẹ Hagari, ó sì sálọ. Angẹli Olúwa sì rí Hagari ní ẹ̀gbẹ́ ìsun omi ní ijù, ìsun omi tí ó wà ní ẹ̀gbẹ́ ọ̀nà tí ó lọ sí Ṣuri. Ó sì wí pé, “Hagari, ìránṣẹ́ Sarai, níbo ni o ti ń bọ̀, níbo sì ni ìwọ ń lọ?” Ó sì dáhùn pé, “Mo ń sálọ kúrò lọ́dọ̀ ọ̀gá mi Sarai ni.” Angẹli Olúwa sì wí fún un pé, “Padà lọ sí ọ̀dọ̀ ọ̀gá rẹ kí o sì tẹríba fún un.” Angẹli Olúwa náà sì fi kún fún un pé, “Èmi yóò sọ ọ́ di orílẹ̀-èdè ńlá, ìran rẹ kì yóò sì lóǹkà.” Angẹli Olúwa náà sì wí fún un pé, “Ìwọ ti lóyún, ìwọ yóò sì bí ọmọkùnrin kan. Ìwọ yóò sì pe orúkọ rẹ̀ ní Iṣmaeli, nítorí tí Olúwa ti rí ìpọ́njú rẹ. Òun yóò jẹ́ oníjàgídíjàgan ènìyàn ọwọ́ rẹ̀ yóò wà lára ènìyàn gbogbo, ọwọ́ ènìyàn gbogbo yóò sì wà lára rẹ̀, yóò sì máa gbé ní ìkanra pẹ̀lú àwọn arákùnrin rẹ̀.” Ó sì pe orúkọ Olúwa tí o bá sọ̀rọ̀ ní, “Ìwọ ni Ọlọ́run tí ó rí mi,” nítorí tí ó wí pé, “Mo ti ri ẹni tí ó rí mi báyìí.” Nítorí náà ni a ṣe ń pe kànga náà ní Beeri-Lahai-Roi; kànga ẹni alààyè tí ó rí mi. Ó wà ní agbede-méjì Kadeṣi àti Beredi. Hagari sì bí ọmọkùnrin kan fún Abramu, Abramu sì pe orúkọ rẹ̀ ní Iṣmaeli. Abramu jẹ́ ẹni ọdún mẹ́rìndínláàádọ́rùn-ún nígbà tí Hagari bí Iṣmaeli fún un. Májẹ̀mú Ilà abẹ́ kíkọ Ní ìgbà tí Abramu di ẹni ọ̀kàndínlọ́gọ́rùn-ún ọdún, Olúwa farahàn án, ó sì wí pé, “Èmi ni Ọlọ́run alágbára,17.1 tí ó túmọ̀ sí, El-Ṣaddai máa rìn níwájú mi, kí o sì jẹ́ aláìlábùkù. Èmi yóò sì fi ìdí májẹ̀mú mi múlẹ̀ pẹ̀lú rẹ. Èmi yóò sì sọ ọ́ di púpọ̀ gidigidi.” Abramu sì dojúbolẹ̀, Ọlọ́run sì wí fún un pé. “Ní ti èmi, májẹ̀mú mi pẹ̀lú rẹ nìyí. Ìwọ yóò di baba orílẹ̀-èdè púpọ̀. A kì yóò pe orúkọ rẹ̀ ní Abramu mọ́, bí kò ṣe Abrahamu, nítorí, mo ti sọ ọ́ di baba orílẹ̀-èdè púpọ̀. Èmi yóò mú ọ bí si lọ́pọ̀lọ́pọ̀, ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè ni èmi yóò sì mú ti ara rẹ jáde wá, àwọn ọba pẹ̀lú yóò sì ti inú rẹ jáde. Èmi yóò sì gbé májẹ̀mú mi kalẹ̀ láàrín tèmi tìrẹ, ní májẹ̀mú ayérayé àti láàrín irú-ọmọ rẹ ní ìran-ìran wọn, láti máa ṣe Ọlọ́run rẹ àti ti irú-ọmọ rẹ lẹ́yìn rẹ. Gbogbo ilẹ̀ Kenaani níbi tí ìwọ ti ṣe àjèjì ni èmi yóò fi fún ọ àti fún irú-ọmọ rẹ lẹ́yìn rẹ láéláé. Èmi yóò sì jẹ́ Ọlọ́run wọn.” Nígbà náà ni Ọlọ́run wí fún Abrahamu pé, “Ìwọ máa pa májẹ̀mú mi mọ́, ìwọ àti irú-ọmọ rẹ lẹ́yìn rẹ àti àwọn ìran tí ó ń bọ̀. Èyí ni májẹ̀mú mi pẹ̀lú rẹ àti ìran rẹ lẹ́yìn rẹ, májẹ̀mú tí ẹ̀yin yóò máa pamọ́. Gbogbo ọkùnrin yín ni a gbọdọ̀ kọ ní ilà. Ẹ̀yin yóò kọ ara yín ní ilà, èyí ni yóò jẹ́ àmì májẹ̀mú láàrín tèmi tiyín. Ní gbogbo ìran tí ń bọ̀ lẹ́yìn, gbogbo ọkùnrin ni a gbọdọ̀ kọ ni ilà ní ọjọ́ kẹjọ tí a bí wọn, àti àwọn tí a bí ní ilé rẹ, tàbí tí a fi owó rà lọ́wọ́ àwọn àjèjì, àwọn tí kì í ṣe ọmọ rẹ̀. Èyí yóò sì jẹ́ májẹ̀mú láéláé tí yóò wà láàrín Èmi àti irú-ọmọ rẹ. Ìbá à ṣe ẹni tí a bí nínú ilé rẹ, tàbí ẹni tí o fi owó rà, a gbọdọ̀ kọ wọ́n ní ilà; májẹ̀mú mí lára yín yóò jẹ́ májẹ̀mú ayérayé. Gbogbo ọmọkùnrin tí kò bá kọ ilà, tí a kò kọ ní ilà abẹ́, ni a ó gé kúrò láàrín àwọn ènìyàn rẹ̀, nítorí pé ó da májẹ̀mú mi.” Ọlọ́run wí fún Abrahamu pé, “Ní ti Sarai, aya rẹ̀, ìwọ kì yóò pè é ní Sarai mọ́, bí kò ṣe Sara. Èmi yóò bùkún fún un, èmi yóò sì fun ọ ní ọmọkùnrin kan nípasẹ̀ rẹ̀. Èmi yóò bùkún un, yóò sì di ìyá àwọn orílẹ̀-èdè, àwọn ọba àwọn orílẹ̀-èdè yóò sì ti ara rẹ̀ jáde wá.” Abrahamu sì dojúbolẹ̀, ó rẹ́rìn-ín, ó sì wí fún ara rẹ̀ pé, “A ó ha bí ọmọ fún ẹni ọgọ́rùn-ún ọdún? Sara tí í ṣe ẹni àádọ́rùn-ún ọdún yóò ha bímọ bí?” Abrahamu sì wí fún Ọlọ́run pé, “Sá à jẹ́ kí Iṣmaeli kí ó wà láààyè lábẹ́ ìbùkún rẹ.” Nígbà náà ni Ọlọ́run wí pé, “Mo gbọ́, ṣùgbọ́n Sara aya rẹ̀ yóò bí ọmọkùnrin kan fún ọ, ìwọ yóò sì pe orúkọ rẹ̀ ní Isaaki, èmi yóò fi ìdí májẹ̀mú mi múlẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀ ní májẹ̀mú ayérayé àti àwọn irú-ọmọ rẹ̀ lẹ́yìn rẹ̀. Ṣùgbọ́n ní ti Iṣmaeli, mo gbọ́ ohun tí ìwọ wí, èmi yóò bùkún fún un nítòótọ́, èmi ó sì mú un bí sí i, yóò sì pọ̀ sí i, òun yóò sì jẹ́ baba fún àwọn ọmọ ọba méjìlá, bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò sì sọ ọ́ di orílẹ̀-èdè ńlá. Ṣùgbọ́n èmi yóò fi ìdí májẹ̀mú mi múlẹ̀ pẹ̀lú Isaaki, ẹni tí Sara yóò bí fún ọ ni ìwòyí àmọ́dún.” Nígbà tí ó ti bá Abrahamu sọ̀rọ̀ tán, Ọlọ́run sì gòkè lọ kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀. Ní ọjọ́ náà gan an ni Abrahamu mú Iṣmaeli ọmọ rẹ̀ àti àwọn ẹrú tí a bí ní ilé rẹ̀ àti àwọn tí ó fi owó rà, ó sì kọ wọ́n ní ilà. Bẹ́ẹ̀ ni ó sì kọ gbogbo ọkùnrin tí ń bẹ ní ilé rẹ̀ ní ilà gẹ́gẹ́ bí àṣẹ Ọlọ́run. Abrahamu jẹ́ ẹni ọ̀kàndínlọ́gọ́rùn-ún ọdún nígbà tí a kọ ọ́ ní ilà. Iṣmaeli ọmọ rẹ̀ jẹ́ ẹni ọdún mẹ́tàlá. Ní ọjọ́ náà gan an ni a kọ Abrahamu ní ilà pẹ̀lú Iṣmaeli ọmọ rẹ̀ ọkùnrin. Àti gbogbo ọkùnrin tí ó wà ní ilé Abrahamu, ìbá à ṣe èyí tí a bí ní ilé rẹ̀ tàbí èyí tí a fi owó rà lọ́wọ́ àlejò ni a kọ ní ilà pẹ̀lú rẹ̀. Àwọn àlejò mẹ́ta Olúwa sì farahan Abrahamu nítòsí àwọn igi ńlá Mamre, bí ó ti jókòó ní ẹnu-ọ̀nà àgọ́ rẹ̀, nígbà tí ọjọ́-kanrí tí oòrùn sì mú. Abrahamu gbójú sókè, ó sì rí àwọn ọkùnrin mẹ́ta tí wọn dúró nítòsí rẹ̀. Nígbà tí ó rí wọn, ó sáré láti lọ pàdé wọn, ó sì tẹríba bí ó ti ń kí wọn. Ó wí pé, “Bí mo bá rí ojúrere yín Olúwa mi, ẹ má ṣe lọ láì yà sọ́dọ̀ ìránṣẹ́ yín. Ẹ jẹ́ kí a bu omi díẹ̀ wá kí ẹ̀yin kí ó wẹ ẹsẹ̀ yín, kí ẹ sì sinmi lábẹ́ igi níhìn-ín. Ẹ jẹ́ kí n wá oúnjẹ wá fún un yín, kí ẹ̀yin kí ó lè jẹ, kí ara sì tù yín, kí ẹ si tẹ̀síwájú ní ọ̀nà yín, nígbà tí ẹ ti yà ní ọ̀dọ̀ ìránṣẹ́ yín.” Wọn sì wí pé “Ó dára.” Abrahamu sì yára tọ Sara aya rẹ̀ lọ nínú àgọ́, ó wí pé, “Tètè mú òsùwọ̀n ìyẹ̀fun dáradára mẹ́ta kí o sì pò ó pọ̀, kí o sì ṣe oúnjẹ.” Abrahamu sì tún sáré lọ sí ibi agbo ẹran, ó sì mú ọmọ màlúù kan fún ìránṣẹ́ rẹ̀, ìránṣẹ́ náà sì tètè ṣè é. Ó sì mú wàrà àti mílíìkì àti màlúù tí ó ti pèsè, ó sì gbé síwájú wọn. Ó sì dúró nítòsí wọn lábẹ́ igi bí wọn ti ń jẹ ẹ́. Wọn béèrè pé, “Sara aya rẹ ń kọ́?” Ó dáhùn pé, “Ó wà nínú àgọ́.” Nígbà náà ni Olúwa wí fún un pé, “Èmi yóò sì tún padà tọ̀ ọ́ wá nítòótọ́ ní ìwòyí àmọ́dún; Sara aya rẹ yóò sì bí ọmọkùnrin kan.” Sara sì ń dẹtí gbọ́ láti ẹnu-ọ̀nà àgọ́ tí ó wà lẹ́yìn ọkùnrin náà. Abrahamu àti Sara sì ti di arúgbó, Sara sì ti kọjá àsìkò ìbímọ. Nítorí náà, Sara rẹ́rìn-ín nínú ara rẹ̀ bí ó ti ń rò ó lọ́kàn rẹ̀ pé, “Lẹ́yìn ìgbà tí mo ti di arúgbó tán tí olúwa mi pẹ̀lú sì ti gbó jọ̀kújọ̀kú, èmi yóò ha tún lè bímọ?” Nígbà náà ni Olúwa wí fún Abrahamu pé, “Kín ló dé tí Sara fi rẹ́rìn-ín tí ó sì wí pé, ‘Èmi yóò ha bímọ nítòótọ́, nígbà tí mo di ẹni ogbó tán?’ Ǹjẹ́ ohunkóhun wà tí ó ṣòro jù fún Olúwa? Èmi ó padà tọ̀ ọ́ wá ní ìwòyí àmọ́dún, Sara yóò sì bí ọmọkùnrin.” Ẹ̀rù sì ba Sara, ó sì sẹ́ pé òun kò rẹ́rìn-ín. Ṣùgbọ́n Olúwa wí fún un pé, “Dájúdájú ìwọ rẹ́rìn-ín.” Abrahamu bẹ Olúwa nítorí Sodomu Nígbà tí àwọn ọkùnrin náà dìde láti máa lọ, wọn kọjú sí ọ̀nà Sodomu, Abrahamu sì sìn wọ́n dé ọ̀nà. Nígbà náà ni Olúwa wí pé, “Ǹjẹ́ èmi yóò ha pa ohun tí mo fẹ́ ṣe mọ́ fún Abrahamu bí? Dájúdájú Abrahamu yóò sá à di orílẹ̀-èdè ńlá àti alágbára, àti gbogbo orílẹ̀-èdè ayé ni a ó bùkún fún nípasẹ̀ rẹ̀. Nítorí tí èmi ti yàn án láti kọ́ àwọn ọmọ rẹ̀ àti àwọn ará ilé rẹ̀ lẹ́yìn rẹ̀, láti máa pa ọ̀nà Olúwa mọ nípa ṣíṣe olóòtítọ́ àti olódodo: kí Olúwa le è mú ìlérí rẹ̀ fún Abrahamu ṣẹ.” Olúwa sì wí pé, igbe Sodomu àti Gomorra pọ̀ púpọ̀ àti pé ẹ̀ṣẹ̀ wọn burú jọjọ. “Èmi yóò sọ̀kalẹ̀ síbẹ̀ láti ṣe ìwádìí igbe tí ó dé sí etí ìgbọ́ mi nípa wọn, kí èmi sì mọ òtítọ́ tí ó wà níbẹ̀.” Àwọn ọkùnrin náà yí padà, wọ́n sì ń lọ sí ìhà Sodomu. Ṣùgbọ́n Abrahamu dúró níbẹ̀ níwájú Olúwa. Nígbà náà ni Abrahamu súnmọ́ ọ̀dọ̀ Olúwa, ó sì wí pé, “Ìwọ yóò ha pa olódodo ènìyàn àti ènìyàn búburú run papọ̀ bí?” “Bí ó bá ṣe pé ìwọ rí àádọ́ta olódodo nínú ìlú náà, ìwọ yóò ha run ún, ìwọ kì yóò ha dá ìlú náà sí nítorí àwọn àádọ́ta olódodo tí ó wà nínú rẹ̀ náà? Kò jẹ́ rí bẹ́ẹ̀! Dájúdájú ìwọ kì yóò ṣe ohun tí ó jọ bẹ́ẹ̀, láti pa olódodo pẹ̀lú àwọn ènìyàn rere àti àwọn ènìyàn búburú. Dájúdájú, ìwọ kì yóò ṣe èyí tí ó tọ́ bi?” Olúwa wí pé, “Bí mo bá rí àádọ́ta olódodo ní ìlú Sodomu, èmi yóò dá ìlú náà sí nítorí tiwọn.” Abrahamu sì tún tẹ̀síwájú pé, “Wò ó nísinsin yìí, níwọ̀n bí èmi ti ní ìgboyà láti bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀ níwájú Olúwa, èmi ẹni tí í ṣe erùpẹ̀ àti eérú, bí ó bá ṣe pe olódodo márùndínláàádọ́ta ni ó wà nínú ìlú, ìwọ yóò ha pa ìlú náà run nítorí ènìyàn márùn-ún bí?” Olúwa dáhùn pé, “Èmi kì yóò pa ìlú náà run bí mo bá rí olódodo márùndínláàádọ́ta nínú rẹ̀.” Òun sì tún wí lẹ́ẹ̀kan si pé, “Bí ó bá ṣe pé ogójì ni ń kọ́?” Olúwa sì tún wí pé, “Èmi kì yóò pa ìlú náà run bí mo bá rí olódodo ogójì nínú rẹ̀.” Abrahamu sì tún bẹ Olúwa pé, “Kí Olúwa má ṣe bínú, ṣùgbọ́n èmi yóò sọ̀rọ̀. Bí ó bá ṣe pé ọgbọ̀n ni a rí níbẹ̀ ń kọ́?” Olúwa dáhùn pé, “Bí mó bá rí ọgbọ̀n, èmi kì yóò pa ìlú run.” Abrahamu wí pé, “Níwọ́n bí mo ti ní ìgboyà láti bá Olúwa sọ̀rọ̀ báyìí, jẹ́ kí n tẹ̀síwájú. Bí o bá ṣe pé olódodo ogún péré ni ó wà nínú ìlú náà ń kọ́?” Olúwa sì dáhùn pé, “Èmi kì yóò pa á run nítorí ogún ènìyàn náà.” Abrahamu sì wí pé, “Jọ̀wọ́ má ṣe bínú Olúwa. Jẹ́ kí ń béèrè lẹ́ẹ̀kan si. Bí ó bá ṣe pé ènìyàn mẹ́wàá ni ó jẹ́ olódodo ń kọ́?” Olúwa wí pé, “Nítorí ènìyàn mẹ́wàá náà, èmi kì yóò pa á run.” Olúwa sì bá tirẹ̀ lọ, nígbà tí ó bá Abrahamu sọ̀rọ̀ tán, Abrahamu sì padà sílé. Ìparun Sodomu àti Gomorra Ní àṣálẹ́, àwọn angẹli méjì sì wá sí ìlú Sodomu, Lọti sì jókòó ní ẹnu ibodè ìlú. Bí ó sì ti rí wọn, ó sì dìde láti pàdé wọn, ó kí wọn, ó sì foríbalẹ̀ fún wọn. Ó wí pé, “Ẹ̀yin olúwa mi, èmi bẹ̀ yín, ẹ yà sí ilé ìránṣẹ́ yín kí ẹ sì wẹ ẹsẹ̀ yín, kí n sì gbà yín lálejò, ẹ̀yin ó sì dìde ní kùtùkùtù òwúrọ̀ láti máa bá ìrìnàjò yín lọ.” Wọ́n sì wí pé, “Rárá o, àwa yóò dúró ní ìgboro ní òru òní.” Ṣùgbọ́n Lọti rọ̀ wọ́n gidigidi tó bẹ́ẹ̀ tí wọ́n gbà láti bá a lọ sì ilé. Ó sì ṣe àsè fún wọn, ó sì dín àkàrà aláìwú fún wọ́n, wọ́n sì jẹ. Ṣùgbọ́n kí ó tó di pé wọ́n lọ sùn, àwọn ọkùnrin ìlú Sodomu tọmọdé tàgbà yí ilé náà ká. Wọ́n pe Lọti pé, “Àwọn ọkùnrin tí ó wọ̀ sí ilé rẹ lálẹ́ yìí ń kọ́? Mú wọn jáde fún wa, kí a le ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú wọn.” Lọti sì jáde láti pàdé wọn, ó sì ti ìlẹ̀kùn lẹ́yìn rẹ̀ bí ó ti jáde. Ó sì wí pé, “Rárá, ẹ̀yin ará mi, ẹ má ṣe ṣe ohun búburú yìí, kíyèsi i, mo ní ọmọbìnrin méjì tí kò mọ ọkùnrin rí, ẹ jẹ́ kí n mú wọn tọ̀ yín wá kí ẹ sì ṣe ohun tí ẹ fẹ́ pẹ̀lú wọn. Ṣùgbọ́n ẹ má ṣe ṣe àwọn ọkùnrin wọ̀nyí ní ibi kan nítorí wọ́n wá wọ̀ lábẹ́ ààbò ní ilé mi.” Wọ́n sì wí fún pé, “Bì sẹ́yìn fún wa. Èyí yìí wá ṣe àtìpó láàrín wa, òun sì fẹ́ ṣe onídàájọ́! Aburú tí a ó fi ṣe ọ́ yóò pọ̀ ju tí wọn lọ.” Wọn rọ́ lu Lọti, wọ́n sì súnmọ́ ọn láti fọ́ ìlẹ̀kùn. Ṣùgbọ́n àwọn ọkùnrin náà nawọ́ fa Lọti wọlé, wọ́n sì ti ìlẹ̀kùn. Wọ́n sì bu ìfọ́jú lu àwọn ọkùnrin tí ó wà ní ẹnu-ọ̀nà ilé náà, àti èwe àti àgbà: wọ́n kò sì rí ẹnu-ọ̀nà mọ́. Àwọn ọkùnrin náà sì wí fún Lọti pé, “Ǹjẹ́ ó ní ẹlòmíràn ní ìlú yìí bí? Àna rẹ ọkùnrin, àwọn ọmọ rẹ lọ́kùnrin àti lóbìnrin, tàbí ẹnikẹ́ni tí ìwọ ní ní ìlú yìí, kó wọn jáde kúrò ní ibí yìí, nítorí a ó pa ìlú yìí run, nítorí igbe iṣẹ́ búburú wọn ń dí púpọ̀ níwájú Olúwa, Olúwa sì rán wa láti pa á run.” Nígbà náà ni Lọti jáde, ó sì wí fún àwọn àna rẹ̀ ọkùnrin tí ó ti bá jẹ́ ẹ̀jẹ́ láti fẹ́ àwọn ọmọ rẹ̀ pé, “Ẹ ṣe kánkán, kí ẹ jáde ní ìlú yìí, nítorí Olúwa fẹ́ pa ìlú yìí run!” Ṣùgbọ́n àwọn ọkọ ọmọ rẹ̀ wọ̀nyí rò pé àwàdà ló ń ṣe. Ní àfẹ̀mọ́júmọ́, àwọn angẹli náà rọ Lọti pé, “Ṣe wéré, mú aya rẹ àti àwọn ọmọbìnrin rẹ méjèèjì tí ó wà níhìn-ín, àìṣe bẹ́ẹ̀, ìwọ yóò parun pẹ̀lú ìlú yìí nígbà tí wọ́n bá ń jìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn.” Nígbà tí ó ń jáfara, àwọn ọkùnrin náà nawọ́ mú un lọ́wọ́, wọ́n sì nawọ́ mú aya rẹ̀ náà lọ́wọ́ àti àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ méjèèjì, wọ́n sì mú wọn jáde sẹ́yìn odi ìlú, nítorí Olúwa ṣàánú fún wọn. Ní kété tí wọ́n mú wọn jáde sẹ́yìn odi tán, ọ̀kan nínú wọn wí pé, “Sá àsálà fún ẹ̀mí rẹ! Má ṣe wo ẹ̀yìn rẹ, bẹ́ẹ̀ ni kí ìwọ kí ó má ṣe dúró ní gbogbo pẹ̀tẹ́lẹ̀! Sá àsálà lọ sí orí òkè, kí ìwọ ó má ba ṣègbé!” Ṣùgbọ́n Lọti wí fún wọn pé, “Rárá, ẹ̀yin Olúwa mi, ẹ jọ̀wọ́! Nígbà tí ìránṣẹ́ rẹ ti rí ojúrere rẹ, tí o sì ti fi àánú rẹ hàn nípa gbígba ẹ̀mí mi là, èmi kò le è sálọ sórí òkè, kí búburú yìí má ba à lé mi bá, kí n sì kú. Wò ó, ìlú kékeré kan nìyí ní tòsí láti sá sí: jẹ́ kí n sálọ síbẹ̀, ìlú kékeré ha kọ́? Ẹ̀mí mi yóò sì yè.” Ó sì wí fún un pé, “Ó dára, mo gba ẹ̀bẹ̀ rẹ. Èmi kì yóò run ìlú náà tí ìwọ sọ̀rọ̀ rẹ̀. Tètè! Sálọ síbẹ̀, nítorí èmi kò le ṣe ohun kan àyàfi tí ó bá dé ibẹ̀.” (ìdí nìyí tí a fi ń pe ìlú náà ní Soari). Nígbà tí Lọti yóò fi dé ìlú Soari, oòrùn ti yọ. Nígbà náà ni Olúwa rọ̀jò iná àti sulfuru19.24 tí ó túmọ̀ sí, òkúta iná sórí Sodomu àti Gomorra láti ọ̀run lọ́dọ̀ Olúwa wá. Báyìí ni ó run àwọn ìlú náà àti gbogbo ilẹ̀ pẹ̀tẹ́lẹ̀, pẹ̀lú gbogbo àwọn tí ó wà ní ìlú ńlá ńlá wọ̀n-ọn-nì àti ohun gbogbo tí ó hù jáde nílẹ̀. Ṣùgbọ́n aya Lọti bojú wo ẹ̀yìn, ó sì di ọ̀wọ́n iyọ̀. Ní kùtùkùtù òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, Abrahamu sì dìde ó sì padà lọ sí ibi tí ó gbé dúró níwájú Olúwa. Ó sì wo ìhà Sodomu àti Gomorra àti àwọn ilẹ̀ pẹ̀tẹ́lẹ̀ wọ̀n-ọn-nì, ó sì rí èéfín tí ń ti ibẹ̀ jáde bí èéfín iná ìléru. Ọlọ́run sì rántí Abrahamu, nígbà tí ó run ìlú pẹ̀tẹ́lẹ̀ wọ̀n-ọn-nì tan, ó sì mú Lọti jáde kúrò láàrín ìparun náà, tí ó kọlu ìlú tí Lọti ti gbé. Lọti àti àwọn ọmọ rẹ̀ obìnrin Lọti àti àwọn ọmọ rẹ̀ obìnrin méjèèjì sì kúrò ní Soari, wọ́n sì ń lọ gbé ní orí òkè ní inú ihò àpáta, nítorí ó bẹ̀rù láti gbé ní ìlú Soari. Ní ọjọ́ kan, èyí ẹ̀gbọ́n sọ fún àbúrò rẹ̀ pé, “Baba wa ti dàgbà, kò sì sí ọkùnrin kankan ní agbègbè yìí tí ìbá bá wa lòpọ̀, bí ìṣe gbogbo ayé. Wá, jẹ́ kí a mú baba wa mu ọtí yó, kí ó ba à le bá wa lòpọ̀, kí àwa kí ó lè bí ọmọ, kí ìran wa má ba à parẹ́.” Ní òru ọjọ́ náà, wọ́n rọ baba wọn ní ọtí yó. Èyí ẹ̀gbọ́n sì wọlé tọ̀ ọ́, ó sì bá a lòpọ̀, baba wọn kò mọ̀ ìgbà tí ó sùn ti òun àti ìgbà tí ó dìde. Ní ọjọ́ kejì èyí ẹ̀gbọ́n wí fún àbúrò rẹ̀ pé, “Ní àná mo sùn ti baba mi. Jẹ́ kí a tún wọlé tọ̀ ọ́, kí a lè ní irú-ọmọ láti ọ̀dọ̀ baba wa.” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n tún fún baba wọn ní ọtí mu yó ni alẹ́ ọjọ́ náà, èyí àbúrò náà sì wọlé tọ̀ ọ́ lọ, ó sì bá a lòpọ̀, kò sì tún mọ ìgbà tí ó wọlé sùn ti òun tàbí ìgbà tí ó dìde. Àwọn ọmọbìnrin Lọti méjèèjì sì lóyún fún baba wọn. Èyí ẹ̀gbọ́n sì bí ọmọkùnrin, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Moabu. Òun ni baba ńlá àwọn ará Moabu lónìí. Èyí àbúrò náà sì bí ọmọkùnrin, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Bene-Ami. Òun ni baba ńlá àwọn ará Ammoni lónìí. Abrahamu àti Abimeleki Abrahamu sì kó kúrò níbẹ̀ lọ sí ìhà gúúsù ó sì ń gbé ní agbede-méjì Kadeṣi àti Ṣuri; ó sì gbé ní ìlú Gerari fún ìgbà díẹ̀. Abrahamu sì sọ ní ti Sara aya rẹ̀ níbẹ̀ pé, “Arábìnrin mi ni.” Abimeleki ọba Gerari sì ránṣẹ́ mú Sara wá sí ààfin rẹ̀. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run tọ Abimeleki wá ní ojú àlá lọ́jọ́ kan, ó sì wí fún un pé, “Kíyèsi, kò sí ohun tí o fi sàn ju òkú lọ, nítorí obìnrin tí ìwọ mú sọ́dọ̀ n nì, aya ẹni kan ní íṣe.” Ṣùgbọ́n Abimeleki kò tí ìbá obìnrin náà lòpọ̀, nítorí náà ó wí pé, “Olúwa ìwọ yóò run orílẹ̀-èdè aláìlẹ́bi bí? Ǹjẹ́ òun kò sọ fún mi pé, ‘Arábìnrin mi ni,’ obìnrin náà pẹ̀lú sì sọ pé, ‘Arákùnrin mí ni’? Ní òtítọ́ pẹ̀lú ọkàn mímọ́ àti ọwọ́ mímọ́, ni mo ṣe èyí.” Nígbà náà ni Ọlọ́run wí fún un nínú àlá náà pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, mo mọ̀ pé pẹ̀lú òtítọ́ inú ni ìwọ ṣe èyí, èyí ni mo fi pa ọ́ mọ́ tí ń kò jẹ́ kí o ṣẹ̀ sí mi. Ìdí nìyí tí n kò fi jẹ́ kí o ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú obìnrin náà. Nísinsin yìí, dá aya ọkùnrin náà padà, nítorí pé wòlíì ni, yóò sì gbàdúrà fún ọ, ìwọ yóò sì yè. Ṣùgbọ́n bí ìwọ kò bá dá a padà, mọ̀ dájú pé ìwọ àti gbogbo ẹni tí í ṣe tìrẹ yóò kú.” Ní òwúrọ̀ kùtùkùtù ọjọ́ kejì, Abimeleki pe gbogbo àwọn ìjòyè rẹ̀. Nígbà tí ó sì sọ gbogbo ohun tí ó ṣẹlẹ̀ fún wọn, ẹ̀rù bà wọ́n gidigidi. Nígbà náà ni Abimeleki pe Abrahamu ó sì wí fún un pé, “Èwo ni èyí tí ìwọ ṣe sí wa yìí? Ẹ̀ṣẹ̀ wo ni mo ṣẹ̀ ọ́ tí ìwọ fi mú ìdálẹ́bi ńlá wá sí orí èmi àti ìjọba mi? Kò yẹ kí ìwọ hu irú ìwà yìí sí mi.” Abimeleki sì bi Abrahamu pé, “Kín ló dé tí ìwọ fi ṣe èyí?” Abrahamu sì dáhùn pé, “Mo ṣe èyí nítorí mo rò nínú ara mi pé, ẹ̀yin tí ẹ wà níhìn-ín, ẹ kò bẹ̀rù Ọlọ́run, pé, ẹ sì le pa mí nítorí aya mi. Yàtọ̀ fún ìyẹn, òtítọ́ ni pé arábìnrin mi ni. Ọmọ baba kan ni wá, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, a kì í ṣe ọmọ ìyá kan. Mo sì fẹ́ ẹ ní aya. Nígbà tí Ọlọ́run sì mú mi rìn kiri kúrò ní ilé baba mi, mo wí fún un pé, ‘Èyí ni ọ̀nà tí ó lè gbà fihàn pé ó fẹ́ràn mi. Gbogbo ibi tí a bá dé máa sọ pé, “Arákùnrin rẹ ni mí.” ’ ” Nígbà náà ni Abimeleki mú àgùntàn àti màlúù wá, àti ẹrúkùnrin àti ẹrúbìnrin, ó sì kó wọn fún Abrahamu, ó sì dá Sara aya rẹ̀ padà fún un. Abimeleki sì tún wí fún un pé, “Gbogbo ilẹ̀ mí nìyí níwájú rẹ, máa gbé ní ibikíbi tí o fẹ́ níbẹ̀.” Abimeleki sì wí fún Sara pé, “Mo fi ẹgbẹ̀rún (1,000) owó ẹyọ fàdákà fún arákùnrin rẹ. Èyí ni owó ìtánràn ẹ̀ṣẹ̀ mi sí ọ níwájú gbogbo ẹni tí ó wà pẹ̀lú rẹ àti pé, a dá ọ láre pátápátá.” Nígbà náà, Abrahamu gbàdúrà sí Ọlọ́run, Ọlọ́run sì wo Abimeleki àti aya rẹ̀ àti àwọn ẹrúbìnrin rẹ̀ sàn. Wọ́n sì tún ń bímọ, nítorí Olúwa ti sé gbogbo ará ilé Abimeleki nínú nítorí Sara aya Abrahamu. Ìbí Isaaki Olúwa sì bẹ Sara wò bí ó ti wí, Olúwa sì ṣe fún Sara gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣèlérí. Sara sì lóyún, ó sì bí ọmọkùnrin kan fún Abrahamu ní ọjọ́ ogbó rẹ̀, ní àkókò náà gan an tí Ọlọ́run ti ṣèlérí fún un. Abrahamu sì sọ orúkọ ọmọ náà tí Sara bí fun un ní Isaaki. Nígbà tí Isaaki pé ọmọ ọjọ́ mẹ́jọ, Abrahamu sì kọ ọ́ ní ilà gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ti pàṣẹ fún un. Ẹni ọgọ́rùn-ún ọdún ni Abrahamu nígbà tí ó bí Isaaki. Sara sì wí pé, “Ọlọ́run ti pa mí lẹ́rìn-ín. Gbogbo ẹni tí ó bá sì gbọ́ pé mo bímọ yóò rẹ́rìn-ín pẹ̀lú mi.” Ó sì fi kún un pé, “Ta ni ó le sọ fún Abrahamu pé, Sara yóò di ọlọ́mọ? Síbẹ̀síbẹ̀, mo sì tún bí ọmọ fún Abrahamu ní ìgbà ogbó rẹ.” A lé Hagari àti Iṣmaeli jáde Nígbà tí ọmọ náà dàgbà, ó sì gbà á lẹ́nu ọmú, ní ọjọ́ tí a gba Isaaki lẹ́nu ọmú, Abrahamu ṣe àsè ńlá. Ṣùgbọ́n Sara rí ọmọ Hagari ará Ejibiti tí ó bí fún Abrahamu tí ó fi ṣe ẹlẹ́yà, ó sì wí fún Abrahamu pé, “Lé ẹrúbìnrin yìí àti ọmọ rẹ̀ jáde, nítorí ọmọ ẹrú yìí kò ní bá ọmọ mi Isaaki pín ogún.” Ọ̀rọ̀ náà sì ba Abrahamu lọ́kàn jẹ́ gidigidi nítorí ọmọ rẹ̀ náà sá à ni Iṣmaeli i ṣe. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run wí fun Abrahamu pé, “Má ṣe ba ọkàn jẹ́ nítorí ọmọ náà àti ẹrúbìnrin rẹ. Gbọ́ ohun tí Sara wí fún ọ, nítorí nínú Isaaki ni a ó ti pe irú-ọmọ rẹ̀. Èmi yóò sọ ọmọ ẹrúbìnrin náà di orílẹ̀-èdè pẹ̀lú, nítorí ọmọ rẹ ni.” Abrahamu sì dìde ní kùtùkùtù òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, ó sì mú oúnjẹ àti ìgò omi kan, ó sì kó wọn fún Hagari, ó kó wọn lé e léjìká, ó sì lé e jáde pẹ̀lú ọmọ náà. Ó sì lọ lọ́nà rẹ, ó sì ń ṣe alárìnkiri ní ijù Beerṣeba. Nígbà tí omi inú ìgò náà tan, ó gbé ọmọ náà sí abẹ́ igbó. Ó sì lọ, ó sì jókòó nítòsí ibẹ̀, níwọ̀n bí ìtafà kan, nítorí, ó rò ó nínú ara rẹ̀ pé, “Èmi kò fẹ́ wo bí ọmọ náà yóò ṣe kú.” Bí ó sì ti jókòó sí tòsí ibẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ sí ní sọkún. Ọlọ́run gbọ́ ohun ẹkún náà, Angẹli Ọlọ́run sì pe Hagari láti ọ̀run, ó sì wí fun un pé, “Hagari, kín ni ó ṣe ọ́? Má bẹ̀rù nítorí Ọlọ́run ti gbọ́ ẹkún ọmọ náà níbi tí o tẹ́ ẹ sí. Dìde, gbé ọmọ náà sókè, kí o sì dìímú (tù ú nínú) nítorí èmi yóò sọ ọmọ náà di orílẹ̀-èdè ńlá.” Ọlọ́run sì ṣí ojú Hagari, ó sì rí kànga kan, ó lọ síbẹ̀, ó rọ omi kún inú ìgò náà, ó sì fún ọmọ náà mu. Ọlọ́run sì wà pẹ̀lú ọmọ náà bí ó ti ń dàgbà, ó ń gbé nínú ijù, ó sì di tafàtafà. Nígbà tí ó ń gbé ni aginjù ní Parani, ìyá rẹ̀ fẹ́ ìyàwó fún un láti ilẹ̀ Ejibiti wá. Májẹ̀mú ní Beerṣeba Ní àkókò yìí ni ọba Abimeleki àti Fikoli, olórí ogun rẹ̀ wí fún Abrahamu pé, “Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ̀ nínú gbogbo ohun tí ó ń ṣe. Ǹjẹ́ nísinsin yìí, fi Ọlọ́run búra fún mi, ìwọ kì yóò tàn mí àti àwọn ọmọ mi àti àwọn ìran mi, ìwọ yóò fi inú rere hàn fún mi àti orílẹ̀-èdè tí ìwọ ti ṣe àtìpó, bí mo ti fihàn fún ọ pẹ̀lú.” Abrahamu sì wí pé, “Èmí búra.” Nígbà náà ni Abrahamu fi ẹ̀dùn ọkàn rẹ̀ hàn fún Abimeleki nípa kànga tí àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ gbà lọ́wọ́ rẹ̀. Ṣùgbọ́n Abimeleki dáhùn pé, “Èmi kò mọ ẹni tí ó ṣe nǹkan yìí. Ìwọ kò sì sọ fún mi, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò gbọ́, bí kò ṣe lónìí.” Abrahamu sì mú àgùntàn àti màlúù wá, ó sì kó wọn fún Abimeleki. Àwọn méjèèjì sì dá májẹ̀mú. Abrahamu sì ya abo ọ̀dọ́-àgùntàn méje nínú agbo àgùntàn rẹ̀ sọ́tọ̀. Abimeleki sì béèrè lọ́wọ́ Abrahamu pé, “Kín ni ìtumọ̀ yíyà tí ìwọ ya àwọn ọ̀dọ́-àgùntàn méje wọ̀nyí sọ́tọ̀ sí.” Ó dalóhùn pé, “Gba àwọn abo ọ̀dọ́-àgùntàn méje wọ̀nyí lọ́wọ́ mi gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí pé èmi ni mo gbẹ́ kànga yìí.” Nítorí náà ni a ṣe ń pe ibẹ̀ náà ni Beerṣeba nítorí níbẹ̀ ni àwọn méjèèjì gbé búra. Lẹ́yìn májẹ̀mú tí wọ́n dá ní Beerṣeba yìí, ni Abimeleki àti Fikoli olórí ogun rẹ̀ padà sí ilẹ̀ àwọn ará Filistini. Abrahamu lọ́ igi tamariski kan sí Beerṣeba, níbẹ̀ ni ó sì pe orúkọ Olúwa Ọlọ́run ayérayé. Abrahamu sì gbé ilẹ̀ àwọn ará Filistini fún ọjọ́ pípẹ́. Ọlọ́run dán Abrahamu wò Nígbà tí ó ṣe, Ọlọ́run dán Abrahamu wò, ó pè é, ó sì wí pé, “Abrahamu.” Abrahamu sì dáhùn pé, “Èmi nìyí.” Ọlọ́run sì wí pé, “Mú ọmọ rẹ, àní Isaaki ọmọ rẹ kan ṣoṣo nì, tí ìwọ fẹ́ràn, lọ sí ilẹ̀ Moria, kí o sì fi rú ẹbọ sísun níbẹ̀ lórí ọ̀kan nínú àwọn òkè tí èmi yóò sọ fún ọ.” Abrahamu sì dìde ní kùtùkùtù òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, ó sì di kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ ní gàárì, ó sì mú méjì nínú àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ àti Isaaki ọmọ rẹ̀, ó sì ṣẹ́ igi fún ẹbọ sísun, ó sì gbéra lọ sí ibi tí Ọlọ́run ti sọ fún un. Nígbà tí ó di ọjọ́ kẹta, Abrahamu gbé ojú sókè, ó sì rí ibi tí ó ń lọ ní òkèrè, Abrahamu sì wí fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, “Ẹ̀yin, ẹ dúró níhìn-ín pẹ̀lú kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, èmi àti ọmọ yìí yóò lọ sí ohunkóhun láti sin Ọlọ́run, a ó sì tún padà wá bá a yín.” Abrahamu sì gbé igi ẹbọ sísun náà ru Isaaki, òun fúnra rẹ̀ sì mú iná àti ọ̀bẹ. Bí àwọn méjèèjì ti ń lọ, Isaaki sì sọ fún Abrahamu baba rẹ̀ wí pé, “Baba mi.” Abrahamu sì dalóhùn pé, “Èmi nìyí ọmọ mi.” Isaaki sì tún wí pé, “Wò ó iná àti igi nìyí, ṣùgbọ́n níbo ni ọ̀dọ́-àgùntàn fún ẹbọ sísun náà wà?” Abrahamu sì dáhùn pé, “Ọmọ mi, Ọlọ́run fúnra rẹ̀ ni yóò pèsè ọ̀dọ́-àgùntàn fún ẹbọ sísun náà.” Bẹ́ẹ̀ ni àwọn méjèèjì jùmọ̀ ń lọ. Nígbà tí wọn sì dé ibi tí Ọlọ́run sọ fún Abrahamu, ó mọ pẹpẹ kan, ó sì to igi lé e lórí, ó sì di Isaaki ọmọ rẹ̀, ó sì da dùbúlẹ̀ lórí pẹpẹ náà. Abrahamu sì nawọ́ mú ọ̀bẹ, láti dúńbú ọmọ rẹ̀. Ṣùgbọ́n angẹli Olúwa ké sí i láti ọ̀run wá wí pé “Abrahamu! Abrahamu!” Abrahamu sì dáhùn pé, “Èmi nìyí.” Angẹli Olúwa sì wí pé, “Má ṣe fọwọ́ kan ọmọ náà, ìwọ kò sì gbọdọ̀ ṣe é ni ohun kan. Nísinsin yìí ni mo mọ̀ pé o bẹ̀rù Ọlọ́run, nítorí pé ìwọ kò fi ọmọ rẹ, àní, ọmọ rẹ kan ṣoṣo dù mí.” Abrahamu sì gbójú sókè, ó sì rí àgbò kan tí ó fi ìwo há pàǹtírí, ó sì lọ mú un, ó sì fi rú ẹbọ sísun dípò ọmọ rẹ̀. Abrahamu sì pe orúkọ ibẹ̀ ni, Jehofah Jire.22.14 Jehofah Jire tí ó túmọ̀ sí, Olúwa Yóò Pèsè Bẹ́ẹ̀ ni a sì ń wí títí di òní olónìí pé, “Ní orí òkè Olúwa, ni a ó ti pèsè.” Angẹli Olúwa sì tún pe Abrahamu láti ọ̀run wá lẹ́ẹ̀kejì. Ó sì wí pé, Olúwa wí pé, “Mo fi ara mi búra, níwọ̀n bí ìwọ ti ṣe èyí, tí ìwọ kò fi ọmọ rẹ, àní, ọmọ rẹ kan ṣoṣo dù mí, nítòótọ́, ní bíbùkún èmi ó bùkún fún ọ, àti ní bíbísí èmi ó sì mú ọ bí sí i bí i ìràwọ̀ ojú ọ̀run àti bí iyanrìn etí Òkun. Irú-ọmọ rẹ yóò sì gba ẹnu ibodè àwọn ọ̀tá wọn, àti nípasẹ̀ irú-ọmọ rẹ ni a ó ti bùkún fún gbogbo orílẹ̀-èdè ayé nítorí tí ìwọ gbọ́rọ̀ sí mi lẹ́nu.” Nígbà náà ni Abrahamu padà tọ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ. Gbogbo wọn sì padà lọ sí Beerṣeba. Abrahamu sì jókòó ní Beerṣeba. Àwọn ọmọ Nahori Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí ni a wí fún Abrahamu pé, “Milka aya Nahori bí àwọn ọmọkùnrin fún un. Usi àkọ́bí rẹ̀, Busi arákùnrin rẹ̀, Kemueli (baba Aramu). Kesedi, Haso, Pildasi, Jidlafi, àti Betueli.” Betueli sì ni baba Rebeka. Milka sì bí àwọn ọmọ mẹ́jọ wọ̀nyí fún Nahori arákùnrin Abrahamu. Àlè rẹ̀ tí ń jẹ́ Reuma náà bí àwọn ọmọkùnrin wọ̀nyí fun un: Teba, Gahamu, Tahasi àti Maaka. Ikú Sara Sara sì pé ọmọ ọdún mẹ́tàdínláàádóje (127). Ó sì kú ní Kiriati-Arba (ìyẹn ní Hebroni) ní ilẹ̀ Kenaani, Abrahamu lọ láti ṣọ̀fọ̀ àti láti sọkún nítorí Sara. Abrahamu sì dìde lẹ́gbẹ̀ẹ́ òkú aya rẹ̀, ó sì sọ fún àwọn ará Hiti wí pé, “Èmi jẹ́ àtìpó àti àlejò láàrín yín, ẹ ta ilẹ̀ ìsìnkú fún mi kí èmi le sin òkú tí ó kú fún mi sí.” Àwọn ọmọ Hiti dá Abrahamu lóhùn pé, “Olúwa mi, gbọ́ tiwa, ó jẹ́ alágbára ọmọ-aládé láàrín wa, sin òkú rẹ sí ibojì tí ó dára jù nínú àwọn ibojì wa, kò sí ẹni tí yóò fi ibojì rẹ dù ọ́ láti sin òkú rẹ sí.” Nígbà náà ni Abrahamu dìde, ó sì tẹríba níwájú àwọn ará ilẹ̀ náà, àwọn ará Hiti. Ó sì wí fún wọn pé, “Bí ó bá ṣe pé, lóòótọ́ ni ẹ fẹ́ kí n sin òkú mi kúrò nílẹ̀, ẹ gbọ́ tèmi, ẹ bá mi bẹ Efroni ọmọ Sohari, kí ó ta ihò àpáta Makpela tí ó jẹ́ tirẹ̀ fún mi, èyí tí ó wà ni orí oko rẹ̀, kí ó tà á fún mi ni iye owó tí à ń ta irú rẹ̀ fún ilẹ̀ ìsìnkú láàrín yín.” Efroni ará Hiti sì wà níbẹ̀ pẹ̀lú, ó sì dá Abrahamu lóhùn lójú gbogbo àwọn ará ìlú tí ó wà níbẹ̀, lẹ́nu ibodè ìlú, pé, “Rárá, olúwa mi. Gbọ́ tèmi; mo fún ọ ní ilẹ̀ náà àti ihò àpáta tí ó wà níbẹ̀. Mo fún ọ níwájú gbogbo àwọn ènìyàn mi. Sin òkú rẹ síbẹ̀.” Abrahamu sì tún tẹríba níwájú àwọn ènìyàn ìlú náà, ó sì wí fún Efroni lójú gbogbo wọn pé, “Bí ìwọ bá fẹ́, gbọ́ tèmi, èmi yóò san owó ilẹ̀ náà, gbà á lọ́wọ́ mi kí n lè sin òkú mi síbẹ̀.” Efroni sì dá Abrahamu lóhùn pé, “Gbọ́ tèmi Olúwa mi, irinwó (400) òsùwọ̀n owó fàdákà ni ilẹ̀ náà, ṣùgbọ́n kín ni ìyẹn já mọ láàrín àwa méjèèjì? Sá à sin òkú rẹ.” Abrahamu sì gbọ́ tí Efroni wí, Abrahamu sì wọn iye fàdákà náà fún Efroni, tí ó sọ ní etí àwọn ọmọ Hiti, irinwó (400) òsùwọ̀n ṣékélì fàdákà, tí ó kọjá lọ́dọ̀ àwọn oníṣòwò. Báyìí ni ilẹ̀ Efroni tí ó wà ni Makpela nítòsí Mamre, ilẹ̀ náà àti ihò àpáta tí ó wà nínú rẹ̀ àti gbogbo igi tí ó wà nínú ilẹ̀ náà ni a ṣe ètò rẹ̀ dájú, bí ohun ìní fún Abrahamu níwájú gbogbo ará Hiti tí ó wá sí ẹnu ibodè ìlú náà. Lẹ́yìn náà ni Abrahamu sin aya rẹ̀ Sara sínú ihò àpáta ní ilẹ̀ Makpela nítòsí Mamre (tí í ṣe Hebroni) ní ilẹ̀ Kenaani. Ilẹ̀ náà àti ihò àpáta tí ó wà nínú rẹ̀ ni àwọn ará Hiti fi fún Abrahamu gẹ́gẹ́ bí ohun ìní títí láé, bí ilẹ̀ ìsìnkú fún àwọn òkú tí ó bá kú fun un. Isaaki àti Rebeka Abrahamu sì ti di arúgbó ní àkókò yìí, Olúwa sì ti bùkún fún un ni gbogbo ọ̀nà, Abrahamu wí fún olórí àwọn ìránṣẹ́ ilẹ̀ rẹ̀, tí ó jẹ́ alábojútó ohun gbogbo tí ó ní pé, “Fi ọwọ́ rẹ sí abẹ́ itan mi. Èmi yóò mú ọ búra lórúkọ Olúwa Ọlọ́run ọ̀run àti ayé, pé, ìwọ kì yóò fẹ́ aya fún ọmọ mi nínú àwọn ọmọbìnrin ará Kenaani, láàrín àwọn ẹni tí èmi ń gbé. Ṣùgbọ́n, ìwọ yóò lọ sí orílẹ̀-èdè mi, láàrín àwọn ará mi láti fẹ́ aya fún Isaaki, ọmọ mi.” Ìránṣẹ́ náà bi í wí pé, “Ǹjẹ́ bí ọmọbìnrin náà bá kọ̀ láti bá mi wá sí ilẹ̀ yìí ń kọ́? Ǹjẹ́ mo lè mú ọmọ rẹ padà lọ sí orílẹ̀-èdè níbi tí ìwọ ti wá?” Abrahamu sì wí fún un pé, “Rí i dájú pé ìwọ kò mú ọmọ mi padà lọ sí ibẹ̀.” Olúwa, Ọlọ́run ọ̀run tí ó mú mi jáde láti ilẹ̀ baba mi àti ní ilẹ̀ tí a bí mi, tí ó bá mi sọ̀rọ̀ tí ó sì búra fún mi pé, ‘Irú-ọmọ rẹ ni n ó fi ilẹ̀ yìí fún,’ yóò rán angẹli rẹ̀ ṣáájú rẹ, kí ìwọ kí ó lè rí aya fẹ́ wá fún ọmọ mi láti ibẹ̀. Bí obìnrin náà kò bá fẹ́ tẹ̀lé ọ wá, nígbà náà ni a tú ọ sílẹ̀ kúrò nínú ìbúra yìí, ṣùgbọ́n pàtàkì ni pé ìwọ kò gbọdọ̀ mú ọmọ mi padà lọ sí ibẹ̀.” Ìránṣẹ́ náà sì fi ọwọ́ rẹ̀ sí abẹ́ itan Abrahamu olúwa rẹ̀, ó sì búra fún nítorí ọ̀rọ̀ náà. Ìránṣẹ́ náà sì mú ìbákasẹ mẹ́wàá, pẹ̀lú onírúurú ohun dáradára láti ọ̀dọ̀ olúwa rẹ̀, ó sì dìde ó sì lọ sí Aramu-Naharaimu, sí ìlú Nahori, ó sì mú àwọn ìbákasẹ náà kúnlẹ̀ nítòsí kànga lẹ́yìn ìlú, ó ti ń di ọwọ́ ìrọ̀lẹ́ ní àkókò tí àwọn obìnrin máa ń lọ pọn omi. Ó sì gbàdúrà wí pé, “Olúwa, Ọlọ́run Abrahamu olúwa à mi; jẹ́ kí n ṣe àṣeyọrí lónìí, sì fi àánú hàn fún Abrahamu olúwa mi. Kíyèsi i, mo dúró ní ẹ̀bá kànga omi yìí, àwọn ọmọbìnrin ìlú yìí sì ń jáde wá pọn omi. Jẹ́ kí ó ṣe pé nígbà tí mo bá wí fún ọ̀kan nínú àwọn ọmọbìnrin pe, ‘Jọ̀wọ́ sọ ládugbó rẹ kalẹ̀, kí n le mu omi,’ tí ó bá sì wí pé, ‘Mu ún, èmi ó sì fún àwọn ìbákasẹ rẹ náà mu pẹ̀lú,’ jẹ́ kí ó ṣe èyí tí o yàn fún ìránṣẹ́ rẹ Isaaki. Nípa èyí ni n ó fi mọ̀ pé o ti fi àánú hàn fún olúwa mi.” Kí o tó di pé, ó parí àdúrà, Rebeka dé pẹ̀lú ìkòkò omi rẹ̀ ní èjìká rẹ̀. Ọmọ Betueli ni. Betueli yìí ni Milka bí fún Nahori arákùnrin Abrahamu. Ọmọbìnrin náà rẹwà, wúńdíá ni, kò sì tí ì mọ ọkùnrin, ó lọ sí ibi ìsun omi náà, ó sì pọn omi sínú ìkòkò omi, ó sì gbé e, ó ń gòkè bọ̀ kúrò níbi omi. Ìránṣẹ́ náà súré lọ pàdé rẹ̀, ó sì wí fun un pé, “Jọ̀wọ́ fún mi ni omi díẹ̀ nínú ìkòkò omi rẹ.” Òun náà dáhùn pé, “Mu, olúwa mi,” ó sì yára sọ ìkòkò omi náà ka ọwọ́ rẹ̀, ó sì fún un mu. Lẹ́yìn tí ó ti fún un ni omi mu tán, ó wí pé, “Èmi ó bu omi fún àwọn ìbákasẹ rẹ pẹ̀lú títí wọn yóò fi mu àmutẹ́rùn.” Ó sì yára da omi inú ìkòkò omi rẹ̀ sínú ìbùmu, ó sáré padà lọ sí ibi omi láti pọn sí i wá fún àwọn ìbákasẹ, títí tí ó fi pọn fún gbogbo wọn. Láìsọ ọ̀rọ̀ kan, ìránṣẹ́ yìí ń wo ọmọbìnrin náà fínní fínní láti mọ̀ bóyá Olúwa ti ṣe ìrìnàjò òun ní rere tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́. Lẹ́yìn tí àwọn ìbákasẹ náà ti mu omi tán, ni ọkùnrin náà mú òrùka wúrà ààbọ̀ ìwọ̀n ṣékélì àti júfù méjì fún ọwọ́ rẹ̀, tí ìwọ̀n ṣékélì wúrà mẹ́wàá. Lẹ́yìn náà, ó béèrè pé, “Ọmọ ta ni ìwọ í ṣe? Jọ̀wọ́ wí fún mi, ǹjẹ́ ààyè wà ní ilé baba rẹ láti wọ̀ sí ní alẹ́ yìí?” Ó dáhùn pé, “Betueli ọmọ tí Milka bí fún Nahori ni baba mi.” Ó sì fi kún un pé, “Àwa ní koríko àti ṣakaṣaka tó pẹ̀lú, àti ààyè láti wọ̀ sí.” Nígbà náà ni ọkùnrin náà tẹríba, ó sì sin Olúwa, wí pe, “Olùbùkún ni fún Olúwa, Ọlọ́run Abrahamu olúwa mi ti kò jẹ́ kí àánú àti òtítọ́ rẹ̀ kí ó yẹ̀ lọ́dọ̀ olúwa mi. Ní ti èmi Olúwa ti darí ìrìnàjò mi sí ilé ìbátan olúwa mi.” Ọmọbìnrin náà sì sáré, ó sì lọ sọ ohun gbogbo wọ̀nyí fún àwọn ará ilé ìyá rẹ̀. Rebeka ní arákùnrin tí ń jẹ́ Labani; Labani sì sáré lọ bá ọkùnrin náà ní etí odò. Bí ó sì ti rí òrùka imú àti ẹ̀gbà ní ọwọ́ arábìnrin rẹ̀ tí ó sì tún gbọ́ ohun tí Rebeka sọ pé ọkùnrin náà sọ fún òun, ó jáde lọ bá ọkùnrin náà, ó sì bá a, ó dúró ti ìbákasẹ wọ̀n-ọn-nì ní ẹ̀bá ìsun omi. Ó wí fún ọkùnrin náà pé, “Wá, ìwọ ẹni ìbùkún Olúwa, èéṣe tí o dúró sí ìta níhìn-ín? Mo ti pèsè ààyè sílẹ̀ fún ọ àti ààyè fún àwọn ìbákasẹ rẹ.” Ọkùnrin náà sì bá Labani lọ ilé, ó sì tú ẹrù orí ìbákasẹ rẹ̀ sílẹ̀, ó sì fún wọn ni koríko àti oúnjẹ. Ó sì bu omi fún ọkùnrin náà àti àwọn arákùnrin rẹ̀ láti wẹ ẹsẹ̀ wọn. Wọ́n sì gbé oúnjẹ síwájú rẹ̀, ṣùgbọ́n, ó wí pé, “Èmi kò ní jẹun àyàfi bí mo bá sọ ohun tí mo ní í sọ.” Labani sì wí pé, “Kò burú, sọ ọ́.” Nítorí náà, ó wí pé, “Ìránṣẹ́ Abrahamu ni èmi. Olúwa sì ti bùkún olúwa mi gidigidi. Ó sì ti di ọlọ́rọ̀, Ó sì ti fún un ní àgùntàn, màlúù, àti fàdákà àti wúrà, ìránṣẹ́kùnrin àti ìránṣẹ́bìnrin àti ìbákasẹ àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́. Sara aya olúwa mi sì ti bí ọmọkùnrin kan fún un, ní ìgbà ogbó rẹ̀, olúwa mi sì ti fún ọmọ náà ní ohun gbogbo tí ó ní. Olúwa mi sì ti mú mi búra wí pé, ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ fẹ́ aya fún ọmọ mi, láàrín àwọn ọmọbìnrin Kenaani, ní ilẹ̀ ibi tí èmi ń gbé, ṣùgbọ́n lọ sí ìdílé baba mi láàrín àwọn ìbátan mi kí o sì fẹ́ aya fún ọmọ mi.’ “Mo sì bí olúwa mi léèrè pé, ‘Ǹjẹ́ bí ọmọbìnrin náà kò bá fẹ́ bá mi wá ń kọ́?’ “Ó sì dáhùn wí pé, ‘Olúwa, níwájú ẹni tí èmi ń rìn yóò rán Angẹli rẹ̀ ṣáájú rẹ yóò sì jẹ́ kí o ṣe àṣeyọrí ní ìrìnàjò rẹ, kí ìwọ kí ó ba le fẹ́ aya fún ọmọ mi, láàrín àwọn ìbátan mi, àti láàrín àwọn ìdílé baba mi. Nígbà tí ìwọ bá lọ sí ọ̀dọ̀ ìdílé baba mi (gẹ́gẹ́ bí mo tí wí), nígbà náà ni ìwọ tó bọ́ nínú ìbúra yìí.’ “Nígbà tí mo dé ibi ìsun omi lónìí, mo wí pé, ‘Olúwa Ọlọ́run Abrahamu olúwa mi, bí ìwọ bá fẹ́, jọ̀wọ́ jẹ́ kí n ṣe àṣeyọrí lórí ohun tí mo bá wá yìí. Wò ó, mo dúró ní ẹ̀bá ìsun omi yìí, kí ó ṣe pé, nígbà tí wúńdíá kan bá jáde wá pọn omi, tí èmi sì wí fún un pé, “Jọ̀wọ́ fún mi ní ìwọ̀nba omi díẹ̀ mu nínú ládugbó rẹ,” tí ó bá sì wí fún mi pé, “Mu ún, èmi yóò sì tún pọn omi fún àwọn ìbákasẹ rẹ pẹ̀lú,” jẹ́ kí ẹni náà jẹ́ ẹni tí Olúwa yàn fún ọmọ Abrahamu, olúwa mi.’ “Kí n sì tó gbàdúrà tán nínú ọkàn mi, Rebeka jáde wá pẹ̀lú ìkòkò omi rẹ̀ ní èjìká rẹ̀, ó sì lọ sí ibi ìsun omi ó sì pọn omi. Mo sì wí fun un pé, ‘Jọ̀wọ́ fún mi ni omi mu.’ “Kíákíá ni ó sọ ìkòkò rẹ̀ kalẹ̀ láti èjìká rẹ̀, ó sì wí fún mi pé, ‘Mu ún, èmi yóò sì tún fún àwọn ìbákasẹ rẹ mu pẹ̀lú.’ Mo sì mu, ó sì tún fún àwọn ìbákasẹ mi mu pẹ̀lú. “Mo béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, ‘Ọmọ ta ní ìwọ í ṣe?’ “Ó sì wí fún mi pé, ‘Ọmọbìnrin Betueli tí í ṣe ọmọ Nahori ni òun, Milka sì ni ìyá òun.’ “Nígbà náà ni mo fi òrùka náà bọ imú rẹ̀, mo sì fi ẹ̀gbà ọwọ́ náà si ní ọwọ́. Èmi sì tẹríba, mo sì wólẹ̀ fún Olúwa, mó sì fi ìbùkún fún Ọlọ́run Abrahamu olúwa mi, ẹni tí ó mú mi tọ ọ̀nà títọ́ láti rí ọmọ ọmọ arákùnrin olúwa mi mú wá fún ọmọ rẹ̀. Ǹjẹ́ nísinsin yìí bí ẹ̀yin yóò bá fi inú rere àti òtítọ́ bá olúwa mi lò, ẹ sọ fún mi, bí bẹ́ẹ̀ sì kọ́, ẹ sọ fún mi, kí ń le è mọ ọ̀nà tí èmi yóò yà sí.” Labani àti Betueli sì dáhùn pé, “Lọ́dọ̀ Olúwa ni èyí ti wá, nítorí náà àwa kò le sọ rere tàbí búburú fún ọ. Rebeka nìyí, mú un kí ó máa lọ, kí ó sì di aya ọmọ olúwa à rẹ, bí Olúwa ti fẹ́.” Nígbà tí ọmọ ọ̀dọ̀ Abrahamu gbọ́ ohun tí wọ́n wí, ó wólẹ̀ níwájú Olúwa. Nígbà náà ni ó kó ohun èlò wúrà àti fàdákà jáde àti aṣọ, ó sì fi wọ́n fún Rebeka, ó fún arákùnrin Rebeka àti ìyá rẹ̀ ní ẹ̀bùn olówó iyebíye pẹ̀lú. Lẹ́yìn náà ni òun àti àwọn ọkùnrin tí ó bá a wá tó jẹ, tí wọ́n sì mu, tí wọn sì sùn níbẹ̀ ní òru ọjọ́ náà. Bí wọ́n ti dìde ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, ó wí pé, “Ẹ rán mi padà lọ sí ọ̀dọ̀ olúwa mi.” Ṣùgbọ́n arákùnrin Rebeka àti ìyá rẹ̀ fèsì pé, “A fẹ́ kí Rebeka wà pẹ̀lú wa fún nǹkan bí ọjọ́ mẹ́wàá sí i, lẹ́yìn èyí, ìwọ le máa mu lọ.” Ṣùgbọ́n ó wí fún wọn pé, “Ẹ má ṣe dá mi dúró, Olúwa sá à ti ṣe ọ̀nà mi ní rere. Ẹ rán mi lọ, kí èmi kí ó le è tọ olúwa à mi lọ.” Nígbà náà ni wọ́n sọ pé, “Jẹ́ kí a pe ọmọ náà gan an kí a sì bi í.” Wọ́n sì pe Rebeka wọ́n sì bi í, wí pé, “Ṣe ìwọ yóò bá ọkùnrin yìí lọ.” Ó sì dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, èmi yóò lọ.” Wọ́n sì gbà kí Rebeka àti olùtọ́jú rẹ̀, pẹ̀lú ìránṣẹ́ Abrahamu àti àwọn ọkùnrin tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ máa lọ. Wọ́n sì súre fún Rebeka, wọn sì wí fun un pé, “Ìwọ ni arábìnrin wa ìwọ yóò di ìyá ẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹgbẹ̀rún; ǹjẹ́ kí àwọn irú-ọmọ rẹ kí ó ni ẹnu ibodè ọ̀tá wọn.” Nígbà náà ni Rebeka àti àwọn ìránṣẹ́bìnrin rẹ̀ múra, wọn sì gun àwọn ìbákasẹ, wọ́n sì bá ọkùnrin náà padà lọ. Ìránṣẹ́ náà sì mú Rebeka, ó sì bá tirẹ̀ lọ. Isaaki sì ń ti ọ̀nà kànga Lahai-Roi bọ, nítorí ìhà gúúsù ni ó ń gbé. Isaaki sì jáde lọ sí oko ni ìrọ̀lẹ́ láti ṣe àṣàrò, bí ó sì ti gbé ojú sókè, ó rí àwọn ìbákasẹ tí ń bọ̀ wá. Rebeka pẹ̀lú sì gbójú sókè, ó sì rí Isaaki. Ó sọ̀kalẹ̀ lórí ìbákasẹ, ó sì béèrè lọ́wọ́ ìránṣẹ́ náà wí pé, “Ta ni ọkùnrin tí ń bọ̀ wá pàdé wa láti inú oko?” Ìránṣẹ́ náà sì wí fun un pé, “Olúwa mi ni,” nítorí náà ni Rebeka mú ìbòjú, ó sì bo ojú rẹ̀. Nígbà náà ni ìránṣẹ́ náà ròyìn fún Isaaki ohun gbogbo tí ó ti ṣe. Nígbà náà ni Isaaki mú Rebeka wọ inú àgọ́ ìyá rẹ̀, Sara, ó sì di aya rẹ̀, ó sì fẹ́ràn rẹ̀; ó sì jẹ́ ìtùnú fún Isaaki lẹ́yìn ikú ìyá rẹ̀. Ikú Abrahamu Abrahamu sì tún fẹ́ aya mìíràn, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ketura. Ó sì bí Simrani, Jokṣani, Medani, Midiani, Iṣbaki, àti Ṣua Jokṣani ni baba Ṣeba àti Dedani, àwọn ìran Dedani ni àwọn ara Asṣuri, Letusi àti Leumiti. Àwọn ọmọ Midiani ni Efani, Eferi, Hanoku, Abida àti Eldaa. Gbogbo àwọn wọ̀nyí ni ìran Ketura. Abrahamu sì fi ohun gbogbo tí ó ní fún Isaaki. Ṣùgbọ́n kí Abrahamu tó kú, Abrahamu fún àwọn ọmọ tí àwọn àlè rẹ̀ bí fún un ní ẹ̀bùn, ó sì lé wọn jáde lọ fún Isaaki ọmọ rẹ sí ilẹ̀ ìlà-oòrùn. Gbogbo àpapọ̀ ọdún tí Abrahamu lò láyé jẹ́ igba kan ó dín mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (175). Abrahamu sì kú ní ọjọ́ ogbó rẹ̀. Ó dàgbà, ó darúgbó kí ó tó kú. A sì sin ín sí ibojì àwọn ènìyàn rẹ̀. Àwọn ọmọ rẹ̀, Isaaki àti Iṣmaeli sì sin ín sínú ihò àpáta ni Makpela ní ẹ̀gbẹ́ Mamre, ní oko Efroni ọmọ Sohari ará Hiti, inú oko tí Abrahamu rà lọ́wọ́ ara Hiti yìí ni a sin Abrahamu àti Sara aya rẹ̀ sí. Lẹ́yìn ikú Abrahamu, Ọlọ́run sì bùkún fún Isaaki ọmọ rẹ̀, tí ó ń gbé nítòsí kànga Lahai-Roi ní ìgbà náà. Àwọn ìran Iṣmaeli Wọ̀nyí ni ìran Iṣmaeli, ọmọ Abrahamu ẹni tí Hagari ará Ejibiti, ọmọ ọ̀dọ̀ Sara bí fún un. Wọ̀nyí ni orúkọ àwọn ọmọ Iṣmaeli bí a ṣe bí wọn, bẹ̀rẹ̀ láti orí: Nebaioti àkọ́bí, Kedari, Adbeeli, Mibsamu, Miṣima, Duma, Massa, Hadadi, Tema, Jeturi, Nafiṣi, àti Kedema. Wọ̀nyí sì ni orúkọ àwọn ọmọ Iṣmaeli, wọ̀nyí ni orúkọ àwọn ọba méjìlá gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yà wọn. Àpapọ̀ ọdún tí Iṣmaeli lò láyé jẹ́ ẹ̀tàdínlógóje (137) ọdún, a sì sin ín pẹ̀lú àwọn ènìyàn rẹ̀. Àwọn ìran rẹ̀ sì tẹ̀dó sí agbègbè Hafila títí tí ó fi dé Ṣuri, ní ẹ̀bá ààlà Ejibiti, bí ìwọ ti ń lọ sí ìhà Asiria. Ó sì kú níwájú àwọn arákùnrin rẹ̀ gbogbo. Jakọbu25.19 Jakọbu yí ni a mọ̀ sí Israẹli. àti Esau Wọ̀nyí ni ìtàn ìran Isaaki ọmọ Abrahamu. Abrahamu bí Isaaki. Nígbà tí Isaaki di ọmọ ogójì ọdún ni ó gbé Rebeka ọmọ Betueli ará Aramu ti Padani-Aramu tí í ṣe arábìnrin Labani ará Aramu ní ìyàwó. Isaaki sì gbàdúrà sì Olúwa, nítorí aya rẹ̀ tí ó yàgàn, Olúwa sì gbọ́ àdúrà rẹ̀, Rebeka sì lóyún. Àwọn ọmọ náà ń gbún ara wọn nínú rẹ̀, ó sì wí pé, “Èéṣe tí èyí ń ṣẹlẹ̀ sí mi,” ó sì lọ béèrè lọ́dọ̀ Olúwa. Olúwa sì wí fún un pé, “Orílẹ̀-èdè méjì ni ń bẹ nínú rẹ, irú ènìyàn méjì ni yóò yà láti inú rẹ; àwọn ènìyàn kan yóò jẹ́ alágbára ju èkejì lọ, ẹ̀gbọ́n ni yóò máa sin àbúrò.” Nígbà tí ó tó àkókò fún un láti bímọ, ìbejì ni ó wà nínú rẹ̀, ọkùnrin sì ni wọ́n. Èyí tí ó kọ jáde jẹ́ ọmọ pupa, irun sì bo gbogbo ara rẹ̀ bí aṣọ onírun, nítorí náà, wọ́n pè é ní Esau. Lẹ́yìn èyí ni arákùnrin èkejì jáde wá, ọwọ́ rẹ̀ sì di Esau ni gìgísẹ̀ mú, nítorí náà ni wọn ṣe pe orúkọ rẹ ni Jakọbu. Ọmọ ọgọ́ta ọdún ni Isaaki, nígbà tí Rebeka bí wọn. Àwọn ọmọkùnrin náà sì dàgbà. Esau sì di ọlọ́gbọ́n ọdẹ, ẹni tí ó fẹ́ràn àti máa dúró ní oko. Jakọbu sì jẹ́ ènìyàn jẹ́ẹ́jẹ́ tí ó ń gbé láàrín ìlú. Isaaki, ẹni tí ó fẹ́ràn ẹran igbó fẹ́ràn Esau nítorí ẹran igbó tí Esau máa ń pa, ṣùgbọ́n Rebeka fẹ́ràn Jakọbu. Ní ọjọ́ kan, Jakọbu sì pa ìpẹ̀tẹ̀, Esau sì ti igbó ọdẹ dé, ó sì ti rẹ̀ ẹ́. Esau wí fún Jakọbu pé, “Èmí bẹ̀ ọ, fi ìpẹ̀tẹ̀ rẹ pupa n nì bọ́ mi, nítorí tí ó rẹ̀ mí gidigidi.” (Nítorí náà ni a ṣe ń pe orúkọ rẹ̀ ní Edomu.) Jakọbu dáhùn pé, “Kò burú, ṣùgbọ́n kọ́kọ́ ta ogún ìbí rẹ fún mi ná.” Esau sì dáhùn pé, “Wò ó mo ti fẹ́rẹ kú, àǹfààní kín sì ni ogún ìbí jẹ́ fún mi?” Ṣùgbọ́n, Jakọbu dáhùn pé, “Kọ́kọ́ búra fún mi pé tèmi ni ogún ìbí náà yóò jẹ́.” Báyìí ni Esau búra tí ó sì gbé ogún ìbí rẹ̀ tà fún Jakọbu. Nígbà náà ni Jakọbu fi àkàrà àti ìpẹ̀tẹ̀ lẹntili fún Esau. Ó sì jẹ, ó sì mu, ó sì bá tirẹ̀ lọ. Báyìí ni Esau gan ogún ìbí rẹ̀. Isaaki àti Abimeleki Ìyàn kan sì mú ní ilẹ̀ náà, yàtọ̀ fún èyí tí ó mú ní ìgbà ayé Abrahamu, Isaaki sì lọ sọ́dọ̀ Abimeleki ọba àwọn Filistini ni Gerari. Olúwa sì fi ara han Isaaki, ó sì wí pé, “Má ṣe sọ̀kalẹ̀ lọ sí Ejibiti, jókòó ní ilẹ̀ tí èmi ó fún ọ. Máa ṣe àtìpó ní ilẹ̀ yìí fún ìgbà díẹ̀, èmi ó sì wà pẹ̀lú rẹ, èmi yóò sì bùkún fún ọ. Nítorí ìwọ àti irú-ọmọ rẹ ni èmi yóò fi gbogbo àwọn ilẹ̀ wọ̀nyí fún, èmi yóò sì fi ìdí ìbúra tí mo ṣe fún Abrahamu baba rẹ múlẹ̀. Èmi yóò sọ ìran rẹ di púpọ̀ bí ìràwọ̀ ojú ọ̀run, èmi yóò sì fi gbogbo ilẹ̀ yìí fún irú àwọn ọmọ rẹ, àti nípasẹ̀ irú-ọmọ rẹ ni a ó bùkún fún gbogbo orílẹ̀-èdè ayé, nítorí tí Abrahamu gba ohùn mi gbọ́, ó sì pa gbogbo ìkìlọ̀, àṣẹ, ìlànà àti òfin mi mọ́.” Nítorí náà Isaaki jókòó ní Gerari. Nígbà tí àwọn ọkùnrin ìlú náà bi í léèrè ní ti aya rẹ̀, ó sì wí pé, “Arábìnrin mi ní í ṣe,” nítorí tí ó bẹ̀rù láti jẹ́wọ́ wí pé, “Aya mi ni.” Ó ń rò wí pé, “Kí àwọn ọkùnrin ibẹ̀ náà má ba à pa mí nítorí Rebeka, nítorí tí òun ní ẹwà púpọ̀.” Nígbà tí Isaaki sì ti wà níbẹ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọjọ́, Abimeleki ọba Filistini yọjú lójú fèrèsé, ó sì rí Isaaki ń bá Rebeka aya rẹ̀ tage. Nígbà náà ni Abimeleki ránṣẹ́ pe Isaaki ó sì wí fun pé, “Nítòótọ́, aya rẹ ni obìnrin yìí í ṣe, èéṣe tí ìwọ fi wí fún wa pé arábìnrin mi ni?” Isaaki sì fèsì pé, “Nítorí mo rò pé mo le pàdánù ẹ̀mí mi nítorí rẹ̀.” Nígbà náà ni Abimeleki dáhùn pé, “Èwo ni èyí tí ìwọ ṣe sí wa yìí? Bí ọ̀kan nínú àwọn ènìyàn wọ̀nyí bá ti bá a lòpọ̀ ń kọ́? Ìwọ ìbá wá mú ẹ̀bi wá sórí wa.” Nígbà náà ni Abimeleki pàṣẹ fún gbogbo ènìyàn pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá fọwọ́ kan ọkùnrin yìí tàbí aya rẹ̀ yóò jẹ̀bi ikú.” Ní ọdún náà, Isaaki gbin ohun ọ̀gbìn sí ilẹ̀ náà, ó sì kórè rẹ̀ ní ìlọ́po ọgọ́rùn-ún ọdún ni ọdún kan náà, nítorí Olúwa bùkún un. Ọkùnrin náà sì di ọlọ́rọ̀ púpọ̀, ọrọ̀ rẹ̀ sì ń pọ̀ si, títí ó fi di ènìyàn ńlá. Ó ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹran ọ̀sìn àti agbo ẹran àti àwọn ìránṣẹ́ tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn Filistini ń ṣe ìlara rẹ̀. Nítorí náà àwọn ará Filistini ru erùpẹ̀ di gbogbo kànga tí àwọn ìránṣẹ́ Abrahamu baba rẹ̀ ti gbẹ́. Nígbà náà ni Abimeleki wí fún Isaaki pé, “Jáde kúrò ní ilẹ̀ wa, nítorí tí ìwọ ti di alágbára púpọ̀ jù wá lọ.” Isaaki sì ṣí kúrò níbẹ̀, ó sì pàgọ́ sí àfonífojì Gerari ó sì ń gbé ibẹ̀. Isaaki sì ṣe àtúngbẹ́ àwọn kànga tí Abrahamu baba rẹ̀ ti gbẹ́ nígbà ayé rẹ̀, èyí tí àwọn Filistini ti dí lẹ́yìn ikú Abrahamu baba rẹ̀, ó sì fún wọn lórúkọ tí baba rẹ̀ ti sọ wọ́n tẹ́lẹ̀. Àwọn ìránṣẹ́ Isaaki sì gbẹ́ kànga ní àfonífojì náà, wọ́n kan ìsun omi níbẹ̀. Ṣùgbọ́n àwọn darandaran Gerari ń bá àwọn darandaran Isaaki jà sí kànga náà pé àwọn ni àwọn ni í. Nítorí náà ni ó fi pe orúkọ kànga náà ní Eseki, nítorí pé wọ́n bá a jà sí kànga náà. Àwọn ìránṣẹ́ Isaaki tún gbẹ́ kànga mìíràn, wọ́n sì tún jà nítorí rẹ̀ pẹ̀lú, ó sì sọ orúkọ rẹ̀ ní Sitna. 26.21 tí ó túmọ̀ sí kànga àtakò Ó sì tún kúrò níbẹ̀, ó sì gbẹ́ kànga mìíràn, wọn kò sì jásí èyí rárá, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Rehoboti, ó wí pé, “Nísinsin yìí, Olúwa ti fi ààyè gbà wá, a ó sì gbilẹ̀ si ní ilẹ̀ náà.” Láti ibẹ̀, ó kúrò lọ sí Beerṣeba. Ní òru ọjọ́ tí ó dé ibẹ̀, Olúwa sì fi ara hàn án, ó sì wí pé, “Èmi ni Ọlọ́run Abrahamu baba rẹ. Má ṣe bẹ̀rù nítorí èmi wà pẹ̀lú rẹ, èmi yóò sì bùsi fún ọ, èmi yóò sì sọ iye ìran rẹ di púpọ̀, nítorí Abrahamu ìránṣẹ́ mi.” Isaaki sì kọ́ pẹpẹ kan síbẹ̀, ó sì pe orúkọ Olúwa. Níbẹ̀ ni ó pàgọ́ rẹ̀ sí, àwọn ìránṣẹ́ rẹ sì gbẹ́ kànga kan níbẹ̀. Nígbà náà ni Abimeleki tọ̀ ọ́ wá láti Gerari, àti Ahussati, olùdámọ̀ràn rẹ̀ àti Fikoli, olórí ogun rẹ̀. Isaaki sì bi wọ́n léèrè pé, “Èéṣe tí ẹ̀yin tọ̀ mí wá, níwọ̀n ìgbà tí ẹ̀yin kórìíra mi tí ẹ sì lé mi jáde kúrò lọ́dọ̀ yín?” Wọ́n dáhùn pé, “A rí i dájú pé Olúwa wà pẹ̀lú rẹ, nítorí náà ni a fi rò ó wí pé, ó yẹ kí májẹ̀mú kí o wà láàrín àwa àti ìwọ. Jẹ́ kí a ṣe àdéhùn pé ìwọ kì yóò ṣe wá ní ibi, bí àwa pẹ̀lú kò ti ṣe ọ́ ní aburú, tí a sì ń ṣe ọ́ dáradára, tí a sì rán ọ jáde ní àlàáfíà láìṣe ọ́ ní ibi, kíyèsi Olúwa sì ti bùkún fún ọ.” Isaaki sì ṣe àsè fún wọn, wọn sì jẹ, wọ́n sì mu. Ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì wọn búra fún ara wọn. Isaaki sì rán wọn lọ, wọ́n sì lọ ní àlàáfíà. Ní ọjọ́ náà gan an ni àwọn ìránṣẹ́ Isaaki wá sọ fún un pé àwọn ti kan omi ní kànga kan tí àwọn gbẹ́. Ó sì pe orúkọ kànga náà ní Ṣiba, 26.33 tí ó túmọ̀ sí, kànga májẹ̀mú títí di òní olónìí, orúkọ ìlú náà ni Beerṣeba. Nígbà tí Esau pé ọmọ ogójì ọdún ó fẹ́ ọmọbìnrin kan tí a ń pè ní Juditi, ọmọ Beeri, ará Hiti, ó sì tún fẹ́ Basemati, ọmọ Eloni ará Hiti. Fífẹ́ tí a fẹ́ àwọn obìnrin wọ̀nyí jẹ́ ìbànújẹ́ fún Isaaki àti Rebeka. Isaaki súre fún Jakọbu Nígbà ti Isaaki di arúgbó, ojú rẹ̀ sì ti di bàìbàì tó bẹ́ẹ̀ tí kò le ríran. Ó pe Esau àkọ́bí rẹ̀, ó sì wí fún un pé, “Ọmọ mi.” Esau sì dáhùn pé, “Èmi nìyí.” Isaaki sì wí pé, “Nísinsin yìí mo di arúgbó, èmi kò sì mọ ọjọ́ tí èmi yóò kú. Nítorí náà, mú ohun èlò ọdẹ rẹ, apó àti ọrún, nísinsin yìí kí o sì lọ pa ẹran wá fún mi nínú igbó. Kí o sì ṣe ẹran àdídùn fún mi, irú èyí tí mo fẹ́ràn, kí o gbe wá fún mi kí n jẹ, kí n sì súre fún ọ kí n tó kú.” Ṣùgbọ́n Rebeka ń fetí léko gbọ́ nígbà tí Isaaki ń bá Esau ọmọ rẹ̀ sọ̀rọ̀. Nítorí náà, nígbà ti Esau ti ṣe ọdẹ lọ sínú igbó, Rebeka sọ fún Jakọbu ọmọ rẹ̀ pé, “Wò ó, mo gbọ́ tí baba rẹ ń wí fún Esau ẹ̀gbọ́n rẹ pé, ‘Pa ẹran fún mi wá, kí o sì ṣe oúnjẹ àdídùn fún mi láti jẹ, kí n ba à le súre fún ọ níwájú Olúwa kí èmi tó kú.’ Nísinsin yìí ọmọ mi, gbọ́ tèmi, kí o sì ṣe ohun tí èmi yóò wí fún ọ. Lọ sínú agbo ẹran, kí o sì mú ọmọ ewúrẹ́ méjì, kí ó lè ṣe oúnjẹ àdídùn fún baba rẹ, irú èyí tí ó fẹ́ràn dáradára. Ìwọ yóò sì gbé e tọ baba rẹ lọ, kí òun ba à lè jẹ ẹ́, kí ó sì súre fún ọ, kí ó tó kú.” Jakọbu sì wí fún Rebeka ìyá rẹ̀ pé, “Ṣùgbọ́n Esau ẹ̀gbọ́n mi jẹ́ ènìyàn onírun lára, bẹ́ẹ̀ alára ọ̀bọ̀rọ́ sì ni èmi, bí baba mi bá fọwọ́ kàn mi ń kọ́? Èmi yóò jọ ẹlẹ́tàn lójú rẹ̀, dípò kí ó súre fún mi, èmi yóò sì mú ègún wá sórí ara mi.” Ìyá rẹ̀ wá wí fun un pé, “Ọmọ mi jẹ́ kí ègún náà wá sórí mi, sá à ṣe ohun tí mo wí, kí o sì mú wọn wá fún mi.” Jakọbu sì ṣe ohun gbogbo tí ìyá rẹ̀ wí fun un, Rebeka sì ṣe oúnjẹ àdídùn náà, irú èyí tí Isaaki fẹ́ràn. Nígbà náà ni Rebeka mú èyí tí ó dára jù nínú aṣọ Esau ọmọ rẹ̀ àgbà tí ó wà nínú ilé Rebeka, ó sì fi wọ Jakọbu ọmọ rẹ̀ àbúrò. Ó sì fi awọ ewúrẹ́ wọ̀n-ọn-nì bo ọwọ́ àti ibi tí ọ̀bọ̀rọ́ ọrùn. Nígbà náà ni ó gbé ẹran dídùn náà àti oúnjẹ tí ó ti sè lé Jakọbu ọmọ rẹ̀ lọ́wọ́. Jakọbu wọlé lọ sí ọ̀dọ̀ baba rẹ̀ ó sì wí pé, “Baba mi.” Baba rẹ sì dáhùn pé, “Èmi nìyí, ìwọ ta ni, ọmọ mi?” Jakọbu sì fèsì pé, “Èmi ni Esau àkọ́bí rẹ, èmi ti ṣe gẹ́gẹ́ bí ìwọ ti sọ fún mi, jọ̀wọ́ dìde jókòó, kí o sì jẹ nínú ẹran igbó mi tí mo ti sè, kí o ba à le súre fún mi pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ.” Isaaki tún béèrè pé, “Ọmọ mi, báwo ni ó ṣe tètè yá ọ bẹ́ẹ̀?” Jakọbu sì tún dáhùn pé, “Olúwa Ọlọ́run rẹ ló fún mi pa.” Nígbà náà ni Isaaki wí fún Jakọbu pé, “Súnmọ́ mi, kí n le è fọwọ́ kàn ọ́, kí n lè mọ̀ bóyá Esau ọmọ mi ni nítòótọ́ tàbí òun kọ́.” Jakọbu sì súnmọ́ Isaaki baba rẹ̀. Isaaki sì fọwọ́ kàn án, ó sì wí pé, “Ohùn ni ohùn Jakọbu; ṣùgbọ́n ọwọ́ ni ọwọ́ Esau.” Kò sì dá Jakọbu mọ̀ nítorí ọwọ́ rẹ̀ ní irun bí i ti Esau arákùnrin rẹ, nítorí náà, ó súre fún un ó sì bi í léèrè pé, “Ǹjẹ́ ìwọ ni Esau ọmọ mi ni tòótọ́?” Jakọbu sì dáhùn pé, “Èmi ni.” Nígbà náà ni Isaaki wí pé, “Gbé ẹran igbó náà súnmọ́ ọ̀dọ̀ mi, kí èmi kí ó jẹ ẹ́, kí èmi sì súre fún ọ láti inú ọkàn mi wá.” Jakọbu sì gbé e wá ó sì jẹ ẹ́, ó sì tún fún un ní wáìnì, ó sì mú un pẹ̀lú. Nígbà náà ni Isaaki baba rẹ̀ wí fun un pé, “Súnmọ́ mi, ọmọ mi, kí o sì fẹnukò mí ní ẹnu.” Ó sì súnmọ́ ọn, ó sì fẹnukò ó ní ẹnu. Nígbà tí Isaaki gbọ́ òórùn aṣọ rẹ̀, ó súre fún un ó wí pé, “Wò ó òórùn ọmọ mi dàbí òórùn oko Olúwa ti bùkún. Kí Ọlọ́run kí ó fún ọ nínú ìrì ọ̀run àti nínú ọ̀rá ilẹ̀ àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọkà àti wáìnì tuntun. Kí àwọn orílẹ̀-èdè kí ó máa sìn ọ́, kí àwọn ènìyàn sì máa tẹríba fún ọ, máa ṣe olórí àwọn arákùnrin rẹ, kí àwọn iyèkan rẹ sì máa wólẹ̀ fún ọ Fífibú ni àwọn ẹni tó fi ọ́ bú, ìbùkún ni fún àwọn ẹni tí ó súre fún ọ.” Bí Isaaki ti súre tán tí Jakọbu ṣẹ̀ṣẹ̀ jáde kúrò ní ọ̀dọ̀ baba rẹ̀ ni Esau ti oko ọdẹ dé. Òun pẹ̀lú ṣe ẹran dídùn, ó sì gbé e tọ baba rẹ̀ wá, ó sì wí fún un pé, “Baba mi, dìde jókòó, kí o sì jẹ nínú ẹran igbó tí mo ti ṣè, kí o sì súre fún mi.” Isaaki baba rẹ̀ sì bi í wí pé, “Ìwọ ta ni?” Ó sì dáhùn pé, “Èmi Esau, àkọ́bí rẹ ni.” Nígbà náà ni Isaaki wárìrì gidigidi, ó sì wí pé, “Ta ni ẹni náà, tí ó ti pa ẹran igbó tí ó sì ti gbe wá fún mi, tí mo sì ti jẹ ẹ́ kí ó tó dé? Mo sì ti súre fún un, sì wò ó dájúdájú a ó sì bùkún un!” Nígbà tí Esau gbọ́ ọ̀rọ̀ baba rẹ̀, ó ké, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ní sọkún kíkorò, ó sì wí fún baba rẹ̀ pé, “Baba mi súre fún èmi náà, àní fún èmi náà pẹ̀lú.” Ṣùgbọ́n Isaaki wí pé, “Àbúrò rẹ ti fi ẹ̀tàn wá, ó sì ti gba ìbùkún rẹ lọ.” Esau sì wí pé, “Lásán ni a pe orúkọ rẹ̀ ní Jakọbu27.36 Jakọbu tí ó túmọ̀ sí, Ajinnilẹ́sẹ̀ bí? Ní ìgbà méjì yìí ni ó ti tàn mí jẹ: ní àkọ́kọ́, ó gba ogún ìbí mi, nísinsin yìí, ó tún gba ìbùkún mi!” O sì béèrè pé, “Ṣe o kò wá fi ìre kankan sílẹ̀ fun mi ni?” Isaaki sì dá Esau lóhùn pé, “Mo ti fi ṣe olórí rẹ àti àwọn ìbátan rẹ ni mo fi ṣe ìránṣẹ́ fún un, àti ọkà àti wáìnì ni mo ti fi lé e lọ́wọ́ lọ́pọ̀lọ́pọ̀, kí ni ó tún kù tí ǹ bá tún fún ọ báyìí ọmọ mi?” Esau sì wí fún baba rẹ̀ pé, “Ṣe ìre kan ṣoṣo ni ìwọ ní lẹ́nu ni baba mi? Súre fún èmi náà, baba mi.” Esau sì sọkún kíkankíkan. Isaaki baba rẹ̀ sì dá a lóhùn pé, “Ibùjókòó rẹ yóò jìnnà sí ọ̀rá ilẹ̀, àti sí ibi ìrì ọ̀run láti òkè wá. Nípa idà rẹ ni ìwọ yóò máa gbé, ìwọ yóò sì máa sin àbúrò rẹ, ṣùgbọ́n ní ìkẹyìn, nígbà tí ìwọ bá di alágbára ìwọ yóò já àjàgà rẹ̀ kúrò lọ́rùn rẹ.” Jakọbu sálọ sí ọ̀dọ̀ Labani Esau sì kórìíra Jakọbu nítorí ìre tí baba rẹ̀ sú fún un, ó sì wí fún ara rẹ̀ pé, “Baba mi sá à ti fẹ́rẹ kú, nígbà náà ni èmi ó pa Jakọbu, arákùnrin mi.” Nígbà tí Rebeka sì gbọ́ ohun tí Esau àkọ́bí rẹ̀ wí, ó sì ránṣẹ́ sí Jakọbu, ó sì wí fun un pé, “Esau ẹ̀gbọ́n rẹ ń tu ara rẹ̀ nínú pẹ̀lú èrò à ti pa ọ́. Nítorí náà ọmọ mi, ṣe ohun tí èmi yóò sọ fún ọ, sálọ sọ́dọ̀ Labani ẹ̀gbọ́n mi ní Harani. Jókòó sí ibẹ̀ títí di ìgbà tí ìbínú ẹ̀gbọ́n rẹ yóò fi rọ̀. Nígbà tí ẹ̀gbọ́n rẹ kò bá bínú sí ọ mọ́, tí ó sì ti gbàgbé ohun tí ìwọ ṣe sí i, èmí ó ránṣẹ́ sí ọ láti padà wá. Èéṣe tí èmi ó fi pàdánù ẹ̀yin méjèèjì ní ọjọ́ kan náà?” Nígbà náà ni Rebeka wí fún Isaaki pé, “Ayé sì sú mi nítorí àwọn ọmọbìnrin Hiti wọ̀nyí. Bí Jakọbu bá fẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ọmọbìnrin Hiti wọ̀nyí, ó kúkú sàn kí n má wà láààyè.” Nítorí náà Isaaki pe Jakọbu, ó sì súre fún un, ó sì pàṣẹ fún un pé, “Ìwọ kò gbọdọ̀ fẹ́ aya láàrín àwọn ọmọbìnrin Kenaani. Dípò bẹ́ẹ̀ lọ sí Padani-Aramu, sí ilé Betueli, baba ìyá rẹ, kí ìwọ kí ó sì fẹ́ aya fún ara rẹ nínú àwọn ọmọbìnrin Labani arákùnrin ìyá rẹ. Kí Ọlọ́run Olódùmarè El-Ṣaddai kí ó bùkún fún ọ, kí ó sì mú ọ bí sí i, kí ó sì mú ọ pọ̀ sí i ní iye títí tí ìwọ yóò di àgbájọ àwọn ènìyàn. Kí Ọlọ́run kí ó fún ìwọ àti irú-ọmọ rẹ ní ìre tí ó sú fún Abrahamu, kí ìwọ kí ó le gba ilẹ̀ níbi tí a ti ń ṣe àtìpó yìí, ilẹ̀ tí Ọlọ́run ti fi fún Abrahamu.” Bẹ́ẹ̀ ni Isaaki sì rán Jakọbu lọ. Ó sì lọ sí Padani-Aramu, lọ́dọ̀ Labani ọmọ Betueli, ará Aramu, tí í ṣe arákùnrin Rebeka ìyá Jakọbu àti Esau. Nígbà tí Esau gbọ́ pé, Isaaki ti súre fún Jakọbu, ó sì ti rán Jakọbu lọ sí Padani-Aramu láti fẹ́ aya níbẹ̀ àti pé nígbà tí ó súre fún un, ó kìlọ̀ fun un pé, kò gbọdọ̀ fẹ́ nínú àwọn ọmọbìnrin Kenaani àti pé, Jakọbu ti gbọ́rọ̀ sí ìyá àti baba rẹ̀ lẹ́nu, ó sì ti lọ sí Padani-Aramu. Nígbà náà ni Esau mọ bí Isaaki baba rẹ ti kórìíra àwọn ọmọbìnrin Kenaani tó. Nítorí náà Esau tọ Iṣmaeli lọ, ó sì fẹ́ Mahalati, arábìnrin Nebaioti, ọmọbìnrin Iṣmaeli tí í ṣe ọmọ Abrahamu. Ó fẹ́ ẹ, kún àwọn ìyàwó tí ó ti ní tẹ́lẹ̀. Àlá Jakọbu ní Beteli Jakọbu kúrò ní Beerṣeba, ó sì kọrí sí ìlú Harani. Nígbà tí ó dé ibìkan, ó dúró ní òru náà nítorí tí ilẹ̀ ti ń ṣú, ó sì gbé òkúta kan ó fi ṣe ìrọ̀rí, ó sì sùn. Ó sì lá àlá pé, a gbé àkàsọ̀ kan dúró ti ó fi ìdí lélẹ̀, orí rẹ̀ sì kan ọ̀run, àwọn angẹli Ọlọ́run sì ń gòkè, wọ́n sì ń sọ̀kalẹ̀ lórí rẹ̀. Olúwa sì dúró lókè rẹ̀, ó sì wí pé, “Èmi ni Olúwa, Ọlọ́run baba rẹ Abrahamu àti Ọlọ́run Isaaki, ìwọ àti ìran rẹ ni èmi yóò fi ilẹ̀ tí ìwọ dùbúlẹ̀ sórí rẹ̀ yìí fún. Ìran rẹ yóò pọ̀ bí erùpẹ̀ ilẹ̀, ìwọ yóò sì tànkálẹ̀ dé ìlà-oòrùn àti ìwọ̀-oòrùn, àti dé gúúsù àti àríwá. A ó sì bùkún gbogbo orílẹ̀-èdè ayé nípasẹ̀ ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ. Èmi wà pẹ̀lú rẹ, èmi yóò sì pa ọ mọ́ ní ibikíbi tí ìwọ bá lọ, èmi yóò sì mú ọ padà wá sí ilẹ̀ yìí ní àlàáfíà. Èmi kì yóò fi ọ sílẹ̀ ní ìgbà kan, títí tí èmi yóò fi mú gbogbo ìlérí mi ṣẹ.” Nígbà tí Jakọbu jí lójú oorun rẹ̀, ó rò nínú ara rẹ̀ pé, “Dájúdájú Olúwa ń bẹ ní ìhín yìí, èmi kò sì mọ̀.” Ẹ̀rù sì bà á, ó sì wí pé, “Ìhín yìí ní ẹ̀rù gidigidi; ibí kì í ṣe ibòmíràn bí kò ṣe ilé Ọlọ́run, àní ẹnu ibodè ọ̀run nìyìí.” Jakọbu sì dìde ní kùtùkùtù òwúrọ̀, ó sì gbé òkúta tí ó fi ṣe ìrọ̀rí lélẹ̀ bí ọ̀wọ́n, ó sì da òróró si lórí. Ó sì pe orúkọ ibẹ̀ ní Beteli, 28.19 tí ó túmọ̀ sí, Ilé Ọlọ́run bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìlú náà ń jẹ́ Lusi tẹ́lẹ̀ rí. Jakọbu sì jẹ́ ẹ̀jẹ́ níbẹ̀ pé, “Bí Ọlọ́run yóò bá wà pẹ̀lú mi, tí yóò sì pa mí mọ́ ní ìrìnàjò mi tí mo ń lọ, tí yóò sì fún mi ní oúnjẹ láti jẹ àti aṣọ láti wọ̀, tí mo sì padà sílé baba mi ní àlàáfíà, nígbà náà Olúwa ni yóò jẹ́ Ọlọ́run mi, Òkúta yìí tí mo gbé kalẹ̀ bí ọ̀wọ́n yóò jẹ́ ilé Ọlọ́run, nínú gbogbo ohun tí ìwọ ó fi fún mi, èmi yóò sì fi ìdámẹ́wàá rẹ̀ fún ọ.” Jakọbu dé Padani-Aramu Jakọbu sì tẹ̀síwájú nínú ìrìnàjò rẹ̀, ó sì dé ilẹ̀ àwọn ará ìlà-oòrùn. Ó sì rí kànga kan ní pápá, agbo àgùntàn mẹ́ta sì dúró láti mu omi ní ibi kànga náà, nítorí pé láti inú kànga náà ni wọ́n ti ń fi omi fún agbo àgùntàn. Òkúta tí a gbé dí ẹnu kànga náà sì tóbi gidigidi. Nígbà tí gbogbo agbo ẹran bá péjọpọ̀ sí ibẹ̀ tán ni àwọn darandaran yóò tó yí òkúta náà kúrò, tí wọn yóò sì fún àwọn ẹran náà ní omi, tí wọ́n bá sì ti ṣe bẹ́ẹ̀ tán, wọn yóò tún yí òkúta náà padà sí ẹnu kànga náà. Jakọbu béèrè lọ́wọ́ àwọn darandaran náà pé, “Ẹ̀yin arákùnrin mi níbo ni ẹ̀yin ti wá?” Àwọn náà sì dáhùn pé, “Láti Harani ni.” Ó sì bi wọ́n pé, “Ǹjẹ́ ẹ mọ Labani ọmọ ọmọ Nahori?” Wọ́n sì dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, àwa mọ̀ ọ́n.” Jakọbu béèrè pé, “Ṣe àlàáfíà ni ó wà?” Wọ́n sì dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, àlàáfíà ni. Wò ó, Rakeli ọmọ rẹ̀ ni ó ń bọ̀ yìí pẹ̀lú agbo àgùntàn.” Ó sì wí pé, “Kíyèsi, ilẹ̀ ò tí ì ṣú, kò tì í tó àkókò fún àwọn ohun ọ̀sìn láti wọ̀. Ẹ fún àwọn ẹran wọ̀nyí ní omi, kí ẹ ba à le tètè dà wọ́n padà láti jẹun.” Wọ́n dá a lóhùn pé, “Àwa kì í yí òkúta kúrò ní ẹnu kànga láti pọn omi fún àwọn ẹran títí gbogbo àwọn darandaran àti àwọn ẹran yóò fi péjọ tán.” Bí wọ́n sì ti ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́ ni Rakeli dé pẹ̀lú agbo àgùntàn baba rẹ̀, nítorí darandaran ni òun náà. Nígbà tí Jakọbu rí Rakeli ọmọbìnrin Labani tí í ṣe ẹ̀gbọ́n ìyá rẹ̀, pẹ̀lú àgùntàn Labani, Jakọbu súnmọ́ kànga náà, ó sì yí òkúta kúrò lẹ́nu rẹ̀, ó sì fún àwọn ẹran arákùnrin ìyá rẹ̀ Labani ní omi. Jakọbu sì fẹnu ko Rakeli ní ẹnu. Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í sọkún. Jakọbu sì wí fún Rakeli pé ìbátan baba rẹ̀ ni òun, àti pé, òun jẹ́ ọmọ Rebeka. Rakeli sì sáré lọ sọ fún baba rẹ̀. Ní kété tí Labani gbúròó Jakọbu ọmọ arábìnrin rẹ̀, ó jáde lọ pàdé Jakọbu, ó dì mọ́ ọn, ó fi ẹnu kò ó ní ẹnu, ó sì mú un lọ sí ilé. Nígbà náà ni Jakọbu ròyìn ohun gbogbo fún un. Labani sì wí pé, “Ẹran-ara àti ẹ̀jẹ̀ ara mi ni ìwọ jẹ́.” Jakọbu fẹ́ àwọn ọmọ Labani Lea àti Rakeli Lẹ́yìn tí Jakọbu sì wà pẹ̀lú rẹ̀ fún odidi oṣù kan, Labani wí fún Jakọbu pé, “Bí a tilẹ̀ jẹ́ ìbátan, kò yẹ kí o máa ṣiṣẹ́ fún mi lásán láìgba ohun kankan. Sọ ohun tì ìwọ fẹ́ gbà fún iṣẹ́ tí ìwọ ń ṣe fún mi!” Wàyí o, Labani ní ọmọbìnrin méjì, orúkọ èyí ẹ̀gbọ́n ń jẹ́ Lea, orúkọ àbúrò sì ń jẹ́ Rakeli. Lea kò ní ẹwà púpọ̀, ṣùgbọ́n Rakeli ní ẹwà gidigidi. Ojú rẹ̀ sì fanimọ́ra. Jakọbu sì fẹ́ràn Rakeli, ó sì wí fún baba rẹ̀ pé, “Èmi yóò ṣiṣẹ́ sìn ọ fún ọdún méje, bí ìwọ yóò bá fún mi ní Rakeli ọmọ rẹ ní aya.” Labani sì dáhùn wí pé, “Ó kúkú sàn kí ń fi fún ọ, ju kí ń fi fún ẹlòmíràn lọ, nítorí náà wà ní ọ̀dọ̀ mi.” Jakọbu sì ṣiṣẹ́ sin Labani fún ọdún méje láti fẹ́ Rakeli. Àwọn ọdún wọ̀nyí sì dàbí ọjọ́ díẹ̀ lára rẹ̀, nítorí ó fẹ́ràn rẹ̀. Jakọbu sì wí fún Labani pé, “Mo ti parí àsìkò tí a jọ ṣe àdéhùn rẹ̀, nítorí náà fún mi ní aya mi, kí òun lè ṣe aya fún mi.” Labani sì pe gbogbo ènìyàn ibẹ̀ jọ, ó sì ṣe àsè ìyàwó fún wọ́n. Ṣùgbọ́n nígbà tí ó di òru, Labani mú Lea tọ Jakọbu lọ. Jakọbu sì bá a lòpọ̀. Labani sì fi Silipa ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ obìnrin fún Lea gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́. Sì kíyèsi, nígbà ti ilẹ̀ mọ́, Jakọbu rí i pé Lea ni! Ó sì wí fún Labani pé, “Èwo ni ìwọ ṣe sí mi yìí? Ṣe bí nítorí Rakeli ni mo ṣe ṣiṣẹ́ sìn ọ, èéṣe tí ìwọ tàn mi?” Labani sì dáhùn pé, “Kò bá àṣà wa mu láti fi àbúrò fún ọkọ ṣáájú ẹ̀gbọ́n rẹ̀. Mú sùúrù parí ọ̀sẹ̀ ìgbéyàwó yìí náà, nígbà náà ni èmi yóò fi àbúrò rẹ̀ fún ọ pẹ̀lú, bí ìwọ ó bá ṣiṣẹ́ sìn mi fún ọdún méje mìíràn.” Jakọbu sì gbà láti sin Labani fún ọdún méje mìíràn. Labani sì fi Rakeli ọmọ rẹ̀ fún un bí aya. Labani sì fi Biliha ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ obìnrin fún Rakeli bí ìránṣẹ́. Jakọbu sì bá Rakeli náà lòpọ̀. Ó sì fẹ́ràn Rakeli ju Lea lọ, ó sì ṣiṣẹ́ sin Labani fún ọdún méje mìíràn. Àwọn ọmọ Jakọbu Nígbà tí Olúwa sì ri pé, Jakọbu kò fẹ́ràn Lea, ó ṣí i ni inú ṣùgbọ́n Rakeli yàgàn. Lea sì lóyún, ó sì bí ọmọkùnrin kan, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Reubeni, nítorí ó wí pé, “Nítorí Olúwa ti mọ ìpọ́njú mi, dájúdájú, ọkọ mi yóò fẹ́ràn mi báyìí.” Ó sì tún lóyún, ó bí ọmọkùnrin kan. Ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Simeoni, wí pé, “Nítorí tí Olúwa ti gbọ́ pé a kò fẹ́ràn mi, ó sì fi èyí fún mi pẹ̀lú.” Ó sì tún lóyún, ó bí ọmọkùnrin kan, ó sì wí pé, “Nígbà yìí ni ọkọ mi yóò fi ara mọ́ mi, nítorí tí mo ti bí ọmọkùnrin mẹ́ta fún un,” nítorí náà ni ó ṣe pe orúkọ rẹ̀ ní Lefi. Ó sì tún lóyún, ó sì tún jẹ́ pé ọmọkùnrin ni ó bí, ó sì wí pé, “Nígbà yìí ni èmi yóò yin Olúwa.” Ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Juda. Ó sì dáwọ́ ọmọ bíbí dúró. Nígbà tí Rakeli rí i pe òun kò bímọ, ó bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ìlara sí Lea, arábìnrin rẹ̀, ó sì wí fún Jakọbu pé, “Fún mi lọ́mọ, bí kò ṣe bẹ́ẹ̀, èmi ó kú!” Inú sì bí Jakọbu sí i, ó sì wí pé, “Èmi ha wà ní ipò Ọlọ́run, ẹni tí ó mú ọ yàgàn bí?” Nígbà náà ni Rakeli wí pé, “Biliha ìránṣẹ́bìnrin mi nìyìí, bá a lòpọ̀, kí ó ba à le bí ọmọ fún mi, kí èmi si le è tipasẹ̀ rẹ̀ ní ọmọ.” Báyìí ni Rakeli fi Biliha fún Jakọbu ní aya, ó sì bá a lòpọ̀. Biliha sì lóyún, ó sì bí ọmọkùnrin kan fún Jakọbu. Rakeli sì wí pé, “Ọlọ́run ti ṣe ìdájọ́ mi; ó sì ti gbọ́ ohùn ẹ̀bẹ̀ mi, ó sì fún mi ni ọmọkùnrin kan.” Nítorí ìdí èyí ni ó ṣe pe orúkọ rẹ̀ ní Dani. Biliha, ọmọ ọ̀dọ̀ Rakeli sì tún lóyún, ó sì bí ọmọkùnrin kejì fún Jakọbu. Nígbà náà ni Rakeli wí pé, “Mo ti bá ẹ̀gbọ́n mi ja ìjàkadì ńlá, èmi sì ti borí.” Ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Naftali. Nígbà tí Lea sì ri pé òun ko tún lóyún mọ́, ó sì fi ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ obìnrin, Silipa fún Jakọbu bí aya. Silipa ọmọ ọ̀dọ̀ Lea sì bí ọmọkùnrin kan fún Jakọbu. Nígbà náà ni Lea wí pé, “Orí rere ni èyí!” Ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Gadi. Silipa ọmọ ọ̀dọ̀ Lea sì tún bí ọmọkùnrin kejì fún Jakọbu. Nígbà náà ni Lea wí pé, “Mo ní ayọ̀ gidigidi! Àwọn ọmọbìnrin yóò sì máa pe mí ní Alábùkún fún.” Ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Aṣeri. Ní ọjọ́ kan, ní àkókò ìkórè ọkà jéró, Reubeni jáde lọ sí oko, ó sì rí èso mándrákì, ó sì mú un tọ Lea ìyá rẹ̀ wá. Rakeli sì wí fún Lea pé, “Jọ̀wọ́ fún mi ní ara èso mándrákì tí ọmọ rẹ mú wá.” Ṣùgbọ́n Lea dalóhùn pé, “Ọkọ mi tí o gbà kò tó kọ́? Ṣe ìwọ yóò tún gba èso mándrákì ọmọ mi pẹ̀lú?” Rakeli sì dáhùn pé, “Ó dára, yóò sùn tì ọ́ lálẹ́ yìí nítorí èso mándrákì ọmọ rẹ.” Nítorí náà, nígbà tí Jakọbu ti oko dé ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ náà, Lea jáde lọ pàdé rẹ̀, ó sì wí pé, “O ní láti sun ọ̀dọ̀ mi ní alẹ́ yìí nítorí mo ti fi èso mándrákì tí ọmọ mi wá bẹ̀ ọ́ lọ́wẹ̀.” Nítorí náà ni Jakọbu sùn tì í ní alẹ́ ọjọ́ náà. Ọlọ́run sì gbọ́ ti Lea, ó sì lóyún, ó sì bí ọmọkùnrin karùn-ún fún Jakọbu. Nígbà náà ni Lea wí pé, “Ọlọ́run ti sẹ̀san ọmọ ọ̀dọ̀ mi ti mo fi fún ọkọ mi fún mi,” ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Isakari. Lea sì tún lóyún, ó sì bí ọmọkùnrin kẹfà fún Jakọbu. Nígbà náà ni Lea tún wí pé “Ọlọ́run ti fún mi ní ẹ̀bùn iyebíye, nígbà yìí ni ọkọ mi yóò máa bu ọlá fún mi.” Nítorí náà ni ó ṣe pe orúkọ rẹ̀ ni Sebuluni. Lẹ́yìn èyí, ó sì bí ọmọbìnrin kan, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Dina. Nígbà náà ni Ọlọ́run rántí Rakeli, Ọlọ́run sì gbọ́ tirẹ̀, ó sì ṣí i ní inú. Ó lóyún, ó sì bí ọmọkùnrin kan ó sì wí pé, “Ọlọ́run ti mú ẹ̀gàn mi kúrò.” Ó sì pe orúkọ rẹ̀ ni Josẹfu, ó sì wí pé, “Ǹjẹ́ kí Olúwa kí ó fi ọmọkùnrin mìíràn kún un fún mi.” Agbo ẹran Jakọbu pọ̀ sí i Lẹ́yìn tí Rakeli ti bí Josẹfu, Jakọbu wí fún Labani pé, “Jẹ́ kí èmi máa lọ sí ilẹ̀ mi tí mo ti wá. Kó àwọn ọmọ àti ìyàwó mi fún mi, àwọn ẹni tí mo ti torí wọn sìn ọ́. Ki èmi lè máa bá ọ̀nà mi lọ. O sá à mọ bí mo ti ṣiṣẹ́ sìn ọ́ tó.” Ṣùgbọ́n Labani wí fún un pé, “Bí o bá ṣe pé mo rí ojúrere rẹ, jọ̀wọ́ dúró, nítorí, mo ti ṣe àyẹ̀wò rẹ, mo sì rí i pé Olúwa bùkún mi nítorí rẹ. Sọ ohun tí o fẹ́ gẹ́gẹ́ bí owó iṣẹ́ ẹ̀ rẹ, èmi yóò sì san án.” Jakọbu sì wí fún un pé, “Ìwọ sá à mọ bí mo ti ṣiṣẹ́ sìn ọ́ àti bí ẹran ọ̀sìn rẹ ti pọ̀ si lábẹ́ ìtọ́jú mi. Ìwọ̀nba díẹ̀ sá à ni o ní kí èmi tó dé, ó sì ti pọ̀ sí i gidigidi, Olúwa sì ti bùkún ọ nínú gbogbo èyí tí mo ṣe. Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, nígbà wo ní èmi yóò pèsè fún ìdílé tèmi.” Ó sì tún béèrè wí pé, “Kín ni kí èmi ó fi fún ọ?” Jakọbu dáhùn pé, “Má fun mi ni ohunkóhun, ṣùgbọ́n bí ìwọ yóò bá ṣe ohun tí mo fẹ́ sọ yìí, èmi yóò sì máa bá ọ tọ́jú àwọn agbo ẹran rẹ, èmi yóò sì máa bọ́ wọn. Jẹ́ kí èmi kí ó la agbo ẹran kọjá ní òní, èmi yóò sì mú gbogbo àgùntàn onílà àti èyí tí ó ní àmì, àti gbogbo àgbò dúdú pẹ̀lú ewúrẹ́ onílà tàbí tí ó ní àmì. Àwọn wọ̀nyí ni yóò dúró fún owó iṣẹ́ mi. Òtítọ́ inú mi yóò sì jẹ́rìí fún mi ní ọjọ́ iwájú nígbà tí ìwọ bá wo owó iṣẹ́ mi tí ìwọ san fún mi, yóò sì ṣe pé gbogbo èyí tí kì í bá ṣe onílà tàbí alámì nínú ewúrẹ́ tàbí tí kì í ṣe dúdú nínú àgùntàn, tí o bá rí ni ọ̀dọ̀ mi ni kí o kà sí mi lọ́rùn pé jíjí ni mo jí gbé.” Labani sì dáhùn pé, “Mo fi ara mọ́ ọn, ṣe bí ìwọ ti wí.” Ní ọjọ́ náà gan an ni Labani kó gbogbo ewúrẹ́ tí ó ní àmì tàbí ilà (àti òbúkọ àti abo, tí ó ní funfun díẹ̀ lára), pẹ̀lú gbogbo àgùntàn dúdú, ó sì fi wọ́n sí ìtọ́jú àwọn ọmọ rẹ̀. Ibi tí Labani àti Jakọbu sì wà sí ara wọn, sì tó ìrìn ọjọ́ mẹ́ta. Jakọbu sì ń tọ́jú agbo ẹran Labani tí ó kù. Nígbà náà ni Jakọbu gé ọ̀pá tẹ́ẹ́rẹ́ tútù kan lára igi Poplari, àti igi almondi àti igi Pileeni. Ó sì bó èèpo kúrò ní ibi kọ̀ọ̀kan lára igi náà láti fún igi náà ní àwọ̀ ju ẹyọ kan lọ. Ó sì mú àwọn ọ̀pá wọ̀nyí tì sí ọ̀ọ́kán agbada omi níbi tí àwọn ẹran ti lè rí i nígbà tí wọ́n bá wá mu omi. Tí àwọn ẹran bá sì ń gùn, níwájú àwọn ọ̀pá náà, wọn sì bí àwọn ẹran onílà àti alámì, àwọn tí ó ní tótòtó lára. Nígbà náà ni ó ya àwọn abo ẹran kúrò nínú agbo ẹran Labani, ó sì yà wọ́n sọ́tọ̀ kúrò lára àgbò, ó sì mú kí wọn máa gùn pẹ̀lú àwọn àgbò Jakọbu dúdú nìkan, bẹ́ẹ̀ ni ó kó agbo ẹran jọ fún ara rẹ̀ láti ara agbo ẹran Labani. Nígbàkígbà tí àwọn ẹran tí ó lera bá ń gùn, Jakọbu yóò fi àwọn ọ̀pá wọ̀nyí lélẹ̀ níwájú wọn, ní ibi tí wọn ti ń mu omi. Ṣùgbọ́n tí ó bá jẹ́ wí pé wọn kò lera, kò ní fi àwọn ọ̀pá náà lélẹ̀. Nítorí náà, àwọn tí kò lera ń jẹ́ ti Labani, nígbà tí àwọn tí ó lera ń jẹ́ ti Jakọbu. Nítorí ìdí èyí, Jakọbu di ọlọ́rọ̀ gidigidi, agbo ẹran rẹ̀ pọ̀ àti àwọn ìránṣẹ́kùnrin, ìránṣẹ́bìnrin pẹ̀lú ìbákasẹ àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́. Jakọbu sá kúrò lọ́dọ̀ Labani Jakọbu sì gbọ́ pé àwọn ọmọ Labani ń wí pé, “Jakọbu ti gba gbogbo ohun ìní baba wa, ó sì ti kó ọrọ̀ jọ fún ara rẹ̀ lára àwọn ohun tí í ṣe ti baba wa.” Jakọbu sì ṣàkíyèsí pé ìwà Labani sí òun ti yí padà sí ti àtẹ̀yìnwá. Nígbà náà ni Olúwa wí fún Jakọbu pé, “Padà lọ sí ilẹ̀ àwọn baba à rẹ, sí ọ̀dọ̀ àwọn ará rẹ, èmi ó sì wà pẹ̀lú rẹ.” Jakọbu sì ránṣẹ́ pe Rakeli àti Lea sí pápá níbi tí àwọn ohun ọ̀sìn rẹ̀ wà. Ó sì wí fún wọn pé, “Mo rí i wí pé ìwà baba yín sí mi ti yí padà sí ti tẹ́lẹ̀, ṣùgbọ́n Ọlọ́run baba mi wà pẹ̀lú mi. Ẹ sá à mọ̀ pé, mo ti fi gbogbo agbára mi ṣiṣẹ́ fún baba yín, síbẹ̀síbẹ̀ baba yín ti rẹ́ mi jẹ ní ẹ̀ẹ̀mẹwàá ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni ó sì ti yí owó iṣẹ́ mi padà. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run kò jẹ́ kí ó le è pa mi lára. Tí ó bá wí pé, ‘Àwọn ẹran onílà ni yóò dúró fún owó iṣẹ́ rẹ,’ nígbà náà ni gbogbo àwọn ẹran ń bí onílà; bí ó bá sì wí pé, ‘Àwọn ẹran onítótòtó ni yóò dúró fún owó iṣẹ́ rẹ,’ nígbà náà ni gbogbo ẹran ń bi onítótòtó. Bẹ́ẹ̀ ni Ọlọ́run gba ẹran baba yín, ó sì fi fún mi. “Ní àsìkò tí àwọn ẹran ń gùn, mo la àlá mo sì ri pé àwọn òbúkọ tí wọ́n ń gun àwọn ẹran jẹ́ onítótòtó, onílà àti alámì. Angẹli Ọlọ́run wí fún mi nínú àlá náà pé, ‘Jakọbu.’ Mo sì wí pé, ‘Èmi nìyí.’ Ó sì wí pé, ‘Gbé ojú rẹ sókè kí o sì wò ó, gbogbo àwọn òbúkọ tí ó ń gun àwọn ẹran jẹ́ onítótòtó, onílà àti alámì, nítorí mo ti rí gbogbo ohun ti Labani ń ṣe sí ọ. Èmi ni Ọlọ́run Beteli, níbi tí ìwọ ti ta òróró sí ọ̀wọ́n, ìwọ sì jẹ́ ẹ̀jẹ́ láti sìn mi. Nísinsin yìí, kúrò ní ilẹ̀ yìí kíákíá kí o sì padà sí ilẹ̀ ibi tí a gbé ti bí ọ.’ ” Nígbà náà ni Rakeli àti Lea dáhùn pé, “Ìpín wo ní a ní nínú ogún baba wa? Àjèjì ha kọ́ ni ó kà wá sí? Kì í ṣe torí pé ó tà wá nìkan, ṣùgbọ́n ó ti ná gbogbo owó tí ó gbà lórí wa tán. Dájúdájú gbogbo ọrọ̀ ti Ọlọ́run gbà lọ́wọ́ baba wa fún ọ, tiwa àti ti àwọn ọmọ wa ní í ṣe. Nítorí náà ohun gbogbo tí Ọlọ́run bá pàṣẹ fun ọ láti ṣe ni kí ìwọ kí ó ṣe.” Nígbà náà ni Jakọbu gbé àwọn ọmọ àti aya rẹ̀ gun ìbákasẹ. Ó sì da gbogbo agbo ẹran rẹ̀ ṣáájú pẹ̀lú gbogbo ọrọ̀ tí ó ti kójọ ni Padani-Aramu, láti lọ sí ọ̀dọ̀ Isaaki baba rẹ̀ ni ilẹ̀ Kenaani. Nígbà tí Labani sì lọ láti rẹ́run àgùntàn, Rakeli sì jí àwọn ère òrìṣà ilé baba rẹ̀. Síwájú sí i, Jakọbu tan Labani ará Aramu, nítorí kò sọ fún un wí pé òun ń sálọ. Ó sì sálọ pẹ̀lú ohun gbogbo tí ó ni, ó sì la odò kọjá (Eufurate), ó sì kọrí sí àwọn ilẹ̀ olókè ti Gileadi. Labani lépa Jakọbu Ní ọjọ́ kẹta ni Labani gbọ́ pé Jakọbu ti sálọ. Ó sì mú àwọn arákùnrin rẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀, ó sì lépa Jakọbu, ó sì lépa wọn fún ọjọ́ méje, ó sì bá wọn ní òkè Gileadi. Ọlọ́run sì yọ sí Labani ará Aramu lójú àlá ní òru, ó sì wí fun un pé, “Ṣọ́ra, má ṣe sọ ohunkóhun fún Jakọbu, ìbá à ṣe rere tàbí búburú.” Jakọbu ti pa àgọ́ rẹ̀ si orí òkè kan, nígbà tí Labani bá a. Labani àti àwọn tí ó wá pẹ̀lú rẹ̀ sì pàgọ́ tì wọ́n sí ilẹ̀ òkè Gileadi. Nígbà náà ni Labani wí fún Jakọbu pé, “Èwo ni ìwọ ṣe yìí? Tí ìwọ sì tàn mi, ó sì kó àwọn ọmọbìnrin mi bi ìgbèkùn tí a fi idà mú. Èéṣe tí ìwọ yọ́ lọ tí ìwọ sì tàn mi? Kí ló dé tí ìwọ kò sọ fún mi pé ìwọ ń lọ, kí èmi fi ayọ̀ àti orin, pẹ̀lú ìlù àti ohun èlò orin sìn ọ́. Ìwọ kò tilẹ̀ jẹ́ kí èmi fi ẹnu ko àwọn ọmọ ọmọ mi lẹ́nu, pẹ̀lú àwọn ọmọbìnrin mi pé ó dìgbà? Ìwọ ṣiwèrè ní ohun tí ìwọ ṣe yìí. Mo ní agbára láti ṣe ọ ni ibi, ṣùgbọ́n ní òru àná, Ọlọ́run baba rẹ sọ fún mi pé, kí èmi ṣọ́ra, kí èmi má ṣe sọ ohun kan fún Jakọbu, ìbá à ṣe rere tàbí búburú. Nísinsin yìí, ìwọ ti lọ nítorí ìwọ fẹ́ láti padà lọ sí ilé baba rẹ, ṣùgbọ́n èéṣe tí ìwọ fi jí àwọn òrìṣà mi?” Jakọbu dá Labani lóhùn pé, “Ẹ̀rù ni ó bà mi nítorí, mo rò pé ìwọ le fi tipátipá gba àwọn ọmọbìnrin rẹ lọ́wọ́ mi. Ṣùgbọ́n bí o bá ri ẹnikẹ́ni pẹ̀lú ère rẹ, kí ẹni náà di òkú. Ó tún wí pé, níwájú gbogbo ìbátan wa báyìí, wò ó fúnra rẹ̀, bí o bá rí ohunkóhun tí í ṣe tìrẹ, mú un.” Jakọbu kò sì mọ̀ pé, Rakeli ni ó jí àwọn òrìṣà náà. Labani sì lọ sínú àgọ́ Jakọbu àti ti Lea àti ti àwọn ìránṣẹ́bìnrin méjèèjì, kò sì rí ohunkóhun. Lẹ́yìn ìgbà tí ó jáde nínú àgọ́ Lea ni ó lọ sí àgọ́ Rakeli. Rakeli sì gbé àwọn òrìṣà náà sínú gàárì ìbákasẹ, ó sì jókòó lé e lórí. Labani sì wá gbogbo inú àgọ́, kò sì rí ohunkóhun. Rakeli sì wí fún baba rẹ̀ pé, “Má ṣe bínú pé èmi ò le dìde dúró níwájú rẹ baba à mi, ohun tí ó fà á ni pé, mò ń ṣe nǹkan oṣù lọ́wọ́.” Ó sì wá àgọ́ kiri, kò sì rí àwọn òrìṣà ìdílé náà. Inú sì bí Jakọbu, ó sì pe Labani ní ìjà pé, “Kí ni ẹ̀ṣẹ̀ mi? Ẹ̀ṣẹ̀ wo ni mo ṣẹ̀ ọ tí ìwọ fi ń lépa mi bí ọ̀daràn? Nísinsin yìí tí ìwọ ti tú gbogbo ẹrù mi wò, kí ni ohun tí í ṣe tirẹ̀ tí ìwọ rí? Kó wọn kalẹ̀ báyìí níwájú gbogbo ìbátan rẹ àti tèmi, kí wọn kí ó sì ṣe ìdájọ́ láàrín àwa méjèèjì. “Mo ti wà lọ́dọ̀ rẹ fún ogún ọdún, àwọn àgùntàn tàbí ewúrẹ́ rẹ kò sọnù bẹ́ẹ̀ n kò pa ọ̀kan jẹ rí nínú àwọn àgbò rẹ. Èmi kò mú ọ̀kankan wá fún ọ rí nínú èyí tí ẹranko búburú fàya, èmi ni ó fi ara mọ́ irú àdánù bẹ́ẹ̀. Ẹrankẹ́ran tí wọ́n bá sì jí lọ, lọ́sàn án tàbí lóru, ìwọ ń gba owó rẹ̀ lọ́wọ́ mi. Báyìí ni mo wà; oòrùn ń pa mi lọ́sàn án, òtútù ń pa mi lóru, mo sì ń ṣe àìsùn. Báyìí ni ohun gbogbo rí fún ogún ọdún tí mo fi wà nínú ilé rẹ. Ọdún mẹ́rìnlá ni mo fi sìn ọ́ fún àwọn ọmọbìnrin rẹ méjèèjì, mo sì sìn ọ fún ọdún mẹ́fà fún àwọn ẹran ọ̀sìn, lẹ́ẹ̀mẹ́wàá ni o sì yí owó iṣẹ́ mi padà. Bí ó bá ṣe pé Ọlọ́run àwọn baba mi, Ọlọ́run Abrahamu àti ẹ̀rù Isaaki kò wà pẹ̀lú mi ni, ìwọ ìbá ti lé mi jáde lọ́wọ́ òfo. Ṣùgbọ́n, Ọlọ́run ti rí gbogbo ìpọ́njú mi àti iṣẹ́ àṣekára tí mo fi ọwọ́ mi ṣe, ó sì kìlọ̀ fún ọ lóru àná.” Labani sì dá Jakọbu lóhùn, “Tèmi ni àwọn obìnrin wọ̀nyí, ọmọ mi ni àwọn ọmọ wọ̀nyí pẹ̀lú, àwọn agbo ẹran yìí, tèmi ni wọ́n pẹ̀lú. Gbogbo ohun tí o rí wọ̀nyí, tèmi ni. Kí ni mo wá le ṣe sí àwọn ọmọbìnrin wọ̀nyí àti àwọn ọmọ wọn tí wọn bí? Wá, jẹ́ kí a dá májẹ̀mú pẹ̀lú ara wa, èyí yóò sì jẹ́ ẹ̀rí ní àárín wa.” Jakọbu sì mú òkúta kan ó sì gbé e dúró bí ọ̀wọ́n. Ó sì wí fún àwọn ìbátan rẹ̀ pé, “Ẹ kó àwọn òkúta díẹ̀ jọ.” Wọ́n sì kó òkúta náà jọ bí òkìtì wọ́n sì jẹun níbẹ̀. Labani sì pe orúkọ rẹ̀ ní Jegari-Sahaduta, ṣùgbọ́n Jakọbu pè é ni Galeedi. Labani sì wí pé, “Òkìtì yìí jẹ́ ẹ̀rí láàrín èmi àti ìwọ ní òní.” Ìdí nìyí tí a fi pe orúkọ rẹ̀ ni Galeedi. Ó tún pè é ni Mispa nítorí, ó wí pé, “Kí Olúwa kí ó máa ṣọ́ èmi àti ìwọ nígbà tí a bá yà kúrò lọ́dọ̀ ara wa tán. Bí o bá fìyà jẹ àwọn ọmọbìnrin mi, tàbí tí o fẹ́ aya mìíràn yàtọ̀ sí wọn, rántí pé, Ọlọ́run ń bẹ láàrín wa bí ẹlẹ́rìí bí ẹnikẹ́ni kò tilẹ̀ sí.” Labani tún sọ síwájú fún Jakọbu pé, “Òkìtì àti ọ̀wọ̀n tí mo gbé kalẹ̀ láàrín èmi àti ìwọ yìí, yóò jẹ́ ẹ̀rí wí pé èmi kò ni ré ọ̀wọ̀n àti òkìtì yìí kọjá láti bá ọ jà àti pé ìwọ pẹ̀lú kì yóò kọjá òkìtì tàbí ọ̀wọ̀n yìí láti ṣe mí ní ibi. Ǹjẹ́ kí Ọlọ́run Abrahamu àti Ọlọ́run Nahori, àti Ọlọ́run baba wọn ṣe ìdájọ́ láàrín wa.” Jakọbu sì fi ẹ̀rù Isaaki baba rẹ̀ búra. Jakọbu sì rú ẹbọ níbẹ̀ ni orí òkè, ó sì pe àwọn ẹbí rẹ̀ láti jẹun. Lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n ti jẹun, ibẹ̀ náà ni wọ́n sùn ní ọjọ́ náà. Ní kùtùkùtù òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, Labani fi ẹnu ko àwọn ọmọ ọmọ rẹ̀ lẹ́nu àti àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ pẹ̀lú, ó sì súre fún wọn. Labani sì padà lọ sí ilé. Jakọbu gbáradì láti pàdé Esau Jakọbu sì ń bá ọ̀nà tirẹ̀ lọ, àwọn angẹli Ọlọ́run sì pàdé rẹ̀. Nígbà tí Jakọbu rí wọn, ó wí pé, “Àgọ́ Ọlọ́run ni èyí!” Ó sì pe orúkọ ibẹ̀ ni Mahanaimu. Jakọbu sì rán àwọn oníṣẹ́ ṣáájú ara rẹ̀ sí Esau arákùnrin rẹ̀ ni ilẹ̀ Seiri ní orílẹ̀-èdè Edomu. Ó pàṣẹ fún wọn pé, “Èyí ni ẹ̀yin yóò wí fún Esau olúwa mi, Jakọbu ìránṣẹ́ rẹ̀ wí pé, ‘Mo ti ṣe àtìpó lọ́dọ̀ Labani títí ó fi di àsìkò yìí. Mo ní màlúù, kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, àgùntàn àti ewúrẹ́. Mo tún ni àwọn ìránṣẹ́kùnrin àti ìránṣẹ́bìnrin. Mo ń ránṣẹ́ yìí sí olúwa mi kí èmi le è rí ojúrere rẹ.’ ” Nígbà tí àwọn ìránṣẹ́ náà padà tọ Jakọbu wà, wọ́n wí pé “Esau arákùnrin rẹ ti múra láti wá pàdé rẹ pẹ̀lú irinwó (400) ọkùnrin.” Pẹ̀lú ìbẹ̀rù àti ìbànújẹ́ ni Jakọbu fi pín àwọn ènìyàn tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ sí ìpín méjì, ó sì pín àwọn ẹran ọ̀sìn, agbo ẹran àti ìbákasẹ bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú. Nítorí ó rò ó nínú rẹ̀ pé, “Bí Esau bá kọjú ogun sí ìpín kan, ìpín kejì yóò sá àsálà.” Nígbà náà ni Jakọbu gbàdúrà pe, “Ọlọ́run Abrahamu baba mi, àti Ọlọ́run Isaaki baba mi, Olúwa tí ó wí fún mi pé, ‘Padà sí orílẹ̀-èdè rẹ àti sọ́dọ̀ àwọn ìbátan rẹ, èmi yóò sì ṣe ọ́ ní rere,’ èmi kò tilẹ̀ yẹ fún àánú àti òtítọ́ tí o ń fihàn fún ìránṣẹ́ rẹ. Nítorí pé, kìkì ọ̀pá mi ni mo mu kúrò ni ilé kọjá Jordani yìí, ṣùgbọ́n nísinsin yìí, èmi ti di ẹgbẹ́ méjì. Jọ̀wọ́ Olúwa gbà mí lọ́wọ́ Esau arákùnrin mi, nítorí ẹ̀rù ń bà mí pé yóò wá dojú ìjà kọ mí àti àwọn ìyàwó pẹ̀lú àwọn ọmọ mi. Ṣùgbọ́n ìwọ ti ṣèlérí pé, ‘Èmi yóò mú ọ gbilẹ̀, èmi yóò sì mú kí àwọn ìran rẹ dà bì í yanrìn òkun tí ẹnikẹ́ni kò le è kà.’ ” Ó sì lo òru ọjọ́ náà níbẹ̀. Ó mú ẹ̀bùn fún Esau arákùnrin rẹ̀ nínú ohun ìní rẹ̀. Igba ewúrẹ́, ogún òbúkọ, igba àgùntàn, ogún àgbò, ọgbọ̀n abo ìbákasẹ pẹ̀lú ọmọ wọn, ogójì abo màlúù àti akọ màlúù mẹ́wàá, ogún abo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ àti akọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ mẹ́wàá. Ó sì fi wọ́n lé àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́ ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́, ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ lọ ṣáájú mi, kí ẹ sì jẹ́ kí àlàfo wà láàrín ọ̀wọ́ agbo ẹran kọ̀ọ̀kan sí èkejì.” Ó pàṣẹ fún èyí tí ó ṣáájú pé, “Nígbà tí arákùnrin mi Esau bá pàdé rẹ tí ó sì béèrè ẹni tí ìwọ í ṣe àti ibi tí ìwọ ń lọ àti ẹni tí ó ni agbo ẹran tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ, nígbà náà ni ìwọ yóò wí pé, ‘Ti ìránṣẹ́ rẹ Jakọbu ni wọ́n. Ẹ̀bùn ni ó sì fi wọ́n ṣe fún Esau olúwa mi, òun pàápàá ń bọ̀ lẹ́yìn wa.’ ” Jakọbu sì pàṣẹ bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ fún ọ̀wọ́ kejì àti ẹ̀kẹta àti àwọn tókù tí ó tẹ̀lé agbo ẹran pé, “Ohun kan ṣoṣo yìí náà ni kí ẹ sọ fún Esau nígbà tí ẹ bá pàdé rẹ̀. Kí ẹ rí i dájú wí pé, ẹ sọ fún un pé, ‘Jakọbu ìránṣẹ́ rẹ̀ ń bọ̀ lẹ́yìn wa.’ ” Èrò Jakọbu ni láti fi àwọn ẹ̀bùn wọ̀nyí tu Esau lójú pé bóyá inú Esau yóò dùn sí òun nígbà tí àwọn bá pàdé. Nítorí náà ẹ̀bùn Jakọbu ṣáájú rẹ̀ lọ, Jakọbu pàápàá sì lo òru ọjọ́ náà nínú àgọ́. Jakọbu bá Ọlọ́run ja ìjàkadì Ó sì dìde ní òru ọjọ́ náà, ó mú àwọn aya rẹ̀ méjèèjì, àwọn ìránṣẹ́bìnrin rẹ̀ méjèèjì, àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ mọ́kọ̀ọ̀kànlá, wọ́n sì kọjá ní ìwọdò Jabbok. Lẹ́yìn ìgbà tí ó ti rán wọn kọjá odò tán sí òkè odò, ó sì rán àwọn ohun ìní rẹ̀ kọjá pẹ̀lú. Ó sì ku Jakọbu nìkan, ọkùnrin kan sì bá a ja ìjàkadì títí ó fi di àfẹ̀mọ́júmọ́. Ṣùgbọ́n nígbà tí ọkùnrin náà rí i pé òun kò le borí Jakọbu, ó fọwọ́ kàn án ní ọ̀ọ́kán ibi tí eegun itan ti bẹ̀rẹ̀, egungun náà sì yẹ̀ kúrò lórí ike, bí ó ti ń ja ìjàkadì. Nígbà náà ni ọkùnrin náà wí fún un pé, “Jẹ́ kí ń máa lọ, nítorí ojúmọ́ ti mọ́.” Ṣùgbọ́n Jakọbu dá a lóhùn pé, “Èmi kò ní jẹ́ kí o lọ, àyàfi bí o bá súre fún mi.” Ọkùnrin náà béèrè orúkọ rẹ̀. Ó sì wí fún un pé, “Jakọbu ni òun ń jẹ́.” Nígbà náà ni ọkùnrin náà wí pé, “Orúkọ rẹ kì yóò jẹ́ Jakọbu mọ́ bí kò ṣe Israẹli, nítorí pé ìwọ ti bá Ọlọ́run àti ènìyàn jà, o sì borí.” Jakọbu sì bẹ ọkùnrin náà pé, “Sọ orúkọ rẹ fún mi.” Ṣùgbọ́n ọkùnrin náà sá à dáhùn pé, “Èéṣe tí o ń béèrè orúkọ mi?” Lẹ́yìn náà ó súre fún Jakọbu níbẹ̀. Jakọbu sì pe orúkọ ibẹ̀ ní Penieli pé, “Mo rí Ọlọ́run ní ojúkojú, síbẹ̀ a dá ẹ̀mí mi sí.” Bí ó sì ti ń kọjá Penieli, oòrùn ràn bá a, ó sì ń tiro nítorí itan rẹ̀. Ìdí nìyí tí àwọn ọmọ Israẹli kì í fi í jẹ iṣan tí ó wà ní ọ̀ọ́kán ibi tí eegun itan ti bẹ̀rẹ̀ títí di òní olónìí, nítorí níbi iṣan náà ni a ti fọwọ́ kan ibi tí egungun itan Jakọbu ti bẹ̀rẹ̀. Jakọbu àti Esau pàdé Jakọbu sì gbójú sókè, ó sì rí Esau àti irinwó (400) ọkùnrin tí wọ́n ń bọ̀, ó sì pín àwọn ọmọ fún Lea, Rakeli àti àwọn ìránṣẹ́bìnrin méjèèjì. Ó sì ti àwọn ìránṣẹ́bìnrin àti àwọn ọmọ wọn síwájú, Lea àti àwọn ọmọ rẹ̀ sì jẹ ọ̀wọ́ kejì tí ó tẹ̀lé wọn, Rakeli àti Josẹfu sì wà lẹ́yìn pátápátá. Jakọbu fúnra rẹ̀ wa lọ síwájú pátápátá, ó sì tẹríba ní ìgbà méje bí ó ti ń súnmọ́ Esau, arákùnrin rẹ̀. Ṣùgbọ́n Esau sáré pàdé Jakọbu, ó sì dì mọ́ ọn, ó rọ̀ mọ́ ọn lọ́rùn, ó sì fẹnukò ó lẹ́nu. Àwọn méjèèjì sì sọkún. Nígbà tí Esau sì ṣe àkíyèsí àwọn ìyàwó àti ọmọ Jakọbu, ó béèrè lọ́wọ́ Jakọbu pé, “Ti ta ni àwọn wọ̀nyí?” Jakọbu sì fèsì wí pé, “Èyí ni àwọn ọmọ tí Ọlọ́run nínú àánú rẹ̀ ti fi fún ìránṣẹ́ rẹ.” Nígbà náà ni àwọn ìránṣẹ́bìnrin àti àwọn ọmọ wọn súnmọ́ tòsí, wọ́n sì tẹríba. Lẹ́yìn náà ni Lea àti àwọn ọmọ rẹ̀ pẹ̀lú dé, wọ́n sì tún tẹríba. Ní ìkẹyìn ni Josẹfu àti Rakeli dé, wọ́n sì tún tẹríba pẹ̀lú. Esau sì béèrè pé, “Kí ni èrò rẹ tí o fi to àwọn ọ̀wọ̀ọ̀wọ́ tí mo pàdé wọ̀nyí?” Jakọbu dáhùn pé, “Kí n ba le rí ojúrere rẹ ni olúwa mi.” Ṣùgbọ́n Esau wí pé, “Tèmi ti tó mi, pa èyí tí o ní mọ́ fún ara rẹ.” Jakọbu bẹ̀ ẹ́ wí pé, “Rárá bẹ́ẹ̀ kọ́, bí ó bá ṣe pé, mo rí ojúrere rẹ, jọ̀wọ́ gba ọrẹ lọ́wọ́ mi. Bí mo ṣe rí ojú rẹ̀ yìí, ó dàbí wí pé mo rí ojú Ọlọ́run ni báyìí, tí inú rẹ̀ ti dùn sí mi. Jọ̀wọ́ gba àwọn ohun tí mo mú wá wọ̀nyí lọ́wọ́ mi. Nítorí Ọlọ́run ti fi oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀ hàn sí mi, gbogbo ohun tí mo fẹ́ sì ni mo ní.” Nígbà tí Jakọbu sì rọ̀ ọ́ pé Esau gbọdọ̀ gbà wọ́n, Esau sì gbà á. Nígbà náà ni Esau wí pé, “Jẹ́ kí a máa lọ, n ó sìn ọ.” Ṣùgbọ́n Jakọbu wí fún un pé, “Ṣe ìwọ náà ṣe àkíyèsí pé ọ̀pọ̀ nínú àwọn ọmọ wọ̀nyí kéré, àwọn màlúù àti àgùntàn pẹ̀lú sì ní àwọn ọmọ kéékèèké. Bí a bá dà wọ́n rìn jìnnà ju bí agbára wọn ṣe mọ lọ, wọ́n lè kú. Èmi bẹ̀ ọ́, máa lọ síwájú ìránṣẹ́ rẹ, àwọn ó sì máa rọra bọ̀, títí èmi àti àwọn ọmọ yóò fi dé ọ̀dọ̀ olúwa mi ní Seiri.” Esau wí pé, “Jẹ́ kí n fi díẹ̀ sílẹ̀ fún ọ nínú àwọn ọkùnrin mi nígbà náà.” Jakọbu wí pé, “Èéṣe, àní kí n sá à rí ojúrere olúwa mi?” Ní ọjọ́ náà gan an ni Esau padà lọ sí Seiri. Jakọbu sì lọ sí Sukkoti, ó sì kọ́ ilé fún ara rẹ̀, ó sì ṣe ọgbà fún àwọn ẹran. Ìdí èyí ní a fi ń pe ibẹ̀ ní Sukkoti. Lẹ́yìn ìgbà tí Jakọbu tí Padani-Aramu dé, àlàáfíà ni Jakọbu dé ìlú Ṣekemu ní ilẹ̀ Kenaani, ó sì pàgọ́ sí itòsí ìlú náà. Ó sì ra ilẹ̀ kan tí ó pàgọ́ sí ni ọgọ́rùn-ún owó fàdákà lọ́wọ́ àwọn ọmọ Hamori tí í ṣe baba Ṣekemu. Níbẹ̀ ni ó gbé tẹ́ pẹpẹ kan tí ó pè ní El Elohe Israẹli. 33.20 tí ó túmọ̀ sí, Ọlọ́run Israẹli Dina àti àwọn ará Ṣekemu Ní ọjọ́ kan, Dina ọmọbìnrin tí Lea bí fún Jakọbu jáde lọ bẹ àwọn ọmọbìnrin ilẹ̀ náà wò. Nígbà tí Ṣekemu ọmọ ọba Hamori ará Hifi rí i, ó mú un, ó sì fi ipá bá a lo pọ̀. Ọkàn rẹ sì fà sí Dina ọmọ Jakọbu gan an, ó sì fẹ́ràn rẹ̀ ó sì bá ọmọbìnrin náà sọ̀rọ̀ ìfẹ́. Ṣekemu sì wí fún Hamori baba rẹ̀ pé, “Fẹ́ ọmọbìnrin yìí fún mi bí aya.” Nígbà tí Jakọbu gbọ́ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ pé a fi ipá bá Dina ọmọbìnrin òun ní ògo jẹ́, ṣùgbọ́n àwọn ọmọ rẹ̀ wà nínú pápá níbi tí wọ́n ti ń daran nítorí náà ó mú sùúrù títí tí wọ́n fi dé. Hamori baba Ṣekemu sì jáde wá láti bá Jakọbu sọ̀rọ̀. Àwọn ọmọ Jakọbu sì ti oko dé, wọ́n sì gbọ́ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ inú wọn sì bàjẹ́, ó sì ń bí wọn nínú gidigidi, nítorí tí ó ṣe ohun búburú ní Israẹli, ní ti ó bá ọmọbìnrin ọmọ Jakọbu lòpọ̀—irú ohun tí kò yẹ kí ó ṣẹlẹ̀ rárá. Hamori sì bá wọn sọ̀rọ̀ pé, “Ọkàn ọmọ mi Ṣekemu fà sí ọmọ rẹ. Jọ̀wọ́ fi fún un gẹ́gẹ́ bí aya. Ẹ jẹ́ kí a máa ṣe ìgbéyàwó láàrín ara wa, kí àwọn ọmọ yín kó máa fẹ́ àwọn ọmọ wa. Ẹ lè máa gbé láàrín wa, ibikíbi tí ó bá tẹ́ yín lọ́rùn láàrín wa ni ẹ lè gbé, ẹ máa ṣe òwò yín kí ẹ sì kó ọrọ̀ jọ fún ara yín.” Ṣekemu sì wí fún baba àti arákùnrin Dina pé, “Ẹ jọ̀wọ́, ẹ jẹ́ kí n rí ojúrere yín, èmi yóò sì fún yín ní ohunkóhun tí ẹ̀yin bá fẹ́ gbà. Iyekíye tí owó orí rẹ̀ bá jẹ́ àti ẹ̀bùn gbogbo tí ẹ bá fẹ́, bí ó ti wù kí ó pọ̀ tó, èmi yóò san án, kí ẹ sá à jẹ́ kí ń fi ọmọ náà ṣe aya.” Àwọn ọmọ Jakọbu sì fi ẹ̀tàn dá Ṣekemu àti Hamori baba rẹ̀ lóhùn, wọ́n sì wí pé, nítorí tí ó ti ba ògo Dina arábìnrin wọn jẹ́. Wọ́n wí fún wọn pé, “Àwa kò le ṣe nǹkan yìí láti fi arábìnrin wa fún aláìkọlà, nítorí àbùkù ni èyí yóò jẹ́ fún wa. Àwa yóò fi ara mọ́ ọn bí ẹ̀yin yóò bá gbà láti dàbí i tiwa, wí pé ẹ̀yin pẹ̀lú yóò kọ gbogbo ọkùnrin yín ní ilà. Nígbà náà ni àwa yóò le máa fún yín ní ọmọ wa, tí àwa náà yóò máa fẹ́ ẹ yín. A ó máa gbé láàrín yín, a ó sì di ara kan pẹ̀lú yín. Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin bá kọ̀ láti kọlà, àwa yóò mú arábìnrin wa, á ó sì máa lọ.” Àbá náà sì dùn mọ́ Hamori àti Ṣekemu ọmọ rẹ̀. Ọ̀dọ́mọkùnrin náà, ẹni tí ó jẹ́ ẹni iyì jùlọ ní ilé baba rẹ̀, kò jáfara láti ṣe ohun tí wọ́n wí. Nítorí tí ó fẹ́ràn ọmọbìnrin Jakọbu. Hamori àti Ṣekemu ọmọ rẹ̀ sì wá sí ẹnu ibodè ìlú náà wọn sì bá àwọn ará ìlú náà sọ̀rọ̀. Wí pé, “Ìwà àwọn ọkùnrin wọ̀nyí dára, ẹ jẹ́ kí wọn máa gbé ní àárín wa, kí wọn sì máa ṣòwò, ilẹ̀ kúkú wà rẹpẹtẹ tó gba ààyè dáradára. A lè fẹ́ àwọn ọmọ wọ́n, ki wọn sì fẹ́ tiwa pẹ̀lú. Ṣùgbọ́n kín ní kan ni a lè ṣe kí wọn tó gbà láti gbé pẹ̀lú wa, ìyẹn sì ni pé àwọn ọkùnrin wa yóò kọlà bí i tiwọn. Ṣe bí àwọn ẹran wọn àti ẹrú wọn àti àwọn ohun ọ̀sìn wọn ni yóò di tiwa bí a bá lè gbà bẹ́ẹ̀, wọn yóò sì máa gbé ni àárín wa.” Gbogbo àwọn ọkùnrin tí ń jáde ní ẹnu-bodè ìlú náà sì gbọ́ ti Hamori àti Ṣekemu ọmọ rẹ̀. Gbogbo ọkùnrin ìlú náà sì kọlà. Lẹ́yìn ọjọ́ kẹta, nígbà tí gbogbo wọn sì wà nínú ìrora. Àwọn ọmọ Jakọbu méjì, Simeoni àti Lefi tí ó jẹ́ ẹ̀gbọ́n fún Dina, sì mú idà wọn pẹ̀lú ìgboyà, wọ́n sì pa gbogbo ọkùnrin ìlú náà. Wọ́n sì fi idà pa Hamori àti Ṣekemu ọmọ rẹ̀, wọ́n mú Dina kúrò ní ilé wọn, wọ́n sì jáde. Àwọn ọmọ Jakọbu sì wọlé àwọn tí a pa, wọ́n sì kó ẹrù ìlú tí a ti ba ògo arábìnrin wọn jẹ́. Wọ́n kó màlúù wọn àti agbo ẹran wọn àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, àti ohun gbogbo tí ó wà nínú ìlú àti ní oko. Gbogbo ọrọ̀ wọn, gbogbo obìnrin ìlú àti àwọn ọmọ wẹẹrẹ pátápátá ni wọ́n kó. Wọ́n sì kó gbogbo ohun tí ó wà nínú ilé wọn bí ìkógun. Nígbà náà ni Jakọbu wí fún Simeoni àti Lefi wí pé, “Ẹ̀yin ti kó ìyọnu bá mi nípa sísọ mí di olóòórùn láàrín ará Kenaani àti Peresi, tí ó ń gbé ilẹ̀ yìí. Àwa kò pọ̀, bí wọn bá wá parapọ̀ ṣígun sí wa, gbogbo wa pátápátá ni wọn yóò parun.” Ṣùgbọ́n wọ́n dáhùn pé, “Ǹjẹ́ ó yẹ kí ó ṣe arábìnrin wa bí panṣágà?” Jakọbu padà sí Beteli Nígbà náà ni Ọlọ́run wí fún Jakọbu pé, “Gòkè lọ sí Beteli kí o sì tẹ̀dó síbẹ̀, kí ó mọ pẹpẹ níbẹ̀ fún Ọlọ́run tó farahàn ọ́ nígbà tí o ń sálọ kúrò níwájú Esau arákùnrin rẹ.” Nítorí náà, Jakọbu wí fún gbogbo ará ilé rẹ̀ pé, “Ẹ mú gbogbo àjèjì òrìṣà tí ó wà lọ́dọ̀ yín kúrò, kí ẹ ya ara yín sí mímọ́, kí ẹ sì pààrọ̀ aṣọ yín. Nígbà náà ni kí ẹ wá, kí ẹ jẹ́ kí a lọ sí Beteli, níbi tí n ó ti mọ pẹpẹ fún Ọlọ́run, tí ó dá mi lóhùn ní ọjọ́ ìpọ́njú mi tí ó sì ti ń pẹ̀lú mi níbi gbogbo tí mo ń lọ.” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n fún Jakọbu ní gbogbo àjèjì òrìṣà tí ó wà lọ́wọ́ wọn, àti yẹtí etí wọn, Jakọbu sì bo gbogbo wọn mọ́lẹ̀ sábẹ́ igi óákù ní Ṣekemu. Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ ìrìnàjò wọn. Ìbẹ̀rù Ọlọ́run sì ń bẹ lára gbogbo ìlú tí ó yí wọn ká, wọ́n kò sì lépa àwọn ọmọ Jakọbu. Jakọbu àti gbogbo àwọn tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ sì dé sí Lusi (ti o túmọ̀ sí Beteli) tí ó wà ní ilẹ̀ Kenaani. Níbẹ̀ ni ó sì mọ pẹpẹ kan tí ó pè ní El-Beteli,35.7 El-Betelití ó túmọ̀ sí Ọlọ́run Beteli nítorí níbẹ̀ ni Ọlọ́run ti gbé fi ara hàn án nígbà tí ó ń sálọ fún arákùnrin rẹ̀. Kò pẹ́ lẹ́yìn èyí ni Debora, olùtọ́jú Rebeka kú, a sì sin ín sábẹ́ igi óákù ní ìsàlẹ̀ Beteli. Nítorí náà a sọ ọ́ ní Aloni-Bakuti. Lẹ́yìn tí Jakọbu padà dé láti Padani-Aramu, Ọlọ́run tún fi ara hàn án, ó sì súre fún un. Ọlọ́run sì wí fun un pé, “Jakọbu ni orúkọ rẹ, a kì yóò pè ọ́ ní Jakọbu35.10 Jakọbu tí ó túmọ̀ sí, ajinnilẹ́sẹ̀ mọ́; bí kò ṣe Israẹli.35.10 Israẹli tí ó túmọ̀ sí, ẹni tí ó bá Ọlọ́run jìjàkadì. ” Nítorí náà, ó sọ orúkọ rẹ̀ ní Israẹli. Ọlọ́run sì wí fún un pé, “Èmi ni Ọlọ́run alágbára, El-Ṣaddai; máa bí sí i, kí o sì máa pọ̀ sí i. Orílẹ̀-èdè àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè ni yóò ti ọ̀dọ̀ rẹ̀ wá, àwọn ọba yóò sì jáde wá láti ara rẹ̀. Gbogbo ilẹ̀ tí mo fi fún Abrahamu àti Isaaki ni èmi yóò fún ọ pẹ̀lú, àti fún àwọn ìran rẹ tí ó ń bọ̀ lẹ́yìn.” Nígbà náà ni Ọlọ́run gòkè lọ kúrò ní ibi tí ó ti ń bá a sọ̀rọ̀. Jakọbu sì fi òkúta ṣe ọ̀wọ̀n kan sí ibi tí Ọlọ́run ti bá a sọ̀rọ̀, ó sì ta ọrẹ ohun mímu sí orí rẹ̀, ó sì da òróró olifi sí orí rẹ̀ pẹ̀lú. Jakọbu sì pe orúkọ ibi tí Ọlọ́run ti bá a sọ̀rọ̀ ní Beteli. Ikú Rakeli àti Isaaki Nígbà náà ni wọ́n ń tẹ̀síwájú nínú ìrìnàjò wọn láti Beteli. Nígbà tí ó sì ku díẹ̀ kí wọn dé Efrata, Rakeli bẹ̀rẹ̀ sí ní rọbí, ó sì ní ìdààmú púpọ̀. Bí ó sì ti ń rọbí pẹ̀lú ìrora yìí, agbẹ̀bí wí fún un pé, “Má bẹ̀rù nítorí ọmọkùnrin mìíràn ni ó ń bọ̀ yìí.” Bí o sì ti fẹ́ gbé ẹ̀mí mi, torí pé ó ń kú lọ, ó pe ọmọ rẹ̀ náà ní Bene-Oni, ọmọ ìpọ́njú. Ṣùgbọ́n Jakọbu sọ ọmọ náà ní Benjamini, ọmọ oókan àyà mi. Báyìí ni Rakeli kú, a sì sin ín sí ọ̀nà Efrata (ti o túmọ̀ sí, Bẹtilẹhẹmu). Jakọbu sì mọ ọ̀wọ́n kan sí ibojì rẹ̀, ọ̀wọ̀n náà sì tọ́ka sí ojú ibojì Rakeli títí di òní. Israẹli sì ń bá ìrìnàjò rẹ̀ lọ, ó sì pa àgọ́ rẹ̀ sí Migida-Ederi, ilé ìṣọ́ Ederi. Nígbà tí Israẹli sì ń gbé ní ibẹ̀, Reubeni wọlé tọ Biliha, àlè baba rẹ̀ lọ, ó sì bá a lòpọ̀, Israẹli sì gbọ́ ọ̀rọ̀ náà. Jakọbu sì bí ọmọkùnrin méjìlá. Àwọn ọmọ Lea, Reubeni tí í ṣe àkọ́bí Jakọbu, Simeoni, Lefi, Juda, Isakari àti Sebuluni. Àwọn ọmọ Rakeli: Josẹfu àti Benjamini. Àwọn ọmọ Biliha ìránṣẹ́bìnrin Rakeli: Dani àti Naftali. Àwọn ọmọ Silipa ìránṣẹ́bìnrin Lea: Gadi àti Aṣeri. Àwọn wọ̀nyí ni ọmọ tí Jakọbu bí ní Padani-Aramu. Jakọbu sì padà dé ilé lọ́dọ̀ Isaaki baba rẹ̀ ni Mamre nítòsí i Kiriati-Arba (ti o túmọ̀ sí Hebroni). Níbi tí Abrahamu àti Isaaki gbé. Ẹni ọgọ́sàn-án ọdún ni Isaaki. Isaaki sì kú láìpẹ́ lẹ́yìn ìpadàbọ̀ Jakọbu, a sì sin ín pẹ̀lú àwọn ènìyàn rẹ̀ ní ọjọ́ ogbó rẹ̀. Esau àti Jakọbu ọmọ rẹ̀ sì sin ín. Àwọn ìránṣẹ́ Esau Wọ̀nyí ni ìran Esau, ẹni tí a ń pè ní Edomu. Nínú àwọn ọmọbìnrin Kenaani ni Esau ti fẹ́ àwọn ìyàwó rẹ̀: Adah ọmọbìnrin Eloni ará Hiti àti Oholibama, ọmọbìnrin Ana, ọmọ ọmọ Sibeoni ará Hifi. Ó sì tún fẹ́ Basemati ọmọ Iṣmaeli arábìnrin Nebaioti. Adah bí Elifasi fún Esau, Basemati sì bí Reueli, Oholibama pẹ̀lú sì bí Jeuṣi, Jalamu, àti Kora. Àwọn wọ̀nyí ni ọmọ tí Esau bí ní Kenaani. Esau sì mú àwọn aya rẹ̀, àwọn ọmọkùnrin rẹ̀, àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ àti gbogbo àwọn ará ilé rẹ̀, àwọn ohun ọ̀sìn rẹ̀ àti àwọn ẹran ọ̀sìn mìíràn àti gbogbo ohun ìní mìíràn tí ó ní, ni Kenaani, ó sì kó lọ sí ilẹ̀ mìíràn, jìnà sí ibi tí Jakọbu arákùnrin rẹ̀ wà. Ohun ìní wọn pọ̀ ju èyí tí àwọn méjèèjì lè máa gbé ní ojú kan lọ. Ilẹ̀ tí wọ́n wà kò le gba àwọn méjèèjì nítorí àwọn ohun ọ̀sìn wọn. Báyìí ni Esau (tí a tún mọ̀ sí Edomu) tẹ̀dó sí àwọn orílẹ̀-èdè olókè tí Seiri. Èyí ni ìran Esau baba àwọn ará Edomu ní àwọn orílẹ̀-èdè olókè Seiri. Wọ̀nyí ni orúkọ àwọn ọmọ Esau: Elifasi ọmọ Adah aya Esau àti Reueli, ọmọ Basemati tí í ṣe aya Esau pẹ̀lú. Àwọn ọmọ Elifasi ni ìwọ̀nyí: Temani, Omari, Sefi, Gatamu, àti Kenasi. Elifasi ọmọ Esau sì tún ní àlè tí a ń pè ní Timna pẹ̀lú, òun ló bí Amaleki fún un. Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ ọmọ Adah aya Esau. Àwọn ọmọ Reueli: Nahati, Sera, Ṣamma àti Missa. Àwọn ni ọmọ ọmọ Basemati aya Esau. Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Oholibama ọmọbìnrin Ana ọmọ ọmọ Sibeoni: tí ó bí fún Esau: Jeuṣi, Jalamu àti Kora. Àwọn wọ̀nyí ni olórí nínú àwọn ọmọ Esau: àwọn ọmọ Elifasi, àkọ́bí Esau, Temani, Omari, Sefi, Kenasi, Kora, Gatamu àti Amaleki. Àwọn wọ̀nyí ló jẹ́ olórí ìdílé tí ó ti ọ̀dọ̀ Elifasi ní Edomu wá, wọ́n jẹ́ ọmọ ọmọ Adah. Wọ̀nyí sì ni àwọn ọmọ Esau, ọmọ Rueli: Nahati olórí, Sera olórí, Ṣamma olórí, Missa olórí. Àwọn wọ̀nyí ló jẹ́ olórí ìdílé tí ó ti ọ̀dọ̀ Reueli jáde ní Edomu. Ọmọ ọmọ Basemati aya Esau ni wọ́n jẹ́. Àwọn ọmọ Oholibama aya Esau: Jeuṣi, Jalamu, àti Kora, àwọn wọ̀nyí ló jẹ́ olórí ìdílé tí ó ti ọ̀dọ̀ Oholibama ọmọ Ana, ìyàwó Esau wá. Àwọn wọ̀nyí ni ọmọ Esau (ti o túmọ̀ sí Edomu). Àwọn wọ̀nyí ni olórí wọn. Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Seiri ará Hori tí ó ń gbé ní ilẹ̀ náà: Lotani, Ṣobali, Sibeoni, Ana, Diṣoni, Eseri, àti Diṣani, àwọn wọ̀nyí olórí ènìyàn Hori, àwọn ọmọ Seiri ni ilẹ̀ Edomu. Àwọn ọmọ Lotani: Hori àti Homamu: Timna sì ni arábìnrin Lotani. Àwọn ọmọ Ṣobali: Alifani, Manahati, Ebali, Ṣefo àti Onamu. Àwọn ọmọ Sibeoni: Aiah àti Ana. Èyí ni Ana tí ó rí ìsun omi gbígbóná ní inú aginjù bí ó ti ń da àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ Ṣebeoni baba rẹ̀. Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Ana: Diṣoni àti Oholibama ọmọbìnrin Ana. Àwọn ọmọ Diṣoni ni: Hemdani, Eṣbani, Itrani àti Kerani. Àwọn ọmọ Eseri: Bilhani, Saafani àti Akani. Àwọn ọmọ Diṣani ni: Usi àti Arani. Àwọn wọ̀nyí ni olórí ìdílé Hori: Lotani, Ṣobali, Sibeoni, Ana, Diṣoni Eseri, àti Diṣani. Àwọn ni olórí ìdílé àwọn ará Hori gẹ́gẹ́ bí ìpín wọn ní ilẹ̀ Seiri. Àwọn aláṣẹ Edomu Àwọn wọ̀nyí ni ọba tí ó jẹ ní Edomu kí ó tó di pé ọba kankan jẹ lórí Israẹli: Bela ọmọ Beori jẹ ní Edomu. Orúkọ ìlú rẹ̀ ni Dinhaba. Nígbà tí Bela kú, Jobabu ọmọ Sera ti Bosra sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀. Nígbà tí Jobabu kú, Huṣamu láti ilẹ̀ Temani sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀. Nígbà tí Huṣamu kú, Hadadi ọmọ Bedadi tí ó kọlu Midiani ní ìgbẹ́ Moabu, ó sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀. Orúkọ ìlú rẹ̀ ni Afiti. Nígbà tí Hadadi sì kú, Samla láti Masreka, ó sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀. Samla sì kú, Saulu ti Rehoboti, létí odò sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀. Nígbà tí Saulu kú, Baali-Hanani ọmọ Akbori jẹ ọba ní ipò rẹ̀. Nígbà tí Baali-Hanani ọmọ Akbori kú, Hadadi ni ó jẹ ọba ní ipò rẹ̀. Orúkọ ìlú rẹ̀ ni Pau, orúkọ ìyàwó sì ni Mehetabeeli ọmọbìnrin Matiredi, ọmọbìnrin Mesahabu. Àwọn wọ̀nyí ni orúkọ àwọn baálẹ̀ tí ó ti ọ̀dọ̀ Esau jáde wá, ní orúkọ ìdílé wọn, bí ìpínlẹ̀ wọn ti rí: baálẹ̀ Timna, baálẹ̀ Alfa, baálẹ̀ Jeteti. Baálẹ̀ Oholibama, baálẹ̀ Ela, baálẹ̀ Pinoni, baálẹ̀ Kenasi, baálẹ̀ Temani, baálẹ̀ Mibsari, Magdieli, àti Iramu. Àwọn wọ̀nyí ni baálẹ̀ Edomu, gẹ́gẹ́ bí wọn ti tẹ̀dó sí ilẹ̀ tí wọ́n gbà. Èyí ni Esau baba àwọn ará Edomu. Àlá Josẹfu Jakọbu sì gbé ilẹ̀ Kenaani ní ibi ti baba rẹ̀ ti gbé. Èyí ni àwọn ìtàn Jakọbu. Nígbà tí Josẹfu di ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún, ó ń ṣọ́ agbo ẹran pẹ̀lú àwọn arákùnrin rẹ̀, àwọn ọmọ Biliha àti Silipa aya baba rẹ̀ Josẹfu sì ń ròyìn àwọn aburú tí wọ́n ń ṣe fún baba wọn. Israẹli sì fẹ́ràn Josẹfu ju gbogbo àwọn ọmọ rẹ̀ tókù lọ, nítorí ní ọjọ́ ogbó rẹ̀ ni ó bí i. O sì dá aṣọ aláràbarà tí ó kún fún onírúurú ọnà lára fún un. Nígbà tí àwọn arákùnrin rẹ̀ rí i pé baba àwọn fẹ́ràn rẹ̀ ju gbogbo wọn lọ, wọ́n kórìíra rẹ̀, wọ́n sì ń fi ẹ̀tanú bá a gbé, kò sì sí àlàáfíà láàrín wọn. Josẹfu lá àlá kan, nígbà tí ó sì sọ fún àwọn arákùnrin rẹ̀, wọ́n túbọ̀ kórìíra rẹ̀ sí i. O wí fún wọn pé, “Ẹ fetí sí àlá tí mo lá, sá à wò ó, àwa ń yí ìtí ọkà nínú oko, ó sì ṣe ìtí ọkà tèmi sì dìde dúró ṣánṣán, àwọn ìtí ọkà tiyín sì dúró yí ìtí tèmi ká, wọ́n sì ń foríbalẹ̀ fún un.” Àwọn arákùnrin rẹ̀ wí fún un pé, “Ìwọ ń gbèrò àti jẹ ọba lé wa lórí bí? Tàbí ìwọ ó ṣe olórí wa nítòótọ́?” Wọn sì túbọ̀ kórìíra rẹ̀ sí i, nítorí àlá rẹ̀ àti nítorí ohun tí ó wí. O sì tún lá àlá mìíràn, ó sì tún sọ ọ́ fún àwọn arákùnrin rẹ̀. Ó wí pé, ẹ tẹ́tí sí mi, “Mo tún lá àlá mìíràn, wò ó, oòrùn, òṣùpá àti ìràwọ̀ mọ́kànlá ń foríbalẹ̀ fún mi.” Nígbà tí ó sọ fún baba rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀ pẹ̀lú, baba rẹ̀ bá a wí pé, “Irú àlá wo ni ìwọ lá yìí? Ṣé ìyá rẹ, pẹ̀lú èmi àti àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ yóò wá foríbalẹ̀ níwájú rẹ ni?” Àwọn arákùnrin rẹ̀ sì ń ṣe ìlara rẹ̀ ṣùgbọ́n baba rẹ̀ pa ọ̀rọ̀ náà mọ́ lọ́kàn rẹ̀. Àwọn arákùnrin Josẹfu tà á Àwọn arákùnrin rẹ̀ sì da ẹran baba wọn lọ sí Ṣekemu. Israẹli sì wí fún Josẹfu pé, “Ṣé o mọ̀ pé, àwọn arákùnrin rẹ ń da ẹran ní Ṣekemu, wá, jẹ́ kí n rán ọ sí wọn.” Josẹfu sì dáhùn pé, “Èmi nìyí.” O sì wí fún un pé, “Lọ wò bí àwọn arákùnrin rẹ àti àwọn agbo ẹran bá wà ní àlàáfíà, kí o sì wá jíṣẹ́ fún mi.” Ó sì rán Josẹfu lọ láti àfonífojì Hebroni. Nígbà tí Josẹfu dé Ṣekemu, ọkùnrin kan sì rí i tí ó ń rìn kiri inú pápá, ó sì bi í pé, “Kín ni ò ń wá?” Ó sì dáhùn pé, “Àwọn arákùnrin mi ni mò ń wá, ǹjẹ́ o mọ ibi tí wọ́n wà pẹ̀lú agbo ẹran?” Ọkùnrin náà dáhùn pé, “Wọ́n ti kúrò ní ìhín, mo gbọ́ tí wọ́n ń wí pé, ‘Ẹ jẹ́ kí a lọ sí Dotani.’ ” Josẹfu sì wá àwọn arákùnrin rẹ̀ lọ, ó sì rí wọn ní tòsí Dotani. Ṣùgbọ́n bí wọ́n sì ti rí i tí ń bọ̀ lókèèrè, kí ó sì tó dé ọ̀dọ̀ wọn, wọn gbìmọ̀ pọ̀ láti pa á. “Alálàá ni ń bọ̀ yìí,” ni wọ́n ń wí fún ara wọn. “Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a pa á. Kí a sì ju òkú rẹ̀ sínú kòtò, a ó sì wí pé, ẹranko búburú ni ó pa á, kí a máa wo ọ̀nà tí àlá rẹ̀ yóò gbà ṣẹ.” Nígbà tí Reubeni gbọ́ èyí, ó gbìyànjú láti gbà á sílẹ̀ ní ọwọ́ wọn, ó sì wí pé, “Ẹ má ṣe jẹ́ kí a gba ẹ̀mí rẹ̀, ẹ má ṣe jẹ́ kí a ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀, ẹ má ṣe fọwọ́ kàn án, ẹ kúkú jù ú sínú kòtò láààyè nínú aginjù níbí.” Reubeni sọ èyí, kí ó ba à le gbà á kúrò lọ́wọ́ wọn, kí ó sì dá a padà lọ fún baba rẹ̀. Nítorí náà, nígbà tí Josẹfu dé ọ̀dọ̀ àwọn arákùnrin rẹ̀, wọ́n bọ́ ẹ̀wù rẹ̀—Ẹ̀wù ọlọ́nà, aláràbarà tí ó wọ̀— wọ́n mú un, wọ́n sì jù ú sínú kòtò. Kòtò náà sì ṣófo, kò sí omi nínú rẹ̀. Bí wọ́n sì ti jókòó láti jẹun, wọ́n gbójú sókè, wọ́n sì rí àwọn oníṣòwò ará Iṣmaeli tí wọ́n ń wọ́ bọ̀ láti Gileadi. Ìbákasẹ wọn sì ru tùràrí, ìkunra àti òjìá, wọ́n ń lọ sí Ejibiti. Juda wí fún àwọn arákùnrin rẹ̀ pé, “Èrè kí ni ó jẹ́ bí a bá pa arákùnrin wa tí a bo ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ mọ́lẹ̀ ti ọkàn wa sì ń dá wa lẹ́bi? Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí á tà á fún àwọn ará Iṣmaeli, kí àwa má sì pa á, ṣè bí àbúrò wa ni, ẹran-ara wa àti ẹ̀jẹ̀ wa ní i ṣe.” Àwọn arákùnrin rẹ̀ sì fi ara mọ́ ohun tí ó sọ. Nítorí náà, nígbà tí àwọn oníṣòwò ara Midiani ń kọjá, àwọn arákùnrin Josẹfu fà á jáde láti inú kòtò, wọ́n sì tà á fún àwọn ará Iṣmaeli ní ogún owó wúrà, wọ́n sì mú Josẹfu lọ sí ilẹ̀ Ejibiti. Nígbà tí Reubeni padà dé ibi kòtò tí ó sì ri pé Josẹfu kò sí níbẹ̀ mọ́, ó fa aṣọ rẹ̀ ya pẹ̀lú ìbànújẹ́. Ó padà lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn arákùnrin rẹ̀, ó sì wí pé, “Ọmọdékùnrin náà kò sí níbẹ̀ mọ́! Níbo ni ẹ fẹ́ kí n wọ̀ báyìí?” Nígbà náà ni wọ́n mú aṣọ Josẹfu, wọ́n pa ewúrẹ́ kan, wọ́n sì tẹ aṣọ náà bọ inú ẹ̀jẹ̀ ewúrẹ́ náà. Wọ́n sì mú aṣọ ọlọ́nà aláràbarà náà padà sí ọ̀dọ̀ baba wọn, wọ́n sì wí pé, “A rí èyí he nínú oko, yẹ̀ ẹ́ wò, kí o sì mọ̀ bóyá ti ọmọ rẹ ni.” Ó sì dá a mọ̀, ó wí pé, “Háà! Aṣọ ọmọ mi ni, ẹranko búburú ti pa á jẹ, láìṣe àní àní, ó ti fa Josẹfu ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ.” Nígbà náà ni Jakọbu fa aṣọ rẹ̀ ya, ó sì wọ aṣọ ọ̀fọ̀, ó sì ṣọ̀fọ̀ ọmọ rẹ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọjọ́. Gbogbo àwọn ọmọ rẹ̀ lọ́kùnrin, lóbìnrin wá láti tù ú nínú, ṣùgbọ́n kò gbà. Ó wí pé, “Rárá, nínú ọ̀fọ̀ yìí ni èmi yóò lọ sí isà òkú lọ́dọ̀ ọmọ mi.” Baba Josẹfu sì sọkún fún un. Ní gbogbo àkókò wọ̀nyí, àwọn ará Midiani ta Josẹfu ní Ejibiti fún Potifari, ọ̀kan nínú àwọn ìjòyè Farao, tí í ṣe olórí ẹ̀ṣọ́. Juda àti Tamari Ní àkókò náà, Juda lọ kúrò lọ́dọ̀ àwọn arákùnrin rẹ̀ láti lọ dúró lọ́dọ̀ ọkùnrin ará Adullamu kan tí ń jẹ́ Hira. Juda sì pàdé ọmọbìnrin Kenaani kan níbẹ̀ ẹni ti orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ṣua. Ó sì fi ṣe aya, ó sì bá a lòpọ̀; ó sì lóyún, ó sì bí ọmọkùnrin kan, tí ó sọ orúkọ rẹ̀ ní Eri. Ó sì tún lóyún, ó sì bí ọmọkùnrin, ó sì sọ orúkọ rẹ̀ ní Onani. Ó sì tún bí ọmọkùnrin mìíràn, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Ṣela. Ní Kesibu ni ó wà nígbà tí ó bí i. Juda sì fẹ́ aya fún Eri, àkọ́bí rẹ̀, orúkọ aya náà ni Tamari. Ṣùgbọ́n Eri àkọ́bí Juda ṣe ènìyàn búburú níwájú Olúwa, Ọlọ́run sì pa á. Nígbà náà ni Juda wí fún Onani, “Bá aya arákùnrin rẹ lòpọ̀, kí o ṣe ojúṣe rẹ fun un gẹ́gẹ́ bí àbúrò ọkọ, kí ó ba à le bí ọmọ fún un ní orúkọ arákùnrin rẹ.” Ṣùgbọ́n Onani mọ̀ pé àwọn ọmọ náà kì yóò jẹ́ ti òun, nítorí náà ni gbogbo ìgbà tí ó bá wọlé tọ aya arákùnrin rẹ̀ lọ, ilẹ̀ ni ó ń da nǹkan ọkùnrin rẹ̀ sí, kí ó má bá a bímọ fún arákùnrin rẹ̀. Ohun tí ó ń ṣe yìí burú lójú Olúwa, ó sì pa òun náà pẹ̀lú. Nígbà náà ni Juda wí fún Tamari, ìyàwó ọmọ rẹ̀ pé, “Lọ máa gbé bí opó ní ilé baba rẹ, títí tí Ṣela yóò fi dàgbà ó lérò pé òun náà lè kú bí àwọn arákùnrin rẹ̀ tókù.” Nígbà náà ni Tamari ń lọ gbé ilé baba rẹ̀. Lẹ́yìn ìgbà pípẹ́, ìyàwó Juda, ọmọbìnrin Ṣua sì kú, nígbà tí ọjọ́ ọ̀fọ̀ Juda sì pé, ó gòkè lọ sí Timna, sí ọ̀dọ̀ àwọn tí ń bá a rẹ́run àgùntàn rẹ̀, Hira ará Adullamu tí í ṣe ọ̀rẹ́ rẹ̀ sì bá a lọ. Nígbà tí ẹnìkan sọ fún Tamari pé, “Baba ọkọ ọ̀ rẹ̀ wà ní ọ̀nà àjò rẹ̀ sí Timna láti rẹ́run àgùntàn rẹ̀.” Ó bọ́ aṣọ opó rẹ̀, ó sì fi ìbòjú bo ojú ara rẹ̀ kí wọn má ba à mọ̀ ọ́n. Ó sì jókòó sí ẹnu-bodè Enaimu, èyí tí ó wà ní ọ̀nà Timna. Nítorí ó rí i wí pé, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Ṣela ti dàgbà, síbẹ̀, a kò fi òun fún un gẹ́gẹ́ bí aya. Nígbà tí Juda rí i, ó rò pé panṣágà ni, nítorí ó ti bo ojú rẹ̀. Láìmọ̀ pé, aya ọmọ òun ní í ṣe, ó yà tọ̀ ọ́ ní ẹ̀bá ọ̀nà, ó wí pé, “Wá kí èmi kí ó lè wọlé tọ̀ ọ́.” Òun sì wí pé, “Kín ni ìwọ yóò fi fún mi kí ìwọ kó lè wọlé tọ̀ mí.” Ó sì wí pé, “Èmi yóò fi ọmọ ewúrẹ́ kan ránṣẹ́ sí ọ láti inú agbo ẹran.” Obìnrin náà sì dáhùn pé, “Ṣé ìwọ yóò fún mi ní ohun kan gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí títí tí ìwọ yóò fi fi ránṣẹ́?” Juda sì bi í pé, “Ẹ̀rí wo ni kí n fún ọ?” Ó sì dáhùn pé, “Èdìdì ìdámọ̀ okùn àti ọ̀pá ìtìlẹ̀ rẹ ti ń bẹ ní ọwọ́ rẹ.” Ó sì kó wọn fún un, ó sì sùn tì í, obìnrin náà sì lóyún nípasẹ̀ rẹ̀. Lẹ́yìn ìgbà tí ó lọ, ó bọ́ ìbòjú ojú rẹ̀, ó sì tún wọ aṣọ opó rẹ̀ padà. Juda sì rán ọmọ ewúrẹ́ náà láti ọwọ́ ọ̀rẹ́ rẹ̀, ará Adullamu náà lọ láti gba ògo n nì wá lọ́wọ́ obìnrin náà. Ṣùgbọ́n wọn kò bá obìnrin náà níbẹ̀. Ó béèrè lọ́wọ́ àwọn ènìyàn àdúgbò náà pé, “Níbo ni alágbèrè ojúbọ òrìṣà tí ó wà ní etí ọ̀nà Enaimu wà?” Wọ́n sì dá a lóhùn pé, “Kò sí alágbèrè ojúbọ òrìṣà kankan níbí.” Ó sì padà lọ sọ́dọ̀ Juda ó wí fún un pé, “Èmí kò rí i, à ti pé àwọn aládùúgbò ibẹ̀ sọ pé kò sí alágbèrè ojúbọ òrìṣà kankan níbẹ̀.” Nígbà náà ni Juda wí pé, “Jẹ́ kí ó máa kó àwọn ohun tí ó wà lọ́wọ́ rẹ̀ lọ bí kò ṣe bẹ́ẹ̀ a ó di ẹlẹ́yà. Mo sá à fi ọmọ ewúrẹ́ ránṣẹ́ sí i, ṣùgbọ́n ìwọ kò rí òun.” Lẹ́yìn nǹkan bí oṣù mẹ́ta, wọn sọ fún Juda pé, “Tamari aya ọmọ rẹ̀ ṣe àgbèrè, ó sì ti lóyún.” Juda sì wí pé, “Ẹ mú un jáde, kí ẹ sì dá iná sun ún.” Bí wọ́n sì ti ń mú un jáde, ó ránṣẹ́ sí baba ọkọ rẹ̀ pé, “Ọkùnrin tí ó ni àwọn nǹkan wọ̀nyí ni ó fún mi lóyún. Wò ó, bóyá o lè mọ ẹni tí ó ni èdìdì ìdámọ̀, okùn àti ọ̀pá ìtìlẹ̀ wọ̀nyí.” Juda sì dá wọn mọ̀, ó sì wí pé, “O ṣe olódodo jù mí lọ, níwọ̀n ìgbà tí n kò fi fún Ṣela ọmọ mi.” Kò sì bá a lòpọ̀ mọ́ láti ọjọ́ náà. Nígbà tí àsìkò ìbímọ rẹ̀ tó. Ìbejì ọkùnrin ni ó bí. Bí ó sì ti ń bímọ, ọ̀kan nínú àwọn ọmọ náà na ọwọ́ jáde; agbẹ̀bí sì so okùn òdòdó mọ́ ọmọ náà ní ọrùn ọwọ́. Ó sì wí pé, “Èyí ni o kọ́kọ́ jáde.” Ṣùgbọ́n nígbà tí ó fa ọwọ́ rẹ̀ padà, èkejì rẹ̀ jáde. Tamari sì wí pé, “Níbo ni ìwọ ti wá?” Ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Peresi. Nígbà náà ni èkejì tí a ti so okùn olódòdó mọ́ lọ́rùn ọwọ́ jáde, wọ́n sì pe orúkọ rẹ̀ ni Sera. Josẹfu àti aya Potifari Nígbà tí wọ́n mú Josẹfu dé Ejibiti, Potifari, ará Ejibiti tí i ṣe ọ̀kan nínú àwọn ìjòyè Farao. Òun ni olórí àwọn ọmọ-ogun Farao. Ó ra Josẹfu lọ́wọ́ àwọn ará Iṣmaeli tí wọ́n mú un lọ síbẹ̀. Olúwa sì wà pẹ̀lú Josẹfu, ó sì bùkún un, ó sì ń gbé ní ilé ọ̀gá rẹ̀ ará Ejibiti. Nígbà tí ọ̀gá rẹ̀ rí i pé Olúwa wà pẹ̀lú rẹ̀, àti pé Olúwa jẹ́ kí ó máa ṣe àṣeyọrí nínú ohun gbogbo tí ó dáwọ́ rẹ̀ lé. Josẹfu sì rí ojúrere Potifari, ó sì di aṣojú rẹ̀, Potifari fi Josẹfu ṣe olórí ilé rẹ̀ àti ohun gbogbo tí ó ní. Láti ìgbà tí ó ti fi Josẹfu jẹ olórí ilé rẹ̀ àti ohun ìní rẹ̀ gbogbo, ni Ọlọ́run ti bẹ̀rẹ̀ sí ní bùkún àwọn ará Ejibiti nítorí Josẹfu. Ìbùkún Olúwa wà lórí gbogbo ohun tí Potifari ní, nílé àti lóko. Ó sì fi Josẹfu ṣe àkóso gbogbo ohun tí ó ní. Kò sì ṣe ìyọnu lórí ohunkóhun mọ àyàfi nípa oúnjẹ tí ó ń jẹ láti ìgbà tí ó ti fi Josẹfu ṣe àkóso ilé e rẹ̀. Josẹfu sì jẹ́ arẹwà ọkùnrin ní ìdúró àti ìrísí rẹ̀, lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, aya rẹ̀ ṣe àkíyèsí Josẹfu, ó sì wí fún un pé, “Wá bá mi lòpọ̀!” Ṣùgbọ́n Josẹfu kọ̀, ó sì wí fún aya ọ̀gá rẹ̀ pé, “Kíyèsi, Olúwa mi kò fi ohunkóhun dù mi nínú ilé yìí, gbogbo ohun ìní rẹ̀ ni ó fi lé mi lọ́wọ́. Kò sí ẹni tí ó jù mi lọ nínú ilé yìí, ọ̀gá mi kò fi ohunkóhun dù mi àyàfi ìwọ, tí í ṣe aya rẹ̀. Báwo ni mo ṣe lè ṣe ohun búburú yìí, kí ń sì ṣẹ̀ sí Ọlọ́run?” Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé gbogbo ìgbà ni ó ń tẹnumọ́ èyí fún Josẹfu, Josẹfu kọ̀ láti bá a lòpọ̀. Ó tilẹ̀ kọ̀ láti máa dúró ni ibi tí ó bá wà. Ní ọjọ́ kan, Josẹfu lọ sínú ilé láti ṣe iṣẹ́, kò sì sí èyíkéyìí nínú àwọn ìránṣẹ́ ní tòsí. Ó sì di aṣọ Josẹfu mú, ó sì wí pé, “Wá bá mi lòpọ̀!” Ṣùgbọ́n Josẹfu fi aṣọ rẹ̀ sílẹ̀ sí i lọ́wọ́, ó sì sá jáde. Nígbà tí ó rí i pé ó ti fi aṣọ rẹ̀ sílẹ̀ sí òun lọ́wọ́, ó sì ti sá jáde, ó pe àwọn ìránṣẹ́ ilé náà, ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ wò ó, ọkọ ọ̀ mi mú Heberu kan wọlé tọ̀ wá wá láti fi wá ṣe ẹlẹ́yà. Ó wọlé tọ̀ mí wá, láti bá mi lòpọ̀, ṣùgbọ́n mo kígbe. Nígbà tí ó gbọ́ pé mo gbé ohùn mi sókè, tí mo sì kígbe, ó jọ̀wọ́ aṣọ rẹ̀ sọ́dọ̀ mi, ó sì sá, ó bọ́ sóde.” Ó sì fi aṣọ náà sọ́dọ̀ títí tí ọkọ rẹ̀ fi dé. Ó rò fún un pé, “Ẹrú ará Heberu tí o rà wá ilé láti fi wá ṣẹlẹ́yà wá láti bá mi lòpọ̀. Ṣùgbọ́n bí mo ti kígbe fún ìrànlọ́wọ́, ó sì sá kúrò nínú ilé.” Nígbà tí Potifari gbọ́ ọ̀rọ̀ aya rẹ̀ pé báyìí ni ẹrú rẹ̀ ṣe sí aya rẹ̀, ó bínú gidigidi. Ó sì ju Josẹfu sí ẹ̀wọ̀n, níbi tí a ń ju àwọn ẹlẹ́wọ̀n ọba sí. Ṣùgbọ́n, nígbà tí Josẹfu wà nínú ẹ̀wọ̀n níbẹ̀, Olúwa sì wà pẹ̀lú rẹ̀, ó sì ṣàánú fún un, ó sì mú kí ó rí ojúrere àwọn alábojútó ọgbà ẹ̀wọ̀n. Nítorí náà, alábojútó ọgbà ẹlẹ́wọ̀n fi Josẹfu ṣe alákòóso ohun gbogbo tí ó wà nínú ẹ̀wọ̀n, àti ohun tí wọn ń ṣe níbẹ̀. Wọ́dà náà kò sì mikàn nípa gbogbo ohun tí ó fi sí abẹ́ àkóso Josẹfu, nítorí pé Olúwa wà pẹ̀lú Josẹfu, ó sì ń jẹ́ kí ó ṣe àṣeyọrí nínú ohun gbogbo tí ó dáwọ́lé. Agbọ́tí àti alásè Kò pẹ́ lẹ́yìn èyí, ni agbọ́tí ọba àti alásè rẹ̀ ṣẹ̀ ọba Ejibiti, olúwa wọn. Farao sì bínú sí méjì nínú àwọn ìjòyè rẹ̀, olórí agbọ́tí àti olórí alásè, Ó sì fi wọ́n sí ìhámọ́ ní ilé olórí ẹ̀ṣọ́, ní inú ẹ̀wọ̀n ibi tí Josẹfu pẹ̀lú wà. Olórí ẹ̀ṣọ́ sì yan Josẹfu láti máa ṣe ìránṣẹ́ wọn. Lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n ti wà ní ìhámọ́ fún ìgbà díẹ̀. Ni ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ọkùnrin méjèèjì náà—olórí agbọ́tí àti olórí alásè ọba Ejibiti, tí a dè sínú túbú, lá àlá ní òru kan náà, àlá kọ̀ọ̀kan sì ní ìtumọ̀ tirẹ̀. Nígbà tí Josẹfu dé ọ̀dọ̀ wọn ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, ó ṣe àkíyèsí pé, inú wọn kò dùn. Ó sì bi àwọn ìjòyè Farao tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ nínú ìhámọ́, nínú ilé olúwa rẹ̀ léèrè pé, “Èéṣe tí ojú yín fi fàro bẹ́ẹ̀ ní òní, tí inú yín kò sì dùn?” Wọ́n wí pé, “Àwa méjèèjì ni a lá àlá, kò sì sí ẹni tí yóò túmọ̀ rẹ̀.” Josẹfu sì wí fún wọn pé, “Ọlọ́run nìkan ni ó ni ìtumọ̀. Ẹ sọ àwọn àlá yín fún mi.” Olórí agbọ́tí sì ṣọ́ àlá rẹ̀ fún Josẹfu, wí pé, “Ní ojú àlá mi, mo rí àjàrà kan (tí wọn ń fi èso rẹ̀ ṣe wáìnì) níwájú mi, mo sì rí ẹ̀ka mẹ́ta lórí àjàrà náà, ó yọ ẹ̀ka tuntun, ó sì tanná, láìpẹ́, ó bẹ̀rẹ̀ sí ní í ní èso tí ó ti pọ́n. Ife Farao sì wà lọ́wọ́ mi, mo sì mú àwọn èso àjàrà náà, mo sì fún un sínú ife Farao, mo sì gbé ife náà fún Farao.” Josẹfu wí fún un pé, “Èyí ni ìtumọ̀ àlá rẹ. Ẹ̀ka mẹ́ta náà dúró fún ọjọ́ mẹ́ta. Láàrín ọjọ́ mẹ́ta Farao yóò mú ọ jáde nínú ẹ̀wọ̀n padà sí ipò rẹ, ìwọ yóò sì tún máa gbé ọtí fún un, gẹ́gẹ́ bí ìṣe rẹ àtẹ̀yìnwá. Ṣùgbọ́n nígbà tí ohun gbogbo bá dára fún ọ, rántí mi kí o sì fi àánú hàn sí mi. Dárúkọ mi fún Farao, kí o sì mú mi jáde kúrò ní ìhín. Nítorí á jí mi gbé tà kúrò ní ilẹ̀ àwọn Heberu ni, àti pé níhìn-ín èmi kò ṣe ohunkóhun tí ó fi yẹ kí èmi wà ní ìhámọ́ bí mo ti wà yìí.” Nígbà tí olórí alásè rí i wí pé ìtumọ̀ tí Josẹfu fún àlá náà dára, ó wí fún Josẹfu pé, “Èmi pẹ̀lú lá àlá, mo ru agbọ̀n oúnjẹ mẹ́ta lórí. Nínú agbọ̀n tí ó wà lókè, onírúurú oúnjẹ ló wà níbẹ̀ fún Farao, ṣùgbọ́n àwọn ẹyẹ sì ń ṣà wọ́n jẹ láti inú apẹ̀rẹ̀ náà tí ó wà lórí mi.” Josẹfu dáhùn, “Èyí ni ìtumọ̀ àlá rẹ. Agbọ̀n mẹ́ta náà túmọ̀ sí ọjọ́ mẹ́ta. Láàrín ọjọ́ mẹ́ta, Farao yóò tú ọ sílẹ̀, yóò sì bẹ́ orí rẹ, yóò sì gbé ara rẹ kọ́ sí orí igi. Àwọn ẹyẹ yóò sì jẹ ara rẹ.” Ọjọ́ kẹta sì jẹ́ ọjọ́ ìbí Farao, ó sì ṣe àsè fún gbogbo àwọn ìjòyè e rẹ̀. Ó sì mú olórí agbọ́tí àti olórí alásè jáde kúrò nínú ẹ̀wọ̀n. Ó dá olórí agbọ́tí padà sí ipò tí ó wà tẹ́lẹ̀, kí ó ba à le máa fi ago lé Farao ní ọwọ́, ṣùgbọ́n, ó so olórí alásè kọ́ sórí igi, gẹ́gẹ́ bí Josẹfu ti sọ fún wọn nínú ìtumọ̀ rẹ̀ sí àlá wọn. Ṣùgbọ́n, olórí agbọ́tí kò rántí Josẹfu mọ́, kò tilẹ̀ ronú nípa rẹ̀. Àwọn àlá Farao Nígbà tí odindi ọdún méjì sì ti kọjá, Farao lá àlá: ó rí ara rẹ̀ tó dúró ní etí odò Naili. Nígbà náà ni màlúù méje jáde láti inú odò, wọ́n dára láti wò, wọ́n sì sanra, wọ́n sì ń jẹ koríko. Lẹ́yìn àwọn wọ̀nyí, ni àwọn màlúù méje mìíràn tí kò lẹ́wà tí ó sì rù jáde wá láti inú odò Naili, wọ́n sì dúró ti àwọn méje tí ó sanra tí ó wà ní bèbè odò náà. Àwọn màlúù tí ó rù, tí kò sì lẹ́wà sì gbé àwọn tí ó lẹ́wà tí ó sanra jẹ. Nígbà náà ni Farao jí. Ó sì tún padà sùn, ó sì lá àlá mìíràn: ó rí síírí ọkà méje tí ó kún, ó yómọ, ó sì dára, ó sì jáde lára igi ọkà kan ṣoṣo. Lẹ́yìn wọn ni síírí ọkà méje mìíràn yọ, wọn kò yómọ, afẹ́fẹ́ ìlà-oòrùn ti rẹ̀ ẹ́ dànù. Àwọn síírí ọkà méje tí kò yómọ (ọmọ rẹ̀ kò tóbi) wọ̀nyí sì gbé àwọn tí ó yómọ (ọmọ rẹ̀ tóbi) mì. Nígbà náà ni Farao jí lójú oorun, ó sì rí i pé àlá ni. Ní òwúrọ̀, ọkàn rẹ̀ dàrú, nítorí náà, ó ránṣẹ́ pe gbogbo àwọn onídán àti ọ̀mọ̀ran ilẹ̀ Ejibiti. Farao rọ́ àlá rẹ̀ fún wọn, ṣùgbọ́n kò rí ọ̀kan nínú wọn tí ó le sọ ìtumọ̀ àlá náà fún un. Nígbà náà ni olórí agbọ́tí wí fún Farao pé, “Lónìí ni mo rántí ẹ̀ṣẹ̀ mi. Nígbà kan tí Farao bínú sí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, tí ó sì fi èmi àti olórí alásè sínú ẹ̀wọ̀n ní ilé olórí ẹ̀ṣọ́. Ọ̀kọ̀ọ̀kan wa lá àlá, àlá kọ̀ọ̀kan sì ní ìtumọ̀ tirẹ̀. Ọmọkùnrin ará Heberu kan tí ó jẹ́ ìránṣẹ́ olórí ẹ̀ṣọ́ wà níbẹ̀ pẹ̀lú wa. A rọ́ àwọn àlá wa fún un, ó sì túmọ̀ wọn fún wa, ó sọ ìtumọ̀ àlá ẹnìkọ̀ọ̀kan fún un. Bí ó sì ti túmọ̀ àlá wọ̀nyí náà ni ohun gbogbo rí. A dá mi padà sí ipò mi, a sì so ọkùnrin kejì kọ́ sórí ọ̀wọ̀n.” Nítorí náà Farao ránṣẹ́ pe Josẹfu, wọn sì mú un wá kíákíá láti inú ìhámọ́. Nígbà tí ó fá irun rẹ̀, tí ó sì pààrọ̀ aṣọ rẹ̀, ó wá síwájú Farao. Farao wí fún Josẹfu, “Mo lá àlá kan, kò sì sí ẹni tí o le è túmọ̀ rẹ̀. Ṣùgbọ́n mo ti gbọ́ nípa rẹ pé bí o bá ti gbọ́ àlá, o le è túmọ̀ rẹ̀.” Josẹfu dá Farao ní ohùn pé, “Kì í ṣe agbára mi, ṣùgbọ́n, Ọlọ́run ni yóò fi ìdáhùn àlàáfíà fún Farao ní ìtumọ̀ àlá náà.” Nígbà náà ni Farao wí fún Josẹfu pé, “Ní inú àlá mi, mo dúró ni etí bèbè odò Naili, sì kíyèsi i, màlúù méje tí ó sanra tí o sì lẹ́wà jáde wá, wọ́n sì ń jẹ koríko ní tòsí ibẹ̀. Lẹ́yìn wọn, màlúù méje mìíràn jáde wá, wọ́n rù hángógó, wọn kò sì lẹ́wà tó bẹ́ẹ̀ tí n kò tí ì rí irú màlúù tí ó ṣe àìlẹ́wà tó bẹ́ẹ̀ rí ní ilẹ̀ Ejibiti. Àwọn màlúù tí ó rù tí kò sì lẹ́wà sì jẹ àwọn màlúù tí ó sanra tí ó kọ́ jáde nínú odò. Ṣùgbọ́n lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n jẹ́ wọ́n tan, kò sì ẹni tí ó le mọ̀ pé wọ́n jẹ ohunkóhun, nítorí wọn kò sanra sí i, wọn sì bùrẹ́wà síbẹ̀. Nígbà náà ni mo tají. “Ní ojú àlá mi, mo tún rí síírí ọkà méje tí ó yó ọmọ tí ó sì dára, wọ́n jáde láti ara igi ọkà kan. Lẹ́yìn wọn, àwọn méje mìíràn yọ jáde, tí kò yó ọmọ bẹ́ẹ̀ ni afẹ́fẹ́ ìlà-oòrùn ti rẹ̀ ẹ́ dànù tán. Àwọn síírí ọkà méje tí kò yómọ sì gbé àwọn méje tí ó dára wọ̀nyí mì. Mo sọ àlá yìí fún àwọn onídán mi, ṣùgbọ́n kò sí ẹni tí ó le túmọ̀ rẹ̀ fún mi.” Nígbà náà ni Josẹfu wí fún Farao, “Ìtumọ̀ kan náà ni àwọn àlá méjèèjì ní. Ọlọ́run fi ohun tí ó fẹ́ ṣe hàn fún Farao. Àwọn màlúù méje ti ó dára jẹ́ ọdún méje, síírí ọkà méje tí ó dára náà sì jẹ́ ọdún méje: ọ̀kan ṣoṣo ni wọn, àlá kan náà ni. Àwọn màlúù méje tí kò sanra, tí kò sì rẹwà tí ó jáde gbẹ̀yìn jẹ́ ọdún méje, bẹ́ẹ̀ náà ni síírí ọkà méje tí kò dára, tí afẹ́fẹ́ ìlà-oòrùn ti rẹ̀ dànù tan, wọn jẹ́ ọdún méje tí ìyàn yóò fi mú. “Bí mo ti wí fún Farao ní ìṣáájú náà ni: Ọlọ́run fi ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ han Farao. Ọdún méje tí oúnjẹ yóò pọ̀ yanturu ń bọ̀ wà ní Ejibiti. Ṣùgbọ́n ọdún méje mìíràn tí ìyàn yóò mú ń bọ̀, nígbà náà ni a ó tilẹ̀ gbàgbé gbogbo ọ̀pọ̀ ní ilẹ̀ Ejibiti, ìyàn yóò sì run gbogbo ilẹ̀ náà. A kò ní rántí àsìkò ọ̀pọ̀ oúnjẹ yanturu náà mọ́ nítorí pé ìyàn tí yóò tẹ̀lé e yóò pọ̀ púpọ̀. Ìdí tí Ọlọ́run fi fi àlá náà han fún Farao ní ọ̀nà méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni pé, Ọlọ́run ti pinnu pé yóò ṣẹlẹ̀ bẹ́ẹ̀ dandan, àti pé kò ni pẹ́ tí Ọlọ́run yóò fi ṣe é. “Ìmọ̀ràn mi ni wí pé, jẹ́ kí Farao wá ọlọ́gbọ́n ènìyàn kan ní ilẹ̀ Ejibiti, kí ó sì fi ṣe alákòóso iṣẹ́ àgbẹ̀ ilẹ̀ Ejibiti. Kí Farao sì yan àwọn alábojútó láti máa gba ìdámárùn-ún ìkórè oko ilẹ̀ Ejibiti ní àsìkò ọdún méje ọ̀pọ̀. Kí wọn kó gbogbo oúnjẹ ilẹ̀ náà ni àwọn ọdún méje ọ̀pọ̀ yìí, kí wọn sì kó àwọn ọkà tí wọn jẹ ṣẹ́kù pamọ́ lábẹ́ àṣẹ Farao. Kí a kó wọn pamọ́ ni àwọn ìlú fún jíjẹ. Kí wọn kó oúnjẹ náà pamọ́ fún orílẹ̀-èdè yìí, kí a ba à le lò ó ni ọdún méje tí ìyàn yóò fi jà ní ilẹ̀ Ejibiti, kí ìyàn náà má ba à pa orílẹ̀-èdè yìí run.” Èrò náà sì dára lójú Farao àti àwọn ìjòyè rẹ̀. Farao sì bi wọ́n pé, “Ǹjẹ́ a le rí ẹnikẹ́ni bi ọkùnrin yìí, nínú ẹni tí ẹ̀mí Ọlọ́run ń gbé?” Nígbà náà ni Farao wí fún Josẹfu, “Níwọ́n bí Ọlọ́run ti fi gbogbo èyí hàn ọ́, kò sí ẹni náà tí ó gbọ́n tí ó sì mọ̀ràn bí i tìrẹ ní ilẹ̀ Ejibiti yìí, ìwọ yóò ṣe àkóso ààfin mi gbogbo àwọn ènìyàn gbọdọ̀ tẹríba fún àṣẹ ẹ̀ rẹ. Ìtẹ́ mi nìkan ni èmi yóò fi jù ọ́ lọ.” Josẹfu di alábojútó ilẹ̀ Ejibiti Farao wí fún Josẹfu pé, “Mo fi ọ́ ṣe alábojútó gbogbo ilẹ̀ Ejibiti.” Farao sì bọ́ òrùka èdìdì ọwọ́ rẹ̀, ó sì fi wọ Josẹfu ó wọ̀ ọ́ ní aṣọ ọ̀gbọ̀ dáradára, ó sì fi ẹ̀gbà tí ó dára sí i lọ́rùn. Ó sì mú un kí ó gun kẹ̀kẹ́-ẹṣin bí igbákejì ara rẹ̀, àwọn ènìyàn sì ń pariwo níwájú rẹ̀ pé, “Ẹ yàgò lọ́nà.” Báyìí ni ó sì fi ṣe alábojútó gbogbo ilẹ̀ Ejibiti. Nígbà náà ni Farao wí fún Josẹfu pé, “Èmi ni Farao. Ṣùgbọ́n láìsí àṣẹ rẹ, ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ ṣe ohunkóhun ní ilẹ̀ Ejibiti.” Farao sì sọ Josẹfu ní orúkọ yìí Safenati-Panea (èyí tí ó túmọ̀ sí ẹni tí ó ni agbára ikú àti ìyè ní ìkáwọ́ bí òrìṣà). Ó sì fun un ní Asenati ọmọ Potifẹra, alábojútó òrìṣà Oni, gẹ́gẹ́ bí aya. Josẹfu sì rin gbogbo ilẹ̀ Ejibiti já. Ọmọ ọgbọ̀n ọdún ni Josẹfu nígbà tí ó wọ iṣẹ́ Farao ọba Ejibiti. Josẹfu sì jáde kúrò níwájú Farao, ó sì ṣe ìbẹ̀wò káàkiri gbogbo ilẹ̀ Ejibiti. Ní ọdún méje ọ̀pọ̀, ilẹ̀ náà so èso lọ́pọ̀lọ́pọ̀. Josẹfu kó gbogbo oúnjẹ tí a pèsè ni ilẹ̀ Ejibiti ní ọdún méje ọ̀pọ̀ yìí, ó sì pa wọ́n mọ́ sí àwọn ìlú. Ní ìlú kọ̀ọ̀kan ni ó kó gbogbo oúnjẹ tí wọ́n gbìn ní àyíká ìlú wọn sí. Josẹfu pa ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọkà mọ́ bí iyanrìn Òkun; ó pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí kò ṣe àkọsílẹ̀ mọ́ nítorí, ó tayọ kíkà. Kí ó tó di pé ọdún ìyàn dé, Asenati ọmọ Potifẹra alábojútó Oni bí ọmọkùnrin méjì fún Josẹfu. Josẹfu sọ orúkọ àkọ́bí rẹ̀ ni Manase, ó sì wí pé, “Nítorí tí Ọlọ́run ti mú mi gbàgbé gbogbo ìdààmú mi àti gbogbo ilé baba mi.” Ó sì sọ orúkọ èkejì ní Efraimu, ó sì wí pé, “Nítorí pé Ọlọ́run fún mi ní ọmọ ní ilẹ̀ ìpọ́njú mi.” Ọdún méje ọ̀pọ̀ oúnjẹ sì wá sí òpin ní ilẹ̀ Ejibiti, ọdún méje ìyàn sì bẹ̀rẹ̀, bí Josẹfu ti wí gan an. Ìyàn sì mú ní gbogbo ilẹ̀ tókù, ṣùgbọ́n oúnjẹ wà ní gbogbo ilẹ̀ Ejibiti. Nígbà tí àwọn ará Ejibiti bẹ̀rẹ̀ sí ní rí ipá ìyàn náà, wọ́n kígbe sí Farao. Nígbà náà ni Farao wí fún wọn pé, “Ẹ lọ bá Josẹfu, ẹ ṣe ohun tí ó bá wí fún un yín.” Nígbà tí ìyàn sì ti tàn ká gbogbo ilẹ̀ náà, Josẹfu ṣí inú àká, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ní ta ọkà fún àwọn ènìyàn, nítorí ìyàn náà mú gan an ní gbogbo ilẹ̀ Ejibiti. Gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè sì ń wá sí Ejibiti láti ra oúnjẹ lọ́wọ́ Josẹfu, nítorí ìyàn náà pọ̀ gidigidi káàkiri gbogbo ayé. Àwọn arákùnrin Josẹfu lọ sí Ejibiti Nígbà tí Jakọbu mọ̀ pé ọkà wà ní Ejibiti, ó wí fún àwọn ọmọ rẹ̀ ọkùnrin pé, “Èéṣe tí ẹ ń wo ara yín lásán?” “Mo tí gbọ́ pé ọkà wà ní ilẹ̀ Ejibiti. Ẹ sọ̀kalẹ̀ lọ sí ibẹ̀ kí ẹ sì rà wá fún wa, kí a má ba à kú.” Nígbà náà ni mẹ́wàá nínú àwọn arákùnrin Josẹfu sọ̀kalẹ̀ lọ sí Ejibiti láti ra ọkà. Ṣùgbọ́n Jakọbu kò rán Benjamini àbúrò Josẹfu lọ pẹ̀lú wọn nítorí ẹ̀rù ń bà á kí aburú má ba à ṣẹlẹ̀ sí i. Nítorí náà, àwọn ọmọ Israẹli wà lára àwọn tó lọ Ejibiti lọ ra oúnjẹ nítorí ìyàn náà mú ni ilẹ̀ Kenaani pẹ̀lú. Nísinsin yìí, Josẹfu ni alábojútó fún gbogbo ilẹ̀ Ejibiti, òun sì ni ó ń bojútó ọkà títà fún gbogbo ènìyàn ìlú náà. Nítorí náà nígbà tí àwọn arákùnrin Josẹfu dé, wọ́n tẹríba, wọ́n sì foríbalẹ̀ fún Josẹfu. Lọ́gán tí Josẹfu ti rí àwọn arákùnrin rẹ̀ ni ó ti dá wọn mọ̀, ṣùgbọ́n ó ṣe bí i wí pé kò mọ̀ wọ́n, ó sì sọ̀rọ̀ líle sí wọn. Ó béèrè pé, “Níbo ni ẹ ti wá?” Wọ́n sì dáhùn pé, “Láti ilẹ̀ Kenaani ni a ti wá ra oúnjẹ.” Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé, Josẹfu mọ àwọn arákùnrin rẹ̀, síbẹ̀ àwọn arákùnrin rẹ̀ kò mọ̀ ọ́n. Nígbà náà ni ó rántí àlá rẹ̀ tí ó lá sí wọn, ó sì wí fún wọn pé, “Amí42.9 tí ó túmọ̀ sí, Ayọ́lẹ̀wò ni yín, ẹ wá láti wo àṣírí ilẹ̀ wa ni.” Wọ́n dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́ olúwa wa, àwọn ìránṣẹ́ rẹ wá láti ra oúnjẹ ni. Ọmọ baba ni wá, olóòtítọ́ ènìyàn sì ni wá pẹ̀lú, àwa kì í ṣe ayọ́lẹ̀wò.” Ó wí fún wọn pé, “Rárá! Ẹ wá láti wo àṣírí ilẹ̀ wa ni.” Ṣùgbọ́n wọ́n tún dáhùn pé, “Arákùnrin méjìlá ni àwa ìránṣẹ́ rẹ, ọmọ baba kan náà, tí ó ń gbé ní ilẹ̀ Kenaani. Èyí tí ó jẹ́ àbíkẹ́yìn wa ń bẹ lọ́dọ̀ baba wa, ọ̀kan sì ti kú.” Josẹfu wí fún wọn pé, “Bí mo ti wí fún un yín náà ni, Ayọ́lẹ̀wò ni yín! Èyí sì ni a ó fi dán an yín wò, èmi búra pé, níwọ̀n ìgbà tí Farao bá wà láààyè, ẹ kì yóò kúrò níbí, àyàfi bí arákùnrin yín kan tókù bá wá sí ibí. Ẹ rán ọ̀kan nínú yín lọ láti mú arákùnrin yín wá, àwa yóò fi ẹ̀yin tókù pamọ́ sínú túbú, kí àwa ba à lè mọ bóyá òtítọ́ ni ẹ̀yin ń wí. Ṣùgbọ́n bí ó bá jẹ́ pé irọ́ ni ẹ̀yin ń pa, ní òtítọ́ bí Farao ti ń bẹ láààyè ayọ́lẹ̀wò ni yín!” Ó sì fi gbogbo wọn sínú túbú fún ọjọ́ mẹ́ta. Ní ọjọ́ kẹta, Josẹfu wí fún wọn pé, “Èyí ni ẹ̀yin yóò ṣe kí ẹ̀yin ba à le yè nítorí mo bẹ̀rù Ọlọ́run. Tí ó bá jẹ́ pé olóòtítọ́ ènìyàn ni yín, ẹ jẹ́ kí ọ̀kan nínú yín dúró ni túbú ní ìhín, nígbà tí àwọn yòókù yín yóò gbé ọkà lọ fún àwọn ará ilé e yín tí ebi ń pa. Ṣùgbọ́n ẹ gbọdọ̀ mú arákùnrin tí ó jẹ́ àbíkẹ́yìn yín wá, kí n ba à le mọ òtítọ́ ohun ti ẹ ń wí, kí ẹ má ba à kú.” Wọn sì gbà láti ṣe èyí. Wọ́n ń sọ ọ́ láàrín ara wọn wí pé, “Àwa jẹ̀bi nítòótọ́ nípa ti arákùnrin wa. A rí ìbànújẹ́ ọkàn rẹ̀ nígbà tí ó ń bẹ̀ wá nítorí ẹ̀mí rẹ̀, ṣùgbọ́n a kò gbẹ́bẹ̀, nítorí náà ni ìdààmú yìí fi dé bá wa.” Reubeni dá wọn ní ohùn pé, “Èmi kò wí fún yín pé kí ẹ má se ṣẹ̀ sí ọmọdékùnrin náà? Ṣùgbọ́n ẹ kò gbọ́! Ṣùgbọ́n nísinsin yìí a ń béèrè ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ lọ́wọ́ wa.” Wọn kò sì mọ̀ pé, Josẹfu ń gbọ́ wọn ní àgbọ́yé nítorí ògbufọ̀ ni ó ń lò tẹ́lẹ̀. Ó yípadà kúrò lọ́dọ̀ wọn, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ní sọkún. Ó sì tún yí padà sí wọn, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ní sọ̀rọ̀. Ó mú Simeoni kúrò láàrín wọn, ó sì dè é ní ojú wọn. Josẹfu pàṣẹ pé kí wọn bu ọkà kún inú àpò wọn, kí wọn sì mú owó ẹnìkọ̀ọ̀kan padà sínú àpò rẹ̀, kí wọn sì fún wọn ní ohun tí wọn yóò lò nírín-àjò wọn padà sílé. Lẹ́yìn ìgbà tí a ti ṣe èyí fún wọn, wọn gbé ẹrù wọn lé kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, wọn sì padà lọ sí ilé. Níbi tí wọ́n ti dúró láti sùn lóru ọjọ́ náà, ọ̀kan nínú wọn tú àpò rẹ̀ láti mú oúnjẹ fún kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀, ó sì rí owó rẹ̀ ní ẹnu àpò rẹ̀. Ó sì wí fún àwọn arákùnrin rẹ̀ pé, “a ti dá owó mi padà, òun nìyí ní ẹnu àpò mi.” Ẹ̀rù bà wọ́n, wọ́n sì ń gbọ̀n, wọ́n sì wí pé, “Èwo nìyí tí Ọlọ́run ṣe sí wa yìí.” Nígbà tí wọ́n padà dé ọ̀dọ̀ Jakọbu baba wọn ní ilẹ̀ Kenaani, wọ́n ròyìn gbogbo ohun tí ó ṣẹlẹ̀ fún un wí pé, “Ọkùnrin náà tí í ṣe alábojútó ilẹ̀ náà, sọ̀rọ̀ líle sí wa, ó sì fi ẹ̀sùn kàn wá pé a wá yọ́ ilẹ̀ náà wò ni. Ṣùgbọ́n, a wí fún un pé, ‘Rárá o, olóòtítọ́ ènìyàn ni wá, a kì í ṣe ayọ́lẹ̀wò. Arákùnrin méjìlá ni wá, ọmọ baba kan náà, ọ̀kan ti kú, èyí tí ó jẹ́ àbíkẹ́yìn wà lọ́dọ̀ baba wa ni ilẹ̀ Kenaani.’ “Nígbà náà ni ọkùnrin tí ó jẹ́ alábojútó ilẹ̀ náà wí fún wa pé, ‘Báyìí ni n ó ṣe mọ̀ bóyá olóòtítọ́ ènìyàn ni yín, ẹ fi ọ̀kan nínú àwọn arákùnrin yín sílẹ̀ níbí, pẹ̀lú mi, ẹ sì mú oúnjẹ lọ fún àwọn ará ilé yín tí ebi ń pa kú lọ, lọ́wọ́ ìyàn. Ṣùgbọ́n ẹ mú arákùnrin yín tí ó kéré jùlọ wá fún mi kí n le mọ̀ pé dájúdájú ẹ kì í ṣe ayọ́lẹ̀wò bí kò ṣe ènìyàn tòótọ́. Nígbà náà ni n ó mú arákùnrin yín padà fún un yín, lẹ́yìn náà ẹ le máa wá ṣe òwò bí ó ti wù yín ní ilẹ̀ yìí.’ ” Bí wọ́n sì ti ń tú àpò ẹrù wọn, ẹnìkọ̀ọ̀kan bá owó tí ó san fún ọjà náà lẹ́nu àpò rẹ̀! Ẹ̀rù sì bà wọ́n gidigidi, àwọn àti baba wọn. Jakọbu baba wọn wí fún wọn pé, “Ẹ ti mú mi pàdánù àwọn ọmọ mi. N kò rí Josẹfu mọ́, bẹ́ẹ̀ ni n kò sì rí Simeoni náà mọ. Ẹ sì tún fẹ́ mú Benjamini lọ. Èmi ni gbogbo ohun búburú yìí wá ń ṣẹlẹ̀ sí!” Nígbà náà ni Reubeni wí fún baba rẹ̀ pé, “Pa àwọn ọmọ mi méjèèjì bí n kò bá mú Benjamini padà wá fún ọ, èmi ni kí o fà á lé lọ́wọ́, n ó sì mu un padà wá.” Ṣùgbọ́n Jakọbu wí pé, “Ọmọ mi kì yóò bá a yín lọ, ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ti kú, òun nìkan sì ni ó kù nínú àwọn ọmọ ìyá rẹ̀. Bí ohunkóhun bá ṣẹlẹ̀ sí i, ìbànújẹ́ ni yóò sì pa mi kú ni ọjọ́ ogbó mi yìí.” Ìrìnàjò ẹ̀ẹ̀kejì lọ sí Ejibiti Báyìí, ìyàn náà sì mú gidigidi ní ilẹ̀ náà. Nígbà tí wọ́n sì ti jẹ gbogbo ọkà tí wọ́n rà ní Ejibiti tan, baba wọn wí fún wọn pé, “Ẹ padà lọ ra oúnjẹ díẹ̀ si wá fún wa.” Ṣùgbọ́n Juda wí fún un pé, “Ọkùnrin náà tẹnumọ́ ọn nínú ìkìlọ̀ rẹ̀ fún wa pé, ‘Ẹ̀yin kì yóò rí ojúrere mi mọ́, àyàfi bí arákùnrin yín bá bá a yín wá’. Tí ìwọ yóò bá rán Benjamini arákùnrin wa lọ pẹ̀lú wa, a ó lọ ra oúnjẹ wá fún ọ. Ṣùgbọ́n bí ìwọ kò bá ni jẹ́ kí ó bá wa lọ, àwa kì yóò lọ, nítorí ọkùnrin náà sọ fún wa pé, ‘Ẹ̀yin kì yóò rí ojúrere mi mọ́ àyàfi bí arákùnrin yín bá bá a yín wá.’ ” Israẹli béèrè pé, “Èéṣe tí ẹ fi kó ìdààmú yìí bá mi nípa sísọ fún ọkùnrin náà wí pé ẹ ní arákùnrin mìíràn?” Wọ́n dáhùn pé, “Ọkùnrin náà fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ wádìí lọ́wọ́ wa nípa ìdílé wa àti àwa fúnra wa. Ó béèrè pé, ‘Ṣe baba yín ṣì wà láààyè? Ǹjẹ́ ẹ tún ní arákùnrin mìíràn?’ A kàn dáhùn ìbéèrè rẹ̀ ni. Báwo ni a ṣe le mọ̀ pé yóò wí pé, ‘Ẹ mú arákùnrin yín wá’?” Juda sì wí fún Israẹli baba rẹ̀, “Jẹ́ kí ọmọkùnrin náà lọ pẹ̀lú mi, a ó sì lọ ní kíákíá, kí àwa àti ìwọ àti àwọn ọmọ wa le yè, kí a má sì kú. Èmi fúnra mi yóò ṣe onídùúró fún un, èmi ni kí o gbà pé o fi lé lọ́wọ́. Bí n kò bá sì mú un padà tọ̀ ọ́ wá, jẹ́ kí ẹ̀bi rẹ̀ kí ó jẹ́ tèmi ní gbogbo ọjọ́ ayé mi níwájú rẹ. Bí ó bá ṣe pé a kò fi falẹ̀ ni, àwa ìbá ti lọ, à bá sì ti padà ní ìgbà méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀.” Nígbà náà ni Israẹli baba wọn wí fún wọn, “Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, èyí ni kí ẹ ṣe, ẹ mú àwọn ohun dáradára ilẹ̀ yìí lọ́wọ́ lọ bí ẹ̀bùn fún ọkùnrin náà—ìkunra díẹ̀, oyin díẹ̀, tùràrí àti òjìá, èso pisitakio àti èso almondi ìlọ́po owó méjì ni kí ẹ mú lọ́wọ́, nítorí ẹ gbọdọ̀ dá owó tí ẹ bá lẹ́nu àpò yín padà. Bóyá ẹnìkan ló ṣèèṣì fi síbẹ̀. Ẹ mú arákùnrin yín lọ́wọ́ pẹ̀lú ki ẹ sì tọ arákùnrin náà lọ. Kí Ọlọ́run alágbára jẹ́ kí ẹ rí àánú gbà lọ́dọ̀ ọkùnrin náà kí ó ba à le jẹ́ kí arákùnrin yín tí ó wà lọ́hùn ún àti Benjamini padà wá pẹ̀lú yín. Ní tèmi, bí mo bá pàdánù àwọn ọmọ mi, n ó ṣọ̀fọ̀ wọn náà ni.” Nítorí náà wọ́n mú àwọn ẹ̀bùn náà àti owó ìlọ́po méjì àti Benjamini, wọ́n sì yára lọ sí ilẹ̀ Ejibiti, wọ́n sì fi ara wọn hàn níwájú Josẹfu. Nígbà tí Josẹfu rí Benjamini pẹ̀lú wọn, ó sọ fún ìránṣẹ́ ilé rẹ̀, “Mú àwọn ọkùnrin wọ̀nyí lọ sí ilé mi, pa ẹran kí o sì ṣe àsè; wọn ó jẹun ọ̀sán pẹ̀lú mi.” Ọkùnrin náà sì ṣe bí Josẹfu ti wí fún un, ó sì mú àwọn ọkùnrin náà lọ sí ilé Josẹfu. Ẹ̀rù sì ba àwọn ọkùnrin náà nígbà tí wọ́n mú wọn lọ sí ilé Josẹfu. Wọ́n rò ó pé, “A mú wa wá sí ìhín nítorí owó tí a fi sí inú àpò wa ní ìgbà àkọ́kọ́. Ó fẹ́ bá wa jà, kí ó mú wa lẹ́rú kí ó sì gba àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wa.” Nítorí náà wọ́n lọ bá ìránṣẹ́ Josẹfu, wọ́n sì ba sọ̀rọ̀ ní ẹnu-ọ̀nà àbáwọlé ilé náà. Wọ́n wí pé, “Jọ̀wọ́ ọ̀gá, ní òtítọ́ ni àwa ti sọ̀kalẹ̀ síyìn-ín láti wá ra oúnjẹ ní ìṣáájú. Ṣùgbọ́n níbi tí a ti dúró ní ọ̀nà láti sùn ní alẹ́, nígbà tí a tú àpò oúnjẹ wa, ẹnìkọ̀ọ̀kan wa bá owó oúnjẹ tirẹ̀ tí ó rà lẹ́nu àpò láì lé, láì dín. Nítorí náà òun nìyí, a ti mu un padà wá pẹ̀lú wa. A sì tún mú owó mìíràn lọ́wọ́ láti fi ra oúnjẹ. A ò mọ ẹni tí ó fi owó wa sí ẹnu àpò.” Ó sì wí fún wọn pé, “Àlàáfíà ni fún yín, ẹ má bẹ̀rù, Ọlọ́run yín, àní Ọlọ́run baba yín ni ó fi ìṣúra sí inú àpò yín; mo rí owó tí ẹ san gbà.” Nígbà náà ni ó mú Simeoni jáde tọ̀ wọ́n wá. Ìránṣẹ́ náà mú àwọn ọkùnrin náà lọ sí ilé Josẹfu, ó fún wọn ní omi láti fi wẹ ẹsẹ̀ wọn nu, ó sì fún àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọn lóúnjẹ pẹ̀lú. Wọ́n pèsè ẹ̀bùn wọn sílẹ̀ fún Josẹfu di ọ̀sán nígbà tí yóò dé, nítorí wọ́n ti gbọ́ pé ibẹ̀ ni àwọn yóò ti jẹun ọ̀sán. Nígbà tí Josẹfu dé sí ilé, wọ́n kó àwọn ẹ̀bùn tí wọ́n ti mú wá fún un, wọ́n sì wólẹ̀ níwájú rẹ̀. Ó béèrè àlàáfíà wọn, ó sì wí pé, “Ṣé àlàáfíà ni baba yín wà, baba arúgbó tí ẹ sọ̀rọ̀ rẹ̀ fún mi, ṣé ó sì wà láààyè?” Wọ́n dáhùn pé, “Ìránṣẹ́ rẹ, baba wa sì wà láààyè, àlàáfíà sì ni ó wà pẹ̀lú.” Wọn sì tẹríba láti bọ̀wọ̀ fún un. Bí ó ti wò yíká tí ó sì rí Benjamini àbúrò rẹ̀, tí í ṣe ọmọ ìyá rẹ̀ gan an. Ó béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Ṣe àbúrò yín tí ó jẹ́ àbíkẹ́yìn tí ẹ sọ fún mi nípa rẹ̀ nìyìí?” Ó sì tún wí pe, “Kí Ọlọ́run kí ó ṣàánú fún ọ, ọmọ mi.” Ọkàn rẹ̀ sì fà sí i gidigidi nígbà tí ó rí arákùnrin rẹ̀, nítorí náà Josẹfu yára jáde láti wá ibi tí ó ti le sọkún. Ó lọ sí iyàrá rẹ̀, ó sì sọkún níbẹ̀. Lẹ́yìn ìgbà tí ó ti bọ́jú tan, ó jáde wá, ó ṣe ọkàn ọkùnrin, ó sì wí fún wọn pé, kí wọ́n gbé oúnjẹ wá kí wọ́n le è jẹun. Wọ́n gbé oúnjẹ tirẹ̀ fún un lọ́tọ̀, àti fún àwọn ará Ejibiti tí ó wá ba jẹun náà lọ́tọ̀, nítorí ará Ejibiti kò le bá ará Heberu jẹun nítorí ìríra pátápátá ló jẹ́ fún àwọn Ejibiti. A mú àwọn ọkùnrin náà jókòó lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀, bí wọ́n ṣe dàgbà sí, láti orí ẹ̀gbọ́n pátápátá dé orí èyí tí ó kéré pátápátá, wọ́n sì ń wo ara wọn tìyanu tìyanu. A sì bu oúnjẹ fún wọn láti orí tábìlì Josẹfu. Oúnjẹ Benjamini sì tó ìlọ́po márùn-ún ti àwọn tókù. Wọ́n ń jẹ, wọ́n sì ń mu lọ́dọ̀ rẹ̀ láìsí ìdíwọ́. Kọ́ọ̀bù idẹ nínú àpò Nígbà náà ni Josẹfu pàṣẹ fún ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, “Di oúnjẹ kún inú àpò àwọn ọkùnrin náà tó ìwọ̀n èyí tí wọ́n le rù, kí o sì mú owó olúkúlùkù àwọn ọkùnrin náà padà sí ẹnu àpò rẹ̀. Nígbà náà ni kí o mú kọ́ọ̀bù idẹ mi sí ẹnu àpò èyí tí ó jẹ́ àbíkẹ́yìn nínú wọn pẹ̀lú owó tí ó fi ra ọkà,” ó sì ṣe bí Josẹfu ti sọ. Bí ilẹ̀ ti ń mọ́, wọ́n bẹ̀rẹ̀ ìrìnàjò wọn padà lọ pẹ̀lú kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọn. Wọn kò tí ì rìn jìnnà sí ìlú náà tí Josẹfu fi wí fún ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, “Lépa àwọn ọkùnrin náà, nígbà tí o bá sì bá wọn, kí o wí pé, ‘Èéṣe ti ẹ fi búburú san rere? Èyí ha kọ́ ni kọ́ọ̀bù tí olúwa mi ń lò fún ohun mímu tí ó sì tún ń fi í ṣe àyẹ̀wò? Ohun tí ẹ ṣe yìí burú púpọ̀.’ ” Nígbà tí ó sì bá wọn, o sọ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí fún wọn. Ṣùgbọ́n wọ́n dá a lóhùn pé, “Kí ló dé tí olúwa mi sọ irú nǹkan wọ̀nyí? Ká má rí i! Àwọn ìránṣẹ́ rẹ kò le ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀! A tilẹ̀ mú owó tí a rí lẹ́nu àpò wa padà tọ̀ ọ́ wá láti ilẹ̀ Kenaani. Nítorí náà èéṣe tí àwa yóò fi jí wúrà tàbí idẹ ní ilé olúwa à rẹ? Bí a bá rí i lọ́wọ́ èyíkéyìí nínú àwọn ìránṣẹ́ rẹ, kíkú ni yóò kú, àwọn tí ó kù yóò sì di ẹrú fún olúwa à rẹ.” Ó wí pé, “Ó dára, kí ó rí bí ẹ ti ṣe sọ. Ẹnikẹ́ni tí mo bá rí i lọ́wọ́ rẹ̀ yóò di ẹrú mi. Ẹ̀yin tí ó kù yóò sì wà láìlẹ́bi.” Olúkúlùkù wọn yára sọ àpò rẹ̀ kalẹ̀, wọ́n sì tú u. Nígbà náà ni ìránṣẹ́ náà bẹ̀rẹ̀ sí ní í wá a, bẹ̀rẹ̀ láti orí ẹ̀gbọ́n títí lọ sórí àbúrò pátápátá. Ó sì rí kọ́ọ̀bù náà nínú àpò ti Benjamini. Nígbà tí wọ́n rí èyí, wọ́n fa aṣọ wọn ya, wọ́n sì banújẹ́ gidigidi, wọn tún ẹrù wọn dì sórí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, wọ́n sì padà sí inú ìlú. Josẹfu sì wà nínú ilé nígbà tí Juda àti àwọn arákùnrin rẹ̀ wọlé wá. Gbogbo wọn sì wólẹ̀ níwájú rẹ̀. Josẹfu wí fún wọn pé, “Èwo ni èyí tí ẹ ṣe yìí? Ṣe ẹ kò mọ pé, ènìyàn bí èmi le è rí ìdí nǹkan nípa ṣíṣe àyẹ̀wò?” Juda dáhùn pé, “Kí ni à bá sọ fún olúwa mi? Báwo ni a ṣe lè wẹ ara wa mọ́? Ọlọ́run ti tú àṣírí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, a ti di ẹrú olúwa à mi báyìí àwa fúnra wa àti ẹni náà tí a rí kọ́ọ̀bù lọ́wọ́ rẹ̀.” Ṣùgbọ́n Josẹfu dáhùn pé, “Ká má rí i pé mo ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀! Ẹni tí a bá kọ́ọ̀bù mi lọ́wọ́ rẹ̀ nìkan ni yóò di ẹrú mi, ẹ̀yin tí ó kù, ẹ máa lọ sọ́dọ̀ baba yín ní àlàáfíà.” Nígbà náà ni Juda súnmọ́ ọ̀dọ̀ rẹ̀, ó sì wí pé, “Jọ̀wọ́ olúwa mi, jẹ́ kí ìránṣẹ́ rẹ kí ó sọ ọ̀rọ̀ kan fún olúwa mi, má ṣe bínú sí ìránṣẹ́ rẹ bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé ìwọ pẹ̀lú láṣẹ bí i ti Farao. Olúwa mi béèrè lọ́wọ́ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, ‘Ǹjẹ́ ó ní baba tàbí arákùnrin?’ Àwa sì wí fún olúwa mi pé, ‘A ni baba tí ó ti darúgbó, ọmọkùnrin kan sì wà pẹ̀lú tí a bí fún un ní ọjọ́ ogbó rẹ̀. Ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ti kú, òun nìkan sì ni ó kù nínú àwọn ọmọ ìyá rẹ̀, baba rẹ̀ sì fẹ́ràn án rẹ̀.’ “Nígbà náà ni ó sọ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, ‘Ẹ mu un tọ̀ mí wá kí n le fojú ara mi rí i.’ A sì sọ fún olúwa à mi pé, ‘Ọmọkùnrin náà kò le è fi baba rẹ̀ sílẹ̀, bí ó bá dán an wò baba rẹ̀ yóò kú.’ Ṣùgbọ́n ìwọ wí fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, ‘Ẹ má ṣe padà tọ̀ mí wá àyàfi bí àbíkẹ́yìn yín bá bá yín wá.’ Nígbà tí a padà lọ sọ́dọ̀ baba wa, tí í ṣe ìránṣẹ́ rẹ, a sọ ohun tí olúwa à mi wí fún un. “Nígbà náà ni baba wa wí pé, ‘Ẹ padà lọ láti lọ ra oúnjẹ díẹ̀ wá.’ Ṣùgbọ́n a wí pe, ‘Àwa kò le è padà lọ, àyàfi bí àbúrò wa pátápátá yóò bá bá wa lọ. A kò le è rí ojú ọkùnrin náà àyàfi tí àbúrò wa bá lọ pẹ̀lú wa.’ “Baba mi, ìránṣẹ́ rẹ wí fún wa pé, ‘Ẹ mọ̀ pé ìyàwó mi bí ọmọkùnrin méjì fún mi. Ọ̀kan nínú wọn lọ kúrò lọ́dọ̀ mi, mo sì wí pé, “Dájúdájú a ti fà á ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ.” N kò sì tí ì ri láti ọjọ́ náà. Tí ẹ bá tún mú èyí lọ, kúrò lọ́dọ̀ mi, tí ohunkóhun bá ṣe é, ìbànújẹ́ ni ẹ ó fi mú ewú orí mi lọ sí ipò òkú.’ “Nítorí náà, bí a bá padà tọ baba wa lọ láìsí ọmọ náà pẹ̀lú wa nígbà tí a mọ̀ pé, ọmọ náà ni ẹ̀mí baba wa. Tí ó bá ri pé ọmọkùnrin náà kò wá pẹ̀lú wa, yóò kùú. Àwọn ìránṣẹ́ rẹ yóò wá mú baba wa tòun ti ewú orí lọ sí ipò òkú ní ìbànújẹ́. Ìránṣẹ́ rẹ ló ṣe onídùúró fún ààbò ọmọ náà lọ́dọ̀ baba mi. Mo wí pé, ‘Bí n kò bá mú un padà tọ̀ ọ́ wá, baba mi, èmi ó ru ẹ̀bi rẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ ayé mi!’ “Nítorí náà, jẹ́ kí ìránṣẹ́ rẹ kí ó dúró ní ìhín lọ́dọ̀ olúwa à mi bí ẹrú dípò ọmọ náà. Kí ọmọ náà bá àwọn arákùnrin rẹ̀ padà. Báwo ni mo ṣe lè padà tọ baba mi lọ láì bá ṣe pé ọmọ náà wà pẹ̀lú mi? Rárá, èmi kò fẹ́ kí n rí ìbànújẹ́ tí yóò dé bá baba mi.” Josẹfu fi ara rẹ̀ hàn fún àwọn arákùnrin rẹ̀ Josẹfu kò sì le è pa á mọ́ra mọ́ níwájú gbogbo àwọn tí ó dúró tì í. Ó sì sọkún sókè tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn tí ó wà ní àyíká gbọ́ ohun ẹkún rẹ̀. “Jẹ́ kí gbogbo ènìyàn kúrò ní ọ̀dọ̀ mi.” Kò sì sí ẹnikẹ́ni lọ́dọ̀ rẹ̀ nígbà tí ó fi ara rẹ̀ hàn fún àwọn arákùnrin rẹ̀. Ó sì sọkún sókè kíkankíkan tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn Ejibiti gbọ́ ohùn ẹkún rẹ̀, àwọn ilé Farao pẹ̀lú sì gbọ́ nípa rẹ̀. Josẹfu wí fún àwọn arákùnrin rẹ̀ pé, “Èmi ni Josẹfu! Ṣe baba mi sì wà láààyè?” Ṣùgbọ́n àwọn arákùnrin rẹ̀ kò le è dá a lóhùn nítorí ẹ̀rù bà wọ́n gidigidi, ẹnu sì yà wọ́n níwájú rẹ̀. Nígbà náà ni Josẹfu wí fún àwọn arákùnrin rẹ̀ pé, “Ẹ súnmọ́ ọ̀dọ̀ mi.” Nígbà tí wọ́n sì ti ṣe bẹ́ẹ̀, ó wí pé, “Èmi ni Josẹfu arákùnrin yín tí ẹ tà sí ilẹ̀ Ejibiti! Ṣùgbọ́n báyìí, ẹ má ṣe banújẹ́, ẹ má sì ṣe bínú sí ara yín ní títà tí ẹ tà mí sí ìhín, nítorí, ọ̀nà àti gba ẹ̀mí yín là ni Ọlọ́run ṣe rán mi sí ìhín ṣáájú yín. Ìyàn tí ó ti mú láti ọdún méjì sẹ́yìn yìí yóò tẹ̀síwájú fún ọdún márùn-ún sí i nínú èyí tí ẹnikẹ́ni kò ní gbìn, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ni kórè. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run rán mi ṣáájú yín sí ìhín láti da irú-ọmọ yín sí fún un yín lórí ilẹ̀ ayé àti láti fi ìgbàlà ńlá gba ẹ̀mí yín là. “Nítorí náà, kì í ṣe ẹ̀yin ni ó rán mi wá sí ibí yìí, bí kò ṣe Ọlọ́run. Ó fi mí ṣe baba, Olùdámọ̀ràn fún Farao, olúwa fún gbogbo ilé Farao àti alákòóso gbogbo ilẹ̀ Ejibiti. Nísinsin yìí, ẹ yára padà sọ́dọ̀ baba mi kí ẹ sì wí fun un pé, èyí ni ohun tí Josẹfu ọmọ rẹ wí, Ọlọ́run ti fi mí ṣe olúwa fún gbogbo ilẹ̀ Ejibiti, ẹ sọ̀kalẹ̀ wá láì jáfara. Ìwọ yóò gbé ní agbègbè Goṣeni, ìwọ kì yóò jìnnà sí mi, àwọn ọmọ rẹ àti àwọn ọmọ ọmọ rẹ, àwọn agbo ẹran rẹ àti agbo màlúù rẹ àti gbogbo ohun tí ìwọ ní. Èmi yóò pèsè fún yín níbẹ̀. Nítorí ó ṣì ku ọdún márùn-ún gbáko ti ìyàn yóò fi mú. Kí ìwọ àti ilé rẹ àti ohun tí í ṣe tìrẹ má ba à di aláìní. “Ẹ̀yin fúnra yín àti Benjamini arákùnrin mi pẹ̀lú rí i pé, lóòótọ́ lóòótọ́, èmi Josẹfu ni mo ń bá a yín sọ̀rọ̀. Ẹ sọ fún baba mi nípa gbogbo ọlá tí a fún mi ní ilẹ̀ Ejibiti àti ohun gbogbo tí ẹ̀yin ti rí, kí ẹ sì mú baba mi tọ̀ mí wá sí ìhín yìí kíákíá.” Nígbà náà ni ó dì mọ́ Benjamini arákùnrin rẹ̀, ó sì sọkún, Benjamini náà sì dì mọ́ ọn, pẹ̀lú omijé lójú. Ó sì tún fẹnu ko gbogbo àwọn arákùnrin rẹ̀ lẹ́nu, ó sì sọkún sí wọn lára. Lẹ́yìn èyí, Josẹfu àti àwọn arákùnrin rẹ̀ sọ̀rọ̀ pọ̀. Nígbà tí ìròyìn náà dé ààfin Farao pé àwọn arákùnrin Josẹfu dé, inú Farao àti àwọn ìjòyè rẹ̀ dùn. Farao wí fún Josẹfu pé, “Wí fún àwọn arákùnrin rẹ pé, ‘Èyí ni kí ẹ ṣe, ẹ di ẹrù lé ẹranko yín kí ẹ sì padà sí ilẹ̀ Kenaani, kí ẹ sì mú baba yín àti ìdílé yín tọ̀ mí wá. Èmi yóò fún un yín ní ibi tí ó dára jùlọ ní ilẹ̀ Ejibiti, ẹ̀yin yóò sì le è gbádùn ilẹ̀ yìí.’ “A pàṣẹ fún ọ láti sọ fún wọn pé, ‘Ẹ ṣe èyí. ẹ mú kẹ̀kẹ́ ẹrù láti ilẹ̀ Ejibiti fún àwọn ọmọ yín àti àwọn aya yín. Kí ẹ sì mú baba yín tọ mí wá. Ẹ má ṣe àníyàn nípa ohun ìní yín nítorí èyí tí ó dára jù nínú ilẹ̀ Ejibiti yóò jẹ́ tiyín.’ ” Àwọn ọmọ Israẹli sì ṣe èyí. Josẹfu fún wọn ni kẹ̀kẹ́ ẹrù bí Farao ti pàṣẹ, ó sì fún wọn ní oúnjẹ fún ìrìnàjò wọn pẹ̀lú. Ó fún ẹni kọ̀ọ̀kan wọn ní aṣọ tuntun. Ṣùgbọ́n Benjamini ni ó fún ní ọ̀ọ́dúnrún (300) ẹyọ owó idẹ fàdákà àti ìpààrọ̀ aṣọ márùn-ún. Àwọn nǹkan wọ̀nyí ni ó kó ránṣẹ́ sí baba rẹ̀: kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ mẹ́wàá tí ó ru àwọn ohun mèremère ilẹ̀ Ejibiti àti abo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ mẹ́wàá tí ó ru ọkà àti oríṣìíríṣìí oúnjẹ. Nígbà náà ni ó rán àwọn arákùnrin rẹ̀ lọ, bí wọ́n ṣe ń pínyà, ó wí fún wọn pé, “Ẹ má ṣe jà ní ọ̀nà o!” Báyìí ni wọ́n jáde kúrò ní ilẹ̀ Ejibiti wá sí ọ̀dọ̀ Jakọbu baba wọn ní ilẹ̀ Kenaani. Wọn wí fún un pé, “Josẹfu ṣì wà láààyè! Kódà òun ni alákòóso ilẹ̀ Ejibiti.” Ẹnu ya Jakọbu, kò sì gbà wọ́n gbọ́. Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n sọ ohun gbogbo tí Josẹfu ti sọ fún wọn fún un tí ó sì rí kẹ̀kẹ́ ẹrù tí Josẹfu fi ránṣẹ́ láti gbé e padà wá, iyè Jakọbu, baba wọn sọ. Israẹli sì wí pé, “Mo gbà dájúdájú wí pé, Josẹfu ọmọ mi wà láààyè. Èmi ó lọ rí i kí n tó kú.” Jakọbu lọ sí Ejibiti Báyìí ni Israẹli mú ìrìnàjò rẹ̀ pọ̀n pẹ̀lú ohun gbogbo tí ó ní, nígbà tí ó sì dé Beerṣeba, ó rú ẹbọ sí Ọlọ́run Isaaki baba rẹ̀. Ọlọ́run sì bá Israẹli sọ̀rọ̀ ní ojú ìran ní òru pé, “Jakọbu! Jakọbu!” Ó sì dáhùn pé, “Èmi nìyí.” Ọlọ́run sì wí pé, “Èmi ni Ọlọ́run, Ọlọ́run baba rẹ, má ṣe bẹ̀rù láti sọ̀kalẹ̀ lọ sí ilẹ̀ Ejibiti nítorí, èmi yóò sọ ọ́ di orílẹ̀-èdè ńlá níbẹ̀. Èmi yóò sì sọ̀kalẹ̀ pẹ̀lú rẹ lọ sí Ejibiti, èmi yóò sì tún mú ọ padà wá. Ọwọ́ Josẹfu fúnra rẹ̀ ni ìwọ yóò sì kú sí.” Nígbà náà ni Jakọbu kúrò ní Beerṣeba, àwọn ọmọ Israẹli sì mú Jakọbu baba wọn àti àwọn aya wọn àti àwọn ọmọ wọn, wọ́n sì kó wọn sí inú kẹ̀kẹ́ ẹrù tí Farao fi ránṣẹ́ fún ìrìnàjò rẹ̀. Wọ́n tún kó àwọn ohun ọ̀sìn wọn àti gbogbo ohun ìní tí wọ́n ti ní láti ilẹ̀ Kenaani, Jakọbu àti gbogbo irú-ọmọ rẹ̀ sọ̀kalẹ̀ lọ sí Ejibiti. Ó kó àwọn ọmọ rẹ̀ ọkùnrin pẹ̀lú àwọn ọmọ ọmọ rẹ̀ ọkùnrin, àwọn ọmọ rẹ̀ obìnrin pẹ̀lú àwọn ọmọ ọmọ rẹ̀ obìnrin, gbogbo irú-ọmọ rẹ̀ lọ sí Ejibiti. Èyí ni orúkọ àwọn ọmọ Israẹli (Jakọbu àti ìran rẹ̀) tí ó sọ̀kalẹ̀ lọ Ejibiti: Reubeni àkọ́bí Jakọbu. Àwọn ọmọkùnrin Reubeni: Hanoku, Pallu, Hesroni àti Karmi. Àwọn ọmọkùnrin Simeoni: Jemueli, Jamini, Ohadi, Jakini, Sohari àti Saulu, tí ìyá rẹ̀ jẹ́ ọmọbìnrin ará Kenaani. Àwọn ọmọkùnrin Lefi: Gerṣoni, Kohati àti Merari. Àwọn ọmọkùnrin Juda: Eri, Onani, Ṣela, Peresi àti Sera (ṣùgbọ́n Ẹri àti Onani ti kú ní ilẹ̀ Kenaani). Àwọn ọmọ Peresi: Hesroni àti Hamulu. Àwọn ọmọkùnrin: Isakari! Tola, Pua, Jaṣibu àti Ṣimroni. Àwọn ọmọkùnrin Sebuluni: Seredi, Eloni àti Jahaleli. Wọ̀nyí ni àwọn ọmọkùnrin Lea tí ó bí fún Jakọbu ní Padani-Aramu yàtọ̀ fún Dina ọmọbìnrin rẹ̀. Àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ àti ọmọbìnrin rẹ̀ wọ̀nyí jẹ́ mẹ́tàlélọ́gbọ̀n (33) lápapọ̀. Àwọn ọmọkùnrin Gadi: Sefoni, Haggi, Ṣuni, Esboni, Eri, Arodi, àti Areli. Àwọn ọmọkùnrin Aṣeri: Imina, Iṣifa, Iṣfi àti Beriah. Arábìnrin wọn ni Sera. Àwọn ọmọkùnrin Beriah: Heberi àti Malkieli. Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ tí Jakọbu bí nípasẹ̀ Silipa, ẹni tí Labani fi fún Lea ọmọbìnrin rẹ̀. Gbogbo wọn jẹ́ mẹ́rìndínlógún lápapọ̀. Àwọn ọmọkùnrin Rakeli aya Jakọbu: Josẹfu àti Benjamini. Ní Ejibiti, Asenati ọmọbìnrin Potifẹra, alábojútó àti àlùfáà Oni, bí Manase àti Efraimu fún Josẹfu. Àwọn ọmọ Benjamini: Bela, Bekeri, Aṣbeli, Gera, Naamani, Ehi, Roṣi, Mupimu, Huppimu àti Ardi. Wọ̀nyí ni àwọn ọmọkùnrin tí Rakeli bí fún Jakọbu. Wọ́n jẹ́ mẹ́rìnlá lápapọ̀. Àwọn ọmọ Dani: Huṣimu. Àwọn ọmọ Naftali: Jasieli, Guni, Jeseri, àti Ṣillemu. Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ tí Biliha ẹni tí Labani fi fún Rakeli ọmọ rẹ̀ bí fún Jakọbu. Wọ́n jẹ́ méje lápapọ̀. Gbogbo àwọn tí ó lọ pẹ̀lú Jakọbu sí Ejibiti, àwọn tí ó jẹ́ ìran rẹ̀ tààrà láìka àwọn aya ọmọ rẹ̀, jẹ́ ènìyàn mẹ́rìndínláàádọ́rin. Pẹ̀lú àwọn ọmọkùnrin méjì tí a bí fún Josẹfu ní Ejibiti àwọn ará ilé Jakọbu tí ó lọ sí Ejibiti jẹ́ àádọ́rin lápapọ̀. Jakọbu sì rán Juda ṣáájú rẹ̀ lọ sọ́dọ̀ Josẹfu, kí wọn bá à le mọ ọ̀nà Goṣeni. Nígbà tí wọ́n dé agbègbè Goṣeni, Josẹfu tọ́jú kẹ̀kẹ́-ẹṣin rẹ̀ ó sì lọ sí Goṣeni láti pàdé Israẹli baba rẹ̀. Bí Josẹfu ti dé iwájú baba rẹ̀, ó dì mọ́ baba rẹ̀ ó sì sọkún fún ìgbà pípẹ́. Israẹli wí fún Josẹfu pé, “Wàyí o, mo le kú, níwọ̀n bí mo ti rí i fún ara mi pé, o wà láààyè síbẹ̀.” Nígbà náà ni Josẹfu wí fún àwọn arákùnrin rẹ̀ àti fún àwọn ará ilé baba rẹ̀ pé, “Èmi yóò gòkè lọ, èmi yóò sì bá Farao sọ̀rọ̀, èmi yóò sì wí fún un pé, ‘Àwọn arákùnrin mi àti ìdílé baba mi tí ń gbé ní Kenaani ti tọ̀ mí wá. Darandaran ni àwọn ènìyàn náà, wọ́n ń tọ́jú ẹran ọ̀sìn, wọ́n sì kó agbo ẹran wọn àti agbo màlúù wọn àti gbogbo ohun tí wọ́n ní pẹ̀lú wá.’ Nígbà tí Farao bá pè yín wọlé tí ó sí béèrè irú iṣẹ́ tí ẹ ń ṣe, ẹ fún un lésì pé, ‘Àwọn ìránṣẹ́ rẹ ń tọ́jú ẹran ọ̀sìn ni láti ìgbà èwe wa wá gẹ́gẹ́ bí a ṣe ba a lọ́wọ́ àwọn baba wa.’ Nígbà náà ni wọn yóò fún un yín láààyè láti tẹ̀dó sí ilẹ̀ Goṣeni, nítorí pé àwọn ará Ejibiti kórìíra ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ́ darandaran.” Josẹfu lọ sọ fún Farao pé, “Baba mi àti àwọn arákùnrin mi, pẹ̀lú agbo ẹran, agbo màlúù àti ohun gbogbo tí wọ́n ní, ti dé láti ilẹ̀ Kenaani, wọ́n sì ti wà ní ilẹ̀ Goṣeni báyìí.” Ó yan márùn-ún àwọn arákùnrin rẹ́, ó sì fi wọ́n han Farao. Farao béèrè lọ́wọ́ àwọn arákùnrin rẹ̀ pé, “Kí ni iṣẹ́ yín?” Wọ́n sì fèsì pé, “Darandaran ni àwọn ìránṣẹ́ rẹ, gẹ́gẹ́ bí àwọn baba wa ti jẹ́ darandaran.” Wọ́n sì tún sọ fun un síwájú sí i pé, “A wá láti gbé ìhín yìí fún ìgbà díẹ̀ nítorí ìyàn náà mú púpọ̀ ní ilẹ̀ Kenaani, àwọn ohun ọ̀sìn àwa ìránṣẹ́ rẹ kò sì rí ewéko jẹ. Nítorí náà jọ̀wọ́ má ṣàì jẹ́ kí àwọn ìránṣẹ́ rẹ tẹ̀dó sí ilẹ̀ Goṣeni.” Farao wí fún Josẹfu pé, “Baba rẹ àti àwọn arákùnrin rẹ tọ̀ ọ́ wá, ilẹ̀ Ejibiti sì nìyí níwájú rẹ, mú àwọn arákùnrin rẹ tẹ̀dó sí ibi tí ó dára jù nínú ilẹ̀ náà. Jẹ́ kí wọn máa gbé ní Goṣeni. Bí o bá sì mọ ẹnikẹ́ni nínú wọn tí ó ní ẹ̀bùn ìtọ́jú ẹran, fi wọ́n ṣe olùtọ́jú ẹran ọ̀sìn mi.” Nígbà náà ni Josẹfu mú Jakọbu baba rẹ̀ wọlé wá sí iwájú Farao. Lẹ́yìn ìgbà tí Jakọbu súre fún Farao tán. Farao béèrè lọ́wọ́ Jakọbu pé, “Ọmọ ọdún mélòó ni ọ́?” Jakọbu sì dá Farao lóhùn, “Ọdún ìrìnàjò ayé mi jẹ́ àádóje, ọjọ́ mi kò pọ̀, ó sì kún fún wàhálà, síbẹ̀ kò ì tí ì tó ti àwọn baba mi.” Nígbà náà ni Jakọbu tún súre fún Farao, ó sì jáde lọ kúrò níwájú rẹ̀. Josẹfu sì fi baba rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀ sí ilẹ̀ Ejibiti, ó sì fún wọn ní ohun ìní ní ibi tí ó dára jù ní ilẹ̀ náà, ní agbègbè Ramesesi bí Farao ti pàṣẹ. Josẹfu sì pèsè oúnjẹ fún baba rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀ àti gbogbo ìdílé baba rẹ̀ gẹ́gẹ́ bi iye àwọn ọmọ wọn. Josẹfu àti ìyàn ní ilẹ̀ Ejibiti Ṣùgbọ́n kò sí oúnjẹ ní gbogbo ilẹ̀ náà nítorí tí ìyàn náà mú púpọ̀ tó bẹ́ẹ̀ tí ilẹ̀ Ejibiti àti ilẹ̀ Kenaani gbẹ nítorí ìyàn náà. Josẹfu gba gbogbo owó tí ó wà ní ilẹ̀ Ejibiti àti Kenaani ní ìpààrọ̀ fún ti ọkà tí wọn ń rà, ó sì mú owó náà wá sí ààfin Farao. Nígbà tí owó wọn tán pátápátá ní Ejibiti àti Kenaani, gbogbo Ejibiti wá bá Josẹfu, wọ́n wí pé, “Fún wa ní oúnjẹ, èéṣe tí a ó fi kú ní ojú rẹ? Gbogbo owó wa ni a ti ná tán.” Josẹfu wí pé, “Ẹ mú àwọn ẹran ọ̀sìn yín wá, èmi yóò fún un yín ní oúnjẹ ní ìpààrọ̀ fún ẹran ọ̀sìn yín, níwọ̀n bí owó yín ti tan.” Nítorí náà wọ́n mú àwọn ẹran ọ̀sìn wọn tọ Josẹfu wá, ó sì fún wọn ní oúnjẹ ní ìpààrọ̀ fún ẹṣin, àgùntàn, ewúrẹ́, màlúù àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọn. Ó sì mú wọn la ọdún náà já, tí ó ń fún wọn ní oúnjẹ ní ìpààrọ̀ fún ẹran ọ̀sìn wọn. Nígbà tí ọdún náà parí, wọn padà tọ̀ ọ́ wá ní ọdún tí ó tẹ̀lé, wọn wí pé, “A kò le fi pamọ́ fun olúwa wa pé níwọ̀n bí owó wa ti tan tí gbogbo ẹran ọ̀sìn wa sì ti di tirẹ̀ pé, kò sí ohunkóhun tókù fún olúwa wa bí kò ṣe ara wa àti ilẹ̀ wa. Èéṣe tí àwa yóò fi parun lójú rẹ, ra àwa tìkára wa àti ilẹ̀ wa ní ìpààrọ̀ fún oúnjẹ, àwa àti ilẹ̀ wa yóò sì wà nínú ìgbèkùn Farao. Fún wa ni oúnjẹ kí àwa kí ó má ba à kú, kí ilẹ̀ wa má ba à di ahoro.” Nítorí náà Josẹfu ra gbogbo ilẹ̀ tí ó wà ní Ejibiti fún Farao, kò sí ẹnìkan tí ó ṣẹ́kù ní Ejibiti tí kò ta ilẹ̀ tirẹ̀ nítorí ìyàn náà mú jù fún wọn. Gbogbo ilẹ̀ náà sì di ti Farao, Josẹfu sì sọ gbogbo ará Ejibiti di ẹrú láti igun kan dé èkejì. Ṣùgbọ́n ṣá, kò ra ilẹ̀ àwọn àlùfáà, nítorí wọ́n ń gba ìpín oúnjẹ lọ́wọ́ Farao, wọn sì ní oúnjẹ tí ó tó láti inú ìpín tí Farao ń fún wọn. Ìdí nìyí tí wọn kò fi ta ilẹ̀ wọn. Josẹfu wí fún àwọn ènìyàn náà pé, “Níwọ́n ìgbà tí mo ti ra ẹ̀yin àti ilẹ̀ yín tan lónìí fún Farao, irúgbìn rèé, ẹ lọ gbìn ín sí ilẹ̀ náà. Ṣùgbọ́n nígbà tí ìre oko náà bá jáde, ẹ ó mú ìdákan nínú ìdámárùn-ún rẹ̀ fún Farao. Ẹ le pa ìdámẹ́rin tókù mọ́ fún ara yín àti ìdílé yín àti àwọn ọmọ yín.” Wọ́n dá á lóhùn pé, “O ti gbà wá là, ǹjẹ́ kí a rí ojúrere níwájú olúwa wa, àwa yóò di ẹrú Farao.” Nítorí náà Josẹfu sọ ọ́ di òfin nípa ọ̀rọ̀ ilẹ̀ ni Ejibiti, ó sì wà bẹ́ẹ̀ di òní olónìí pé, ìdákan nínú ìdámárùn-ún ìre oko jẹ́ ti Farao, ilẹ̀ àwọn àlùfáà nìkan ni kò di ti Farao. Àwọn ará Israẹli sì tẹ̀dó sí Ejibiti ní agbègbè Goṣeni. Wọ́n ní ohun ìní fún ara wọn, wọ́n sì bí sí i tó bẹ́ẹ̀ tí wọ́n pọ̀ si gidigidi ní iye. Jakọbu gbé ní Ejibiti fún ọdún mẹ́tàdínlógún iye ọdún ọjọ́ ayé rẹ̀ sì jẹ́ ẹẹ́tàdínlàádọ́jọ (147). Nígbà tí àkókò ń súnmọ́ etílé fún Israẹli láti kú, ó pe Josẹfu, ọmọ rẹ̀, ó sì wí fún un pé, “Bí mo bá rí ojúrere ni ojú rẹ̀ fi ọwọ́ rẹ sí abẹ́ itan mi, kí o sì ṣe ìlérí pé ìwọ yóò fi àánú àti òtítọ́ hàn sí mi. Má ṣe sin òkú mi sí ilẹ̀ Ejibiti. Ṣùgbọ́n, nígbà tí mo bá sinmi pẹ̀lú àwọn baba mi, gbé mí jáde kúrò ní Ejibiti kí o sì sin mí sí ibi tí wọ́n sin àwọn baba mi sí.” Josẹfu sì dáhùn wí pé, “Èmi ó ṣe bí ìwọ ti wí.” Jakọbu wí pé, “Búra fún mi,” Josẹfu sì búra fún un. Israẹli sì tẹ orí rẹ̀ ba, bí ó ti sinmi lé orí ibùsùn rẹ̀. Manase àti Efraimu Lẹ́yìn ìgbà díẹ̀ si, a wí fún Josẹfu pé, “Baba rẹ ń ṣàìsàn,” nítorí náà, ó mú àwọn ọmọ rẹ̀ méjèèjì, Manase àti Efraimu lọ́wọ́ lọ pẹ̀lú rẹ̀. Nígbà tí a sọ fún Jakọbu pé, “Josẹfu ọmọ rẹ wá sí ọ̀dọ̀ rẹ,” Israẹli rọ́jú dìde jókòó lórí ibùsùn rẹ̀. Jakọbu wí fún Josẹfu pé, “El-Ṣaddai,48.3 El-Ṣaddai tí ó túmọ̀ sí, Ọlọ́run Olódùmarè fi ara hàn mí ní Lusi ní ilẹ̀ Kenaani, níbẹ̀ ni ó sì ti súre fún mi. Ó sì wí fún mi pé, ‘Èmi yóò mú kí o bí sí i, ìwọ yóò sì pọ̀ sí i, èmi yóò sì sọ ọ́ di orílẹ̀-èdè ńlá, èmi yóò sì fún ìwọ àti irú-ọmọ rẹ lẹ́yìn rẹ ní ilẹ̀ yìí gẹ́gẹ́ bí ohun ìní ayérayé.’ “Nítorí náà báyìí, àwọn ọmọ rẹ méjèèjì tí a bí fún ọ ní ilẹ̀ Ejibiti, kí èmi kí ó tó tọ̀ ọ́ wá ní ìhín, ni mo sọ di ọmọ mi fúnra mi. Manase àti Efraimu yóò jẹ́ tèmi gẹ́gẹ́ bí Reubeni àti Simeoni ti jẹ́ tèmi. Àwọn ọmọ mìíràn tí ìwọ bá bí lẹ́yìn wọn yóò jẹ́ ọmọ rẹ. Ní ilẹ̀ tí wọn yóò jogún, orúkọ arákùnrin wọn ni a ó máa fi pè wọ́n. Bí mo ti ń padà láti Padani, Rakeli kú ní ọ̀nà nígbà tí ó ṣì wà ní ilẹ̀ Kenaani, èyí tó mú ìbànújẹ́ bá mi, níbi tí kò jìnnà sí Efrata. Nítorí náà èmí sì sin ín sí ẹ̀bá ọ̀nà tí ó lọ sí Efrata” (tí ṣe Bẹtilẹhẹmu). Nígbà tí Israẹli rí àwọn ọmọ Josẹfu, ó béèrè wí pé, “Àwọn wo nìyí?” Josẹfu fún baba rẹ̀ lésì pé, “Wọ̀nyí ni àwọn ọmọkùnrin tí Ọlọ́run ti fi fún mi ní ìhín.” Nígbà náà ni Israẹli wí pé, “Kó wọn wá sí ọ̀dọ̀ mi kí èmi kí ó ba à le súre fún wọn.” Báyìí, ojú Israẹli ti ń di bàìbàì nítorí ogbó, agbára káká sì ni ó fi ń ríran. Josẹfu sì kó àwọn ọmọ rẹ̀ súnmọ́ ọ̀dọ̀ rẹ̀, baba rẹ̀ fẹnukò wọ́n ni ẹnu, ó sì dì mọ́ wọn. Israẹli wí fún Josẹfu pé, “Èmi kò lérò rárá pé, mo tún le rí ojú rẹ mọ́ láéláé, ṣùgbọ́n Ọlọ́run tún fún mi ní àǹfààní, mo sì tún rí àwọn ọmọ rẹ pẹ̀lú.” Nígbà náà ni Josẹfu kó àwọn ọmọ náà kúrò ní orí eékún baba rẹ̀, ó wólẹ̀, ó sì tẹríba. Josẹfu sì mú àwọn méjèèjì, Efraimu ni o fi sí ọwọ́ ọ̀tún òun tìkára rẹ̀, èyí tí í ṣe ọwọ́ òsì fún Israẹli, ó sì fi Manase sí ọwọ́ òsì ara rẹ̀, èyí tí ó bọ́ sí ọwọ́ ọ̀tún Israẹli. Israẹli sì na ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ jáde, ó sì gbe lé Efraimu lórí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òun ni àbúrò, ó sì fi ọwọ́ rẹ̀ tàsé ara wọn, ó sì na ọwọ́ òsì lé Manase lórí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Manase ni àkọ́bí. Nígbà náà ni ó súre fún Josẹfu wí pé, “Ǹjẹ́ kí Ọlọ́run, ẹni tí baba mi Abrahamu àti Isaaki rìn níwájú rẹ̀, Ọlọ́run tí ó ti jẹ́ olùtọ́jú àti aláàbò mi ní gbogbo ọjọ́ ayé mi títí di òní, Angẹli tí ó dá mi ní ìdè kúrò lọ́wọ́ gbogbo ewu, kí ó súre fún àwọn ọmọkùnrin wọ̀nyí. Kí a máa fi orúkọ mi pè wọ́n àti orúkọ àwọn baba mi Abrahamu àti Isaaki, kí wọn kí ó sì pọ̀ sí i lọ́pọ̀lọ́pọ̀ lórí ilẹ̀ ayé.” Nígbà tí Josẹfu rí i pé baba òun gbé ọwọ́ ọ̀tún lé Efraimu lórí, inú rẹ̀ bàjẹ́, ó sì gbá ọwọ́ baba rẹ̀ mú láti gbé ọwọ́ rẹ̀ kúrò lórí Efraimu lọ sí orí Manase. Josẹfu wí fun pé, “Rárá, baba mi, èyí ni àkọ́bí, orí rẹ̀ ni kí ìwọ kí o gbé ọwọ́ ọ̀tún rẹ lé.” Ṣùgbọ́n baba rẹ̀ kò gbà, ó wí pé, “Mo mọ̀, ọmọ mi, mo mọ̀. Òun náà yóò di orílẹ̀-èdè, òun náà yóò sì di ńlá. Ṣùgbọ́n àbúrò rẹ̀ yóò di ẹni ńlá jù ú lọ, irú-ọmọ rẹ yóò sì di ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè.” Ó súre fún wọn lọ́jọ́ náà pé, “Ní orúkọ yín ni Israẹli yóò máa súre yìí pé, ‘Kí Ọlọ́run ṣe ọ́ bí i ti Efraimu àti Manase.’ ” Ó sì gbé Efraimu gẹ́gẹ́ bí ẹ̀gbọ́n sí Manase. Nígbà náà ni Israẹli wí fún Josẹfu pé, “Ọjọ́ ikú mi súnmọ́ etílé, ṣùgbọ́n Ọlọ́run yóò wà pẹ̀lú yín, yóò sì mú un yín padà sí ilẹ̀ àwọn baba yín. Pẹ̀lúpẹ̀lú èmi yóò fún ọ ní ìpín kan ju ti àwọn arákùnrin rẹ lọ. Ilẹ̀ tí mo fi idà àti ọ̀kọ̀ mi gbà lọ́wọ́ àwọn ará Amori.” Ọ̀rọ̀ ìkẹyìn Jakọbu sí àwọn ọmọ rẹ̀ Nígbà náà ni Jakọbu ránṣẹ́ pe àwọn ọmọ rẹ̀, ó sì wí pé, “Ẹ kó ara yín jọ pọ̀, kí n le è sọ ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ iwájú fún un yín. “Ẹ kó ara yín jọ pọ̀, kí ẹ sì tẹ́tí, ẹ̀yin ọmọ Jakọbu; ẹ fetí sí Israẹli baba yín. “Reubeni, ìwọ ni àkọ́bí mi, agbára mi, ìpilẹ̀ṣẹ̀ ipá mi, títayọ ní ọlá àti títayọ ní agbára. Ẹni ríru bí omi Òkun, ìwọ kì yóò tayọ mọ́, nítorí pé ìwọ gun ibùsùn baba rẹ, lórí àkéte mi, ìwọ sì bà á jẹ́ (ìwọ bá ọ̀kan nínú àwọn aya baba rẹ lòpọ̀). “Simeoni àti Lefi jẹ́ arákùnrin— idà wọn jẹ́ ohun èlò ogun alágbára. Kí ọkàn mi má ṣe ni àṣepọ̀ pẹ̀lú wọn, kí n má sì ṣe dúró níbí ìpéjọpọ̀ wọn, nítorí wọ́n ti pa àwọn ènìyàn ní ìbínú wọn, wọ́n sì da àwọn màlúù lóró bí ó ti wù wọ́n. Ìfibú ni ìbínú wọn nítorí tí ó gbóná púpọ̀, àti fún ìrunú wọn nítorí tí ó kún fún ìkà! Èmi yóò tú wọn ká ní Jakọbu, èmi ó sì fọ́n wọn ká ní Israẹli. “Juda, àwọn arákùnrin rẹ yóò yìn ọ, ọwọ́ rẹ yóò wà ní ọrùn àwọn ọ̀tá rẹ, àwọn ọmọkùnrin baba rẹ yóò foríbalẹ̀ fún ọ. Ọmọ kìnnìún ni ọ́, ìwọ Juda, o darí láti igbó ọdẹ, ọmọ mi. Bí i kìnnìún, o ba mọ́lẹ̀, o sì sùn sílẹ̀ bí i abo kìnnìún, ta ni ó tó bẹ́ẹ̀, kí o lé e dìde? Ọ̀pá oyè kì yóò kúrò ní Juda bẹ́ẹ̀ ni ọ̀pá-ìṣàkóso kì yóò kúrò láàrín ẹsẹ̀ rẹ̀, títí tí Ṣilo tí ó ni í yóò fi dé, tí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè yóò máa wárí fún un. Yóò má so ọmọ ẹṣin rẹ̀ mọ́ igi àjàrà, àti ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ mọ́ ẹ̀ka tí ó dára jù. Yóò fọ aṣọ rẹ̀ nínú wáìnì àti ẹ̀wù rẹ̀ nínú omi-pupa ti èso àjàrà. Ojú rẹ̀ yóò rẹ̀ dòdò ju wáìnì lọ, eyín rẹ yóò sì funfun ju omi-ọyàn lọ. “Sebuluni yóò máa gbé ní etí Òkun, yóò sì jẹ́ èbúté fún ọkọ̀ ojú omi, agbègbè rẹ yóò tàn ká títí dé Sidoni. “Isakari jẹ́ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ alágbára tí ó dùbúlẹ̀ láàrín agbo àgùntàn. Nígbà tí ó bá rí bí ibi ìsinmi òun ti dára tó, àti bí ilẹ̀ rẹ̀ ti ní ìdẹ̀ra tó, yóò tẹ èjìká rẹ̀ ba láti ru àjàgà, yóò sì fi ara rẹ̀ fún iṣẹ́ ipá. “Dani yóò ṣe ìdájọ́ àwọn ènìyàn rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan nínú àwọn ẹ̀yà Israẹli. Dani yóò jẹ́ ejò ni pópónà àti paramọ́lẹ̀ ní ẹ̀bá ọ̀nà, tí ó bu ẹṣin jẹ ní ẹsẹ̀, kí ẹni tí ń gùn ún bá à le è ṣubú sẹ́yìn. “Mo ń dúró de ìtúsílẹ̀ rẹ, Olúwa. “Ẹgbẹ́ ogun àwọn ẹlẹ́ṣin yóò kọlu Gadi, ṣùgbọ́n yóò kọlu wọ́n ní gìgísẹ̀ wọn. “Oúnjẹ Aṣeri yóò dára; yóò ṣe àsè tí ó yẹ fún ọba. “Naftali yóò jẹ́ abo àgbọ̀nrín tí a tú sílẹ̀ tí ó ń bí ọmọ dáradára. “Josẹfu jẹ́ àjàrà eléso, àjàrà eléso ní etí odò, tí ẹ̀ka rẹ̀ gun orí odi. Pẹ̀lú ìkorò, àwọn tafàtafà dojú ìjà kọ ọ́, wọ́n tafà sí í pẹ̀lú ìkanra. Ṣùgbọ́n ọrun rẹ̀ dúró ni agbára, ọwọ́ agbára rẹ̀ ni a sì mu lára le, nítorí ọwọ́ alágbára Jakọbu, nítorí olùtọ́jú àti aláàbò àpáta Israẹli, nítorí Ọlọ́run baba rẹ tí ó ràn ọ́ lọ́wọ́, nítorí Olódùmarè tí ó bùkún ọ pẹ̀lú láti ọ̀run wá, ìbùkún ọ̀gbìn tí ó wà ní ìsàlẹ̀, ìbùkún ti ọmú àti ti inú. Ìbùkún baba rẹ pọ̀ púpọ̀ ju ìbùkún àwọn òkè ńlá ìgbàanì, ju ẹ̀bùn ńlá àwọn òkè láéláé. Jẹ́ kí gbogbo èyí sọ̀kalẹ̀ sí orí Josẹfu, lé ìpéǹpéjú ọmọ-aládé láàrín arákùnrin rẹ̀. “Benjamini jẹ́ ìkookò tí ó burú; ní òwúrọ̀ ni ó jẹ ẹran ọdẹ rẹ, ní àṣálẹ́, ó pín ìkógun.” Gbogbo ìwọ̀nyí ni àwọn ẹ̀yà Israẹli méjìlá, èyí sì ni ohun tí baba wọn sọ fún wọn nígbà tí ó súre fún wọn, tí ó sì fún ẹnìkọ̀ọ̀kan ní ìbùkún tí ó tọ́ sí i. Ikú Jakọbu Nígbà náà ni ó fún wọn ní àwọn ìlànà yìí, “Ọjọ́ ikú mi kù fẹ́ẹ́rẹ́. Kí ẹ sin mí sí ibojì pẹ̀lú àwọn baba mi ní inú àpáta ní ilẹ̀ Hiti ará Efroni. Ihò àpáta tí ó wà ní ilẹ̀ Makpela, nítòsí Mamre ní Kenaani, èyí tí Abrahamu rà gẹ́gẹ́ bí ilẹ̀ ìsìnkú lọ́wọ́ Efroni ará Hiti pẹ̀lú ilẹ̀ rẹ̀. Níbẹ̀ ni a sin Abrahamu àti aya rẹ̀ Sara sí, níbẹ̀ ni a sin Isaaki àti Rebeka aya rẹ̀ sí, níbẹ̀ sì ni mo sìnkú Lea sí. Ilẹ̀ náà àti ihò àpáta tí ó wà nínú rẹ̀ ni a rà lọ́wọ́ ará Hiti.” Nígbà tí Jakọbu ti pàṣẹ yìí fún àwọn ọmọ rẹ̀, ó gbé ẹsẹ̀ rẹ̀ sókè sórí ibùsùn, ó sì kú, a sì ko jọ pọ̀ mọ́ àwọn ènìyàn rẹ̀. Josẹfu sì ṣubú lé baba rẹ̀, ó sọkún, ó sì fẹnukò ó ní ẹnu. Nígbà náà ni Josẹfu pàṣẹ fún àwọn oníṣègùn tí ó wà ní ìkáwọ́ rẹ̀ pé kí wọn kí ó ṣe òkú Israẹli baba rẹ̀ lọ́jọ̀, àwọn oníṣègùn náà sì ṣe bẹ́ẹ̀. Fún ogójì ọjọ́ ni wọ́n fi ṣe èyí, nítorí èyí ni àsìkò tí a máa ń fi ṣe ẹ̀ǹbáàmù òkú. Àwọn ará Ejibiti sì ṣọ̀fọ̀ rẹ̀ fún àádọ́rin ọjọ́. Nígbà tí ọjọ́ ìṣọ̀fọ̀ náà kọjá. Josẹfu wí fún àwọn ará ilé Farao pé, “Bí mo bá bá ojúrere yín pàdé, ẹ bá mi sọ fún Farao. ‘Baba mi mú mi búra ó sì wí fún mi pé, “Mo ti fẹ́rẹ kú: sinmi sínú ibojì tí mo gbẹ́ fún ara mi ní ilẹ̀ Kenaani.” Nísinsin yìí, jẹ́ kí n lọ kí n sì sìnkú baba mi, lẹ́yìn náà èmi yóò padà wa.’ ” Farao wí pé, “Gòkè lọ, kí o sì sin baba rẹ, bí ó tí mú ọ búra.” Báyìí ni Josẹfu gòkè lọ láti sìnkú baba rẹ̀. Gbogbo àwọn ìjòyè Farao ni ó sìn ín lọ—àwọn àgbàgbà ilé rẹ̀, àti gbogbo àwọn àgbàgbà ilẹ̀ Ejibiti. Yàtọ̀ fún gbogbo àwọn ará ilé Josẹfu àti ti àwọn arákùnrin rẹ̀ àti àwọn tí ó jẹ́ ilé baba rẹ̀, àwọn ọmọ wọn nìkan àti agbo ẹran pẹ̀lú agbo màlúù ni ó sẹ́ kù ní Goṣeni. Kẹ̀kẹ́-ẹṣin àti àwọn ẹlẹ́ṣin pẹ̀lú gòkè lọ. Àìmoye ènìyàn ni ó lọ. Nígbà tí wọ́n dé ilẹ̀ ìpakà Atadi, ní ẹ̀bá Jordani, wọn pohùnréré ẹkún, níbẹ̀ ni Josẹfu sì tún dúró ṣọ̀fọ̀ baba rẹ̀ fún ọjọ́ méje. Nígbà tí àwọn ará Kenaani tí ń gbé níbẹ̀ rí i bí wọ́n ti ń ṣọ̀fọ̀ náà ni ilẹ̀ ìpakà Atadi, wọ́n wí pé, “Ọ̀fọ̀ ńlá ni àwọn ará Ejibiti ń ṣe yìí.” Ìdí èyí ni a fi ń pe ibẹ̀ ní Abeli-Misraimu.50.11 Abeli-Misraimu tí ó túmọ̀ sí, ìṣọ̀fọ̀ àwọn ará Ejibiti Kò sì jìnnà sí Jordani. Báyìí ni àwọn ọmọ Jakọbu ṣe ohun tí baba wọn pàṣẹ fún wọn. Wọ́n gbé e lọ sí ilẹ̀ Kenaani, wọ́n sì sin ín sínú ihò àpáta tí ó wà ní oko Makpela, ní tòsí i Mamre tí Abrahamu rà gẹ́gẹ́ bí ilẹ̀ ìsìnkú lọ́wọ́ Efroni ará Hiti, pẹ̀lú ilẹ̀ náà. Lẹ́yìn ìgbà tí ó ti sìnkú baba rẹ̀ tan, Josẹfu padà sí Ejibiti pẹ̀lú àwọn arákùnrin rẹ̀ àti àwọn mìíràn tí ó tẹ̀lé e lọ láti sin baba rẹ̀. Josẹfu fi ọkàn àwọn arákùnrin rẹ̀ balẹ̀ Nígbà tí àwọn arákùnrin Josẹfu rí i pé baba wọn kú, wọ́n wí fún ara wọn pé, “Ǹjẹ́ bí ó bá ṣe pé Josẹfu ṣì fi wá sínú ń kọ́, tí ó sì fẹ́ gbẹ̀san gbogbo aburú tí a ti ṣe sí i?” Nítorí náà wọ́n ránṣẹ́ sí Josẹfu wí pé, “Baba rẹ fi àṣẹ yìí sílẹ̀ kí ó tó lọ wí pé, ‘Èyí ni kí ẹ̀yin kí ó sọ fún Josẹfu, mo bẹ̀ ọ́ kí o dáríjì àwọn arákùnrin rẹ, gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ àti aburú tí wọ́n ṣe sí ọ, èyí tí ó mú ibi bá ọ’. Nísinsin yìí, jọ̀wọ́ dárí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run baba rẹ jì wọ́n.” Nígbà tí iṣẹ́ ti wọ́n rán dé ọ̀dọ̀ rẹ̀, Josẹfu sọkún. Àwọn arákùnrin rẹ̀ wá, wọ́n sì wólẹ̀ níwájú rẹ̀, wọ́n wí pé, “Ẹrú rẹ ni a jẹ́.” Ṣùgbọ́n Josẹfu wí fún wọn pé, “Ẹ má ṣe bẹ̀rù, èmi ha wà ní ipò Ọlọ́run bí? Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ gbèrò láti ṣe mi ní ibi, ṣùgbọ́n Ọlọ́run gbèrò láti fi ṣe rere tí ń ṣe lọ́wọ́ yìí; ni gbígba ẹ̀mí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn là. Nítorí náà, ẹ má ṣe bẹ̀rù. Èmi yóò pèsè fún ẹ̀yin àti àwọn ọmọ yín.” Ó tún fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀, ó sì sọ ọ̀rọ̀ rere fun wọn. Ikú Josẹfu Josẹfu sì ń gbé ní Ejibiti pẹ̀lú gbogbo ìdílé baba rẹ̀. Ó sì wà láààyè fún àádọ́fà ọdún. Ó sì rí ìran kẹta ọmọ Efraimu-Àwọn ọmọ Makiri, ọmọkùnrin Manase ni a sì gbé le eékún Josẹfu nígbà tí ó bí wọn. Nígbà náà ni Josẹfu wí fún àwọn arákùnrin rẹ̀ pé, “Mo ti fẹ́rẹ kú, ṣùgbọ́n dájúdájú Ọlọ́run yóò wá sí ìrànlọ́wọ́ yín, yóò sì mú un yín jáde kúrò ní ilẹ̀ yìí lọ sí ilẹ̀ tí ó ti ṣèlérí ní ìbúra fún Abrahamu, Isaaki àti Jakọbu.” Josẹfu sì mú kí àwọn ọmọ Israẹli búra májẹ̀mú kan wí pé, “Dájúdájú Ọlọ́run yóò wá sí ìrànlọ́wọ́ yín, nígbà náà ni ẹ gbọdọ̀ kó egungun mi lọ́wọ́ kúrò ní ìhín.” Báyìí ni Josẹfu kú nígbà tí ó pé àádọ́fà ọdún. Lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n ṣe òkú rẹ̀ lọ́jọ̀ tan, a gbé e sí inú pósí ní Ejibiti.