- Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible 2017 2 Samuẹli Ìwé Samuẹli Kejì 2 Samuẹli 2Sa Ìwé Samuẹli Kejì Dafidi gbọ́ ti ikú Saulu ọba Lẹ́yìn ikú Saulu, Dafidi ti ibi tí ó ti ṣẹ́gun àwọn ará Amaleki bọ̀, ó sì dúró ní Siklagi ní ọjọ́ méjì. Ní ọjọ́ kẹta, ọkùnrin kan dé láti ibi ibùdó Saulu, pẹ̀lú aṣọ rẹ̀ tí ó ti ya; àti erùpẹ̀ ní orí rẹ̀. Nígbà tí ó dé ọ̀dọ̀ Dafidi, ó wólẹ̀ fún un láti bu ọlá fún un. Dafidi sì béèrè pé, “Ibo ni ìwọ ti wá?” “Èmi sá láti ibùdó àwọn ọmọ Israẹli.” Dafidi béèrè pé, “Kí ni ó ṣẹlẹ̀?” “Sọ fún mi.” Ó wí pé, “Àwọn ọkùnrin náà sá láti ojú ogun. Ọ̀pọ̀ wọn ṣubú, wọ́n sì kú. Saulu àti ọmọ rẹ̀ ọkùnrin Jonatani sì kú pẹ̀lú.” Nígbà náà, ní Dafidi sọ fún ọ̀dọ́mọkùnrin tí ó mú ìròyìn wá fún un pé, “Báwo ni o ṣe mọ̀ pé Saulu àti ọmọkùnrin rẹ̀ Jonatani ti kú.” Ọ̀dọ́mọkùnrin náà sọ pé, “Mo wà ní orí òkè Gilboa níbẹ̀ ni Saulu fi ara tí ọkọ̀ rẹ̀, àwọn kẹ̀kẹ́ àti ẹlẹ́ṣin sì ń lépa rẹ̀. Nígbà tí ó wò yíká, tí ó rí mí, ó pè mi, mo sì wí pé, ‘Kí ni mo lè ṣe?’ “Ó bi mí wí pé, ‘Ta ni ìwọ?’ “Mo dáhùn pé, ‘Ará a Amaleki.’ “Nígbà náà ó wí fún mi pé, ‘Dúró lórí ì mi kí o sì pa mí! Èmi wà nínú ìrora ikú, ṣùgbọ́n mo wà láààyè.’ “Nígbà náà, mo dúró lórí i rẹ̀, mo sì pa á nítorí mo mọ̀ wí pé, lẹ́yìn ìgbà tí ó ti ṣubú, kò le è yè mọ́. Mo sì mú adé tí ó wà lórí rẹ̀, idẹ tí ó wà ní apá a rẹ̀, mo sì kó wọn wá síbí fún olúwa mi.” Nígbà náà ni, Dafidi àti gbogbo àwọn tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀, di aṣọ wọn mú, wọ́n sì fà á ya. Wọ́n ṣọ̀fọ̀, wọ́n sì sọkún, wọ́n sì gbààwẹ̀ títí di ìrọ̀lẹ́ fún Saulu àti ọmọ rẹ̀ Jonatani àti fún àwọn ọmọ-ogun Olúwa, àti fún àwọn ilé Israẹli, nítorí wọ́n ti ṣubú nípa idà. Dafidi sọ fún ọkùnrin tí ó mú ìròyìn wá fún un pé, “Níbo ni ó ti wá?” O dáhùn pé, “Ọmọ àlejò ni mo jẹ́, ará Amaleki.” Dafidi béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Kí ni ó dé tí ìwọ kò fi bẹ̀rù láti gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè láti fi pa ẹni àmì òróró Olúwa?” Nígbà náà Dafidi pe ọ̀kan nínú ọkùnrin, ó sì wí pé, “Lọ, gbé e lulẹ̀!” Nígbà náà ó gbé e lulẹ̀, ó sì kú. Nítorí Dafidi wí fún un pé, “Ẹ̀jẹ̀ rẹ yóò wà lórí ara rẹ, nítorí ẹnu ara rẹ ni o fi sọ pé, ‘Mo pa ẹni àmì òróró Olúwa.’ ” Dafidi sì fi orin ọ̀fọ̀ yìí ṣọ̀fọ̀ lórí Saulu àti lórí Jonatani ọmọ rẹ̀, Ó sì pàṣẹ pé kí a kọ́ àwọn ọkùnrin Juda ní orin arò yìí tí ó jẹ́ ti ọrun (a kọ ọ́ sí inú ìwé Jaṣari): “Ògo rẹ, Israẹli ni a pa ní òkè gíga rẹ. Wò bí àwọn alágbára ṣe ń ṣubú! “Ẹ má ṣe sọ ọ́ ní Gati, ẹ má ṣe kéde rẹ̀ ní òpópónà Aṣkeloni, kí àwọn ọmọbìnrin Filistini má bá à yọ̀, kí àwọn ọmọbìnrin aláìkọlà má ba à dunnú. “Ẹ̀yin òkè Gilboa, kí ẹ̀yin kí ó má ṣe rí ìrì tàbí òjò, tàbí oko tí ó mú èso ọrẹ wá. Nítorí ibẹ̀ ni asà alágbára ti ṣègbé, asà Saulu, bí ẹni pé a kò fi òróró yàn án. “Ọrun Jonatani kì í padà bẹ́ẹ̀ ni idà Saulu kì í padà lásán, láì kan ẹ̀jẹ̀ àwọn tí a pa, àti ẹran àwọn alágbára. Saulu àti Jonatani— ní ọjọ́ ayé, wọ́n fẹ́ràn ara, wọn sì dùn, ní ikú, wọn kò sì yà ara wọ́n. Wọ́n yára ju idì lọ, wọ́n lágbára ju kìnnìún lọ. “Ẹ̀yin ọmọbìnrin Israẹli, ẹ sọkún lórí Saulu, ẹni tí ó fi aṣọ ọ̀gbọ̀ dáradára wọ̀ yín, ẹni tí ó fi wúrà sí ara aṣọ yín. “Wò ó bí alágbára ti ṣubú ní ojú ogun! Jonatani, ìwọ tí a pa ní òkè gíga. Ọkàn mi gbọgbẹ́ fún ọ Jonatani arákùnrin mi; ìwọ ṣọ̀wọ́n fún mi. Ìfẹ́ rẹ sí mi jẹ́ ìyanu, ó jẹ́ ìyanu ju ti obìnrin lọ. “Wò ó bí alágbára ti ṣubú! Ohun ìjà sì ti ṣègbé!” A yan Dafidi ní ọba Juda Lẹ́yìn àkókò yìí, Dafidi wádìí lọ́wọ́ Olúwa. Ó sì béèrè pé, “Ṣé èmi lè gòkè lọ sí ọ̀kan lára àwọn ìlú Juda?” Olúwa sì wí pé, “Gòkè lọ.” Dafidi sì béèrè pé, “Ní ibo ni kí èmi kí ó lọ?” Olúwa sì dá a lóhùn pé, “Sí Hebroni.” Nígbà náà ni Dafidi gòkè lọ síbẹ̀ pẹ̀lú ìyàwó rẹ̀ méjì Ahinoamu ará Jesreeli, àti Abigaili obìnrin opó Nabali ti Karmeli. Dafidi sì mú àwọn ọkùnrin tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀, olúkúlùkù pẹ̀lú ìdílé rẹ̀, wọ́n sì ń gbé ní Hebroni àti ìlú rẹ̀ mìíràn. Nígbà náà àwọn ọkùnrin ará Juda wá sí Hebroni, níbẹ̀ ni wọ́n ti fi àmì òróró yan Dafidi gẹ́gẹ́ bí ọba lórí ilé Juda. Nígbà tí wọ́n sọ fún Dafidi pé, àwọn ọkùnrin ti Jabesi Gileadi ni ó sin òkú Saulu, Dafidi rán oníṣẹ́ sí àwọn ọkùnrin Jabesi Gileadi láti sọ fún wọn pé, “Olúwa bùkún un yín fún fífi inú rere yín hàn sí Saulu ọ̀gá yín nípa sí sin ín. Olúwa kí ó fi inú rere àti òtítọ́ fún un yín, èmi náà yóò sì san oore yìí fún un yín, nítorí tí ẹ̀yin ti ṣe èyí. Ǹjẹ́ nísinsin yìí, ẹ mú ara yín le, kí ẹ sì ní ìgboyà, nítorí Saulu ọba yín ti kú, ilé Juda sì ti fi àmì òróró yàn mí ní ọba lórí wọn.” Ogun láàrín ilé Dafidi àti Saulu Lákòókò yìí, Abneri ọmọ Neri olórí ogun Saulu ti mú Iṣboṣeti ọmọ Saulu, ó sì mú un kọjá sí Mahanaimu. Ó sì fi jẹ ọba lórí Gileadi Aṣuri àti Jesreeli àti lórí Efraimu àti lórí Benjamini àti lórí gbogbo Israẹli. Iṣboṣeti ọmọ Saulu sì jẹ́ ọmọ ogójì ọdún nígbà tí ó jẹ ọba lórí Israẹli, ó sì jẹ ọba fún ọdún méjì. Ilé Juda sì ń tọ Dafidi lẹ́yìn. Gbogbo àkókò tí Dafidi fi jẹ ọba ní Hebroni lórí ilé Juda sì jẹ́ ọdún méje àti oṣù mẹ́fà. Abneri ọmọ Neri pẹ̀lú àwọn ọkùnrin ti Iṣboṣeti ọmọkùnrin Saulu kúrò ní Mahanaimu, wọ́n sì lọ sí Gibeoni. Joabu ọmọ Seruiah pẹ̀lú àwọn ọkùnrin Dafidi jáde lọ láti lọ bá wọn ní adágún Gibeoni. Ẹgbẹ́ kan sì jókòó ní apá kan adágún, àti ẹgbẹ́ kejì ní apá kejì adágún. Nígbà náà, Abneri sọ fún Joabu pé, “Jẹ́ kí díẹ̀ nínú àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin yìí ó dìde láti bá ara wọn jà níwájú wa.” Joabu sì dáhùn pé, “Ó dára, jẹ́ kí wọ́n ṣe é.” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n dìde sókè, a sì kà wọ́n sí ọkùnrin méjìlá fún Benjamini àti Iṣboṣeti ọmọ Saulu àti méjìlá fún Dafidi. Nígbà náà olúkúlùkù ọkùnrin gbá ẹnìkejì rẹ̀ mú ní orí, ó sì fi idà gún ẹnìkejì rẹ̀ lẹ́gbẹ̀ẹ́, wọ́n sì ṣubú lulẹ̀ papọ̀. Bẹ́ẹ̀ ni ibẹ̀ ni Gibeoni ti à ń pè ni Helikatihu Hasurimu. Ogun náà ní ọjọ́ náà gbóná. Àwọn ọmọkùnrin Dafidi sì ṣẹ́gun Abneri pẹ̀lú àwọn ọkùnrin Israẹli. Àwọn ọmọkùnrin Seruiah mẹ́tẹ̀ẹ̀ta ni ó wà níbẹ̀: Joabu, Abiṣai àti Asaheli. Nísinsin yìí ẹsẹ̀ Asaheli sì fẹ́rẹ̀ bí ẹsẹ̀ èsúró tí ó wà ní pápá. Asaheli sì ń lépa Abneri, bí òun tí ń lọ kò sì yípadà sí ọ̀tún tàbí sí òsì láti máa tọ́ Abneri lẹ́yìn. Abneri bojú wo ẹ̀yìn rẹ̀, Ó sì béèrè pé, “Ṣé ìwọ Asaheli ni?” Ó dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni.” Nígbà náà, Abneri sọ fún un pé, “Yípadà sí ọ̀tún tàbí òsì; mú ọ̀kan lára àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin kí o sì bọ́ ìhámọ́ra rẹ.” Ṣùgbọ́n Asaheli kọ̀ láti dẹ́kun lílépa rẹ̀. Abneri tún kìlọ̀ fún Asaheli, “Dẹ́kun lílépa mi! Èéṣe tí èmi yóò fi lù ọ́ bolẹ̀? Báwo ni èmi yóò ti wo arákùnrin rẹ Joabu lójú?” Ṣùgbọ́n ó sí kọ̀ láti padà, Abneri sì fi òdì ọ̀kọ̀ gún un lábẹ́ inú, ọ̀kọ̀ náà sì jáde ní ẹ̀yìn rẹ̀: òun sì ṣubú lulẹ̀ níbẹ̀, ó sì kú ní ibi kan náà; ó sí ṣe gbogbo ènìyàn tí ó dé ibi tí Asaheli gbé ṣubú si, tí ó sì kú, sì dúró jẹ́. Joabu àti Abiṣai sì lépa Abneri: oòrùn sì wọ̀, wọ́n sì dé òkè ti Amima tí o wà níwájú Giah lọ́nà ijù Gibeoni. Àwọn ọmọ Benjamini sì kó ara wọn jọ wọ́n tẹ̀lé Abneri, wọ́n sì wá di ẹgbẹ́ kan, wọ́n sì dúró lórí òkè kan. Abneri sì pe Joabu, ó sì bi í léèrè pé, “Idà yóò máa parun títí láéláé bí? Ǹjẹ́ ìwọ kò ì tí ì mọ̀ pé yóò korò níkẹyìn? Ǹjẹ́ yóò ha ti pẹ́ tó kí ìwọ tó sọ fún àwọn ènìyàn náà, kí wọ́n dẹ́kun láti máa lépa arákùnrin wọn.” Joabu sì wí pé, “Bí Ọlọ́run ti ń bẹ, bí kò ṣe bí ìwọ ti wí, nítòótọ́ ní òwúrọ̀ ni àwọn ènìyàn náà ìbá padà lẹ́yìn arákùnrin wọn.” Joabu sì fọ́n ìpè, gbogbo ènìyàn sì dúró jẹ́ẹ́, wọn kò sì lépa Israẹli mọ́, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò sì tún jà mọ́. Abneri àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ sì fi gbogbo òru náà rìn ní pẹ̀tẹ́lẹ̀, wọ́n sì kọjá Jordani, wọ́n sì rìn ní gbogbo Bitironi, wọ́n sì wá sí Mahanaimu. Joabu sì dẹ́kun àti máa tọ Abneri lẹ́yìn: ó sì kó gbogbo àwọn ènìyàn náà jọ, ènìyàn mọ́kàndínlógún ni ó kú pẹ̀lú Asaheli nínú àwọn ìránṣẹ́ Dafidi. Ṣùgbọ́n àwọn ìránṣẹ́ Dafidi sì pa nínú àwọn ènìyàn Benjamini: nínú àwọn ọmọkùnrin Abneri; òjìdínnírinwó (360) ènìyàn. Wọ́n si gbé Asaheli wọ́n sì sin ín sínú ibojì baba rẹ̀ tí ó wà ní Bẹtilẹhẹmu. Joabu àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ fi gbogbo òru náà rìn, ilẹ̀ sì mọ́ wọn sí Hebroni. Abneri àti Iṣboṣeti jà Ogun náà sì pẹ́ títí láàrín ìdílé Saulu àti ìdílé Dafidi: agbára Dafidi sì ń pọ̀ sí i, ṣùgbọ́n ìdílé Saulu ń rẹ̀yìn sí i. Dafidi sì bí ọmọkùnrin ní Hebroni: Amnoni ni àkọ́bí rẹ̀ tí Ahinoamu ará Jesreeli bí fún un. Èkejì rẹ̀ sì ni Kileabu, tí Abigaili aya Nabali ará Karmeli bí fún un; ẹ̀kẹta sì ni Absalomu ọmọ tí Maaka ọmọbìnrin Talmai ọba Geṣuri bí fún un. Ẹ̀kẹrin sì ni Adonijah ọmọ Haggiti; àti ẹ̀karùnún ni Ṣefatia ọmọ Abitali; Ẹ̀kẹfà sì ni Itreamu, tí Egla aya Dafidi bí fún un. Wọ̀nyí ni a bí fún Dafidi ni Hebroni. Ó sì ṣe, nígbà tí ogun wà láàrín ìdílé Saulu àti ìdílé Dafidi, Abneri sì dì alágbára ní ìdílé Saulu. Saulu ti ní àlè kan, orúkọ rẹ̀ sì ń jẹ́ Rispa, ọmọbìnrin Aiah: Iṣboṣeti sì bi Abneri léèrè pé, “Èéṣe tí ìwọ fi wọlé tọ àlè baba mi lọ.” Abneri sì bínú gidigidi nítorí ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ti Iṣboṣeti sọ fún un, ó sì wí pé, “Èmi jẹ́ bí orí ajá ti Juda bí? Di òní yìí ni mo ṣàánú fún ìdílé Saulu baba rẹ, àti fún àwọn arákùnrin rẹ̀, àti fún àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀, tí èmi kò sì fi ọ́ lé Dafidi lọ́wọ́, ìwọ sì kà ẹ̀ṣẹ̀ sí mí lọ́rùn nítorí obìnrin yìí lónìí? Bẹ́ẹ̀ ni kí Ọlọ́run ó ṣe Abneri, àti jù bẹ́ẹ̀ lọ pẹ̀lú, bí Olúwa ti búra fún Dafidi, bí èmi kò ní ṣe bẹ́ẹ̀ fún un. Láti mú ìjọba náà kúrò ní ìdílé Saulu, àti láti gbé ìtẹ́ Dafidi kalẹ̀ lórí Israẹli, àti lórí Juda, láti Dani títí ó fi dé Beerṣeba.” Òun kò sì lè dá Abneri lóhùn kan nítorí tí ó bẹ̀rù rẹ̀. Abneri sì rán àwọn oníṣẹ́ sí Dafidi nítorí rẹ̀ wí pé, “Ti ta ni ilẹ̀ náà ń ṣe? Bá mi ṣe àdéhùn, èmi yóò si kó gbogbo Israẹli tọ̀ ọ́ wá.” Òun sì wí pé, “Ó dára, èmi ó bá ọ ṣe àdéhùn, ṣùgbọ́n ohun kan ni èmi ó béèrè lọ́wọ́ rẹ, èyí ni pé, ìwọ kì yóò rí ojú mi, àfi bí ìwọ bá kọ́ mú Mikali ọmọbìnrin Saulu wá, nígbà tí ìwọ bá wá, láti rí ojú mi.” Dafidi sì rán àwọn ìránṣẹ́ sí Iṣboṣeti ọmọ Saulu pé, “Fi Mikali obìnrin mi lé mi lọ́wọ́, ẹni tí èmi ti fi ọgọ́rùn-ún awọ iwájú orí àwọn Filistini fẹ́.” Iṣboṣeti sì ránṣẹ́, ó sì gbà á lọ́wọ́ ọkùnrin tí a ń pè ní Paltieli ọmọ Laiṣi. Ọkọ rẹ̀ sì ń bà a lọ, ó ń rìn, ó sì ń sọkún lẹ́yìn rẹ̀ títí ó fi dé Bahurimu Abneri sì wí fún un pé, “Padà sẹ́yìn!” Òun sì padà. Abneri wá kí Dafidi ní Hebroni Abneri sì bá àwọn àgbàgbà Israẹli sọ̀rọ̀ pé, “Ẹ̀yin ti ń ṣe àfẹ́rí Dafidi ní ìgbà àtijọ́, láti jẹ ọba lórí yín. Ǹjẹ́ ẹ ṣe, nítorí tí Olúwa ti sọ fún Dafidi pé, ‘Láti ọwọ́ Dafidi ìránṣẹ́ mi lé mi ó gba Israẹli ènìyàn mi là kúrò lọ́wọ́ àwọn Filistini àti lọ́wọ́ gbogbo àwọn ọ̀tá a wọn.’ ” Abneri sì sọ̀rọ̀ létí Benjamini: Abneri sì lọ sọ létí Dafidi ní Hebroni, gbogbo èyí tí ó dára lójú Israẹli, àti lójú gbogbo ilé Benjamini. Abneri sì tọ Dafidi wá ní Hebroni, ogún ọmọkùnrin sì lọ pẹ̀lú rẹ̀ Dafidi sì ṣe àsè fún Abneri àti fún àwọn ọmọkùnrin tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀. Abneri sì wí fún Dafidi pé, “Èmi ó dìde, èmi ó sì lọ, èmi ó sì kó gbogbo Israẹli jọ sọ́dọ̀ ọba olúwa mi, wọn ó sì bá a ṣe àdéhùn, ìwọ ó sì jẹ ọba gbogbo wọn bí ọkàn rẹ ti ń fẹ́.” Dafidi sì rán Abneri lọ; òun sì lọ ní àlàáfíà. Joabu gbọ́ nípa wíwá Abneri sí Hebroni Sì wò ó, àwọn ìránṣẹ́ Dafidi àti Joabu sì ti ibi ìlépa ẹgbẹ́ ogun kan bọ̀, wọ́n sì mú ìkógun púpọ̀ bọ̀; ṣùgbọ́n Abneri kò sí lọ́dọ̀ Dafidi ní Hebroni; nítorí tí òun ti rán an lọ, òun sì ti lọ ní àlàáfíà. Nígbà tí Joabu àti gbogbo ogun tí ó pẹ̀lú rẹ̀ sì dé, wọ́n sì sọ fún Joabu pé Abneri, ọmọ Neri ti tọ ọba wá, òun sì ti rán an lọ, ó sì ti lọ ní àlàáfíà. Joabu sì tọ ọba wá, ó sì sọ pé, “Kí ni ìwọ ṣe yìí? Wò ó, Abneri tọ̀ ọ́ wá; èéha ti ṣe tí ìwọ sì fi rán an lọ? Òun sì ti lọ. Ìwọ mọ Abneri ọmọ Neri, pé ó wá láti tàn ọ́ jẹ ni, àti láti mọ ìjáde lọ rẹ, àti wíwọlé rẹ́ àti láti mọ gbogbo èyí tí ìwọ ń ṣe.” Joabu pa Abneri Nígbà tí Joabu sì jáde kúrò lọ́dọ̀ Dafidi, ó sì rán àwọn ìránṣẹ́ láti lépa Abneri, wọ́n sì pè é padà láti ibi kànga Sira, Dafidi kò sì mọ̀. Abneri sì padà sí Hebroni, Joabu sì bá a tẹ̀ láàrín ojú ọ̀nà láti bá a sọ̀rọ̀ ní àlàáfíà, ó sì gún un níbẹ̀ lábẹ́ inú, ó sì kú, nítorí ẹ̀jẹ̀ Asaheli arákùnrin rẹ̀. Lẹ́yìn ìgbà tí Dafidi sì gbọ́ ọ, ó sì wí pé, “Èmi àti ìjọba mi sì jẹ́ aláìlẹ́bi níwájú Olúwa títí láé, ní ti ẹ̀jẹ̀ Abneri ọmọ Neri, jẹ́ kí ó wà ní orí Joabu, àti ní orí gbogbo ìdílé baba rẹ̀; kí a má sì fẹ́ ẹni ó tí ní ààrùn ìsun, tàbí adẹ́tẹ̀, tàbí ẹni tí ń tẹ ọ̀pá, tàbí ẹni tí a ó fi idà pa, tàbí ẹni tí ó ṣe aláìní oúnjẹ kù ní ilé Joabu.” (Joabu àti Abiṣai arákùnrin rẹ̀ sì pa Abneri, nítorí pé òun ti pa Asaheli arákùnrin wọn ní Gibeoni ní ogun.) Dafidi sì wí fún Joabu àti fún gbogbo ènìyàn tí ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ̀ pé, “Ẹ fa aṣọ yín ya, kí ẹ̀yin sì mú aṣọ ọ̀fọ̀, kí ẹ̀yin sì sọkún níwájú Abneri.” Dafidi ọba tìkára rẹ̀ sì tẹ̀lé pósí rẹ̀. Wọ́n sì sin Abneri ní Hebroni, ọba sì gbé ohùn rẹ̀ sókè, ó sì sọkún ní ibojì Abneri; gbogbo àwọn ènìyàn náà sì sọkún. Ọba sì sọkún lórí Abneri, ó sì wí pé, “Ǹjẹ́ Abneri ó yẹ kí ó kú bí aṣiwèrè? A kò sá à dè ọ́ lọ́wọ́, bẹ́ẹ̀ ni a kò kan ẹsẹ̀ rẹ ní àbà. Gẹ́gẹ́ bí ènìyàn tí ń ṣubú níwájú àwọn ìkà ènìyàn, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ ṣubú.” Gbogbo àwọn ènìyàn náà sì tún sọkún lórí rẹ̀. Nígbà tí gbogbo ènìyàn sì wá láti gba Dafidi ní ìyànjú kí ó jẹun, nígbà tí ọjọ́ sì ń bẹ, Dafidi sì búra wí pé, “Bẹ́ẹ̀ ni kí Ọlọ́run ó ṣe sí mi àti jù bẹ́ẹ̀ lọ, bí èmi yóò bá tọ́ oúnjẹ wò, tàbí nǹkan mìíràn títí oòrùn yóò fi wọ̀!” Gbogbo àwọn ènìyàn sì kíyèsi i, ó sì dára lójú wọn, gbogbo èyí tí ọba ṣe sì dára lójú gbogbo àwọn ènìyàn náà. Gbogbo àwọn ènìyàn náà àti gbogbo Israẹli sì mọ̀ lọ́jọ́ náà pé, kì í ṣe ìfẹ́ ọba láti pa Abneri ọmọ Neri. Ọba sì wí fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, “Ẹ̀yin kò mọ̀ pé olórí àti ẹni ńlá kan ni ó ṣubú lónìí ní Israẹli. Èmi sì ṣe aláìlágbára lónìí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a fi èmi jẹ ọba; àwọn ọkùnrin wọ̀nyí ọmọ Seruiah sì le jù mí lọ: Olúwa ni yóò san án fún ẹni tí ó ṣe ibi gẹ́gẹ́ bí ìwà búburú rẹ̀!” Ikú Iṣboṣeti Nígbà tí ọmọ Saulu sì gbọ́ pé, Abneri kú ní Hebroni, ọwọ́ rẹ̀ sì rọ, gbogbo Israẹli sì rẹ̀wẹ̀sì. Ọmọ Saulu sì ní ọkùnrin méjì tí í ṣe olórí ẹgbẹ́ ogun: a ń pe orúkọ ọ̀kan ní Baanah, àti orúkọ èkejì ní Rekabu, àwọn ọmọ Rimoni ará Beeroti ti àwọn ọmọ Benjamini (nítorí pé a sì ka Beeroti pẹ̀lú Benjamini). Àwọn ará Beeroti sì ti sálọ sí Gittaimu, wọ́n sì ṣe àtìpó níbẹ̀ títí ó fi di ọjọ́ òní yìí. (Jonatani ọmọ Saulu sì ti bí ọmọkùnrin kan tí ẹsẹ̀ rẹ̀ rọ, òun sì jẹ́ ọdún márùn-ún, nígbà tí ìròyìn dé ní ti Saulu àti Jonatani láti Jesreeli wá, olùtọ́ rẹ̀ sì gbé e, o sì sálọ, ó sì ṣe, bí ó sì ti ń yára láti sálọ, òun sì ṣubú, ó sì ya arọ. Orúkọ rẹ̀ a máa jẹ́ Mefiboṣeti.) Àwọn ọmọ Rimoni, ará Beeroti, Rekabu àti Baanah sì lọ wọ́n sì wá síh ilé Iṣboṣeti ní ọ̀sán gangan, òun sì sinmi lórí ibùsùn kan ní ọjọ́-kanrí. Sì wò ó, bí olùṣọ́ ẹnu-ọ̀nà ilé náà ti ń gbọn àwọn pàǹtí, ó tòògbé ó sì sùn lọ, wọ́n sì wá sí àárín ilé náà, wọ́n sì ṣe bí ẹni pé wọ́n ń fẹ́ mú alikama; wọ́n sì gún un lábẹ́ inú. Rekabu àti Baanah arákùnrin rẹ̀ sì sálọ. Nígbà tí wọ́n wọ ilé náà lọ, òun sì dùbúlẹ̀ lórí ibùsùn rẹ̀ nínú iyàrá rẹ̀, wọ́n sì pa á, wọ́n sì bẹ́ ẹ lórí, wọ́n gbé orí sálọ, wọ́n sì fi gbogbo òru rìn ni pẹ̀tẹ́lẹ̀ náà. Wọ́n sì gbé orí Iṣboṣeti tọ Dafidi wá ní Hebroni, wọ́n sì wí fún ọba pé, “Wò ó, orí Iṣboṣeti ọmọ Saulu ọ̀tá rẹ, tí ó ti ń wá ẹ̀mí rẹ kiri, Olúwa ti gbẹ̀san fún ọba olúwa mi lónìí lára Saulu àti lára irú-ọmọ rẹ̀.” Dafidi sì dá Rekabu àti Baanah arákùnrin rẹ̀, àwọn ọmọ Rimoni ará Beeroti lóhùn, ó sì wí fún wọn pé, “Bí Olúwa ti ń bẹ, ẹni tí ó gba ẹ̀mí mi lọ́wọ́ gbogbo ìpọ́njú. Nígbà tí ẹnìkan rò fún mi pé, ‘Wò ó, Saulu ti kú,’ lójú ara rẹ̀ òun sì jásí ẹni tí ó mú ìyìnrere wá, èmi sì mú un, mo sì pa á ní Siklagi, ẹni tí ó ṣe bí òun ó rí nǹkan gbà nítorí ìròyìn rere rẹ̀. Mélòó mélòó ni, nígbà tí àwọn ìkà ènìyàn pa olódodo ènìyàn kan ni ilé rẹ̀ lórí ibùsùn rẹ̀—ǹjẹ́ èmi ha sì lè ṣe aláìbéèrè ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ lọ́wọ́ yín bí? Kí èmi sì mú yín kúrò láààyè.” Dafidi sì fi àṣẹ fún àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin rẹ̀, wọ́n sì pa wọ́n, wọ́n sì gé ọwọ́ àti ẹsẹ̀ wọn, a sì fi wọ́n há lórí igi ní Hebroni. Ṣùgbọ́n wọ́n mú orí Iṣboṣeti, wọ́n sì sin ín ní ibojì Abneri ní Hebroni. A fi Dafidi jẹ ọba lórí gbogbo Israẹli Gbogbo ẹ̀yà Israẹli sì tọ Dafidi wá ní Hebroni, wọ́n sì wí pé, “Ẹran-ara rẹ àti ẹ̀jẹ̀ rẹ ni àwa ń í ṣe. Àti nígbà àtijọ́, nígbà tí Saulu fi jẹ ọba lórí wa, ìwọ ni ẹni tí ó máa ń kó Israẹli jáde, ìwọ sì ni ó máa ń mú wọn bọ̀ wá ilé: Olúwa sì wí fún ọ pé, ‘Ìwọ yóò ṣe olùṣọ́ Israẹli àwọn ènìyàn mi, ìwọ yóò sì jẹ́ olórí fún Israẹli.’ ” Gbogbo àgbàgbà Israẹli sì tọ ọba wá ní Hebroni, Dafidi ọba sì bá wọn ṣe àdéhùn kan ní Hebroni, níwájú Olúwa: wọ́n sì fi òróró yan Dafidi ní ọba Israẹli. Dafidi sì jẹ́ ẹni ọgbọ̀n ọdún nígbà tí ó jẹ ọba; ó sì jẹ ọba ní ogójì ọdún. Ó jẹ ọba ní Hebroni ní ọdún méje àti oṣù mẹ́fà lórí Juda, ó sì jẹ ọba ní Jerusalẹmu ní ọdún mẹ́tàlélọ́gbọ̀n lórí gbogbo Israẹli àti Juda. Dafidi fi agbára gba Jerusalẹmu Àti ọba àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ sì lọ sí Jerusalẹmu sọ́dọ̀ àwọn ará Jebusi, àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà; àwọn tí ó sì ti wí fún Dafidi pé, “Bí kò ṣe pé ìwọ bá mú àwọn afọ́jú àti àwọn arọ kúrò, ìwọ kì yóò wọ ìhín wá.” Wọ́n sì wí pé, “Dafidi kì yóò lè wá síyìn-ín.” Ṣùgbọ́n Dafidi fi agbára gba ìlú odi Sioni: èyí náà ni í ṣe ìlú Dafidi. Dafidi sọ lọ́jọ́ náà pé, “Ẹnikẹ́ni tí yóò kọlu àwọn ará Jebusi, jẹ́ kí ó gba ojú àgbàrá, kí o sí kọlu àwọn arọ, àti àwọn afọ́jú tí ọkàn Dafidi kórìíra.” Nítorí náà ni wọ́n ṣe wí pé, “Afọ́jú àti arọ wà níbẹ̀, kì yóò lè wọlé.” Dafidi sì jókòó ní ilé àwọn ọmọ-ogun tí ó ní odi, a sì ń pè é ní ìlú Dafidi. Dafidi mọ ògiri yí i ká láti Millo wá, ó sì kọ́ ilé nínú rẹ̀. Dafidi sì ń pọ̀ sí i, Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun sì wà pẹ̀lú rẹ̀. Hiramu ọba Tire sì rán àwọn ìránṣẹ́ sí Dafidi, àti igi kedari, àti àwọn gbẹ́nàgbẹ́nà, àti àwọn tí ń gbẹ́ òkúta, wọ́n kọ́ ilé kan fún Dafidi. Dafidi sì kíyèsi i pé, Olúwa ti fi ìdí òun múlẹ̀ láti jẹ ọba lórí Israẹli, àti pé, ó gbé ìjọba rẹ̀ ga nítorí Israẹli àwọn ènìyàn rẹ̀. Dafidi sì tún mú àwọn àlè àti aya sí i láti Jerusalẹmu wá, lẹ́yìn ìgbà tí ó ti Hebroni bọ̀, wọ́n sì bí ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin fún Dafidi. Èyí sì ni orúkọ àwọn tí a bí fún un ní Jerusalẹmu; Ṣammua, Ṣobabu, Natani àti Solomoni. Àti Ibhari, àti Eliṣua, àti Nefegi, àti Jafia. Àti Eliṣama, àti Eliada, àti Elifeleti. Dafidi ṣẹ́gun àwọn Filistini Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn Filistini gbọ́ pé, wọ́n ti fi Dafidi jẹ ọba lórí Israẹli, gbogbo àwọn Filistini sì gòkè wá láti wá Dafidi; Dafidi sì gbọ́, ó sì sọ̀kalẹ̀ lọ sí ìlú olódi. Àwọn Filistini sì wá, wọ́n sì tẹ ara wọn ní àfonífojì Refaimu. Dafidi sì béèrè lọ́dọ̀ Olúwa pé, “Kí èmi ó gòkè tọ àwọn Filistini bí? Ìwọ ó fi wọ́n lé mi lọ́wọ́ bí?” Olúwa sì wí fún Dafidi pé, “Gòkè lọ, nítorí pé dájúdájú èmi ó fi àwọn Filistini lé ọ lọ́wọ́.” Dafidi sì dé Baali-Perasimu, Dafidi sì pa wọ́n níbẹ̀, ó sì wí pé, “Olúwa ti ya lu àwọn ọ̀tá mi níwájú mi, gẹ́gẹ́ bí omi ti ń ya.” Nítorí náà ni òun ṣe pe orúkọ ibẹ̀ náà ni Baali-Perasimu. Wọ́n sì fi òrìṣà wọn sílẹ̀ níbẹ̀, Dafidi àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ sì kó wọn. Àwọn Filistini sì tún gòkè wá, wọ́n sì tan ara wọn kalẹ̀ ní àfonífojì Refaimu. Dafidi sì béèrè lọ́dọ̀ Olúwa, òun sì wí pé, “Má ṣe gòkè lọ; ṣùgbọ́n bù wọ́n lẹ́yìn, kí o sì kọlù wọ́n níwájú àwọn igi Baka. Yóò sì ṣe, nígbà tí ìwọ bá gbọ́ ìró ẹsẹ̀ lórí àwọn igi Baka náà, nígbà náà ni ìwọ yóò sì yára, nítorí pé nígbà náà ni Olúwa yóò jáde lọ níwájú rẹ láti kọlù ogun àwọn Filistini.” Dafidi sì ṣe bẹ́ẹ̀, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún un; ó sì kọlu àwọn Filistini láti Geba títí dé Geseri. A gbé àpótí ẹ̀rí wá sí Jerusalẹmu Dafidi sì tún kó gbogbo àwọn akọni ọkùnrin ní Israẹli jọ, wọ́n sì jẹ́ ẹgbàá mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (30,000). Dafidi sì dìde, ó sì lọ àti gbogbo àwọn ènìyàn tí ń bẹ́ lọ́dọ̀ rẹ́, láti Baalahi ní Juda wá, láti mú àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run tí ibẹ̀ wá, èyí tí a ń pe orúkọ rẹ̀ ní orúkọ Olúwa àwọn ọmọ-ogun tí ó jókòó láàrín àwọn kérúbù. Wọ́n sì gbé àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run náà gun kẹ̀kẹ́ tuntun kan, wọ́n sì mú un láti ilé Abinadabu wá, èyí tí ó wà ní Gibeah: Ussa àti Ahio, àwọn ọmọ Abinadabu sì ń dá kẹ̀kẹ́ tuntun náà. Wọ́n sì mú un láti ilé Abinadabu jáde wá, tí ó wà ní Gibeah, pẹ̀lú àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run, Ahio sì ń rìn níwájú àpótí ẹ̀rí náà. Dafidi àti gbogbo ilé Israẹli sì ṣiré níwájú Olúwa lára gbogbo onírúurú ohun èlò orin tí a fi igi arère ṣe àti lára ìlù haapu, ní ara tambori, sisitirumu àti lára kimbali. Nígbà tí wọ́n dé sí ilẹ̀ ìpakà Nakoni, Ussa sì na ọwọ́ rẹ̀ sí àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run, ó sì dìímú, nítorí tí màlúù kọsẹ̀. Ìbínú Olúwa sì ru sí Ussa; Ọlọ́run sì pa á níbẹ̀ nítorí ìṣísẹ̀ rẹ̀; níbẹ̀ ni ó sì kù ní ẹ̀bá àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run. Inú Dafidi sì bàjẹ́ nítorí tí Olúwa gé Ussa kúrò, ó sì pe orúkọ ibẹ̀ ní Peresi-Usa títí ó fi di òní yìí. Dafidi sì bẹ̀rù Olúwa ní ọjọ́ náà, ó sì wí pé, “Àpótí ẹ̀rí Olúwa yóò ti ṣe tọ̀ mí wá?” Dafidi kò sì fẹ́ mú àpótí ẹ̀rí Olúwa sọ́dọ̀ rẹ̀ sí ìlú Dafidi; ṣùgbọ́n Dafidi sì mú un yà sí ilé Obedi-Edomu ará Gitti. Àpótí ẹ̀rí Olúwa sì gbé ní ilé Obedi-Edomu ará Gitti ní oṣù mẹ́ta; Olúwa sì bùkún fún Obedi-Edomu, àti gbogbo ilé rẹ̀. A sì rò fún Dafidi ọba pé, “Olúwa ti bùkún fún ilé Obedi-Edomu, àti gbogbo èyí tí í ṣe tirẹ̀, nítorí àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run.” Dafidi sì lọ, ó sì mú àpótí ẹ̀rí náà gòkè láti ilé Obedi-Edomu wá sí ìlú Dafidi pẹ̀lú ayọ̀. Ó sì ṣe nígbà tí àwọn ènìyàn tí ó ru àpótí ẹ̀rí Olúwa bá sì ṣí ẹsẹ̀ mẹ́fà, òun a sì fi màlúù àti ẹran àbọ́pa rú ẹbọ. Dafidi sì fi gbogbo agbára rẹ̀ jó níwájú Olúwa; Dafidi sì wọ efodu ọ̀gbọ̀. Bẹ́ẹ̀ ni Dafidi àti gbogbo ilé Israẹli sì gbé àpótí ẹ̀rí Olúwa gòkè wá, pẹ̀lú ìhó ayọ̀, àti pẹ̀lú ìró ìpè. Bí àpótí ẹ̀rí Olúwa sì ti wọ ìlú Dafidi wá; Mikali ọmọbìnrin Saulu sì wo láti ojú fèrèsé, ó sì rí Dafidi ọba ń fò sókè ó sì ń jó níwájú Olúwa; òun sì kẹ́gàn rẹ̀ ní ọkàn rẹ̀. Wọ́n sì mú àpótí ẹ̀rí Olúwa náà wá, wọ́n sì gbé e kalẹ̀ sípò rẹ̀ láàrín àgọ́ náà tí Dafidi pa fún un. Dafidi sì rú ẹbọ sísun àti ẹbọ ìrẹ́pọ̀ níwájú Olúwa. Dafidi sì parí ìṣe ẹbọ sísun àti ẹbọ ìrẹ́pọ̀ náà, ó sì súre fún àwọn ènìyàn náà ní orúkọ Olúwa àwọn ọmọ-ogun. Ó sì pín fún gbogbo àwọn ènìyàn náà, àní fún gbogbo ọ̀pọ̀ ènìyàn Israẹli, àti ọkùnrin àti obìnrin; fún olúkúlùkù ìṣù àkàrà kan àti ekìrí ẹran kan, àti àkàrà díndín kan. Gbogbo àwọn ènìyàn náà sì túká lọ, olúkúlùkù sí ilé rẹ̀. Ẹ̀ṣẹ̀ Mikali Dafidi sì yípadà láti súre fún àwọn ará ilé rẹ̀, Mikali ọmọbìnrin Saulu sì jáde láti wá pàdé Dafidi, ó sì wí pé, “Báwo ni ọba Israẹli ṣe ṣe ara rẹ̀ lógo bẹ́ẹ̀ lónìí, tí ó bọ́ ara rẹ̀ sílẹ̀ lónìí lójú àwọn ìránṣẹ́bìnrin àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bi ọ̀kan nínú àwọn ènìyàn lásán tí ń bọ́ra rẹ̀ sílẹ̀.” Dafidi sì wí fún Mikali pé, “Níwájú Olúwa ni, ẹni tí ó yàn mí fẹ́ ju baba rẹ lọ, àti ju gbogbo ìdílé rẹ lọ, láti fi èmi ṣe olórí àwọn ènìyàn Olúwa, àní lórí Israẹli, èmi ó sì súre níwájú Olúwa. Èmi ó sì tún rẹ ara mi sílẹ̀ jú bẹ́ẹ̀ lọ, èmi ó sì ṣe aláìníyìn lójú ara mi, àti lójú àwọn ìránṣẹ́bìnrin náà ti ìwọ wí, lọ́dọ̀ wọn náà ni èmi ó sì ní ògo.” Mikali ọmọbìnrin Saulu kò sì bí ọmọ, títí o fi di ọjọ́ ikú rẹ̀ nítorí tí ó sọ̀rọ̀-òdì yìí sí Dafidi. Ìlérí Ọlọ́run si Dafidi Ó sì ṣe, nígbà tí ọba ń gbé ní ilé rẹ̀, tí Olúwa sì fún un ní ìsinmi yíkákiri kúrò lọ́wọ́ gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ̀. Ọba sì wí fún Natani wòlíì pé, “Sá wò ó, èmi ń gbé inú ilẹ̀ tí a fi kedari kọ́, ṣùgbọ́n àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run ń gbé inú ibi tí a fi aṣọ gé.” Natani sì wí fún ọba pé, “Lọ, kí o sì ṣe gbogbo èyí tí ó wà ní ọkàn rẹ, nítorí pé Olúwa wà pẹ̀lú rẹ.” Ṣùgbọ́n Ọlọ́run kọ̀ fún Dafidi láti kọ́ tẹmpili Ó sì ṣe ní òru náà, ọ̀rọ̀ Olúwa tọ Natani wá pé, “Lọ, sọ fún ìránṣẹ́ mi, fún Dafidi pé, ‘Báyìí ni Olúwa wí, ìwọ ó ha kọ́ ilé fún mi tí èmi yóò gbé. Nítorí pé, èmi kò ì ti gbé inú ilé kan láti ọjọ́ tí èmi ti mú àwọn ọmọ Israẹli gòkè ti ilẹ̀ Ejibiti wá, títí di òní yìí, ṣùgbọ́n èmi ti ń rìn nínú àgọ́, fún ibùgbé mi. Ní ibi gbogbo tí èmi ti ń rìn pẹ̀lú gbogbo àwọn ọmọ Israẹli, ǹjẹ́ èmi ti bá ọ̀kan nínú ẹ̀yà Israẹli, tí èmi pa àṣẹ fún láti máa bọ́ àwọn ènìyàn mi àní Israẹli, sọ̀rọ̀ pé, “Èéṣe tí ẹ̀yin kò fi kedari kọ́ ilé fún mi.” ’ “Ǹjẹ́, nítorí náà, báyìí ni ìwọ yóò sì wí fún ìránṣẹ́ mi àní Dafidi pé, ‘Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí, Èmi ti mú ìwọ kúrò láti inú agbo àgùntàn wá láti má tẹ̀lé àwọn àgùntàn, mo sì fi ọ́ jẹ olórí àwọn ènìyàn mi, àní Israẹli. Èmi sì wà pẹ̀lú rẹ níbikíbi tí ìwọ ń lọ, èmi sá à gé gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ kúrò níwájú rẹ, èmi sì ti sọ orúkọ rẹ di ńlá, gẹ́gẹ́ bí orúkọ àwọn ènìyàn ńlá tí ó wà ní ayé. Èmi ó sì yan ibìkan fún àwọn ènìyàn mi, àní Israẹli, èmi ó sì gbìn wọ́n, wọn ó sì má gbé bí ibùjókòó tiwọn, wọn kì yóò sì sípò padà mọ́; àwọn ọmọ ènìyàn búburú kì yóò sì pọ́n wọn lójúmọ́, bí ìgbà àtijọ́. Àti gẹ́gẹ́ bí àkókò ìgbà tí èmi ti fi àṣẹ fún àwọn onídàájọ́ lórí àwọn ènìyàn mi, àní Israẹli, èmi fi ìsinmi fún ọ lọ́wọ́ gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ. “ ‘Olúwa sì wí fún ọ pé Olúwa yóò kọ ilé kan fún ọ. Nígbà tí ọjọ́ rẹ bá pé, tí ìwọ ó sì sùn pẹ̀lú àwọn baba rẹ, èmi yóò sì gbé irú-ọmọ rẹ lékè lẹ́yìn rẹ, èyí tí ó ti inú rẹ jáde wá, èmi yóò sì fi ìdí ìjọba rẹ kalẹ̀. Òun ó sì kọ́ ilé fún orúkọ mi, èmi yóò sì fi ìdí ìjọba rẹ kalẹ̀ láéláé. Èmi ó máa ṣe baba fún un, òun yóò sì máa jẹ́ ọmọ mi. Bí òun bá dẹ́ṣẹ̀, èmi yóò sì fi ọ̀pá ènìyàn nà án, àti ìnà àwọn ọmọ ènìyàn. Ṣùgbọ́n àánú mi kì yóò yípadà kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí èmi ti mú un kúrò lọ́dọ̀ Saulu, tí èmi ti mú kúrò níwájú rẹ. A ó sì fi ìdílé rẹ àti ìjọba rẹ múlẹ̀ níwájú rẹ títí láé, a ó sì fi ìdí ìtẹ́ rẹ múlẹ̀ títí láé.’ ” Gẹ́gẹ́ bí gbogbo ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, àti gẹ́gẹ́ bí gbogbo ìran yìí, bẹ́ẹ̀ ni Natani sì sọ fún Dafidi. Àdúrà Dafidi Dafidi ọba sì wọlé lọ, ó sì dúró níwájú Olúwa, ó sì wí pé, Olúwa Olódùmarè, ta ni èmi, àti kí sì ni ìdílé mi, tí ìwọ fi mú mi di ìsinsin yìí? Nǹkan kékeré ni èyí sá à jásí lójú rẹ, Olúwa Olódùmarè; ìwọ sì ti sọ nípa ìdílé ìránṣẹ́ rẹ pẹ̀lú ní ti àkókò tí o jìnnà. Èyí ha ṣe ìwà ènìyàn bí, Olúwa Olódùmarè? “Àti kín ní ó tún kù tí Dafidi ìbá tún máa wí fún ọ? Ìwọ, Olúwa Olódùmarè mọ̀ ìránṣẹ́ rẹ. Nítorí ọ̀rọ̀ rẹ, àti gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ ọkàn rẹ, ni ìwọ ṣe ṣe gbogbo nǹkan ńlá wọ̀nyí, kí ìránṣẹ́ rẹ lè mọ̀. “Ìwọ sì tóbi, Olúwa Olódùmarè! Kò sì sí ẹni tí ó dàbí rẹ, kò sì sí Ọlọ́run kan lẹ́yìn rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí gbogbo èyí tí àwa fi etí wá gbọ́. Orílẹ̀-èdè kan wo ni ó sì ń bẹ ní ayé tí ó dàbí àwọn ènìyàn rẹ, àní Israẹli, àwọn tí Ọlọ́run lọ rà padà láti sọ wọ́n di ènìyàn rẹ̀, àti láti sọ wọ́n ní orúkọ, àti láti ṣe nǹkan ńlá fún un yín, àti nǹkan ìyanu fún ilé rẹ̀, níwájú àwọn ènìyàn rẹ, tí ìwọ ti rà padà fún ara rẹ láti Ejibiti wá, àní àwọn orílẹ̀-èdè àti àwọn òrìṣà wọn. Ìwọ sì fi ìdí àwọn ènìyàn rẹ, àní Israẹli kalẹ̀ fún ara rẹ láti sọ wọ́n di ènìyàn rẹ títí láé; ìwọ Olúwa sì wá di Ọlọ́run fún wọn. “Ǹjẹ́, Olúwa Ọlọ́run, jẹ́ kí ọ̀rọ̀ náà tí ìwọ sọ ní ti ìránṣẹ́ rẹ, àti ní ti ìdílé rẹ̀, kí ó dúró títí láé, kí ó sí ṣe bí ìwọ ti wí. Jẹ́ kí orúkọ rẹ ó ga títí láé, pé, ‘Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni Ọlọ́run lórí Israẹli!’ Sì jẹ́ kí a fi ìdílé Dafidi ìránṣẹ́ rẹ múlẹ̀ níwájú rẹ. “Nítorí pé ìwọ, Olúwa àwọn ọmọ-ogun, Ọlọ́run Israẹli ti sọ létí ìránṣẹ́ rẹ, pé, ‘Èmí ó kọ́ ilé kan fún ọ.’ Nítorí náà ni ìránṣẹ́ rẹ sì ṣe ní i lọ́kàn rẹ̀ láti gbàdúrà yìí sí ọ. Ǹjẹ́, Olúwa Olódùmarè, ìwọ ni Ọlọ́run náà, àwọn ọ̀rọ̀ rẹ sì jásí òtítọ́, ìwọ sì jẹ́ ẹ̀jẹ́ nǹkan rere yìí fún ìránṣẹ́ rẹ. Ǹjẹ́, jẹ́ kí ó wù ọ́ láti bùkún ìdílé ìránṣẹ́ rẹ, kí ó wà títí láé níwájú rẹ, nítorí ìwọ, Olúwa Olódùmarè, ni ó ti sọ ọ́: sì jẹ́ kí ìbùkún wà ní ìdílé ìránṣẹ́ rẹ títí láé, nípasẹ̀ ìbùkún rẹ.” Dafidi ń ti ìṣẹ́gun dé ìṣẹ́gun Ó sì ṣe, lẹ́yìn èyí, Dafidi sì kọlu àwọn Filistini, ó sì tẹrí wọn ba, Dafidi sì gba Metegamima lọ́wọ́ àwọn Filistini. Dafidi sì kọlu Moabu, ó sì fi okùn títa kan dì wọ́n, ó sì dá wọn dùbúlẹ̀; ó sì ṣe òsùwọ̀n okùn méjì ni iye àwọn tí yóò dá sí. Àwọn ará Moabu sì ń sin Dafidi, wọn a sì máa mú ẹ̀bùn wá. Dafidi sì kọlu Hadadeseri ọmọ Rehobu, ọba Soba, bí òun sì ti ń lọ láti mú agbára rẹ̀ bọ̀ sípò ni odò Eufurate. Dafidi sì gba ẹgbẹ̀rún (1,000) kẹ̀kẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀, àti ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárin (7,000) ẹlẹ́ṣin, àti ogún ẹgbẹ̀rún (20,000) àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀. Dafidi sì já gbogbo àwọn ẹṣin kẹ̀kẹ́ wọn ní pàtì, ṣùgbọ́n ó dá ọgọ́rùn-ún kẹ̀kẹ́ sí nínú wọn. Nígbà tí àwọn ará Siria ti Damasku sì wá láti ran Hadadeseri ọba Soba lọ́wọ́, Dafidi sì pa ẹgbẹ̀rún méjìlélógún (22,000) ènìyàn nínú àwọn ará Siria. Dafidi sì fi àwọn ológun sí Siria ti Damasku, àwọn ará Siria sì wá sin Dafidi, wọn a sì máa mú ẹ̀bùn wá, Olúwa sì pa Dafidi mọ́ níbikíbi tí o ń lọ. Dafidi sì gba àṣà wúrà tí ó wà lára àwọn ìránṣẹ́ Hadadeseri, ó sì gbé wọn wá sí Jerusalẹmu. Láti Beta, àti láti Berotai, àwọn ìlú Hadadeseri, ọba Dafidi kó ọ̀pọ̀lọpọ̀ idẹ wá. Nígbà tí Tou ọba Hamati sì gbọ́ pé Dafidi ti pa gbogbo ogun Hadadeseri. Toi sì rán Joramu ọmọ rẹ̀ sí Dafidi ọba, láti kí i, àti láti súre fún un, nítorí pé ó tí bá Hadadeseri jagun, ó sì ti pa á, nítorí tí Hadadeseri sá à ti bá Toi jagun. Joramu sì ni ohun èlò fàdákà, àti ohun èlò wúrà, àti ohun èlò idẹ ní ọwọ́ rẹ̀. Dafidi ọba sì fi wọ́n fún Olúwa pẹ̀lú fàdákà, àti wúrà tí ó yà sí mímọ́, èyí tí ó ti gbà lọ́wọ́ àwọn orílẹ̀-èdè tí ó ti ṣẹ́gun. Lọ́wọ́ Siria àti lọ́wọ́ Moabu àti lọ́wọ́ àwọn ọmọ Ammoni, àti lọ́wọ́ àwọn Filistini, àti lọ́wọ́ Amaleki, àti nínú ìkógun Hadadeseri ọmọ Rehobu ọba Soba. Dafidi sì ní òkìkí gidigidi nígbà tí ó padà wá ilé láti ibi pípa àwọn ará Siria ní àfonífojì Iyọ̀, àwọn tí o pa jẹ́ ẹgbàá mẹ́sàn (18,000) ènìyàn. Ó sì fi àwọn ológun sí Edomu; àti ní gbogbo Edomu yíká ni òun sì fi ológun sí, gbogbo àwọn tí ó wà ní Edomu sì wá sin Dafidi, Olúwa sì fún Dafidi ní ìṣẹ́gun níbikíbi tí ó ń lọ. Àwọn ìránṣẹ́ Dafidi Dafidi sì jẹ ọba lórí gbogbo Israẹli; Dafidi sì ṣe ìdájọ́ àti òtítọ́ fún àwọn ènìyàn rẹ̀. Joabu ọmọ Seruiah ni ó sì ń ṣe olórí ogun; Jehoṣafati ọmọ Ahiludi sì ń ṣe akọ̀wé. Sadoku ọmọ Ahitubu, àti Ahimeleki ọmọ Abiatari, ni àwọn àlùfáà; Seraiah a sì máa ṣe akọ̀wé. Benaiah ọmọ Jehoiada ni ó sì ń ṣe olórí àwọn Kereti, àti àwọn Peleti; àwọn ọmọ Dafidi sì jẹ́ aláṣẹ. Dafidi àti Mefiboṣeti Dafidi sì béèrè pé, ọ̀kan nínú àwọn ẹni tí ń ṣe ìdílé Saulu kù síbẹ̀ bí? Kí èmi lè ṣe oore fún un nítorí Jonatani. Ìránṣẹ́ kan sì ti wà ní ìdílé Saulu, orúkọ rẹ̀ sí ń jẹ́ Ṣiba, wọ́n sì pè é wá sọ́dọ̀ Dafidi, ọba sì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Ìwọ ni Ṣiba bí?” Ó sì dáhùn wí pé, “Ìránṣẹ́ rẹ ni.” Ọba sì wí pé, “Kò ha sí ọ̀kan nínú ìdílé Saulu síbẹ̀, kí èmi ṣe oore Ọlọ́run fún un?” Ṣiba sì wí fún ọba pé, “Jonatani ní ọmọ kan síbẹ̀ tó ya arọ.” Ọba sì wí fún un pé, “Níbo ni ó gbé wà?” Ṣiba sì wí fún ọba pé, “Wò ó, òun wà ní ilé Makiri, ọmọ Ammieli, ní Lo-Debari.” Dafidi ọba sì ránṣẹ́, ó sì mú un láti ilé Makiri ọmọ Ammieli láti Lo-Debari wá. Mefiboṣeti ọmọ Jonatani ọmọ Saulu sì tọ Dafidi wá, ó sì wólẹ̀ níwájú rẹ̀, ó sì bú ọlá fún un. Dafidi sì wí pé, “Mefiboṣeti!” Òun sì dáhùn wí pé, “Wò ó, ìránṣẹ́ rẹ!” Dafidi sì wí fún un pé, “Má ṣe bẹ̀rù, nítorí pé nítòótọ́ èmi ó ṣe oore fún ọ nítorí Jonatani baba rẹ, èmi ó sì tún fi gbogbo ilé Saulu baba rẹ fún ọ, ìwọ ó sì máa bá mi jẹun nígbà gbogbo ní ibi oúnjẹ mi.” Mefiboṣeti sì tẹríba, ó sì wí pé, “Kí ni ìránṣẹ́ rẹ jásí, tí ìwọ ó fi máa wo òkú ajá bí èmi.” Ọba sì pe Ṣiba ìránṣẹ́ Saulu, ó sì wí fún un pé, “Gbogbo nǹkan tí í ṣe ti Saulu, àti gbogbo èyí tí í ṣe ti ìdílé rẹ̀ ni èmi fi fún ọmọ olúwa rẹ. Ìwọ, àti àwọn ọmọ rẹ, àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ ni yóò sì máa ro ilẹ̀ náà fún un, ìwọ ni yóò sì máa mú ìkórè wá, ọmọ olúwa rẹ yóò sì máa rí oúnjẹ jẹ, ṣùgbọ́n Mefiboṣeti ọmọ olúwa rẹ yóò sì máa bá mi jẹun nígbà gbogbo ní ibi oúnjẹ mi.” (Ṣiba sì ní ọmọ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún àti ogún ìránṣẹ́kùnrin.) Ṣiba sì wí fún ọba pé, “Gẹ́gẹ́ bí gbogbo èyí tí olúwa mi ọba ti pàṣẹ fún ìránṣẹ́ rẹ, bẹ́ẹ̀ náà ni ìránṣẹ́ rẹ ó ṣe.” Ọba sì wí pé, “Ní ti Mefiboṣeti, yóò máa jẹun ní ibi oúnjẹ mi, gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan nínú àwọn ọmọ ọba.” Mefiboṣeti sì ní ọmọ kékeré kan, orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Mika. Gbogbo àwọn tí ń gbé ní ilé Ṣiba ni ó sì ń ṣe ìránṣẹ́ fún Mefiboṣeti. Mefiboṣeti sì ń gbé ní Jerusalẹmu, òun a sì máa jẹun nígbà gbogbo ní ibi oúnjẹ ọba; òun sì yarọ ní ẹsẹ̀ rẹ̀ méjèèjì. Dafidi ṣẹ́gun Ammoni Ó sì ṣe lẹ́yìn èyí, ọba àwọn ará Ammoni sì kú, Hanuni ọmọ rẹ̀ sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀. Dafidi sì wí pé, “Èmi yóò ṣe oore fún Hanuni ọmọ Nahaṣi gẹ́gẹ́ bí baba rẹ̀ sì ti ṣe oore fún mi.” Dafidi sì ránṣẹ́ láti tù Hanuni nínú láti ọwọ́ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ wá, nítorí ti baba rẹ̀. Àwọn ìránṣẹ́ Dafidi sì wá sí ilé àwọn ọmọ Ammoni. Àwọn olórí àwọn ọmọ Ammoni sì wí fún Hanuni olúwa wọn pé, “Ǹjẹ́ o rò pé Dafidi ń bu ọlá fún baba rẹ nígbà tí ó rán ènìyàn wá láti bá ọ kẹ́dùn? Kò ha ṣe pé Dafidi rán àwọn ìránṣẹ́ sí ọ láti wo ìlú àti láti yọ́ ọ wò àti láti gbà ọ́.” Hanuni sì mú àwọn ìránṣẹ́ Dafidi ó fá apá kan irùngbọ̀n wọn, ó sì gé ààbọ̀ kúrò ní agbádá wọn, títí ó fi dé ìdí wọn, ó sì rán wọn lọ. Wọ́n sì sọ fún Dafidi, ó sì ránṣẹ́ lọ pàdé wọn, nítorí tí ojú ti àwọn ọkùnrin náà púpọ̀: ọba sì wí pé, “Ẹ dúró ní Jeriko títí irùngbọ̀n yín yóò fi hù, nígbà náà ni kí ẹ tó máa bọ̀.” Àwọn ogun Siria àti Ammoni sá níwájú Israẹli Àwọn ará Ammoni sì ri pé, wọ́n di ẹni ìríra níwájú Dafidi, àwọn ọmọ Ammoni sì ránṣẹ́, wọ́n sì fi owó bẹ́ ogún àwọn ará Siria ti Beti-Rehobu; àti Siria-Soba, ogún ẹgbẹ̀rún (20,000) ẹlẹ́ṣẹ̀ àti ti ọba Maaka, ẹgbẹ̀rún (1,000) ọkùnrin àti ti Tobu ẹgbàá mẹ́fà (12,000) ọkùnrin lọ́wẹ̀. Dafidi sì gbọ́, ó sì rán Joabu, àti gbogbo ogún àwọn ọkùnrin alágbára. Àwọn ọmọ Ammoni sì jáde wá, wọ́n sì tẹ́ ogun ní ẹnu odi; ará Siria-Soba, àti ti Rehobu, àti Tobu, àti Maaka, wọ́n sì tẹ ogun ni pápá fún ara wọn. Nígbà tí Joabu sì rí i pé ogun náà dojúkọ òun níwájú àti lẹ́yìn, ó sì yàn nínú gbogbo àwọn akíkanjú ọkùnrin ní Israẹli, ó sì tẹ́ ogun kọjú sí àwọn ará Siria. Ó sì fi àwọn ènìyàn tí ó kù lé Abiṣai àbúrò rẹ̀ lọ́wọ́, kí ó lè tẹ ogun kọjú sí àwọn ọmọ Ammoni. Ó sì wí pé, “Bí agbára àwọn ará Siria bá pọ̀ ju èmi lọ, ìwọ yóò sì wá ràn mí lọ́wọ́, ṣùgbọ́n bí ọwọ́ àwọn ọmọ Ammoni bá sì pọ̀jù ọ́ lọ, èmi ó sì wá ràn ọ́ lọ́wọ́. Mú ọkàn lè, jẹ́ kí a ṣe onígboyà nítorí àwọn ènìyàn wa, àti nítorí àwọn ìlú Ọlọ́run wa; Olúwa yóò sì ṣe èyí tí ó dára lójú rẹ̀.” Joabu àti àwọn ènìyàn tí ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ̀ sì bá àwọn ará Siria pàdé ìjà, wọ́n sì sá níwájú rẹ̀. Nígbà tí àwọn ọmọ Ammoni sì rí i pé àwọn ará Siria sá, àwọn pẹ̀lú sì sá níwájú Abiṣai, wọ́n sì wọ inú ìlú lọ. Joabu sì padà kúrò lẹ́yìn àwọn ọmọ Ammoni, ó sì wá sí Jerusalẹmu. Ìṣẹ́gun lórí ogun Ammoni àti Siria ní Helami Nígbà tí àwọn ará Siria sì rí i pé àwọn ṣubú níwájú Israẹli, wọ́n sì kó ara wọn jọ Hadadeseri sì ránṣẹ́, ó sì mú àwọn Siria tí ó wà ní òkè odò Eufurate jáde wá, wọ́n sì wá sí Helami; Sobaki olórí ogun Hadadeseri sì ṣe olórí wọn. Nígbà tí a sọ fún Dafidi, ó sì kó gbogbo Israẹli jọ, wọ́n sì kọjá Jordani, wọ́n sì wá sí Helami, àwọn ará Siria sì tẹ́ ogun kọjú sí Dafidi, wọ́n sì bá a jà. Àwọn ará Siria sì sá níwájú Israẹli, Dafidi sì pa nínú àwọn ará Siria ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin (700) àwọn oníkẹ̀kẹ́, àti ọ̀kẹ́ méjì (40,000) ẹlẹ́ṣin, wọ́n sì kọlu Sobaki olórí ogun wọn, ó sì kú níbẹ̀. Nígbà tí gbogbo àwọn ọba tí ó wà lábẹ́ Hadadeseri sì rí i pé wọ́n di bíbì ṣubú níwájú Israẹli, wọ́n sì bá Israẹli làjà, wọ́n sì ń sìn wọ́n. Àwọn ará Siria sì bẹ̀rù láti máa ran àwọn ọmọ Ammoni lọ́wọ́ mọ́. Dafidi àti Batṣeba Lẹ́yìn ìgbà tí ọdún yípo, ní àkókò ìgbà tí àwọn ọba máa ń jáde ogun, Dafidi sì rán Joabu, àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀, àti gbogbo Israẹli; wọ́n sì pa àwọn ọmọ Ammoni, wọ́n sì dó ti Rabba. Dafidi sì jókòó ní Jerusalẹmu. Ó sì ṣe, ní ìgbà àṣálẹ́ kan, Dafidi sì dìde ní ibùsùn rẹ̀, ó sì ń rìn lórí òrùlé ilé ọba, láti orí òrùlé náà ni ó sì rí obìnrin kan tí ó ń wẹ̀ ara rẹ̀; obìnrin náà sì ṣe arẹwà lójú láti wò. Dafidi sì ránṣẹ́ ó sì béèrè obìnrin náà. Ẹnìkan sì wí pé, “Èyí ha kọ́ ni Batṣeba, ọmọbìnrin Eliamu, aya Uriah ará Hiti.” Dafidi sì rán àwọn ìránṣẹ́, ó sì mú un; ó sì wọ inú ilé tọ̀ ọ́ lọ, ó sì bá a dàpọ̀, nígbà tí ó sì wẹ ara rẹ̀ mọ́ tán, ó sì padà lọ sí ilé rẹ̀. Obìnrin náà sì lóyún, ó sì ránṣẹ́ ó sì sọ fún Dafidi, ó sì wí pé, “Èmi ti lóyún.” Dafidi tan Uriah wá sílé Dafidi sì ránṣẹ́ sí Joabu, pé, “Rán Uriah ará Hiti sí mi.” Joabu sì rán Uriah sí Dafidi. Nígbà tí Uriah sì dé ọ̀dọ̀ rẹ̀, Dafidi sì bi í léèrè báwo ni Joabu ti ṣe àti àlàáfíà àwọn ènìyàn náà, àti bí ogun náà ti ń ṣe. Dafidi sì wí fún Uriah pé, “Sọ̀kalẹ̀ lọ sí ilé rẹ, kí o sì wẹ ẹsẹ̀ rẹ.” Uriah sì jáde kúrò ní ilé ọba, oúnjẹ láti ọ̀dọ̀ ọba wá sì tọ̀ ọ́ lẹ́yìn. Ṣùgbọ́n Uriah sun ní ẹnu-ọ̀nà ilé ọba lọ́dọ̀ gbogbo ìránṣẹ́ olúwa rẹ̀, kò sì sọ̀kalẹ̀ lọ sí ilé rẹ̀. Nígbà tí wọ́n sì sọ fún Dafidi pé, “Uriah kò sọ̀kalẹ̀ lọ sí ilé rẹ̀,” Dafidi sì wí fún Uriah pé, “Ṣe bí ọ̀nà àjò ni ìwọ ti wá? Èéha ti ṣe tí ìwọ kò fi sọ̀kalẹ̀ lọ sí ilé rẹ.” Uriah sì wí fún Dafidi pé, “Àpótí ẹ̀rí, àti Israẹli, àti Juda jókòó nínú àgọ́; àti Joabu olúwa mi, àti àwọn ìránṣẹ́ olúwa mi wà ní ibùdó ní pápá, èmi ó ha lọ sí ilé mi, láti jẹ àti láti mu, àti láti bá obìnrin mi sùn? Bí ìwọ bá wà láààyè, àti bí ẹ̀mí rẹ́ si ti ń bẹ láààyè, èmi kì yóò ṣe nǹkan yìí.” Dafidi sì wí fún Uriah pé, “Sì dúró níhìn-ín lónìí, lọ́la èmi ó sì jẹ́ kí ìwọ ó lọ.” Uriah sì dúró ní Jerusalẹmu ní ọjọ́ náà, àti ọjọ́ kejì. Dafidi sì pè é, ó sì jẹ, ó sì mú nítorí rẹ̀; ó sì mu kí ọtí pa á; òun sì jáde ní alẹ́ lọ sí ibùsùn rẹ̀ lọ́dọ̀ àwọn ìránṣẹ́ olúwa rẹ̀, kò sì sọ̀kalẹ̀ lọ sí ilé rẹ̀. Dafidi pàṣẹ kí wọn ó pa Uriah ní ogun Ó sì ṣe ní òwúrọ̀, Dafidi sì kọ̀wé sí Joabu, ó fi rán Uriah. Ó sì kọ sínú ìwé pé, “Fi Uriah síwájú ibi tí ogun gbé le, kí ẹ sì fàsẹ́yìn, kí wọn lè kọlù ú, kí ó sì kú.” Ó sì ṣe nígbà tí Joabu ṣe àkíyèsí ìlú náà, ó sì yan Uriah sí ibi kàn ní ibi tí òun mọ̀ pé àwọn alágbára ọkùnrin ń bẹ níbẹ̀. Àwọn ọkùnrin ìlú náà sì jáde wá, wọ́n sì bá Joabu jà, díẹ̀ sì ṣubú nínú àwọn ènìyàn náà nínú àwọn ìránṣẹ́ Dafidi, Uriah ará Hiti sì kú pẹ̀lú. Joabu sì ránṣẹ́ ó sì ro gbogbo nǹkan ogun náà fún Dafidi. Ó sì pàṣẹ fún ìránṣẹ́ náà pé, “Nígbà tí ìwọ bá sì parí àti máa ro gbogbo nǹkan ogun náà fún ọba. Bí ó bá ṣe pé, ìbínú ọba bá ru, ti òun sì wí fún ọ pé, ‘Èéṣe tí ẹ̀yin fi súnmọ́ ìlú náà láti bá wọn jà, ẹ̀yin kò mọ̀ pé wọn ó tafà láti orí odi wá. Ta ni ó pa Abimeleki ọmọ Jerubu-Beṣeti? Kì í ṣe obìnrin ni ó yí òkúta-ọlọ lù ú láti orí odi wá, tí ó sì kú ní Tebesi? Èéha ti rí tí ẹ̀yin fi súnmọ́ odi náà? Ìwọ yóò sì wí fún un pé, Uriah ìránṣẹ́ rẹ ará Hiti kú pẹ̀lú.’ ” Ìránṣẹ́ náà sì lọ, ó sì wá, ó sì jẹ́ gbogbo iṣẹ́ tí Joabu rán an fún Dafidi. Ìránṣẹ́ náà sì wí fún Dafidi pé, “Nítòótọ́ àwọn ọkùnrin náà lágbára jù wá lọ, wọ́n sì jáde tọ̀ wá wá ní pápá, àwa sì tẹ̀lé wọn títí wọ́n fi dé ẹ̀yìn odi. Àwọn tafàtafà sì ta sí ìránṣẹ́ rẹ láti orí odi wá, díẹ̀ nínú àwọn ìránṣẹ́ ọba sì kú, ìránṣẹ́ rẹ̀ Uriah ará Hiti sì kú pẹ̀lú.” Dafidi sì wí fún ìránṣẹ́ náà pé, “Báyìí ni ìwọ yóò wí fún Joabu pé, ‘Má ṣe jẹ́ kí nǹkan yìí burú ní ojú rẹ, nítorí pé idà a máa pa lọ́tùn ún lósì, mú ìjà rẹ le sí ìlú náà, kí o sì bì í ṣubú.’ Kí ìwọ sì mú un lọ́kàn le.” Dafidi fẹ́ Batṣeba ní ìyàwó Nígbà tí aya Uriah sì gbọ́ pé Uriah ọkọ rẹ̀ kú, ó sì ṣọ̀fọ̀ nítorí ọkọ rẹ̀. Nígbà tí ìṣọ̀fọ̀ náà sì kọjá tan, Dafidi sì ránṣẹ́, o sì mú un wá sí ilé rẹ̀, ó sì di aya rẹ̀, ó sì bí ọmọkùnrin kan fún un, ṣùgbọ́n nǹkan náà tí Dafidi ṣe burú níwájú Olúwa. Natani bá Dafidi wí Olúwa sì rán Natani sí Dafidi òun sì tọ̀ ọ́ wá, ó sì wí fún un pé, “Ọkùnrin méjì ń bẹ ní ìlú kan; ọ̀kan jẹ́ ọlọ́rọ̀, èkejì sì jẹ́ tálákà. Ọkùnrin ọlọ́rọ̀ náà sì ní àgùntàn àti màlúù lọ́pọ̀lọ́pọ̀. Ṣùgbọ́n ọkùnrin tálákà náà kò sì ní nǹkan bí kò ṣe àgùntàn kékeré kan èyí tí ó sì ń tọ́, ó sì dàgbà ní ọwọ́ rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀; a máa jẹ nínú oúnjẹ rẹ̀, a sí máa mu nínú ago rẹ̀, a sì máa dùbúlẹ̀ ní àyà rẹ̀, ó sì dàbí ọmọbìnrin kan fún un. “Àlejò kan sì tọ ọkùnrin ọlọ́rọ̀ náà wá, òun kò sì fẹ́ mú nínú àgùntàn rẹ̀, àti nínú màlúù rẹ̀, láti fi ṣe àlejò fún ẹni tí ó tọ̀ ọ́ wá, o sì mú àgùntàn ọkùnrin tálákà náà fi ṣe àlejò fún ọkùnrin tí ó tọ̀ ọ́ wá.” Ìbínú Dafidi sì ru gidigidi sí ọkùnrin náà; ó sì wí fún Natani pé, “Bí Olúwa ti ń bẹ láààyè, ọkùnrin náà tí ó ṣe nǹkan yìí, kíkú ni yóò kú. Òun yóò sì san àgùntàn náà padà ní mẹ́rin mẹ́rin, nítorí tí ó ṣe nǹkan yìí àti nítorí tí kò ní àánú.” Natani sì wí fún Dafidi pé, “Ìwọ ni ọkùnrin náà. Báyìí ni Olúwa Ọlọ́run Israẹli wí, ‘Èmi fi ọ́ jẹ ọba lórí Israẹli, èmi sì gbà ọ́ lọ́wọ́ Saulu. Èmi sì fi ilé olúwa rẹ fún ọ, àti àwọn obìnrin olúwa rẹ sí àyà rẹ, èmi sì fi ìdílé Israẹli àti ti Juda fún ọ; tí àwọn wọ̀nyí bá sì kéré jù fún ọ èmi ìbá sì fún ọ sí i jù bẹ́ẹ̀ lọ. Èéṣe tí ìwọ fi kẹ́gàn ọ̀rọ̀ Olúwa, tí ìwọ fi ṣe nǹkan tí ó burú lójú rẹ̀, àní tí ìwọ fi fi idà pa Uriah ará Hiti, àti tí ìwọ fi mú obìnrin rẹ̀ láti fi ṣe obìnrin rẹ, o sì fi idà àwọn ọmọ Ammoni pa á. Ǹjẹ́ nítorí náà idà kì yóò kúrò ní ilé rẹ títí láé; nítorí pé ìwọ gàn mí, ìwọ sì mú aya Uriah ará Hiti láti ṣe aya rẹ.’ “Báyìí ni Olúwa wí, kíyèsi i, ‘Èmi ó jẹ́ kí ibi kí ó dìde sí ọ láti inú ilé rẹ wá, èmi ó sì gba àwọn obìnrin rẹ lójú rẹ, èmi ó sì fi wọ́n fún aládùúgbò rẹ, òun ó sì bá àwọn obìnrin rẹ sùn níwájú òòrùn yìí. Àti pé ìwọ ṣe é ní ìkọ̀kọ̀, ṣùgbọ́n èmi ó ṣe nǹkan yìí níwájú gbogbo Israẹli, àti níwájú òòrùn.’ ” Dafidi sì wí fún Natani pé, “Èmi ṣẹ̀ sí Olúwa!” Natani sì wí fún Dafidi pé, “Olúwa pẹ̀lú sì ti mú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ kúrò; ìwọ kì yóò kú. Ṣùgbọ́n nítorí nípa ìwà yìí, ìwọ fi ààyè sílẹ̀ fún àwọn ọ̀tá Olúwa láti sọ ọ̀rọ̀-òdì, ọmọ náà tí a ó bí fún ọ, kíkú ní yóò kú.” Ọmọ náà kú Natani sì lọ sí ilé rẹ̀ Olúwa sì fi ààrùn kọlu ọmọ náà tí obìnrin Uriah bí fún Dafidi, ó sì ṣe àìsàn púpọ̀. Dafidi sì bẹ Ọlọ́run nítorí ọmọ náà, Dafidi sì gbààwẹ̀, ó sì wọ inú ilé lọ, ó sì dùbúlẹ̀ lórí ilé ni òru náà. Àwọn àgbàgbà ilé rẹ̀ sì dìde tọ̀ ọ́ lọ, láti gbé e dìde lórí ilé, ó sì kọ̀, kò sì bá wọn jẹun. Ní ọjọ́ keje, ọmọ náà sì kú. Àwọn ìránṣẹ́ Dafidi sì bẹ̀rù láti wí fún un pé, ọmọ náà kú: nítorí tí wọ́n wí pé, “Kíyèsi i, nígbà tí ọmọ náà ń bẹ láààyè, àwa sọ̀rọ̀ fún un, òun kọ̀ si gbọ́ ohùn wa! Ǹjẹ́ yóò ti ṣe ara rẹ̀ ní èṣe tó, bí àwa bá wí fún un pé, ọmọ náà kú.” Nígbà tí Dafidi sì rí pé àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ń sọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́, Dafidi sì kíyèsi i, pé ọmọ náà kú, Dafidi sì béèrè lọ́wọ́ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, “Ọmọ náà kú bí?” Wọ́n sì dá a lóhùn pé, “Ó kú.” Dafidi sì dìde ní ilẹ̀, ó sì wẹ̀, ó fi òróró pa ara, ó sì pààrọ̀ aṣọ rẹ̀, ó sì wọ inú ilé Olúwa lọ, ó sì wólẹ̀ sin, ó sì wá sí ilé rẹ̀ ó sì béèrè, wọ́n sì gbé oúnjẹ kalẹ̀ níwájú rẹ̀, ó sì jẹun. Àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ sì bí léèrè pé, “Kí ni èyí tí ìwọ ṣe yìí? Nítorí ọmọ náà nígbà tí ó ń bẹ láààyè ìwọ gbààwẹ̀, o sì sọkún; ṣùgbọ́n nígbà tí ọmọ náà kú, ó dìde ó sì jẹun.” Ó sì wí pé, “Nígbà tí ọmọ náà ń bẹ láààyè, èmi gbààwẹ̀, èmi sì sọkún: nítorí tí èmi wí pé, ‘Ta ni ó mọ̀? Bí Olúwa ó ṣàánú mi, kí ọmọ náà le yè.’ Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, ó ti kú, nítorí kín ni èmi ó ṣe máa gbààwẹ̀? Èmi ha tún lè mú un padà bí? Èmi ni yóò tọ̀ ọ́ lọ, òun kì yóò sì tún tọ̀ mí wá.” Batṣeba sì tún bí ọmọ mìíràn tí a pè ní Solomoni Dafidi sì ṣìpẹ̀ fún Batṣeba aya rẹ̀, ó sì wọlé tọ̀ ọ́, ó sì bá a dàpọ̀, òun sì bí ọmọkùnrin kan, Dafidi sì sọ orúkọ rẹ̀ ní Solomoni, Olúwa sì fẹ́ ẹ. Ó sì rán Natani wòlíì, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Jedidiah, nítorí Olúwa. Ìṣẹ́gun Dafidi lórí àwọn Ammoni Joabu sì bá Rabba ti àwọn ọmọ Ammoni jagun, ó sì gba ìlú ọba wọn. Joabu sì rán àwọn ìránṣẹ́ sí Dafidi, ó sì wí pé, “Èmi ti bá Rabba jà, èmi sì ti gba àwọn ìlú olómi. Ǹjẹ́ nítorí náà kó àwọn ènìyàn ìyókù jọ, kí o sì dó ti ìlú náà, kí o sì gbà á, kí èmi má bá à gba ìlú náà kí a má ba à pè é ní orúkọ mi.” Dafidi sì kó gbogbo ènìyàn náà jọ, sí Rabba, ó sì bá a jà, ó sì gbà á. Òun sì gba adé ọba wọn kúrò lórí rẹ̀, ìwúwo rẹ̀ sì jẹ́ tálẹ́ǹtì wúrà kan, ó sì ní òkúta oníyebíye lára rẹ̀; a sì fi dé Dafidi lórí. Òun sì kó ìkógun ìlú náà ni ọ̀pọ̀lọpọ̀. Ó sì kó àwọn ènìyàn náà tí ó wà nínú rẹ̀, ó sì fi wọ́n sí iṣẹ́ ayùn, àti sí iṣẹ́ nǹkan ìtulẹ̀ tí a fi irin ṣe, àti sí iṣẹ́ àáké irin, ó sì fi wọ́n sí iṣẹ́ bíríkì ṣíṣe, bẹ́ẹ̀ náà ni òun sì ṣe sí gbogbo ìlú àwọn ọmọ Ammoni. Dafidi àti gbogbo àwọn ènìyàn náà sì padà sí Jerusalẹmu. Amnoni àti Tamari Ó sì ṣe, lẹ́yìn èyí, Absalomu ọmọ Dafidi ní àbúrò obìnrin kan tí ó ṣe arẹwà, orúkọ rẹ̀ a sì máa jẹ́ Tamari; Amnoni ọmọ Dafidi sì fẹ́ràn rẹ̀. Amnoni sì banújẹ́ títí ó fi ṣe àìsàn nítorí Tamari àbúrò rẹ̀ obìnrin; nítorí pé wúńdíá ni; ó sì ṣe ohun tí ó ṣòro lójú Amnoni láti bá a dàpọ̀. Ṣùgbọ́n Amnoni ní ọ̀rẹ́ kan, orúkọ rẹ̀ a sì máa jẹ́ Jonadabu, ọmọ Ṣimea ẹ̀gbọ́n Dafidi, Jonadabu sì jẹ́ alárékérekè ènìyàn gidigidi. Ó sì wí fún un pé, “Èéṣe tí ìwọ ọmọ ọba ń fi ń rù lójoojúmọ́ báyìí? Ǹjẹ́ o kò ní sọ fún mi?” Amnoni sì wí fún un pé, “Èmi fẹ́ Tamari àbúrò Absalomu arákùnrin mi.” Jonadabu sì wí fún un pé, “Dùbúlẹ̀ ní ibùsùn rẹ kí ìwọ sì díbọ́n pé, ìwọ kò sàn, baba rẹ yóò sì wá wò ọ́, ìwọ ó sì wí fún un pé, ‘Jọ̀wọ́ jẹ́ kí Tamari àbúrò mi wá kí ó sì fún mi ní oúnjẹ kí ó sì ṣe oúnjẹ náà níwájú mi kí èmi ó rí i, èmi ó sì jẹ ẹ́ ní ọwọ́ rẹ̀.’ ” Amnoni sì dùbúlẹ̀, ó sì díbọ́n pé òun ṣàìsàn, ọba sì wá wò ó, Amnoni sì wí fún ọba pé, “Jọ̀wọ́, jẹ́ kí Tamari àbúrò mi ó wá, kí ó sì dín àkàrà méjì lójú mi, èmi ó sì jẹ ní ọwọ́ rẹ̀.” Dafidi sì ránṣẹ́ sí Tamari ní ilé pé, “Lọ sí ilé Amnoni ẹ̀gbọ́n rẹ, kí ó sì se oúnjẹ fún un.” Tamari sì lọ sí ilé Amnoni ẹ̀gbọ́n rẹ̀, òun sì ń bẹ ní ìdùbúlẹ̀. Tamari sì mú ìyẹ̀fun, ó sì pò ó, ó sì fi ṣe àkàrà lójú rẹ̀, ó sì dín àkàrà náà. Òun sì mú àwo náà, ó sì dà á sínú àwo mìíràn níwájú rẹ̀; ṣùgbọ́n ó kọ̀ láti jẹ. Amnoni sì wí pé, “Jẹ́ kí gbogbo ọkùnrin jáde kúrò lọ́dọ̀ mi!” Wọ́n sì jáde olúkúlùkù ọkùnrin kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀. Amnoni sì wí fún Tamari pé, “Mú oúnjẹ náà wá sí yàrá, èmi ó sì jẹ ẹ́ lọ́wọ́ rẹ.” Tamari sì mú àkàrà tí ó ṣe, ó sì mú un tọ Amnoni ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ní yàrá. Nígbà tí ó sì súnmọ́ ọn láti fi oúnjẹ fún un, òun sì dìímú, ó sì wí fún un pé, “Wá dùbúlẹ̀ tì mí, àbúrò mi.” Òun sì dá a lóhùn wí pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́ ẹ̀gbọ́n mi, má ṣe tẹ́ mi; nítorí pé kò tọ kí a ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ní Israẹli, ìwọ má ṣe hùwà òmùgọ̀ yìí. Àti èmi, níbo ni èmi ó gbé ìtìjú mi wọ̀? Ìwọ ó sì dàbí ọ̀kan nínú àwọn aṣiwèrè ní Israẹli. Ǹjẹ́ nítorí náà, èmi bẹ̀ ọ́, sọ fún ọba; nítorí pé òun kì yóò kọ̀ láti fi mí fún ọ.” Ṣùgbọ́n ó kọ̀ láti gbọ́ ohùn rẹ̀; ó sì fi agbára mú un, ó sì ṣẹ́gun rẹ̀, ó sì bá a dàpọ̀. Amnoni sì kórìíra rẹ̀ gidigidi, ìríra náà sì wá ju ìfẹ́ tí òun ti ní sí i rí lọ. Amnoni sì wí fún un pé, “Dìde, kí o sì máa lọ!” Òun sì wí fún un pé, “Kó ha ní ìdí bí! Lílé tí ìwọ ń lé mi yìí burú ju èyí tí ìwọ ti ṣe sí mi lọ.” Ṣùgbọ́n òun kò fẹ́ gbọ́ tirẹ̀. Òun sì pe ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ tí í ṣe ìránṣẹ́ rẹ̀, ó sì wí fún un pé, “Jọ̀wọ́, ti obìnrin yìí sóde fún mi, kí o sì ti ìlẹ̀kùn mọ́ ọn.” Òun sì ní aṣọ aláràbarà kan lára rẹ̀, nítorí irú aṣọ àwọ̀lékè bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọbìnrin ọba tí í ṣe wúńdíá máa ń wọ̀. Ìránṣẹ́ rẹ̀ sì mú un jáde, ó sì ti ìlẹ̀kùn mọ́ ọn. Tamari sì bu eérú sí orí rẹ̀, ó sì fa aṣọ aláràbarà tí ń bẹ lára rẹ̀ ya, ó sì ká ọwọ́ rẹ̀ lé orí, ó sì ń kígbe bí ó ti ń lọ. Absalomu kọlu Amnoni Absalomu ẹ̀gbọ́n rẹ̀ sì bí i léèrè pé, “Amnoni ẹ̀gbọ́n rẹ bá ọ sùn bí? Ǹjẹ́ àbúrò mi, dákẹ́; ẹ̀gbọ́n rẹ ní í ṣe; má fi nǹkan yìí sí ọkàn rẹ.” Tamari sì jókòó ní ìbànújẹ́ ní ilé Absalomu ẹ̀gbọ́n rẹ̀. Ṣùgbọ́n nígbà tí Dafidi ọba gbọ́ gbogbo nǹkan wọ̀nyí, inú rẹ̀ bàjẹ́ gidigidi. Absalomu kò sì bá Amnoni sọ nǹkan rere, tàbí búburú, nítorí pé Absalomu kórìíra Amnoni nítorí èyí tí ó ṣe, àní tí ó fi agbára mú Tamari àbúrò rẹ̀. Ó sì ṣe, lẹ́yìn ọdún méjì, Absalomu sì ní olùrẹ́run àgùntàn ní Baali-Hasori, èyí tí ó gbé Efraimu, Absalomu sì pe gbogbo àwọn ọmọ ọba. Absalomu sì tọ ọba wá, ó sì wí pé, “Wò ó, jọ̀wọ́, ìránṣẹ́ rẹ ní olùrẹ́run àgùntàn, èmi bẹ̀ ọ́, jẹ́ kí ọba, àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ bá ìránṣẹ́ rẹ lọ.” Ọba sì wí fún Absalomu pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ, ọmọ mi, mo bẹ̀ ọ́, má ṣe jẹ́ kí gbogbo wa lọ, kí a má bá à mú ọ náwó púpọ̀.” Ó sì rọ̀ ọ́ gidigidi, ṣùgbọ́n òun kò fẹ́ lọ, òun sì súre fún un. Absalomu sì wí pé, “Bí kò bá le rí bẹ́ẹ̀, èmi bẹ̀ ọ́, jẹ́ kí Amnoni ẹ̀gbọ́n mi bá wa lọ.” Ọba sì wí pé, “Ìdí rẹ̀ tí yóò fi bá ọ lọ.” Absalomu sì rọ̀ ọ́, òun sì jẹ́ kí Amnoni àti gbogbo àwọn ọmọ ọba bá a lọ. Absalomu sì fi àṣẹ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, “Kí ẹ̀yin máa kíyèsi àkókò tí ọtí-wáinì yóò mú ọkàn Amnoni dùn, èmi ó sì wí fún yín pé, ‘Kọlu Amnoni,’ kí ẹ sì pa á. Ẹ má bẹ̀rù. Ṣé èmi ni ó fi àṣẹ fún yin? Ẹ ṣe gírí, kí ẹ ṣe bí alágbára ọmọ.” Àwọn ìránṣẹ́ Absalomu sì ṣe sí Amnoni gẹ́gẹ́ bí Absalomu ti pàṣẹ. Gbogbo àwọn ọmọ ọba sì dìde, olúkúlùkù gun ìbáaka rẹ̀, wọ́n sì sá. Nígbà tí wọ́n ń bẹ lọ́nà, ìròyìn sì dé ọ̀dọ̀ Dafidi pé, “Absalomu pa gbogbo àwọn ọmọ ọba, ọ̀kan kò sì kù nínú wọn.” Ọba sì dìde, ó sì fa aṣọ rẹ̀ ya, ó sì dùbúlẹ̀ ni ilẹ̀; gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tí wọ́n dúró tì í sì fà aṣọ wọn ya. Jonadabu ọmọ Ṣimea arákùnrin Dafidi sì dáhùn ó sì wí pé, “Kí olúwa mi ọba má ṣe rò pé wọ́n ti pa gbogbo àwọn ọ̀dọ́mọdékùnrin àwọn ọmọ ọba; nítorí pé Amnoni nìkan ṣoṣo ni ó kú, nítorí láti ẹnu Absalomu wá ni a ti pinnu rẹ̀ láti ọjọ́ tí ó ti fi agbára mú Tamari àbúrò rẹ̀. Ǹjẹ́ kí olúwa mi ọba má ṣe fi nǹkan yìí sí ọkàn pé gbogbo àwọn ọmọ ọba ni o kú, nítorí Amnoni nìkan ṣoṣo ni ó kú.” Absalomu sálọ sí Geṣuri Absalomu sì sá. Ọ̀dọ́mọkùnrin náà ti ń ṣọ́nà sì gbé ojú rẹ̀ sókè, o si rí i pé, “Ọ̀pọ̀ ènìyàn ń bọ́ lọ́nà lẹ́yìn rẹ̀ láti ìhà òkè wá.” Jonadabu sì wí fún ọba pé, “Wò ó, àwọn ọmọ ọba ń bọ́; gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ ìránṣẹ́ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ó rí.” Nígbà tí ó sì parí ọ̀rọ̀ tí ó ń sọ, sì wò ó àwọn ọmọ ọba dé, wọ́n sì gbé ohùn wọn sókè, wọ́n sì sọkún, ọba àti gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pẹ̀lú sì sọkún ńlá ńlá. Absalomu sì sá, ó sì tọ Talmai lọ, ọmọ Ammihudu, ọba Geṣuri. Dafidi sì ń káàánú nítorí ọmọ rẹ̀ lójoojúmọ́. Absalomu sì sá, ó sì lọ sí Geṣuri ó sì gbé ibẹ̀ lọ́dún mẹ́ta. Ọkàn Dafidi ọba sì fà gidigidi sí Absalomu, nítorí tí ó tí gba ìpẹ̀ ní ti Amnoni: ó sá à ti kú. Absalomu padà si Jerusalẹmu Joabu ọmọ Seruiah sì kíyèsi i, pé ọkàn ọba sì fà sí Absalomu. Joabu sì ránṣẹ́ sí Tekoa, ó sì mú ọlọ́gbọ́n obìnrin kan láti ibẹ̀ wá, ó sì wí fún un pé, “Èmi bẹ̀ ọ́, ṣe bí ẹni tí ń ṣọ̀fọ̀, kí o sì fi aṣọ ọ̀fọ̀ sára, kí o má sì ṣe fi òróró pa ara, kí o sì dàbí obìnrin ti ó ti ń ṣọ̀fọ̀ fún òkú lọ́jọ́ púpọ̀. Kí o sì tọ ọba wá, kí o sọ fún un gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ yìí.” Joabu sì fi ọ̀rọ̀ sí lẹ́nu. Nígbà tí obìnrin àrá Tekoa sì ń fẹ́ sọ̀rọ̀ fún ọba, ó wólẹ̀, ó dojúbolẹ̀, o sí bu ọlá fún un, o sì wí pé, “Ọba, gbà mi.” Ọba sì bi í léèrè pé, “Kín ni o ṣe ọ́?” Òun sì dáhùn wí pé, “Nítòótọ́ opó ni èmi ń ṣe, ọkọ mi sì kú. Ìránṣẹ́bìnrin rẹ̀ sì ti ní ọmọkùnrin méjì, àwọn méjèèjì sì jọ jà lóko, kò sì si ẹni tí yóò là wọ́n, èkínní sì lu èkejì, ó sì pa á. Sì wò ó, gbogbo ìdílé dìde sí ìránṣẹ́bìnrin rẹ̀, wọ́n sì wí pé, ‘Fi ẹni tí ó pa arákùnrin rẹ fún wa, àwa ó sì pa á ní ipò ẹ̀mí arákùnrin rẹ̀ tí ó pa, àwa ó sì pa àrólé náà run pẹ̀lú.’ Wọn ó sì pa iná mi tí ó kù, wọn kì yóò sì fi orúkọ tàbí ẹni tí ó kú sílẹ̀ fún ọkọ mi ní ayé.” Ọba sì wí fún obìnrin náà pé, “Lọ sí ilé rẹ̀, èmi ó sì kìlọ̀ nítorí rẹ.” Obìnrin ará Tekoa náà sì wí fún ọba pé, “Olúwa mi, ọba, jẹ́ kí ẹ̀ṣẹ̀ náà wà lórí mi, àti lórí ìdílé baba mí; kí ọba àti ìtẹ́ rẹ̀ ó jẹ́ aláìlẹ́bi.” Ọba sì wí pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá sọ̀rọ̀ sí ọ, mú ẹni náà tọ̀ mí wá, òun kì yóò sì tọ́ ọ mọ́.” Ó sì wí pé, “Èmi bẹ̀ ọ́ jẹ́ kí ọba ó rántí Olúwa Ọlọ́run rẹ̀, kí olùgbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ má ṣe ní ipá láti ṣe ìparun, kí wọn o má bá a pa ọmọ mi!” Òun sì wí pé, “Bí Olúwa ti ń bẹ láààyè ọ̀kan nínú irun orí ọmọ rẹ ki yóò bọ sílẹ̀.” Ẹ̀bẹ̀ ní ti Absalomu Obìnrin náà sì wí pé, “Èmí bẹ̀ ọ́, jẹ́ kí ìránṣẹ́bìnrin rẹ sọ̀rọ̀ kan fún olúwa mi ọba.” Òun si wí pé, “Máa wí.” Obìnrin náà sì wí pé, “Nítorí kín ni ìwọ sì ṣe ro irú nǹkan yìí sí àwọn ènìyàn Ọlọ́run? Nítorí pé ní sísọ nǹkan yìí ọba ní ẹ̀bi, nítorí pé ọba kò mú ìsáǹsá rẹ̀ bọ̀ wá ilé. Nítorí pé àwa ó sá à kú, a ó sì dàbí omi tí a tú sílẹ̀ tí a kò sì lè ṣàjọ mọ́; nítorí bí Ọlọ́run kò ti gbà ẹ̀mí rẹ̀, ó sì ti ṣe ọ̀nà kí a má bá a lé ìsáǹsá rẹ̀ kúrò lọ́dọ̀ rẹ. “Ǹjẹ́ nítorí náà ni èmi sì ṣe wá sọ nǹkan yìí fún olúwa mi ọba, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ènìyàn ti dẹ́rùbà mí; ìránṣẹ́bìnrin rẹ sì wí pé, ‘Ǹjẹ́ èmi ó sọ fún ọba; ó lè rí bẹ́ẹ̀ pé ọba yóò ṣe ìfẹ́ ìránṣẹ́bìnrin rẹ̀ fún un. Nítorí pé ọba ò gbọ́, láti gbà ìránṣẹ́bìnrin rẹ sílẹ̀ lọ́wọ́ ọkùnrin náà tí ó ń fẹ́ gé èmi àti ọmọ mi pẹ̀lú kúrò nínú ilẹ̀ ìní Ọlọ́run.’ “Ìránṣẹ́bìnrin rẹ̀ sì wí pé, ‘Ǹjẹ́ ọ̀rọ̀ ọba olúwa mi yóò sì jásí ìtùnú; nítorí bí angẹli Ọlọ́run bẹ́ẹ̀ ni olúwa mi ọba láti mọ rere àti búburú: Olúwa Ọlọ́run rẹ yóò sì wà pẹ̀lú rẹ.’ ” Dafidi mọ̀ pé Joabu ni ó ṣe èyí Ọba sì dáhùn, ó sì wí fún obìnrin náà pé, “Má ṣe fi nǹkan tí èmi ó béèrè lọ́wọ́ rẹ pamọ́ fún mi, èmi bẹ̀ ọ́.” Obìnrin náà wí pé, “Jẹ́ kí olúwa mi ọba máa wí?” Ọba sì wí pé, “Ọwọ́ Joabu kò ha wà pẹ̀lú rẹ nínú gbogbo èyí?” Obìnrin náà sì dáhùn ó sì wí pé, “Bí ẹ̀mí rẹ ti ń bẹ láààyè, olúwa mi ọba, kò sí ìyípadà sí ọwọ́ ọ̀tún, tàbí sí ọwọ́ òsì nínú gbogbo èyí tí olúwa mi ọba ti wí, nítorí pé Joabu ìránṣẹ́ rẹ, òun ni ó rán mi, òun ni ó sì fi gbogbo ọ̀rọ̀ wọ̀nyí sí ìránṣẹ́bìnrin rẹ lẹ́nu. Láti mú irú ọ̀rọ̀ wọ̀nyí wá ni Joabu ìránṣẹ́ rẹ ṣe ṣe nǹkan yìí: olúwa mi sì gbọ́n, gẹ́gẹ́ bí ọgbọ́n angẹli Ọlọ́run, láti mọ gbogbo nǹkan tí ń bẹ̀ ní ayé.” Absalomu padà wá sí ilé Ọba sì wí fún Joabu pé, “Wò ó, èmi ó ṣe nǹkan yìí, nítorí náà lọ, kí o sì mú ọmọdékùnrin náà Absalomu padà wá.” Joabu sì wólẹ̀ ó dojú rẹ̀ bolẹ̀, ó sì tẹríba fún un, ó sì súre fún ọba. Joabu sì wí pé, “Lónìí ni ìránṣẹ́ rẹ mọ̀ pé, èmi rí oore-ọ̀fẹ́ gbà lójú rẹ, olúwa mi, ọba, nítorí pé ọba ṣe ìfẹ́ ìránṣẹ́ rẹ̀.” Joabu sì dìde, ó sì lọ sí Geṣuri, ó sì mú Absalomu wá sí Jerusalẹmu. Ọba sì wí pé, “Jẹ́ kí ó yípadà lọ sí ilé rẹ̀, má ṣe jẹ́ kí ó rí ojú mi.” Absalomu sì yípadà sí ilé rẹ̀, kò sì rí ojú ọba. Ẹwà Absalomu àti àwọn ọmọ rẹ̀ Kó sì sí arẹwà kan ní gbogbo Israẹli tí à bá yìn bí Absalomu: láti àtẹ́lẹsẹ̀ rẹ̀ títí dé àtàrí rẹ̀ kò sí àbùkù kan lára rẹ̀. Nígbà tí ó bá sì rẹ́ irun orí rẹ̀ (nítorí pé lọ́dọọdún ni òun máa ń rẹ́ ẹ. Nígbà tí ó bá wúwo fún un, òun a sì máa rẹ́ ẹ) òun sì wọn irun orí rẹ̀, ó sì jásí igba ṣékélì nínú òsùwọ̀n ọba. A sì bí ọmọkùnrin mẹ́ta fún Absalomu àti ọmọbìnrin kan ti orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Tamari: òun sì jẹ́ obìnrin tí ó lẹ́wà lójú. Ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ Absalomu Absalomu sì gbé ni ọdún méjì ní Jerusalẹmu kò sì rí ojú ọba. Absalomu sì ránṣẹ́ sí Joabu, láti rán an sí ọba, ṣùgbọ́n òun kò fẹ́ wá sọ́dọ̀ rẹ̀; ó sì ránṣẹ́ lẹ́ẹ̀kejì òun kò sì fẹ́ wá. Ó sì wí fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, “Wò ó, oko Joabu gbé ti èmi, ó sì ní ọkà barle níbẹ̀; ẹ lọ kí ẹ sì ti iná bọ̀ ọ́.” Àwọn ìránṣẹ́ Absalomu sì tiná bọ oko náà. Joabu sì dìde, ó sì tọ Absalomu wá ní ilé, ó sì wí fún un pé, “Èéṣe tí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ fi tiná bọ oko mi?” Absalomu sì dá Joabu lóhùn pé, “Wò ó, èmi ránṣẹ́ sí ọ, wí pé, ‘Wá níhìn-ín yìí, èmi ó sì rán ọ lọ sọ́dọ̀ ọba, láti béèrè pé, “Kí ni èmi ti Geṣuri wá si? Ìbá sàn fún mí bí ó ṣe pé èmi wà lọ́hùn ún síbẹ̀!” ’ Ǹjẹ́ nísinsin yìí jẹ́ kí èmi lọ síwájú ọba bí ó bá sì ṣe ẹ̀bi ń bẹ nínú mi, kí ó pa mí.” Joabu sì tọ ọba wá, ó sì rò fún un: ó sì ránṣẹ́ pe Absalomu, òun sì wá sọ́dọ̀ ọba, ó tẹríba fún un, ó sì dojú rẹ̀ bolẹ̀ níwájú ọba, ọba sì fi ẹnu ko Absalomu lẹ́nu. Absalomu dìtẹ̀ sí Dafidi baba rẹ̀ Lẹ́yìn èyí náà, Absalomu sì pèsè kẹ̀kẹ́ àti ẹṣin fún ara rẹ̀, àti àádọ́ta ọmọkùnrin tí yóò máa sáré níwájú rẹ̀. Absalomu sì dìde ní kùtùkùtù, ó sì dúró ní apá kan ọ̀nà ẹnu ibodè. Bí ẹnìkan bá ní ẹjọ́ tí ó ń fẹ́ mú tọ ọba wá fún ìdájọ́, a sì pè é sọ́dọ̀ rẹ̀, a sì bi í pé, “Ará ìlú wo ni ìwọ?” Òun a sì dáhùn pé, “Ìránṣẹ́ rẹ ti inú ọ̀kan nínú ẹ̀yà Israẹli wá.” Absalomu yóò sì wí fún un pé, “Wò ó, ọ̀ràn rẹ ṣá dára, ó sì tọ́, ṣùgbọ́n kò sí ẹnìkan tí ọba fi àṣẹ fún láti gbọ́ ọ̀ràn rẹ.” Absalomu a sì wí pé, “À bá jẹ́ fi mi ṣe onídàájọ́ ní ilẹ̀ yìí! Kí olúkúlùkù ẹni tí ó ní ẹjọ́ tàbí ọ̀ràn kan bá à lè máa tọ̀ mí wá, èmi ìbá sì ṣe ìdájọ́ òtítọ́ fún un.” Bẹ́ẹ̀ ni bí ẹnìkan bá sì súnmọ́ láti tẹríba fún un, òun a sì nawọ́ rẹ̀, a sì dìímú, a sì fi ẹnu kò ó lẹ́nu. Irú ìwà báyìí ni Absalomu a máa hù sí gbogbo Israẹli tí ó tọ́ ọba wá nítorí ìdájọ́, Absalomu sì fi fa ọkàn àwọn ènìyàn Israẹli sọ́dọ̀ rẹ̀. Ó sì ṣe lẹ́yìn ogójì ọdún, Absalomu sì wí fún ọba pé, “Èmi bẹ́ ọ́, jẹ́ kí èmi ó lọ, kí èmi sì san ìlérí mi tí èmi ti ṣe fún Olúwa, ní Hebroni. Nítorí tí ìránṣẹ́ rẹ ti jẹ́ ẹ̀jẹ́ kan nígbà tí èmi ń bẹ ní Geṣuri ní Siria pé, ‘Bí Olúwa bá mú mi padà wá sí Jerusalẹmu, nítòótọ́, èmi ó sì sin Olúwa.’ ” Ọba sì wí fún un pé, “Máa lọ ní àlàáfíà.” Ó sì dìde, ó sì lọ sí Hebroni. Ṣùgbọ́n Absalomu rán àmì sáàrín gbogbo ẹ̀yà Israẹli pé, “Nígbà tí ẹ̀yin bá gbọ́ ìró ìpè, kí ẹ̀yin sì wí pé, ‘Absalomu jẹ ọba ní Hebroni.’ ” Igba ọkùnrin sì bá Absalomu ti Jerusalẹmu jáde, nínú àwọn tí a ti pè; wọ́n sì lọ nínú àìmọ̀kan wọn, wọn kò sì mọ nǹkan kan. Absalomu sì ránṣẹ́ pe Ahitofeli ará Giloni, ìgbìmọ̀ Dafidi, láti ìlú rẹ̀ wá, àní láti Giloni, nígbà tí ó ń rú ẹbọ. Ìdìmọ̀lù náà sì le; àwọn ènìyàn sì ń pọ̀ sọ́dọ̀ Absalomu. Dafidi sálọ kúrò lórí oyè Ẹnìkan sì wá rò fún Dafidi pé, “Ọkàn àwọn ọkùnrin Israẹli ṣí sí Absalomu.” Dafidi sì wí fún gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tí ó wá lọ́dọ̀ rẹ̀ ni Jerusalẹmu pé, “Ẹ dìde! Ẹ jẹ́ kí a sálọ, nítorí pé kò sí ẹni tí yóò gbà wá lọ́wọ́ Absalomu; ẹ yára, kí a lọ kúrò, kí òun má bá à yára lé wa bá, kí ó má sì mú ibi bá wa, kí ó má sì fi ojú idà pa ìlú run.” Àwọn ìránṣẹ́ ọba sì wí fún ọba pé, “Gẹ́gẹ́ bí gbogbo èyí tí olúwa wa ọba ń fẹ́, wò ó, àwa ìránṣẹ́ rẹ̀ ti murá.” Ọba sì jáde, gbogbo ilé rẹ̀ sì tẹ̀lé e. Ọba sì fì mẹ́wàá nínú àwọn obìnrin rẹ̀ sílẹ̀ láti máa ṣọ́ ilé. Ọba sì jáde, gbogbo ènìyàn sì tẹ̀lé e, wọ́n sì dúró ní ibìkan tí ó jìnnà. Gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ sì kọjá sí iwájú rẹ̀, àti gbogbo àwọn Kereti, àti gbogbo àwọn Peleti, àti gbogbo àwọn ará Gitti, ẹgbẹ̀ta (600) ọmọkùnrin tí ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn láti Gati wá, sì kọjá níwájú ọba. Ìwà òótọ́ Itai ará Gitti Ọba sì wí fún Ittai ará Gitti pé, “Èéṣe tí ìwọ fi ń bá wa lọ pẹ̀lú, padà, kí o sì ba ọba jókòó; nítorí pé àlejò ni ìwọ, ìwọ sì ti fi ìlú rẹ sílẹ̀. Lánàá yìí ni ìwọ dé, èmi ó ha sì mú kí ìwọ máa bá wá lọ káàkiri lónìí bí? Èmi ń lọ sí ibikíbi tí mo bá rí: padà, kí o sì mú àwọn arákùnrin rẹ padà, kí àánú àti òtítọ́ Olúwa wà pẹ̀lú rẹ.” Ittai sì dá ọba lóhùn, ó sì wí pé, “Bí Olúwa tí ń bẹ láààyè, àti bí olúwa mi ọba ti ń bẹ láààyè, nítòótọ́ níbikíbi tí olúwa mi ọba bá gbé wà, ìbá à ṣe nínú ikú, tàbí nínú ìyè, níbẹ̀ pẹ̀lú ni ìránṣẹ́ rẹ yóò gbé wà.” Dafidi sì wí fún Ittai pé, “Lọ kí o sì rékọjá!” Ittai ará Gitti náà sì rékọjá, àti gbogbo àwọn ọmọkùnrin rẹ̀, àti gbogbo àwọn ọmọ kéékèèké tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀. Gbogbo ìlú náà sì fi ohùn rara sọkún, gbogbo ènìyàn sì rékọjá; ọba sì rékọjá àfonífojì Kidironi, gbogbo àwọn ènìyàn náà sì rékọjá, sí ìhà ọ̀nà ijù. A gbé àpótí ẹ̀rí padà sí ìlú Jerusalẹmu Sì wò ó, Sadoku pẹ̀lú àti gbogbo àwọn ọmọ Lefi tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ sí ń ru àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run, wọ́n sì gbé àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run náà sọ̀kalẹ̀; Abiatari sí gòkè, títí gbogbo àwọn ènìyàn sì fi dẹ́kun àti máa kọjá láti ìlú wá. Ọba sì wí fún Sadoku pé, “Sì tún gbé àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run náà padà sí ìlú, bí èmi bá rí ojúrere gbà lọ́dọ̀ Olúwa, yóò sì tún mú mi padà wá, yóò sì fi àpótí ẹ̀rí náà hàn mí àti ibùgbé rẹ̀. Ṣùgbọ́n bí òun bá sì wí pé, ‘Èmi kò ní inú dídùn sí ọ,’ wò ó, èmi nìyìí, jẹ́ kí òun ó ṣe sí mi gẹ́gẹ́ bí ó ti tọ́ ní ojú rẹ̀.” Ọba sì wí fún Sadoku àlùfáà pé, “Aríran ha kọ́ ni ọ́? Padà sí ìlú ní àlàáfíà, àti àwọn ọmọ rẹ méjèèjì pẹ̀lú rẹ, Ahimasi ọmọ rẹ, àti Jonatani ọmọ Abiatari. Wò ó, èmi ó dúró ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ ijù náà, títí ọ̀rọ̀ ó fi ti ọ̀dọ̀ rẹ̀ wá láti sọ fún mi.” Sadoku àti Abiatari sì gbé àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run padà sí Jerusalẹmu, wọ́n sì gbé ibẹ̀. Ahitofeli lọ́wọ́ sí ìdìtẹ̀ náà Dafidi sì ń gòkè lọ ní òkè igi olifi, o sì ń sọkún bí ó ti ń gòkè lọ, ó sì bo orí rẹ̀, ó ń lọ láìní bàtà ní ẹsẹ̀, gbogbo ènìyàn tí o wà lọ́dọ̀ rẹ̀, olúkúlùkù ọkùnrin sì bo orí rẹ̀, wọ́n sì ń gòkè lọ, wọ́n ń sọkún bí wọ́n ti ń gòkè lọ. Ẹnìkan sì sọ fún Dafidi pé, “Ahitofeli wà nínú àwọn aṣọ̀tẹ̀ pẹ̀lú Absalomu.” Dafidi sì wí pé, “Olúwa, èmi bẹ̀ ọ́, sọ ìmọ̀ Ahitofeli di asán.” Huṣai padà sí Jerusalẹmu Ó sì ṣe, Dafidi dé orí òkè, níbi tí ó gbé wólẹ̀ sin Ọlọ́run, sì wò ó, Huṣai ará Arki sì wá láti pàdé rẹ̀ pẹ̀lú aṣọ rẹ̀ yíya, àti erùpẹ̀, lórí rẹ̀. Dafidi sì wí fún un pé, “Bí ìwọ bá bá mi kọjá, ìwọ ó sì jẹ́ ìdíwọ́ fún mi. Bí ìwọ bá sì padà sí ìlú, tí o sì wí fún Absalomu pé, ‘Èmi ó ṣe ìránṣẹ́ rẹ ọba, gẹ́gẹ́ bí èmi ti ṣe ìránṣẹ́ baba rẹ nígbà àtijọ́, bẹ́ẹ̀ ni èmi ó sì jẹ́ ìránṣẹ́ rẹ nísinsin yìí,’ kí ìwọ sì bá ìmọ̀ Ahitofeli jẹ́. Ṣé Sadoku àti Abiatari àwọn àlùfáà wà níbẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀? Yóò sì ṣe, ohunkóhun tí ìwọ bá gbọ́ láti ilé ọba wá, ìwọ ó sì sọ fún Sadoku àti Abiatari àwọn àlùfáà. Wò ó, àwọn ọmọ wọn méjèèjì sì wà níbẹ̀ pẹ̀lú wọn, Ahimasi ọmọ Sadoku, àti Jonatani ọmọ Abiatari; láti ọwọ́ wọn ni ẹ̀yin ó sì rán ohunkóhun tí ẹ̀yin bá gbọ́ sí mi.” Huṣai ọ̀rẹ́ Dafidi sì wá sí ìlú, Absalomu sì wá sí Jerusalẹmu. Dafidi àti Ṣiba Nígbà tí Dafidi sì fi díẹ̀ kọjá orí òkè náà, sì wò ó, Ṣiba ìránṣẹ́ Mefiboṣeti sì ń bọ̀ wá pàdé rẹ̀, òun àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ méjì tí a ti dì ní gàárì, àti igba ìṣù àkàrà lórí wọn, àti ọgọ́rùn-ún síírí àjàrà gbígbẹ, àti ọgọ́rùn-ún èso ẹ̀rún, àti ìgò ọtí wáìnì kan. Ọba sì wí fún Ṣiba pé, “Kí ni wọ̀nyí?” Ṣiba sì wí pé, “Kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọ̀nyí ni fún àwọn ará ilé ọba láti máa gùn àti àkàrà yìí, àti èso ẹ̀rún yìí ni fún àwọn ọ̀dọ́mọdékùnrin láti jẹ; àti ọtí wáìnì yìí ni fún àwọn aláàárẹ̀ ní ijù láti mu.” Ọba sì wí pé, “Ọmọ olúwa rẹ dà?” Ṣiba sì wí fún ọba pé, “Wò ó, ó jókòó ní Jerusalẹmu; nítorí tí ó wí pé, ‘Lónìí ni ìdílé Israẹli yóò mú ìjọba baba mi padà wá fún mi.’ ” Ọba sì wí fún Ṣiba pé, “Wò ó, gbogbo nǹkan tí í ṣe ti Mefiboṣeti jẹ́ tìrẹ.” Ṣiba sì wí pé, “Mo túúbá, jẹ́ kí n rí oore-ọ̀fẹ́ lójú rẹ, olúwa mi ọba.” Ṣimei Bú Dafidi Dafidi ọba sì dé Bahurimu, sì wò ó, ọkùnrin kan ti ibẹ̀ jáde wá, láti ìdílé Saulu wá, orúkọ rẹ̀ sì ń jẹ́ Ṣimei, ọmọ Gera, ó sì ń bú èébú bí o tí ń bọ̀. Ó sì sọ òkúta sí Dafidi, àti sí gbogbo ìránṣẹ́ Dafidi ọba, àti sí gbogbo ènìyàn, gbogbo àwọn alágbára ọkùnrin sì wà lọ́wọ́ ọ̀tún rẹ̀ àti lọ́wọ́ òsì rẹ̀. Báyìí ni Ṣimei sì wí nígbà tí ó ń yọ èébú, “Jáde, ìwọ ọkùnrin ẹ̀jẹ̀, ìwọ ọkùnrin Beliali. Olúwa mú gbogbo ẹ̀jẹ̀ ìdílé Saulu padà wá sí orí rẹ, ní ipò ẹni tí ìwọ jẹ ọba; Olúwa ti fi ìjọba náà lé Absalomu ọmọ rẹ lọ́wọ́: sì wò ó, ìwà búburú rẹ ni ó mú èyí wá bá ọ, nítorí pé ọkùnrin ẹ̀jẹ̀ ni ìwọ.” Abiṣai ọmọ Seruiah sì wí fún ọba pé, “Èéṣe tí òkú ajá yìí fi ń bú olúwa mi ọba? Jẹ́ kí èmi kọjá, èmi bẹ̀ ọ́, kí èmi sì bẹ́ ẹ́ lórí.” Ọba sì wí pé, “Kín ni èmi ní ṣe pẹ̀lú yín, ẹ̀yin ọmọ Seruiah? Bí ó bá ń bú èébú, nítorí tí Olúwa ti wí fún un pé, ‘Bú Dafidi!’ Ta ni yóò sì wí pé, ‘Kín ni ìdí tí o fi ṣe bẹ́ẹ̀.’ ” Dafidi sì wí fún Abiṣai, àti fún gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, “Wò ó, ọmọ mi tí ó ti inú mi wá, ń wá mi kiri, ǹjẹ́ mélòó mélòó ni ará Benjamini yìí yóò sì ṣe? Fi í sílẹ̀, sì jẹ́ kí o máa yan èébú; nítorí pé Olúwa ni ó sọ fún un. Bóyá Ọlọ́run yóò wo ìpọ́njú mi, Olúwa yóò sì fi ìre san án fún mi ní ipò èébú rẹ̀ lónìí.” Dafidi àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ sì ń lọ ní ọ̀nà, Ṣimei sì ń rìn òdìkejì òkè tí ó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀, ó sì ń yan èébú bí ó ti ń lọ, ó sì ń sọ ọ́ lókùúta, ó sì ń fọ́n erùpẹ̀. Ọba, àti gbogbo àwọn ènìyàn tí ó ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ̀ sì dé Jordani, ó sì rẹ̀ wọ́n, wọ́n sì sinmi níbẹ̀. Huṣai farahàn Absalomu bí ẹni tí ó ní ìfẹ́ sí i Absalomu àti gbogbo àwọn ènìyàn, àwọn ọkùnrin Israẹli sì wá sí Jerusalẹmu, Ahitofeli sì wà pẹ̀lú rẹ̀. Ó sì ṣe, nígbà tí Huṣai ará Arki, ọ̀rẹ́ Dafidi tọ Absalomu wá, Huṣai sì wí fún Absalomu pé, “Kí ọba ó pẹ́! Kí ọba ó pẹ́.” Absalomu sì wí fún Huṣai pé, “Oore rẹ sí ọ̀rẹ́ rẹ ni èyí? Èéṣe tí ìwọ kò bá ọ̀rẹ́ rẹ lọ?” Huṣai sì wí fún Absalomu pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́ nítorí ẹni tí Olúwa, àti gbogbo àwọn ènìyàn yìí, àti gbogbo àwọn ọkùnrin Israẹli bá yàn, tirẹ̀ lèmi ó jẹ́, òun lèmi ó sì bá jókòó. Àti pé, ta ni èmi ó sì sìn? Kò ha yẹ kí èmi ó máa sìn níwájú ọmọ rẹ̀? Gẹ́gẹ́ bí èmi ti ń sìn rí níwájú baba rẹ, bẹ́ẹ̀ ni èmi ó sìn níwájú rẹ.” Absalomu wọlé tọ àwọn obìnrin baba rẹ̀ Absalomu sì wí fún Ahitofeli pé, “Ẹ bá ará yín gbìmọ̀ ohun tí àwa ó ṣe.” Ahitofeli sì wí fún Absalomu pé, “Wọlé tọ àwọn obìnrin baba rẹ lọ, tí ó fi sílẹ̀ láti máa ṣọ́ ilé, gbogbo Israẹli yóò sì gbọ́ pé, ìwọ di ẹni ìríra sí baba rẹ, ọwọ́ gbogbo àwọn tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ yóò sì le.” Wọ́n sì tẹ́ àgọ́ kan fún Absalomu ní òrùlé; Absalomu sì wọlé tọ àwọn obìnrin baba rẹ̀ lójú gbogbo Israẹli. Ìmọ̀ Ahitofeli tí ó máa ń gbà ni ìgbà náà, ó dàbí ẹni pé ènìyàn béèrè nǹkan lọ́wọ́ Ọlọ́run, bẹ́ẹ̀ ni gbogbo ìmọ̀ Ahitofeli fún Dafidi àti fún Absalomu sì rí. Ahitofeli gbìmọ̀ pé kí a lépa Dafidi Ahitofeli sì wí fún Absalomu pé, “Èmi ó yan ẹgbàá mẹ́fà (12,000) ọkùnrin èmi ó sì dìde, èmi ó sì lépa Dafidi lóru yìí. Èmi ó sì yọ sí i nígbà tí àárẹ̀ bá mú un tí ọwọ́ rẹ̀ sì ṣe aláìle, èmi ó sì dá a ní ìjì, gbogbo àwọn ènìyàn tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ yóò sì sá, èmi ó sì kọlu ọba nìkan ṣoṣo. Èmi ó sì mú gbogbo àwọn ènìyàn padà sọ́dọ̀ rẹ bi ìgbà tí ìyàwó bá padà sí ọ̀dọ̀ ọkọ rẹ̀. Ọkàn ẹnìkan ṣoṣo tí ìwọ ń wá yìí ni ó túmọ̀ sí ìpadàbọ̀ gbogbo wọn; gbogbo àwọn ènìyàn yóò sì wà ní àlàáfíà.” Ọ̀rọ̀ náà sì tọ́ lójú Absalomu, àti lójú gbogbo àwọn àgbàgbà Israẹli. Huṣai fi ọgbọ́n yí ìmọ̀ náà po Absalomu sì wí pé, “Ǹjẹ́ pe Huṣai ará Arki, àwa ó sì gbọ́ èyí tí ó wà lẹ́nu rẹ̀ pẹ̀lú.” Huṣai sì dé ọ̀dọ̀ Absalomu, Absalomu sì wí fún un pé, “Báyìí ni Ahitofeli wí, kí àwa ṣe bí ọ̀rọ̀ rẹ bí? Bí ko bá sì tọ́ bẹ́ẹ̀, ìwọ wí.” Huṣai sì wí fún Absalomu pé, “Ìmọ̀ tí Ahitofeli gbà yìí, kò dára nísinsin yìí.” Huṣai sì wí pé, “Ìwọ mọ baba rẹ àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ pé alágbára ni wọ́n, wọ́n sì wà ní kíkorò ọkàn bí àmọ̀tẹ́kùn tí a gbà ní ọmọ ni pápá, baba rẹ sì jẹ́ jagunjagun ọkùnrin kì yóò bá àwọn ènìyàn náà gbé pọ̀ lóru. Kíyèsi i, ó ti fi ara rẹ̀ pamọ́ nísinsin yìí ni ihò kan, tàbí ní ibòmíràn: yóò sì ṣe, nígbà tí díẹ̀ nínú wọn bá kọ́ ṣubú, ẹnikẹ́ni tí ó bá gbọ́ yóò sì wí pé, ‘Ìparun sì ń bẹ́ nínú àwọn ènìyàn tí ń tọ Absalomu lẹ́yìn.’ Ẹni tí ó sì ṣe alágbára, tí ọkàn rẹ̀ sì dàbí ọkàn kìnnìún, yóò sì rẹ̀ ẹ́: nítorí gbogbo Israẹli ti mọ̀ pé alágbára ni baba rẹ, àti pé, àwọn tí ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ jẹ́ alágbára. “Nítorí náà èmi dámọ̀ràn pé, kí gbogbo Israẹli wọ́jọ pọ̀ sọ́dọ̀ rẹ, láti Dani títí dé Beerṣeba, gẹ́gẹ́ bí iyanrìn létí òkun fún ọ̀pọ̀lọpọ̀; àti pé, kí ìwọ tìkára rẹ̀ ó lọ sí ogun náà. Àwa ó sì yọ sí i níbikíbi tí àwa o gbé rí i, àwa ó sì yí i ká bí ìrì ti ń ṣẹ̀ sí ilẹ̀ àní, ọkàn kan kì yóò kù pẹ̀lú rẹ̀ nínú gbogbo àwọn ọmọkùnrin tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀. Bí o bá sì bọ́ sí ìlú kan, gbogbo Israẹli yóò mú okùn wá sí ìlú náà, àwa ó sì fà á lọ sí odò, títí a kì yóò fi rí òkúta kéékèèké kan níbẹ̀.” Absalomu àti gbogbo ọkùnrin Israẹli sì wí pé, “Ìmọ̀ Huṣai ará Arki sàn ju ìmọ̀ Ahitofeli lọ! Nítorí Olúwa fẹ́ láti yí ìmọ̀ rere ti Ahitofeli po.” Nítorí kí Olúwa lè mú ibi wá sórí Absalomu. Huṣai ránṣẹ́ sí Dafidi nípa ìmọ̀ náà Huṣai sì wí fún Sadoku àti fún Abiatari àwọn àlùfáà pé, “Báyìí ni Ahitofeli ti bá Absalomu àti àwọn àgbàgbà Israẹli dámọ̀ràn, báyìí lèmi sì bá a dámọ̀ràn. Nítorí náà yára ránṣẹ́ nísinsin yìí kí o sì sọ fún Dafidi pé, ‘Má ṣe dúró ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ ijù náà lálẹ́ yìí, ṣùgbọ́n yára rékọjá kí a má bá a gbé ọba mì, àti gbogbo àwọn ènìyàn tí ó ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ.’ ” Jonatani àti Ahimasi sì dúró ní En-Rogeli ọ̀dọ́mọdébìnrin kan sì lọ, ó sì sọ fún wọn, wọ́n sì lọ wọ́n sọ fún Dafidi ọba nítorí pé kí a má bá à rí wọn pé wọ́n wọ ìlú. Ṣùgbọ́n ọ̀dọ́mọdékùnrin kan rí wọn, ó sì wí fún Absalomu, ṣùgbọ́n àwọn méjèèjì sì yára lọ kúrò, wọ́n sì wá sí ilé ọkùnrin kan ní Bahurimu, ẹni tí ó ní kànga kan ní ọgbà rẹ̀, wọ́n sì sọ̀kalẹ̀ sí ibẹ̀. Obìnrin rẹ̀ sì mú nǹkan ó fi bo kànga náà, ó sì sá àgbàdo sórí rẹ̀, a kò sì mọ̀. Àwọn ìránṣẹ́ Absalomu sì tọ obìnrin náà wá sí ilé náà, wọ́n sì béèrè pé, “Níbo ni Ahimasi àti Jonatani gbé wà?” Obìnrin náà sì wí fún wọn pé, “Wọ́n ti gòkè rékọjá ìṣàn odò náà.” Wọ́n sì wá wọn kiri, wọn kò sì rí wọn, wọ́n sì yípadà sí Jerusalẹmu. Ó sì ṣe lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n ti lọ tán, àwọn ọkùnrin náà sì jáde kúrò nínú kànga, wọ́n sì lọ wọ́n sì rò fún Dafidi ọba. Wọ́n sọ fún Dafidi pé, “Dìde kí o sì gòkè odò kánkán, nítorí pé báyìí ni Ahitofeli gbìmọ̀ sí ọ.” Dafidi sì dìde, àti gbogbo àwọn ènìyàn tí ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n sì gòkè odò Jordani: kí ilẹ̀ tó mọ́, ènìyàn kò kù tí kò gòkè odò Jordani. Ahitofeli pokùnso Nígbà tí Ahitofeli sì rí i pé wọn kò fi ìmọ̀ tirẹ̀ ṣe, ó sì di kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ ni gàárì, ó sì dìde, ó lọ ilé rẹ̀, ó sì palẹ̀ ilé rẹ̀ mọ̀, ó sì so, ó sì kú, a sì sin ín sí ibojì baba rẹ̀. Absalomu gbógun ti Dafidi. Dafidi sì wá sí Mahanaimu, Absalomu sì gòkè odò Jordani, òun àti gbogbo àwọn ọkùnrin Israẹli pẹ̀lú rẹ̀. Absalomu sì fi Amasa ṣe olórí ogun ní ipò Joabu: Amasa ẹni tí í ṣe ọmọ ẹnìkan, orúkọ ẹni tí a ń pè ní Itira, ará Israẹli, tí ó wọlé tọ Abigaili ọmọbìnrin Nahaṣi, arábìnrin Seruiah, ìyá Joabu. Israẹli àti Absalomu sì dó ní ilẹ̀ Gileadi. Nígbà tí Dafidi sì wá sí Mahanaimu, Ṣobi ọmọ Nahaṣi ti Rabba tí àwọn ọmọ Ammoni, àti Makiri ọmọ Ammieli ti Lo-Debari, àti Barsillai ará Gileadi ti Rogelimu. Mú àwọn àkéte, àti àwọn àwo, àti ìkòkò amọ̀, àti alikama, àti ọkà barle, àti ìyẹ̀fun, àti àgbàdo díndín, àti ẹ̀wà, àti erèé, àti lẹntili. Àti oyin, àti òrí-àmọ́, àti àgùntàn, àti wàràǹkàṣì màlúù, wá fún Dafidi àti fún àwọn ènìyàn tí ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ̀, láti jẹ: nítorí tí wọ́n wí pé, “Ebi ń pa àwọn ènìyàn, ó sì rẹ̀ wọ́n, òǹgbẹ sì ń gbẹ wọ́n ní aginjù.” Wọ́n pàdé ogun ní igbó Efraimu Dafidi sì ka àwọn ènìyàn tí ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ̀, ó sì mú wọn jẹ balógun ẹgbẹẹgbẹ̀rún, àti balógun ọ̀rọ̀ọ̀rún lórí wọn. Dafidi sì fi ìdámẹ́ta àwọn ènìyàn náà lé Joabu lọ́wọ́, ó sì rán wọn lọ, àti ìdámẹ́ta lé Abiṣai ọmọ Seruiah àbúrò Joabu lọ́wọ́ àti ìdámẹ́ta lè Ittai ará Gitti lọ́wọ́, ọba sì wí fún àwọn ènìyàn náà pé, “Nítòótọ́ èmi tìkára mi yóò sì bá yín lọ pẹ̀lú.” Àwọn ènìyàn náà sì wí pé, “Ìwọ kì yóò bá wa lọ, nítorí pé bí àwa bá sá, wọn kì yóò náání wa, tàbí bí ó tilẹ̀ ṣe pé ìdajì wa kú, wọn kì yóò náání wa, nítorí pé ìwọ nìkan tó ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) wa. Nítorí náà, ó sì dára kí ìwọ máa ràn wá lọ́wọ́ láti ìlú wá.” Ọba sì wí fún wọn pé, “Èyí tí ó bá tọ́ lójú yin ni èmi ó ṣe.” Ọba sì dúró ní apá kan ẹnu odi, gbogbo àwọn ènìyàn náà sì jáde ní ọ̀rọ̀ọ̀rún àti ní ẹgbẹẹgbẹ̀rún. Ọba sì pàṣẹ fún Joabu àti Abiṣai àti Ittai pé, “Ẹ tọ́jú ọ̀dọ́mọkùnrin náà Absalomu fún mi.” Gbogbo àwọn ènìyàn náà sì gbọ́ nígbà tí ọba pàṣẹ fún gbogbo àwọn balógun nítorí Absalomu. Àwọn ènìyàn náà sì jáde láti pàdé Israẹli ní pápá; ní igbó Efraimu ni wọ́n gbé pàdé ìjà náà. Níbẹ̀ ni a gbé pa àwọn ènìyàn Israẹli níwájú àwọn ìránṣẹ́ Dafidi, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ni ó ṣubú lọ́jọ́ náà, àní ogún ẹgbẹ̀rún (20,000) ènìyàn. Ogun náà sì fọ́n káàkiri lórí gbogbo ilẹ̀ náà, igbó náà sì pa ọ̀pọ̀ ènìyàn ju èyí tí idà pa lọ lọ́jọ́ náà. Joabu sì kọlu Absalomu Absalomu sì pàdé àwọn ìránṣẹ́ Dafidi. Absalomu sì gun orí ìbáaka kan, ìbáaka náà sì gba abẹ́ ẹ̀ka ńlá igi óákù kan tí ó tóbi lọ, orí rẹ̀ sì kọ́ igi óákù náà òun sì rọ̀ sókè ní agbede-méjì ọ̀run àti ilẹ̀; ìbáaka náà tí ó wà lábẹ́ rẹ̀ sì lọ kúrò. Ọkùnrin kan sì rí i, ó sì wí fún Joabu pé, “Wò ó, èmi rí Absalomu so rọ̀ láàrín igi óákù kan.” Joabu sì wí fún ọkùnrin náà tí ó sọ fún un pé, “Sá wò ó, ìwọ rí i, èéha ti ṣe tí ìwọ kò fi lù ú bolẹ̀ níbẹ̀? Èmi ìbá sì fún ọ ní ṣékélì fàdákà mẹ́wàá, àti àmùrè kan.” Ọkùnrin náà sì wí fún Joabu pé, “Bí èmi tilẹ̀ gba ẹgbẹ̀rún (1,000) ṣékélì fàdákà sí ọwọ́ mí, èmi kì yóò fi ọwọ́ mi kan ọmọ ọba, nítorí pé àwa gbọ́ nígbà tí ọba kìlọ̀ fún ìwọ àti Abiṣai, àti Ittai, pé, ‘Ẹ kíyèsi i, kí ẹnikẹ́ni má ṣe fi ọwọ́ kan ọ̀dọ́mọkùnrin náà Absalomu.’ Bí ó bá ṣe bẹ́ẹ̀ èmi ìbá ṣe sí ara mi, nítorí pé kò sí ọ̀ràn kan tí ó pamọ́ fún ọba, ìwọ tìkára rẹ̀ ìbá sì kọjú ìjà sí mi pẹ̀lú.” Joabu sì wí pé, “Èmi kì yóò dúró bẹ́ẹ̀ níwájú rẹ.” Ó sì mú ọ̀kọ̀ mẹ́ta lọ́wọ́ rẹ̀, ó sì fi wọ́n gún Absalomu ní ọkàn, nígbà tí ó sì wà láààyè ní agbede-méjì igi óákù náà. Àwọn ọ̀dọ́mọdékùnrin mẹ́wàá tí ó máa ń ru ìhámọ́ra Joabu sì yí Absalomu ká, wọ́n sì kọlù ú, wọ́n sì pa á. Joabu sì fun ìpè, àwọn ènìyàn náà sì yípadà láti máa lépa Israẹli, nítorí Joabu ti pe àwọn ènìyàn náà padà. Wọ́n sì gbé Absalomu, wọ́n sì sọ ọ́ sínú ihò ńlá kan ní igbó náà, wọ́n sì kó òkúta púpọ̀ jọ sí i lórí, gbogbo Israẹli sì sá, olúkúlùkù sí inú àgọ́ rẹ̀. Absalomu ní ìgbà ayé rẹ̀, sì mọ ọ̀wọ́n kan fún ara rẹ̀, tí ń bẹ ní àfonífojì Ọba: nítorí tí ó wí pé, “Èmi kò ní ọmọkùnrin tí yóò pa orúkọ mi mọ́ ní ìrántí,” òun sì pe ọ̀wọ́n náà nípa orúkọ rẹ̀, a sì ń pè é títí di òní, ní ọ̀wọ́n Absalomu. Dafidi ṣọ̀fọ̀ Ahimasi ọmọ Sadoku sì wí pé, “Jẹ́ kí èmi ó súré nísinsin yìí, kí èmi sì mú ìròyìn tọ ọba lọ, bí Olúwa ti gbẹ̀san rẹ̀ lára àwọn ọ̀tá rẹ̀.” Joabu sì wí fún un pé, “Ìwọ kì yóò mù ìròyìn lọ lónìí, ṣùgbọ́n ìwọ ó mú lọ ní ọjọ́ mìíràn, ṣùgbọ́n lónìí yìí ìwọ kì yóò mú ìròyìn kan lọ, nítorí tí ọmọ ọba ṣe aláìsí.” Joabu sì wí fún Kuṣi pé, “Lọ, kí ìwọ ro ohun tí ìwọ rí fún ọba.” Kuṣi sì wólẹ̀ fún Joabu ó sì sáré. Ahimasi ọmọ Sadoku sì tún wí fún Joabu pé, “Jọ̀wọ́, bí ó ti wù kí ó rí, èmi ó sáré tọ Kuṣi lẹ́yìn.” Joabu sì bi í pé, “Nítorí kín ni ìwọ ó ṣe sáré, ọmọ mi, ìwọ kò ri pé kò sí ìròyìn rere kan tí ìwọ ó mú lọ.” Ó sì wí pé, “Bí ó ti wù kí ó rí, èmi ó sáré.” Ó sì wí fún un pé, “Sáré!” Ahimasi sì sáré ní ọ̀nà pẹ̀tẹ́lẹ̀, ó sì sáré kọjá Kuṣi. Dafidi sì jókòó lẹ́nu odi láàrín ìlẹ̀kùn méjì, alóre sì gòkè òrùlé bodè lórí odi, ó sì gbé ojú rẹ̀ sókè, ó sì wò, wò ó, ọkùnrin kan ń sáré òun nìkan. Alóre náà sì kígbe, ó sì wí fún ọba. Ọba sì wí pé, “Bí ó bá ṣe òun nìkan ni, ìròyìn rere ń bẹ lẹ́nu rẹ̀.” Òun sì ń súnmọ́ tòsí. Alóre náà sì rí ọkùnrin mìíràn tí ń sáré, alóre sì kọ sí ẹni tí ń ṣọ́ bodè, ó sì wí pe, “Wò ó, ọkùnrin kan ń sáré òun nìkan.” Ọba sì wí pé, “Èyí náà pẹ̀lú ń mú ìròyìn rere wá.” Alóre náà sì wí pé, “Èmi wo ìsáré ẹni tí ó wà níwájú ó dàbí ìsáré Ahimasi ọmọ Sadoku.” Ọba sì wí pé, “Ènìyàn re ni, ó sì ń mú ìyìnrere wá!” Ahimasi sì dé, ó sì wí fún ọba pé, “Àlàáfíà!” Ó sì wólẹ̀ fún ọba, ó dojúbolẹ̀ ó sì wí pé, “Alábùkún fún ni Olúwa Ọlọ́run rẹ, ẹni tí ó fi àwọn ọkùnrin tí ó gbé ọwọ́ wọn sókè sí olúwa mi ọba lé ọ lọ́wọ́.” Ọba sì béèrè pé, “Àlàáfíà ha wà fún Absalomu, ọmọdékùnrin náà bí?” Ahimasi sì dáhùn pé, “Nígbà tí Joabu rán ìránṣẹ́ ọba, àti èmi ìránṣẹ́ rẹ̀, mo rí ọ̀pọ̀ ènìyàn, ṣùgbọ́n èmi kò mọ ìdí rẹ̀.” Ọba sì wí fún un pé, “Yípadà kí o sì dúró níhìn-ín.” Òun sì yípadà, ó sì dúró jẹ́ẹ́. Sì wò ó, Kuṣi sì wí pé, “Ìyìnrere fún olúwa mi ọba, nítorí tí Olúwa ti gbẹ̀san rẹ lónìí lára gbogbo àwọn tí ó dìde sí ọ.” Ọba sì bi Kuṣi pé, “Àlàáfíà kọ́ Absalomu ọ̀dọ́mọdékùnrin náà wá bí?” Kuṣi sì dáhùn pe, “Kí àwọn ọ̀tá olúwa mi ọba, àti gbogbo àwọn tí ó dìde sí ọ ní ibi, rí bí ọ̀dọ́mọdékùnrin náà.” Ọba sì kẹ́dùn púpọ̀ ó sì gòkè lọ, sí yàrá tí ó wà lórí òkè ibodè, ó sì sọkún; báyìí ni ó sì ń wí bí ó ti ń lọ, “Ọmọ mi Absalomu! Ọmọ mi, ọmọ mí Absalomu! Á à! Ìbá ṣe pé èmi ni ó kú ní ipò rẹ̀! Absalomu ọmọ mi, ọmọ mi!” Joabu bá Dafidi wí gidigidi A sì rò fún Joabu pe, “Wò ó, ọba ń sọkún, ó sì ń gbààwẹ̀ fún Absalomu.” Ìṣẹ́gun ọjọ́ náà sì di àwẹ̀ fún gbogbo àwọn ènìyàn náà, nítorí àwọn ènìyàn náà gbọ́ ní ọjọ́ náà bí inú ọba ti bàjẹ́ nítorí ọmọ rẹ̀. Àwọn ènìyàn náà sì yọ́ lọ sí ìlú ní ọjọ́ náà gẹ́gẹ́ bí àwọn bí ènìyàn tí a dójútì ṣe máa ń yọ́ lọ nígbà tí wọ́n bá sá lójú ìjà. Ọba sì bo ojú rẹ̀, ọba sì kígbe ní ohùn rara pé, “Á à! Ọmọ mi Absalomu! Absalomu ọmọ mi, ọmọ mi!” Joabu sì wọ inú ilé tọ ọba lọ, ó sì wí pé, “Ìwọ dójúti gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ lónìí, àwọn tí ó gba ẹ̀mí rẹ̀ là lónìí, àti ẹ̀mí àwọn ọmọkùnrin rẹ̀, àti ti àwọn ọmọbìnrin rẹ̀, àti àwọn aya rẹ̀, àti ẹ̀mí àwọn obìnrin rẹ. Nítorí pé ìwọ fẹ́ àwọn ọ̀tá rẹ, ìwọ sì kórìíra àwọn ọ̀rẹ́ rẹ. Nítorí tí ìwọ wí lónìí pé, Ìwọ kò náání àwọn ọmọ ọba tàbí àwọn ìránṣẹ́; èmi sì rí lónìí pé, ìbá ṣe pé Absalomu wà láààyè, kí gbogbo wa sì kú lónìí, ǹjẹ́ ìbá dùn mọ́ ọ gidigidi. Sì dìde nísinsin yìí, lọ, kí o sì sọ̀rọ̀ ìtùnú fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ, nítorí pé èmi fi Olúwa búra, bí ìwọ kò bá lọ, ẹnìkan kì yóò bá ọ dúró ni alẹ́ yìí, èyí ni yóò sì burú fún ọ ju gbogbo ibi tí ojú rẹ ti ń rí láti ìgbà èwe rẹ wá títí ó fi di ìsinsin yìí.” Ọba sì dìde, ó sì jókòó ní ẹnu-ọ̀nà, wọ́n sì wí fún gbogbo àwọn ènìyàn náà pé, “Wò ó, ọba jókòó ní ẹnu-ọ̀nà.” Gbogbo ènìyàn sì wá sí iwájú ọba. Nítorí pé, Israẹli ti sá, olúkúlùkù sí àgọ́ rẹ̀. Àwọn àgbà mú Dafidi ọba padà Gbogbo àwọn ènìyàn náà sì ń bà ara wọn jà nínú gbogbo ẹ̀yà Israẹli, pé, “Ọba ti gbà wá là lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wa, ó sì ti gbà wá kúrò lọ́wọ́ àwọn Filistini; òun sì wá sá kúrò ní ìlú nítorí Absalomu. Absalomu, tí àwa fi jẹ ọba lórí wa sì kú ní ogun, ǹjẹ́ èéṣe tí ẹ̀yin fi dákẹ́ tí ẹ̀yin kò sì sọ̀rọ̀ kan láti mú ọba padà wá?” Dafidi ọba sì ránṣẹ́ sí Sadoku, àti sí Abiatari àwọn àlùfáà pé, “Sọ fún àwọn àgbàgbà Juda, pé, ‘Èéṣe tí ẹ̀yin fi kẹ́yìn láti mú ọba padà wá sí ilé rẹ̀? Ọ̀rọ̀ gbogbo Israẹli sì ti dé ọ̀dọ̀ ọba àní ní ilé rẹ̀. Ẹ̀yin ni ara mi, ẹ̀yin ni egungun mi, àti ẹran-ara mi: èéṣì ti ṣe tí ẹ̀yin fi kẹ́yìn láti mú ọba padà wá.’ Kí ẹ̀yin sì wí fún Amasa pé, ‘Egungun àti ẹran-ara mi kọ́ ni ìwọ jẹ́ bí? Kí Ọlọ́run ó ṣe bẹ́ẹ̀ sí mi àti jù bẹ́ẹ̀ lọ pẹ̀lú, bí ìwọ kò ba ṣe olórí ogun níwájú mi títí, ní ipò Joabu.’ ” Òun sì yí gbogbo àwọn ọkùnrin Juda lọ́kàn padà àní bí ọkàn ènìyàn kan; wọ́n sì ránṣẹ́ sí ọba, pé, “Ìwọ padà àti gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ.” Ọba sì padà, o sì wá sí odò Jordani. Juda sì wá sí Gilgali láti lọ pàdé ọba, àti láti mú ọba kọjá odò Jordani. Ọba dáríjì Ṣimei Ṣimei ọmọ Gera, ará Benjamini ti Bahurimu, ó yára ó sì bá àwọn ọkùnrin Juda sọ̀kalẹ̀ láti pàdé Dafidi ọba. Ẹgbẹ̀rún ọmọkùnrin sì wà lọ́dọ̀ rẹ̀ nínú àwọn ọmọkùnrin Benjamini, Ṣiba ìránṣẹ́ ilé Saulu, àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún àti ogún ìránṣẹ́ sì pẹ̀lú rẹ̀; wọ́n sì gòkè odò Jordani ṣáájú ọba. Ọkọ̀ èrò kan ti rékọjá láti kó àwọn ènìyàn ilé ọba sí òkè, àti láti ṣe èyí tí ó tọ́ lójú rẹ̀. Ṣimei ọmọ Gera wólẹ̀. Ó sì dojúbolẹ̀ níwájú ọba, bí ó tí gòkè odò Jordani. Ó sì wí fún ọba pé, “Kí olúwa mi ó má ṣe ka ẹ̀ṣẹ̀ sí mi lọ́rùn, má sì ṣe rántí àfojúdi tí ìránṣẹ́ rẹ̀ ṣe ni ọjọ́ tí olúwa mi ọba jáde ní Jerusalẹmu, kí ọba má sì fi sí inú. Nítorí pé ìránṣẹ́ rẹ mọ̀ pé èmi ti ṣẹ̀; sì wò ó, mo wá lónìí yìí, ẹni àkọ́kọ́ ní gbogbo ìdílé Josẹfu tí yóò sọ̀kalẹ̀ wá pàdé olúwa mi ọba.” Ṣùgbọ́n Abiṣai ọmọ Seruiah dáhùn ó sì wí pé, “Kò ha tọ́ kí a pa Ṣimei nítorí èyí? Nítorí pé òun ti bú ẹni àmì òróró Olúwa.” Dafidi sì wí pé, “Kí ni èmi ní ṣe pẹ̀lú yín, ẹ̀yin ọmọ Seruiah tí ẹ dàbí ọ̀tá fún mi lónìí? A ha lè pa ènìyàn kan lónìí ní Israẹli? Tàbí èmi kò ha mọ̀ pé lónìí èmi ni ọba Israẹli.” Ọba sì wí fún Ṣimei pé, “Ìwọ kì yóò kú!” Ọba sì búra fún un. Mefiboṣeti ṣe àlàyé fún Dafidi Mefiboṣeti ọmọ Saulu sì sọ̀kalẹ̀ láti wá pàdé ọba, kò wẹ ẹsẹ̀ rẹ̀, kò sí tọ́ irùngbọ̀n rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò sì fọ aṣọ rẹ̀ láti ọjọ́ tí ọba ti jáde títí ó fi di ọjọ́ tí ó fi padà ní àlàáfíà. Nígbà tí òun sì wá sí Jerusalẹmu láti pàdé ọba, ọba sì wí fún un pé, “Èéṣe tí ìwọ kò fi bá mi lọ, Mefiboṣeti?” Òun sì dáhùn wí pé, “Olúwa mi, ọba, ìránṣẹ́ mi ni ó tàn mí, nítorí ìránṣẹ́ rẹ wí fún un pé, ‘Di kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ní gàárì fún mi èmi ó gùn ún, èmi ó sì tọ ọba lọ.’ Nítorí tí ìránṣẹ́ rẹ yarọ. Ó sì sọ̀rọ̀ ìbàjẹ́ sí ìránṣẹ́ rẹ, fún olúwa mi ọba, ṣùgbọ́n bí angẹli Ọlọ́run ni olúwa mi ọba rí, nítorí náà ṣe èyí tí ó dára lójú rẹ. Nítorí pé gbogbo ilé baba mi bí òkú ènìyàn ni wọ́n sá à rí níwájú olúwa mi ọba, ìwọ sì fi ipò fún ìránṣẹ́ rẹ láàrín àwọn tí ó ń jẹun ní ibi oúnjẹ. Nítorí náà àre kín ni èmi ní tí èmi yóò fi máa ké pe ọba síbẹ̀.” Ọba sì wí fún un pé, “Èéṣe tí ìwọ fi ń sọ ọ̀ràn ara rẹ fún mi èmi sá à ti wí pé, kí ìwọ àti Ṣiba pín ilẹ̀ náà.” Mefiboṣeti sì wí fún ọba pé, “Jẹ́ kí ó mú gbogbo rẹ̀, kí olúwa mi ọba sá à ti padà bọ̀ wá ilé rẹ̀ ni àlàáfíà.” Dafidi súre fún Barsillai Barsillai ará Gileadi sì sọ̀kalẹ̀ láti Rogelimu wá, ó sì bá ọba gòkè odò Jordani, láti ṣe ìkẹ́ rẹ̀ sí ìkọjá odò Jordani. Barsillai sì jẹ́ arúgbó ọkùnrin gidigidi, ẹni ogbó ọgọ́rin ọdún sì ni, ó sì pèsè ohun jíjẹ fún ọba nígbà tí ó ti wà ní Mahanaimu; nítorí pé ọkùnrin ọlọ́lá ni òun ń ṣe. Ọba sì wí fún Barsillai pé, “Ìwọ wá bá mi gòkè odò, èmi ó sì máa pèsè fún ọ ní Jerusalẹmu.” Barsillai sì wí fún ọba pé, “Ọjọ́ mélòó ni ọdún ẹ̀mí mi kù, tí èmi ó fi bá ọba gòkè lọ sí Jerusalẹmu. Ẹni ogbó ọgọ́rin ọdún sá à ni èmi lónìí, ǹjẹ́ èmi mọ ìyàtọ̀ nínú rere àti búburú? Ǹjẹ́ ìránṣẹ́ rẹ le mọ adùn ohun tí òun ń jẹ tàbí ohun ti òun ń mu bí? Èmi tún lè mọ adùn ohùn àwọn ọkùnrin tí ń kọrin àti àwọn obìnrin tí ń kọrin bí, ǹjẹ́ nítorí kín ni ìránṣẹ́ rẹ yóò ṣe jẹ́ ìyọnu síbẹ̀ fún olúwa mi ọba. Ìránṣẹ́ rẹ yóò sì sin ọba lọ díẹ̀ gòkè odò Jordani; èéṣì ṣe tí ọba yóò fi san ẹ̀san yìí fún mi. Èmi bẹ̀ ọ́, jẹ́ kí ìránṣẹ́ rẹ padà, èmi ó sì kú ní ìlú mi, a ó sì sin mí ní ibojì baba àti ìyá mi. Sì wo Kimhamu ìránṣẹ́ rẹ, yóò bá olúwa mi ọba gòkè; ìwọ ó sì ṣe ohun tí ó bá tọ́ lójú rẹ fún un.” Ọba sì dáhùn wí pé, “Kimhamu yóò bá mi gòkè, èmi ó sì ṣe èyí tí ó tọ́ lójú rẹ̀ fún un; ohunkóhun tí ìwọ bá sì béèrè lọ́wọ́ mi, èmi ó ṣe é fún ọ.” Gbogbo àwọn ènìyàn sì gòkè odò Jordani ọba sì gòkè; ọba sì fi ẹnu ko Barsillai lẹ́nu, ó sì súre fún un; òun sì padà sí ilé rẹ̀. Ọba sì ń lọ́ sí Gilgali, Kimhamu sì ń bà a lọ, gbogbo àwọn ènìyàn Juda sì ń ṣe ìkẹ́ ọba, àti ààbọ̀ àwọn ènìyàn Israẹli. Israẹli ń jowú Sì wò ó, gbogbo àwọn ọkùnrin Israẹli sì tọ ọba wá, wọ́n sì wí fún ọba pé, “Èéṣe tí àwọn arákùnrin wa àwọn ọkùnrin Juda fi jí ọ kúrò, tí wọ́n sì fi mú ọba àti àwọn ará ilé rẹ̀ gòkè odò Jordani, àti gbogbo àwọn ènìyàn Dafidi pẹ̀lú rẹ?” Gbogbo ọkùnrin Juda sì dá àwọn ọkùnrin Israẹli lóhùn pé, “Nítorí pé ọba bá wa tan ni; èéṣe tí ẹ̀yin fi bínú nítorí ọ̀ràn yìí? Àwa jẹ nínú oúnjẹ ọba rárá bí? Tàbí ó fi ẹ̀bùn kan fún wa bí?” Àwọn ọkùnrin Israẹli náà sì dá àwọn ọkùnrin Juda lóhùn pé, “Àwa ní ipá mẹ́wàá nínú ọba, àwa sì ní nínú Dafidi jù yín lọ, èéṣì ṣe tí ẹ̀yin kò fi kà wá sí, tí ìmọ̀ wa kò fi ṣáájú láti mú ọba wa padà?” Ọ̀rọ̀ àwọn ọkùnrin Juda sì le ju ọ̀rọ̀ àwọn ọkùnrin Israẹli. Ṣeba ṣọ̀tẹ̀ sí Dafidi Ọkùnrin Beliali kan sì ń bẹ níbẹ̀ orúkọ rẹ̀ sì ń jẹ́ Ṣeba ọmọ Bikri ará Benjamini; ó sì fún ìpè ó sì wí pé, “Àwa kò ní ipa nínú Dafidi, bẹ́ẹ̀ ni àwa kò ni ìní nínú ọmọ Jese! Kí olúkúlùkù ọkùnrin lọ sí àgọ́ rẹ̀, ẹ̀yin Israẹli!” Gbogbo àwọn ọkùnrin Israẹli sì lọ kúrò lẹ́yìn Dafidi, wọ́n sì ń tọ́ Ṣeba ọmọ Bikri lẹ́yìn, ṣùgbọ́n àwọn ọkùnrin Juda sì fi ara mọ́ ọba wọn láti odò Jordani wá títí ó fi dé Jerusalẹmu. Dafidi sì wà ní ilé rẹ̀ ní Jerusalẹmu; ọba sì mú àwọn obìnrin mẹ́wàá tí í ṣe àlè rẹ̀, àwọn tí ó ti fi sílẹ̀ láti máa ṣọ́ ilé, Ó sì há wọn mọ́ ilé, ó sì ń bọ́ wọn, ṣùgbọ́n kò sì tún wọlé tọ̀ wọ́n mọ́. A sì sé wọn mọ́ títí di ọjọ́ ikú wọn, wọ́n sì wà bí opó. Joabu fi idà gún Amasa, ó sì kú Ọba sì wí fún Amasa pé, “Pe àwọn ọkùnrin Juda fún mi ní ìwọ̀n ọjọ́ mẹ́ta òní, kí ìwọ náà kí o sì wà níhìn-ín yìí.” Amasa sì lọ láti pe àwọn ọkùnrin Juda; ṣùgbọ́n ó sì dúró pẹ́ ju àkókò tí a fi fún un. Dafidi sì wí fún Abiṣai pé, “Nísinsin yìí Ṣeba ọmọ Bikri yóò ṣe wá ní ibi ju ti Absalomu lọ; ìwọ mú àwọn ìránṣẹ́ olúwa rẹ, kí o sì lépa rẹ̀, kí ó má ba à rí ìlú olódi wọ̀, kí ó sì bọ́ lọ́wọ́ wa.” Àwọn ọmọkùnrin Joabu sì jáde tọ̀ ọ́ lọ, àti àwọn Kereti, àti àwọn Peleti, àti gbogbo àwọn ọkùnrin alágbára, wọ́n sì ti Jerusalẹmu jáde lọ, láti lépa Ṣeba ọmọ Bikri. Nígbà tí wọ́n dé ibi òkúta ńlá tí ó wà ní Gibeoni, Amasa sì ṣáájú wọn, Joabu sì di àmùrè sí agbádá rẹ̀ tí ó wọ̀, ó sì sán idà rẹ̀ mọ́ ìdí, nínú àkọ̀ rẹ̀, bí ó sì ti ń lọ, ó yọ́ jáde. Joabu sì bi Amasa léèrè pé, “Àlàáfíà ha kọ́ ni bí, ìwọ arákùnrin mi?” Joabu sì na ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀, di Amasa ní irùngbọ̀n mú láti fi ẹnu kò ó lẹ́nu. Ṣùgbọ́n Amasa kò sì kíyèsi idà tí ń bẹ lọ́wọ́ Joabu, bẹ́ẹ̀ ni òun sì fi gún un ní ikùn, ìfun rẹ̀ sì tú dà sílẹ̀, òun kò sì tún gún un mọ́, Amasa sì kú. Joabu àti Abiṣai arákùnrin rẹ̀ sì lépa Ṣeba ọmọ Bikri. Joabu lépa Seba Ọ̀kan nínú àwọn ọ̀dọ́mọdékùnrin tí ó wà lọ́dọ̀ Joabu sì dúró tì Amasa, ó sì wí pé, “Ta ni ẹni tí ó fẹ́ràn Joabu? Ta ni ó sì ń ṣe ti Dafidi, kí ó máa tọ Joabu lẹ́yìn.” Amasa sì ń yíràá nínú ẹ̀jẹ̀ láàrín ọ̀nà. Ọkùnrin náà sì rí i pé gbogbo ènìyàn sì dúró tì í, ó sì gbé Amasa kúrò lójú ọ̀nà lọ sínú igbó, ó sì fi aṣọ bò ó, nígbà tí ó rí i pé ẹnikẹ́ni tí ó bá dé ọ̀dọ̀ rẹ̀, á dúró. Nígbà tí ó sì gbé Amasa kúrò lójú ọ̀nà gbogbo ènìyàn sì tọ Joabu lẹ́yìn láti lépa Ṣeba ọmọ Bikri. Wọ́n gé Ṣeba lórí Ṣeba kọjá nínú gbogbo ẹ̀yà Israẹli sí Abeli-Beti-Maaka, àti gbogbo àwọn ará Beri; wọ́n sì kó ara wọn jọ, wọ́n sì tọ̀ ọ́ lẹ́yìn pẹ̀lú. Wọ́n wá, wọ́n sì dó tì Ṣeba ní Abeli-Beti-Maaka, wọ́n sì mọ odi ti ìlú náà, odi náà sì dúró ti odi ìlú náà, gbogbo ènìyàn tí ń bẹ lọ́dọ̀ Joabu sì ń gbìyànjú láti wó ògiri náà lulẹ̀. Obìnrin ọlọ́gbọ́n kan sì kígbe sókè láti ìlú náà wá pé, “Fetísílẹ̀! Fetísílẹ̀! Èmi bẹ̀ yín, ẹ sọ fún Joabu pé, ‘Súnmọ́ ìhín yìí èmi ó sì bá a sọ̀rọ̀.’ ” Nígbà tí òun sì súnmọ́ ọ̀dọ̀ rẹ̀, obìnrin náà sì wí pé, “Ìwọ ni Joabu bí?” Òun sì dáhùn wí pé, “Èmi náà ni.” Obìnrin náà sì wí fún un pé, “Gbọ́ ọ̀rọ̀ ìránṣẹ́bìnrin rẹ.” Òun sì dáhùn wí pé, “Èmi ń gbọ́.” Ó sì sọ̀rọ̀ wí pé, “Wọ́n ti ń wí ṣáájú pé, ‘Gba ìdáhùn rẹ ní Abeli,’ bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì parí ọ̀ràn náà. Èmi ni ọ̀kan nínú àwọn ẹni àlàáfíà àti olóòtítọ́ ní Israẹli, ìwọ ń wá ọ̀nà láti pa ìlú kan run tí ó jẹ́ ìyá ní Israẹli, èéṣe tí ìwọ ó fi gbé ìní Olúwa mì.” Joabu sì dáhùn wí pé, “Kí a má rí i, kí a má rí i lọ́dọ̀ mi pé èmi gbé mì tàbí èmi sì parun. Ọ̀ràn náà kò sì rí bẹ́ẹ̀; ṣùgbọ́n ọkùnrin kan láti òkè Efraimu, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ṣeba, ọmọ Bikri, ni ó gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè sí ọba, àní sí Dafidi: fi òun nìkan ṣoṣo lé wa lọ́wọ́, èmi ó sì fi ìlú sílẹ̀.” Obìnrin náà sì wí fún Joabu pé, “Wò ó, orí rẹ̀ ni a ó sì sọ láti inú odi wá.” Obìnrin náà sì mú ìmọ́ràn rẹ̀ tọ gbogbo àwọn ènìyàn náà, wọ́n sì bẹ Ṣeba ọmọ Bikri lórí, wọ́n sì sọ ọ́ sí Joabu. Òun sì fún ìpè, wọ́n sì túká ní ìlú náà, olúkúlùkù sí àgọ́ rẹ̀. Joabu sí padà lọ sí Jerusalẹmu àti sọ́dọ̀ ọba. Àwọn ìránṣẹ́ Dafidi Joabu sì ni olórí gbogbo ogun Israẹli; Benaiah ọmọ Jehoiada sì jẹ́ olórí àwọn Kereti, àti ti àwọn Peleti. Adoniramu sì jẹ́ olórí àwọn agbowó òde; Jehoṣafati ọmọ Ahiludi sì jẹ́ olùkọsílẹ̀ ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀ ní ìlú. Ṣefa sì jẹ́ akọ̀wé; Sadoku àti Abiatari sì ni àwọn àlùfáà. Ira pẹ̀lú, ará Jairi ni ń ṣe àlùfáà lọ́dọ̀ Dafidi. Àwọn ará Gibeoni gba ẹ̀san Ìyàn kan sì mú lọ́jọ́ Dafidi ní ọdún mẹ́ta, láti ọdún dé ọdún; Dafidi sì béèrè lọ́dọ̀ Olúwa, Olúwa sì wí pé, “Nítorí ti Saulu ni, àti nítorí ilé rẹ̀ tí ó kún fún ẹ̀jẹ̀, nítorí pé ó pa àwọn ará Gibeoni.” Ọba sì pe àwọn ará Gibeoni, ó sì bá wọn sọ̀rọ̀; àwọn ará Gibeoni kì í ṣe ọ̀kan nínú àwọn ọmọ Israẹli, ṣùgbọ́n wọ́n jẹ́ àwọn tí ó kù nínú àwọn ọmọ Amori; àwọn ọmọ Israẹli sì ti búra fún wọn, Saulu sì ń wá ọ̀nà àti pa wọ́n ní ìtara rẹ̀ fún àwọn ọmọ Israẹli àti Juda. Dafidi sì bi àwọn ará Gibeoni léèrè pé, “Kí ni èmi ó ṣe fún un yín? Àti kín ni èmi ó fi ṣe ètùtù, kí ẹ̀yin lè súre fún ilẹ̀ ìní Olúwa?” Àwọn ará Gibeoni sì wí fún un pé, “Kì í ṣe ọ̀rọ̀ fàdákà tàbí wúrà láàrín wa àti Saulu tàbí ìdílé rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni a kò sì fẹ́ kí ẹ pa ẹnìkan ní Israẹli.” Dafidi sì wí pé, “Èyí tí ẹ̀yin bá wí ni èmi ó ṣe?” Wọ́n sì wí fún ọba pé, “Ọkùnrin tí ó run wá, tí ó sì rò láti pa wá rẹ́ ki a má kù níbikíbi nínú gbogbo agbègbè Israẹli. Mú ọkùnrin méje nínú àwọn ọmọ rẹ̀ fún wá, àwa ó sì so wọ́n rọ̀ fún Olúwa ní Gibeah ti Saulu ẹni tí Olúwa ti yàn.” Ọba sì wí pé, “Èmi ó fi wọ́n fún yín.” Síso Àwọn Ènìyàn Saulu Méje Rọ̀ Ṣùgbọ́n ọba dá Mefiboṣeti sí, ọmọ Jonatani, ọmọ Saulu, nítorí ìbúra Olúwa tí ó wà láàrín Dafidi àti Jonatani ọmọ Saulu. Ọba sì mú àwọn ọmọkùnrin méjèèjì tí Rispa ọmọbìnrin Aiah bí fún Saulu, àní Ammoni àti Mefiboṣeti àwọn ọmọkùnrin márààrún ti Merabu, ọmọbìnrin Saulu, àwọn tí ó bí fún Adrieli ọmọ Barsillai ará Mehola. Ó sì fi wọ́n lé àwọn ará Gibeah lọ́wọ́, wọ́n sì so wọ́n rọ̀ lórí òkè níwájú Olúwa: àwọn méjèèjì sì ṣubú lẹ́ẹ̀kan, a sì pa wọ́n ní ìgbà ìkórè, ní ìbẹ̀rẹ̀, ìkórè ọkà barle. Rispa ọmọbìnrin Aiah sì mú aṣọ ọ̀fọ̀ kan, ó sì tẹ́ fún ará rẹ̀ lórí àpáta ní ìbẹ̀rẹ̀ ìkórè, títí omi fi dà sí wọn lára láti ọ̀run wá, kò sì jẹ́ kí àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run bà lé wọn lọ́sàn, tàbí àwọn ẹranko igbó lóru. A sì ro èyí, tí Rispa ọmọbìnrin Aiah obìnrin Saulu ṣe, fún Dafidi. Dafidi sì lọ ó sì kó egungun Saulu, àti egungun Jonatani ọmọ rẹ̀ kúrò lọ́dọ̀ àwọn ọkùnrin Jabesi Gileadi, àwọn tí ó jí wọn kúrò ní ìta Beti-Ṣani, níbi tí àwọn Filistini gbé so wọ́n rọ̀, nígbà tí àwọn Filistini pa Saulu ní Gilboa. Ó sì mú egungun Saulu àti egungun Jonatani ọmọ rẹ̀ láti ibẹ̀ náà wá; wọ́n sì kó egungun àwọn tí a ti so rọ̀ jọ. Wọ́n sì sin egungun Saulu àti ti Jonatani ọmọ rẹ̀ ní ilé Benjamini, ní Ṣela, nínú ibojì Kiṣi baba rẹ̀, wọ́n sì ṣe gbogbo èyí tí ọba paláṣẹ, lẹ́yìn èyí ni Ọlọ́run si gba ẹ̀bẹ̀ nítorí ilẹ̀ náà. Ìṣẹ́gun lórí Filistini Ogun sì tún wà láàrín àwọn Filistini àti Israẹli; Dafidi sì sọ̀kalẹ̀, àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀, ó sì bá àwọn Filistini jà, ó sì rẹ Dafidi. Iṣbi-Benobu sì jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn Rafa, ẹni tí ọ̀kọ̀ rẹ̀ wọn ọ̀ọ́dúnrún (300) ṣékélì idẹ, ó sì sán idà tuntun, ó sì gbèrò láti pa Dafidi. Ṣùgbọ́n Abiṣai ọmọ Seruiah ràn án lọ́wọ́, ó sì kọlu Filistini náà, ó sì pa á. Nígbà náà ni àwọn ìránṣẹ́ Dafidi sì búra fún un pé, “Ìwọ kì yóò sì tún bá wa jáde lọ sí ibi ìjà mọ́ kí ìwọ má ṣe pa iná Israẹli.” Lẹ́yìn èyí, ìjà kan sì tún wà láàrín àwọn Israẹli àti àwọn Filistini ní Gobu, nígbà náà ni Sibekai ará Huṣati pa Safu, ẹni tí í ṣe ọ̀kan nínú àwọn Rafa. Ìjà kan sì tún wà ní Gobu láàrín àwọn Israẹli àti àwọn Filistini, Elhanani ọmọ Jairi ará Bẹtilẹhẹmu sì pa arákùnrin Goliati ará Gitti, ẹni tí ọ̀pá ọ̀kọ̀ rẹ̀ dàbí ìdábùú apásá ìhunṣọ. Ìjà kan sì tún wà ní Gati, ọkùnrin kan sì wà tí ó ga púpọ̀, ó sì ní ìka mẹ́fà ní ọwọ́ kan, àti ọmọ ẹsẹ̀ mẹ́fà ní ẹsẹ̀ kan, àpapọ̀ rẹ̀ sì jẹ́ mẹ́rìnlélógún; a sì bí òun náà ní Rafa. Nígbà tí òun sì pe Israẹli ní ìjà. Jonatani ọmọ Ṣimea arákùnrin Dafidi sì pa á. Àwọn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin wọ̀nyí ni ìran Rafa ní Gati, wọ́n sì ti ọwọ́ Dafidi ṣubú àti ọwọ́ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀. Orin ìyìn Dafidi Dafidi sì kọ ọ̀rọ̀ orin yìí sí Olúwa ní ọjọ́ tí Olúwa gbà á kúrò lọ́wọ́ gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ̀, àti kúrò lọ́wọ́ Saulu. Ó sì wí pé, Olúwa ni àpáta mi, àti Olùgbàlà mi; Ọlọ́run mi, àpáta mi, nínú ẹni tí èmi ní ààbò, àti ìwo ìgbàlà mi, ibi ìsádi gíga mi. Àti ibi ìlùmọ̀ mi, Olùgbàlà mi; ìwọ ni ó ti gbà mí kúrò lọ́wọ́ ìwà ipá. “Èmi ké pe Olúwa, tí ó yẹ láti máa yìn, ó sì gbà mí lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá mi. Nígbà tí ìbìlù ìrora ikú yí mi káàkiri; tí àwọn ìṣàn ènìyàn búburú dẹ́rùbà mí. Ọ̀já isà òkú yí mi káàkiri; ìkẹ́kùn ikú dojúkọ mí. “Nínú ìpọ́njú mi, èmi ké pé Olúwa, èmi sì gbé ohùn mi sókè sí Ọlọ́run mi. Ó sí gbóhùn mi láti tẹmpili rẹ̀ igbe mí wọ etí rẹ̀. Ilẹ̀ sì mì, ó sì wárìrì; ìpìlẹ̀ ọ̀run wárìrì, ó sì mì, nítorí tí ó bínú. Èéfín ti ihò imú rẹ̀ jáde wá, iná ajónirun ti ẹnu rẹ̀ jáde wá, ẹ̀yin iná bú jáde láti inú rẹ̀. Ó tẹ orí ọ̀run ba pẹ̀lú, ó sì sọ̀kalẹ̀; òkùnkùn biribiri sì ń bẹ ní àtẹ́lẹsẹ̀ rẹ̀. Ó sì gun orí kérúbù, ó sì fò, a sì rí i lórí ìyẹ́ afẹ́fẹ́. Ó sì fi òkùnkùn ṣe ibùjókòó yí ara rẹ̀, àti àgbájọ omi, àní ìṣúdudu ìkùùkuu àwọ̀ sánmọ̀. Nípasẹ̀ ìmọ́lẹ̀ iwájú rẹ̀ ẹ̀yín iná ràn. Olúwa sán àrá láti ọ̀run wá, Ọ̀gá-ògo jùlọ sì fọhùn rẹ̀. Ó sì ta ọfà, ó sì tú wọn ká; ó kọ mànàmànà, ó sì ṣẹ́ wọn. Ìṣàn ibú òkun sì fi ara hàn, ìpìlẹ̀ ayé fi ara hàn, nípa ìbáwí Olúwa, nípa fífún èémí ihò imú rẹ̀. “Ó ránṣẹ́ láti òkè wá, ó mú mi; ó fà mí jáde láti inú omi ńlá wá. Ó gbà mí lọ́wọ́ ọ̀tá mi alágbára, lọ́wọ́ àwọn tí ó kórìíra mi, nítorí pé wọ́n lágbára jù mí lọ. Wọ́n wá láti borí mi lọ́jọ́ ìpọ́njú mi, ṣùgbọ́n Olúwa ni aláfẹ̀yìntì mi. Ó sì mú mi wá sí ààyè ńlá, ó gbà mi, nítorí tí inú rẹ̀ dún sí mi. Olúwa sán án fún mi gẹ́gẹ́ bí òdodo mi; ó sì san án fún mi gẹ́gẹ́ bí mímọ́ ọwọ́ mi. Nítorí pé èmi pa ọ̀nà Olúwa mọ́, èmi kò sì fi ìwà búburú yapa kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run mi. Nítorí pé gbogbo ìdájọ́ rẹ̀ ni ó wà níwájú mi; àti ní ti òfin rẹ̀, èmi kò sì yapa kúrò nínú wọn. Èmi sì wà nínú ìwà títọ́ sí í, èmi sì pa ara mi mọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ mi. Olúwa sì san fún mi gẹ́gẹ́ bí òdodo mi, gẹ́gẹ́ bí ìwà mímọ́ mi níwájú rẹ̀. “Fún aláàánú ni ìwọ ó fi ara rẹ̀ hàn ni aláàánú, àti fún ẹni ìdúró ṣinṣin ní òdodo ni ìwọ ó fi ara rẹ hàn ní ìdúró ṣinṣin ní òdodo. Fún onínú funfun ni ìwọ fi ara rẹ hàn ní funfun; àti fún ẹni wíwọ́ ni ìwọ ó fi ara rẹ hàn ní wíwọ́. Àwọn ènìyàn tí ó wà nínú ìyà ni ìwọ ó sì gbàlà; ṣùgbọ́n ojú rẹ wà lára àwọn agbéraga, láti rẹ̀ wọ́n sílẹ̀. Nítorí ìwọ ni ìmọ́lẹ̀ mi, Olúwa; Olúwa yóò sì sọ òkùnkùn mi di ìmọ́lẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni nítorí nípa rẹ̀ ni èmi ti la àárín ogun kọjá; nípa Ọlọ́run mi èmi ti fo odi kan. “Ọlọ́run yìí, pípé ni ọ̀nà rẹ̀; ọ̀rọ̀ Olúwa ni a ti dánwò. Òun sì ni asà fún gbogbo àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé e. Nítorí ta ni Ọlọ́run, bí kò ṣe Olúwa? Ta ni àpáta, bí kò ṣe Ọlọ́run wa. Ọlọ́run alágbára ni ó fún mi ní agbára, ó sì sọ ọ̀nà mi di títọ́. Ó ṣe ẹsẹ̀ mi bí ẹsẹ̀ abo àgbọ̀nrín; ó sì mú mi dúró ní ibi gíga mi. Ó kọ́ ọwọ́ mi ní ogun jíjà; tó bẹ́ẹ̀ tí apá mi fa ọrun idẹ. Ìwọ sì ti fún mi ní asà ìgbàlà rẹ̀; ìrẹ̀lẹ̀ rẹ̀ sì ti sọ mí di ńlá. Ìwọ sì sọ ìtẹ̀lẹ̀ di ńlá ní abẹ́ mi; tó bẹ́ẹ̀ tí ẹsẹ̀ mi kò fi yọ̀. “Èmi ti lépa àwọn ọ̀tá mi, èmi sì ti run wọ́n, èmi kò pẹ̀yìndà títí èmi fi run wọ́n. Èmi ti pa wọ́n run, èmi sì ti fọ́ wọn, wọn kò sì le dìde mọ́, wọ́n ṣubú lábẹ́ mi. Ìwọ sì ti fi agbára dì mí ní àmùrè fún ìjà; àwọn tí ó ti dìde sí mi ni ìwọ sì ti tẹ̀ lórí ba fún mi. Ìwọ sì mú àwọn ọ̀tá mi pẹ̀yìndà fún mi, èmi ó sì pa àwọn tí ó kórìíra mi run. Wọ́n wò, ṣùgbọ́n kò sí ẹnìkan láti gbà wọ́n; wọ́n wo Olúwa, ṣùgbọ́n kò dá àwọn lóhùn. Nígbà náà ni èmi sì gún wọn wẹ́wẹ́ bí erùpẹ̀ ilẹ̀, èmi sì tẹ̀ wọ́n mọ́lẹ̀ bí ẹrẹ̀ ìta, èmi sì tẹ́ wọn gbọrọ. “Ìwọ sì gbà mí kúrò lọ́wọ́ ìjà àwọn ènìyàn mi, ìwọ pa mi mọ́ ki èmi lè ṣe olórí àwọn àjèjì orílẹ̀-èdè. Àwọn ènìyàn tí èmi kò tí mọ̀ yóò máa sìn mí. Àwọn àjèjì wá láti tẹríba fún mi; bí wọ́n bá ti gbúròó mi, wọ́n á sì gbọ́ tèmi. Àyà yóò pá àwọn àlejò, wọ́n ó sì fi ìbẹ̀rù sá kúrò níbi kọ́lọ́fín wọn. Olúwa ń bẹ́; olùbùkún sì ni àpáta mi! Gbígbéga sì ni Ọlọ́run àpáta ìgbàlà mi. Ọlọ́run ni ẹni tí ń gbẹ̀san mi, àti ẹni tí ń rẹ àwọn ènìyàn sílẹ̀ lábẹ́ mi. Àti ẹni tí ó gbà mí kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá mi. Ìwọ sì gbé mi sókè ju àwọn tí ó kórìíra mi lọ; ìwọ sì gbà mí kúrò lọ́wọ́ àwọn ọkùnrin oníwà ipá. Nítorí náà èmi ó fi ọpẹ́ fún ọ, Olúwa, láàrín àwọn àjèjì orílẹ̀-èdè, èmi ó sì kọrin sí orúkọ rẹ. “Òun ni ilé ìṣọ́ ìgbàlà fún ọba rẹ̀; ó sì fi àánú hàn fún ẹni àmì òróró rẹ̀, fún Dafidi, àti fún irú-ọmọ rẹ̀ títí láéláé.” Ọ̀rọ̀ ìkẹyìn Dafidi Wọ̀nyí sì ni ọ̀rọ̀ ìkẹyìn Dafidi. “Dafidi ọmọ Jese, àní ọkùnrin tí a ti gbéga, ẹni àmì òróró Ọlọ́run Jakọbu, àti olórin dídùn Israẹli wí pé, “Ẹ̀mí Olúwa sọ ọ̀rọ̀ nípa mi, ọ̀rọ̀ rẹ̀ sì ń bẹ ní ahọ́n mi. Ọlọ́run Israẹli ni, àpáta Israẹli sọ fún mi pé, ‘Ẹnìkan ti ń ṣe alákòóso ènìyàn lódodo, tí ń ṣàkóso ní ìbẹ̀rù Ọlọ́run. Yóò sì dàbí ìmọ́lẹ̀ òwúrọ̀ nígbà tí oòrùn bá là, òwúrọ̀ tí kò ní ìkùùkuu, nígbà tí koríko tútù bá hù wá láti ilẹ̀ lẹ́yìn òjò.’ “Lóòtítọ́ ilé mi kò rí bẹ́ẹ̀ níwájú Ọlọ́run, ṣùgbọ́n ó ti bá mi dá májẹ̀mú àìnípẹ̀kun, tí a túnṣe nínú ohun gbogbo, tí a sì pamọ́; nítorí pé gbogbo èyí ni ìgbàlà, àti gbogbo ìfẹ́ mi, ilé mi kò lè ṣe kí ó má dàgbà. Ṣùgbọ́n gbogbo àwọn ọmọ Beliali yóò dàbí ẹ̀gún ẹ̀wọ̀n tí a ṣá tì, nítorí pé a kò lè fi ọwọ́ kó wọn. Ṣùgbọ́n ọkùnrin tí yóò tọ́ wọn yóò fi irin àti ọ̀pá ọ̀kọ̀ ṣagbára yí ara rẹ̀ ká; wọ́n ó jóná lúúlúú níbìkan náà.” Iṣẹ́ àwọn alágbára tí Dafidi ní Wọ̀nyí sì ni orúkọ àwọn akọni ọkùnrin tí Dafidi ní: Joṣebu-Basṣebeti ará Takemoniti ni olórí àwọn balógun, òun sì ni akọni rẹ̀ tí ó pa ẹgbẹ̀rin (800) ènìyàn lẹ́ẹ̀kan náà. Ẹni tí ó tẹ̀lé e ni Eleasari ọmọ Dodo ará Ahohi, ọ̀kan nínú àwọn alágbára ọkùnrin mẹ́ta ti ó wà pẹ̀lú Dafidi, nígbà tí wọ́n pe àwọn Filistini ní ìjà, àwọn ọkùnrin Israẹli sì ti lọ kúrò. Òun sì dìde, ó sì kọlu àwọn Filistini títí ọwọ́ fi kún un, ọwọ́ rẹ̀ sì lẹ̀ mọ́ idà; Olúwa sì ṣiṣẹ́ ìgbàlà ńlá lọ́jọ́ náà, àwọn ènìyàn sì padà bọ̀ lẹ́yìn rẹ̀ láti kó ìkógun. Ẹni tí ó tẹ̀lé e ni Ṣamma ọmọ Agee ará Harari, àwọn Filistini sì kó ara wọn jọ láti piyẹ́, oko kan sì wà níbẹ̀ tí ó kún fun lẹntili, àwọn ọmọ-ogun Israẹli sì sá kúrò níwájú àwọn Filistini. Ṣamma sì dúró láàrín méjì ilẹ̀ náà, ó sì gbà á sílẹ̀, ó sì pa àwọn Filistini Olúwa sì ṣe ìgbàlà ńlá. Mẹ́ta nínú àwọn ọgbọ̀n ìjòyè sọ̀kalẹ̀, wọ́n sì tọ Dafidi wá ní àkókò ìkórè nínú ihò Adullamu, ọ̀wọ́ àwọn Filistini sì dó sí àfonífojì Refaimu. Dafidi sì wà nínú odi, ibùdó àwọn Filistini sì wà ní Bẹtilẹhẹmu nígbà náà. Dafidi sì ń pòǹgbẹ, ó wí báyìí pé, “Ta ni yóò fún mi mu nínú omí kànga tí ń bẹ ní Bẹtilẹhẹmu, èyí tí ó wà ní ìhà ẹnu-bodè.” Àwọn ọkùnrin alágbára mẹ́ta sì la ogún àwọn Filistini lọ, wọ́n sì fa omi láti inú kànga Bẹtilẹhẹmu wá, èyí tí ó wà ní ìhà ẹnu-bodè, wọ́n sì mú tọ Dafidi wá, òun kò sì fẹ́ mu nínú rẹ̀, ṣùgbọ́n ó tú u sílẹ̀ fún Olúwa. Òun sì wí pé, “Kí a má rí, Olúwa, tí èmi ó fi ṣe èyí; ṣé èyí ni ẹ̀jẹ̀ àwọn ọkùnrin tí ó lọ tí àwọn tí ẹ̀mí wọn lọ́wọ́?” Nítorí náà òun kò sì fẹ́ mú un. Nǹkan wọ̀nyí ni àwọn ọkùnrin alágbára mẹ́tẹ̀ẹ̀ta yìí ṣe. Abiṣai, arákùnrin Joabu, ọmọ Seruiah, òun náà ni pàtàkì nínú àwọn mẹ́ta. Òun ni ó sì gbé ọ̀kọ̀ rẹ̀ sókè sí ọ̀ọ́dúnrún (300) ènìyàn, ó sì pa wọ́n, ó sì ní orúkọ nínú àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta. Ọlọ́lá jùlọ ni òun jẹ́ nínú àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta, ó sì jẹ́ olórí fún wọn, ṣùgbọ́n òun kò tó àwọn mẹ́ta ìṣáájú. Benaiah, ọmọ Jehoiada, ọmọ akọni ọkùnrin kan tí Kabṣeeli, ẹni tí ó pọ̀ ní iṣẹ́ agbára, òun pa àwọn ọmọ Arieli méjì ti Moabu; ó sọ̀kalẹ̀ pẹ̀lú ó sì pa kìnnìún kan nínú ihò lákoko òjò-dídì. Ó sì pa ará Ejibiti kan, ọkùnrin tí ó dára láti wò, ará Ejibiti náà sì ní ọ̀kọ̀ kan ní ọwọ́ rẹ̀, ṣùgbọ́n Benaiah sì sọ̀kalẹ̀ tọ̀ ọ́ lọ, pẹ̀lú ọ̀pá ní ọwọ́, ó sì gba ọ̀kọ̀ náà lọ́wọ́ ará Ejibiti náà, ó sì fi ọ̀kọ̀ rẹ̀ pa á. Nǹkan wọ̀nyí ní Benaiah ọmọ Jehoiada ṣe, ó sì ní orúkọ nínú àwọn ọkùnrin alágbára mẹ́ta náà. Nínú àwọn ọgbọ̀n náà, òun ní ọlá jùlọ, ṣùgbọ́n òun kò tó àwọn mẹ́ta ti ìṣáájú. Dafidi sì fi í ṣe ìgbìmọ̀ rẹ̀. Ọ̀kan nínú àwọn ọgbọ̀n náà: Asaheli arákùnrin Joabu sì Jásí Elhanani ọmọ Dodo ti Bẹtilẹhẹmu; Ṣamma ará Haroditi, Elika ará Harodi. Helesi ará Palti, Ira ọmọ Ikẹsi ará Tekoa; Abieseri ará Anatoti, Sibekai ará Huṣati; Salmoni ará Ahohi, Maharai ará Netofa; Heledi ọmọ Baanah, ará Netofa, Ittai ọmọ Ribai to Gibeah ti àwọn ọmọ Benjamini; Benaiah ará Piratoni, Hiddai ti àfonífojì Gaaṣi, Abi-Alboni ará Arbati, Asmafeti Barhumiti; Eliaba ará Ṣaalboni, àwọn ọmọ Jaṣeni, Jonatani; ọmọ Ṣamma ará Harari, Ahiamu ọmọ Ṣarari ará Harari; Elifeleti ọmọ Ahasbai, ọmọ ará Maakati, Eliamu ọmọ Ahitofeli ará Giloni; Hesro ará Karmeli, Paarai ará Arba; Igali ọmọ Natani ti Soba, Bani ará Gadi; Seleki ará Ammoni, Naharai ará Beeroti, ẹni tí ń ru ìhámọ́ra Joabu ọmọ Seruiah; Ira ará Itri, Garebu ará Itri. Uriah ará Hiti. Gbogbo wọn jẹ́ mẹ́tàdínlógójì. Kíka àwọn ènìyàn Israẹli Ìbínú Olúwa sì ru sí Israẹli, ó sì ti Dafidi sí wọn, pé, “Lọ ka iye Israẹli àti Juda!” Ọba sì wí fún Joabu olórí ogun, tí ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ̀ pé, “Lọ ní ìsinsin yìí sí gbogbo ẹ̀yà Israẹli láti Dani títí dé Beerṣeba, kí ẹ sì ka iye àwọn ènìyàn, kí èmi lè mọ iye àwọn ènìyàn náà!” Joabu sì wí fún ọba pé, “Kí Olúwa Ọlọ́run rẹ fi kún iye àwọn ènìyàn náà, iyekíye tí ó wù kí wọn jẹ́, ní ọ̀rọ̀ọ̀rún, ojú olúwa mi ọba yóò sì rí i, ṣùgbọ́n èétiṣe tí olúwa mi ọba fi fẹ́ nǹkan yìí?” Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ ọba borí ti Joabu, àti ti àwọn olórí ogun. Joabu àti àwọn olórí ogun sì jáde lọ kúrò níwájú ọba, láti lọ ka àwọn ènìyàn Israẹli. Wọ́n sì kọjá odò Jordani, wọ́n sì pàgọ́ ní Aroeri, ní ìhà apá ọ̀tún ìlú tí ó wà láàrín àfonífojì Gadi, àti sí ìhà Jaseri. Wọ́n sì wá sí Gileadi, àti sí ilé Tatimi Hodṣi; wọ́n sì wá sí Dani Jaani àti yíkákiri sí Sidoni. Wọ́n sì wá sí ìlú olódi Tire, àti sí gbogbo ìlú àwọn Hifi, àti ti àwọn ará Kenaani, wọ́n sì jáde lọ síhà gúúsù ti Juda, àní sí Beerṣeba. Wọ́n sì la gbogbo ilẹ̀ náà já, wọ́n sì wá sí Jerusalẹmu ní òpin oṣù kẹsànán àti ogúnjọ́. Joabu sì fi iye tí àwọn ènìyàn náà jásí lé ọba lọ́wọ́. Ó sì jẹ́ ogójì ọ̀kẹ́ (800,000) ọkùnrin alágbára ní Israẹli, àwọn onídà, àwọn ọkùnrin Juda sì jẹ́ ọ̀kẹ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (500,000) ènìyàn. Dafidi yan ìbáwí Olúwa Àyà Dafidi sì gbọgbẹ́ lẹ́yìn ìgbà tí ó ka àwọn ènìyàn náà tán. Dafidi sì wí fún Olúwa pé, “Èmi ṣẹ̀ gidigidi ní èyí tí èmi ṣe, ṣùgbọ́n, èmi bẹ̀ ọ, Olúwa, fi ẹ̀ṣẹ̀ ìránṣẹ́ rẹ jì ní, nítorí pé èmi hùwà aṣiwèrè gidigidi!” Dafidi sì dìde ní òwúrọ̀, ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ Gadi wòlíì wá, aríran Dafidi wí pé, “Lọ kí o sì wí fún Dafidi pé, ‘Báyìí ni Olúwa wí, èmi fi nǹkan mẹ́ta lọ̀ ọ́; yan ọ̀kan nínú wọn, kí èmi ó sì ṣe é sí ọ.’ ” Gadi sì tọ Dafidi wá, ó sì bi í léèrè pé, “Kí ìyàn ọdún méje ó tọ̀ ọ́ wá ní ilẹ̀ rẹ bí? Tàbí kí ìwọ máa sá ní oṣù mẹ́ta níwájú àwọn ọ̀tá rẹ, nígbà tí wọn ó máa lé ọ? Tàbí kí ààrùn ìparun ọjọ́ mẹ́ta ó wá sí ilẹ̀ rẹ? Rò ó nísinsin yìí, kí o sì mọ èsì tí èmi ó mú padà tọ ẹni tí ó rán mi.” Dafidi sì wí fún Gadi pé, “Ìyọnu ńlá bá mi. Jẹ́ kí a fi ara wa lé Olúwa ní ọwọ́; nítorí pé àánú rẹ̀ pọ̀; kí ó má sì ṣe fi mí lé ènìyàn ní ọwọ́.” Olúwa sì rán ààrùn ìparun sí Israẹli láti òwúrọ̀ títí dé àkókò tí a dá, ẹgbẹ̀rún ní ọ̀nà àádọ́rin (70,000) ènìyàn sì kú nínú àwọn ènìyàn náà láti Dani títí fi dé Beerṣeba. Nígbà tí angẹli náà sì nawọ́ rẹ̀ sí Jerusalẹmu láti pa á run, Olúwa sì káàánú nítorí ibi náà, ó sì sọ fún angẹli tí ń pa àwọn ènìyàn náà run pé, “Ó tó, dá ọwọ́ rẹ dúró wàyí!” Angẹli Olúwa náà sì wà níbi ìpakà Arauna ará Jebusi. Dafidi sì wí fún Olúwa nígbà tí ó rí angẹli tí ń kọlu àwọn ènìyàn pé, “Wò ó, èmi ti ṣẹ̀, èmi sì ti hùwà búburú ṣùgbọ́n àwọn àgùntàn wọ̀nyí, kín ni wọ́n ha ṣe? Jẹ́ kí ọwọ́ rẹ, èmi bẹ̀ ọ́, kí ó wà lára mi àti ìdílé baba mi.” Pẹpẹ ní ibi ìpakà Ornani Gadi sì tọ Dafidi wá ní ọjọ́ náà, ó sì wí fún un pé, “Gòkè, tẹ́ pẹpẹ kan fún Olúwa lórí ilẹ̀ ìpakà Arauna ará Jebusi.” Gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Gadi, Dafidi sì gòkè lọ bí Olúwa ti pa á ní àṣẹ. Arauna sì wò, ó sì rí ọba àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ń bọ̀ wá lọ́dọ̀ rẹ̀, Arauna sì jáde, ó sì wólẹ̀ níwájú ọba ó sì dojú rẹ̀ bolẹ̀. Arauna sì wí pé, “Nítorí kín ni olúwa mi ọba ṣe tọ ìránṣẹ́ rẹ̀ wá?” Dafidi sì dáhùn pé, “Láti ra ibi ìpakà rẹ lọ́wọ́ rẹ, láti tẹ́ pẹpẹ kan fún Olúwa, kí ààrùn ìparun lè dá lára àwọn ènìyàn náà.” Arauna sì wí fún Dafidi pé, “Jẹ́ kí olúwa mi ọba ó mú èyí tí ó dára lójú rẹ̀, kí o sì fi í rú ẹbọ, wò ó, màlúù nìyìí láti fi ṣe ẹbọ sísun, àti ohun èlò ìpakà, àti ohun èlò mìíràn ti màlúù fún igi. Gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni Arauna fi fún ọba, bí ọba.” Arauna sì wí fún ọba pé, “Kí Olúwa Ọlọ́run rẹ ó gba ọrẹ rẹ.” Ọba sì wí fún Arauna pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́; ṣùgbọ́n èmi ó rà á ní iye kan lọ́wọ́ rẹ, bí ó ti wù kí ó ṣe; bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò fi èyí tí èmi kò náwó fún, rú ẹbọ sísun sí Olúwa Ọlọ́run mi.” Dafidi sì ra ibi ìpakà náà, àti àwọn màlúù náà ní àádọ́ta ṣékélì fàdákà. Dafidi sì tẹ́ pẹpẹ kan níbẹ̀ sí Olúwa, ó sì rú ẹbọ sísun àti ti ìlàjà. Olúwa sì gbọ́ ẹ̀bẹ̀ fún ilẹ̀ náà, ààrùn náà sì dá kúrò ní Israẹli.