- Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible 2017 Efesu Ìwé sí àwọn ará Efesu Efesu Ef Ìwé sí àwọn ará Efesu Paulu, aposteli Jesu Kristi nípa ìfẹ́ Ọlọ́run, Sí àwọn ènìyàn mímọ́ tí ó wà ní Efesu, àti sí àwọn olóòtítọ́ nínú Kristi Jesu: Oore-ọ̀fẹ́ sí yín àti àlàáfíà láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba wá àti Jesu Kristi Olúwa. Ìbùkún ti Ẹ̀mí Mímọ́ nínú Kristi Ògo ni fún Ọlọ́run àti Baba Jesu Kristi Olúwa wa, ẹni tí ó ti bùkún wa láti inú ọ̀run wá pẹ̀lú àwọn ìbùkún ẹ̀mí gbogbo nínú Kristi. Àní, gẹ́gẹ́ bí o ti yàn wá nínú rẹ̀ ṣáájú ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé, láti jẹ́ mímọ́ àti aláìlábùkù níwájú rẹ̀ nínú ìfẹ́ ẹni tí ò ti yàn wá tẹ́lẹ̀ sí ìsọdọmọ nípa Jesu Kristi fún ara rẹ̀, ní ìbámu ìdùnnú ìfẹ́ rẹ̀, fún ìyìn ògo oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀, èyí tí ò ti fi fún wa nínú Àyànfẹ́ rẹ̀. Nínú rẹ̀ ni àwa rí ìràpadà gba nípa ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ àti ìdáríjì àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa, ní ìbámu pẹ̀lú ọrọ̀ oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run èyí tí ó fún wa lọ́pọ̀lọ́pọ̀ pẹ̀lú gbogbo ọgbọ́n àti ìmòye, Ó ti sọ ohun ìjìnlẹ̀ ìfẹ́ rẹ̀ di mí mọ̀ fún wa gẹ́gẹ́ bí ìdùnnú rere rẹ̀, èyí ti o pinnu nínú Kristi, èyí tí yóò jẹ jáde ní kíkún àkókò, láti ṣe àkójọpọ̀ àwọn ohun tí ọ̀run àti ti ayé lábẹ́ Kristi. Nínú rẹ̀ ni a yàn wá fẹ́ lẹ́yìn tí ó ti yàn wá tẹ́lẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìpinnu ẹni tí ń ṣiṣẹ́ ohun gbogbo ní ìbámu ìfẹ́ rẹ̀, kí àwa kí ó le wà fún ìyìn ògo rẹ̀, àwa tí a ti ni ìrètí ṣáájú nínú Kristi. Àti ẹ̀yin pẹ̀lú darapọ̀ nínú Kristi nígbà tí ẹ̀yin gbọ́ ọ̀rọ̀ òtítọ́ náà àní ìyìnrere ìgbàlà yin. Nígbà tí ẹ̀yin gbàgbọ́, a fi Ẹ̀mí Mímọ́ ṣe èdìdì ayé yin nínú rẹ, èyí tí a ti ṣe ìlérí rẹ̀ tẹ́lẹ̀, èyí tí ó jẹ́ ìdánilójú àṣansílẹ̀ ogún wa títí yóò fi di àkókò ìràpadà àwọn tí í ṣe ti Ọlọ́run sí ìyìn ògo rẹ̀. Ìdúpẹ́ àti àdúrà Nítorí ìdí èyí, nígbà tí mo ti gbúròó ìgbàgbọ́ ti ń bẹ láàrín yín nínú Jesu Olúwa, àti ìfẹ́ yín sí gbogbo àwọn ènìyàn mímọ́. Èmi kò sì sinmi láti máa dúpẹ́ nítorí yín, àti láti máa rántí yín nínú àdúrà mi. Mo sì ń béèrè nígbà gbogbo pé kí Ọlọ́run Jesu Kristi Olúwa wa, Baba ògo, lè fún yín ni Ẹ̀mí nípa ti ọgbọ́n àti ti ìfihàn kí ẹ̀yin kí ó tún lè mọ̀ ọ́n sí i. Mo tún ń gbàdúrà bákan náà wí pé kí ojú ọkàn yín lè mọ́lẹ̀; kí ẹ̀yin lè mọ ohun tí ìrètí ìpè rẹ̀ jẹ́, àti ọrọ̀ ògo rẹ̀ èyí tí í ṣe ogún àwọn ènìyàn mímọ́, àti aláìlẹ́gbẹ́ títóbi agbára rẹ̀ fún àwa tí a gbàgbọ́. Gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ agbára rẹ̀, èyí tí ó fi sínú Kristi, nígbà tí o ti jí dìde kúrò nínú òkú, tí ó sì mú un jókòó lọ́wọ́ ọ̀tún nínú àwọn ọ̀run. Ó gbéga ju gbogbo ìjọba, àti àṣẹ, àti agbára, àti òye àti gbogbo orúkọ tí a ń dá, kì í ṣe ni ayé yìí nìkan, ṣùgbọ́n ni èyí tí ń bọ̀ pẹ̀lú. Ọlọ́run sì ti fi ohun gbogbo sábẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀, ó sì fi í ṣe orí lórí ohun gbogbo fún ìjọ, èyí tí i ṣe ara rẹ̀, ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ẹni tí ó kún ohun gbogbo ní gbogbo ọ̀nà. Ìṣọdààyè nínú Kristi Ní ti ẹ̀yin, ẹ̀yin ni ó sì ti sọ di ààyè, nígbà ti ẹ̀yin ti kú nítorí ìrékọjá àti àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín, nínú èyí tí ẹ̀yin ti gbé rí, àní bí ìlànà ti ayé yìí, gẹ́gẹ́ bí aláṣẹ agbára ojú ọ̀run, ẹ̀mí tí n ṣiṣẹ́ ni ìsinsin yìí nínú àwọn ọmọ aláìgbọ́ràn. Nínú àwọn ẹni tí gbogbo wa pẹ̀lú ti wà rí nínú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara wa, a ń mú ìfẹ́ ara àti ti inú ṣẹ, àti nípa ìṣẹ̀dá àwa sì ti jẹ́ ọmọ ìbínú, gẹ́gẹ́ bí àwọn ìyókù pẹ̀lú. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run, ẹni tí í ṣe ọlọ́rọ̀ ni àánú, nítorí ìfẹ́ ńlá rẹ̀ tí ó fi fẹ́ wa, nígbà tí àwa tilẹ̀ ti kú nítorí ìrékọjá wa, ó sọ wá di ààyè pẹ̀lú Kristi, oore-ọ̀fẹ́ ni a ti fi gbà yín là. Ọlọ́run sì ti jí wa dìde pẹ̀lú Kristi, ó sì ti mú wa jókòó pẹ̀lú rẹ̀ nínú àwọn ọ̀run nínú Kristi Jesu. Pé ni gbogbo ìgbà tí ń bọ̀ kí ó bà á lè fi ọ̀rọ̀ oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀ tí o pọ̀ rékọjá hàn fún wa nínú ìṣeun rẹ̀ sì wà nínú Kristi Jesu. Nítorí oore-ọ̀fẹ́ ní a fi gbà yín là nípa ìgbàgbọ́. Èyí kì í ṣe nípa agbára ẹ̀yin fúnra yín: ẹ̀bùn Ọlọ́run ni, kì í ṣe nípa àwọn iṣẹ́, kí ẹnikẹ́ni má ba à ṣògo. Nítorí àwa ni iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ tí a ti dá nínú Kristi Jesu fún àwọn iṣẹ́ rere, èyí tí Ọlọ́run ti pèsè tẹ́lẹ̀, fún wa láti ṣe. Ọ̀kan nínú Kristi Nítorí náà ẹ rántí pé, nígbà àtijọ́ rí, ẹ̀yin tí ẹ ti jẹ́ Kèfèrí nípa ti ìbí, tí àwọn tí a ń pè ní “aláìkọlà” láti ọwọ́ àwọn tí ń pe ara wọn “akọlà” (èyí ti a fi ọwọ́ ènìyàn ṣe sí ni ní ara). Ẹ rántí pé ni àkókò náà ẹ̀yin wà láìní Kristi, ẹ jẹ́ àjèjì sí Israẹli, àti àjèjì sí àwọn májẹ̀mú ìlérí náà, láìní ìrètí, àti láìní Ọlọ́run ni ayé. Ṣùgbọ́n nísinsin yìí nínú Kristi Jesu ẹ̀yin tí ó ti jìnà réré nígbà àtijọ́ rí ni a mú súnmọ́ tòsí, nípa ẹ̀jẹ̀ Kristi. Nítorí òun ni àlàáfíà wa, ẹni tí o ti ṣe méjèèjì ni ọ̀kan, tí ó sì ti wó ògiri ìkélé ti ìkórìíra èyí tí ń bẹ láàrín yín. Ó sì ti fi òpin sí ọ̀tá náà nínú ara rẹ̀, àní sí òfin àti àṣẹ wọ̀n-ọn-nì tí ń bẹ nínú ìlànà, kí ó lè sọ àwọn méjèèjì di ẹni tuntun kan nínú ara rẹ̀, kí ó sì ṣe ìlàjà àti kí ó lè mú àwọn méjèèjì bá Ọlọ́run làjà nínú ara kan nípa àgbélébùú; nípa èyí tí yóò fi pa ìṣọ̀tá náà run. Ó sì ti wá, ó sì ti wàásù àlàáfíà fún ẹ̀yin tí o jìnnà réré, àti àlàáfíà fún àwọn tí o súnmọ́ tòsí. Nítorí nípa rẹ̀ ni àwa méjèèjì ti ni àǹfààní sọ́dọ̀ baba nípa Ẹ̀mí kan. Ǹjẹ́ nítorí náà ẹ̀yin kì í ṣe àlejò àti àjèjì mọ́, ṣùgbọ́n àjùmọ̀jogún ọmọ ìbílẹ̀ pẹ̀lú àwọn ènìyàn mímọ́, àti àwọn ará ilé Ọlọ́run; a sì ń gbé yín ró lórí ìpìlẹ̀ àwọn aposteli, àti àwọn wòlíì, pẹ̀lú Jesu Kristi fúnra rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí pàtàkì òkúta igun ilé. Nínú rẹ ni gbogbo ilé náà, tí a ń kọ wà papọ̀ ṣọ̀kan tí ó sì ń dàgbàsókè láti di tẹmpili mímọ́ kan nínú Olúwa. Nínú rẹ̀ ni a ń gbé ẹ̀yin pẹ̀lú ró pẹ̀lú fún ibùjókòó Ọlọ́run nínú Ẹ̀mí rẹ̀. Paulu jẹ́ oníwàásù sí àwọn aláìkọlà Nítorí èyí náà ni èmi Paulu ṣe di òǹdè Jesu Kristi nítorí ẹ̀yin aláìkọlà. Lóòtítọ́ ẹ̀yin tilẹ̀ ti gbọ́ ti iṣẹ́ ìríjú oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run, tí a fi fún mi fún yín; bí ó ti ṣe pé nípa ìfihàn ni ó ti fi ohun ìjìnlẹ̀ hàn fún mi gẹ́gẹ́ bí mo ti kọ ṣáájú ni ṣókí. Nígbà tí ẹ̀yin bá kà á, nípa èyí tí ẹ̀yin o fi lè mọ òye mi nínú ìjìnlẹ̀ Kristi. Èyí tí a kò í tí ì fihàn àwọn ọmọ ènìyàn rí nínú ìran mìíràn gbogbo, bí a ti fi wọ́n hàn nísinsin yìí fún àwọn aposteli rẹ̀ mímọ́ àti àwọn wòlíì nípa Ẹ̀mí; pé, àwọn aláìkọlà jẹ́ àjùmọ̀jogún àti ẹ̀yà ara kan náà, àti alábápín ìlérí nínú Kristi Jesu nípa ìyìnrere. Ìránṣẹ́ èyí tí a fi mi ṣe gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run tí a fi fún mi, gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ agbára rẹ̀. Fún èmi tí o kéré jùlọ nínú gbogbo àwọn ènìyàn mímọ́, ní a fi oore-ọ̀fẹ́ yìí fún, láti wàásù àwámárídìí ọ̀rọ̀ Kristi fún àwọn aláìkọlà; àti láti mú kí gbogbo ènìyàn rí ohun tí iṣẹ́ ìríjú ohun ìjìnlẹ̀ náà jásí, èyí tí a ti fi pamọ́ láti ìgbà àtijọ́ nínú Ọlọ́run, ẹni tí ó dá ohun gbogbo nípa Jesu Kristi. Kí a bá à lè fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ onírúurú ọgbọ́n Ọlọ́run hàn nísinsin yìí fún àwọn ìjòyè àti àwọn alágbára nínú àwọn ọ̀run, nípasẹ̀ ìjọ, gẹ́gẹ́ bí ìpinnu ayérayé tí ó ti pinnu nínú Kristi Jesu Olúwa wa. Nínú ẹni tí àwa ní ìgboyà, àti ọ̀nà pẹ̀lú ìgbẹ́kẹ̀lé nípa ìgbàgbọ́ wa nínú rẹ̀. Nítorí náà, mo bẹ̀ yín kí àárẹ̀ má ṣe mú yín ni gbogbo wàhálà mi nítorí yín, èyí tí ṣe ògo yín. Àdúrà fún àwọn ará Efesu Nítorí ìdí èyí ni mo ṣe ń fi eékún mi kúnlẹ̀ fún Baba Olúwa wa Jesu Kristi. Orúkọ ẹni tí a fi ń pe gbogbo ìdílé tí ń bẹ ni ọ̀run àti ní ayé. Kí òun kí ó lè fi agbára rẹ̀ fún ẹni inú yín ní okun, nípasẹ̀ Ẹ̀mí Mímọ́. Kí Kristi lè máa gbé inú ọkàn yín nípa ìgbàgbọ́; pé bí ẹ ti ń fi gbòǹgbò múlẹ̀ tí ẹ sì ń fi ẹsẹ̀ múlẹ̀ nínú ìfẹ́; kí ẹ̀yin lè ní agbára láti mọ̀ pẹ̀lú gbogbo àwọn ènìyàn mímọ́, ohun tí ìbú, àti gígùn, àti jíjìn, àti gíga ìfẹ́ Kristi jẹ́. Àti láti mọ̀ ìfẹ́ Kristi yìí tí ó ta ìmọ̀ yọ, kí a lè fi gbogbo ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ Ọlọ́run kún yín. Ǹjẹ́ ẹni tí o lè ṣe lọ́pọ̀lọ́pọ̀ ju gbogbo èyí tí a ń béèrè tàbí tí a ń rò lọ, gẹ́gẹ́ bí agbára tí ń ṣiṣẹ́ nínú wa. Òun ni kí a máa fi ògo fún nínú ìjọ àti nínú Kristi Jesu láti ìrandíran gbogbo àní, ayé àìnípẹ̀kun, Àmín. Ìṣọ̀kan nínú ara Jesu Nítorí náà, èmi òǹdè nínú Olúwa ń bẹ̀ yín pé kí ẹ̀yin máa gbé ìgbé ayé tí ó yẹ sí ìpè tí a pè yín sí. Pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀ gbogbo àti inú tútù, pẹ̀lú ìpamọ́ra, ẹ máa fi ìfẹ́ faradà fún ẹnìkejì yín. Kí ẹ sì máa làkàkà láti pa ìṣọ̀kan Ẹ̀mí mọ́ ni ìdàpọ̀ àlàáfíà. Ara kan ni ń bẹ, àti Ẹ̀mí kan, àní bí a ti pè yín sínú ìrètí kan nígbà tí a pè yín. Olúwa kan, ìgbàgbọ́ kan àti ìtẹ̀bọmi kan. Ọlọ́run kan àti Baba gbogbo aráyé, ẹni tí ó ṣe olórí ohun gbogbo àti nípá gbogbo àti nínú ohun gbogbo. Ṣùgbọ́n olúkúlùkù wa ni a fi oore-ọ̀fẹ́ fun gẹ́gẹ́ bi òsùwọ̀n ẹ̀bùn Kristi. Nítorí náà a wí pé: “Nígbà tí ó gòkè lọ sí ibi gíga, ó di ìgbèkùn ni ìgbèkùn, ó sì fi ẹ̀bùn fun ènìyàn.” (Ǹjẹ́ ní ti pé, “Ó gòkè lọ!” Kín ni ó túmọ̀ sí, bí kò ṣe pé ó kọ́ sọ̀kalẹ̀ pẹ̀lú lọ sí ìsàlẹ̀ ilẹ̀? Ẹni tí ó ti sọ̀kalẹ̀, Òun kan náà ni ó sì ti gòkè rékọjá gbogbo àwọn ọ̀run, kí ó lè kún ohun gbogbo.) Nítorí náà ó sì ti fi àwọn kan fún ni bí aposteli; àti àwọn mìíràn bí i wòlíì; àti àwọn mìíràn bí efangelisti, àti àwọn mìíràn bí olùṣọ́-àgùntàn àti olùkọ́ni. Fún àṣepé àwọn ènìyàn mímọ́ fun iṣẹ́ ìránṣẹ́, fún ìmúdàgbà ara Kristi. Títí gbogbo wa yóò fi dé ìṣọ̀kan ìgbàgbọ́ àti ìmọ̀ Ọmọ Ọlọ́run, títí a ó fi di ọkùnrin, títí a ó fi dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìwọ̀n Kristi. Kí àwa má ṣe jẹ́ èwe mọ́, tí a ń fi gbogbo afẹ́fẹ́ ẹ̀kọ́ tì síwá tì sẹ́yìn, tí a sì fi ń gbá kiri, nípa ìtànjẹ ènìyàn, nípa àrékérekè fun ọgbọ́nkọ́gbọ́n àti mú ni ṣìnà. Ṣùgbọ́n ká a máa sọ òtítọ́ ní ìfẹ́, kí a lè máa dàgbàsókè nínú rẹ̀ ní ohun gbogbo ẹni tí i ṣe orí, àní Kristi. Láti ọ̀dọ̀ ẹni ti ara náà tí a ń so ṣọ̀kan pọ̀, tí ó sì ń fi ara mọ́ra, nípasẹ̀ oríkèé kọ̀ọ̀kan tí a ti pèsè, nígbà tí ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan bá ń ṣiṣẹ́ dáradára, yóò mú ara dàgbà, yóò sì gbé ara òun tìkára rẹ̀ dìde nínú ìfẹ́. Gbígbé ìgbé ayé gẹ́gẹ́ bí ọmọ ìmọ́lẹ̀ Ǹjẹ́ èyí ni mo ń wí, tí mo sì ń jẹ́rìí nínú Olúwa pé, láti ìsinsin yìí lọ, kí ẹ̀yin má ṣe rìn mọ́, àní gẹ́gẹ́ bí àwọn aláìkọlà ti ń rìn nínú ìrònú asán wọn. Òye àwọn ẹni tí ó ṣókùnkùn, a sì yà wọ́n nínú ìyè Ọlọ́run nítorí àìmọ̀ tí ń bẹ nínú wọn, nítorí líle ọkàn wọn. Àwọn ẹni tí ọkàn wọn le rékọjá, tí wọ́n sì ti fi ara wọn fún wọ̀bìà, láti máa fi ìwọra ṣiṣẹ́ ìwà èérí gbogbo. Ṣùgbọ́n a kò fi Kristi kọ́ yín bẹ́ẹ̀. Bí ó bá ṣe pé nítòótọ́ ni ẹ ti gbóhùn rẹ̀ ti a sì ti kọ́ yín nínú rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí òtítọ́ ti ń bẹ nínú Jesu. Pé, ní tì ìwà yín àtijọ́, kí ẹ̀yin bọ́ ògbólógbòó ọkùnrin nì sílẹ̀, èyí tí ó díbàjẹ́ gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ẹ̀tàn; kí ẹ sì di tuntun ni ẹ̀mí inú yín; kí ẹ sì gbé ọkùnrin tuntun ni wọ̀, èyí tí a dá ni àwòrán Ọlọ́run nínú òdodo àti ìwà mímọ́ ti òtítọ́. Nítorí náà ẹ fi èké ṣíṣe sílẹ̀, ki olúkúlùkù yín kí ó máa ba ọmọnìkejì rẹ̀ sọ òtítọ́, nítorí ẹ̀yà ara ọmọnìkejì wa ni àwa jẹ́. Nínú ìbínú yín, ẹ máa ṣe ṣẹ̀, ẹ má ṣe jẹ́ kí oòrùn wọ̀ bá ìbínú yín, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ má ṣe fi ààyè ẹ̀gbẹ́ kan fún Èṣù. Kí ẹni tí ń jalè má ṣe jalè mọ́: ṣùgbọ́n kí ó kúkú máa ṣe làálàá, kí ó máa fi ọwọ́ rẹ̀ ṣiṣẹ́ ohun tí ó dára, kí òun lè ní láti pín fún ẹni tí ó ṣe aláìní. Ẹ má ṣe jẹ́ kí ọ̀rọ̀ ìdíbàjẹ́ kan ti ẹnu yín jáde, ṣùgbọ́n irú èyí tí ó lè ràn ìdàgbàsókè wọn lọ́wọ́ gẹ́gẹ́ bí ohun tí wọ́n nílò, kí ó lè máa fi oore-ọ̀fẹ́ fún àwọn tí ń gbọ́. Ẹ má sì ṣe mú Ẹ̀mí Mímọ́ Ọlọ́run bínú, ẹni tí a fi ṣe èdìdì yín dé ọjọ́ ìdáǹdè. Gbogbo ìwà kíkorò àti ìbínú, àti ìrunú, àti ariwo, àti ọ̀rọ̀ búburú ni kí a mú kúrò lọ́dọ̀ yín, pẹ̀lú gbogbo àrankàn. Ẹ máa ṣoore fún ọmọnìkejì yín, ẹ ní ìyọ́nú, ẹ máa dáríjì ara yín, gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run nínú Kristi ti dáríjì yín. Nítorí náà, ẹ máa ṣe àfarawé Ọlọ́run bí àwọn olùfẹ́ ọmọ, ẹ sì máa rìn ní ìfẹ́, gẹ́gẹ́ bí Kristi pẹ̀lú ti fẹ́ wa, tí ó sì fi ara rẹ̀ fún wa ní ọrẹ àti ẹbọ fún Ọlọ́run fún òórùn dídùn. Ṣùgbọ́n àgbèrè àti gbogbo ìwà èérí, tàbí ojúkòkòrò, kí a má tilẹ̀ dárúkọ rẹ̀ láàrín yín mọ́, bí ó ti yẹ àwọn ènìyàn mímọ́. Ìbá à ṣe ìwà ọ̀bùn, àti ìṣọ̀rọ̀ òmùgọ̀, tàbí ìṣẹ̀fẹ̀ àwọn ohun tí kò tọ́; ṣùgbọ́n ẹ kúkú máa dúpẹ́. Nítorí ẹ̀yin mọ èyí dájú pé, kò sí panṣágà, tàbí aláìmọ́ ènìyàn, tàbí wọ̀bìà (tí í ṣé abọ̀rìṣà), tí yóò ni ìpín kan ni ìjọba Kristi àti Ọlọ́run. Ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni fi ọ̀rọ̀ asán tàn yín jẹ: nítorí nípasẹ̀ nǹkan wọ̀nyí ní ìbínú Ọlọ́run fi ń bọ̀ wá sórí àwọn ọmọ aláìgbọ́ràn. Nítorí náà ẹ má ṣe jẹ́ alájọpín pẹ̀lú wọn. Nítorí ẹ̀yin tí jẹ́ òkùnkùn lẹ́ẹ̀kan ṣùgbọ́n nísinsin yìí, ẹ̀yin dí ìmọ́lẹ̀, nípa tí Olúwa: ẹ máa rín gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ ìmọ́lẹ̀ (nítorí èso Ẹ̀mí ni ìṣoore, àti òdodo àti òtítọ́). Ẹ sì máa wádìí ohun tí í ṣe ìtẹ́wọ́gbà fún Olúwa. Ẹ má sì ṣe bá àwọn oníṣẹ́ òkùnkùn kẹ́gbẹ́ pọ̀, ṣùgbọ́n ẹ kúkú máa bá wọn wí. Nítorí ìtìjú tilẹ̀ ni láti máa sọ̀rọ̀ nǹkan wọ̀n-ọn-nì tí àwọn aláìgbọ́ràn ń ṣe ní ìkọ̀kọ̀. Ṣùgbọ́n ohun gbogbo tí a tú síta ni ìmọ́lẹ̀ ń fì hàn: nítorí ohunkóhun tí ó bá fi nǹkan hàn, ìmọ́lẹ̀ ni. Nítorí náà ni ó ṣe wí pé, “Jí, ìwọ̀ ẹni tí ó sun, sí jíǹde kúrò nínú òkú Kristi yóò sì fún ọ ní ìmọ́lẹ̀.” Nítorí náà ẹ kíyèsi láti máa rìn ní ìwà pípé, kì í ṣé bí àwọn òmùgọ̀, ṣùgbọ́n bí àwọn ọlọ́gbọ́n; ẹ máa ra ìgbà padà, nítorí búburú ní àwọn ọjọ́. Nítorí náà, ẹ má ṣé jẹ aláìlóye, ṣùgbọ́n ẹ máa mòye ohun tí ìfẹ́ Olúwa jásí. Ẹ má sí ṣe mú wáìnì ní àmupara, nínú èyí tí rúdurùdu wà; ṣùgbọ́n ẹ kún fún Ẹ̀mí Mímọ́. Ẹ sì máa bá ara yín sọ̀rọ̀ nínú Saamu, àti orin ìyìn, àti orin Ẹ̀mí, ẹ máa kọrin, kí ẹ sì máa kọrin dídùn ní ọkàn yín sí Olúwa. Ẹ máa dúpẹ́ nígbà gbogbo fún ohun gbogbo lọ́wọ́ Ọlọ́run, àní Baba, ní orúkọ Jesu Kristi Olúwa wá. Àwọn aya àti ọkọ Ẹ máa tẹríba fún ara yín ní ìbẹ̀rù Ọlọ́run. Ẹ̀yin aya, ẹ máa tẹríba fún àwọn ọkọ yín, gẹ́gẹ́ bí fún Olúwa. Nítorí pé ọkọ ni ó ń ṣe orí aya, gẹ́gẹ́ bí Kristi tí i ṣe orí ìjọ, tí òun si ń ṣe ara rẹ̀, Òun sì ni Olùgbàlà rẹ̀. Nítorí náà gẹ́gẹ́ bí ìjọ tí i tẹríba fún Kristi, bẹ́ẹ̀ sì ní kì àwọn aya máa ṣe sí ọkọ wọn ní ohun gbogbo. Ẹ̀yin ọkọ, ẹ fẹ́ràn àwọn aya yín, gẹ́gẹ́ bí Kristi tí fẹ́ràn ìjọ, tí ó sì fi ara rẹ̀ fún un. Kí òun lè sọ ọ́ di mímọ́ lẹ́yìn tí ó tí fi ọ̀rọ̀ wẹ̀ ẹ́ nínú agbada omí. Kí òun lé mú un wá sọ́dọ̀ ara rẹ̀ bí ìjọ tí ó ní ògo ní àìlábàwọ́n, tàbí àlébù kan, tàbí irú nǹkan bá-wọ̀n-ọn-nì: ṣùgbọ́n kí ó lè jẹ́ mímọ́ àti aláìlábùkù. Bẹ́ẹ̀ ní ó tọ́ kí àwọn ọkùnrin máa fẹ́ràn aya wọn gẹ́gẹ́ bí ara àwọn fúnra wọn. Nítorí kò sì ẹnìkan tí ó ti kórìíra ara rẹ̀; bí kò ṣe pé kí ó máa bọ́ ọ kí ó sì máa ṣìkẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Kristi sì ti ń ṣe sí ìjọ. Nítorí pé àwa ni ẹ̀yà ara rẹ̀, àti tí ẹran-ara rẹ̀, àti egungun ara rẹ̀. Nítorí èyí ní ọkùnrin yóò fi baba àti ìyá rẹ̀ sílẹ̀, òun yóò sì dàpọ̀ mọ́ aya rẹ̀, àwọn méjèèjì yóò sì di ara kan. Àṣírí ńlá ní èyí: ṣùgbọ́n èmí ń sọ nípá ti Kristi àti tí ìjọ. Ṣùgbọ́n kí olúkúlùkù yín fẹ́ràn aya rẹ̀, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ bí òun fúnra rẹ̀; kí aya kí ó sì bọ̀wọ̀ fún ọkọ rẹ̀. Àwọn ọmọ àti àwọn òbí Ẹ̀yin ọmọ, ẹ máa gbọ́ tí àwọn òbí i yín nínú Olúwa, nítorí pé èyí ní ó tọ́. “Bọ̀wọ̀ fún baba àti ìyá rẹ,” èyí tí í ṣe òfin kìn-ín-ní pẹ̀lú ìlérí, “ki ó lé dára fún ọ, àti kí ìwọ lè wà pẹ́ ní ayé.” Àti ẹ̀yin baba, ẹ má ṣe mú àwọn ọmọ yín bínú, ṣùgbọ́n ẹ máa tọ́ wọn nínú ẹ̀kọ́ àti ìkìlọ̀ Olúwa. Àwọn ẹrú àti olówó wọn Ẹ̀yin ọmọ ọ̀dọ̀, ẹ máa gbọ́ ti àwọn olúwa yín nípá ti ara, pẹ̀lú ìbẹ̀rù àti ìwárìrì, nínú òtítọ́ ọkàn yín, bí ẹni pé sí Kristi. Gbọ́ ọ̀rọ̀ sí wọn lẹ́nu kì í ṣe láti rí ojúrere wọn nígbà tí ojú wọn bá ń bẹ lára rẹ, ṣùgbọ́n bí ẹrú Kristi, ní ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọ́run láti inú ọkàn rẹ. Ẹ máa fi gbogbo ọkàn yin ṣe iṣẹ́ ìsìn bí sí Olúwa, kì í sí ṣe sí ènìyàn. Bí ẹ̀yin ti mọ̀ pé ohun rere tí olúkúlùkù bá ṣe òun náà ní yóò sí gbà padà lọ́dọ̀ Olúwa, ìbá à ṣe ẹrú, tàbí òmìnira. Àti ẹ̀yin ọ̀gá, ẹ máa ṣe irú ìtọ́jú kan náà sí àwọn ẹrú yin, ẹ máa dín ìbẹ̀rù yín kù bí ẹ̀yin ti mọ̀ pé Olúwa ẹ̀yin tìkára yín ń bẹ ní ọ̀run; kò sì ṣí ojúsàájú ènìyàn lọ́dọ̀ rẹ̀. Ìhámọ́ra Ọlọ́run Ní àkótán, ara mí, ẹ jẹ́ alágbára nínú Olúwa, àti nínú agbára ipá rẹ̀. Ẹ gbé gbogbo ìhámọ́ra Ọlọ́run wọ̀, kí ẹ̀yin lè kọ ojú ìjà sí àrékérekè èṣù. Nítorí pé kì í ṣe ẹ̀jẹ̀ àti ẹran-ara ní àwa ń bá jìjàkadì, ṣùgbọ́n àwọn ìjòyè, àwọn ọlọ́lá, àwọn aláṣẹ ìbí òkùnkùn ayé yìí, àti àwọn ẹ̀mí búburú ní ojú ọ̀run. Nítorí náà, ẹ gbé gbogbo ìhámọ́ra Ọlọ́run wọ̀, kí ẹ̀yin lè dúró tiiri sí ọjọ́ ibi, nígbà tí ẹ̀yin bá sì ti ṣe ohun gbogbo tan kí ẹ sì dúró. Ẹ dúró nítorí náà lẹ́yìn tí ẹ fi àmùrè òtítọ́ dì ẹ̀gbẹ́ yin, tí ẹ sì ti di ìgbàyà òdodo mọ́ra. Tí ẹ sì ti fi ìmúra ìyìnrere àlàáfíà wọ ẹsẹ̀ yín ní bàtà. Ní àfikún, ẹ mú àpáta ìgbàgbọ́, nípa èyí tí ẹ̀yin lè máa fi paná gbogbo ọfà iná ẹni ibi náà. Kí ẹ sì mú àṣíborí ìgbàlà, àti idà ẹ̀mí, tí í ṣe ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Pẹ̀lú gbogbo àdúrà àti ẹ̀bẹ̀ ni kí ẹ máa gbàdúrà nígbà gbogbo nínú Ẹ̀mí, kí ẹ sì máa ṣọ́ra sí i nínú ìdúró ṣinṣin gbogbo àti ẹ̀bẹ̀ fún gbogbo ènìyàn mímọ́. Kí ẹ sì máa gbàdúrà fún mí pẹ̀lú, kí Ọlọ́run lè fún mí ní ọ̀rọ̀ tí ó yẹ kí èmi lè máa fì ìgboyà sọ àwọn ohun ìjìnlẹ̀ ìyìnrere náà. Nítorí èyí tí èmí jẹ́ ikọ̀ nínú ẹ̀wọ̀n, kí èmi lè máa fi ìgboyà sọ̀rọ̀ nínú rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ó ti tọ́ fún mí láti máa sọ. Àwọn ìkíni ìkẹyìn Tikiku, arákùnrin olùfẹ́ àti ìránṣẹ́ olóòtítọ́ nínú Olúwa yóò sọ ohun gbogbo dí mí mọ̀ fún yín, kí ẹ̀yin pẹ̀lú lè mọ̀ bí nǹkan ti rí fún mí àti bí mo tí ń ṣe sí. Ẹni tí mo rán sí yín nítorí èyí náà, kí ẹ lè mọ̀ bí a tí wà, kì òun lè tu ọkàn yín nínú. Àlàáfíà fún àwọn ará, àti ìfẹ́ pẹ̀lú ìgbàgbọ́, láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba wà, àti Olúwa wà Jesu Kristi. Kí oore-ọ̀fẹ́ wà pẹ̀lú gbogbo àwọn tí ó fẹ́ Olúwa wa Jesu Kristi ni àìṣẹ̀tàn.